Ẹ ní Ìgboyà Dáradára!
“Ẹ ní ìgboyà dáradára kí ẹ sì wí pe: ‘Jehofa ni olùrànlọ́wọ́ mi.’” —HEBERU 13:6, NW.
1. Àìṣojo wo ni àwọn wọnnì tí wọ́n kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ Ọlọrun ní ọ̀rúndún kìn-ín-ní C.E. fihàn?
NÍ Ọ̀RÚNDÚN kìn-ín-ní nínú Sànmánì Tiwa ni. Messia tí a ti ń dúrò dè tipẹ́ náà ti dé. Ó ti kọ́ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ dáradára ó sì ti ṣèfilọ́lẹ̀ iṣẹ́ ìwàásù ṣíṣekókó kan. Àkókò tó fún àwọn ènìyàn láti wàásù ìhìnrere Ìjọba Ọlọrun. Fún ìdí yìí, àwọn ọkùnrin àti obìnrin tí wọ́n ti kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ fi àìṣojo polongo ìhìn-iṣẹ́ àgbàyanu yẹn.—Matteu 28:19, 20.
2. Èéṣe tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa fi nílò ìgboyà lónìí?
2 Ìjọba náà ni a kò fìdí rẹ̀ múlẹ̀ ní àwọn ọjọ́ wọnnì. Ṣùgbọ́n Àyànsípòṣe-Ọba náà, Jesu Kristi, ti sàsọtẹ́lẹ̀ nípa wíwàníhìn-ín rẹ̀ ọjọ́ iwájú láìṣeéfojúrí nínú agbára Ìjọba. A ó sàmì sí i nípa irú àwọn nǹkan bíi ogun tí kò ní alábàádọ́gba, ìyàn, àjàkálẹ̀-àrùn, ìsẹ̀lẹ̀, àti ìwàásù ìhìnrere kárí-ayé. (Matteu 24:3-14; Luku 21:10, 11) Gẹ́gẹ́ bí Ẹlẹ́rìí fún Jehofa, a nílò ìgboyà láti kojú ìṣòro àwọn ipò wọ̀nyí àti inúnibíni tí a bá nírìírí rẹ̀. Nítorí náà yóò ṣàǹfààní láti ṣàyẹ̀wò àwọn àkọsílẹ̀ Bibeli nípa àwọn onígboyà olùpòkìkí Ìjọba náà ní ọ̀rúndún kìn-ín-ní C.E.
Ìgboyà Láti Ṣàfarawé Kristi
3. Ta ni ó pèsè àpẹẹrẹ ìgboyà dídára jùlọ, kí ni a sì sọ nípa rẹ̀ nínú Heberu 12:1-3?
3 Jesu Kristi pèsè àpẹẹrẹ ìgboyà dídára jùlọ. Lẹ́yìn tí ó ti tọ́kasí ‘àwọsánmà ńlá’ ti àwọn ẹlẹ́rìí Jehofa onígboyà ṣáájú àkókò Kristian, aposteli Paulu kó àfiyèsí jọ sára Jesu nípa sísọ pé: “Nítorí náà bí a ti fi àwọ̀sánmà tí ó kún tó báyìí fún àwọn ẹlẹ́rìí yí wa ká, ẹ jẹ́ kí á pa ohun ìdíwọ́ gbogbo tì sí apákan, àti ẹ̀ṣẹ̀ tí ó rọrùn láti dì mọ́ wa, kí a sì máa fi sùúrù súré ìje tí a gbé ka iwájú wa. Kí a máa wo Jesu olùpilẹ̀ṣẹ̀ àti aláṣepé ìgbàgbọ́ wa; ẹni, nítorí ayọ̀ tí a gbé ka iwájú rẹ̀, tí ó farada [òpó-igi ìdálóró, NW], láìka ìtìjú sí, tí ó sì jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún ìtẹ́ Ọlọrun. Ṣáà ro ti ẹni tí ó farada irú ìsọ̀rọ̀-òdì yìí láti ọ̀dọ̀ àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ sí ara wọn, kí ẹ má baà rẹ̀wẹ̀sì ní ọkàn yín, kí àárẹ̀ sì mú yín.”—Heberu 12:1-3.
