ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w07 7/15 ojú ìwé 21-25
  • Ṣé ẹ Óò Máa Bá a Lọ Láti “Rìn Nípa Ẹ̀mí”?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ṣé ẹ Óò Máa Bá a Lọ Láti “Rìn Nípa Ẹ̀mí”?
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Sún Mọ́ Ọlọ́run àti Kristi Tímọ́tímọ́
  • Ẹ ‘Máa Nífẹ̀ẹ́ Ara Yín Lẹ́nì Kìíní-Kejì’
  • “Ìdùnnú Jèhófà Ni Odi Agbára Yín”
  • Jẹ́ Ẹlẹ́mìí Àlàáfíà àti Onípamọ́ra
  • Jẹ́ Onínú Rere àti Oníwà Rere
  • “Ìgbàgbọ́ Láìsí Àgàbàgebè”
  • Jẹ́ Ẹni Tó Ní Ìwà Tútù àti Ìkóra-ẹni-níjàánu
  • Máa Bá A Lọ Láti Rìn Nípa Ẹ̀mí
  • Ṣé Ò Ń jẹ́ Kí Ẹ̀mí Ọlọ́run Máa Darí rẹ?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2011
  • Bí Ẹ̀mí Ọlọrun Ṣe Lè Nípalórí Rẹ
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Máa Rìn Nípa Ẹ̀mí Kó O Sì Mú Ẹ̀jẹ́ Ìyàsímímọ́ Rẹ Ṣẹ
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2010
  • Ẹmi Jehofa Ń Darí Awọn Eniyan Rẹ̀
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
w07 7/15 ojú ìwé 21-25

Ṣé ẹ Óò Máa Bá a Lọ Láti “Rìn Nípa Ẹ̀mí”?

“Ẹ máa rìn nípa ẹ̀mí, ẹ kì yóò sì ṣe ìfẹ́-ọkàn ti ẹran ara rárá.”—GÁLÁTÍÀ 5:16.

1. Kí lèèyàn lè ṣe tí ìbẹ̀rù pé òun lè lọ ṣẹ̀ sí ẹ̀mí mímọ́ ò fi ní gbà á lọ́kàn?

NǸKAN kan wà téèyàn lè ṣe tí ìbẹ̀rù pé òun lè lọ ṣẹ̀ sí ẹ̀mí mímọ́ ò fi ní gbà á lọ́kàn. Òun ni pé kéèyàn ṣe ohun tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ. Ó ní: “Ẹ máa rìn nípa ẹ̀mí, ẹ kì yóò sì ṣe ìfẹ́-ọkàn ti ẹran ara rárá.” (Gálátíà 5:16) Tá a bá jẹ́ kí ẹ̀mí Ọlọ́run máa darí wa, ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara ò ní borí wa.—Róòmù 8:2-10.

2, 3. Bá a bá ń rìn nípa ẹ̀mí, ipa wo ni yóò ní lórí wa?

2 Bá a bá ń “rìn nípa ẹ̀mí,” ìyẹn ni pé ká jẹ́ kí ẹ̀mí mímọ́ tí í ṣe agbára ìṣiṣẹ́ Ọlọ́run máa darí wa, ẹ̀mí náà yóò mú ká lè máa ṣègbọràn sí Jèhófà. A óò máa fìwà jọ Ọlọ́run tá a bá wà lóde ẹ̀rí, nínú ìjọ, lọ́ọ̀dẹ̀ ilé wa àti níbi gbogbo. Yóò máa hàn nínú àjọṣe wa pẹ̀lú ọkọ wa, aya wa, àwọn ọmọ wa, àwọn onígbàgbọ́ bíi tiwa àtàwọn ẹlòmíì pé ẹ̀mí Ọlọ́run ń darí wa.

3 Tá a bá ń gbé ìgbé ayé wa bí ẹni tó “wà láàyè ní ti ẹ̀mí ní ojú ìwòye Ọlọ́run,” àá lè jáwọ́ nínú ìwà ẹ̀ṣẹ̀. (1 Pétérù 4:1-6) Bí ẹ̀mí Ọlọ́run bá sì ń darí wa, ó dájú pé a ò ní dá ẹ̀ṣẹ̀ tí kò ní ìdáríjì. Àwọn ọ̀nà míì wo la ó ti jàǹfààní bá a bá ń jẹ́ kí ẹ̀mí Ọlọ́run máa darí wa?

