ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w94 3/1 ojú ìwé 4-7
  • Àlàáfíà Ọkàn Nínú Àwùjọ Abáradíje

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àlàáfíà Ọkàn Nínú Àwùjọ Abáradíje
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìpilẹ̀ṣẹ̀ Ẹ̀mí Ìbáradíje
  • Àṣeyọrísírere Láìsí Ìdíje
  • Bí A Ṣe Lè Pa Àlàáfíà Ọkàn Mọ́
  • Ìdíje Ha Ni Kọ́kọ́rọ́ náà sí Àṣeyọrísírere Bí?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
  • Inú Rere Àìlẹ́tọ̀ọ́sí La Fi Gbà Wọ́n Là, Kì í Ṣe Iṣẹ́ Nìkan
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2005
  • Ṣé ẹ Óò Máa Bá a Lọ Láti “Rìn Nípa Ẹ̀mí”?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
  • Ẹ Má Ṣe Máa Bá Ara Yín Díje, Àlàáfíà Ni Kí Ẹ Máa Wá
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2021
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
w94 3/1 ojú ìwé 4-7

Àlàáfíà Ọkàn Nínú Àwùjọ Abáradíje

JESU Kristi gba àwọn aposteli rẹ̀ nímọ̀ràn pé: “Bí ẹnikẹ́ni bá ń fẹ́ ṣe ẹni iwájú, òun náà ni yóò ṣe ẹni ìkẹyìn gbogbo wọn.” Àwọn aposteli ń jiyàn lórí ẹni tí ó tóbilọ́lá jùlọ láàárín wọn. Wọ́n mọ̀ pé Jesu kórìíra irú ẹ̀mí bẹ́ẹ̀. Òun kò fìgbàkan rí forí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ gbárí gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà láti gbé ìtẹ̀síwájú nípa tẹ̀mí lárugẹ.​—⁠Marku 9:​33-⁠37.

Ṣáájú kí ó tó wá sórí ilẹ̀-ayé, Jesu Kristi ṣàjọpín nínú ìṣẹ̀dá tọkọtaya ènìyàn àkọ́kọ́ ó sì mọ bí a ṣe dá wọn. (Kolosse 1:​15, 16) Àwọn ènìyàn àkọ́kọ́ ni a dá pẹ̀lú agbára láti tẹ̀síwájú láìsí bíbá ẹlòmíràn díje láìláàánú. Kò sí ìdí kankan rí fún àwọn ènìyàn láti máa bá araawọn jà láti pinnu ẹni tí ó jẹ́ olórí wọn, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò sì bá àwọn ẹranko díje nínú ìjàkadì láti wàláàyè.​—⁠Genesisi 1:26; 2:20-⁠24; 1 Korinti 11:⁠3.

Ìpilẹ̀ṣẹ̀ Ẹ̀mí Ìbáradíje

Nígbà náà, báwo ni ẹ̀mí ìbáradíje onírẹ́rùnrẹ́rùn ṣe wá di irú agbára kan tí ń darí ẹgbẹ́ àwùjọ ènìyàn? Ọ̀ràn ìpànìyàn àkọ́kọ́ nínú ìtàn ènìyàn pèsè ìsọfúnni kan. Ẹ̀mí ìbáradíje níhà ọ̀dọ̀ Kaini, àkọ́bí tọkọtaya ènìyàn àkọ́kọ́, ni ó yọrísí ìṣẹ̀lẹ̀ bíbaninínújẹ́ náà. Kaini pa arákùnrin rẹ̀ Abeli nítorí pé ẹbọ Abeli dùn mọ́ Ọlọrun nínú, nígbà tí ti Kaini kò rí bẹ́ẹ̀. Bibeli sì sọ pé Kaini “jẹ́ ti ẹni búburú nì, tí ó sì pa arákùnrin rẹ̀.”​—⁠1 Johannu 3:12; Genesisi 4:​4-⁠8.

