Ìdíje Ha Ni Kọ́kọ́rọ́ náà sí Àṣeyọrísírere Bí?
“KÒ SÍ ohun tí ó ṣe pàtàkì ju bíborí lọ.” Lónìí ọ̀pọ̀ ènìyàn ń gbé ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, tí a sábà máa ń kà sí ti Vince Lombardi, olùdánilẹ́kọ̀ọ́ eré bọ́ọ̀lù àfẹsẹ̀gbá ní ilẹ̀ America. Nísinsìnyí, àwọn orílẹ̀-èdè Kọmunist tẹ́lẹ̀rí ti darapọ̀ nínú gbígbé ìlànà ìdíje lárugẹ. Dídá ìdíje sílẹ̀ ní ibi ètò káràkátà wọn ní wọ́n sọ pé ó jẹ́ ohun tí ń múni jèrè ọrọ̀ rẹpẹtẹ. Ní àwọn ilẹ̀ Gábàsì, ọ̀pọ̀ òbí ń mu àwọn ọmọ wọn forígbárí tí wọ́n sì ń rán wọn lọ sí ilé-ẹ̀kọ́ aládàáni tí ń kọ́ wọn ni àwọn ọgbọ́n bérébéré fún yíyege nínú ìdánwò àṣewọlé. Àwọn òbí tí ọ̀ràn yìí kálára gbà pé ìwọlé sínú ilé-ẹ̀kọ́ títayọlọ́lá ni kọ́kọ́rọ́ náà sí aásìkí ọjọ́-ọ̀la.
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ gbàgbọ́ lọ́nà lílágbára pé ìdíje ni kọ́kọ́rọ́ náà sí àṣeyọrísírere. Gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti gbàgbọ́, àwọn ènìyàn ti ní ìlọsíwájú nípa bíbá araawọn díje. Ìpín 65.9 nínú ọgọ́rùn-ún àwọn olùdarí àgbà ní àwọn ilé-iṣẹ́ pàtàkì tí Àjọ Ètò Ọrọ̀-Ajé Orílẹ̀-Èdè Japan wádìí wò sọ pé: “Ìdíje fún ìgbéga ni orísun agbára àwọn ilé-iṣẹ́ ilẹ̀ Japan.” Ó sì dàbí ẹni pé ó ṣe díẹ̀ tí àwọn ilé-iṣẹ́ ilẹ̀ Japan ti ń kẹ́sẹjárí. Bí ó ti wù kí ó rí, ìdíje ha ni kọ́kọ́rọ́ náà sí àṣeyọrísírere bí?
Ó Ha Lérè Níti Tòótọ́ Bí?
Àwọn ènìyàn tí wọ́n ń bá àwọn ẹlòmíràn díje ń fi ìṣarasíhùwà ìmọtara-ẹni-nìkan, tèmi-làkọ́kọ́ hàn. Wọ́n ń láyọ̀ nígbà tí nǹkan bá burú fún àwọn ẹlòmíràn, ní ríronú pé yóò mú kí ipò tiwọn gbé pẹ́ẹ́lí síi. Fún èrè ìmọtara-ẹni-nìkan tiwọn, wọ́n lè lo àwọn ọgbọ́n àyínìke tí yóò pa àwọn ẹlòmíràn lára. Kí ni irú ìlépa àṣeyọrí nípasẹ̀ ìdíje bẹ́ẹ̀ yóò jálẹ̀ sí? Yasuo, tí ó ri araarẹ̀ wọnú ìdíje láti di ẹni pàtàkì nínú ilé-iṣẹ́ rẹ̀ rántí ipa-ọ̀nà rẹ̀ àtijọ́ ó sì wí pé: “Bí mo ti kún fún ẹ̀mí ìbánidíje àti ìrònú ìgbéga, mo fi araami wé àwọn ẹlòmíràn mo sì nímọ̀lára pé mo sàn jù. Nígbà tí a bá gbé àwọn wọ̀nyẹn sí ipò tí ó ga ju tèmi lọ, lójoojúmọ́ ni mo máa ń bínú tí mo sì ń ṣàròyé nípa ọ̀nà tí a gbà ń bójútó àwùjọ òṣìṣẹ́ ilé-iṣẹ́ náà. Kí n sọ ọ́ bí ọ̀rọ̀ náà ti rí gan-an, èmi kò ní ọ̀rẹ́ kankan.”
