ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w93 12/1 ojú ìwé 19-24
  • Aláyọ̀ ni Àwọn Onírẹ̀lẹ̀-Ọkàn

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Aláyọ̀ ni Àwọn Onírẹ̀lẹ̀-Ọkàn
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìgbàgbọ́ Nínú Jehofa Ń Ràn Wá Lọ́wọ́ Láti Jẹ́ Onírẹ̀lẹ̀-Ọkàn
  • Ìrẹ̀lẹ̀-Ọkàn—Ipa-Ọ̀nà Ọgbọ́n
  • Ìrẹ̀lẹ̀-Ọkàn Ń Mú Kí A Ní Ìbátan Rere Pẹ̀lú Àwọn Ẹlòmíràn
  • Ìfẹ́ Yóò Ràn Wá Lọ́wọ́ Láti Jẹ́ Onírẹ̀lẹ̀-Ọkàn
  • Ní Ojúlówó Ẹ̀mí Ìrẹ̀lẹ̀
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2005
  • Báwo Lo Ṣe Lè Fi Ojúlówó Ẹ̀mí Ìrẹ̀lẹ̀ Hàn?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
  • Jèhófà Ń ṣí Ògo Rẹ̀ Payá Fáwọn Onírẹ̀lẹ̀
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
  • Jèhófà Mọyì Àwọn Ìránṣẹ́ Rẹ̀ Tó Jẹ́ Onírẹ̀lẹ̀
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2019
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
w93 12/1 ojú ìwé 19-24

Aláyọ̀ ni Àwọn Onírẹ̀lẹ̀-Ọkàn

“Ọlọrun kọjúùjà sí àwọn onírera, ṣùgbọ́n ó ń fi inúrere àìlẹ́tọ̀ọ́sí fún àwọn onírẹ̀lẹ̀-ọkàn.”—1 PETERU 5:5, NW.

1, 2. Báwo ni Jesu ṣe so ọ̀ràn jíjẹ́ aláyọ̀ pọ̀ mọ́ ti jíjẹ́ onírẹ̀lẹ̀-ọkàn nínú Ìwàásù rẹ̀ Lórí Òkè?

JÍJẸ́ aláyọ̀ àti jíjẹ́ onírẹ̀lẹ̀-ọkàn ha báratan bí? Nínú ìwàásù rẹ̀ tí ó lókìkí jùlọ, Jesu Kristi, ọkùnrin títóbilọ́lá jùlọ tí ó tíì gbé ayé rí, ṣàpèjúwe ayọ̀, tàbí inúdídùn mẹ́sàn-án. (Matteu 5:1-12) Jesu ha mú jíjẹ́ aláyọ̀ bá jíjẹ́ onírẹ̀lẹ̀-ọkàn tan bí? Bẹ́ẹ̀ni, ó ṣe bẹ́ẹ̀, nítorí pé jíjẹ́ onírẹ̀lẹ̀-ọkan wémọ́ púpọ̀ nínú àwọn ayọ̀ tí òun mẹ́nukàn. Fún àpẹẹrẹ, ẹnìkan níláti jẹ́ onírẹ̀lẹ̀-ọkàn kí àìní rẹ̀ nípa tẹ̀mí tó lè jẹ ẹ́ lọ́kàn. Kìkì àwọn onírẹ̀lẹ̀-ọkàn ni ebi ń pa tí òùngbẹ sì ń gbẹ fún òdodo. Àwọn agbéraga kìí sìí ṣe oníwàtútù wọn kìí sìí ṣe aláàánú, bẹ́ẹ̀ ni wọn kìí ṣe onílàjà.

2 Àwọn onírẹ̀lẹ̀-ọkàn láyọ̀ nítorí pé ó tọ̀nà kò sì lábòsí láti jẹ́ onírẹ̀lẹ̀-ọkàn. Jù bẹ́ẹ̀ lọ, àwọn onírẹ̀lẹ̀-ọkàn láyọ̀ nítorí pé ó bọ́gbọ́nmu láti jẹ́ onírẹ̀lẹ̀-ọkàn; ó ń mú kí a ní ìbátan rere pẹ̀lú Jehofa Ọlọrun àti àwọn Kristian ẹlẹgbẹ́ wa. Síwájú síi pẹ̀lú, àwọn ènìyàn tí wọ́n jẹ́ onírẹ̀lẹ̀-ọkàn láyọ̀ nítorí pé ó jẹ́ ìfìfẹ́hàn ní apá ọ̀dọ̀ wọn láti jẹ́ onírẹ̀lẹ̀-ọkàn.

3. Èéṣe tí àìlábòsí fi mu kí ó jẹ́ ohun àìgbọ́dọ̀máṣe fún wa láti jẹ́ onírẹ̀lẹ̀-ọkàn?