Bẹ́ẹ̀ni, ẹni búburú nì, Satani Eṣu, ni olùpilẹ̀ṣẹ̀ àti olùgbé ẹ̀mí ìbáradíje lárugẹ. Bí òun tilẹ̀ jẹ́ angẹli ọmọkùnrin Ọlọrun pẹ̀lú àwọn àǹfààní gíga, òun ń fẹ́ púpọ̀ síi. (Fiwé Esekieli 28:​14, 15.) Nígbà tí ó tan Efa jẹ, ó fi ohun tí ìfẹ́-ọkàn rẹ̀ jẹ́ hàn. O sọ pé nípa jíjẹ èso tí a kà léèwọ̀ náà, òun ‘yóò dàbí Ọlọrun.’ (Genesisi 3:​4, 5) Níti gidi, Satani ni ẹni náà tí ó fẹ́ láti dàbí Ọlọrun, ní fífigagbága pẹ̀lú Jehofa. Ẹ̀mí bíbá Ọlọrun díje sún un láti ṣọ̀tẹ̀.​—⁠Jakọbu 1:​14, 15.

Ẹ̀mí yìí máa ń ranni. Lábẹ́ agbára ìdarí Satani, àlàáfíà tí Ọlọrun fifún ìṣètò ìdílé àkọ́kọ́ sọnù. (Genesisi 3:​6, 16) Láti ìgbà tí Satani Eṣu ti ṣọ̀tẹ̀ sí Ọlọrun ni ó ti ń ṣàkóso aráyé, ní mímú ẹ̀mí ìbáradíje gbèèràn, ní fífi ẹ̀tàn mú kí àwọn ọkùnrin ati obìnrin pàápàá gbàgbọ́ pé ìbáradíje onírẹ́rùnrẹ́rùn ni kọ́kọ́rọ́ náà sí àṣeyọrísírere. Bí ó ti wù kí ó rí, Bibeli ṣàlàyé pé: “Ibi tí owú òun ìjà bá gbé wà, níbẹ̀ ni rúdurùdu àti iṣẹ́ búburú gbogbo wà.” (Jakọbu 3:​14-⁠16) Satani tipa báyìí ja ènìyàn lólè ayọ̀ àti àlàáfíà ọkàn rẹ̀.

Àṣeyọrísírere Láìsí Ìdíje

Ní ìyàtọ̀ sí ìyíniléròpadà Satani, Bibeli fúnni ní àwọn àpẹẹrẹ àṣeyọrísírere tí kò ní ìdíje nínú. Ti Jesu Kristi ni èyí tí ó gba ipò iwájú jùlọ. Bí ó tilẹ̀ wà ni àwòrán Ọlọrun, òun kò ronú rẹ̀ rí láti bá Ọlọrun dọ́gba ṣùgbọ́n ó gbé àwọ̀ ìránṣẹ́ wọ̀ ó sì wá sí ilẹ̀-ayé. Jù bẹ́ẹ̀ lọ, ó rẹ araarẹ̀ sílẹ̀ ó sì ṣègbọràn títí dé ojú ikú lórí òpó igi ìdálóró. Ìṣarasíhùwà onígbọràn yìí, tí kò ní ẹ̀mí ìfigagbága kankan nínú, yọrísí jíjèrè tí òun jèrè ìtẹ́wọ́gbà Ọlọrun. “Nítorí náà Ọlọrun pẹ̀lú sì ti gbé e ga gidigidi, ó sì ti fi orúkọ kan fún un tí ó borí gbogbo orúkọ.” (Filippi 2:​5-⁠9) Àṣeyọrísírere tí ó ju èyí lọ wo ni ẹ̀dá èyíkéyìí tún lè ní? Ó mú inú baba rẹ̀ dùn dé ìwọ̀n tí ẹ̀dá mìíràn kan kò lè ṣe é dé, èyí ni òun sì ṣe láìsí ẹ̀mí ìfigagbága tàbí ìbáradíje èyíkéyìí.​—⁠Owe 27:⁠11.

Ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn angẹli olùṣòtítọ́ ní ọ̀run fi ìṣarasíhùwà yìí kan náà hàn. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Jesu, tí ó jẹ́ olórí àwọn angẹli, di ẹni tí ó rẹlẹ̀ sí wọn díẹ̀ nígbà tí ó wá sórí ilẹ̀-ayé, wọ́n fínnú-fíndọ̀ ṣiṣẹ́sìn fún àwọn àìní rẹ̀. Ní kedere, wọn kò gba ìrònú èyíkéyìí láyè láti lo àǹfààní ipò tí ó ṣí sílẹ̀ náà kí wọ́n sì gbìyànjú láti gbapò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Olú-Angẹli.​—⁠Matteu 4:11; 1 Tessalonika 4:16; Heberu 2:⁠7.

Ìríra tí wọ́n ní fún àwọn ìṣarasíhùwà ìbáradíje tilẹ̀ farahàn kedere síi nígbà tí a bá ṣàgbéyẹ̀wò ọ̀nà tí wọ́n ti gbà dáhùnpadà sí ète Ọlọrun láti gbé àwọn ènìyàn aláìpé kan ga sí ipò ẹ̀mí ti ìwàláàyè àìlèkú, nínú èyí tí wọn yóò ti “ṣe ìdájọ́ àwọn angẹli.” (1 Korinti 6:3) Àwọn angẹli ní ọ̀pọ̀ ìrírí nínú ṣíṣiṣẹ́sin Jehofa wọ́n sì ní agbára tí ó pọ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀ láti ṣàṣeparí ohun rere ju bí àwọn ènìyàn aláìpé ti lè ṣe lọ. Síbẹ̀, àwọn angẹli ń fi tayọ̀tayọ̀ ṣèránṣẹ́ fún àwọn ẹni-àmì-òróró tí ń bẹ lórí ilẹ̀-ayé, láìjowú ohun tí àwọn wọ̀nyí yóò gbà. (Heberu 1:14) Àpẹẹrẹ ìṣarasíhùwà rere, aláìbánidíje wọn mú kí ó ṣeéṣe fún wọn láti ṣiṣẹ́sìn níwájú ìtẹ́ Jehofa Oluwa Ọba-Aláṣẹ.

Nígbà náà, ronú nípa àwọn olùṣòtítọ́ ìránṣẹ́ Ọlọrun ní ìgbàanì tí a o jí dìde sórí ilẹ̀-ayé. Abrahamu jẹ́ àpẹẹrẹ títayọ ti ìgbàgbọ́ a sì pè é ní “baba gbogbo àwọn tí ó gbàgbọ́.” (Romu 4:​9, 11) Jobu fi àpẹẹrẹ títayọlọ́lá níti ìfaradà lélẹ̀. (Jakọbu 5:11) Mose, ti “ó ṣe ọlọ́kàn tútù ju gbogbo ènìyàn lọ tí ń bẹ lórí ilẹ̀,” ṣamọ̀nà orílẹ̀-èdè Israeli débi ìsọdòmìnira. (Numeri 12:⁠3) Ta ni nínú àwọn ènìyàn aláìpé tí ó tíì fi àpẹẹrẹ ìgbàgbọ́, ìfaradà, àti ọkàn-tútù tí ó dára ju ti àwọn ọkùnrin wọ̀nyí lọ hàn? Bí ó ti wù kí ó rí, wọ́n wà ní ìlà fún jíjogún apá ìhà ilẹ̀-ayé ti Ìjọba Ọlọrun. (Matteu 25:34; Heberu 11:​13-⁠16) Àwọn, bíi ti Johannu Arinibọmi, ni a óò fi sí ipò tí ó rẹlẹ̀ sí ti “ẹni tí ó kéré jùlọ ní ìjọba ọ̀run.” (Matteu 11:11) Wọn yóò ha ronú nípa ṣíṣàròyé, títẹpẹlẹ mọ́ ọn pé ìgbàgbọ́, ìfaradà, tabi ọkàn-tútù wọn báradọ́gba tàbí nínú àwọn ọ̀ràn kan pé ó tilẹ̀ ju ti àwọn wọnnì tí a fún ni ìyè ní ọ̀run lọ bí? Dájúdájú bẹ́ẹ̀kọ́! Wọn yóò jẹ́ aláyọ̀ ọmọ-abẹ́ Ìjọba Ọlọrun lórí ilẹ̀-ayé.

