“Ọ̀tá Ìkẹyìn” náà Ni A Ó Ṣẹ́gun!
NÍGBÀ tí o wà ní ọmọdé, òkùnkùn ti lè bà ọ́ lẹ́rù. Àwọn ìtàn tí ń dẹ́rùbani àti àlọ́ nípa àwọn iwin pàápàá ti lè mú ọ kún fún ìbẹ̀rùbojo. Báwo ni ó ti fi ọ́ lọ́kàn balẹ̀ tó nígbà tí ìyá tàbí bàbá rẹ bá fi àtùpà kan sílẹ̀ ní títàn bí o ti ń gbìyànjú láti sùn lọ!
Bákan náà ni ikú ṣe máa ń kó jìnnìjìnnì bá ọ̀pọ̀lọpọ̀. Síbẹ̀, kò yẹ kí ó bà wọ́n lẹ́rù. Èéṣe? Nítorí ohun tí ikú jẹ́ níti gidi.
Mọ Ọ̀tá Rẹ
Ọlọ́gbọ́n Ọba Solomoni ti Israeli ìgbàanì polongo pè: “Alààyè mọ̀ pé àwọn ó kú; ṣùgbọ́n àwọn òkú kò mọ ohun kan.” (Oniwasu 9:5) Ní ìbámu pẹ̀lú èrò tí a mísí látọ̀runwá yìí tí ó wà nínú Bibeli tìrẹ, ikú wulẹ̀ jẹ́ òdìkejì ìyè ni. Àwọn òkú kò nímọ̀lára kankan.
Ní títọ́ka sí ikú lọ́nà àpèjúwe, Kristian aposteli Paulu kọ̀wé pé: “Ikú, oró rẹ dà? Isà òkú, ìṣẹ́gun rẹ dà?” Kì ni oró náà tí ń mú ikú wá? Paulu sọ pé: “Oró [tí ń mú] ikú [wá] ni ẹ̀ṣẹ̀.” (1 Korinti 15:55, 56; Hosea 13:14) Nígbà náà, kí ni ìpilẹ̀ṣẹ̀ oró tí ó lè fa ikú yìí? Níbòmíràn nínú Ìwé Mímọ́, Paulu sọ pé: “Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀ṣẹ̀ ti ti ipa ọ̀dọ̀ ènìyàn kan wọ ayé, àti ikú nípa ẹ̀ṣẹ̀; bẹ́ẹ̀ ni ikú sì kọjá sórí ènìyàn gbogbo, láti ọ̀dọ̀ ẹni tí gbogbo ènìyàn ti dẹ́ṣẹ̀.” (Romu 5:12) Aposteli náà kò fini sínú iyèméjì nípa ẹni tí “ènìyàn kan” náà jẹ́ nígbà tí ó sọ pé: “Gbogbo ènìyàn ti kú nínú Adamu.” (1 Korinti 15:22) Bẹ́ẹ̀ni, nípasẹ̀ àìgbọ́ràn babańlá wa àkọ́kọ́, Adamu, gbogbo wa ni oró ikú lè mú.—Genesisi 3:1-19.
Pẹ̀lú ìlera dáradára àti ìdílé onífẹ̀ẹ́ nínú àwọn àyíká gbígbádùnmọ́ni, kò sí ẹnikẹ́ni nínú wa tí yóò yàn láti kú. Bí ó ti wù kí ó rí, gẹ́gẹ́ bí Bibeli ti fihàn, ‘ìgbà àti èèṣì’ lè fi ìwàláàyè dù wá. (Oniwasu 9:11) Nítòótọ́, a kò mọ ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ sí ìwàláàyè wa lọ́la. (Jakọbu 4:14) Ohun kan dájú—gbogbo wa ni a ti jogún ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú. Nítorí náà, ikú ń dọdẹ wa ó sì ń kọlù wá gẹ́gẹ́ bí ọ̀tá kan.