3 Èéṣe tí àìlábòsí fi béèrè pé kí a jẹ́ onírẹ̀lẹ̀-ọkàn? Fún ohun kan, ó jẹ́ nítorí pé gbogbo wa jogún àìpé a sì ń ṣe àṣìṣe léraléra. Aposteli Paulu sọ nípa araarẹ̀ pé: “Èmi mọ̀ pé kò sí ohun rere kan tí ń gbé inú mi, èyíinì nínú ara mi: nítorí ìfẹ́ ohun tí ó dára ń bẹ fún mi, ṣùgbọ́n ọ̀nà àtiṣe é ni èmi kò rí.” (Romu 7:18) Bẹ́ẹ̀ni, gbogbo wa ni a ti dẹ́ṣẹ̀ tí a sì ti kùnà ògo Ọlọrun. (Romu 3:23) Òtítọ́ yóò pa wá mọ́ láti máṣe jẹ́ agbéraga. Ó béèrè fún ìrẹ̀lẹ̀-ọkàn láti gba àṣìṣe, àìlábòsí yóò sì ràn wá lọ́wọ́ láti gba ẹ̀bi nígbàkigbà tí a bá ṣe àṣìṣe. Níwọ̀n bí a ti ń kùnà láti dójú-ìwọ̀n ohun tí a ń làkàkà láti ṣe, a ní ìdí tí ó yèkooro láti jẹ́ onírẹ̀lẹ̀-ọkàn.

4. Ìdí tí ń múnilápàpàǹdodo wo ni a fifúnni ní 1 Korinti 4:7 fún jíjẹ́ tí ó yẹ kí a jẹ́ onírẹ̀lẹ̀-ọkàn?

4 Aposteli Paulu fún wa ní ìdí mìíràn tí àìlábòsí fi níláti mú wa jẹ́ onírẹ̀lẹ̀-ọkàn. Ó sọ pé: “Ta ni ó mú ọ yàtọ̀? kí ni ìwọ sì ní tí ìwọ kò ti gbà? ǹjẹ́ bí ìwọ bá sì ti gbà á, èéhatiṣe tí ìwọ fi ń halẹ̀, bí ẹni pé ìwọ kò gbà á?” (1 Korinti 4:7) Kò sí iyèméjì nípa rẹ̀ pé, fún wa láti gba ògo fún araawa, láti gbéraga nípa àwọn ohun-ìní, òye, tàbí àṣeyọrí wa, kò ní jẹ́ àìlábòsí. Àììlábòsí ń pakún níní ẹ̀rí-ọkàn rere wa níwájú Ọlọrun, kí a baà lè “hùwà-darí araawa ní àìlábòsí nínú ohun gbogbo.”—Heberu 13:18, NW.

5. Báwo ni àìlábòsí pẹ̀lú yóò ṣe ràn wá lọ́wọ́ nígbà tí a bá ti ṣe àṣìṣe kan?

5 Àìlábòsí ń ràn wá lọ́wọ́ láti jẹ́ onírẹ̀lẹ̀-ọkàn nígbà tí a bá ṣe àṣìṣe. Yóò mú kí a túbọ̀ wà ní ìmúratán láti gba ẹ̀bi, dípò gbígbìyànjú láti dá araawa láre tàbí kí a ti ẹ̀bi náà sí ẹlòmíràn. Nípa báyìí, nígbà tí ó jẹ́ pé Adamu dẹ́bi fún Efa, Dafidi kò dẹ́bi fún Batṣeba, ní sísọ pé, ‘Òun kì bá tí wẹ̀ níbi tí ojú ti lè rí i. Ọ̀nà dà tí a kò fi ní dán mi wò.’ (Genesisi 3:12; 2 Samueli 11:2-4) Nítòótọ́, a lè sọ pé ní ọwọ́ kan, jíjẹ́ aláìlábòsí ń ràn wá lọ́wọ́ láti jẹ́ onírẹ̀lẹ̀-ọkàn; ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, jíjẹ́ onírẹ̀lẹ̀-ọkàn ń ràn wá lọ́wọ́ láti jẹ́ aláìlábòsí.

Ìgbàgbọ́ Nínú Jehofa Ń Ràn Wá Lọ́wọ́ Láti Jẹ́ Onírẹ̀lẹ̀-Ọkàn

6, 7. Báwo ni ìgbàgbọ́ nínú Ọlọrun ṣe ń ràn wá lọ́wọ́ láti jẹ́ onírẹ̀lẹ̀-ọkàn?

6 Ìgbàgbọ́ nínú Jehofa yóò tún ràn wá lọ́wọ́ láti jẹ́ onírẹ̀lẹ̀-ọkàn. Mímọrírì bí Ẹlẹ́dàá, Ọba-Aláṣẹ Àgbáyé, ti tóbi tó nítòótọ́, yóò mú kí a yẹra fún kíka araawa sí ẹni tí ó ṣe pàtàkì jù. Báwo ni wòlíì Isaiah ti rán wa létí èyí dáradára tó! Ní Isaiah 40:15, 22, a kà pé: “Kíyèsí i, àwọn orílẹ̀-èdè dàbí ìró kan nínú omi ládugbó, a sì kà wọ́n bí ekuru kín-ún nínú ìwọ̀n: . . . òun ni ẹni tí ó jókòó lórí òbìrí ayé, gbogbo àwọn tí ń gbé ibẹ̀ sì dàbí ẹlẹ́ǹgà.”