Lónìí pẹ̀lú, ó máa ń gbádùnmọ́ni láti wà láyìíká àwọn ènìyàn tí kò ní ìṣarasíhùwà ìbáradíje. Yasuo, tí a mẹ́nukàn nínú ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ tí ó ṣáájú, kówọnú gbèsè níbi tí ó ti dáwọ́lé títa góòlù tí ó sì pàdánù gbogbo ohun-⁠ìní rẹ̀. “Awọn ọ̀rẹ́” rẹ̀ kọ̀ ọ́ sílẹ̀. Níwọ̀n bí ìyàwó rẹ̀ si ti bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́kọ̀ọ́ Bibeli pẹ̀lú àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa, ó lọ sí àwọn ìpàdé wọn láti inú ìmọ̀lára àbámọ̀ fún ìjìyà tí ó ti múwá sórí ìdílé rẹ̀. Ní àṣẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, ó gba araarẹ̀ lọ́wọ́ ìbánidíje ó sì di ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa. Nísinsìnyí òun láyọ̀ pé àwọn ọ̀rẹ́ tí wọ́n jẹ́ Kristian yí òun ká, irú àwọn wọnnì tí wọ́n múratán láti ràn án lọ́wọ́ ní àwọn àkókò ìdààmú.

Bí A Ṣe Lè Pa Àlàáfíà Ọkàn Mọ́

Kìí fìgbà gbogbo rọrùn láti pa àlàáfíà ọkàn mọ́ nínú àwùjọ aláìláàánú, abáradíje kan. A ṣe dáradára láti kíyèsi pé Bibeli dẹ́bi fún “ìríra, ìjà, ìlara, ìbínú, asọ̀, ìṣọ̀tẹ̀, àdámọ̀, àránkàn” gẹ́gẹ́ bí “awọn iṣẹ́ ti ara” tí ń ṣèdíwọ́ fún àwọn ènìyàn láti máṣe jogún Ìjọba Ọlọrun. Gbogbo àwọn iṣẹ́ wọ̀nyí máa ń bá ẹ̀mí ìbáradíje rìn ní ìfẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́. Abájọ tí aposteli Paulu fi gba àwọn ará Galatia níyànjú pé: “Ẹ máṣe jẹ́ kí a máa ṣògo-asán, kí a máa [ru ìdíje sókè láàárín araawa, NW], kí a máṣe ìlara ọmọnìkejì wa.”​—⁠Galatia 5:​19-21, 26.

