Jèhófà Ń ṣí Ògo Rẹ̀ Payá Fáwọn Onírẹ̀lẹ̀
“Ìyọrísí ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ àti ìbẹ̀rù Jèhófà ni ọrọ̀ àti ògo àti ìyè.”—Òwe 22:4.
1, 2. (a) Báwo ni ìwé Ìṣe ṣe fi hàn pé Sítéfánù jẹ́ “ọkùnrin kan tí ó kún fún ìgbàgbọ́ àti ẹ̀mí mímọ́”? (b) Kí ló fi hàn pé onírẹ̀lẹ̀ èèyàn ni Sítéfánù?
SÍTÉFÁNÙ jẹ́ “ọkùnrin kan tí ó kún fún ìgbàgbọ́ àti ẹ̀mí mímọ́.” Ó tún “kún fún oore ọ̀fẹ́ àti agbára.” Gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀, ó ṣe àwọn iṣẹ́ àmì àti iṣẹ́ àgbàyanu láàárín àwọn èèyàn. Nígbà kan báyìí, àwọn ọkùnrin kan kóra wọn jọ láti bá a ṣe awuyewuye “síbẹ̀, wọn kò lè dúró lòdì sí ọgbọ́n àti ẹ̀mí tí ó fi ń sọ̀rọ̀.” (Ìṣe 6:5, 8-10) Ó ṣe kedere pé Sítéfánù jẹ́ ẹnì kan tó máa ń kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run dáadáa, ó sì máa ń gbèjà rẹ̀ níwájú àwọn aṣáájú ìsìn Júù tó wà nígbà ayé rẹ̀. Ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ọ̀rọ̀ tó sọ nínú ìwé Ìṣe orí keje fi hàn pé ìfẹ́ tó ní sí ète Ọlọ́run tó ń ṣí payá ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé pọ̀ gan-an.
2 Onírẹ̀lẹ̀ èèyàn ni Sítéfánù, kò dà bí àwọn aṣáájú ìsìn tí ipò àti ìmọ̀ wọn mú kí wọ́n máa rò pé àwọn sàn ju àwọn gbáàtúù èèyàn lọ. (Mátíù 23:2-7; Jòhánù 7:49) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ògbóǹkangí ló jẹ́ nínú ìmọ̀ Ìwé Mímọ́, síbẹ̀ inú rẹ̀ dùn gan-an nígbà tí wọ́n ní kó máa “pín oúnjẹ sórí àwọn tábìlì” kí àwọn àpọ́sítélì lè ráyè fi ara wọn “fún àdúrà àti iṣẹ́ òjíṣẹ́ ọ̀rọ̀ náà.” Àwọn ará sọ̀rọ̀ Sítéfánù dáadáa, èyí sì mú kó wà lára àwọn ọkùnrin méje tí a jẹ́rìí gbè tá a yàn láti máa bójú tó iṣẹ́ pípín oúnjẹ fáwọn èèyàn lójoojúmọ́. Tìrẹ̀lẹ̀tìrẹ̀lẹ̀ ló sì fi tẹ́wọ́ gba iṣẹ́ náà.—Ìṣe 6:1-6.
3. Kí ni ìran kíkàmàmà tí Sítéfánù rí nípa inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run?
3 Jèhófà mọ̀ pé Sítéfánù jẹ́ onírẹ̀lẹ̀, ó tún mọ̀ pé ó jẹ́ ẹni tẹ̀mí àti oníwà títọ́. Nígbà tí Sítéfánù ń wàásù fáwọn òǹrorò aṣáájú Júù ti Sànhẹ́dírìn, àwọn alátakò rẹ̀ “rí i pé ojú rẹ̀ rí bí ojú áńgẹ́lì.” (Ìṣe 6:15) Ojú ẹ̀ dà bíi ti ìránṣẹ́ Ọlọ́run, tòun ti àlàáfíà tó wá látọ̀dọ̀ Jèhófà, Ọlọ́run ògo. Bí Sítéfánù ṣe fi ìgboyà wàásù fún ìgbìmọ̀ Sànhẹ́dírìn tán, ó rí ìfihàn inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run lọ́nà tó pabanbarì. “Òun, bí ó ti kún fún ẹ̀mí mímọ́, ó tẹjú mọ́ ọ̀run, ó sì tajú kán rí ògo Ọlọ́run àti Jésù tí ó dúró ní ọwọ́ ọ̀tún Ọlọ́run.” (Ìṣe 7:55) Lójú Sítéfánù, ńṣe ni ìran kíkàmàmà yìí túbọ̀ fìdí ẹ̀rí náà múlẹ̀ pé Jésù ni Ọmọ Ọlọ́run àti Mèsáyà náà. Ìran náà fún Sítéfánù onírẹ̀lẹ̀ lágbára, ó sì jẹ́ kó dá a lójú pé òun ti rí ojú rere Jèhófà.