Kíkojú Ìṣòro Ikú Ẹnìkan tí A Fẹ́ràn
Ní pàtàkì jùlọ ni ikú jẹ́ ọ̀tá kan nígbà tí ó bá kọlu ẹnìkan tí a fẹ́ràn. “Tìrẹ ló máa burú jù níbẹ̀,” ni aya kan tí ń ṣàìṣàn bíi-kíkú-bíi-yíyè sọ fún ọkọ rẹ̀ bi ó ti ń ronú ikú. Èéṣe tí ó fi lè sọ iyẹn? Nítorí Bibeli sọ pé: “Ohunkóhun tí ọwọ́ rẹ̀ rí ní ṣíṣe, fi agbára rẹ ṣe é; nítorí tí kò sí ète, bẹ́ẹ̀ni kò sí ìmọ̀, tàbí ọgbọ́n, ní isà-òkú níbi tí ìwọ ń rè.” (Oniwasu 9:10) Àwọn òkú kò tún jìyà mọ́. Ṣùgbọ́n ẹrù-ìnira ẹ̀dùn ọkàn já lé àwọn ìbátan àti ọ̀rẹ́ tí wọ́n wàláàyé lórí. A ha lè ṣe ohunkóhun nípa irú ìjìyà bẹ́ẹ̀ bí?
Àwọn ojú-ìwé Ọ̀rọ̀ Ọlọrun, Bibeli, ní ọ̀pọ̀ ọ̀rọ̀ ìtùnú nínú. Fún àpẹẹrẹ, kíkà àti ṣíṣàṣàrò lórí àwọn psalmu dájúdájú jẹ́ orísun ìrẹnilẹ́kún kan. Nítòótọ́, ni irú àwọn ọ̀rọ̀ bí ìwọ̀nyí jẹ́ ọ̀kan tí ń tuninínú: “Olùbùkún ni Oluwa lójoojúmọ́, bí a di ẹrù rù wá; Ọlọrun náà ni ìgbàlà wa.”—Orin Dafidi 68:19.
Orísun ìtùnú mìíràn ni ìjọ Kristian. Ní ọ̀rúndún kìn-ín-ní C.E., aposteli Paulu kọ̀wé pé: “Bọ̀wọ̀ fún àwọn opó tíí ṣe opó nítòótọ́. Ṣùgbọ́n bí opó kan bá ní ọmọ tàbí ọmọ-ọmọ [tí ó lè bójútó o nípa ti ara], jẹ́ kí wọ́n tètè kọ́ àti ṣe ìtọ́jú ilé àwọn tìkáraawọn, kí wọn kí ó sì san oore àwọn òbí wọ́n padà: nítorí pé èyí ni ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà níwájú Ọlọrun. Máṣe kọ orúkọ ẹni tí ó bá dín ní ọgọ́ta ọdún sílẹ̀ bí opó, tí ó ti jẹ́ obìnrin ọkọ kan, ẹni tí a jẹ́rìí rẹ̀ fún iṣẹ́ rere; bí ó bá ti ń tọ́ ọmọ rí, bí ó bá ti ń gba àlejò, bí ó bá ti ń wẹ ẹsẹ̀ àwọn ènìyàn mímọ́, bí ó bá ti ń ran àwọn olùpọ́njú lọ́wọ́, bí ó bá ti ń lépa iṣẹ́ rere gbogbo.” (1 Timoteu 5:3, 4, 9, 10) Bákan-náà lónìí àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ń ṣèrànwọ́ wọ́n sì ń tu irú àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹ́gbẹ́ wọn bẹ́ẹ̀ nínú.
Lọ́pọ̀ ìgbà àtúnṣebọ̀sípò gíga jùlọ tí ẹni tí ọ̀fọ̀ ṣẹ̀ níláti ṣe jẹ́ ti onímìí-ẹ̀dùn. “Mo nífẹ̀ẹ́ aya mi gidigidi,” ni ọkùnrin kan tí alábàáṣègbéyàwó rẹ̀ kú ní ọdún méjì ṣáájú kọ̀wé. “Èyí ni ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó bà mí nínú jẹ́ jùlọ nínú ìgbésí-ayé mi, ó sì ṣòro fún mi láti faradà á.” Ẹnìkan tí ó ti ṣègbéyàwó fún àkókò kan ti lo ìgbésí-ayé rẹ̀ lọ́kùnrin tàbí lóbìnrin pẹ̀lú ẹlòmíràn kan nínú ipò-ìbátan ènìyàn tí ó súnmọ́ra pẹ́kípẹ́kí jùlọ. Nígbà tí alábàáṣègbéyàwó kan bá kú, ẹnìkejì tí ó wàláàyè yóò nímọ̀lára ìpàdánù ńláǹlà lọ́nà ti ó bá ìwà ẹ̀dá mú. Ta ni ẹnìkejì yẹn lè yíjú sí fún ìrànlọ́wọ́?