Nínú àyíká-ọ̀rọ̀ yìí, lẹ́tà Paulu fi kọ́kọ́rọ́ náà fún kíkojú ìdíje ológo-asán hàn. O wí pé: “Èso ti ẹ̀mí ni ìfẹ́, ayọ̀, àlàáfíà, ìpamọ́ra, ìwà pẹ̀lẹ́, ìṣoore, ìgbàgbọ́, ìwà tútù, àti ìkóra-ẹni-níjàánu: òfin kan kò lòdì sí irú wọnnì.” (Galatia 5:​22, 23) Èso ti ẹ̀mí ń ràn wá lọ́wọ́ láti mú ìfagagbága kúrò ní ọkàn wa. Gbé ànímọ́ ìfẹ́ yẹ̀wò gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ. Paulu ṣàlàyé pé: “Ìfẹ́ kìí ṣe ìlara; kìí sọ̀rọ̀ ìgbéraga, kìí fẹ̀, kìí hùwà àìtọ́, kìí wa ohun ti araarẹ̀, a kìí mú un bínú.” (1 Korinti 13:​4-⁠7) Nípa mímú ìfẹ́ dàgbà, a lè fa owú tí o jẹ agbára ìsúnniṣe tí ó wà lẹ́yìn ẹ̀mí ìbánidíje tu. Àwọn èso ti ẹ̀mí yòókù ń ràn wá lọ́wọ́ pẹ̀lú láti fọ ràlẹ̀rálẹ̀ ẹ̀mí ìbáradíje, onírẹ́rùnrẹ́rùn, èyíkéyìí tí ó bá ṣẹ́kù kúrò nínú ọkàn àti àyà wa. Họ́wù, pẹ̀lú ìkóra-ẹni-níjàánu a kò ní pẹ́ borí ìsúnniṣe èyíkéyìí tí o lè mú kí a fẹ́ láti bá àwọn ẹlòmíràn díje kí á baà lè borí ní àforí-àfọrùn!​—⁠Owe 17:⁠27.

Bí ó ti wù kí ó rí, láti lè mú àwọn ànímọ́ wọ̀nyí dàgbà, a gbọ́dọ̀ yọ̀ǹda fún ẹ̀mí Ọlọrun láti ṣiṣẹ́ lórí wa. A lè gba ìṣiṣẹ́ akúnfúnlera ti ẹ̀mí mímọ́ yìí láyè nípa fíforítì nínú àdúrà àti bíbèèrè fún ẹ̀mí Ọlọrun láti ràn wá lọ́wọ́. (Luku 11:13) Ní ìdáhùn sí àdúrà wa, kí ni Ọlọrun yóò fifún wa? Bibeli dáhùn pé: “Ẹ máṣe àníyàn ohunkohun; ṣùgbọ́n nínú ohun gbogbo, nípa àdúrà àti ẹ̀bẹ̀ pẹ̀lú ìdúpẹ́, ẹ máa fi ìbéèrè yín hàn fún Ọlọrun. Àti àlàáfíà Ọlọrun, tí ó ju ìmọ̀ràn gbogbo lọ, yóò ṣọ́ ọkàn àti èrò yín nínú Kristi Jesu.”​—⁠Filippi 4:​6, 7.

Èyí ṣe kedere nínú ọ̀ràn ti àwọn aposteli Jesu. Kódà lẹ́yìn tí Jesu ti dá Oúnjẹ Alẹ́ Oluwa sílẹ̀ ní alẹ́ tí ó wà pẹ̀lú àwọn aposteli rẹ̀ kẹ́yìn, wọ́n ṣì ń jà síbẹ̀ lórí ta ni ó jẹ́ ẹni tí ó tóbilọ́lá jùlọ nínú wọn. (Luku 22:​24-⁠27) Jesu ti gbìyànjú ni àkókò mìíràn kan tí ó yàtọ̀ láti ràn wọ́n lọ́wọ́ láti yí ìrònú wọn padà, ṣùgbọ́n ìṣarasíhùwà ìbáradíje yìí ti di bárakú fún wọn. (Marku 9:34-⁠37; 10:35-⁠45; Johannu 13:​12-⁠17) Bí ó ti wù kí ó rí, gbàrà tí wọ́n ti gba ẹ̀mí mímọ́ ní nǹkan bí 50 ọjọ́ lẹ́yìn àríyànjiyàn yẹn, ìṣarasíhùwà wọn yípadà. Kò tún sí iyàn jíjà mọ́ lórí ẹni tí yóò ṣojú fún wọn láti bá àwùjọ àwọn ènìyàn tí wọn ń fẹ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ tí wọn kórajọ ní ọjọ́ Pentikosti sọ̀rọ̀.​—⁠Iṣe 2:​14-⁠21.