7 Ìgbàgbọ́ nínú Jehofa yóò tún ràn wá lọ́wọ́ nígbà tí a bá nímọ̀lára pé a ti jìyà àìṣèdájọ́ òdodo. Dípò kí a kanra nítorí ọ̀ràn náà, àwa yóò fi ìrẹ̀lẹ̀-ọkàn dúró dé Jehofa, gẹ́gẹ́ bí onípsalm náà ti rán wa létí ní Orin Dafidi 37:1-3, 8, 9. Aposteli Paulu sọ kókó kan-náà pé: “Olùfẹ́, ẹ máṣe gbẹ̀san ara yín, ṣùgbọ́n ẹ fi ààyè sílẹ̀ fún ìbínú; nítorí a ti kọ ọ́ pé, Oluwa wí pé, Tèmi ni ẹ̀san, èmi ó gbẹ̀san.”—Romu 12:19.

Ìrẹ̀lẹ̀-Ọkàn—Ipa-Ọ̀nà Ọgbọ́n

8. Èéṣe tí ìrẹ̀lẹ̀-ọkàn fi ń mú kí a ní ipò-ìbátan rere pẹ̀lú Jehofa?

8 Ìdí púpọ̀ ni ó wà tí jíjẹ́ onírẹ̀lẹ̀-ọkàn fi jẹ́ ipa-ọ̀nà ọgbọ́n. Ọ̀kan ni pé, gẹ́gẹ́ bí a ti fihàn ṣáájú, ó ń mú kí a ní ìbátan rere pẹ̀lú Olùṣẹ̀dá wa. Ní kedere ni Ọ̀rọ̀ Ọlọrun sọ ní Owe 16:5 pé: “Olúkúlùkù ènìyàn tí ó gbéraga ní àyà, ìríra ni lójú Oluwa.” A tún kà ní Owe 16:18 pé: “Ìgbéraga níí ṣáájú ìparun, agídí ọkàn níí ṣáájú ìṣubú.” Bópẹ́-bóyá agbéraga ènìyàn a bọ́ sínú ìbànújẹ́. Ó wulẹ̀ níláti rí bẹ́ẹ̀ nítorí ohun tí a kà ní 1 Peteru 5:5 (NW): “Gbogbo yín ẹ fi ìrẹ̀lẹ̀ èrò-inú di ara yín ní àmùrè sí ara yín ẹnìkínní kejì, nítorí Ọlọrun kọjúùjà sí àwọn onírera, ṣùgbọ́n ó ń fi inúrere àìlẹ́tọ̀ọ́sí fún àwọn onírẹ̀lẹ̀-ọkàn.” Ìwọ yóò rí kókó kan-náà nínú òwe-àkàwé tí Jesu fúnni nípa Farisi àti agbowó-òde tí ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ń gbàdúrà. Agbowó-òde náà tí ó jẹ́ onírẹ̀lẹ̀-ọkàn ni a fihàn pé ó jẹ́ olódodo jù.—Luku 18:9-14.

9. Ìrànlọ́wọ́ wo ni ìrẹ̀lẹ̀-ọkàn jẹ́ nínú àwọn ipò tí kò báradé?

9 Ìrẹ̀lẹ̀-ọkàn jẹ́ ipa-ọ̀nà ọgbọ́n nítorí pé ìrẹ̀lẹ̀-ọkàn ń mú kí ó túbọ̀ rọrùn fún wa láti kọbiara sí ìmọ̀ràn tí a rí ní Jakọbu 4:7 pé: “Nítorí náà ẹ tẹríba fún Ọlọrun.” Bí a bá jẹ́ onírẹ̀lẹ̀-ọkàn, àwa kì yóò ṣọ̀tẹ̀ nígbà ti Jehofa bá yọ̀ọ̀da pé kí a jìyà ipò-àìbáradé. Ìrẹ̀lẹ̀-ọkàn yóò mú kí ó ṣeéṣe fún wa láti ní ìtẹ́lọ́rùn pẹ̀lú àwọn àyíká-ipò wa àti láti faradà. Agbéraga ènìyàn jẹ́ aláìnítẹ̀ẹ́lọ́rùn, nígbà gbogbo ni ó ń fẹ́ púpọ̀ síi ṣáá, tí ó sì ń ṣọ̀tẹ̀ ní àwọn àyíká-ipò tí kò máyọ̀wá. Ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, onírẹ̀lẹ̀-ọkàn a máa farada àwọn ìnira àti àdánwò, àní gẹ́gẹ́ bí Jobu pàápàá ti ṣe. Jobu jìyà ìpàdánù gbogbo ohun-ìní rẹ̀ pátá a sì fi àrùn ríronilára kan kọlù ú, lẹ́yìn náà sì ni aya rẹ̀ gbà á nímọ̀ràn láti tẹ̀lé ipa-ọ̀nà ìgbéraga, ní wíwí pé: “Bú Ọlọrun kí o sì kú.” Báwo ni òun ṣe dáhùnpadà? Àkọsílẹ̀ Bibeli sọ fún wa pé: “Òun dá a lóhùn pé, ìwọ sọ̀rọ̀ bí ọ̀kan nínú àwọn obìnrin aláìmòye tií sọ̀rọ̀; kínla! àwa ó ha gba ire lọ́wọ́ Ọlọrun, kí a má sì gba ibi! Nínú gbogbo èyí Jobu kò fi ètè rẹ̀ ṣẹ̀.” (Jobu 2:9, 10) Nítorí pé Jobu jẹ́ onírẹ̀lẹ̀-ọkàn, òun kò ṣọ̀tẹ̀ ṣùgbọ́n ó fi pẹ̀lú ọgbọ́n juwọ́sílẹ̀ fún ohunkóhun tí Jehofa bá yọ̀ọ̀da pé kí ó wá sórí rẹ̀. Àti níkẹyìn rẹ̀ a san èrè dídọ́ṣọ̀ fún un.—Jobu 42:10-16; Jakọbu 5:11.

