Ìlà-Oòrùn àti Ìwọ̀-Oòrùn, Jehofa Ń Fún Àwọn Ènìyàn Rẹ̀ Lókun
NÍ ÀWỌN àgbègbè-ìpínlẹ̀ tí a ti fòfinde iṣẹ́ ìwàásù, ní àwọn ilẹ̀ tí ìwà-ipá ti pín sọ́tọ̀ọ̀tọ̀, àti ní àwọn orílẹ̀-èdè tí a ti ṣẹ̀ṣẹ̀ mú ìfòfindè kúrò—nítòótọ́, jákèjádò pápá kárí-ayé—Jehofa ń báa lọ láti pèsè “agbára tí ó rékọjá ìwọ̀n ti ẹ̀dá” fún àwọn Ẹlẹ́rìí rẹ̀.—2 Kọrinti 4:7, NW.
Aásìkí Lábẹ́ Ìfòfindè
Ní ọ̀kan lára àwọn àgbájọ erékùṣù Ìlà-Oòrùn Jíjìnnà-Réré, iṣẹ́ ìwàásù náà ti wà lábẹ́ ìfòfindè fún ọdún 17 nísinsìnyí. Àwọn Ẹlẹ́rìí náà ha rẹ̀wẹ̀sì bí? Bẹ́ẹ̀kọ́ rárá! Ní oṣù May tí ó kọjá yìí, wọ́n dé góńgó titun ti 10,756 àwọn akéde, tí 1,297 lára wọn sì ń ṣiṣẹ́sìn gẹ́gẹ́ bí àwọn òjíṣẹ́ alákòókò-kíkún. Bí àwọn ipò ayé ti ń jórẹ̀yìn, àwọn ènìyàn erékùṣù náà túbọ̀ ń ní ìtẹ̀sí síi ju ti àtẹ̀yìnwá lọ láti fetísílẹ̀ sí òtítọ́. Nítorí náà wọ́n ti ń ròyìn 15,654 àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli tí wọ́n darí nínú ilé àwọn olùfìfẹ́hàn. Ṣáájú ìgbà náà, àwọn 25,397 ni wọ́n wá sí àwọn ìpàdé tí a ṣe ní bòókẹ́lẹ́ láti ṣèrántí ikú Jesu.
Nígbà tí àwọn Àpéjọpọ̀ Àgbègbè “Ẹ̀kọ́ Àtọ̀runwá” wáyé—lẹ́ẹ̀kan síi pẹ̀lú ọgbọ́n-inú ní ìbámu pẹ̀lú àwọn àyíká-ipò àdúgbò—inú àwọn ará dùn láti gba ẹ̀dà tiwọn, nínú àwọn ìwé kan-náà tí a ti mújáde ní United States, ní èdè àdúgbò. Àwọn olùtúmọ̀, olùkàyẹ̀wò, àti àwọn mìíràn ti fínnú-fíndọ̀ yọ̀ǹda araawọn láti fi àfikún àkókò ṣiṣẹ́ kí wọ́n baà lè múra ìmújáde pàtàkì náà sílẹ̀, pẹ̀lú àwọn ọgọ́rọ̀ọ̀rún ojú-ìwé tí ó ní, gẹ́gẹ́ bí a ti wéwèé. Ilé-iṣẹ́ ìtẹ̀wé kan láti ìta sì láyọ̀ láti ṣe iṣẹ́ lílẹ́wà ti ìtẹ̀wé àti ìdìwépọ̀. Inú àwọn olùpéjọpọ̀ dùn láti gba ìtẹ̀jáde náà, pẹ̀lú ìtògẹ̀n-ẹ̀n-rẹ̀n àwòrán mèremère rẹ̀ tí ó ju ẹgbẹ̀rún lọ. Ọ̀pọ̀ àwọn ìjòyè-òṣìṣẹ́ ìjọba bọ̀wọ̀ fún àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa, láti ọ̀dọ̀ àwùjọ-àlùfáà Kristẹndọm sì ni inúnibíni tí máa ń wá jù. A nírètí pé a óò mú ìfòfindè náà kúrò láìpẹ́.
Àwọn Ilẹ̀ America Ńkọ́?
Àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa tí ń bẹ ní àwọn orílẹ̀-èdè Ìwọ̀-Oòrùn wọ̀nyí wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú àwọn arákùnrin wọn ní Ìlà-Oòrùn ní fífi àìṣojo yanjú àwọn ìṣòro wọn, ẹ̀mí mímọ́ Jehofa sì ń ràn wọ́n lọ́wọ́ láti borí àwọn ipò-ọ̀ràn tí ó ṣòro. Gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ, ṣàgbéyẹ̀wò ìròyìn tí ó tẹ̀lé e yìí láti ilẹ̀ Latin-America kan níbi tí àwọn àwùjọ tí ń rí sí ìmújáde àti ìṣòwò egbòogi tí kò bófinmu ti ń gba inú igbó-ẹgàn kọjá déédéé.