4. Báwo ni Jesu ṣe fi ìgboyà hàn nígbà ti Satani dán an wò?
4 Lẹ́yìn ìrìbọmi rẹ̀ àti ogójì ọjọ́ fún àṣàrò, àdúrà, àti ààwẹ̀ nínú aginjù, Jesu fi ìgboyà dojúùjà kọ Satani. Bí Eṣu ti dán an wò láti sọ àwọn òkúta di àkàrà, Jesu kọ̀ nítorí pé ó lòdì làti ṣe iṣẹ́ ìyanu láti fi tẹ́ ìfẹ́-ọkàn ara-ẹni lọ́rùn. Jesu sọ pé: “A ti kọ̀wé rẹ̀ pé, Ènìyàn kì yóò wà láàyè nípa àkàrà nìkan, bíkòṣe nípa gbogbo ọ̀rọ̀ tí ó ti ẹnu Ọlọrun jáde wá.” Nígbà ti Satani gbé ìpèníjà dìde sí i láti bẹ́ láti orí odi òrùlé tẹ́ḿpìlì, Jesu kọ̀ nítorí pé ìbá ti jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ láti dán Ọlọrun wò láti yọ ọ́ nínú ewu tí ó lè yọrísí ìfọwọ́ ara-ẹni para-ẹni. “A tún kọ ọ́ pé,” ni Kristi sọ, “Ìwọ kò gbọ́dọ̀ dán Oluwa Ọlọrun rẹ wò.” Satani fi gbogbo ìjọba ayé lọ̀ ọ́ fún ‘ìforíbalẹ̀’ kanṣoṣo, ṣùgbọ́n Jesu kò jẹ́ hùwà ìpẹ̀yìndà kí ó sì ṣètìlẹ́yìn fún ìpèníjà Eṣu pé àwọn ènìyàn kò ní dúró bí olóòótọ́ sí Ọlọrun lábẹ́ ìdánwò. Nítorí náà Jesu polongo pé: “Padà kúrò lẹ́yìn mi, Satani: nítorí a kọ̀wé rẹ̀ pé, Oluwa Ọlọrun rẹ ni kí ìwọ kí ó foríbalẹ̀ fún, òun nìkanṣoṣo ni kí ìwọ máa sìn.” Kí ni ó gbọ́ ìyẹn sí, Olùdẹwò náà “fi í sílẹ̀ lọ di sáà kan.”—Matteu 4:1-11; Luku 4:13.
5. Kí ni ó lè ràn wá lọ́wọ́ láti dojúkọ ìdẹwò?
5 Jesu wà ní ìtẹríba fún Jehofa ó sì kọjúùjà sí Satani. Bí àwa bákan náà bá ‘tẹríba fún Ọlọrun tí a sì kọ ojú ìjà sí Eṣu, òun ó sá kúrò lọ́dọ̀ wa.’ (Jakọbu 4:7) Bíi ti Jesu, àwa lè fi tìgboyà-tìgboyà ko ìdẹwò lójú bí a bá fi Ìwé Mímọ́ sílò, bóyá kí a tilẹ̀ fa ọ̀rọ̀ wọn yọ nígbà tí a bá dẹ wá wò láti ṣe ohun kan tí ó kún fún ẹ̀ṣẹ̀. Ó ha ṣeéṣe pé kí a juwọ́sílẹ̀ fún ìdẹwò láti dẹ́ṣẹ̀ olè-jíjà bí a bá tún òfin Ọlọrun náà sọ fún araawa pé: “Ìwọ kò gbọ́dọ̀ jalè”? Ṣíṣeéṣe náà ha wà pé àwọn Kristian méjì yóò jọ̀gọ̀nù fún ìwà-pálapàla ìbálòpọ̀ takọtabo kání ọ̀kan nínú wọn tilẹ̀ fi tìgboyà-tìgboyà mẹ́nukan àwọn ọ̀rọ̀ náà pé: “Ìwọ kò gbọ́dọ̀ ṣe panṣágà”?—Romu 13:8-10; Eksodu 20:14, 15.
6. Báwo ni Jesu ṣe jẹ́ onígboyà aṣẹ́gun ayé?
6 Gẹ́gẹ́ bíi Kristian tí ayé yìí kórìíra, a lè yẹra fún ẹ̀mí àti ìwà rẹ̀ tí ó kún fún ẹ̀ṣẹ̀. Jesu sọ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Nínú ayé, ẹ̀yin ó ní ìpọ́njú; ṣùgbọ́n ẹ tújúká; mo ti ṣẹ́gun ayé.” (Johannu 16:33) Ó yọ ayọ̀ ìṣẹ́gun lórí ayé nípa ṣíṣàìdàbí rẹ̀. Àpẹẹrẹ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí aṣẹ́gun àti àbájáde ipa-ọ̀nà ìpàwàtítọ́mọ́ rẹ̀ lè mú kí a kún fún ìgboyà láti ṣàfarawé rẹ̀ nípa wíwà ní ìyàsọ́tọ̀ kúrò nínú ayé yìí kí a má sì ṣe sọ wá di ẹlẹ́gbin nípasẹ̀ rẹ̀.—Johannu 17:16.