Ìrẹ̀lẹ̀-Ọkàn Ń Mú Kí A Ní Ìbátan Rere Pẹ̀lú Àwọn Ẹlòmíràn

10. Báwo ni ìrẹ̀lẹ̀-ọkàn ṣe ń mú ìbátan wa sunwọ̀n síi pẹ̀lú àwọn Kristian ẹlẹgbẹ́ wa?

10 Ìrẹ̀lẹ̀-ọkàn jẹ́ ipa-ọ̀nà ọgbọ́n nítorí pé ó ń mú kí a ní ìbátan rere pẹ̀lú àwọn Kristian ẹlẹgbẹ́ wa. Ó bọ́gbọ́nmu pé aposteli Paulu gbà wá nímọ̀ràn pé: [Ẹ máṣe] ohunkóhun láti inú ẹ̀mí gbólóhùn-asọ̀ tàbí láti inú ògo-asán, ṣùgbọ́n pẹ̀lú ìrẹ̀lẹ̀ èrò-inú kí ẹ máa kà á sí pé àwọn ẹlòmíràn lọ́lá jù yín lọ, ní mímójútó, kìí ṣe kìkì àǹfààní-ire ara-ẹni nínú àwọn kókó-ọ̀ràn tiyín fúnraayín nìkan, ṣùgbọ́n nínú àǹfààní-ire ara-ẹni wọnnì tí wọ́n jẹ́ ti àwọn ẹlòmíràn pẹ̀lú.” (Fillipi 2:3, 4, NW) Ìrẹ̀lẹ̀-ọkàn yóò mú kí a fi pẹ̀lú ọgbọ́n yẹra fún bíbá àwọn ẹlòmíràn díje tàbí gbìyànjú láti tayọ rékọjá àwọn ẹlòmíràn. Irú ìṣarasíhùwà èrò-orí bẹ́ẹ̀ yóò mú ìṣòro wá fún wa àti fún àwọn Kristian ẹlẹgbẹ́ wa.

11. Èéṣe tí ìrẹ̀lẹ̀-ọkàn fi lè ràn wá lọ́wọ́ láti yẹra fún ṣíṣe àwọn àṣìṣe?

11 Ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà ìrẹ̀lẹ̀-ọkàn yóò ràn wá lọ́wọ́ láti yẹra fún ṣíṣe àṣìṣe. Báwo ni ó ṣe lè rí bẹ́ẹ̀? Nítorí pé ìrẹ̀lẹ̀-ọkàn yóò pa wá mọ́ kúrò nínú jíjẹ́ ẹni tí ó dá ara wa lójú jù. Kàkà bẹ́ẹ̀, àwa yóò mọrírì ìmọ̀ran Paulu ní 1 Korinti 10:12 pé: “Ẹni tí ó bá rò pé òun dúró, kí ó kíyèsára, kí ó má baà ṣubú.” Agbéraga ènìyàn jẹ́ ẹni tí ó da araarẹ̀ lójú jù, nítorí náà ó ní ìtẹ̀sí láti ṣe àwọn àṣìṣe nítorí àwọn agbára-ìdarí láti ẹ̀yìn-òde tàbí àwọn àìlera tirẹ̀.

12. Ìrẹ̀lẹ̀-ọkàn yóò jẹ́ kí a dójú ìlà ohun tí Ìwé Mímọ́ béèrè fún wo?