4. Àwọn wo ni Jèhófà máa ń ṣí ògo rẹ̀ payá fún?
4 Gẹ́gẹ́ bó ṣe hàn kedere nínú ìran tá a fi hàn Sítéfánù, àwọn tó bẹ̀rù Ọlọ́run, tí wọ́n ní ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀, tí wọ́n sì mọyì àjọṣe tí wọ́n ní pẹ̀lú rẹ̀ ni Jèhófà máa ń ṣí ògo rẹ̀ àti ète rẹ̀ payá fún. Bíbélì sọ pé, “ìyọrísí ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ àti ìbẹ̀rù Jèhófà ni ọrọ̀ àti ògo àti ìyè.” (Òwe 22:4) Nítorí náà, ó ṣe pàtàkì pé ká mọ ohun tí ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ tòótọ́ jẹ́, ká mọ ba a ṣe lè ní ànímọ́ pàtàkì yìí àti bá a ṣe lè jàǹfààní látinú lílo ànímọ́ náà nínú gbogbo ohun tá a bá ń ṣe.
Ẹ̀mí Ìrẹ̀lẹ̀ Jẹ́ Ànímọ́ Ọlọ́run
5, 6. (a) Kí ni ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀? (b) Ọ̀nà wo ni Jèhófà gbà lo ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀? (d) Ipa wo ló yẹ kí ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ Jèhófà ní lórí wa?
5 Ó lè ya àwọn kan lẹ́nu láti mọ̀ pé Jèhófà Ọlọ́run, ẹni gíga jù lọ tó sì tún jẹ́ ológo jù lọ láyé lọ́run ló jẹ́ àpẹẹrẹ tó ga jù lọ tó bá dọ̀rọ̀ lílo ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀. Dáfídì Ọba sọ fún Jèhófà pé: “Ìwọ yóò sì fún mi ní apata ìgbàlà rẹ, ọwọ́ ọ̀tún rẹ yóò sì gbé mi ró, ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ rẹ sì ni yóò sọ mí di ńlá.” (Sáàmù 18:35) Nígbà tí Dáfídì ń sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ Jèhófà, ó lo ọ̀rọ̀ Hébérù tá a mú jáde látinú ọ̀rọ̀ ìpìlẹ̀ tó túmọ̀ sí “tẹ orí bá.” Yàtọ̀ sí ọ̀rọ̀ náà “ìrẹ̀lẹ̀,” àwọn ọ̀rọ̀ mìíràn tó tún wé mọ́ ọ̀rọ̀ ìpìlẹ̀ kan náà yìí ni “ọkàn tútù,” àti “ìrẹra-ẹni-wálẹ̀.” Nítorí náà, ńṣe ni Jèhófà rẹ ara rẹ̀ wálẹ̀ nígbà tí àjọṣe wà láàárín òun àti Dáfídì tó jẹ́ èèyàn aláìpé tó sì tún lò ó gẹ́gẹ́ bí ọba láti ṣojú fún òun. Gẹ́gẹ́ bí àkọlé Sáàmù kejìdínlógún ṣe fi hàn, Jèhófà dáàbò bo Dáfídì, ó tì í lẹ́yìn, ó sì dá a nídè “kúrò ní àtẹ́lẹwọ́ gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ̀ àti kúrò ní ọwọ́ Sọ́ọ̀lù.” Dáfídì alára mọ̀ pé tí Jèhófà ò bá fi ìrẹ̀lẹ̀ ti òun lẹ́yìn, òun ò ní lè dé ipò ọlá tàbí ògo kankan gẹ́gẹ́ ọba. Mímọ̀ tí Dáfídì mọ èyí mú kó lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ tó sì ń bá a lọ bẹ́ẹ̀.