Ìgboyà Láti Máa Wàásù Nìṣó
7, 8. Kí ni yóò ràn wá lọ́wọ́ láti máa wàásù nìṣó láìka inúnibíni sí?
7 Jesu àti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ gbáralé Ọlọrun fún ìgboyà láti máa wàásù nìṣó láìka inúnibíni sí. Kristi fi àìṣojo mú iṣẹ́-òjíṣẹ́ rẹ̀ ṣẹ láìka inúnibíni sí, lẹ́yìn Pentekosti 33 C.E., àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ tí a ṣenúnibíni sí ń polongo ìhìnrere náà nìṣó bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn aṣáájú ìsìn Ju gbìyànjú láti dá wọn dúró. (Iṣe 4:18-20; 5:29) Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn gbàdúrà pé: “Oluwa, kíyèsí ìkìlọ̀ wọn: kí o sì fifún àwọn ọmọ-ọ̀dọ̀ rẹ láti máa fi ìgboyà gbogbo sọ ọ̀rọ̀ rẹ.” Kí ni ó sì ṣẹlẹ̀? “Nígbà tí wọ́n gbàdúrà tán, ibi tí wọ́n gbé péjọ sí mì tìtì; gbogbo wọn sì kún fún Ẹ̀mí Mímọ́, wọ́n sì ń fi ìgboyà sọ ọ̀rọ̀ Ọlọrun.”—Iṣe 4:24-31.
8 Níwọ̀n bí ọ̀pọ̀ jùlọ nínú àwọn ènìyàn lónìí kò ti ṣetán láti gba ìhìnrere, àìṣojo ní a máa ń sábàá nílò láti máa wàásù fún wọn nìṣó. Ní pàtàkì jùlọ nígbà tí a bá ṣenúnibíni sí wọn, àwọn ìránṣẹ́ Jehofa nílò ìgboyà tí Ọlọrun fi fúnni kí wọ́n baà lè jẹ́rìí kúnnákúnná. (Iṣe 2:40; 20:24) Nítorí náà olùfìgboyà pòkìkí Ìjọba náà Paulu sọ fún alábàáṣiṣẹ́pọ̀ rẹ̀ kan tí ó jẹ́ èwe, tí kò fi bẹ́ẹ̀ nírìírí pé: “Ọlọrun kò fún wa ni ẹ̀mí ìbẹ̀rù; bíkòṣe ti agbára, àti ti ìfẹ́, àti ti inú tí ó yè kooro. Nítorí náà máṣe tijú ẹ̀rí Oluwa wa, tàbí èmi òǹdè rẹ̀: ṣùgbọ́n kí ìwọ kí ó ṣe alábàápín nínú ìpọ́njú ìhìnrere gẹ́gẹ́ bí agbára Ọlọrun.” (2 Timoteu 1:7, 8) Bí a bá gbàdúrà fún ìgboyà, àwa yóò lè máa wàásù nìṣó, inúnibíni kì yóò sì lè gba ayọ̀ wa kúrò lọ́wọ́ wa gẹ́gẹ́ bí olùpòkìkí Ìjọba.—Matteu 5:10-12.
Ìgboyà Láti Mú Ìdúró Síhà Ọ̀dọ̀ Jehofa
9, 10. (a) Kí ni àwọn Ju àti Keferi ọ̀rúndún kìn-ín-ní ṣe kí wọ́n baà lè di ọmọlẹ́yìn Kristi tí a baptisi? (b) Èéṣe tí ó fi gba ìgboyà láti di Kristian?