Nínú irú àwọn àyíká-ipò bẹ́ẹ̀, àwọn Kristian alábàákẹ́gbẹ́ rere lè jẹ́ ọ̀kan tí ń gbéniró. “Ọ̀rẹ́ a máa fẹ́ni nígbà gbogbo, ṣùgbọ́n arákùnrin ni a bí fún ìgbà ìpọ́njú,” ni òwe ọlọgbọ́n kan sọ. (Owe 17:17) Opó tàbí ọkùnrin kan tí aya rẹ̀ ti kú nílò ìrànlọ́wọ́—àwọn alábàákẹ́gbẹ́ tí ń fúnni ní ìtìlẹ́yìn gidi. Àwọn ọlọgbọ́n ọ̀rẹ́ ń fún ẹni tí ń ṣọ̀fọ̀ náà ní ìṣírí láti sọ̀rọ̀, bí ṣíṣe bẹ́ẹ̀ bá tilẹ̀ mú omijé wá. Bóyá Kristian kan tí ó ti ní ìrírí ìrora àti ẹ̀dùn-ọkàn pípàdánù alábàáṣègbéyàwó kan rí lè pèsè ìrànlọ́wọ́ onínúure. “Ẹ máa tu àwọn aláìlọ́kàn nínú,” ni Bibeli gbaninímọ̀ràn. (1 Tessalonika 5:14) Ṣùgbọ́n rántí pé àwọn opó àti àwọn ọkùnrin tí aya wọn ti kú nímọ̀lára àìsí alábàáṣègbéyàwó wọn. Nítorí náà, ẹni náà tí ọ̀fọ̀ ṣẹ níláti finúhan àwọn ẹlòmíràn kìkì lábẹ́ àwọn àyíká-ipò tí ó mú kí ó ṣeéṣe fún gbogbo wọn láti pa ìwà mímọ́ mọ́.—1 Peteru 2:12.
Aporó dídára jùlọ fún ìrora tí ikú fi ń jẹniníyà ni láti mú kí ọwọ́ ẹni dí nínú ríran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́—tí ó jẹ́ ìpèníjà gidigidi kan fún àwọn wọnnì tí wọ́n rò pé àwọn ni ẹni tí ó nílò ìrànlọ́wọ́! Níhìn-ín ni àìmọtara-ẹni-nìkan ti ń kó ipa kan. Fífi àìmọtara-ẹni-nìkan ṣe nǹkan fún àwọn ẹlòmíràn ń ṣèrànlọ́wọ́ láti lé ìbànújẹ́ àti ẹ̀dùn-ọkàn lọ kúrò, nítorí Jesu sọ pé: “Àti fúnni ó ní ìbùkún ju àti gbà lọ.”—Iṣe 20:35.
Ìṣẹ́gun Lórí Ikú
Oró oyin a máa ronilára gógó, ó tilẹ̀ lè yọrísí ikú. Ṣùgbọ́n, gẹ́gẹ́ bí ó ti sábà máa ń rí, yíyọ ẹ̀gún oró kòkòrò náà tí ó ti wọ inú ẹran-ara rẹ kúrò yóò ṣèrànwọ́ láti mú ìtura wá. Ṣùgbọ́n ìfojúsọ́nà wo ní ń bẹ fún ìtura kúrò lọ́wọ́ oró tí ń mú ikú wá?
Lẹ́yìn ṣíṣàlàyé pé oró tí ń mú ikú wá ní ẹ̀ṣẹ̀, Paulu polongo pé: “Ọpẹ́ ni fún Ọlọrun ẹni tí ó fí ìṣẹ́gun fún wa nípa Oluwa wa Jesu Kristi.” (1 Korinti 15:57) Báwo ni ìṣẹ́gun lórí ikú ṣe ní ìsopọ̀ pẹ̀lú Kristi? Jesu fihàn pé bí ọ̀ràn ti rí nìyí nígbà tí ó sọ nípa araarẹ̀ pé: “Ọmọ ènìyàn kò . . . wá kí a ṣe ìránṣẹ́ fún un, bíkòṣe láti ṣe ìránṣẹ́ fúnni, àti láti fi ẹ̀mí rẹ̀ ṣe ìràpadà ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn.” (Matteu 20:28) Bẹ́ẹ̀ni, fún àwọn wọnnì tí ń lo ìgbàgbọ́ nínú Ọmọkùnrin Ọlọrun, Jesu Kristi, àti ẹbọ ìràpadà tí Jehofa ti pèsè nípasẹ̀ rẹ̀, ikú tí a jogún láti ọ̀dọ̀ Adamu kì yóò yọrísí àìsíláàyè títílọgbére.—Johannu 3:16.
