ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w96 1/1 ojú ìwé 24-28
  • Jehofa Kò Fìgbà Kankan Pa Wá Tì

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Jehofa Kò Fìgbà Kankan Pa Wá Tì
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Kíkẹ́kọ̀ọ́ Òtítọ́ Bibeli
  • Wíwàásù Láìka Àtakò Sí
  • Ìnira Nígbà Ogun Àgbáyé Kejì
  • A Dán Wa Wo Lórí Ọ̀ràn Àìdásítọ̀túntòsì
  • Mo Padà Sí Abúlé Wa
  • A Dá Ìpèsè Ìwé Ìkẹ́kọ̀ọ́ Dúró
  • Ìṣòro Ń Pọ̀ Sí I
  • Ìyípadà Òjijì
  • Fún Ìjọba Ọlọrun Nìkan
  • Jèhófà ti fún Mi Ní “Agbára tí Ọ́ Ré Kọjá Ìwọ̀n ti Ẹ̀dá”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2002
  • Wọ́n Yọ̀ǹda Ara Wọn Tinútinú—Ní Alibéníà àti Kosovo
    Ìrírí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà
  • Bí A Ṣe Pa Òùngbẹ Tẹ̀mí Tó Ń Gbẹ Mí
    Jí!—2003
  • Ìlà-Oòrùn àti Ìwọ̀-Oòrùn, Jehofa Ń Fún Àwọn Ènìyàn Rẹ̀ Lókun
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
w96 1/1 ojú ìwé 24-28

Jehofa Kò Fìgbà Kankan Pa Wá Tì

GẸ́GẸ́ BÍ NASHO DORI ṢE SỌ Ọ́

Mbreshtan jẹ́ abúlé kékeré, tí ó ní òkè, ní gúúsù Albania, tí kò jìnnà sí ilẹ̀ Gíríìkì. Níbẹ̀ ni a bí mi ní 1907. Nígbà tí mo pé ọmọ ọdún márùn-ún, mo bẹ̀rẹ̀ sí lọ sí ilé ẹ̀kọ́ Gíríìkì, ṣùgbọ́n ìdádúró bá lílọ sí ilé ẹ̀kọ́ mi nígbà tí ẹgbẹ́ ọmọ ogun Itali kógun ti Albania nígbà Ogun Àgbáyé Kìíní. Lẹ́yìn ogun náà, mo padà sí ilé ẹ̀kọ́, ṣùgbọ́n ó jẹ́ ní èdè Albania.

BÍ Ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn òbí mi kò fi bẹ́ẹ̀ nífẹ̀ẹ́ nínú ìsìn, wọ́n máa ń pa àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ Ṣọ́ọ̀ṣì Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì Albania mọ́. Àbúrò bàbá mi àgbà jẹ́ àlùfáà ní Mbreshtan, nítorí náà, mo ṣiṣẹ́ ní ṣọ́ọ̀ṣì, mo sì rí ohun tí ń ṣẹlẹ̀ níbẹ̀ gan-an. Ààtò ìsìn náà dà bí ohun tí kò já mọ́ nǹkan kan, àgàbàgebè náà sì kọ mí lóminú.

Àwọn òbí mi yan ọ̀dọ́mọbìnrin kan fún mi láti fẹ́, gẹ́gẹ́ bí àṣà àdúgbò. Argjiro wá láti abúlé Grabova nítòsí, a sì ṣègbéyàwó ní 1928, nígbà tí ó jẹ́ ọmọ ọdún 18.

Kíkẹ́kọ̀ọ́ Òtítọ́ Bibeli

Ní àkókò náà, mo ṣàròyé nípa Ṣọ́ọ̀ṣì Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì fún mọ̀lẹ́bí mi kan tí ó wá kí wa láti United States. Ó dáhùn pé: “Ní America, nítòsí ilé mi, àwùjọ àwọn ènìyàn kan wà tí wọn kò ní ṣọ́ọ̀ṣì, ṣùgbọ́n wọ́n ń kẹ́kọ̀ọ́ Bibeli.” Èrò kíkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli láìní ṣọ́ọ̀ṣì wù mí. Nítorí náà, mo béèrè bóyá ó lè fi ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli díẹ̀ ránṣẹ́ sí mi.