9 Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn Ju àti Keferi ọ̀rúndún kìn-ín-ní fi tìgboyà-tìgboyà pa àwọn àṣà-àtọwọ́dọ́wọ́ tí kò bá ìwé mímọ́ mu tì láti di ọmọlẹ́yìn Kristi tí a baptisi. Kété lẹ́yìn Pentekosti 33 C.E., “iye àwọn ọmọ-ẹ̀yìn sì pọ̀ síi gidigidi ní Jerusalemu; ọ̀pọ̀ nínú ẹgbẹ́ àwọn àlùfáà sì fetísí ti ìgbàgbọ́ náà.” (Iṣe 6:7) Àwọn Ju wọnnì ní ìgboyà láti já ìdè ti ìsìn kí wọ́n sì tẹ́wọ́gba Jesu gẹ́gẹ́ bíi Messia.
10 Bẹ̀rẹ̀ ní 36 C.E., ọ̀pọ̀ àwọn Keferi di onígbàgbọ́. Nígbà tí Korneliu, àwọn mẹ́ḿbà ìdílé rẹ̀, àti àwọn Keferi mìíràn gbọ́ ìhìnrere náà, wọ́n tẹ́wọ́gbà á ní kánmọ́, wọ́n gba ẹ̀mí mímọ́, a sì “baptisi wọn ní orúkọ Jesu Kristi.” (Iṣe 10:1-48) Ní Filippi Keferi onítúbú kan àti agbo-ilé rẹ̀ yára tẹ́wọ́gba ìsìn Kristian, “a sì baptisi rẹ̀, àti gbogbo àwọn ènìyàn rẹ̀ lójú kan-náà.” (Iṣe 16:25-34) Ó béèrè fún ìgboyà láti gbé irú ìgbésẹ̀ bẹ́ẹ̀ nítorí pé àwọn Kristian ti jẹ́ àwùjọ kékeré kan tí kò gbajúmọ̀, tí a ń ṣenúnibíni sí. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣì jẹ́ síbẹ̀. Ṣùgbọ́n bí ìwọ kò bá tíì ṣe ìyàsímímọ́ sí Ọlọrun kí a sì baptisi rẹ gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa, àkókò kò ha ti tó fún ọ láti gbé àwọn ìgbésẹ̀ onígboyà wọ̀nyí bí?
Ìgboyà Nínú Àwọn Agbo-Ilé tí Ó Pínyà
11. Àwọn àpẹẹrẹ ìgboyà rere wo ni Eunike àti Timoteu pèsè?
11 Eunike àti ọmọkùnrin rẹ̀ Timoteu gbé àpẹẹrẹ ìgbàgbọ́ onígboyà kalẹ̀ nínú agbo-ilé tí ó pínyà níti ìsìn. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Eunike ní ọkọ tí ó jẹ́ abọ̀rìṣà, ó kọ́ ọmọkùnrin rẹ̀ ní “ìwé-mímọ́” láti ìgbà ọmọdé. (2 Timoteu 3:14-17) Lẹ́yìn tí ó di Kristian tán, ó fi “ìgbàgbọ́ àìṣẹ̀tàn” hàn. (2 Timoteu 1:5) Ó tún ni ìgboyà náà láti fi ẹ̀kọ́ Kristian kọ́ Timoteu nígbà tí ó ń fi ọ̀wọ̀ hàn fún ipo-orí ọkọ rẹ̀ tí ó jẹ́ aláìgbàgbọ́. Dájúdájú, ìgbàgbọ́ àti ìgboyà rẹ̀ ni a san èrè fún nígbà tí a yan ọmọkùnrin rẹ̀ tí ó ti kọ́lẹ́kọ̀ọ́ dáradára láti máa bá Paulu rìn nínú àwọn ìrìn-àjò ìjíhìn-iṣẹ́ Ọlọrun rẹ̀. Báwo ni èyí ti lè fún àwọn òbí Kristian tí wọ́n bá araawọn nínú àyíká-ipò kan-náà ní ìṣírí tó!