6 Àwa náà ńkọ́? Jèhófà ti fi òtítọ́ kọ́ wa, àwọn kan lára wa sì ti lè láǹfààní àkànṣe iṣẹ́ ìsìn nípasẹ̀ ètò àjọ rẹ̀, tàbí kó ti lò wá làwọn ọ̀nà kan láti mú ìfẹ́ rẹ̀ ṣẹ. Báwo ló ṣe yẹ kí gbogbo èyí rí lára wa? Ǹjẹ́ kò yẹ kí èyí mú ká rẹ ara wa sílẹ̀? Ǹjẹ́ kò yẹ ká dúpẹ́ pé Jèhófà jẹ́ onírẹ̀lẹ̀, ká sì yẹra fún ẹ̀mí ìgbéraga nítorí pé ó máa ṣàkóbá fún wa?—Òwe 16:18; 29:23.
7, 8. (a) Báwo ní Jèhófà ṣe fi ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ hàn nínú bó ṣe bá Mánásè lò? (b) Ọ̀nà wo ní Jèhófà àti Mánásè gbà fi àpẹẹrẹ lé lẹ̀ fún wa nípa bá a ṣe lè lo ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀?
7 Kì í kàn án ṣe pé Jèhófà lo ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ tó pọ̀ nípa níní àjọse pẹ̀lú ọmọ aráyé aláìpé nìkan ni, àmọ́ ó tún fi hàn pé òun ṣe tán láti ṣíjú àánú rẹ̀ wo àwọn ẹni rírẹlẹ̀, àní ó tiẹ̀ ṣe tán láti gbé àwọn tó rẹ ara wọn sílẹ̀ ga pàápàá. (Sáàmù 113:4-7) Bí àpẹẹrẹ, wo ọ̀ràn ti Mánásè Ọba Júdà. Ó ń lo àǹfààní bàǹtàbanta tó ní gẹ́gẹ́ bí ọba láti gbé ìjọsìn èké lárugẹ, àti pé “ní ìwọ̀n tí ó bùáyà ni ó ṣe ohun tí ó burú ní ojú Jèhófà, láti mú un bínú.” (2 Kíróníkà 33:6) Ní àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, Jèhófà fìyà jẹ Mánásè nípa gbígba ọba Ásíríà láyé láti mú un kúrò lórí ìtẹ́. Nígbà tí Mánásè wà lọ́gbà ẹ̀wọ̀n, ó “tu Jèhófà Ọlọ́run rẹ̀ lójú, ó sì ń bá a nìṣó ní rírẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ gidigidi” débi pé Jèhófà gbé e gorí ìtẹ́ lẹ́ẹ̀kan sí i ní Jerúsálẹ́mù, Mánásè “sì wá mọ̀ pé Jèhófà ni Ọlọ́run tòótọ́.” (2 Kíróníkà 33:11-13) Bẹ́ẹ̀ ni o, ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ tí Mánásè fi hàn lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn múnú Jèhófà dùn, Jèhófà náà sì fi ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ hàn sí i nípa dídárí jì í àti nípa gbígbé e gorí ìtẹ́ lẹ́ẹ̀kan sí i.
8 Bí Jèhófà ṣe múra tán láti dárí ji Mánásè àti ẹ̀mí ìrònúpìwàdà tí Mánásè fi hàn jẹ́ ẹ̀kọ́ pàtàkì fún wa nípa ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀. Ó yẹ ká máa rántí ní gbogbo ìgbà pé bá a ṣe ń ṣe sí àwọn tó bá ṣẹ̀ wá àti ẹ̀mí tá a bá fi hàn nígbà tá a bá dẹ́ṣẹ̀ lè nípa lórí ọ̀nà tí Jèhófà yóò gbà bá wa lò. Tá a bá dárí ji àwọn tó ṣẹ̀ wá tinútinú tá a sì fi ìrẹ̀lẹ̀ gba àṣìṣe wa, nígbà náà Jèhófà lè wá ṣíjú àánú rẹ̀ wò wá.—Mátíù 5:23, 24; 6:12.
Ọlọ́run Ṣí Ògo Rẹ̀ Payá Fáwọn Onírẹ̀lẹ̀
9. Ṣé òmùgọ̀ làwọn tó lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ ni? Ṣàlàyé.