Mo ti gbàgbé pátápátá nípa ìjíròrò wa títí di nǹkan bí ọdún kan lẹ́yìn náà, nígbà tí mo rí ẹrù kan gbà láti Milwaukee, Wisconsin. Ìwé náà, Duru Ọlọrun, ní èdè Albania àti Ilé-Ìṣọ́nà ní èdè Gíríìkì wà nínú rẹ̀. Mo wo ìwé náà gààrà, mo sì ṣàkíyèsí pé ó tọ́ka sí ṣọ́ọ̀ṣì tòótọ́. Ìyẹn dà mí lọ́kàn rú. Mo sọ fún ara mi pé, ‘N kò fẹ́ ní ohunkóhun ṣe pẹ̀lú ṣọ́ọ̀ṣì.’ Nítorí náà, n kò ka ìwé náà dáradára.

Ní 1929, mo wọ iṣẹ́ ológun, a sì rán mi lọ sí ìlú Tiranë, olú ìlú Albania. Níbẹ̀ ni mo ti padé Stathi Muçi, tí ń ka Bibeli Gíríìkì. Mo béèrè pé: “O ha máa ń lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì bí?” Ó dáhùn pé: “Rárá. Mo ti fi ṣọ́ọ̀ṣì sílẹ̀. Mo jẹ́ ọ̀kan lára àwọn àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bibeli Kárí Ayé.” Ní ọjọ́ Sunday, èmi àti sójà míràn bá Stathi lọ sí ìpàdé. Níbẹ̀ ni mo ti kẹ́kọ̀ọ́ pé ṣọ́ọ̀ṣì tòótọ́ kì í ṣe ilé tàbí ìsìn kan, ṣùgbọ́n ó jẹ́ àkójọpọ̀ àwọn ẹni àmì òróró ìránṣẹ́ Kristi. Nígbà náà ni ohun tí ìwé Duru Ọlọrun ń sọ tó yé mi.

Nasho Idrizi àti Spiro Vruho ti padà sí Albania láti United States ní àárín àwọn ọdún 1920, wọ́n sì ń tan òtítọ́ Bibeli tí wọ́n ti kọ́ níbẹ̀ kálẹ̀. Mo bẹ̀rẹ̀ sí lọ sí ìpàdé ní Tiranë, pa pọ̀ pẹ̀lú Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bibeli díẹ̀. Láìpẹ́, ó ṣe kedere sí mi pé, mo ti rí ètò àjọ Jehofa. Nítorí náà, ní August 4, 1930, mo ṣe batisí ní odò kan nítòsí.

Lẹ́yìn náà, mo padà sí Mbreshtan láti máa bá iṣẹ́ bàtà ṣíṣe mi nìṣó. Ṣùgbọ́n ní pàtàkì, mo tún bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàjọpín òtítọ́ Bibeli tí mo ti kọ́ pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn. Mo máa ń sọ fún wọn pé: “Jesu Kristi kò rí bí àwọn ère tí ó wà nínú ṣọ́ọ̀ṣì. Ó wà láàyè!”

Wíwàásù Láìka Àtakò Sí

Ahmed Bey Zogu gba ìjọba ní 1925, ó sọ ara rẹ̀ di Ọba Zog Kìíní ní 1928, ó sì jọba títí di 1939. Mínísítà rẹ̀ fún ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn fọwọ́ sí iṣẹ́ Kristian wa. Síbẹ̀síbẹ̀, a ní ìṣòro. Ó jẹ́ nítorí pé Musa Juka, tí ó jẹ́ mínísítà ọ̀rọ̀ abẹ́lé, ní ìbáṣepọ̀ tímọ́tímọ́ pẹ̀lú póòpù ní Romu. Juka pàṣẹ pé kìkì ìsìn mẹ́ta péré ni kí a fọwọ́ sí—ìsìn Mùsùlùmí, Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì àti Roman Kátólíìkì. Àwọn ọlọ́pàá gbìyànjú láti gbẹ́sẹ̀ lé àwọn ìwé wa, kí wọ́n sì dá iṣẹ́ ìwàásù wa dúró, ṣùgbọ́n wọn kò ṣàṣeyọrí.