Àwùjọ àwọn Ẹlẹ́rìí kan wọ bọ́ọ̀sì kan lọ sí àgbègbè-ìpínlẹ̀ àdádó kan. Bí wọ́n ti sọ̀kalẹ̀ láti inú bọ́ọ̀sì náà, wọ́n kíyèsí ọ̀nà ojúgbó kan tí ó gba abúlé náà kọjá. Nítorí náà àwọn arákùnrin márùn-ún náà rìn lọ láti rí ibi tí ògbóóró ọ̀nà eléruku náà já sí, ní yíyan àwọn arábìnrin àti àwọn ọmọdé láti ṣiṣẹ́ nínú abúlé. Ọ̀kan nínú àwọn arákùnrin náà ròyìn pé:
“Ìwọ̀nba àwọn ilé díẹ̀ ni a rí fún wákàtí méjì tí a fi rìn lójú ọ̀nà náà. Lẹ́yìn náà, àwọn ọkùnrin mẹ́jọ tí wọ́n dìhámọ́ra tí wọ́n sì gbé ìbòrí wọ̀ jáde wá lójijì láti inú aginjù. Àwọn kan gbé ìbọn arọ̀jò-ọta, àwọn kan sì mú àdá lọ́wọ́. Inú kí ni a kó sí yìí? A bẹ̀rẹ̀ síí béèrè ohun tí wọ́n ń fẹ́, ṣùgbọ́n wọ́n sọ pé kí a dákẹ́ kí a máṣe sọ̀rọ̀—kí a ṣáà máa rìn nìṣó. A ṣe bẹ́ẹ̀! Rírìn fún wákàtí méjì síi lá inú igbo kìjikìji náà kọjá mú wa dé ibi títẹ́jú kan tí ó hàn gbangba pé ó jẹ́ ibùdó ẹ̀ka ológun. Àwọn ẹ̀ṣọ́ tí wọ́n gbé ìbọn lọ́wọ́ wà káàkiri. Ilé kan tí wọ́n kọ́ lọ́nà bíbójúmu wà láàárín, ibẹ̀ sì ni wọ́n dári wa sí.
“Lẹ́yìn tí a ti jókòó tán ọ̀kan nínú wọn tí ó hàn gbangba pé òun ni aṣáájú wọn ní ibùdó náà bá wa sọ̀rọ̀. Ó múra ṣémúṣémú, ó ní ìmọ̀-ẹ̀kọ́ dáradára, ó sì lọ́wọ̀ lára gan-an. Ó nawọ́ sí ọ̀kan nínú àwùjọ àwọn arákùnrin wa ó sì ní kí ó dìde dúró. Ó wá bií léèrè pé: ‘Kì ni èrò rẹ̀ nípa àwùjọ [wa]?’ Ní mímọ ibi tí a wà lẹ́kùn-ún-rẹ́rẹ́, arákùnrin náà fèsì pé: ‘Tóò, a mọ̀ nípa àwùjọ yín, ṣùgbọ́n àwa kò lọ́kàn-ìfẹ́ kankan nínú rẹ̀ tàbí nínú àwùjọ òṣèlú mìíràn. Ìdí kanṣoṣo tí a fi wà níhìn-ín jẹ́ láti wàásù nípa Ìjọba Jehofa Ọlọrun nípasẹ̀ Kristi Jesu. Yóò pa gbogbo àkóso òṣèlú ètò-ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan yìí run láìpẹ́ yóò sì mú ìbùkún àgbàyanu wá fún àwọn ènìyàn lórí ilẹ̀-ayé yìí lábẹ́ àwọn ipò bíi ti Paradise—ohun kan tí ènìyàn tàbí àwùjọ àwọn ènìyàn kankan kò lè ṣe.’
“Ìṣarasíhùwà ọkùnrin náà yípadà. Ó bẹ̀rẹ̀ síí béèrè àwọn ìbéèrè. ‘Níbo ni o ti kọ́ gbogbo èyí? Báwo ni o ṣe wà ní ìmúrasílẹ̀ láti sọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀yẹn?’ Fún wákàtí kan àti ààbọ̀, ó ṣeéṣe fún wa láti jẹ́rìí fún wọn dáradára nípa àwọn ipò ayé àti láti fihàn pé Bibeli fi ìrètí kanṣoṣo tí ó wà fún aráyé hàn. A tún ṣàlàyé Romu orí 13—pé a ń ṣègbọràn sí àwọn aláṣẹ tí ń ṣàkóso, ṣùgbọ́n nígbà tí ìforígbárí bá wà láàárín Ọ̀rọ̀ Jehofa àti tiwọn, àwa yóò ṣègbọràn sí Ọlọrun wa, Jehofa, lákọ̀ọ́kọ́. Níkẹyìn, a fi àwọn ìwé tí a ní lọ̀ ọ́. Ó gba mẹ́ta àti Bibeli kan lára wọn àti sí ìyàlẹ́nu wà gidigidi, ó fún wa ní ọrẹ fún wọn. Ó sọ pé òun yóò kà wọ́n.