9 Àmọ́ ṣá o, kò yẹ ká wá máa wo àwọn tó lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ tàbí àwọn ànímọ́ mìíràn tó dà bíi rẹ̀ bí ẹni pé òmùgọ̀ ni wọ́n tàbí pé wọ́n ń gba ìwà tí ò dáa láyè. Gẹ́gẹ́ bí Ìwé Mímọ́ ṣe fi hàn, onírẹ̀lẹ̀ ni Jèhófà, síbẹ̀ náà, ó máa ń bínú lọ́nà òdodo ó sì máa ń lo agbára tó kàmàmà nígbà tó bá yẹ kó ṣe bẹ́ẹ̀. Nítorí ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ tí Jèhófà ní ló ṣe ń ṣíjú àánú wo àwọn ẹni rírẹlẹ̀ tó sì ń gba tiwọn rò lọ́nà tó ṣàrà ọ̀tọ̀, àmọ́ ó máa ń jìnnà sáwọn tó bá ń gbéra ga. (Sáàmù 138:6) Báwo ni Jèhófà ṣe ń gba táwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ onírẹ̀lẹ̀ rò lọ́nà tó ṣàrà ọ̀tọ̀?
10. Kí ni Jèhófà ṣí payá fáwọn onírẹ̀lẹ̀ gẹ́gẹ́ bí 1 Kọ́ríńtì 2:6-10 ṣe sọ?
10 Nígbà tí ó tó àkókò lójú Jèhófà, ó fi kúlẹ̀kúlẹ̀ bóun á ṣe mú ète òun ṣẹ han àwọn onírẹ̀lẹ̀, ó sì ṣe èyí nípasẹ̀ ètò tó fi ń bá wọn sọ̀rọ̀. Kò fi àwọn nǹkan ológo yìí han àwọn tí ìgbéraga àti agídí mú kí wọ́n gbára lé ọgbọ́n àti èrò èèyàn, tí wọ́n sì wonkoko mọ́ wọn. (1 Kọ́ríńtì 2:6-10) Àmọ́, nítorí pé a ti mú káwọn onírẹ̀lẹ̀ ní ìmọ̀ pípéye nípa ète Jèhófà, inú wọn dùn láti máa fi ògo fún Jèhófà nítorí pé wọ́n túbọ̀ mọyì ògo rẹ̀ tó kàmàmà.
11. Ọ̀nà wo làwọn kan gbà fi ẹ̀mí ìgbéraga hàn ní ọ̀rúndún kìíní, báwo lèyí sì ṣe ṣàkóbá fún wọn?
11 Ọ̀pọ̀ lára àwọn tó gbáyé ní ọ̀rúndún kìíní, títí kan àwọn kan tó pera wọn ní Kristẹni, ni kò lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀, wọ́n tiẹ̀ dẹni ìkọsẹ̀ nítorí ohun tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ fún wọn nípa ète Ọlọ́run. Pọ́ọ̀lù di “àpọ́sítélì fún àwọn orílẹ̀-èdè,” àmọ́ kì í ṣe nítorí orílẹ̀-èdè tó ti wá, ìwé tó kà, ọjọ́ orí rẹ̀ tàbí nítorí ọ̀pọ̀ ohun rere tó ti ṣe. (Róòmù 11:13) Ohun táwọn tí kì í ṣe ẹni tẹ̀mí sì sábà máa ń wo bíi pé òun ló máa pinnu ẹni tó yẹ kí Jèhófà lò nìyẹn. (1 Kọ́ríńtì 1:26-29; 3:1; Kólósè 2:18) Ṣùgbọ́n, Pọ́ọ̀lù lẹni tí Jèhófà yàn níbàámu pẹ̀lú inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí àti ète òdodo Rẹ̀. (1 Kọ́ríńtì 15:8-10) Àwọn tí Pọ́ọ̀lù pè ní ‘àpọ́sítélì adárarégèé,’ àtàwọn alátakò mìíràn kò tẹ́wọ́ gba Pọ́ọ̀lù, wọn ò sì fara mọ́ àlàyé tó ṣe lórí Ìwé Mímọ́. Ìgbéraga wọn ò jẹ́ kí wọ́n ní ìmọ̀ àti òye nípa àwọn ọ̀nà ológo tí Jèhófà gbà ń mú ète rẹ̀ ṣẹ. Ẹ má ṣe jẹ́ ká fojú kéré àwọn tí Jèhófà ń lò láti mú ìfẹ́ rẹ̀ ṣẹ, ẹ má sì ṣe jẹ́ ká ní èrò òdì nípa wọn láé.—2 Kọ́ríńtì 11:4-6.
