Jíjọ́sìn Ọlọ́run Ní Òtítọ́
Kí ìjọsìn tó lè ṣètẹ́wọ́gbà lọ́dọ̀ Ọlọ́run, ó gbọ́dọ̀ dá lórí òtítọ́. (Jòhánù 4:23) Bíbélì tọ́ka pé àwọn olùjọsìn tòótọ́ jẹ́ ara “ìjọ Ọlọ́run alààyè, ọwọ̀n àti ìtìlẹyìn òtítọ́.” (1 Tímótì 3:15) Kì í ṣe pé àwọn tí wọ́n parapọ̀ di ìjọ Ọlọ́run gba òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run gbọ́ nìkan ni, wọ́n tún ń gbé ní ìbámu pẹ̀lú rẹ̀, wọ́n sì ń gbèjà rẹ̀, wọ́n sì ń sọ ọ́ di mímọ̀ jákèjádò ayé.—Mátíù 24:14; Róòmù 10:9-15.
A MỌ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà dáadáa fún iṣẹ́ ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí wọ́n ń ṣe, tí wọ́n ti ṣe dé ilẹ̀ tí ó lé ní 200 báyìí. Wọ́n ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, wọ́n sì ń fi kọ́ni bí òtítọ́, láìfi àbá èrò orí ènìyàn tí ń dín agbára tí Bíbélì ń ní lórí ẹni kù kún un. Ìwọ ha mọ àwọn ohun tí wọ́n fi ń kọ́ni láti inú Bíbélì bí? Ọ̀pọ̀ ènìyàn kì í fẹ́ gbọ́ ọ̀rọ̀ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nítorí àwọn ọ̀rọ̀ burúkú tí àwọn ènìyàn ń sọ nípa wọn. Àmọ́ a ń ké sí àwọn aláìlábòsí-ọkàn láti pinnu fúnra wọn bóyá òtítọ́ ni ohun tí Àwọn Ẹlẹ́rìí ń wàásù rẹ̀ tàbí kì í ṣe òtítọ́. Kò yẹ kí a gbé irú ìpinnu ṣíṣekókó bẹ́ẹ̀ karí àgbọ́sọ. Ọ̀pọ̀ àwọn tí wọ́n ti ṣèwádìí fúnra wọn nípa àwọn ohun tí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi ń kọ́ni ti jàǹfààní ńláǹlà.
Ìmọ̀ Òtítọ́ Ń Bi Ìbẹ̀rù Dànù
Fún àpẹẹrẹ, gbé ọ̀ràn Eugenia yẹ̀ wò. Inú ìdílé onísìn Kátólíìkì tí kò gba gbẹ̀rẹ́ ni wọ́n ti tọ́ ọ dàgbà. Bàbá rẹ̀ wà lára àwọn tó ṣètò pé kí póòpù wá bẹ Mexico wò ní ọdún 1979. Nígbà tí Eugenia ń bẹ àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ wò, ó bá Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà pàdé. Wọ́n ràn án lọ́wọ́, ó sì túbọ̀ bẹ̀rẹ̀ sí ṣàyẹ̀wò ohun tí Bíbélì sọ kínníkínní. Ó rántí pé: “Lákọ̀ọ́kọ́, ẹ̀rù bẹ̀rẹ̀ sí í bà mí gan-an. Mo ti rí òtítọ́! Ṣùgbọ́n èyí túmọ̀ sí pé púpọ̀ lára àwọn ohun tí mo ti gbà gbọ́ tẹ́lẹ̀ kò tọ̀nà. Àwọn ẹbí, ọ̀rẹ́, àwọn tí mo fẹ́ràn—kò sí èyí tó tọ̀nà nínú wọn. Ojora mú mi. Mo bẹ̀rẹ̀ sí bi ara mi léèrè nípa bí àwọn ẹbí mi yóò ṣe hùwà padà sí ohun tí mo ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣàwárí náà. Bí àkókò ti ń lọ àti pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Jèhófà, mo bẹ̀rẹ̀ sí mú ara bá ìrírí kíkọyọyọ yìí mu. Lọ́jọ́ kan, mo pinnu láti fi àṣírí náà han ọ̀rẹ́ ìdílé wa kan, tí ó jẹ́ ọ̀jọ̀gbọ́n nínú ẹ̀kọ́ ìsìn. Mo sọ gbogbo ìfẹ́ ọkàn mi láti rí òtítọ́ fún un. Lẹ́yìn náà, ó sọ pé: ‘Bí o bá fẹ́ mọ òtítọ́, wá Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà rí.’”