Ẹ̀mí ìbáradíje tún lè yọrísí ikú àìtọ́jọ́. Báwo? Ìwé-ìròyìn Japan náà Mainichi Daily News so karoshi, tàbí ikú tí àṣejù iṣẹ́ ń múwá, mọ́ ìṣarasíhùwà onípò kìn-ín-ní. Onípò kìn-ín-ní ṣàpèjúwe ọ̀nà ìgbàhùwà kan tí ń fi wàdùwàdù, ìbáradíje, àti àránkàn kojú pákáǹleke. Àwọn onímọ̀ nípa àrùn ọkàn-àyà tí wọ́n jẹ́ ọmọ ilẹ̀ America, Friedman àti Rosenman so ìṣarasíhùwà onípò kìn-ín-ní pọ̀ mọ́ àrùn ìṣàn ẹ̀jẹ̀ ọkàn-àyà. Bẹ́ẹ̀ni, ẹ̀mí ìbáradíje lè ṣekúpani.
Ìdíje ní ibi iṣẹ́ tún lè yọrísí àrùn ìṣiṣẹ́gbòdì ara àti ti ọpọlọ pẹ̀lú. Àpẹẹrẹ kan ni ti Keinosuke, tí ó jẹ́ òǹtàjà títayọlọ́lá fún ọ̀kan nínú àwọn oníṣòwò ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ ti Japan. Ó tayọlọ́lá nípa títa àròpọ̀ 1,250 ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́. Fọ́tò rẹ̀ ni a yà tí a sì gbékọ́ sí iyàrá tí àwọn ìgbìmọ̀ olùṣàbójútó ẹgbẹ́-òwò náà ń lò. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òun kórìíra lílo àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí òkúta àtẹ̀gùn fún rírí ìgbéga, ilé-iṣẹ́ náà sún un láti díje. Gẹ́gẹ́ bí ìyọrísí rẹ̀, láàárín ọdún kan ó ṣàìsàn ọgbẹ́ inú àti ti ìfun. Ní ọdún yẹn kan náà, àwọn olùdarí àgbà 15 ní ilé-iṣẹ́ rẹ̀ ni a gbà sí ilé ìwòsàn, ọ̀kan sì fi ọwọ́ araarẹ̀ pa araarẹ̀.
Ní ilé, ìṣarasíhùwà ní-oun-tẹ́gbẹ́-ń-ní náà ń sún àwọn ènìyàn láti ṣe àṣehàn ṣekárími nípa àwọn ohun-ìní wọn nínú ìgbésí-ayé nínú ìfagagbága kan tí kò lópin. (1 Johannu 2:16) Ètò ìṣòwò nìkan ni èyí ń ṣàǹfààní fún, ní rírọ́ owó dà sọ́wọ́ àwọn oníṣòwò ilẹ̀-ayé.—Fiwé Ìfihàn 18:11.
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìfigagbága àti ẹ̀mí ìbáradíje lè mú ìjáfáfá lẹ́nu iṣẹ́ wá, kò yanilẹ́nu pé Ọba Solomoni ṣàkíyèsí pé: “Mo ro gbogbo làálàá àti [ìjáfáfá, NW] iṣẹ́ gbogbo, pé èyíyìí ni ìlara ẹnìkínní láti ọ̀dọ̀ ẹnìkejì rẹ̀. Asán ni èyí pẹ̀lú àti ìmúlẹ̀mófo.” (Oniwasu 4:4) Nítorí náà báwo ni a ṣe lè ní àlàáfíà ọkàn nígbà tí a ń gbé nínú àwùjọ abáradíje kan? Láti ṣàwárí ọ̀nà tí a lè gbà ṣe bẹ́ẹ̀, ẹ jẹ́ kí a kọ́kọ́ wo ibi ti èrò nípa ìbáradíje ti bẹ̀rẹ̀.