Ní àwọn ọdún 1930, mo sábà máa ń ṣèbẹ̀wò sí Berat, ìlú kan tí ó tóbi ní Albania, láti ibi tí Mihal Sveci ti ń darí iṣẹ́ ìwàásù wa. A ṣètò ìrìn àjò ìwàásù jákèjádò orílẹ̀-èdè náà. Nígbà kan, a ran mi lọ sí ìlú Shkodër, fún ọ̀sẹ̀ méjì, o sì ṣeé ṣe fún mi láti fi ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ púpọ̀ sóde. Ní 1935, díẹ̀ lára wa háyà bọ́ọ̀sì kan láti wàásù ní ìlú Këlcyrë. Lẹ́yìn náà, a ṣètò ìrìn àjò tí ó túbọ̀ tóbi láàárín Albania sí ìlú Përmet, Leskovik, Ersekë, Korçë, Pogradec àti Elbasan. A parí ìrìn àjò náà sí Tiranë lásìkò, kí a baà lè ṣayẹyẹ Ìṣe Ìrántí ikú Kristi.

Ìpèsè oúnjẹ nípa tẹ̀mí ràn wá lọ́wọ́ láti máa lágbára nípa tẹ̀mí, nítorí náà, a kò nímọ̀lára pé a pa wá tì. Láti 1930 sí 1939, mo rí Ilé-Ìṣọ́nà lédè Gíríìkì gbà déédéé. Góńgó mi tún ni láti ka Bibeli fún ó kéré tán wákàtí kan lójoojúmọ́, mo sì ṣe bẹ́ẹ̀ fún nǹkan bí 60 ọdún kí agbára ìríran mi tóó bàjẹ́. Lẹ́nu àìpẹ́ yìí ni Bibeli lódindi tóó ṣẹ̀ṣẹ̀ wà ní èdè Albania, nítorí náà, inú mi dùn pé mo kọ́ èdè Gíríìkì nígbà tí mo wà ní ọmọdé. Àwọn Ẹlẹ́rìí ọmọ ilẹ̀ Albania mìíràn pẹ̀lú, nígbà yẹn lọ́hùn-ún kọ́ bí a ti ń ka Gíríìkì, kí àwọn pẹ̀lú baà lè ka Bibeli lódindi.

Argjiro ṣe batisí ní 1938. Nígbà tí ó fi di 1939, a ti bí méje nínú àwọn ọmọ wa mẹ́wàá. Ó bani nínú jẹ́ pé, mẹ́ta lára àwọn ọmọ wa méje àkọ́kọ́ kú ní kékeré.

Ìnira Nígbà Ogun Àgbáyé Kejì

Ní April 1939, kété kí Ogun Àgbáyé Kejì tó bẹ̀rẹ̀, ẹgbẹ́ ọmọ ogun Ìjọba Aláṣẹ Oníkùmọ̀ ti Itali kọlu Albania. Láìpẹ́ lẹ́yìn náà, a gbẹ́sẹ̀ lé iṣẹ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa, ṣùgbọ́n àwùjọ wa kékeré tí ó ní 50 àwọ̀n olùpòkìkí Ìjọba nínú ń bá iṣẹ́ ìwàásù lọ. Nǹkan bí 15,000 ìwé àti ìwé pélébé wa ni wọ́n gbẹ́sẹ̀ lé, tí wọ́n sì bà jẹ́ nígbà Ogun Àgbáyé Kejì.

Jani Komino ní ilé ìkẹ́rùsí ńlá kan fún àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́, tí a kọ́ mọ́ ilé rẹ̀. Nígbà tí agbo ọmọ ogun Itali náà mọ̀ pé United States ni a ti tẹ àwọn ìwé náà, inú wọn ru. Wọ́n sọ pé: “Agbékèéyíde ni yín! United States lòdì sí Itali!” Wọ́n fàṣẹ ọba mú àwọn ọ̀dọ́ arákùnrin onítara náà, Thomai àti Vasili Cama, nígbà tí wọ́n sì gbọ́ pé ọ̀dọ̀ Komino ni àwọn ìwé tí wọ́n ń pín ti wá, a fàṣẹ ọba mú òun pẹ̀lú. Láìpẹ́, àwọn ọlọ́pàá pè mí fún ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò.

Wọ́n béèrè pé: “O ha mọ àwọn ọkùnrin wọ̀nyí bí?”

Mo dáhùn pé: “Bẹ́ẹ̀ ni.”

“O ha ń bá wọn ṣiṣẹ́ bí?”