12 Ìrẹ̀lẹ̀-ọkàn yóò ràn wá lọ́wọ́ láti dójú ìlà àwọn ohun tí a béèrè fún níti wíwà ní ìtẹríba. Ní Efesu 5:21 (NW), a gbà wá nímọ̀ràn pé: “Ẹ máa wà ní ìtẹríba fún ara yín ẹnìkínní kejì ní ìbẹ̀rù Kristi.” Níti gidi, gbogbo wa kò ha níláti wà ní ìtẹríba bí? Àwọn ọmọ níláti tẹríba fún àwọn òbí wọn, àwọn aya fún àwọn ọkọ wọn, ati àwọn ọkọ fún Kristi. (1 Korinti 11:3; Efesu 5:22; 6:1) Lẹ́yìn náà, nínú ìjọ Kristian èyíkéyìí, gbogbo ènìyàn, títíkan àwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́-òjíṣẹ́, níláti fi ìtẹríba hàn fún àwọn alàgbà. Kìí ha ṣe òtítọ́ pẹ̀lú pé àwọn alàgbà wà ní ìtẹríba fún ẹgbẹ́ ẹrú olùṣòtítọ́, pàápàá jùlọ gẹ́gẹ́ bí a ti ń ṣojú fún wọn nípasẹ̀ alábòójútó àyíká? Ní àfikún, alábòójútó àyíká gbọ́dọ̀ wà ní ìtẹríba fún alábòójútó àgbègbè, àti alábòójútó àgbègbè fún Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka ilẹ̀ náà tí òun ti ń ṣiṣẹ́sìn. Kí ni nípa ti àwọn mẹ́ḿbà Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka? Wọ́n gbọ́dọ̀ wà ‘ní ìtẹríba fún ara wọn ẹnìkínní kejì’ àti pẹ̀lú fún Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso, ti ń ṣojú fún ẹgbẹ́ ẹrú olùṣòtítọ́ àti ọlọ́gbọ́n-inú tí, àwọn pẹ̀lú, yóò jíhìn fún Jesu, Ọba tí a ti gbégun-orí-ìtẹ́ náà. (Matteu 24:45-47, NW) Gẹ́gẹ́ bí ó ti rí nínú ẹgbẹ́ àwọn alàgbà èyíkéyìí, àwọn mẹ́ḿbà Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso níláti bọ̀wọ̀ fún ojú-ìwòye àwọn yòókù. Fún àpẹẹrẹ, ẹnìkan lè rò pé òun ní èrò-ọkàn dídára kan. Ṣùgbọ́n bíkòṣe pé iye tí ó pọ̀ tó nínú àwọn mẹ́ḿbà yòókù bá gbà pẹ̀lú ìmọ̀ràn rẹ̀, ó wulẹ̀ níláti gbé ọ̀ràn náà tì sápákan ni. Lóòótọ́, gbogbo wa nílò ìrẹ̀lẹ̀-ọkàn, nítorí pé gbogbo wa ni a wà ní ìtẹríba.

13, 14. (a) Nínú àyíká-ipò wo ní pàtàkì ni ìrẹ̀lẹ̀-ọkàn yóò ti ràn wá lọ́wọ́? (b) Àpẹẹrẹ wo ni Peteru gbé kalẹ̀ níti títẹ́wọ́gba ìmọ̀ràn?

13 Ní pàtàkì jùlọ ni a lè rí i pé ìrẹ̀lẹ̀-ọkàn jẹ́ ipa-ọ̀nà ọgbọ́n níti pé ìrẹ̀lẹ̀-ọkàn ń mú kí ó rọrùn fún wa láti gba ìmọ̀ràn àti ìbáwí. Ẹnìkọ̀ọ̀kan wa nílò ìbáwí ní àwọn ìgbà mìíràn, àwa yóò sì ṣe dáradára láti kọbiara sí ìmọ̀ràn tí ó wà ní Owe 19:20 pé: “Fetísí ìmọ̀ kí o sì gba ẹ̀kọ́, kí ìwọ kí ó lè gbọ́n ní ìgbẹ̀yìn rẹ.” Gẹ́gẹ́ bí a ti sọ ọ́ lọ́nà títọ́, ìrẹ̀lẹ̀-ọkàn kìí mú kí ìdálẹ́bi tàbí ìbáwí tanilára. Ní àfikún, aposteli Paulu, ní Heberu 12:4-11, gbà wá nímọ̀ràn nípa ọgbọ́n tí ó wà nínú fífi ìrẹ̀lẹ̀-ọkàn juwọ́sílẹ̀ fún ìbáwí. Kìkì ní ọ̀nà yìí ni a lè nírètí láti dárí ipa-ọ̀nà ìgbésí-ayé wa ọjọ́-iwájú lọ́nà ọgbọ́n kí a sì wá padà jèrè ẹ̀bùn ìyè àìnípẹ̀kun. Ẹ wo irú ìyọrísí aláyọ̀ tí ìyẹn yóò jẹ́!