12. Irú ènìyàn wo ni Timoteu dì, àwọn wo ni wọ́n sì ń fẹ̀rí hàn pé àwọn dàbí rẹ̀ nísinsìnyí?
12 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Timoteu gbé nínú agbo-ilé tí ó pínyà níti ìsìn, òun fi tìgboyà-tìgboyà tẹ́wọ́gba ìsìn Kristian ó sì di ẹni tẹ̀mí tí Paulu fi lè sọ nípa rẹ̀ pé: “Mo ní ìrètí nínú Jesu Oluwa, láti rán Timoteu sí yín [àwọn ará Filippi] ní lọ́ọ́lọ́ọ́ yìí, kí èmi pẹ̀lú lè ní ìfàyàbalẹ̀ nígbà tí mó bá gbúròó ìjókòó yín. Nítorí èmi kò ní ẹni onínú kan-náà tí ó dàbí rẹ̀, tí yóò máa fi tinútinú ṣe àníyàn yín. . . . Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ti mọ̀ ọ́n dájúdájú, pé gẹ́gẹ́ bí ọmọ lọ́dọ̀ baba rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni ó sì ti ń bá mi ṣiṣẹ́ pọ̀ nínú ìhìnrere.” (Filippi 2:19-22) Lónìí, ọ̀pọ̀ àwọn ọmọdékùnrin àti ọmọdébìnrin nínú àwọn ilé tí ó pínyà níti ìsìn ń fìgboyà tẹ́wọ́gba ìsìn Kristian tòótọ́. Bíi Timoteu wọ́n ń fi ẹ̀rí hàn nípa araawọn, a sì ti láyọ̀ tó pé wọ́n jẹ́ apákan ètò-àjọ Jehofa!
Ìgboyà Láti ‘Fi Ọrùn Wa Wewu’
13. Ní ọ̀nà wo ni Akuila àti Priskilla gbà fi ìgboyà hàn?
13 Akuila àti aya rẹ̀, Priskilla (Priska), fi àpẹẹrẹ kan lélẹ̀ nípa fífi tìgboyà-tìgboyà ‘fi ọrùn wọn wewu’ fùn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wọn kan. Wọ́n gba Paulu sínú ilé wọn, wọ́n bá a ṣe iṣẹ́ àgọ́ pípa papọ̀, wọ́n sì ràn án lọ́wọ́ láti gbé ìjọ titun tí ó wà ní Korinti ró. (Iṣe 18:1-4) Láàárín ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún ìbádọ́rẹ̀ẹ́ wọn, wọ́n tilẹ̀ mú ìwàláàyè wọn wá sábẹ́ ewu nítorí tirẹ̀ ni ọ̀nà kan tí a kò sọ. Wọ́n ń gbé ní Romu nígbà tí ó sọ fún àwọn Kristian níbẹ̀ pé: “Ẹ kí Priska àti Akuila, àwọn alábàáṣiṣẹ́ mi nínú Kristi Jesu: àwọn ẹni tí ó, ti ìtorí ẹ̀mí mi, fi ọrùn wọn lélẹ̀ [“wewu,” NW]: fún àwọn ẹni tí kìí ṣe kìkì èmi nìkan ni ó ń dúpẹ́, ṣùgbọ́n gbogbo ìjọ láàárín àwọn Keferi pẹ̀lú.”—Romu 16:3, 4.
14. Nípa fífi ọrùn wọn wewu fún Paulu, Akuila àti Priska ń gbégbèésẹ̀ ní ìbámu pẹ̀lú òfin wo?
14 Nípa fífi ọrùn wọn wewu fun Paulu, Akuila àti Priska gbégbèésẹ̀ ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ Jesu pé: “Òfin titun kan ni mo fifún yín, kí ẹ̀yin kí ó fẹ́ ọmọnìkejì yín; gẹ́gẹ́ bí èmi ti fẹ́ràn yín, kí ẹ̀yin kí ó sì lè fẹ́ràn ọmọnìkejì yín.” (Johannu 13:34) Òfin yìí jẹ́ “titun” níti pé ó lọ rékọjá ohun tí Òfin Mose béèrè fún pé kí ẹnìkan fẹ́ràn aládùúgbò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ó ti fẹ́ràn araarẹ̀. (Lefitiku 19:18) Ó béèrè fún ìfẹ́ ìfira-ẹni-rúbọ tí yóò lọ jìnnà débi fífi ìwàláàyè ẹni lélẹ̀ fún àwọn ẹlòmíràn, gẹ́gẹ́ bí Jesu ti ṣe. Òǹkọ̀wé náà Tertullian ti ọ̀rúndún ìkejì àti ìkẹta C.E. fa ọ̀rọ̀ àwọn ènìyàn ayé yọ nípa àwọn Kristian nígbà tí ó kọ̀wé pé: “‘Wò ó,’ ni wọ́n sọ, ‘bí wọ́n ti fẹ́ràn araawọn tó . . . tí wọ́n sì múratán àní láti kú fún araawọn pàápàá.’” (Apology, orí XXXIX, 7) Ní pàtàkì nígbà inúnibíni ó lè di ohun àìgbọ́dọ̀máṣe fún wa láti fi ìfẹ́ ará hàn nípa fífi tìgboyà-tìgboyà fi ẹ̀mí wa wewu láti lè yẹra fún fífi ìdáàbòbò kúrò lọ́wọ́ ìwà òkú-òǹrorò tàbí ikú láti ọwọ́ ọ̀tá du àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wa.—1 Johannu 3:16.