Mo dáhùn pé: “Bẹ́ẹ̀ ni. Ẹlẹ́rìí Jehofa ni wá. A kò lòdì sí ìjọba. A kò dá sí tọ̀túntòsì.”

“O ha ti ń pín ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ yìí kiri bí?”

Nígbà tí mo dáhùn pé bẹ́ẹ̀ ni, wọ́n fi ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ sí mi lọ́wọ́, wọ́n sì fi mí sẹ́wọ̀n ní July 6, 1940. Níbẹ̀ ni mo ti dara pọ̀ mọ́ àwọn márùn-ún mìíràn láti abúlé mi—Josef Kaci, Llukan Barko, Jani Komino, àti àwọn ọmọ Cama. Nígbà tí a wà ní ọgbà ẹ̀wọ̀n, a pàdé àwọn Ẹlẹ́rìí mẹ́ta mìíràn—Gori Naçi, Nikodhim Shyti, àti Leonidas Pope. Wọ́n fún àwa mẹ́sẹ̀ẹ̀sán pọ̀ sí yàrá àhámọ́ kékeré kan tí ó jẹ́ mítà 1.8 lóòró àti mítà 3.7 níbùú!

Lẹ́yìn ọjọ́ díẹ̀, wọ́n fi ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ dè wá pa pọ̀, wọ́n sì gbé wa lọ sí ilú Përmet. Oṣù mẹ́ta lẹ́yìn náà, wọ́n gbé wa lọ sí ọgbà ẹ̀wọ̀n ní Tiranë, wọ́n sì tì wá mọ́lé fún oṣù mẹ́jọ mìíràn láìgbẹ́jọ́ wa.

Níkẹyìn, a fara hàn níwájú ilé ẹjọ́ ológun kan. A fi èmi àti Arákùnrin Shyti sí ẹ̀wọ̀n oṣù 27, a fi Arákùnrin Komino sí ẹ̀wọ̀n oṣù 24, a sì dá àwọn yòókù sílẹ̀ lẹ́yìn oṣù 10. A gbé wa lọ sí ọgbà ẹ̀wọ̀n Gjirokastër, níbi tí Arákùnrin Gole Flloko ti ṣèrànwọ́ láti rí i pé a tú wa sílẹ̀ ní 1943. Lẹ́yìn náà, ìdílé wa fìdí kalẹ̀ sí ìlú Përmet, níbi tí mo ti di alábòójútó ìjọ kékeré náà.

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a fòfin de iṣẹ́ wa, tí Ogun Àgbáyé Kejì sì ń jà rànyìn ní àwọn orílẹ̀-èdè tí ó yí wa ká, a ń bá a lọ láti máa ṣe ohun tí a lè ṣe láti ṣe iṣẹ́ tí a fún wa láti wàásù ìhìn iṣẹ́ Ìjọba náà. (Matteu 24:14) Ní 1944, àwọn Ẹlẹ́rìí 15 ni ó wà ní ọgbà ẹ̀wọ̀n lápapọ̀. Síbẹ̀, ní àwọn àkókò líle koko yìí, a kò fìgbà kankan nímọ̀lára pé Jehofa pa wá tì.

A Dán Wa Wo Lórí Ọ̀ràn Àìdásítọ̀túntòsì

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ogun náà parí ní 1945, ìṣòro wa ń bá a lọ, ó sì túbọ̀ ń burú sí i. Ìdìbò ní ọ̀ràn-anyàn ni a kànńpá nígbà ìdìbò December 2, 1946. Ẹnikẹ́ni tí ó bá gbójúgbóyà láti kọ̀ ni a kà sí ọ̀tá Ìjọba. Àwọn tí wọ́n wà ní ìjọ wa ní Përmet bẹ̀rẹ̀ sí í béèrè pé, “Kí ni kí á ṣe?”

Mo dáhùn pé: “Bí ẹ bá gbẹ́kẹ̀ lé Jehofa, kò yẹ kí ẹ béèrè ohun tí ẹ óò ṣe lọ́wọ́ mi. Ẹ ti mọ̀ tẹ́lẹ̀ pé àwọn ènìyàn Jehofa kì í dá sí tọ̀tún tòsì. Wọn kì í ṣe apá kan ayé.”—Johannu 17:16.