Sún Mọ́ Ọlọ́run àti Kristi Tímọ́tímọ́

4, 5. Irú ojú wo la fi ń wo Jésù nítorí jíjẹ́ tá à ń jẹ́ kí ẹ̀mí mímọ́ máa darí wa?

4 Jíjẹ́ tá a jẹ́ kí ẹ̀mí mímọ́ máa darí wa la fi lè ní àjọṣe tó dán mọ́rán pẹ̀lú Ọlọ́run àti Ọmọ rẹ̀. Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń kọ̀wé nípa àwọn ẹ̀bùn ẹ̀mí, ó sọ fáwọn onígbàgbọ́ bíi tiẹ̀ nílùú Kọ́ríńtì pé: “Èmi yóò mú kí ẹ [ìyẹn àwọn tó ti jẹ́ abọ̀rìṣà tẹ́lẹ̀ rí] mọ̀ pé kò sí ẹnì kankan nígbà tí ó bá ń fi ẹ̀mí Ọlọ́run sọ̀rọ̀ tí ń wí pé: ‘Ẹni ègún ni Jésù!’ kò sì sí ẹnì kankan tí ó lè wí pé: ‘Jésù ni Olúwa!’ bí kò ṣe nípasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́.” (1 Kọ́ríńtì 12:1-3) Tí ẹ̀mí kan bá fi lè máa mú káwọn èèyàn fi Jésù gégùn-ún, dájúdájú, ọ̀dọ̀ Sátánì Èṣù lẹ̀mí náà ti wá. Ṣùgbọ́n ní tàwa Kristẹni tí ẹ̀mí mímọ́ ń darí, ó dá wa lójú pé Jèhófà jí Jésù dìde ó sì gbé e ga ju gbogbo ẹ̀dá yòókù lọ. (Fílípì 2:5-11) A nígbàgbọ́ nínú ẹbọ ìràpadà Kristi a sì gbà pé Ọlọ́run ti fi Jésù jẹ Olúwa wa.

5 Àwọn Kristẹni aláfẹnujẹ́ kan ní ọ̀rúndún kìíní Sànmánì Kristẹni kò gbà pé Jésù wá sáyé nínú ẹran ara. (2 Jòhánù 7-11) Ẹ̀kọ́kẹ́kọ̀ọ́ yìí sì mú kí àwọn tó tẹ́wọ́ gbà á kẹ̀yìn sí ẹ̀kọ́ òtítọ́ nípa Jésù tí í ṣe Mèsáyà. (Máàkù 1:9-11; Jòhánù 1:1, 14) Tá a bá ń jẹ́ kí ẹ̀mí mímọ́ máa darí wa, a ò ní gba irú ẹ̀kọ́ àwọn apẹ̀yìndà bẹ́ẹ̀ láyè. Bá a bá ń fiyè sí ẹ̀kọ́ òtítọ́ tó wà nínú Bíbélì nìkan la fi lè máa rí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí gbà lọ́dọ̀ Jèhófà, tá a ó sì máa “bá a lọ ní rírìn nínú òtítọ́.” (3 Jòhánù 3, 4) Nítorí náà, ńṣe ni ká rí i dájú pé a ò gba ìpẹ̀yìndà èyíkéyìí láyè rárá kí àjọṣe tímọ́tímọ́ tó wà láàárín àwa àti Baba wa ọ̀run mà bàa bà jẹ́.

6. Àwọn ànímọ́ wo ni ẹ̀mí Ọlọ́run máa ń mú káwọn tó bá gbà á láyè láti máa darí àwọn nínú ohun gbogbo ní?

