“Ẹ Wá Jehofa, Gbogbo Ẹ̀yin Onínútútù”
“ẸWÁ Jehofa, gbogbo ẹ̀yin onínútútù ilẹ̀-ayé, tí ẹ ti sọ ṣiṣe ìpinnu ìdájọ́ Tirẹ̀ fúnraarẹ̀ dàṣà. Ẹ wá òdodo, ẹ wá inútútù. Bóyá a ó lè fi yín pamọ́ ní ìkọ̀kọ̀ ní ọjọ́ ìbínú Jehofa.”—Sefaniah 2:3, NW.
Wòlíì Sefaniah sọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn sí àwọn “onínútútù ilẹ̀-ayé,” ó sì rọ̀ wọ́n láti “wá inútútù” kí á baà lè dáàbòbò wọ́n ní “ọjọ́ ìbínú Jehofa.” Kò fi iyèméjì kankan sílẹ̀ pé inútútù jẹ́ ohun àkọ́kọ́ tí a béèrè fún, fún lílàájá. Ṣùgbọ́n èéṣe?
Èéṣe tí a fi Níláti Wá Inútútù?
Inútútù jẹ́ ànímọ́ ti jíjẹ́ oníwà tútù, tí kò ní ìfẹgẹ̀ tàbí gbígbọ́n lójú ara-ẹni nínú. Ó ní ìsopọ̀ tímọ́tímọ́ pẹ̀lú àwọn ìwàrere mìíràn, bí ìrẹ̀lẹ̀ àti ìwàtútù. Bí ìyẹn ti jẹ́ bẹ́ẹ̀, àwọn onínútútù ṣeékọ́, wọ́n sì ń múratán láti gba ìbáwí láti ọwọ́ Ọlọrun, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó lè dàbí èyí tí ń mú ẹ̀dùn-ọkàn báni ní àkókò ìsinsìnyí.—Orin Dafidi 25:9; Heberu 12:4-11.
Nínú araarẹ̀ inútútù lè ní díẹ̀ láti ṣe pẹ̀lú ẹ̀kọ́-ìwé ẹnìkan tàbí ipò nínú ìgbésí-ayé. Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn tí wọ́n kàwé gan-an tàbí tí wọ́n ṣàṣeyọrí ní ọ̀nà ti ayé nítẹ̀sí láti lérò pé àwọn tóótun láti dá ṣe àwọn ìpinnu fúnraawọn nínú ohun gbogbo, kódà nínú àwọn ọ̀ràn ìjọsìn. Èyí lè ṣèdíwọ́ fún wọn láti fàyègba ẹlòmíràn láti kọ́ wọn ní ohun kan tàbí láti gba ìmọ̀ràn kí wọ́n sì ṣe àwọn ìyípadà tí ó yẹ nínú ìgbésí-ayé wọn. Àwọn mìíràn tí wọ́n lọ́rọ̀ nípa ti ara lè ṣubú sínú ìrònú òdì ti ríronú pé àìléwu wọn sinmi lé àwọn ohun-ìní wọn nípa ti ara. Nípa báyìí, wọ́n kò nímọ̀lára àìní kankan fún àwọn ọ̀rọ̀ tẹ̀mí láti inú Bibeli, Ọ̀rọ̀ Ọlọrun.—Matteu 4:4; 5:3; 1 Timoteu 6:17.
Ronú nípa àwọn akọ̀wé-òfin, àwọn Farisi, àti àwọn olórí àlùfáà ní ọjọ́ Jesu. Ní àkókò kan nígbà tí àwọn oníṣẹ́ tí wọ́n rán láti fi àṣẹ ọba mú Jesu padà dé láìmú un wá, àwọn Farisi wí pé: “A ha tan ẹ̀yin jẹ pẹ̀lú bi? Ó ha sí ẹnìkan nínú àwọn ìjòyè, tàbí àwọn Farisi tí ó gbà á gbọ́? Ṣugbọn ìjọ ènìyàn yìí, tí kò mọ òfin, di ẹni ìfibú.” (Johannu 7:45-49) Ní èdè mìíràn, sí wọn, kìkì àwọn aláìmọ̀kan ati àwọn púrúǹtù ni yóò ya òpè tóbẹ́ẹ̀ láti gbà Jesu gbọ́.
Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, òtítọ́ fa àwọn Farisi díẹ̀ mọ́ra, wọ́n tilẹ̀ gbèjà Jesu àti àwọn Kristian. Lára wọn ni Nikodemu àti Gamalieli. (Johannu 7:50-52; Iṣe 5:34-40) Lẹ́yìn ikú Jesu, “ọ̀pọ̀ nínú ẹgbẹ́ àwọn àlùfáà sì fetísí ti ìgbàgbọ́ náà.” (Iṣe 6:7) Láìṣe àníàní, àpẹẹrẹ títayọ jùlọ ni ti aposteli Paulu. Ó gba ìmọ̀ ẹ̀kọ́-ìwé lábẹ́ ẹsẹ̀ Gamalieli ó sì di ọ̀jáfáfá gan-an àti alágbàwí tí a bọ̀wọ̀ fún nínú ìsìn àwọn Ju. Bí ó ti wù kí ó rí, bí àkókò ti ń lọ, ó dáhùnpadà tìrẹ̀lẹ̀-tìrẹ̀lẹ̀ sí ìpè Kristi Jesu ó sì di ọmọlẹ́yìn rẹ̀ onítara.—Iṣe 22:3; 26:4, 5; Galatia 1:14-24; 1 Timothy 1:12-16.
Gbogbo èyí ṣàpèjúwe pé láìka ohun tí ipò-àtilẹ̀wá ẹni lè jẹ́ sí tàbí ohun tí ẹnìkan lè rò nísinsìnyí nípa ìhìn-iṣẹ́ náà láti inú Bibeli, àwọn ọ̀rọ̀ Sefaniah ṣì ṣeé fisílò. Bí ẹnìkan bá ń fẹ́ kí Ọlọrun tẹ́wọ́gba òun kí Ọ̀rọ̀ rẹ̀ sì máa ṣamọ̀nà òun, inútútù jẹ́ kòṣeémánìí.
Àwọn tí Wọ́n “Wá Inútútù” Lónìí
Ọ̀pọ̀ million ènìyàn yíká ayé ni wọ́n ń dáhùnpadà sí ìhìnrere Ìjọba náà. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ń darí iye tí ó ju million mẹ́rin ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ ní ilé irú àwọn ènìyàn bẹ́ẹ̀. Àwọn wọ̀nyí ti inú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ipò-àtilẹ̀wá tí ó yàtọ̀síra àti àwọn ipò ìṣúnná-owó àti ẹgbẹ́-òun-ọ̀gbà tí ó yàtọ̀ wá. Síbẹ̀, ohun kan tí ó wọ́pọ̀ láàárín wọn ni pé wọ́n ní ìrẹ̀lẹ̀ tí ó pọ̀ tó láti gba ìhìn-iṣẹ́ Bibeli tí ẹnìkan nawọ́ rẹ sí wọn ni ẹnu ọ̀nà ilé tiwọn fúnraawọn tàbí ní ibòmíràn. Ọ̀pọ̀ lára wọn sì ń tẹ̀síwájú dáradára nítorí pé wọn múratán láti lo ìsapá náà láti borí àwọn ohun ìdínà tí ó ń dí wọn lọ́wọ́. Bẹ́ẹ̀ni, wọ́n wà lára àwọn ‘onínútútù ayé’ lónìí.
Gbé àpẹẹrẹ Maria ní Mexico yẹ̀wò. Ó kẹ́kọ̀ọ́ òfin ní yunifásítì ó sì ní ààbò níti ọ̀ràn -ìnáwó nítorí ogún kan. Nítorí ìdí èyí, ó mú àwọn ìpìlẹ̀-èrò kan tí ó fààyègba ohun gbogbo dàgbà, gẹ́gẹ́ bí ó ti wí, èyí tí ó sọ ọ́ di “ọlọ̀tẹ̀, aláìmọ̀wàáhù, atẹnilóríba, àti aláìgbàgbọ́ nínú wíwà Ọlọrun.” “Mo wá ronú pé owó lè yanjú ohun gbogbo àti pé Ọlọrun kò ṣepàtàkì. Níti gidi, mo lérò pé òun kò tilẹ̀ sí,” ni Maria padà rántí. “Ní ojú tèmi, ṣọ́ọ̀ṣì jẹ́ yẹ̀yẹ́ tí ó sì wulẹ̀ jẹ́ ohun-àbéèrè-fún ẹgbẹ́-òun-ọ̀gbà kan lásán,” ni ó fikún un.