Ọjọ́ ìdìbò pé, àwọn aṣojú ìjọba sì wá sí ilé wa. Wọ́n bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ohùn tútù: “Ẹ jẹ́ kí a mu kọfí kí a sì sọ̀rọ̀ pọ̀. O ha mọ irú ọjọ́ tí òní jẹ́ bí?”

Mo dáhùn pé: “Bẹ́ẹ̀ ni, òní ni ọjọ́ ìdìbò.”

Òṣìṣẹ́ kan sọ pé: “O jẹ́ ṣe kíá, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, ìwọ yóò pẹ́.”

Mo dáhùn pé: “Rárá, n kò wéwèé láti lọ. Jehofa ni a dìbò fún.”

“Nígbà náà, wá lọ dìbò fún àwọn alátakò.”

Mo ṣàlàyé pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa kì í dá sí tọ̀túntòsì rárá. Nígbà tí wọ́n mọ ìdúró wa dáradára, wọ́n túbọ̀ fúngun mọ́ wa. Wọ́n pàṣẹ pé kí a má ṣe ìpàdé mọ́, nítorí náà, a bẹ̀rẹ̀ sí pàdé pọ̀ níkọ̀kọ̀.

Mo Padà Sí Abúlé Wa

Ní 1947, èmi àti ìdílé mi padà sí Mbreshtan. Láìpẹ́ lẹ́yìn náà, ní ọ̀sán ọjọ́ kan tí òtútù ń mú ní December, wọ́n pè mí wá sí ọ́fíìsì Sigurimi (ọlọ́pàá ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́). Ọlọ́pàá náà béèrè pé: “O ha mọ ìdí tí mo fi pè ọ́ bí?”

Mo fèsì pé: “Mo fura pé ó jẹ́ nítorí pé o ti gbọ́ ẹ̀sùn kan nípa mi. Ṣùgbọ́n Bibeli sọ pé ayé yóò kórìíra wa, nítorí náà ìfẹ̀sùnkanni kò yà mí lẹ́nu.”—Johannu 15:18‚ 19.

Ó kígbe mọ́ mi pé: “Máà bá mi sọ̀rọ̀ nípa Bibeli. N óò fìyà pá ọ lórí.”

Ọlọ́pàá náà àti àwọn ọmọ abẹ́ rẹ̀ jáde, ṣùgbọ́n wọ́n ní kí n dúró síta nínú òtútù. Lẹ́yìn àkókò díẹ̀, ó pè mi padà sínú ọ́fíìsì rẹ̀, ó sì pàṣẹ fún mi láti dá ìpàdé ṣíṣe nínú ilé wa dúró. Ó béèrè pé: “Àwọn mélòó ni ń gbé ní abúlé rẹ?”

Mo wí pé: “Ọgọ́fà ènìyàn.”

“Ìsìn wo ni wọ́n ń ṣe?”

“Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì Albania.”

“Ìwọ ńkọ́?”

“Mo jẹ́ ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa.”

“Ọgọ́fà ènìyàn dorí kọ ibì kan, ìwọ́ gba ibòmíràn?” Lẹ́yìn náà, ó pàṣẹ fún mi láti tan àbẹ́là nínú ṣọ́ọ̀ṣì. Nígbà tí mo sọ pé n kò lè ṣe é, ó bẹ̀rẹ̀ sí í fi ọ̀pá lù mí. Nǹkan bí aago kan òru ni wọ́n tó tú mi sílẹ̀.

A Dá Ìpèsè Ìwé Ìkẹ́kọ̀ọ́ Dúró

Lẹ́yìn tí Ogun Àgbáyé Kejì parí, a tún bẹ̀rẹ̀ sí í rí Ilé-Ìṣọ́nà gbà nípasẹ̀ ìfìwéránṣẹ́, ṣùgbọ́n àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, àwọn ìwé ìròyìn náà ni a kò fi jíṣẹ́ mọ́. Lẹ́yìn náà, ní alẹ́ ọjọ́ kan, ní aago mẹ́wàá, àwọn ọlọ́pàá ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ mú mi lọ. Wọ́n sọ fún mi pé: “Ìwé ìròyìn kan ní èdè Gíríìkì ti dé, a sì fẹ́ kí o ṣàlàyé ohun tí ó dá lé lórí fún wa.”

Mo sọ pé: “N kò mọ èdè Gíríìkì dáradára. Aládùúgbò mi mọ̀ ọ́n jù mí lọ. Bóyá ó lè ràn yín lọ́wọ́.”