Àwọn ọ̀rọ̀ Jesu jẹ́ èyí tí ń múnilọ́kànyọ̀ nítòótọ́: “Wákàtí ń bọ̀, nínú èyí tí gbogbo àwọn tí ó wà ní isà-òkú yóò gbọ́ ohùn rẹ̀. Wọn ó sì jáde wá; àwọn tí ó ṣe rere, sí àjíǹde ìyè; àwọn tí ó sì ṣe búburú, sí àjíǹde ìdájọ́.”—Johannu 5:28, 29.
Ní ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún ṣáájú, Isaiah wòlíì Ọlọrun ti sọtẹ́lẹ̀ pé: “Òun [Jehofa Ọlọrun] óò gbé ikú mì láéláé; Oluwa Jehofa yóò nu omijé nù kúrò ní ojú gbogbo ènìyàn.” (Isaiah 25:8) Lẹ́ẹ̀kan síi, ní Ìfihàn 21:4, Bibeli gbé ìfojúsọ́nà àgbàyanu yìí kalẹ̀: “Ọlọrun yóò sì nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú wọn; kì yóò sì sí ikú mọ́, tàbí ọ̀fọ̀, tàbí ẹkún, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sí ìrora mọ́: nítorí pé ohun àtijọ́ ti kọjá lọ.” Bí a ti fokun fún wọn nípasẹ̀ ìrètí Bibeli yìí fún àwọn wọnnì tí ń sùn nínú ikú, ko sí ìdí fún àwọn tí ọ̀fọ̀ ṣẹ̀ láti máa “binújẹ́ bí àwọn ìyókù tí kò ní ìrètí.”—1 Tessalonika 4:13.
Gbìyànjú láti fojú inú wo ohun tí Ọlọrun ní ní ìpamọ́ fún aráyé, gẹ́gẹ́ bí a ti ṣípayá rẹ̀ nínú Bibeli. “Ìpọ́njú ńlá” náà tí ó kù sí dẹ̀dẹ̀ túmọ̀sí àgbákò ìparun fún ètò-ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan búburú ti ìsinsìnyí. (Ìfihàn 7:14) Àwọn wọnnì tí ń ṣe ìsìn èké ni a parun. Àwọn ìsọ̀rí àwùjọ ti ìṣèlú àti ti ìṣòwò tí wọ́n jẹ́ oníwọra tí wọ́n pakún ìyàn àti ogun jíjà ti lọ kúrò. Jesu Kristi tẹ̀síwájú láti sọ Satani Eṣu, tí ó ti ṣokùnfà ikú ènìyàn púpọ̀ gan-an sínú ọ̀gbun àìnísàlẹ̀. Lẹ́yìn náà ni Kristi bẹ̀rẹ̀ Àkóso Ìjọba Ẹlẹ́gbẹ̀rún-Ọdún rẹ̀, lákòókò èyí tí òun lo ìníyelórí ẹbọ ìràpadà rẹ̀ fún aráyé. Àwọn òkú padà wá nípasẹ̀ àjíǹde tí a ń retí náà, ìmọ́lẹ̀ láti inú Ọ̀rọ̀ Ọlọrun sì mọ́lẹ̀ kedere tóbẹ́ẹ̀ tí ó fi jẹ́ pé àwọn ojú-ìwòye ti ìgbàgbọ́ nínú ohun asán nípa ikú, ọ̀tá aráyé, kò tún sí mọ́. Gbogbo àwọn tí ń bẹ láàyè nígbà náà ní àǹfààní láti kẹ́kọ̀ọ́ àwọn ọ̀nà Ọlọrun kí wọ́n sì mú araawọn bá àwọn ọ̀pá ìdíwọ̀n òdodo rẹ̀ mu.—Owe 4:18; Iṣe 24:15; Heberu 2:14, 15; Ìfihàn 18:4-8; 19:19-21; 20:1-3.