Ìgboyà Ń Mú Ayọ̀ Wá
15, 16. Gẹ́gẹ́ bí a ti fihàn ní Iṣe orí 16, báwo ni a ṣe lè so ìgboyà àti ayọ̀ pọ̀?
15 Paulu àti Sila pèsè ẹ̀rí pé fífí ìgboyà hàn láàárín àdánwò lè mú ayọ̀ wá. Nípa àṣẹ láti ọ̀dọ̀ àwọn adájọ́ ìbílẹ̀ ní ìlú Filippi, a fi ọ̀pá nà wọ́n ní gbangba à sì fi wọ́n sínú àbà nínú ẹ̀wọ̀n. Síbẹ̀, wọn kò fìbẹ̀rù ṣojo pẹ̀lú ìsoríkodò. Láìka àwọn àyíká-ipò wọn tí ń dánniwò sí, wọn ṣì ní ìgboyà tí Ọlọrun fi fúnni àti ayọ̀ tí ó ń mú wá fún àwọn Kristian olùṣòtítọ́.
16 Ní nǹkan bíi ọ̀gànjọ́ òru, Paulu àti Sila ń gbàdúrà wọ́n sì ń fi orin yin Ọlọrun. Lójijì, ìsẹ̀lẹ̀ kan mi ọgbà ẹ̀wọ̀n náà tìtì, ó tú ìdè wọn, ó sì ṣí ilẹ̀kùn sílẹ̀ gbayawu. Onítúbú tí jìnnìjìnnì ti dàbò náà àti ìdílé rẹ̀ ní a fún ní ìjẹ́rìí aláìṣojo tí ó jálẹ̀ sí ìrìbọmi wọn gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ Jehofa. Òun fúnraarẹ̀ “yọ̀ gidigidi pẹ̀lú gbogbo àwọn ará ilé rẹ̀, nítorí ó gba Ọlọrun gbọ́.” (Iṣe 16:16-34) Èyí yóò ti mú ayọ̀ wá fún Paulu àti Sila tó! Lẹ́yìn tí a ti gbé èyí àti àwọn àpẹẹrẹ Ìwé Mímọ́ mìíràn yẹ̀wò, báwo ní a ṣe lè máa jẹ́ onígboyà nìṣó gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ Jehofa?
Ẹ Máa Ní Ìgboyà Dáradára Nìṣó
17. Gẹ́gẹ́ bí a ti fihàn ní Orin Dafidi 27, báwo ni níní ìrètí nínú Jehofa ṣe tanmọ́ ìgboyà?
17 Níní ìrètí nínú Jehofa yóò ràn wá lọ́wọ́ láti máa jẹ́ onígboyà nìṣó. Dafidi kọrin pé: “Ní ìrètí nínú Jehofa; jẹ́ onígboyà kí o sì mú ọkàn-àyà rẹ lókun. Bẹ́ẹ̀ni, ní ìrètí nínú Jehofa.” (Orin Dafidi 27:14, NW) Orin Dafidi 27 fihàn pé Dafidi gbáralé Jehofa gẹ́gẹ́ bí “agbára” ẹ̀mí rẹ̀. (Ẹsẹ 1) Rírí tí Dafidi rí ohun tí Ọlọrun ti ṣe sí àwọn elénìní rẹ̀ ní ìgbà tí ó ti kọjá fún un ní ìgboyà. (Ẹsẹ 2, 3) Ìmọrírì fún ọ̀gangan ibi ìkóríjọ fún ìjọsìn Jehofa jẹ́ kókó abájọ mìíràn. (Ẹsẹ 4) Níní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú ìrànlọ́wọ́, ìdáàbòbò, àti ìdáǹdè Jehofa tún gbé ìgboyà Dafidi ró pẹ̀lú. (Ẹsẹ 5 sí 10) Pẹ̀lúpẹ̀lú, ìtọ́ni tí ń báa lọ nínú àwọn ìlànà nípa ọ̀nà òdodo Jehofa, tún ṣèrànlọ́wọ́. (Ẹsẹ 11) Àdúrà onígbọ̀ọ́kànlé fún ìdáǹdè kúrò lọ́wọ́ àwọn elénìní rẹ̀, papọ̀ pẹ̀lú ìgbàgbọ́ àti ìrètí, ran Dafidi lọ́wọ́ láti jẹ́ onígboyà. (Ẹsẹ 12 sí 14) Àwa pẹ̀lú lè gbé ìgboyà wa ró lọ́nà kan-náà, kí a sì tipa bẹ́ẹ̀ fihàn pé nítòótọ́ ní a “ní ìrètí nínú Jehofa.”