6 Pọ́ọ̀lù ka ẹ̀ya ìsìn àti ìbọ̀rìṣà tó ń sọni di apẹ̀yìndà mọ́ “àwọn iṣẹ́ ti ara” bí àgbèrè àti ìwà àìníjàánu. Ṣùgbọ́n ó ṣàlàyé pé: “Àwọn tí ó jẹ́ ti Kristi Jésù kan ẹran ara mọ́gi pa pọ̀ pẹ̀lú ìfẹ́ onígbòónára àti ìfẹ́-ọkàn rẹ̀. Bí a bá wà láàyè nípa ẹ̀mí, ẹ jẹ́ kí a máa rìn létòletò nípa ẹ̀mí pẹ̀lú.” (Gálátíà 5:19-21, 24, 25) Àwọn ànímọ́ wo ni ẹ̀mí Ọlọ́run máa ń mú káwọn tó bá gbà á láyè láti máa darí àwọn nínú ohun gbogbo ní? Àwọn ni Pọ́ọ̀lù mẹ́nu kàn, pé: “Èso ti ẹ̀mí ni ìfẹ́, ìdùnnú, àlàáfíà, ìpamọ́ra, inú rere, ìwà rere, ìgbàgbọ́, ìwà tútù, ìkóra-ẹni-níjàánu.” (Gálátíà 5:22, 23) Ẹ jẹ́ ká gbé àwọn apá tí èso tẹ̀mí pín sí yìí yẹ̀ wò lọ́kọ̀ọ̀kan.

Ẹ ‘Máa Nífẹ̀ẹ́ Ara Yín Lẹ́nì Kìíní-Kejì’

7. Kí ni ìfẹ́, kí sì ni díẹ̀ lára àwọn ohun tó máa ń ṣe àtàwọn ohun tí kì í ṣe?

7 Ìfẹ́, tó jẹ́ apá kan èso ti ẹ̀mí, ni ànímọ́ tó ń mú ká nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn tọkàntọkàn, ká máa ṣaájò wọn tinútinú ká sì sún mọ́ wọn tímọ́tímọ́. Ìwé Mímọ́ sọ pé “Ọlọ́run jẹ́ ìfẹ́” nítorí pé òun lẹni tó nífẹ̀ẹ́ jù láyé àtọ̀run. Ọ̀nà kan tí Ọlọ́run àti Ọmọ rẹ̀ gbà fi ìfẹ́ ńlá wọn hàn sí aráyé ni ẹbọ ìràpadà Jésù Kristi. (1 Jòhánù 4:8; Jòhánù 3:16; 15:13; Róòmù 5:8) Ní ti àwa tá a jẹ́ ọmọlẹ́yìn Jésù, ìfẹ́ tá a ní sí ara wa ló ń fi wá hàn yàtọ̀. (Jòhánù 13:34, 35) Ńṣe ni Bíbélì tiẹ̀ pa á láṣẹ fún wa pé ká “máa nífẹ̀ẹ́ ara wa lẹ́nì kìíní-kejì.” (1 Jòhánù 3:23) Pọ́ọ̀lù sì sọ pé ṣe ni ìfẹ́ máa ń ní ìpamọ́ra àti inú rere. Kì í jowú, kì í fọ́nnu, kì í hùwà lọ́nà tí kò bójú mu, kì í sì í wá àwọn ire tirẹ̀ nìkan. A kì í tán ìfẹ́ ní sùúrù, kì í sì í kọ àkọsílẹ̀ ìṣeniléṣe. Ó máa ń yọ̀ lórí òtítọ́, kì í yọ̀ lórí àìṣòdodo. Ìfẹ́ máa ń mú ohun gbogbo mọ́ra, ó ń gba ohun gbogbo gbọ́, ó ń retí ohun gbogbo, ó sì ń fara da ohun gbogbo. Ju gbogbo rẹ̀ lọ, ìfẹ́ kì í kùnà láé.—1 Kọ́ríńtì 13:4-8.