12. Báwo ni àpẹẹrẹ Mósè ṣe fi hàn pé Jèhófà máa ń ṣojú rere sáwọn onírẹ̀lẹ̀?
12 Ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àpẹẹrẹ ló wà nínú Bíbélì tó fi hàn bí àwọn tó lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ ṣe kófìrí ògo Ọlọ́run. Mósè, tó “fi gbọ̀ọ̀rọ̀-gbọọrọ jẹ́ ọlọ́kàn tútù jù lọ” nínú gbogbo ènìyàn rí ògo Ọlọ́run ó sì ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú rẹ̀. (Númérì 12:3) Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀nà ni Ẹlẹ́dàá gbà ṣojú rere sí ọkùnrin onírẹ̀lẹ̀ tó fi ogójì ọdún ṣe olùṣọ́ àgùntàn rírẹlẹ̀ yìí. Ó sì lè jẹ́ pé àgbègbè Arébíà tí omi fẹ́rẹ̀ẹ́ yí po ni Mósè ti lo èyí tó pọ̀ jù lọ lára àwọn ọdún náà. (Ẹ́kísódù 6:12, 30) Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Jèhófà, Mósè di agbọ̀rọ̀sọ àti olùṣekòkáárí fún orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì. Òun àti Ọlọ́run jọ sọ̀rọ̀. Ó tipasẹ̀ ìran kan rí “ìrísí Jèhófà.” (Númérì 12:7, 8; Ẹ́kísódù 24:10, 11) A tún bù kún àwọn tó tẹ́wọ́ gba ìránṣẹ́ onírẹ̀lẹ̀ àti aṣojú Ọlọ́run yìí. A ó sì bù kún àwa náà tá a bá tẹ́wọ́ gba wòlíì tó tóbi ju Mósè lọ, ìyẹn Jésù, tá a sì ṣègbọràn sí òun àti “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” tó ti yàn.—Mátíù 24:45, 46; Ìṣe 3:22.
13. Báwo ni Jèhófà ṣe ṣí ògo rẹ̀ payá fáwọn onírẹ̀lẹ̀ olùṣọ́ àgùntàn ní ọ̀rúndún kìíní?
13 Àwọn wo ni ‘ògo Jèhófà ràn yòò’ yí ká nígbà táwọn áńgẹ́lì wá polongo ìhìn rere nípa ìbí ‘Olùgbàlà kan tí í ṣe Kristi Olúwa’? Kì í ṣe àwọn agbéraga aṣáájú ìsìn tàbí àwọn èèyàn jàǹkànjàǹkàn tí ń bẹ nípò gíga ni ògo náà ràn yòò yí ká, bí kò se àwọn onírẹ̀lẹ̀ olùṣọ́ àgùntàn “tí wọ́n ń gbé ní ìta, tí wọ́n sì ń ṣọ́ àwọn agbo ẹran wọn ní òru.” (Lúùkù 2:8-11) Àwọn èèyàn ò fi bẹ́ẹ̀ kà wọ́n sí nítorí irú èèyàn tí wọ́n jẹ́ àti iṣẹ́ tí wọ́n ń ṣe. Síbẹ̀, àwọn gan-an ní Jèhófà kíyè sí, àwọn ló sì kọ́kọ́ gbọ́ nípa ìbí Mèsáyà náà. Bẹ́ẹ̀ ni o, àwọn tó lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ àtàwọn tó bẹ̀rù Ọlọ́run ni Jèhófà máa ń ṣí ògo rẹ̀ payá fún.