18. (a) Kí ni ó fihàn pé ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ déédéé pẹ̀lú àwọn olùjọ́sìn Jehofa ẹlẹgbẹ́ wa lè ràn wá lọ́wọ́ láti máa jẹ́ onígboyà nìṣó? (b) Ipa wo ni àwọn ìpàdé Kristian ń kó nínú gbígbé ìgboyà ró?
18 Ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ déédéé pẹ̀lú àwọn olùjọ́sìn Jehofa ẹlẹgbẹ́ wa lè ràn wá lọ́wọ́ láti máa jẹ́ onígboyà nìṣó. Nígbà tí Paulu pẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn síwájú Kesari tí ó sì ń rìnrìn-àjò lọ sí Romu, àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ pàdé rẹ̀ níbi Ọjà Apii Foroni àti Àrójẹ Mẹ́ta. “Nígbà tí Paulu sì rí wọn,” ni àkọsílẹ̀ náà sọ, “ó dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọrun, ó mú ọkàn le.” (Iṣe 28:15) Bí a ti ń lọ sí àwọn ìpàdé Kristian déédéé, a ń kọbiara sí ìmọ̀ràn Paulu: “Ẹ jẹ́ kí a yẹ ara wa wò láti rú ara wa sí ìfẹ́ àti sí iṣẹ́ rere: kí á má máa kọ ìpéjọpọ̀ ara wa sílẹ̀, gẹ́gẹ́ bí àṣà àwọn ẹlòmíràn; ṣùgbọ́n kí a máa gba ara ẹni níyànjú: pẹ̀lúpẹ̀lú bí ẹ̀yin ti rí i pé ọjọ́ nì ń súnmọ́ etílé.” (Heberu 10:24, 25) Kí ni ó túmọ̀sí láti gba ara ẹni níyànjú? Láti gbaniníyànjú túmọ̀sí “láti mú kún fún ìgboyà, ẹ̀mí, tàbí ìrètí.” (Webster’s Ninth New Collegiate Dictionary) A lè ṣe púpọ̀ láti mú kí àwọn Kristian mìíràn kún fún ìgboyà, ìgbaniníyànjú tiwọn pẹ̀lú sì lè gbé ànímọ́ yìí ró nínú wa.
19. Báwo ni Ìwé Mímọ́ àti àwọn ìtẹ̀jáde Kristian ṣe tanmọ́ra pẹ̀lú bibáa nìṣó wa láti máa jẹ́ onígboyà?
19 Láti máa jẹ́ onígboyà nìṣó, a gbọ́dọ̀ máa kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọrun déédéé kí a sì fi ìmọ̀ràn rẹ̀ sílò nínú ígbésí-ayé wa. (Deuteronomi 31:9-12; Joṣua 1:8) Ìkẹ́kọ̀ọ́ déédéé wa níláti ní àwọn ìtẹ̀jáde Kristian tí a gbékarí Ìwé Mímọ́ nínú, nítorí pé ìmọ̀ràn yíyèkooro tí a ó tipa bẹ́ẹ̀ pèsè yóò ràn wá lọ́wọ́ láti kojú àwọn ìdánwò ìgbàgbọ́ pẹ̀lú ìgboyà tí Ọlọrun fi fúnni. Láti inú àwọn àkọsílẹ̀ Bibeli, a ti rí bí àwọn ìránṣẹ́ Jehofa ti jẹ́ onígboyà nínú àwọn onírúurú ipò-ọ̀ràn. Ní lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí, a lè má mọ bí irú ìsọfúnni bẹ́ẹ̀ ṣe lè ràn wá lọ́wọ́, ṣùgbọ́n Ọ̀rọ̀ Ọlọrun ní agbára, ohun tí a bá sì kọ́ láti inú rẹ̀ lè ṣàǹfààní fún wa nígbà gbogbo. (Heberu 4:12) Fún àpẹẹrẹ, bí ìbẹ̀rù ènìyàn bá níláti bẹ̀rẹ̀ síí nípa lórí iṣẹ́-òjíṣẹ́ wa, a lè rántí bí Enoku ti ṣe ní ìgboyà láti fi ìhìn-iṣẹ́ Ọlọrun jíṣẹ́ fún àwọn aláìwà-bí-Ọlọ́run.—Juda 14, 15.