14 Níti èyí a lè tọ́ka sí àpẹẹrẹ aposteli Peteru. Ó gba ìmọ̀ràn mímúná láti ọ̀dọ̀ aposteli Paulu, gẹ́gẹ́ bí a ti mọ̀ láti inú àkọsílẹ̀ tí ó wà ní Galatia 2:14 pé: “Nígbà tí mo rí i pé wọn kò rìn déédéé gẹ́gẹ́ bí òtítọ́ ìhìnrere, mo wí fún Peteru níwájú gbogbo wọn pé, Bí ìwọ, tíí ṣe Ju, bá ń rìn gẹ́gẹ́ bí ìwà àwọn Keferi, láìṣe bí àwọn Ju, èéṣe tí ìwọ fi ń fi agbára mú àwọn Keferi láti máa rìn bí àwọn Ju?” Inú ha bí aposteli Peteru bí? Kìí ṣe fún ìgbà pípẹ́títí, bí ó ba tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀ rárá, bí a ti lè rí i nínú ìtọ́kasí tí ó ṣe lẹ́yìn náà sí “Paulu . . . arákùnrin wa olùfẹ́” ní 2 Peteru 3:15, 16.

15. Kí ni ipò-ìbátan tí ó wà láàárín pé kí a jẹ́ onírẹ̀lẹ̀-ọkàn àti kí a jẹ́ aláyọ̀?

15 Ọ̀ràn ti níní ẹ̀mí ohun-moní-tómi, ẹ̀mí ìtẹ́lọ́rùn tún wà níbẹ̀. A kò wulẹ̀ lè láyọ̀ rárá ni àyàfi bí a bá ní ẹ̀mí-ìtẹ́lọ́rùn pẹ̀lú ìpín wa, àǹfààní wa, ìbùkún wa. Kristian onírẹ̀lẹ̀-ọkàn ń ní ìṣarasíhùwà náà pé: “Bí Ọlọrun bá yọ̀ọ̀da rẹ̀, mo lè faramọ́ ọn,” tí ó jẹ́ òun tí aposteli Paulu sọ níti gidi, gẹ́gẹ́ bí a ti kà á ní 1 Korinti 10:13 pé: “Kò sí ìdánwò kan tí ó tíì bá yín, bíkòṣe irú èyí tí ó mọ níwọ̀n fún ènìyàn: ṣùgbọ́n olódodo ni Ọlọrun, ẹni tí kì yóò jẹ́ kí a dán yín wò ju bí ẹ̀yin ti lè gba; ṣùgbọ́n tí yóò sì ṣe ọ̀nà àtiyọ pẹ̀lú nínú ìdánwò náà, kí ẹ̀yin kí ó baà lè gbà á.” Nítorí náà a tún padà rí i bí ìrẹ̀lẹ̀-ọkàn ṣe jẹ́ ipa-ọ̀nà ọgbọ́n, nítorí pé ó ń ràn wá lọ́wọ́ láti jẹ́ aláyọ̀ láìka ohun tí ìpín wa lè jẹ́ sí.

Ìfẹ́ Yóò Ràn Wá Lọ́wọ́ Láti Jẹ́ Onírẹ̀lẹ̀-Ọkàn

16, 17. (a) Àpẹẹrẹ Ìwé Mímọ́ wo ni ó tẹnumọ́ ànímọ́-ìwà títóbi jùlọ tí ó lè ràn wá lọ́wọ́ láti jẹ́ onírẹ̀lẹ̀-ọkàn? (b) Àpẹẹrẹ ti ayé wo ni ó tún ṣàkàwé kókó yìí?

16 Jú ohunkóhun mìíràn lọ, ìfẹ́ àìmọtara-ẹni-nìkan, a·gaʹpe, yóò ràn wá lọ́wọ́ láti jẹ́ onírẹ̀lẹ̀-ọkàn. Èéṣe tí Jesu fi lè fi ìrẹ̀lẹ̀-ọkàn bẹ́ẹ̀ farada ìrírí òpó-igi ìdálóró rẹ̀ tí Paulu ṣàpèjúwe fún àwọn ará Filippi? (Filippi 2:5-8) Èéṣe tí òun kò fi dà á rò rárá láti bá Ọlọrun dọ́gba? Nítorí pé, gẹ́gẹ́ bí òun fúnraarẹ̀ ti sọ: “Èmi fẹ́ràn Baba.” (Johannu 14:31) Ìdí níyẹn tí òun fi ń darí ògo àti ọlá sí Jehofa, Baba rẹ̀ ọ̀run ní gbogbo ìgbà. Nípa báyìí, ní àkókò-ìṣẹ̀lẹ̀ mìíràn ó tẹnumọ́ ọn pé Baba rẹ̀ ọ̀run nìkanṣoṣo ni ó jẹ́ ẹni rere.—Luku 18:18, 19.