14. Báwo ni Ọlọ́run ṣe ń bù kún àwọn tó lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀?
14 Kí lóhun táwọn àpẹẹrẹ wọ̀nyí kọ́ wa? Ó kọ́ wa pé Jèhófà máa ń ṣojú rere sáwọn tó lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀, ó sì máa ń jẹ́ kí wọ́n ní ìmọ̀ àti òye nípa ète òun. Àwọn tí kò jámọ́ nǹkankan lójú ọmọ aráyé ni Jèhófà máa ń yàn, àwọn ló sì máa ń lò láti polongo ète rẹ̀ ológo fáwọn èèyàn. Ó yẹ kí èyí sún wa láti máa wo Jèhófà, Ọ̀rọ̀ rẹ̀ alásọtẹ́lẹ̀ àti ètò àjọ rẹ̀ fún ìtọ́sọ́nà ní gbogbo ìgbà. Ó dá wa lójú pé Jèhófà ò ní yéé sọ fáwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ onírẹ̀lẹ̀ nípa ète rẹ̀ ológo tó ń ṣí payá ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé. Wòlíì Ámósì sọ pé: “Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ kì yóò ṣe ohun kan láìjẹ́ pé ó ti ṣí ọ̀ràn àṣírí rẹ̀ payá fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ wòlíì.”—Ámósì 3:7.
Ní Ẹ̀mí Ìrẹ̀lẹ̀ Kó O sì Rí Ojú Rere Ọlọ́run
15. Kí nìdí tó fi yẹ ká máa ní ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ ní gbogbo ìgbà, báwo sì ni ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Sọ́ọ̀lù Ọba Ísírẹ́lì ṣe fi èyí hàn?
15 Tá a bá fẹ́ máa rí ojú rere Ọlọ́run títí lọ, a gbọ́dọ̀ jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ ká sì máa bá a lọ bẹ́ẹ̀. Torí pé ẹnì kan lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ lónìí ò túmọ̀ sí pé ó máa lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ ní gbogbo ìgbà. Ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ lè tán lára èèyàn kí ẹ̀mí ìgbéraga sí wà jọba lọ́kàn rẹ̀, èyí sì lè mú kéèyàn kọjá àyè ẹ̀ tàbí kó tiẹ̀ rí láburú pàápàá. Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Sọ́ọ̀lù tó jẹ́ ẹni àkọ́kọ́ tá a fòróró yàn ṣe ọba Ísírẹ́lì nìyẹn. Nígbà tá a kọ́kọ́ yan Sọ́ọ̀lù, ó “kéré lójú ara [rẹ̀].” (1 Sámúẹ́lì 15:17) Àmọ́, lẹ́yìn ọdún méjì péré tó ti di ọba, ó hùwà ọ̀yájú. Ó fojú di ètò tí Jèhófà là kalẹ̀ pé wòlíì Sámúẹ́lì ni kó rúbọ, ló bá ń ṣe àwọn àwáwí kan pé ìyẹn ló mú kóun máa rú ẹbọ fúnra òun. (1 Sámúẹ́lì 13:1, 8-14) Ibi tí ọ̀pọ̀ nǹkan tó ṣe tó jẹ́ ká rí i pé òótọ́ ló lẹ́mìí ìgbéraga ti bẹ̀rẹ̀ gan-an nìyẹn. Ohun tó kẹ́yìn ẹ̀ ni pé ẹ̀mí Ọlọ́run fi í sílẹ̀, ó tún pàdánù ojú rere Ọlọ́run, ní àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀ ó kú ikú ẹ̀sín. (1 Sámúẹ́lì 15:3-19, 26; 28:6; 31:4) Ẹ̀kọ́ tá a rí kọ́ níbẹ̀ ṣe kedere, ìyẹn ni pé, ó yẹ ká sapá gidigidi láti máa ní ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ àti ẹ̀mí ìtẹríba ní gbogbo ìgbà, ká yéé jọ ara wa lójú jù, nítorí ìyẹn ló máa mú ká yẹra fún ìwà ọ̀yájú èyíkéyìí tó máa mú kí Jèhófà bínú sí wa.
16. Báwo ni ríronú lórí àjọṣe tá a ní pẹ̀lú Jèhófà àti ọmọnìkejì wa ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ láti lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀?