Bí ọlọ́pàá kan ti fa ẹ̀dà Ilé-Ìṣọ́nà lédè Gíríìkì yọ, ó sọ pé: “Rárá, ìwọ ni a fẹ́ kí o ṣàlàyé eléyìí.”

Mo pariwo pé: “Tèmi nìwọ̀nyí! Dájúdájú, mo lè ṣàlàyé èyí. Ṣé ẹ rí i, Brooklyn, New York, ni àwọn ìwé ìròyìn wọ̀nyí ti wá. Ibẹ̀ ni orílé-iṣẹ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa wà. Mo jẹ́ ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa. Ṣùgbọ́n ó dà bí pé wọ́n ṣe àṣìṣe nínú àdírẹ́sì tí wọ́n kọ. Èmi ni ó yẹ kí wọ́n fi àwọn ìwé ìròyìn wọ̀nyí ránṣẹ́ sí, kì í ṣe ẹ̀yin.”

Wọn kò fún mi ni àwọn ìwé ìròyìn náà, àti láti ìgbà náà wá títí di 1991, ní èyí tí ó lé ní 40 ọdún lẹ́yìn náà, a kò rí ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli kankan gbà ní Albania. Ní gbogbo àwọn ọdún wọ̀nyẹn, a ń bá a lọ láti máa wàásù, ní lílo Bibeli wa nìkan. Nǹkan bí 20 Ẹlẹ́rìí ni wọ́n wà ní ọgbà ẹ̀wọ̀n ní 1949; a fi àwọn kan sí ẹ̀wọ̀n ọdún márùn-ún.

Ìṣòro Ń Pọ̀ Sí I

Ní àwọn ọdún 1950, a pàṣẹ fún àwọn ènìyàn láti máa mú ìwé tí ń fi hàn pé wọ́n fara mọ́ ológun rìn kiri. Ṣùgbọ́n àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa kọ̀ láti mú irú ìwé bẹ́ẹ̀ rìn. Nítorí èyí, èmi àti Arákùnrin Komino lo oṣù méjì míràn ní ọgbà ẹ̀wọ̀n.

A ní ìwọ̀n òmìnira díẹ̀ nígbà tí Ìjọba fàyè gbà á pé kí àwọn ìsìn kan wà. Ṣùgbọ́n, ní 1967, a fòfin de gbogbo ìsìn, èyí sì sọ Albania di orílẹ̀-èdè tí kò gbọlọ́run gbọ́. Àwọn Ẹlẹ́rìí ń bá a nìṣó láti máa gbìyànjú láti ṣe ìpàdé, ṣùgbọ́n ó ṣòro gidigidi. Díẹ̀ lára wa rán àpò àràmàǹdà sínú ìtẹ́nú ẹ̀wù wa, kí a baà lè fi Bibeli kékeré pa mọ́ sínú rẹ̀. Nígbà náà, a lè lọ sínú pápá láti lọ kà á.

Wọ́n gbá àwọn Ẹlẹ́rìí ní Tiranë mú, wọ́n sì fi mẹ́ta lára wọn sẹ́wọ̀n ọdún márùn-ún ní àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ jíjìnnà réré. Nítorí ìdí èyí, àwọn ìdílé wọn jìyà. A kò kó àwa tí a wá láti abúlé kékeré, tí ó wà ní àdádó, nítorí pé a kò kà wá sí ewu kankan lọ títí. Ṣùgbọ́n ìdúró àìdásítọ̀túntòsì wa mú kí a yọ orúkọ wa kúrò nínú iwé tí a fi ń pín oúnjẹ. Nítorí náà, ìgbésí ayé le koko. Bákan náà, méjì sí i lára àwọn ọmọ wa kú. Síbẹ̀ a kò fìgbà kankan nímọ̀lára pé Jehofa pa wá tì.

Ìbẹ̀rù gba ibi gbogbo kan ní Albania. A ń ṣọ́ gbogbo ènìyàn, àwọn ọlọ́pàá ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ ń kọ ìròyìn nípa ẹnikẹ́ni tí ó bá gbójúgbóyà láti sọ ohun kan tí ó yàtọ̀ sí ti ẹgbẹ́ tí ń ṣàkóso. Nítorí náà, a ń ṣọ́ra gidigidi nípa ṣíṣe àkọsílẹ̀ kankan nípa ìgbòkègbodò wa. A kò lè pàdé pọ̀ láti gbé ara wa ró nípa tẹ̀mí ní àwùjọ tí ó ju méjì tàbí mẹ́ta lọ. Síbẹ̀, a kò dáwọ́ wíwàásù dúró.

