ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • ijwbq àpilẹ̀kọ 54
  • Kí Nìdí Tí Àwa Èèyàn Fi Ń Kú?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Kí Nìdí Tí Àwa Èèyàn Fi Ń Kú?
  • Ohun Tí Bíbélì Sọ
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ohun tí Bíbélì sọ
  • Jésù Ń gbani Là—Lọ́nà Wo?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2001
  • Kí Nìdí Tí Jésù Fi Kú?
    Ohun Tí Bíbélì Sọ
  • Ki Ni Ẹ̀ṣẹ̀ Ìpilẹ̀ṣẹ̀?
    Ohun Tí Bíbélì Sọ
  • Kí Nìdí Tí Jésù Fi Jìyà Tó sì Kú?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2016
Àwọn Míì
Ohun Tí Bíbélì Sọ
ijwbq àpilẹ̀kọ 54

Kí Nìdí Tí Àwa Èèyàn Fi Ń Kú?

Ohun tí Bíbélì sọ

Kò burú rárá tí a bá béèrè pé kí nìdí tí àwa èèyàn fi ń kú, àgàgà tí ẹnì kan tá a fẹ́ràn gan-an bá kú. Bíbélì sọ pé: “Oró ikú ni ẹ̀ṣẹ̀.”​—1 Kọ́ríńtì 15:56, Bíbélì Mímọ́.

Kí nìdí tí àwa èèyàn fi ń dẹ́sẹ̀ tí a sì ń kú?

Àwọn èèyàn tí Ọlọ́run kọ́kọ́ dá, ìyẹn Ádámù àti Éfà kú torí pé wọ́n dẹ́ṣẹ̀ sí Ọlọ́run. (Jẹ́nẹ́sísì 3:17-19) Ohun kan ṣoṣo tó lè jẹ́ àbájáde ìwà ọ̀tẹ̀ tí wọ́n hù sí Ọlọ́run ni ikú, torí pé Ọlọ́run “ni orísun ìyè.”​—Sáàmù 36:9; Jẹ́nẹ́sísì 2:17.

Gbogbo àtọmọdọ́mọ Ádámù pátá ló jogún ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀. Bíbélì sọ pé: “Ẹ̀ṣẹ̀ ti tipasẹ̀ ènìyàn kan wọ ayé àti ikú nípasẹ̀ ẹ̀ṣẹ̀, ikú sì tipa báyìí tàn dé ọ̀dọ̀ gbogbo ènìyàn nítorí pé gbogbo wọn ti dẹ́ṣẹ̀.” (Róòmù 5:12) Gbogbo èèyàn kú nítorí gbogbo wọn ń dẹ́ṣẹ̀.​—Róòmù 3:23.

Bí ikú ṣe máa dópin

Ọlọ́run ṣèlérí pé ìgbà kan ń bọ̀ tí “òun yóò gbé ikú mì títí láé.” (Aísáyà 25:8) Kí Ọlọ́run tó lè mú ikú kúrò, ó gbọ́dọ̀ fòpin sí ẹ̀ṣẹ̀ tó ń fa ikú. Ọlọ́run yóò fòpin sí ikú nípasẹ̀ Jésù Kristi, ẹni “tí ó kó ẹ̀ṣẹ̀ ayé lọ.”​—Jòhánù 1:29; 1 Jòhánù 1:7.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́