16 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé níbi tá a to àwọn èso ẹ̀mí Ọlọ́run sí, kò sí ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ lára wọn, síbẹ̀ ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ jẹ́ ànímọ́ Ọlọ́run tó yẹ kéèyàn ní. (Gálátíà 5:22, 23; Kólósè 3:10, 12) Nítorí pé ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ jẹ́ ànímọ́ kan tó ní í ṣe pẹ̀lú èrò inú ẹni, ìyẹn ojú tá a fi ń wo ara wa àtàwọn ẹlòmíì, ó gba pé ká dìídì máa fi ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ kọ́ra. Ríronú nípa àjọṣe tá a ní pẹ̀lú Jèhófà àti pẹ̀lú ọmọnìkejì wa àti ṣíṣe àṣàrò lé e lórí lè ràn wá lọ́wọ́ láti lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀. Lójú Ọlọ́run, gbogbo ẹ̀dá ẹlẹ́ran ara aláìpé dà bí koríko tútù tó máa wà fúngbà díẹ̀, tá sì gbẹ dànù tó bá yá. Bíi tata tó wà nínú igbó lásán léèyàn rí. (Aísáyà 40:6, 7, 22) Ǹjẹ́ ìdí wà fún ọwọ́ koríko kan láti máa gbéra ga kìkì nítorí pé ó fi díẹ̀ ga ju ọwọ́ àwọn koríko yòókù lọ? Ṣé ó yẹ kí tata kan máa wá ganpá kìkì nítorí pé ó lágbára láti máa fò káàkiri ju àwọn ẹgbẹ́ rẹ̀ lọ? Kò tiẹ̀ yẹ kéèyàn rò bẹ́ẹ̀ rárá. Nípa bẹ́ẹ̀, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù rán àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ Kristẹni létí pé: “Ta ní mú ọ yàtọ̀ sí ẹlòmíràn? Ní tòótọ́, kí ni ìwọ ní tí kì í ṣe pé ìwọ gbà? Wàyí o, bí ó bá jẹ́ pé gbígbà ni ìwọ gbà á ní tòótọ́, èé ṣe tí ìwọ fi ń ṣògo bí ẹni pé ìwọ kò gbà á?” (1 Kọ́ríńtì 4:7) Ríronú lórí àwọn ẹsẹ Bíbélì bí irú èyí lè ràn wá lọ́wọ́ láti lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ ká sì máa fi í hàn ní ìgbésí ayé wa.
17. Kí ló ran wòlíì Dáníẹ́lì lọ́wọ́ láti ní ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀, kí ni yóò sì ran àwa náà lọ́wọ́ láti ṣe bíi tirẹ̀?
17 Bíbélì sọ pé Dáníẹ́lì, wòlíì Hébérù nì jẹ́ “ọkùnrin fífani-lọ́kàn-mọ́ra gidigidi” lójú Ọlọ́run nítorí pé o “rẹ ara rẹ sílẹ̀,” ìyẹn nítorí ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ tó ní. (Dáníẹ́lì 10:11, 12) Kí ló ran Dáníẹ́lì lọ́wọ́ láti ní ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀? Ohun àkọ́kọ́ tó ràn án lọ́wọ́ ni pé ó gbára lé Jèhófà láìkù síbì kan, ó ń gbàdúrà sí i déédéé. (Dáníẹ́lì 6:10, 11) Yàtọ̀ síyẹn, Dáníẹ́lì jẹ́ ẹnì kan tó máa ń fi ọkàn tó dáa kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lójú méjèèjì, èyí ló sì jẹ́ kó gbájú mọ́ ète ológo ti Ọlọ́run. Ó tún ṣe tán láti gba àṣìṣe rẹ̀, kì í kàn án ṣe tàwọn èèyàn rẹ̀ nìkan. Kì í sì í ṣe òdodo tòun fúnra ẹ̀ ló ká a lára bí kò ṣe bóun á ṣe máa polongo òdodo Ọlọ́run. (Dáníẹ́lì 9:2, 5, 7) Ǹjẹ́ a lè fi àpẹẹrẹ rere Dáníẹ́lì ṣe àwòṣe, ká sapá láti ní ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ ká sì máa lo ẹ̀mí yìí nínú gbogbo ohun tá a bá ń ṣe ní ìgbésí ayé wa?
18. Ògo wo ló ń bẹ lọ́jọ́ ọ̀la fáwọn tó lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ lónìí?
