Àwọn Ọ̀dọ́ tí Wọ́n ‘Gbẹ́kẹ̀lé Jehofa’
ẸWÀ kìí ṣe ti àwọn èwe nìkan, bẹ́ẹ̀ sì ni ọgbọ́n kìí ṣe ti àwọn àgbà nìkan. (Fiwé Owe 11:22; Oniwasu 10:1.) Kàkà bẹ́ẹ̀, àwọn wọnnì tí wọ́n ni ẹwà wíwà títílọ àti ojúlówó ọgbọ́n ni àwọn wọnnì tí wọ́n gbẹ́kẹ̀lé Jehofa tí wọ́n sì fi tọkàntara sọ nípa rẹ̀ pé: “Ìwọ ni Ọlọrun mi.”—Orin Dafidi 31:14; Owe 9:10; 16:31.
Ogunlọ́gọ̀ àwọn arẹwà ènìyàn ń pọ̀ síi yíká ayé, àti èwe àti àgbà, tí wọ́n ń fi ọgbọ́n wọn hàn nípa ṣíṣiṣẹ́sin Ọlọrun àti wíwàásù ìhìnrere Ìjọba Ọlọrun. Fún àpẹẹrẹ, gbé ọ̀ràn ti Sabrina ọmọ ọdún mẹ́jọ yẹ̀wò.
Sabrina ń gbé ní Germany ó sì wà ní ìpele-ẹ̀kọ́ kejì. Òun ni Ẹlẹ́rìí Jehofa àkọ́kọ́ ní ilé-ẹ̀kọ́ rẹ̀. Ó baninínújẹ́ pé ó jẹ́ àyànsọjú fún ìwọ̀sí àwọn ọmọ-ilé-ẹ̀kọ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ títí di ọjọ́ tí olùkọ́ sọ pé kí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ mú ìwé tí wọ́n yànláàyò jùlọ wá sí kíláàsì. Sabrina pinnu láti mú Iwe Itan Bibeli Mi lọ. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ojora mú un ní alẹ́ tí ó ṣáájú, ó múrasílẹ̀ dáradára fún kíláàsì. Níwọ̀n bí ó ti jẹ́ pé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ 26 ni wọ́n wà ní kíláàsì rẹ̀, ó mọ̀ pé òun lè má ní àkókò púpọ̀. Ṣùgbọ́n ó pinnu láti máṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni dí ìgbékalẹ̀-ọ̀rọ̀ òun lọ́wọ́ ó sì dá a lójú pé Jehofa yóò ran òun lọ́wọ́. Ní ọjọ́ tí a yàn náà, olùkọ́ béèrè ẹni tí ó bá mú ìwé wá tí yóò sì fẹ́ láti kọ́kọ́ fi í hàn. Lọ́nà tí ó yanilẹ́nu, Sabrina nìkan ni ó mú ọ̀kan wá. Ó dúró níwájú kíláàsì ó sì bẹ̀rẹ̀ síí sọ̀rọ̀, ní kíkà àti fífi àwọn àwòrán hàn láti inú ìwé náà tí ó sì ń ṣàlàyé pé gbogbo rẹ̀ ní a gbékarí Bibeli. Ní ìparí ó béèrè pé: “Ta ni yóò fẹ́ láti ní ìwé yìí?” Ó fún olùkọ́ náà ní ẹ̀dà kan, àti ní ọjọ́ díẹ̀ lẹ́yìn náà, ó fi ìwé mẹ́wàá síi ní àfikún fún díẹ̀ nínú àwọn ọmọ-ilé-ẹ̀kọ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀. Àlàyé kanṣoṣo tí olùkọ́ rẹ̀ ṣe lórí ìgbékalẹ̀-ọ̀rọ̀ náà ni pé: “Èmi kò tíì rí ohun tí ó dàbí rẹ̀ rí.” Ó fún Sabrina ní máàkì o-yege tí ó dára jùlọ fún iṣẹ́ rẹ̀.