Kí wọ́n baà lè dá rúgúdù sílẹ̀ láàárín àwọn ará, àwọn ọlọ́pàá ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ tan àhesọ náà kálẹ̀ pé Ẹlẹ́rìí kan tí ó gbajúmọ̀ ní Tiranë jẹ́ amí. Èyí mú kí àwọn kan sọ ìgbọ́kànlé wọn nù, ó sì ba ìṣọ̀kan wa jẹ́ lọ́nà kan ṣáá. Nítorí pé a kò ní ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli ti lọ́ọ́lọ́ọ́ kankan, a kò sí ní àjọṣepọ̀ pẹ̀lú ètò àjọ Jehofa tí ó ṣeé fojú rí, àwọn díẹ̀ juwọ́ sílẹ̀ fún ìbẹ̀rù.

Ní àfikún sí i, àwọn aláṣẹ tan àhesọ náà kálẹ̀ pé Spiro Vruho, Kristian alàgbà kan tí àwọn ènìyàn fẹ́ràn gan-an ní Albania, ti pokùn so. Wọ́n sọ pé: “Kò tán, Vruho pàápàá ti juwọ́ sílẹ̀.” Ó hàn gbangba lẹ́yìn náà pé ní ti gidi, ńṣe ni wọ́n pa Arákùnrin Vruho.

Ní 1975, èmi àti Argjiro gbé lọ́dọ̀ ọmọkùnrin wa ní Tiranë fún oṣù mélòó kan. Ní àkókò ìdìbò náà, àwọn aláṣẹ ìlú náà fúngun mọ́ wa nípa híhalẹ̀ pé: “Bí ẹ kò bá dìbò, a óò gbaṣẹ́ lọ́wọ́ ọmọkùnrin yín.”

Mo dáhùn pé: “Ọmọ mi ti wà lẹ́nu iṣẹ́ rẹ̀ fún ọdún 25. Ẹ ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àkọsílẹ̀ nípa rẹ̀ àti ìdílé rẹ̀. N kò dìbò láti nǹkan tí ó lé ní 40 ọdún. Bí ó ti yẹ kí ó rí, ìsọfúnni yìí wà nínú àkọsílẹ̀ nípa ẹnì kọ̀ọ̀kan. Bí kò bá rí bẹ́ẹ̀, nígbà náà, àkọsílẹ̀ yín kò pé. Bí ó bá wà nínú àkọsílẹ̀ yín, nígbà náà ẹ ti ṣàìṣòótọ́ sí ẹgbẹ́ yín, nípa yíyọ̀ọ̀da fún un láti ṣiṣẹ́ fún ọ̀pọ̀ ọdún.” Nígbà tí wọ́n gbọ́ èyí, àwọn aláṣẹ náà sọ pé, bí a bá padà sí Mbreshtan, àwọn kì yóò fa ọ̀rọ̀ náà mọ́.

Ìyípadà Òjijì

Ní 1983, a ṣí kúrò ní Mbreshtan lọ sí ìlú Laç. Láìpẹ́ lẹ́yìn náà, ní 1985, aláṣẹ bóofẹ́bóokọ̀ náà kú. Ó ti ń ṣàkóso láti ìgbà ìbò ọ̀rànanyàn àkọ́kọ́ náà ní 1946. Kò pẹ́ kò jìnnà, a sọ ère rẹ̀ tí ó wà ní ọ̀gangan ìkóríta Tiranë kalẹ̀ pẹ̀lú ti Stalin.

Láàárín àwọn ẹ̀wádún ìfòfinde ìgbòkègbodò wa náà, ọ̀pọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí ni a fìyà jẹ yánnayànna, a sì pa àwọn kan. Ọkùnrin kan sọ fún àwọn Ẹlẹ́rìí ní òpópónà pé: “Nígbà ìjọba Kọ́múníìsì, gbogbo wa ti gbàgbé Ọlọrun. Kìkì àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ni wọ́n jẹ́ olùṣòtítọ́ sí i, láìka àdánwò àti ìnira sí.”