Kò sí àyè fún ènìyàn kan láti jẹgàba lórí ijọ Kristian ọ̀rúndún kìn-⁠ín-⁠ní. Nígbà tí wọ́n níláti yanjú ìṣòro kan lórí ìkọlà, Jakọbu, tí kìí tilẹ̀ ṣe ọmọ-ẹ̀yìn ní àkókò ikú Jesu, ni ó ṣalága ìpàdé pàtàkì náà. Kò sí àmì kankan nípa àríyànjiyàn lórí ta ni yóò mú ipò ìwájú nínú ìpàdé ti ẹgbẹ́ olùṣàkóso ìjọ Kristian yẹn. Ẹ wo bí èyí ti yàtọ̀ tó sí ti àkókò náà tí ànímọ́ búburú ti ẹ̀mí ìbáradíje wà lára àwọn aposteli! Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ ẹ̀mí mímọ́, wọ́n rántí àwọn ẹ̀kọ́ Jesu wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí lóye ìtumọ̀ àwọn ìtọ́ni rẹ̀.​—⁠Johannu 14:⁠26.

Ohun kan-náà lè jẹ́ òtítọ́ nípa tiwa. Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ ẹ̀mí mímọ́, a lè borí ìsúnniṣe èyíkéyìí tí ó bá ṣẹ́kù tí ń sún wa láti bá àwọn ẹlòmíràn díje kí a baà lè fi wọ́n ṣe àtẹ̀gùn ìtẹ̀síwájú. Dípò bẹ́ẹ̀, a lè jèrè àlàáfíà ọkàn tí ó ju ìmọ̀ràn gbogbo lọ. Bibeli mú kí ó dá wa lójú pé okùnfà ìbáradíje onírẹ́rùnrẹ́rùn, Satani Èṣù, ni a óò gbé sọ sínú ọ̀gbun, a óò sọ ọ́ di aláìlèṣiṣẹ́mọ́. (Ìfihàn 20:​1-⁠3) Ìfigagbága láàárín àwọn aládùúgbò kì yóò sí mọ́. Ìyọrísí náà yóò ha jẹ́ àwùjọ tí kì yóò ní ìtẹ̀síwájú èyíkéyìí bí? Kí a má rí! Àwọn ènìyàn yóò dàgbà dé ìjẹ́pípé, kìí ṣe nípasẹ̀ ìdíje èyíkéyìí láàárín araawọn, ṣùgbọ́n nípasẹ̀ ìfisílò ẹbọ ìràpadà Jesu fún wọn.​—⁠1 Johannu 2:​1, 2.

Keinosuke, tí a mẹ́nukàn ṣáájú, tí ó ti fìgbàkan rí nírìírí ògo àṣeyọrí ti ayé nípa títa iye ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ tí ó pọ̀ jùlọ, mú nǹkan sú araarẹ̀ níti èrò-orí àti ti ara, ṣùgbọ́n ó fi iṣẹ́ rẹ̀ sílẹ̀ níkẹyìn. “Nísinsìnyí, ìgbésí-ayé mi kún fún ayọ̀ tòótọ́,” ni òun sọ. Ó wá rí ìdí tí àṣeyọrísírere tòótọ́ fi sàmìsí ìgbésí-ayé Jesu. Ó rí ìtẹ́lọ́rùn nísinsìnyí nínú gbogbo ohun tí ó lè ṣe nínú ìjọ Ọlọrun kárí-ayé. A ń tipa báyìí múra rẹ̀ sílẹ̀ fún ayé titun náà, tí kì yóò ní ìdíje nínú. Ìwọ pẹ̀lú lè rí àrítẹ́lẹ̀ ẹgbẹ́ ayé titun yìí nípa ṣíṣèbẹ̀wò sí ọ̀kan lára àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba tí ó wà ní àdúgbò rẹ àti dídarapọ̀ pẹ̀lú àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

Àwùjọ ẹ̀dá ènìyàn yóò gbádùn àlàáfíà ati ìfọwọ́sowọ́pọ̀ nínú ayé titun ti Ọlọrun

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́