Nítòótọ́, ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́ Ẹlẹ́rìí ni wọ́n jẹ́ aláyọ̀ akéde ìhìnrere náà ní ilé-ẹ̀kọ́. Àpẹẹrẹ mìíràn ni ti Erika, akéde ọmọ ọdún 11 ní Mexico. A ti kọ́ ọ láti nífẹ̀ẹ́ Jehofa láti ìgbà ọmọdé jòjòló. Iṣẹ́ ilé-ẹ̀kọ́ rẹ̀ tayọ. Ọ̀kan nínú àwọn iṣẹ́-àyànfúnni rẹ̀ ni láti múra àkójọpọ̀-ọ̀rọ̀ kan sílẹ̀ lórí àrùn AIDS àti sísọ tábà àti ọtí-líle di bárakú. Ó múrasílẹ̀ dáradára, ní lílo ìwé-ìròyìn Jí!, ó sì gba máàkì tí ó dára jùlọ. Olùkọ́ rẹ̀ béèrè ibi tí ó ti rí ìsọfúnni náà ó sì fún un ní àwọn ìwé-ìròyìn tí ó ní àwọn ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ nípa kókó-ẹ̀kọ́ náà nínú. Lẹ́yìn náà, olùkọ́ náà lo àwọn ìwé-ìròyìn wọ̀nyí láti jíròrò kókó-ẹ̀kọ́ náà pẹ̀lú gbogbo kíláàsì. Nítorí ìwà Erika, ọ̀wọ̀ tí ó ní fún àwọn olùkọ́ rẹ̀, àti máàkì o-yege dídára tí ó máa ń gbà, ó ti tóótun fún àwọn ẹ̀bùn, ìwé-ẹ̀rí, àti àwọn àǹfààní ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ alábọ́ọ́dé. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ó nímọ̀lára pé àṣeyọrí òun tí ó tóbi jùlọ ni pé òun ti fi ara òun hàn gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa, pé òun ti lè fi ìwé-ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli sóde, tí òun sì ti gbé orúkọ Ọlọrun ga.
Shannon, ọmọdékùnrin ọlọ́dún mẹ́wàá tí ń gbé ní New Zealand kò gbẹ́yìn rárá. Ẹyọkan nínú ojú rẹ̀ ni ó ń ríran; káńsà ti fọ́ ọ̀kan yòókù mọ́ ọn lọ́wọ́ nígbà tí ó ṣì wà ní ọmọ-ọwọ́. Nígbà tí Shannon wà ní ọmọ ọdún méje, ìyá rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ síí kẹ́kọ̀ọ́ Bibeli pẹ̀lú àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa. Bí ó ti wù kí ó rí, láìpẹ́ lẹ́yìn tí ó bẹ̀rẹ̀ ẹ̀kọ́ Bibeli rẹ̀, ó bẹ̀rẹ̀ síí gbé pẹ̀lú ọkùnrin kan láìsí àǹfààní ìgbéyàwó ó sì pinnu láti dá ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ dúró. Shannon bẹ̀bẹ̀ pé kí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli òun máa báa lọ. Wọ́n gbà bẹ́ẹ̀ fún un. Àwọn Ẹlẹ́rìí náà sì ń bẹ̀ ẹ́ wò nìṣó, àti ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀ gbogbo àwọn mẹ́ḿbà mẹ́tẹ̀ẹ̀ta nínú ìdílé náà kẹ́kọ̀ọ́ Bibeli wọ́n sì tẹ̀síwájú nípa tẹ̀mí. Lẹ́yìn tí wọ́n ti ṣègbéyàwó lábẹ́ òfin tán, ìyá Shannon àti ọkọ ìyá rẹ̀ ní a baptisi.
Ní ọjọ́ kan Shannon àti ìyàwó alábòójútó àyíká jọ wà nínú iṣẹ́-ìsìn pápá. Onílé kan béèrè lọ́wọ́ Shannon pé: “Kí ni ó ṣe ọ́ lójú?” “Káńsà ló mú mi níbẹ̀, wọ́n sì níláti yọ ọ́ kúrò,” ni ó dáhùn. “Láìpẹ́ Jehofa yóò fún mi ní titun mìíràn nínú Paradise, ohun tí a sì wá sọ fún ọ nípa rẹ̀ nìyẹn.”