Láìpẹ́, Maria ṣàkíyèsí àwọn ìyípadà nínú iyèkan rẹ̀ lẹ́yìn tí ó di ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa. “Ẹni lílekoko ni tẹ́lẹ̀, ṣùgbọ́n nísinsìnyí ó ti di ẹni àlááfíà gan-an àti adúróṣinṣin,” ni Maria ṣàlàyé. “Àwọn ìbátan rẹ̀ sọ pé ó jẹ́ oníwàásù ó sì ń ka Bibeli, àti fún ìdí yẹn, kìí mutí tàbí kí ó máa gbá tọ àwọn obìnrin lẹ́yìn mọ́. Nítorí náà mo fẹ́ kí ó wá ka Bibeli fún mi nítorí mo lérò pé ní ọ̀nà yii ni èmi yoo gbà rí àlàáfíà àti ìtòròparọ́rọ́ tí mo fẹ́ gidigidi gan-an.” Ìyọrísí rẹ̀ ni pé Maria tẹ́wọ́gba ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli kan pẹ̀lú àwọn tọkọtaya Ẹlẹ́rìí kan.
Ó ní ohun púpọ̀ láti borí, ó sì tún ṣòro gidigidi fún un láti tẹ́wọ́gba ìlànà Bibeli nípa ipò-orí kí ó baà lè wà ní ìtẹríba fún ọkọ rẹ̀. Ṣùgbọ́n ó yípadà pátápátá nínú ìgbésí-ayé àti ìsạrasíhùwà rẹ̀. Ó jẹ́wọ́ pé: “Mo lérò pé láti ìgbà tí àwọn ará ti mú ìrànlọ́wọ́ Jehofa wá sí ẹnu-ọ̀nà ilé mi, ayọ̀, ìtòròparọ́rọ́, ati ìbùkún Ọlọrun ti ń gbé nínú ilé mi.” Lónìí, Maria jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jehofa olùyara-ẹni sí mímọ́, tí a ti baptisi.
Nínú ìlépa ìjọsìn tòótọ́, apá mìíràn wà nínú èyí tí inútútù, tàbí ṣíṣàìní i, ti kó ipa pàtàkì kan. Ní ọ̀pọ̀ ìgbà, aya nínú ìdílé kan yóò gba òtítọ́ tí yóò sì fẹ́ láti sin Ọlọrun, síbẹ̀ ọkọ a máa lọ́tìkọ̀. Bóyá ó ṣòro fún àwọn ọkọ díẹ̀ láti tẹ́wọ́gba èrò náà pé ẹlòmíràn kan wà—Jehofa Ọlọrun—tí aya rẹ̀ níláti tẹríba fún nísinsìnyí. (1 Korinti 11:3) Obìnrin kan ní Chihuahua, Mexico, béèrè fún ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli, bí àkókò sì ti ń lọ òun àti àwọn ọmọ rẹ̀ méje wá sínú òtítọ́. Lákọ̀ọ́kọ́, ọkọ rẹ̀ ṣàtakò. Èéṣe? Nítorí pé kò fẹ́ kí ìdílé rẹ̀ máa lọ wàásù láti ilé dé ilé, ní fífi àwọn ìwé-ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli lọni. Ní kedere, ó lérò pé èyí bu iyì-ọlá rẹ̀ kú. Bi ó ti wù kí ó rí, ìdílé rẹ̀ dúró gbọnyingbọnyin nínú ìpinnu wọn láti ṣiṣẹ́sin Ọlọrun. Bí àkókò ti ń lọ, ọkọ rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ síí rí ìníyelórí títẹ́wọ́gba ìṣètò Ọlọrun. Ṣùgbọ́n ọdún 15 kọjá kí ó tó ya araarẹ̀ sí mímọ́ fún Jehofa.