20. Èéṣe tí a fi lè sọ pé àdúrà ṣekókó bí a bá níláti máa jẹ́ onígboyà nìṣó gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ Jehofa?
20 Láti máa jẹ́ onígboyà nìṣó gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ Jehofa, a gbọ́dọ̀ máa forítì nínú àdúrà. (Romu 12:12) Jesu farada àwọn àdánwó rẹ̀ tìgboyà-tìgboyà nítorí pé ó “fi ẹkún rara àti omijé gbàdúrà, tí ó sì bẹ̀bẹ̀ lọ́dọ̀ ẹni tí ó lè gbà á sílẹ̀ lọ́wọ́ ikú, a sì gbóhùn rẹ̀ nítorí ẹ̀mí ọ̀wọ̀ rẹ̀.” (Heberu 5:7) Nípa sísúnmọ́ Ọlọrun pẹ́kípẹ́kí nínú àdúrà, àwa kì yóò dàbí àwọn ojo inú ayé tí a ti kádàrá pé wọn yóò nírìírí “ikú kejì” nínú èyí tí kò sí àjíǹde. (Ìfihàn 21:8) Ààbò àtọ̀runwá àti ìyè nínú ayé titun Ọlọrun wà fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ onígboyà.
21. Èéṣe tí àwọn adúróṣinṣin Ẹlẹ́rìí Jehofa fi lè jẹ́ onígboyà?
21 Gẹ́gẹ́ bí Ẹlẹ́rìí adúróṣinṣin ti Jehofa, kò sí ìdí fún wa láti bẹ̀rù àwọn ẹ̀mí-èṣù tàbí àwọn ènìyàn tí wọ́n jẹ́ ọ̀tá, nítorí a ní ìtìlẹ́yìn Ọlọrun àti àpẹẹrẹ ìgboyà ti Jesu gẹ́gẹ́ bí aṣẹ́gun ayé. Ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ tí ń gbéniró nípa tẹ̀mí pẹ̀lú àwọn ènìyàn Jehofa bákan-náà lè ràn wá lọ́wọ́ láti jẹ́ onígboyà. Ìgboyà wa ni a tún ń gbéró nípasẹ̀ ìtọ́sọ́nà àti ìmọ̀ràn inú Ìwé Mímọ́ àti àwọn ìtẹ̀jáde Kristian. Àkọsílẹ̀ Bibeli nípa àwọn ìránṣẹ́ Ọlọrun ní ìgbà àtijọ́ sì tún ràn wá lọ́wọ́ láti fi tìgboyà-tìgboyà rìn ní àwọn ọ̀nà rẹ̀. Nítorí náà, ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn lílekoko wọ̀nyí, ẹ jẹ́ kí á máa fi àìṣojo tẹ̀síwájú nìṣó nínú iṣẹ́-ìsìn mímọ́-ọlọ́wọ̀. Bẹ́ẹ̀ni, ẹ jẹ́ kí gbogbo ènìyàn Jehofa ní ìgboyà dáradára!
Báwo Ni Ìwọ Yóò Ṣe Fèsìpadà?
◻ Báwo ni àpẹẹrẹ Jesu ṣe lè mú kí a kún fùn ìgboyà?
◻ Kí ni ó fún Jesu àti àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ní ìgboyà láti máa wàásù nìṣó?
◻ Èéṣe tí àwọn Ju àti Keferi fi nílò ìgboyà láti mú ìdúró níhà ọ̀dọ̀ Jehofa?
◻ Àwọn àpẹẹrẹ ìgboyà wo ni Eunike àti Timoteu pèsè?
◻ Ẹ̀rí wo ni ó wà pé ìgboyà ń mú ayọ̀ wá nígbà inúnibíni pàápàá?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
Bíi Jesu, àwa lè ko ìdẹwò lójú bí a bá fi Ìwé Mímọ́ sílò tí a sì mẹ́nukàn án