Bí a ti túbọ̀ ń fún wọn ní òmìnira sí i, àwọn mẹ́sàn-án ni wọ́n ròyìn ìgbòkègbodò nínú iṣẹ́ ìsìn Kristian ní June 1991. Ní June 1992, oṣù kan lẹ́yìn tí wọ́n mú ìfòfindè náà kúrò, ènìyàn 56 ni ó nípìn-ín nínú iṣẹ́ ìwàásù náà. Ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún náà, a láyọ̀ púpọ̀ láti rí i pé 325 ni ó pésẹ̀ síbi Ìṣe Ìrántí ikú Kristi. Láti ìgbà náà wá, iye àwọn tí ń wàásù ti lọ sókè sí iye tí ó lé ní 600, àpapọ̀ àwọn tí wọ́n pésẹ̀ síbi Ìṣe Ìrántí ní April 14, 1995, sì jẹ́ 3,491! Ní àwọn ọdún àìpẹ́ yìí, mo ti ní ayọ̀ tí kò ṣeé ṣàpèjúwe láti rí iye àwọn ọ̀dọ́ tí ń pọ̀ sí i tí wọ́n ń dara pọ̀ mọ́ àwọn ìjọ wa.

Argjiro ti ń bá a lọ láti máa jẹ́ olùṣòtítọ́ sí Jehofa, ó sì ti dúró ṣinṣin tì mí ní gbogbo ọ̀pọ̀ ọdún yìí wá. Nígbà tí mo wà lẹ́wọ̀n tàbí tí mo ń rìnrìn àjò nínú iṣẹ́ ìwàásù, ó ti fi sùúrù bójú tó àìní ìdílé wa láìṣàròyé. Ọ̀kan lára àwọn ọmọ wa àti ìyàwó rẹ̀ ṣe batisí ní 1993. Èyí mú wa láyọ̀ gidigidi.

Fún Ìjọba Ọlọrun Nìkan

Inú mi dùn láti rí i pé ètò àjọ Jehofa ní Albania wà ní ìṣọ̀kan pẹ́kípẹ́kí tí ó sì ń gbádùn ìlọsíwájú nípa tẹ̀mí. Ìmọ̀lára mi dà bi ti Simeoni arúgbó náà ní Jerusalemu, ẹni tí a fún ní àǹfààní rírí Messia tí a ti ṣèlérí tipẹ́tipẹ́ sẹ́yìn náà, ṣáájú ikú rẹ̀. (Luku 2:30‚ 31) Nísinsìnyí, nígbà tí a bá bi mi pé irú ìjọba wo ni mo fara mọ́, mo máa ń wí pé: “N kò fara mọ́ yálà ti Kọ́múníìsì tàbí ti ètò ìṣòwò bòḿbàtà. Ohun tí ó ṣe pàtàkì kì í ṣe bóyá àwọn ènìyàn tàbí Ìjọba ni ó ni ilẹ̀. Àwọn ìjọba ń ṣe títì, wọ́n ń fa iná mànàmáná lọ sí àwọn abúlé tí ó jìnnà réré, wọ́n sì ń mú kí nǹkan wà létòlétò dé ìwọ̀n àyè kan. Àmọ́ ṣáá o, ìṣàkóso Jehofa, Ìjọba rẹ̀ ọ̀run, ni ojútùú kan ṣoṣo sí ìṣòro líle koko tí àwọn ará Albania àti ìyókù gbogbo ayé ń dojú kọ.”

Ohun tí àwọn ìránṣẹ́ Ọlọrun ń ṣe kárí ayé ní wíwàásù nípa Ìjọba Ọlọrun kì í ṣe iṣẹ́ ẹ̀dá ènìyàn kankan. Iṣẹ́ Ọlọrun ni. Àwa ni ìránṣẹ́ rẹ̀. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, a ní ìṣòro púpọ̀ ní Albania, tí a kò sì ní ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ pẹ̀lú ètò àjọ Jehofa tí ó ṣeé fojú rí fún ọ̀pọ̀ ọdún, kò fìgbà kankan pa wá tì. Ẹ̀mí rẹ̀ wà níbẹ̀ nígbà gbogbo. Ó ń tọ́ gbogbo ìṣísẹ̀ wa sọ́nà. Mo ti rí èyí jálẹ̀ ìgbésí ayé mi.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́