Jákèjádò Mexico, ọ̀pọ̀ àwọn àdúgbò àdádó ni ó ṣì wà níbi tí àwọn olùgbé àdúgbò ti ní èdè àbínibí India ati àwọn àṣà ìbílẹ̀ wọn. Ìhìn-iṣẹ́ Bibeli ń dé ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn wọ̀nyí ó sì ń ràn wọ́n lọ́wọ́ láti mú ipò àṣà ìbílẹ̀ wọn sunwọ̀n síi, bí àwọn kan ti kọ́ láti mọ̀ọ́kọ-mọ̀ọ́kà nígbà tí wọ́n ń kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́. Bí ó ti wù kí ó rí, òtítọ́ náà pé àwọn ènìyàn ní ìmọ̀ ẹ̀kọ́-ìwé díẹ̀ tàbí ìwọ̀nba àwọn ohun-àmúṣọrọ̀ kò fi dandan túmọ̀sí pé wọn yóò túbọ̀ ṣetán láti gbà. Ìgbéraga ẹ̀yà-ìran ati ìsopọ̀ lílágbára mọ́ àṣà-àtọwọ́dọ́wọ́ ti àwọn babańlá nígbà mìíràn ń mú kí ó ṣòro fún àwọn kan láti tẹ́wọ́gba òtítọ́. Èyí tún ṣàlàyé ìdí tí ó fi jẹ́ pé ní àwọn abúlé India kan, àwọn ará abúlé yòókù sábà máa ń fòòró àwọn tí wọ́n bá tẹ́wọ́gba òtítọ́. Nítorí náà, inútútù ní apá-ìhà púpọ̀.
Fi Inútútù Dáhùnpadà
Ìwọ gẹ́gẹ́ bí ẹnìkan ńkọ́? Ìwọ ha ń dáhùnpadà sí òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọrun bí? Tàbí ó ha ṣòro fún ọ láti tẹ́wọ́gba àwọn òtítọ́ Bibeli kan bí? Bóyá ìwọ yóò fẹ́ láti yẹ araarẹ wò láti rí ohun tí ń fà ọ́ sẹ́yìn. Ìwọ ha ń dààmú nítorí pé ọ̀pọ̀ jùlọ àwọn ènìyàn tí òtítọ́ fàmọ́ra ní ìpilẹ̀ṣẹ̀ rírẹlẹ̀ bí? Ó ha lè jẹ́ pé ìgbéraẹni -ga wà nínú ìrònú rẹ bí? Ó dára láti ronú lórí ọ̀rọ̀ aposteli Paulu náà: “Ọlọrun ti yan àwọn ohun wèrè ayé láti fi dààmú àwọn ọlọgbọ́n; Ọlọrun sì ti yan àwọn ohun àìlera ayé láti fi dààmú àwọn ohun tí ó ní agbára; àti àwọn ohun ayé tí kò níyì, àti àwọn ohun tí a ń kẹ́gàn, ni Ọlọrun sì ti yàn, àní, àwọn ohun tí kò sí, láti sọ àwọn ohun tí ó wà di asán: kí ó máṣe sí ẹlẹ́ran-ara tí yóò ṣògo níwájú rẹ̀.”—1 Korinti 1:27-29.
Ìwọ yóò ha kọ ìṣúra kan sílẹ̀ kìkì nítorí pé o rí i nínú ìkòkò kan tí kò níláárí bí? Dájúdájú, bẹ́ẹ̀kọ́! Síbẹ̀, ọ̀nà tí Ọlọrun yàn láti gbà gbé Ọ̀rọ̀ òtítọ́ agbẹ̀mílà rẹ̀ kalẹ̀ fún wa nìyẹn, gẹ́gẹ́ bí aposteli Paulu ti ṣàlàyé pé: “Àwa ní ìṣúra yìí nínú ohun-èèlò amọ̀, kí ọlá ńlá agbára náà kí ó lè ṣe ti Ọlọrun, kí ó má ti ọ̀dọ̀ wa wá.” (2 Korinti 4:7) Inútútù àti ìrẹ̀lẹ̀ yóò jẹ́ kí a lè rí ìníyelórí tòótọ́ ìṣúra náà kìí ṣe “ohun-èèlò amọ̀,” tàbí àwọn aṣojú ènìyàn, tí wọ́n ń mú un wá sọ́dọ̀ wa. Ní ṣíṣe bẹ́ẹ̀, a óò tún mú ṣíṣeéṣe láti jẹ́ ẹni tí a ‘pa mọ́ ní ọjọ́ ìbínú Jehofa’ ga síi a ó sì wà lára àwọn onínútútù tí yóò “jogún ayé.”—Sefaniah 2:3; Matteu 5:5.