18 Ìwé Òwe 22:4 sọ pé: “Ìyọrísí ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ àti ìbẹ̀rù Jèhófà ni ọrọ̀ àti ògo àti ìyè.” Bẹ́ẹ̀ ni o, Jèhófà máa ń ṣojú rere sáwọn tó lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀, ìyọrísí rẹ̀ sì ní ògo àti ìyè. Nígbà tó ku díẹ̀ kí Ásáfù tó jẹ́ onísáàmù ṣe ó dìgbóṣe sí iṣẹ́ ìsìn rẹ̀ sí Ọlọ́run, àmọ́ tí Jèhófà ràn án lọ́wọ́ láti yí èrò rẹ̀ padà, ó wá sọ tìrẹ̀lẹ̀tìrẹ̀lẹ̀ pé: “Ìmọ̀ràn rẹ ni ìwọ yóò fi ṣamọ̀nà mi, lẹ́yìn ìgbà náà, ìwọ yóò sì mú mi wọnú ògo pàápàá.” (Sáàmù 73:24) Àwa náà ńkọ́ lónìí? Ògo wo ló ń bẹ lọ́jọ́ ọ̀la fún àwọn tó bá lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀? Yàtọ̀ sí pé wọ́n ń gbádùn àjọṣe aláyọ̀ pẹ̀lú Jèhófà, wọ́n tún lè máa retí àtirí ìmúṣẹ ọ̀rọ̀ onímìísí tí Dáfídì Ọba sọ pé: “Àwọn ọlọ́kàn tútù ni yóò ni ilẹ̀ ayé, ní tòótọ́, wọn yóò sì rí inú dídùn kíkọyọyọ nínú ọ̀pọ̀ yanturu àlàáfíà.” Ọjọ́ ọ̀la ológo ni lóòótọ́!—Sáàmù 37:11.
Ǹjẹ́ O Rántí?
• Ọ̀nà wo ni Sítéfánù gbà jẹ́ àpẹẹrẹ ẹni tó lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ tí Jèhófà ṣí ògo Rẹ̀ payá fún?
• Àwọn ọ̀nà wo ni Jèhófà Ọlọ́run gbà lo ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀?
• Àpẹẹrẹ wo ló fi hàn pé Jèhófà máa ń ṣí ògo rẹ̀ payá fáwọn tó lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀?
• Báwo ni àpẹẹrẹ Dáníẹ́lì ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ láti ní ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀?
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 12]
Ó Jẹ́ Alágbára Síbẹ̀ Ó Lẹ́mìí Ìrẹ̀lẹ̀
Ní àpéjọ àgbègbè tí àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bibeli (tá a mọ̀ sáwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lónìí) ṣe lọ́dún 1919 ní Cedar Point, Ohio, ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, tayọ̀tayọ̀ ni J. F. Rutherford, ẹni àádọ́ta ọdún tó ń ṣe kòkáárí iṣẹ́ náà nígbà yẹn fi yọ̀ǹda ara rẹ̀ láti mú àwọn tó wá sí àpéjọ náà lọ sí yàrá tá a ṣètò dé wọ́n, ó sì tún bá wọn ru ẹrù wọn. Lọ́jọ́ tó kẹ́yìn àpéjọ àgbègbè náà, inú àwọn ẹgbẹ̀rún méje [7,000] èèyàn tó tẹ́tí bẹ̀lẹ̀jẹ́ sí ọ̀rọ̀ rẹ̀ dùn dọ́ba nígbà tó sọ pé: “Ẹ̀yin ni ikọ̀ fún Ọba àwọn ọba àti Olúwa àwọn olúwa, tó ń kéde . . . ìjọba ológo ti Olúwa wa fún àwọn ènìyàn.” Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Arákùnrin Rutherford jẹ́ ẹnì kan tọ́rọ̀ ẹ̀ dá a lójú, tó máa ń sọ̀rọ̀ tagbáratagbára, tí kì í yẹhùn lórí ohun tó gbà pé ó jóòótọ́, ó tún lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ gan-an níwájú Ọlọ́run, èyí sì máa ń hàn nínú àdúrà rẹ̀ nígbà tí wọ́n bá ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ ojoojúmọ́ láàárọ̀ ní Bẹ́tẹ́lì.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]
Sítéfánù tó jẹ́ ògbóǹkangí nínú ìmọ̀ Ìwé Mímọ́, fi ìrẹ̀lẹ̀ pín oúnjẹ fáwọn èèyàn
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ tí Mánásè ní múnú Jèhófà dùn
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12]
Kí ló mú kí Dáníẹ́lì jẹ́ “ọkùnrin fífani-lọ́kàn-mọ́ra gidigidi”?