8. Kí nìdí tá a fi ní láti nífẹ̀ẹ́ àwọn ará wa tá a jọ ń sin Jèhófà?

8 Bá a bá jẹ́ kí ẹ̀mí Ọlọ́run gbin ìfẹ́ sí wa lọ́kàn, ìfẹ́ yìí yóò máa hàn nínú àjọṣe wa pẹ̀lú Ọlọ́run àti ọmọnìkejì wa. (Mátíù 22:37-39) Àpọ́sítélì Jòhánù sọ pé: “Ẹni tí kò nífẹ̀ẹ́ dúró nínú ikú. Olúkúlùkù ẹni tí ó bá kórìíra arákùnrin rẹ̀ jẹ́ apànìyàn, ẹ̀yin sì mọ̀ pé kò sí apànìyàn kankan tí ìyè àìnípẹ̀kun dúró nínú rẹ̀.” (1 Jòhánù 3:14, 15) Nílẹ̀ Ísírẹ́lì ayé àtijọ́, tẹ́nì kan tó pààyàn bá ti lẹ́mìí ìkórìíra sẹ́ni náà tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀, kò lè ráyè forí pa mọ́ sí ìlú ààbò. (Diutarónómì 19:4, 11-13) Tí ẹ̀mí mímọ́ bá ń darí wa, a óò nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run, a óò nífẹ̀ẹ́ àwọn ará wa tá a jọ ń sin Ọlọ́run àtàwọn ẹlòmíì.

“Ìdùnnú Jèhófà Ni Odi Agbára Yín”

9, 10. Kí ni ìdùnnú jẹ́, kí sì làwọn ìdí tó fi yẹ kínú wa máa dùn?

9 Ìdùnnú jẹ́ ayọ̀ àtọkànwá. Jèhófà ni “Ọlọ́run aláyọ̀.” (1 Tímótì 1:11; Sáàmù 104:31) Inú Jésù Ọmọ rẹ̀ sì máa ń dùn láti ṣe ìfẹ́ rẹ̀. (Sáàmù 40:8; Hébérù 10:7-9) Àwa náà sì rèé, “ìdùnnú Jèhófà ni odi agbára [wa].”—Nehemáyà 8:10.

10 Ìdùnnú tí Ọlọ́run ń fúnni máa ń jẹ́ ká ní ìbàlẹ̀-ọkàn bá a ṣe ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run, àní nígbà ìnira, nígbà ọ̀fọ̀ tàbí inúnibíni pàápàá. Téèyàn bá sì ní “ìmọ̀ Ọlọ́run gan-an,” ayọ̀ rẹ̀ máa ń pọ̀ jọjọ! (Òwe 2:1-5) Ìmọ̀ pípéye àti ìgbàgbọ́ tá a ní nínú Ọlọ́run àti nínú ẹbọ ìràpadà Jésù ló jẹ́ ká lè ní àjọṣe pẹ̀lú Ọlọ́run, èyí tó ń fún wa láyọ̀. (1 Jòhánù 2:1, 2) Nǹkan míì tó tún ń múnú wa dùn ni pé a jẹ́ ara ojúlówó ẹgbẹ́ ará tòótọ́ kan ṣoṣo náà tó kárí ayé. (Sefanáyà 3:9; Hágáì 2:7) Ìjọba Ọlọ́run tá à ń retí àti àǹfààní tá a ní láti máa polongo ìhìn rere ń múnú wa dùn. (Mátíù 6:9, 10; 24:14) Ìrètí ìyè àìnípẹ̀kun tá a ní náà tún ń múnú wa dùn. (Jòhánù 17:3) Pẹ̀lú àwọn ohun àgbàyanu tá à ń retí yìí, ńṣe ló yẹ ká máa fìgbà gbogbo “kún fún ìdùnnú” lóòótọ́.—Diutarónómì 16:15.

Jẹ́ Ẹlẹ́mìí Àlàáfíà àti Onípamọ́ra

11, 12. (a) Ṣàlàyé ohun tí àlàáfíà jẹ́. (b) Ipa wo ni àlàáfíà Ọlọ́run ń ní lórí wa?

11 Àlàáfíà jẹ́ apá míì lára èso ti ẹ̀mí. Àlàáfíà yìí sì ni pé kéèyàn wà nípò tí ọkàn rẹ̀ fi balẹ̀ pẹ̀sẹ̀ láìsí pé ó ń ṣàníyàn rárá. Baba wa ọ̀run jẹ́ Ọlọ́run àlàáfíà, Bíbélì sì mú un dá wa lójú pé: “Jèhófà tìkára rẹ̀ yóò fi àlàáfíà bù kún àwọn ènìyàn rẹ̀.” (Sáàmù 29:11; 1 Kọ́ríńtì 14:33) Jésù sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Mo fi àlàáfíà sílẹ̀ fún yín, mo fi àlàáfíà mi fún yín.” (Jòhánù 14:27) Ìrànlọ́wọ́ wo lèyí máa ṣe fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀?