17 Èyí tí ó ṣàkàwé kókó yìí ni ìṣẹ̀lẹ̀ kan nínú ìgbésí-ayé ọ̀kan nínú àwọn akéwì ìjímìjí ní America, John Greenleaf Whittier. Ọkùnrin yìí ní olólùfẹ́ kan ní ìgbà ọmọdé rẹ̀, nígbà kan rí níbi eré-ìdíje sípẹ́lì ọ̀rọ̀, olólùfẹ́ rẹ̀ náà gba sípẹ́lì ọ̀rọ̀ kan, nígbà tí ó jẹ́ pé òun ṣì í. Ó dun olólùfẹ́ náà gidigidi. Èéṣe? Gẹ́gẹ́ bí akéwì náà tí padà rántí, olólùfẹ́ náà sọ pé: “Ó dùn mí pé mo sípẹ́lì ọ̀rọ̀ yẹn. Mo kórìíra títa ọ yọ . . . nítorí pé, ṣe ó ríi, mo nífẹ̀ẹ́ rẹ.” Bẹ́ẹ̀ni, bí a bá nífẹ̀ẹ́ ẹnìkan, àwa yóò fẹ́ kí ẹni yẹn wà lókè, kìí ṣe ní abẹ́ wa, nítorí pé ìfẹ́ jẹ́ onírẹ̀lẹ̀-ọkàn.

18. Ìmọ̀ràn Ìwé Mímọ́ wo ni ìrẹ̀lẹ̀-ọkàn yóò mú kí a kọbiara sí?

18 Ẹ̀kọ́-àríkọ́gbọ́n dídára ni èyí jẹ́ fún gbogbo Kristian, pàápàá jùlọ àwọn arákùnrin. Nígbà tí ó bá kan ti àǹfààní iṣẹ́-ìsìn àkànṣe kan, àwa yóò ha láyọ̀ pé arákùnrin wa rí i gbà dípò wa, tàbí àwa yóò ní owú àti ìlara fẹ́ẹ́rẹ́fẹ́ bí? Bí a bá nífẹ̀ẹ́ arákùnrin wa nítòótọ́, àwa yóò láyọ̀ pé ó rí àkànṣe iṣẹ́-àyànfúnni tàbí ìkàsí tàbí àǹfààní iṣẹ́-ìsìn yẹn gbà. Bẹ́ẹ̀ni, ìrẹ̀lẹ̀-ọkàn yóò mú kí ó rọrùn láti kọbiara sí ìmọ̀ràn náà pé: “Níti ọlá, ẹ máa fi ẹnìkejì yín ṣáájú.” (Romu 12:10) Ìtumọ̀ mìíràn kà pé: “Bọlá fún ẹnìkínní kejì rékọjá araàrẹ.” (New International Version) Síwájú síi, aposteli Paulu gbà wá nímọ̀ràn pé: “Ẹ máa fi ìfẹ́ sin ọmọnìkejì yín.” (Galatia 5:13) Bẹ́ẹ̀ni, bí a bá ní ìfẹ́, àwa yóò láyọ̀ láti fi ìmúratán ran àwọn arákùnrin wa lọ́wọ́, láti sìn wọ́n, ní fífi àǹfààní-ire àti ire-àlàáfíà tiwọn ṣáájú tiwa, èyí tí ó béèrè fún ìrẹ̀lẹ̀-ọkàn. Ìrẹ̀lẹ̀-ọkàn yóò tún pa wá mọ́ kúrò nínú ṣíṣògo kí a sì tipa bẹ́ẹ̀ yẹra fún ríru ẹ̀mí owú àti ìlara sókè nínú àwọn ẹlòmíràn. Paulu kọ̀wé pé ìfẹ́ “kìí fọ́nnu, kìí wú-fùkẹ̀.” Èéṣe tí kìí fií ṣe bẹ́ẹ̀? Nítorí pé ète-ìsúnniṣe tí ó wà lẹ́yìn fífọ́nnu àti wíwú-fùkẹ̀ jẹ́ ìmọtara-ẹni-nìkan, ìgbéra-ẹni-lárugẹ, nígbà tí ó jẹ́ pé ìfẹ́ ni ànímọ́ tí ó jẹ́ kòṣeémánìí níti àìmọtara-ẹni-nìkan.—1 Korinti 13:4, NW.

19. Àwọn àpẹẹrẹ Bibeli wo ni ó ṣàkàwé pé ìrẹ̀lẹ̀-ọkàn àti ìfẹ́ wà ní ìfẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́, gẹ́gẹ́ bí ó ti rí pẹ̀lú ìgbéraga àti ìmọtara-ẹni-nìkan?

