Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
Níwọ̀n bí ó ti jẹ́ pé àlùfáà ìgbàanì tí a pè ní Melkisedeki jẹ́ ènìyàn gidi kan, èéṣe tí Bibeli fi sọ pé òun wà “láìní ìlà ìdílé”?
Gbólóhùn-ọ̀rọ̀ yìí ni a sọ ní Heberu 7:3. Kíyèsí ẹsẹ náà nínú àyíká-ọ̀rọ̀ rẹ̀:
“Nítorí Melkisedeki yìí, ọba Salemu, àlùfáà Ọlọrun Ọ̀gá-Ògo, ẹni tí ó pàdé Abrahamu bí ó ti ń padà láti ibi pípa àwọn ọba bọ̀, tí ó sì súre fún un; ẹni tí Abrahamu sì pín ìdámẹ́wàá ohun gbogbo fún; ní ọ̀nà èkínní ní ìtumọ̀ rẹ̀ ọba òdodo, àti lẹ́yìn náà pẹ̀lú ọba Salemu, tíí ṣe ọba àlááfíà; láìní baba, láìní ìyá, láìní [ìlà ìdílé, NW], bẹ́ẹ̀ ni kò ní ìbẹ̀rẹ̀ ọjọ́ tàbí òpin ọjọ́ ayé; ṣùgbọ́n a ṣe é bi Ọmọ Ọlọrun; ó wà ní àlùfáà títí.”—Heberu 7:1-3.
Gẹ́gẹ́ bí a ti mẹ́nukàn án, Melkisedeki jẹ́ ènìyàn gidi kan, ó jẹ́ gidi bíi Abrahamu, ẹni tí ó ní àjọṣepọ̀ tààràtà pẹ̀lú. (Genesisi 14:17-20; Heberu 7:4-10) Bí ìyẹn bá rí bẹ́ẹ̀, Melkisedeki ti níláti ní òbí, bàbá kan àti ìyá kan, òun sì ti níláti ní àwọn ọmọ. Fún ìdí yìí, gẹ́gẹ́ bí ènìyàn kan ó ní ìlà ìdílé, tàbí àwòrán ìlà ìdílé. Ó tún ní òpin ìgbésí-ayé rẹ̀ nípa ti ara. Nígbà tí ó tó àkókò kan Melkisedeki kú, ní ìbámu pẹ̀lú gbólóhùn-ọ̀rọ̀ aposteli Paulu ní Romu 5:12, 14. Ṣùgbọ́n níwọ̀n bí a kò ti mọ ìgbà ti Melkisedeki kú tí ó sì tipa bẹ́ẹ̀ ṣíwọ́ láti máa ṣiṣẹ́sìn gẹ́gẹ́ bí àlùfáà, ní ọ̀nà yẹn ó ṣiṣẹ́sìn láìsí òpin kan tí a mọ̀.
Nínú Heberu, Paulu ṣe àwọn àlàyé nípa Melkisedeki nígbà tí ó ń jíròrò ipa-iṣẹ́ Jesu Kristi gẹ́gẹ́ bí Àlùfáà Àgbà onípò gíga jù. Ní títọ́ka sí Melkisedeki gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ-irú, tàbí àpẹẹrẹ àwòṣe, ti Jesu nínú ipa-iṣẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bi àlùfáà, Paulu sọ pé: “Jesu ti . . . jẹ́ [àlùfáà àgbà, NW] títíláé nípa ẹsẹ̀ Melkisedeki.” (Heberu 6:20) Ní èrò-ìtumọ̀ wo?
Paulu ti gbọ́dọ̀ mọ̀ pé àkọsílẹ̀ Bibeli kò fúnni ní kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa ìlà-ìran ìdílé Melkisedeki—àwọn babańlá rẹ̀ tàbí ọmọ-ìran èyíkéyìí kan. Ìsọfúnni yẹn kìí wulẹ̀ ṣe ọ̀ràn àkọsílẹ̀ inú Bibeli. Nítorí náà, láti inú ojú-ìwòye ohun tí Paulu mọ̀ tàbí tí àwa mọ̀, Melkisedeki ni a lè fi pẹ̀lú ẹ̀tọ́ sọ nípa rẹ̀ pé ó wà “láìní ìlà ìdílé” (New World Translation of the Holy Scriptures; American Standard Version), “láìní àkọsílẹ̀ lẹ́sẹẹsẹ orírun” (W. J. Conybeare), tàbí tí kò ní “àwòrán ìlà ìdílé kankan.”—J. B. Phillips.
Ní ọ̀nà wo ni Jesu gbà rí bẹ́ẹ̀? Kí á gbà pé, a mọ̀ pé Jehofa Ọlọrun ni Bàbá Jesu àti pé ìyà rẹ̀ tí ó jẹ́ ènìyàn ni Maria ti ẹ̀yà Juda. Síbẹ̀, ìbáradọ́gba kan wà láàárín Melkisedeki àti Jesu. Báwo ni ó ṣe rí bẹ́ẹ̀? Jesu ni a kò bí nínú ẹ̀yà Lefi, ẹ̀yà ti àwọn àlùfáà ní orílẹ̀-èdè Israeli. Rárá, Jesu ni kò di àlùfáà nípasẹ̀ ìlà ìdílé ènìyàn. Bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú sì ni Melkisedeki, ẹni ti kò di àlùfáà “gẹ́gẹ́ bí òfin ìlànà nípa ti ara,” ìyẹn ni pé, nípa bíbí i sínú ẹ̀yà àti ìdílé àlùfáà. (Heberu 7:15, 16) Dípò kí ó di àlùfáà nípasẹ̀ bàbá kan tí ó jẹ́ ènìyàn tí òun fúnraarẹ̀ ti jẹ́ àlùfáà, Jesu ni “a yàn ní [àlùfáà àgbà, NW] láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun wá nípa ẹsẹ̀ Melkisedeki.”—Heberu 5:10.
Síwájú síi, Jesu kò ní àwọn ọmọ ìran tàbí àrólé èyíkéyìí tí yóò gba ipò àlùfáà rẹ̀. Ní èrò-ìtumọ̀ yìí pẹ̀lú, òun wà láìní ìlà ìdílé. Yóò máa bá iṣẹ́-ìsìn àlùfáà rẹ̀ lọ títí ayérayé gẹ́gẹ́ bí olùkọ́ni tí ń rannilọ́wọ́. Paulu ṣàlàyé lórí iṣẹ́-ìsìn títílọkánrin yìí, ní wíwí pé:
“Nítorí tí [Jesu] wà títíláé, ó ní oyè àlùfáà tí a kò lè rọ̀nípò. Nítorí náà ó sì lè gbà wọ́n là pẹ̀lú títí dé òpin, ẹni tí ó bá tọ Ọlọrun wá nípasẹ̀ rẹ̀, nítorí tí ó ń bẹ láàyè títíláé láti máa bẹ̀bẹ̀ fún wọn.”—Heberu 7:24, 25.
Nítorí náà ìgbéyẹ̀wò tí a ṣe nípa ọ̀rọ̀ Paulu tí ó wà ní Heberu 7:3 nílatí rékọjá ìrépé ìmọ̀ kan tí a níláti tọ́jú pamọ́ sórí wa lásán. Ó nílatí túbọ̀ fi agbára fún ìmọrírì wa fún ìpèsè onífẹ̀ẹ́ tí Jehofa Ọlọrun ti ṣe fún wa láti rí ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ gbà láìnípẹ̀kun àti fún ọ̀nà tí òun ti ṣètò fún wa làti rí ìrànlọ́wọ́ àti ìtọ́sọ́nà gbà títílọkánrin.