“Lẹ́yìn náà, aṣáájú náà ṣẹ́wọ́ sí ọ̀kan nínú àwọn ọkùnrin náà pé kí ó mú wa jáde kúrò nínú ibùdó náà. Láìpẹ́ a bọ́ sójú ọ̀nà tí a gbà wá padà, ní dídúpẹ́ lọ́wọ́ Jehofa fún ìṣẹ́gun tí a ni nínú pápá ìjẹ́rìí mìíràn.”
Ní Africa tí Gbọ́nmisí-Omi-Òtó ti Pín Yẹ́lẹyẹ̀lẹ
Ní àárín méjì Ìlà-Oòrùn Jíjìnnà-Réré àti Ìwọ̀-Oòrùn jíjìnnà-réré ni kọ́ńtínẹ́ǹtì Africa wà. Ogun-jíjà láàárín ẹ̀yà ti sọ àwọn orílẹ̀-èdè kan níbẹ̀ di ibi tí ìwà-ipá ti ń rugùdù. Ní Liberia, ìgasókè ogun abẹ́lé lójijì ti nípa gidigidi lórí àwọn ènìyàn Jehofa lẹ́ẹ̀kan síi. Lákọ̀ọ́kọ́, ìjà wà nínú olú-ìlú ńlá àti ní àyíká rẹ̀ nínú oṣù October àti November 1992. Lẹ́yìn náà, bí ogun náà ti ń gbèèràn lọ sí àwọn ìlú ẹ̀yìn odi, odidi àwọn ìjọ ni a túká bí àwọn ará ti sálọ sínú igbó pẹ̀lú ìyókù àwọn ará ìlú. Bí ó ti wù kí ó rí, ìtara wọn kò dínkù rárá. Bí wọ́n tí ń sálọ, wọ́n ń wàásù, èyí sì ti yọrísí fífúnni ní ìjẹ́rìí pípabambarì ní àwọn apá ibi tí ó jẹ́ àdádó jùlọ.
Ìjọ kan tí ó ní àwọn ará tí a fipá mú láti fi ilé wọn sílẹ̀ kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba fún ìlò ìgbà díẹ̀ kan sáàárín oko rọ́bà. Nínú ìlú kan lẹ́bàá ibi tí ogun ti le, ní ọ̀sán àwọn ará ìlú yóò sá lọ sínú àwọn oko rọ́bà tí ó wà yí ibẹ̀ ká láti yẹra fún òjò-ọta láti ojú òfuurufú. Àwọn ará ní àdúgbò (títíkan ọ̀pọ̀ àwọn ará tí a fipa mú láti fi ilé wọn sílẹ̀ láti olú-ìlú, Monrovia) ṣètò iṣẹ́-òjíṣẹ́ pápá a sì lè rí wọn déédéé tí wọ́n ń wàásù fún ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn tí ó forípamọ́ sábẹ́ àwọn igi rọ́bà náà! Nígbàkigbà tí ọkọ̀ òfuurufú kan bá ń bọ̀, àwọn arákùnrin àti arábìnrin náà yóò bẹ́ sínú kòtò kan tí ó bá wà nítòsí, nígbà tí ewu náà bá sì ti kọjá lọ tán, wọ́n a máa bá ìkésíni wọn nìṣó.
Lọ́nà tí ó yanilẹ́nu, àwọn akéde ìjọ tí wọ́n lé ní ẹgbẹ̀rún kan náà, tí ó ṣeéṣe fún láti fi ìròyìn wọn ráńṣẹ́ sí Society ti ní ìpíndọ́gba 18.1 wákàtí nínú iṣẹ́-òjíṣẹ́ pápá wọ́n sì ń darí 3,111 ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli lóṣooṣù, láìka àwọn ipò ogun abẹ́lé wọ̀nyí sí.
Ní ọdún mẹ́rin tí ó kọjá ní Africa, àwọn ìkálọ́wọ́kò lórí iṣẹ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ni a ti mú kúrò ní orílẹ̀-èdè 18. Ìdùnnú ṣubú layọ̀! Ní August 12, ìfofindè tí a ti gbékarí àwọn Ẹlẹ́rìí ní Malawi láti October 1967, ni a mú kúrò. Nígbà gbogbo ni wíwàásù ìhìnrere lábẹ́lẹ̀ máa ń láásìkí, ṣùgbọ́n ó ṣeéṣe fún àwọn Ẹlẹ́rìí láti máa fi òmìnira tẹ̀síwájú nísinsìnyí, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn yóò níláti dúró de àjíǹde láti tún kí ọ̀pọ̀ àwọn alábàákẹ́gbẹ́ wọn ọ̀wọ́n tí àwọn aninilára ti ṣekúpa káàbọ̀.