19 Ipò-ìbátan Dafidi pẹ̀lú Ọba Saulu àti Jonatani ọmọkùnrin rẹ̀ jẹ́ àpẹẹrẹ yíyàtọ̀ gedegbe nípa bí ìfẹ́ àti ìrẹ̀lẹ̀-ọkàn ṣe wà ní ìfẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́ àti bí ìgbéraga àti ìmọtara-ẹni-nìkan bákan náà ṣe wà ní ìfẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́. Nítorí àwọn àṣeyọrí Dafidi nínú ìjà-ogun, àwọn obìnrin Israeli kọrin pé: “Saulu pa ẹgbẹẹgbẹ̀rún tirẹ̀, Dafidi sì pa ẹgbẹẹgbàárùn-ún tirẹ̀.” (1 Samueli 18:7) Láìní ìrẹ̀lẹ̀-ọkàn rárá ṣùgbọ́n, kàkà bẹ́ẹ̀, bí ó ti kún fún ìgbéraga, láti ìgbà náà lọ ni Saulu ti ń gbé ìkórìíra ìṣekúpani sọ́kàn nítorí Dafidi. Ẹ wo bí èyí ti yàtọ̀ sí ẹ̀mí ọmọkùnrin rẹ̀ Jonatani tó! A kà pé Jonatani nífẹ̀ẹ́ Dafidi bí ọkàn òun tìkáraarẹ̀. (1 Samueli 18:1) Nítorí náà báwo ni Jonatani ṣe hùwàpadà nígbà tí, bí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ti ń bá a lọ, ó ṣe kedere pé Jehofa ń bùkún fún Dafidi àti pé òun ni yóò gbapò Saulu gẹ́gẹ́ bí ọba Israeli, kìí ṣe Jonatani? Jonatani ha nímọ̀lára owú tàbí ìlara bí? Bẹ́ẹ̀kọ́ rárá! Nítorí ìfẹ́ ńlá tí ó ní fún Dafidi, òun lè sọ, gẹ́gẹ́ bí a ti kà ní 1 Samueli 23:17 pé: “Máṣe bẹ̀rù: nítorí ọwọ́ Saulu baba mi kì yóò tẹ̀ ọ́: ìwọ ni yóò jọba lórí Israeli, èmi ni yóò sì ṣe ibìkejì rẹ; Saulu baba mi mọ̀ bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú.” Ìfẹ́ ńlá tí Jonatani ní fún Dafidi mú kí ó fi ìrẹ̀lẹ̀-ọkàn gba ohun tí ó wò pé ó jẹ́ ìfẹ́-inú Ọlọrun níti ẹni tí ó yẹ kí ó gbapò baba rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba Israeli.

20. Báwo ni Jesu ṣe fi ipò-ìbátan tímọ́tímọ́ tí ó wà láàárín ìfẹ́ àti ìrẹ̀lẹ̀-ọkàn hàn?

20 Ohun tí ó tún nú-ẹnu-mọ́ ipò-ìbátan tí ó wà láàárín ìfẹ́ àti ìrẹ̀lẹ̀-ọkàn ni ohun tí ó ṣẹlẹ̀ ní alẹ́ tí Jesu Kristi wà pẹ̀lú àwọn aposteli rẹ̀ kẹ́yìn kí ó tó kú. Ní Johannu 13:1, a kà pé “fífẹ́ tí” Jesu “fẹ́ àwọn tirẹ̀ tí ó wà ní ayé, ó fẹ́ wọn títí dé òpin.” Tẹ̀lé ìyẹn, a kà pé, Jesu wẹ ẹsẹ̀ àwọn aposteli rẹ̀, ní ṣíṣe gẹ́gẹ́ bí ẹrú rírẹlẹ̀. Ẹ wo ẹ̀kọ́-àríkọ́gbọ́n lílágbára níti ìrẹ̀lẹ̀-ọkàn tí èyí jẹ́!—Johannu 13:1-11.

21. Ní àkópọ̀, èéṣe tí a fi níláti jẹ́ onírẹ̀lẹ̀-ọkàn?

21 Lóòótọ́, ìdí púpọ̀ wà láti jẹ́ onírẹ̀lẹ̀-ọkàn. Ohun tí ó tọ́, tí ó sì jẹ́ aláìlábòsí ni láti jẹ́ onírẹ̀lẹ̀-ọkàn. Ó jẹ́ ipa-ọ̀nà ìgbàgbọ́. Ó ń mú kí a ní ìbátan rere pẹ̀lú Jehofa Ọlọrun àti pẹ̀lú àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wa. Ó jẹ́ ipa-ọ̀nà ọgbọ́n. Ju gbogbo rẹ̀ lọ, ó jẹ́ ipa-ọ̀nà ìfẹ́ ó sì ń mú ayọ̀ tòótọ́ wá.

Báwo ni Ìwọ Yóò Ṣe Dáhùn?

◻ Ní àwọn ọ̀nà wo ni àìlábòsí gbà jẹ́ ìrànlọ́wọ́ níti jíjẹ́ onírẹ̀lẹ̀-ọkàn?

◻ Èéṣe tí ìgbàgbọ́ nínú Jehofa fi lè ràn wá lọ́wọ́ láti jẹ́ onírẹ̀lẹ̀-ọkàn?

◻ Kí ni ó fihàn pé jíjẹ́ onírẹ̀lẹ̀-ọkàn jẹ́ ipa-ọ̀nà ọgbọ́n?

◻ Èéṣe tí ìfẹ́ fi ṣèrànlọ́wọ́ ní pàtàkì níti pé kí a jẹ́ onírẹ̀lẹ̀-ọkàn?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]

Jobu fi ìrẹ̀lẹ̀-ọkàn mú araarẹ̀ tẹríbea fún Jehofa. Òun kò ‘bú Ọlọrun kí ó sì kú’

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

Peteru fi ìrẹ̀lẹ̀-ọkàn tẹríba nígbà tí Paulu fún un ní ìmọ̀ràn ní gbangba

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́