Ohun tí Eugenia bẹ̀rù ló ṣẹlẹ̀, àwọn ẹbí rẹ̀ lé e jáde nílé. Àmọ́, Àwọn Ẹlẹ́rìí kò yé ràn-án lọ́wọ́ nípa tẹ̀mí. Ó wí pé: “Mo rí okun tí yóò mú mi dúró níhà òtítọ́. Mo mọ̀ pé ohun tí ó tó jà fún ni. Títẹ́wọ́ tí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tẹ́wọ́ gbà mí ṣe pàtàkì gan-an. Mo nímọ̀lára pé àwọn ará nífẹ̀ẹ́ mi nínú ìjọ Kristẹni. Sísúnmọ́ ètò àjọ Ọlọ́run ràn mí lọ́wọ́ láti borí ìbẹ̀rù àìrí ìtìlẹ́yìn àwọn ẹbí mi.”
Tún gbé àpẹẹrẹ mìíràn yẹ̀ wò. Nínú ìdílé tí Sabrina ti dàgbà, àṣà wọn ni láti máa jíròrò nípa Bíbélì déédéé. Ní gidi, wọ́n ní irú ‘ẹ̀sìn ìdílé’ kan. Ó jẹ́ àṣà rẹ̀ láti máa dara pọ̀ mọ́ àwọn mẹ́ńbà onírúurú ìsìn kí ó bàa lè tú àṣírí àwọn àṣìṣe wọn. Nígbà tí ọ̀kan lára Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ̀ ọ́, kíá ló gbà, àmọ́ pẹ̀lú èrò fífi hàn pé àwọn ohun tí wọ́n gbà gbọ́ kò tọ̀nà. Ó rántí pé: “Lẹ́yìn kíkẹ́kọ̀ọ́ fún ohun tí ó lé ní ọdún kan, ẹ̀rù bẹ̀rẹ̀ sí bà mí pé n óò sọ ‘òtítọ́ mi’ nù. Ó ti máa ń rọrùn fún mi láti tú àṣírí ìwà ẹ̀tàn tí ó wà nínú ọ̀pọ̀ ìsìn tí mo ti ṣe, àmọ́ kò rọrùn nínú ọ̀ràn ti Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà.”
Ẹ̀rù tí ń ba Sabrina mú kí ó dá ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń bá a ṣe dúró. Àmọ́ ṣá, ó nímọ̀lára àìjámọ́ǹkan nípa tẹ̀mí. Ó pinnu láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ padà, ó sì wá gba òtítọ́ tuntun yìí lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn. Sabrina tẹ̀ síwájú débi tí ó fi ń fẹ́ láti ṣàjọpín ohun tí ó ń kọ́ pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn. Ó tilẹ̀ sọ pé òun fẹ́ máa bá Àwọn Ẹlẹ́rìí jáde nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn ilé-dé-ilé. Sabrina ṣàlàyé pé: “Kí wọ́n tó fọwọ́ sí i pé kí n máa jáde ìwàásù pẹ̀lú Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, wọ́n béèrè lọ́wọ́ mi pé: ‘Ṣé o fẹ́ di ọ̀kan lára Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní ti gidi?’ Mo dáhùn pé: ‘Rárá!’ Ẹ̀rù tún bà mí gan-an.” Níkẹyìn, lẹ́yìn tí Sabrina tún bẹ̀rẹ̀ sí lọ sí gbogbo ìpàdé, tí ó sì ń ṣàkíyèsí àwọn ènìyàn Ọlọ́run àti bí wọ́n ṣe ń fi àwọn ìlànà Bíbélì sílò, ó wá parí èrò sí pé, láìsí tàbí-tàbí, òtítọ́ ni ó jẹ́. Ó ṣèrìbọmi, ó sì ti di ajíhìnrere alákòókò kíkún nísinsìnyí.