Ní Mozambique, àdéhùn-àjùmọ̀ṣe àlàáfíà kan bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ní October 4, 1992. Àwọn ìpínlẹ̀ tí kò ṣeédé tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀ nítorí ogun tí ń panirun láti ọdún 16 sẹ́yìn ni a ti ń dé. Ní agbègbè Carioco, a fìdí ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ múlẹ̀ lẹ́ẹ̀kan síi pẹ̀lú 375 àwọn arákùnrin àti arábìnrin tí wọ́n ti pàdánù gbogbo ìfarakanra pẹ̀lú ètò-àjọ náà fún ọdún méje tí ó ti kọjá. A ṣe àpéjọ àkànṣe ọlọ́jọ́ kan ní Milange, olú-ìlú ibi tí a mọ̀ tẹ́lẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ibùdó ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ àti ibùdó-ìgbòkègbodò fún “ìtúnkọ́lẹ́kọ̀ọ́” àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa, ọ̀pọ̀ àwọn ẹni tí wọ́n jẹ́ olùwá-ibi-ìsádi láti Malawi. Àròpọ̀ iye yíyanilẹ́nu kan ti 2,915 ènìyàn ni wọ́n pésẹ̀, títíkan olùṣàbójútó ìlú náà, tí ó fi inúdídùn tẹ́wọ́gba àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa. Ní ọ̀nà yìí ibùdó-ìgbòkègbodò “ìtúnkọ́lẹ́kọ̀ọ́” tẹ́lẹ̀rí náà di ibùdó-ìgbòkègbodò fún ẹ̀kọ́ àtọ̀runwá ní ọjọ́ náà.
Míṣọ́nnárì kan kọ̀wé pé: “Níti awọn ará wa tí wọ́n bá araawọn ní àwọn ibùdó olùwá-ibi-ìsádi ní Ẹkùn-Ìpínlẹ̀ Tete, aṣojú UNHCR (Kọmíṣọ́nnà Àgbà ti Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè fún Àwọn Olùwá-Ibi-Ìsádi) kan ṣe àkíyèsí kan tí ń ru ọkàn-ìfẹ́ sókè. Ó sọ pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ti ṣètò àwọn ibùdó tiwọn, kúrò ní ọ̀dọ̀ àwọn àwùjọ yòókù. Ó sọ pé, ‘Ibùdó wọn ni ọ̀kanṣoṣo tí a ń bójútó lọ́nà yíyẹ,’ ní fífikún-un pé, ‘àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa jẹ́ afínjú, wọ́n wà létòlétò, wọn sì ní ìmọ̀-ẹ̀kọ́.’ Lẹ́yìn náà ni ó yọ̀ǹda láti fi ọkọ̀ òfuurufú gbé mi sọdá igbó náà láti rí i fúnraami. Láti òfuurufú, awakọ̀-òfuurufú náà tọ́kasí àwọn ibùdó méjì. Ọ̀kan rí jákujàku ó sì dọ̀tí, pẹ̀lú àwọn ilé alámọ̀ tí wọ́n kọ́ wúruwùru sẹ́gbẹ̀ẹ́ araawọn. Èkejì ni a wéwèé dáradára, pẹ̀lú àwọn ilé tí a fi ojú-ọ̀nà pààlà sí láàárín lọ́wọ̀ọ̀wọ́. Àwọn ilé náà ní ìrísí mímọ́ tónítóní, pẹ̀lú àwọn àgbàlá tí a gbámọ́. Wọ́n tilẹ̀ kun àwọn kan ní ọ̀dà tí wọ́n fi ọwọ́ ara wọn ṣe. ‘Méfò ewo ni ó jẹ́ tiyín?’ ni awakọ̀-òfuurufú náà sọ. Ayọ̀ ńlá gbáà ni ó jẹ́ fún mí láti pàdé àwọn ará ní ibùdó yìí. Ìjọ mẹ́jọ ni ó wà ní abúlé àwọn Ẹlẹ́rìí yìí nísinsìnyí.”