‘Nígbà náà ni òpin yóò dé,’ ni Paulu sọ, ‘nígbà tí Kristi Jesu bá fi ìjọba fún Ọlọrun àní Baba. Nítorí pé òun kò lè ṣàìmá jọba títí yóò fi fi gbogbo àwọn ọ̀tá sábẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀. Ikú ni ọ̀tá ìkẹyìn tí a ó parun.’ (1 Korinti 15:24-26) Gbogbo àbùkù-ara tí ó jẹ́ àbájáde ẹ̀ṣẹ̀ Adamu ti lọ kúrò. Ìdánwò ìkẹyìn wáyé, àwọn olùfẹ́ Ọlọrun sì là á kọjá pẹ̀lú ìṣòtítọ́. (Ìfihàn 20:4-10) Bí a ti mú wọn padàbọ̀ sípò ìjẹ́pípé, àwọn ènìyàn onígbọràn wọ̀nyí wàláàyé, kìí ṣe fún àádọ́rin tàbí àádọ́fà ọdún lásán, ṣùgbọ́n títíláé. Ẹ wo ẹ̀bùn tí èyí jẹ́ láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun nípasẹ̀ àyànfẹ́ Ọmọkùnrin rẹ̀!—Romu 6:23.
Wàyí o, nígbà náà, báwo ni ìwọ ṣe lè wàláàyè pẹ́ tó? Àkókò ìgbésí-ayé rẹ lè lọ kánrin títí ayérayé. Ní wíwàláàyè bí ìwọ ti wà nísinsìnyí nínú “àkókò òpin” ti ayé yìí, ìwọ lè má kú láé. (Danieli 12:4; Johannu 11:25, 26; 17:3) Bí ìwọ bá ṣe ìfẹ́-inú Ọlọrun, ìwọ lè wàláàyè wọnú ayé titun tí Ọlọrun ṣèlérí gan-an.—2 Peteru 3:13.
Bí ó ti wù kí ó rí, bí o bá tí darúgbó, ìwọ gbọ́dọ̀ fojú tòótọ́ gbé ṣíṣeéṣe náà láti kú yẹ̀wò. Dájúdájú, ìrètí àjíǹde ń mú ayọ̀ wá. Ṣùgbọ́n ìwọ lè ṣe kàyééfì nípa bí Jehofa yóò ṣe ṣètò ìgbésí-ayé ìdílé nínú ètò àwọn nǹkan titun yẹn. Máṣe jẹ́ kí irú àwọn ọ̀ràn bẹ́ẹ̀ mú ọ ṣàníyàn, nítorí pé Jehofa yóò rí síi pé ayọ̀ àwọn wọnnì tí wọ́n jẹ́ olùṣòtítọ́ sí i wà pẹ́ títí.
Bí àwọn “ìkẹyìn ọjọ́” lílekoko ti ètò-ìgbékalẹ̀ burúkú ti Satani wọ̀nyí ti ń lọ sí òpin wọn, máṣe jẹ́ kí ìbẹ̀rú ikú jà ọ́ lólè àǹfààní ṣíṣiṣẹ́sin Jehofa nísinsìnyí gan-an. (2 Timoteu 3:1) Bí ìwọ bá pàdánù ẹnìkan tí o fẹ́ràn nínú ikú, fi àìwàpẹ́títí agbára rẹ̀ tu araàrẹ nínú. (Ìfihàn 20:13, 14) Nígbẹ̀ẹ́kẹ̀lé nínú ìrètí àjíǹde. Nígbà náà, yálà ìwọ wọlé sínú ayé titun náà nípa líla ìpọ́njú ńlá náà já tàbí nípasẹ̀ àjíǹde, ní ìdánilójú nípa ẹ̀rí tí a mísí náà pé ikú, ọ̀tá ìkẹyìn, ni a ó sọ dòfo.—Ìfihàn 7:9, 14.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]
Àwọn Kristian alábàákẹ́gbẹ́ rere lè gbé ẹni tí ọ̀fọ̀ ṣẹ̀ ró nípa tẹ̀mí
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Mímú kí ọwọ́ ẹni dí nínú ríran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ ń dín ẹ̀dùn-ọkàn tí ikú ẹnìkan tí a fẹ́ràn mú wá kù