Èyí Ṣe Yàtọ̀?
Àwọn kan lè béèrè pé, ‘Èé ṣe tí ohun tí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi ń kọ́ni ṣe yàtọ̀ sí ti àwọn ẹlẹ́sìn mìíràn?’ Yíyára wo ohun tí Àwọn Ẹlẹ́rìí gbà gbọ́ yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti rí i pé Kristẹni tí kò lábòsí, tí ń fi òtítọ́ ọ̀kan kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ni wọ́n. A rọ̀ ọ́ láti wo àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí wọ́n jẹ́ àkópọ̀ ìpìlẹ̀ ìgbàgbọ́ wọn, tí a fi hàn lókè yìí, nínú Bíbélì rẹ.
Nípa wíwo àwọn ohun tí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà gbà gbọ́ dáradára àti bí wọ́n ṣe ń pa ohun tí Bíbélì fi ń kọ́ni mọ́, a lè fi òmìnira tí òtítọ́ ń fúnni jíǹkí rẹ. (Jòhánù 17:17) Kò sí ìdí tí a fi ní láti bẹ̀rù òtítọ́. Rántí ìlérí tí Jésù ṣe pé: “Ẹ ó sì mọ òtítọ́, òtítọ́ yóò sì dá yín sílẹ̀ lómìnira.”—Jòhánù 8:32.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 6]
DÍẸ̀ LÁRA ÀWỌN LÁJORÍ ÌGBÀGBỌ́ ÀWỌN ẸLẸ́RÌÍ JÈHÓFÀ
◯ Jèhófà ni Ọlọ́run alágbára ńlá gbogbo. Ó lé ní ibi 7,000 tí orúkọ rẹ̀ ti hàn nínú àwọn ìwé àfọwọ́kọ Bíbélì.—Sáàmù 83:18.
◯ Ọmọ Ọlọ́run ni Jésù Kristi, ó wá sí orí ilẹ̀ ayé láti fi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀ fún aráyé. (Jòhánù 3:16, 17) Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń tẹ̀ lé àwọn ohun tí Jésù Kristi fi kọ́ni bí ó ṣe wà nínú àwọn ìwé Ìhìn Rere.
◯ A gbé orúkọ náà, Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, karí Aísáyà 43:10, tí ó wí pé: “‘Ẹ̀yin ni ẹlẹ́rìí mi,’ ni àsọjáde Jèhófà.”
◯ Ìṣàkóso ti ọ̀run tí kò ní pẹ́ mú gbogbo ìyà àti ìrora kúrò ní ayé, kí àyè lè wà fún Párádísè tí Bíbélì ṣèlérí ni Ìjọba tí àwọn ènìyàn ń gbàdúrà fún nínú àdúrà “Baba Wa Tí Ń Bẹ Ní Ọ̀run.”—Aísáyà 9:6, 7; Dáníẹ́lì 2:44; Mátíù 6:9, 10; Ìṣípayá 21:3, 4.
◯ Olúkúlùkù ẹni tí ó bá ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run ló ní àǹfààní láti gbádùn àwọn ìbùkún Ìjọba náà títí ayérayé.—Jòhánù 17:3; 1 Jòhánù 2:17.
◯ Àwọn Kristẹni gbọ́dọ̀ máa fi ohun tí Bíbélì wí tọ́ ìwà wọn sọ́nà. Wọ́n gbọ́dọ̀ gbìyànjú láti jẹ́ aláìlábòsí, kí wọ́n gbé ìgbésí ayé tí kò lábààwọ́n, ìgbésí ayé oníwàrere, kí wọ́n sì fi ìfẹ́ hàn fún àwọn aládùúgbò wọn.—Mátíù 22:39; Jòhánù 13:35; 1 Kọ́ríńtì 6:9, 10.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]
Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń sọ òtítọ́ Bíbélì di mímọ̀ fún àwọn ènìyàn ní ilẹ̀ tí ó lé ní 200