Ní “Ilẹ̀ Àwọn Idì”
Bẹ́ẹ̀kọ́, èyí kìí ṣe idì ti United States! Láàárín Ìlà-Oòrùn àti Ìwọ̀-Oòrùn ni orílẹ̀-èdè ilẹ̀ Europe kan, Albania wà, orúkọ rẹ̀ nínú èdè tí a fàṣẹ sí, Shqipëria, túmọ̀sí “Ilẹ̀ Àwọn Idì.” Òfin oníkà tí a fi de àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ní ilẹ̀ yìí láti 50 ọdún ni a ti mú kúrò lẹ́nu àìpẹ́ yìí, ó sì ṣeéṣe fún wọn láti sopọ̀ṣọ̀kan pẹ̀lú àwọn ará wọn láti Ìlà-Oòrùn àti Ìwọ̀-Oòrùn nínú ìgbádùn òmìnira ìjọsìn wọn. Nítòótọ́ ni wọ́n ń “ra ìgbà padà.” (Efesu 5:16) Àpéjọ àkọ́kọ́ nínú ọ̀rọ̀-ìtàn Albania, àpéjọ ọlọ́jọ́ kan, ni a ṣe ní Gbọ̀ngàn-Ìwòran Orílẹ̀-Èdè, ní olú-ìlú náà, Tiranë, ní Sunday, March 21. Ní ọ̀sán Saturday agbo-òṣìṣẹ́ àwọn Ẹlẹ́rìí olùyọ̀ǹda ara-ẹni 75 ti sọ ibi ìpàdé tí ó ti di ẹgẹrẹmìtì náà di gbọ̀ngàn àpéjọ lílẹ́wà kan, tí ó mọ́ tónítóní. Ọ̀rọ̀ kọ sísọ fún àwọn olùṣàbójútó ibẹ̀. Ó sì yẹ fún àfiyèsí pé nínú àwọn olùyọ̀ǹda ara-ẹni 75 náà, 20 péré ni ó ti ṣèrìbọmi!
Ojú-ọjọ́ dára. Bí àwọn àyànṣaṣojú láti ilẹ̀ òkèèrè ti ń dé, ìkíni—lọ́pọ̀ jùlọ nípa ìfaraṣàpèjúwe àti ìfọwọ́gbánimọ́ra—mú kí ọjọ́ àpéjọ àkànṣe yẹn jẹ́ àkànṣe gan-an. Pẹ̀lú àtẹ́lẹwọ́ tí ó ṣí sókè, Arákùnrin Nasho Dori gba àdúrà ìbẹ̀rẹ̀. A baptisi rẹ ní 1930 ojú rẹ̀ sì ti di bàìbàì nísinsìnyí. Ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà ní a gbékalẹ̀ ní èdè Albania, tí apá tí ó pọ̀ jùlọ sì jẹ́ láti ẹnu àwọn aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe láti ilẹ̀ òkèèrè. Gbogbo àwọn 585 tí wọ́n wà níbẹ̀ kọ orin náà “Iyasimimọ Kristian”—ọ̀kan nínú mẹ́fà tí wọ́n ti túmọ̀sí èdè Albania fún àkókò-ìṣẹ̀lẹ̀ náà—bí àwọn arákùnrin àti arábìnrin 41 ti ń tò lọ sí ibi ìkùdu kan tí àwọn ará tí ń sọ èdè Griki tí wọ́n ń ṣèbẹ̀wò síbẹ̀ ti finúrere tò kalẹ̀ nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba àdúgbò náà. Ẹ wo bí èyí ti jẹ́ ìyípadà kan tó! Tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀, níní Bibeli kan lọ́wọ́ túmọ̀sí lílọ sí ibùdó iṣẹ́-àṣekára, a sì fi àwọn ìpàdé mọ sí àwùjọ ènìyàn méjì tàbí mẹ́ta.
Ní ọjọ́ tí ó tẹ̀lé àpéjọ náà, ọ́fíìsì Watch Tower rí ìkésíni lórí fóònù gbà láti ọ̀dọ̀ olùdarí gbọ̀ngàn-ìwòran náà. Kìí ní púpọ̀ láti ṣe pẹ̀lú ẹni tí ó bá lo gbọ̀ngàn-ìwòran náà. Iṣẹ́ igbákejì olùdarí nìyẹn. Ṣùgbọ́n ó sọ pé: “Mó ṣáà níláti ṣe ìkésíni láti dúpẹ́ lọ́wọ́ yín ni. Èmi kò tíì rí i rí kí ibí yìí mọ́ tónítóní tóbẹ́ẹ̀. Bí mo bá níláti ṣàpèjúwe rẹ̀, èmi yóò sọ pé atẹ́gùn kan láti ọ̀run sọ̀kalẹ̀ sórí gbọ̀ngàn-ìwòran wa ní àná. Nígbàkigbà tí ẹ óò bá fẹ́ láti lo ilé wa, ẹ jọ̀wọ́ ẹ padà wá, àwa yóò sì fi yín sí ipò àkọ́kọ́. Ṣé ẹ mọ̀, níti gidi ó yẹ kí a máa jẹ́ kí ẹ wá lóṣù mẹ́ta mẹ́ta láìsanwó rẹ́ǹtì.”
Àwọn Ẹlẹ́rìí tí a ti fúnlókun tí wọ́n sì kún fún ọpẹ́ náà padà lọ sí ìlú wọn tí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ síí múrasílẹ̀ fún Ìṣe-Ìrántí ikú Jesu. Ní kìkì ọjọ́ 15 lẹ́yìn náà, ní Tuesday, April 6, Ìṣe-Ìrántí àkọ́kọ́ ní gbangba ni a ṣe ní ibi méje.
Ní ìlú Berat, iye àwọn tí ń wá sí ìpàdé ti ròkè dé nǹkan bíi 170, inú sì bí àlùfáà àdúgbò náà gidigidi. Nínú àwọn akéde Ìjọba 33 tí ń bẹ ní Berat, 21 ni ó ṣèrìbọmi ní àpéjọ náà. Berat ròyìn 472 tí wọ́n pésẹ̀ síbi Ìṣe-Ìrántí náà. Iye àwọn tí ó pésẹ̀ síbi Ìṣe-Ìrántí yòókù tún tayọ pẹ̀lú, lọ́pọ̀ jùlọ nítorí ìdarí rere tí àwọn aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe fifúnni.
Ní ìlú tí àwọn Katoliki pọ̀ sí jùlọ ní Albania, Shkodër, níbi tí ṣọ́ọ̀ṣì bàsílíkà wà, ṣọ́ọ̀ṣì náà bẹ̀rẹ̀ síí tẹ àkójọ-ìsọfúnni olóṣooṣù fún àwọn mẹ́ḿbà rẹ̀, ìtẹ̀jáde kọ̀ọ̀kan sì ti níí ṣe pẹ̀lú “Bi A Ṣe Lè Yẹra fún Àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa.” Ìtẹ̀jáde tí ó kẹ́yìn sọ pé: “Àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ti rọ́wọ Shkodër”! Ẹgbẹ́-ọmọ-ogun ńlá náà ti àwọn Ẹlẹ́rìí méjì tí ó wà níbẹ̀ kó àwọn ènìyàn 74 tí wọ́n mọ̀wàáhù tí wọ́n sì mọnú-ún-rò wá síbi Ìṣe-Ìrántí. Lẹ́yìn gbígbọ́ ọ̀rọ̀-àsọyé Ìṣe-Ìrántí náà, àwọn ìdílé 15 béèrè fún ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli inú ilé. Ní ìlú mìíràn, Durres, níbi tí ẹgbẹ́-ọmọ-ogun àwọn Ẹlẹ́rìí mẹ́rin wà, ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀ pé àwọn 79 ni wọ́n pésẹ̀.
Nítorí àtakò láti ọ̀dọ̀ àwọn èwe onísìn Kátólíkì, tí wọ́n halẹ̀ pé àwọn yóò fi òkúta lé àwọn Ẹlẹ́rìí náà lọ, ìpàdé Ìṣe-Ìrántí ní abúlé olókè-ńlá ti Kalmeti i Vogel ní a lọ ṣe ní ilé arákùnrin kan ní àdúgbò, níbi tí àwọn 22 pésẹ̀ sí ní àlàáfíà. Àwọn akéde márùn-ún ni wọ́n wà nínú àwùjọ yìí, mẹ́ta nínú wọn sì ṣèrìbọmi ní àpéjọ tí ó wáyé ní Tiranë.
Ní Vlorë àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin méjì kan gba ẹ̀dà Ilé-Ìṣọ́nà kan, wọ́n kà á, wọ́n sì kọ̀wé sí Society pé: “A ń pe araawa ní Ẹlẹ́rìí Jehofa nísinsìnyí nítorí òtítọ́ tí a ti kọ́ nínú Ilé-Ìṣọ́nà. Ẹ jọ̀wọ́ ẹ nasẹ̀ ìrànlọ́wọ́ dé ọ̀dọ̀ wa.” Àwọn aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe méjì ní a rán lọ síbẹ̀, ọ̀kan nínú àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin wọ̀nyí sì yára tóótun gẹ́gẹ́ bí akéde kan. Ó láyọ̀ láti wà lára àwọn 64 tí wọ́n pésẹ̀ síbi Ìṣe-Ìrántí ní Vlorë.
Arákùnrin ará Albania kan tí ó kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ ní United States padà sí ìlú ìbílẹ̀ rẹ̀ Gjirokastër ní àwọn ọdún 1950, níbi tí ó ti ṣiṣẹ́sìn dé ìwọ̀n-ààyè tí ó lè ṣeé dé títí di ọjọ́ ikú rẹ̀. Ó gbin irúgbìn òtítọ́ sínú ọkàn-àyà ọmọkùnrin rẹ̀. Nígbà tí a mú ìfòfindè náà kúrò, ọmọkùnrin yìí béèrè fún ìrànlọ́wọ́ lọ́dọ̀ Watch Tower Society. Olùfìfẹ́hàn mìíràn tí ń gbé ní abúlé kan tí ó wà ní ìhà àríwá ni òun pẹ̀lú ti kọ̀wé fún ìrànlọ́wọ́, nítorí náà àwọn aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe mẹ́rin ni a rán lọ síbẹ̀. Ní òwúrọ̀ ọjọ́ Wednesday tí ó tẹ̀lé Ìṣe-Ìrántí, ọ̀kan nínú wọn késí ọ́fíìsì Society ní Tiranë lórí fóònù pé: “Èmi kò lè ṣàìmá sọ fún yín bí ohun tí ẹ̀mí Jehofa ṣe ti pọ̀ tó. A láyọ̀ gan-an ni. Ìṣe-Ìrántí náà yọrísírere.” Iye àwọn tí ó pésẹ̀ jẹ́ 106, títíkan agbo àwọn akéde Ìjọba wọn méje.
Kí ni nípa ti àròpọ̀ àwọn tí wọ́n pésẹ̀ síbi Ìṣe-Ìrántí? Ní 1992, nígbà tí 30 àwọn akéde Ìjọba péré wà, iye àwọn tí ó pésẹ̀ jẹ́ 325. Ní 1993, àwọn 131 akéde náà ti kó 1,318 àwọn olùpésẹ̀ jọ. Ní ọdún méjèèjì, àwọn olùpésẹ̀ ti fi ìgbà mẹ́wàá ju iye àwọn akéde lọ. Ẹ wo bí ó ti ru ìmọ̀lára sókè tó láti ríi tí “ẹni-kékeré kan . . . di ẹgbẹ̀rún” láàárín irú àkókò kúkúrú bẹ́ẹ̀!—Isaiah 60:22.
“Mú Kí Àwọn Okùn Àgọ́ Rẹ Gùn Síi”
Bí iṣẹ́ ìwàásù àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ti ń gbòòrò lọ dé gbogbo igun ilẹ̀-ayé, ìpè náà jáde lọ pé: “Mú kí ibi àgọ́ rẹ fẹjú síi. Sì jẹ́ kí wọ́n na àwọn aṣọ àgọ́ ti àgọ́-ìsìn títóbilọ́lá rẹ jáde gbalaja. Máṣe fawọ́ sẹ́yìn. Mú kí àwọn okùn àgọ́ rẹ gùn síi, kí o sì sọ àwọn ìdólẹ̀ àgọ́ rẹ wọnnì di alágbára. Nítorí ìwọ ó máa jáde lọ nìṣó sí ọ̀tún àti sí òsì.” (Isaiah 54:2, 3, NW) Jíjáde lọ nìṣó yìí nínú “àgọ́-ìsìn títóbilọ́lá” ti Ọlọrun—ti a ṣojú fún nípasẹ̀ ìjọ àwọn olùjọ́sìn rẹ̀ kárí-ayé—ti hàn kedere nítòótọ́ ní Ìlà-Oòrùn Europe, ní pàtàkì jùlọ ní àwọn ilẹ̀ Soviet Union àtijọ́. Lẹ́yìn mímú àwọn ènìyàn rẹ̀ dúró ní àwọn ẹ̀wádún ìfàṣẹ kánilọ́wọ́kò, nísinsìnyí Jehofa ń pèsè okun-inú alágbára-iṣẹ́ tí àwọn Ẹlẹ́rìí rẹ̀ nílò láti mú ètò-àjọ náà gbòòrò kí ó sì lókun síi.
Ní Moscow, Russia, ní Pápá-Ìṣeré Locomotive, ní July 22 sí 25, góńgó iye 23,743 pésẹ̀ síbi àpéjọpọ̀ àgbáyé mánigbàgbé kan tí ó jẹ́ ti ọ̀wọ́ “Ẹ̀kọ́ Àtọ̀runwá” ní ọdún tí ó kọjá. Ta ni ó lè ronú pé èyí yóò ṣeéṣe, kódà ní ọdún méjì sẹ́yìn? Ṣùgbọ́n ó ṣeéṣe! Iye tí ó ju 1,000 wá láti Japan àti Korea, iye tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó 4,000 wá láti United States àti Canada, ẹgbẹẹgbẹ̀rún mìíràn sì wá láti àwọn ilẹ̀ tí ó ju 30 lọ ní Gúúsù Pacific, Africa, Europe, àti àwọn agbègbè mìíràn—ìpàdéra Ìlà-Oòrùn àti Ìwọ̀-Oòrùn ni nítòótọ́. Ẹ wo bí ó ti fún gbogbo àwọn wọ̀nyí níṣìírí tó láti darapọ̀ fàlàlà pẹ̀lú iye tí ó ju 15,000 àwọn arákùnrin àti arábìnrin wọn láti Russia! Ayọ̀ kún àkúnwọ́sílẹ̀.
Àròpọ̀ iye yíyanilẹ́nu ti 1,489 àwọn Ẹlẹ́rìí titun ni a baptisi. Àwọn oníròyìn fún ìrìbọmi náà ní ìpolongo ńláǹlà yíká ayé, títíkan àwòrán dídára kan ní ojú-ewé àkọ́kọ́ ìwé-ìròyìn The New York Times. Bí àtẹ́wọ́ ti dún-bí-ààrá tó nígbà ìrìbọmi, ti ìgbà ọ̀rọ̀-àsọyé ìparí tún lékenkà, nígbà tí olùbánisọ̀rọ̀ náà, lẹ́yìn tí ó ti dúpẹ́ lọ́wọ́ 4,752 àwọn olùyọ̀ǹda ara-ẹni àti àwọn ìjòyè-òṣìṣẹ́ tí wọ́n ti ṣèrànlọ́wọ́ láti mú kí àpéjọpọ̀ náà yọrísírere, sọ pé: “Ju gbogbo rẹ̀ lọ, a dúpẹ́ lọ́wọ́ Jehofa!” Bẹ́ẹ̀ni, ẹ̀mí Jehofa ti dá àtakò lílekoko láti ọ̀dọ̀ àwọn onísìn Orthodox dúró ó sì ti pèsè agbára-ìṣiṣẹ́ ṣíṣekókó tí ó mú kí àpéjọpọ̀ náà jẹ́ òtítọ́-gidi kan tí ń múnilóríyá.
Bí ó ti wù kí ó rí, púpọ̀ síi ṣì ń bọ̀, ní ìlú-ńlá Kiev ní Ukraine, ní August 5 sí 8. Lẹ́ẹ̀kan síi, àwọn olùyọ̀ǹda ara-ẹni tí wọ́n wà ní ìmúratán sọ pápá-ìṣeré náà dọ̀tun pátápátá, Gbọ̀ngàn Ìjọba gìrìwò yìí sì gba 64,714 gẹ́gẹ́ bíi góńgó iye àwọn tí ó pésẹ̀. Lẹ́ẹ̀kan síi, àwọn Ẹlẹ́rìí náà wá láti Ìlà-Oòrùn àti Ìwọ̀-Oòrùn àti àwọn apá ibi gbogbo nínú ayé. Àwọn lájorí ọ̀rọ̀-àsọyé ní a ṣètúmọ̀ sí èdè 12. Nǹkan bíi 53,000 àwọn àyànṣaṣojú, tí wọ́n bá onírúurú ohun-ìrìnnà wá, ní a níláti lọ pàdé ní àwọn ìdíkọ̀ àti ibùdó ọkọ̀ òfuurufú tí a sì gbé wọn lọ sí ilé-ibùgbé wọn ní àwọn òtẹ́ẹ̀lì, ilé-ẹ̀kọ́, àti àwọn ilé-àdáni, àti lórí àwọn ọkọ̀-ojú-omi pẹ̀lú. Gbogbo èyí ni a ṣe láìnáwó rẹpẹtẹ pẹ̀lú ètò tí ó lọ geere tí ó sì gbéṣẹ́ kan tí ó mú kí àwọn ọlọ́pàá ìlú náà sọ àwọn ọ̀rọ̀ ìyàlẹ́nu àti ọ̀rọ̀ ìyìn jáde.
Apá títayọ nínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ àpéjọpọ̀ tí ó múnilóríyá náà ni ìrìbọmi, èyí tí ó gba wákàtí méjì àti ààbọ̀ gbáko. Àròpọ̀ 7,402 àwọn arákùnrin àti arábìnrin titun fi ẹ̀rí ìyàsímímọ́ wọn fún Jehofa hàn, nígbà ti àtẹ́wọ́ ń dún léraléra ṣáá yíká pápá-ìṣeré gbàràmù náà. Èyí pọ̀ ju góńgó ìrìbọmi ti tẹ́lẹ̀ tí ó ju ti ìgbàkígbà rí lọ ti 7,136 tí a ṣe àkọsílẹ̀ nígbà tí 253,922 àwọn olùpéjọpọ̀ kórajọ ní New York City ní 1958.
Bí àkókò ìdájọ́ yìí ti ń tẹ̀síwájú nísinsìnyí sí paríparí-òpin rẹ̀, àwọn ẹni-bí-àgùtàn láti Ìlà-Oòrùn, Ìwọ̀-Oòrùn, àti láti “apá ibi jíjìnnà jùlọ ní ilẹ̀-ayé” ni a ń kójọ sínú ìṣọ̀kan kan tí kò ní ìbádọ́gba nínú gbogbo ọ̀rọ̀-ìtàn ènìyàn. Nítòótọ́, “ogunlọ́gọ̀ ńlá kan . . . láti inú gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè àti ẹ̀yà àti ènìyàn àti ahọ́n” ń darapọ̀ mọ́ Israeli tẹ̀mí ní pípolongo ìgbàgbọ́ wọn nínú ẹbọ ìràpadà ṣíṣeyebíye ti Jesu, ìpìlẹ̀ gbogbo ohun tí a tí ń ṣaṣeparí ní ìdáláre ìṣàkóso Jehofa ọba-aláṣẹ.—Iṣe 1:8, NW; Ìfihàn 7:4, 9, 10, NW.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8, 9]
Ìlà-Oòrùn pàdé Ìwọ̀-Oòrùn ní Moscow àti Kiev