12 Àlàáfíà tí Jésù fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ń mú kí ara tù wọ́n, kí ọkàn wọn balẹ̀ pẹ̀sẹ̀, kí àníyàn wọn sì dín kù. Nígbà tí wọ́n sì gba ẹ̀mí mímọ́ tí Jésù ṣèlérí fún wọn, àlàáfíà yẹn túbọ̀ wá pọ̀ sí i. (Jòhánù 14:26) Lóde òní bákan náà, a ní “àlàáfíà Ọlọ́run” tí kò láfiwé nítorí pé ẹ̀mí Ọlọ́run ń darí wa àti pé Ọlọ́run ń gbọ́ àdúrà wa. Àlàáfíà Ọlọ́run yìí máa ń jẹ́ kí ara tù wá kí ọkàn wa sì balẹ̀ pẹ̀sẹ̀. (Fílípì 4:6, 7) Ìyẹn nìkan kọ́, ẹ̀mí Jèhófà ń jẹ́ ká lè máa fi sùúrù àti ẹ̀mí àlàáfíà bá àwọn ará wa àtàwọn ẹlòmíì lò.—Róòmù 12:18; 1 Tẹsalóníkà 5:13.

13, 14. Kí ni ìpamọ́ra jẹ́, kí sì nìdí tó fi yẹ ká ní in?

13 Ìpamọ́ra ò fi bẹ́ẹ̀ yàtọ̀ sí níní ẹ̀mí àlàáfíà, torí ìpamọ́ra ni pé kéèyàn máa fi ẹ̀mí sùúrù fara da ohun tó lè bíni nínú tàbí àìdáa tí wọ́n ṣe síni, pẹ̀lú ìrètí pé àyípadà máa wà. Ọlọ́run jẹ́ onípamọ́ra. (Róòmù 9:22-24) Jésù náà ní ìpamọ́ra. Àwa náà lè jàǹfààní níní tí Jésù ní ànímọ́ yìí, torí Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Ìdí tí a fi fi àánú hàn sí mi ni pé nípasẹ̀ mi gẹ́gẹ́ bí ọ̀ràn àkọ́kọ́, kí Kristi Jésù lè fi gbogbo ìpamọ́ra rẹ̀ hàn gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ kan lára àwọn tí yóò gbé ìgbàgbọ́ wọn lé e fún ìyè àìnípẹ̀kun.”—1 Tímótì 1:16.

14 Ẹ̀mí ìpamọ́ra kì í jẹ́ ká gbaná jẹ nígbà táwọn èèyàn bá sọ̀rọ̀ tí ò dáa sí wa tàbí tí wọ́n ṣàìdáa sí wa. Pọ́ọ̀lù rọ àwọn Kristẹni bíi tiẹ̀ pé: “Ẹ máa ní ìpamọ́ra fún gbogbo ènìyàn.” (1 Tẹsalóníkà 5:14) Níwọ̀n bí gbogbo wa ti jẹ́ aláìpé tó ń ṣàṣìṣe, ó dájú pé a máa ń fẹ́ káwọn èèyàn ṣe sùúrù fún wa, kí wọ́n lo ìpamọ́ra tá a bá ṣẹ̀ wọ́n. Ó wá yẹ káwa náà rí i dájú pé à ń lo “ìpamọ́ra pẹ̀lú ìdùnnú.”—Kólósè 1:9-12.

Jẹ́ Onínú Rere àti Oníwà Rere

15. Ṣàlàyé ohun tí inú rere jẹ́, kó o sì mú àwọn àpẹẹrẹ wa.

15 Inú rere ni pé kéèyàn ṣaájò ọmọnìkejì rẹ̀, nípa sísọ̀rọ̀ tó máa ṣe é láǹfààní tàbí tó máa ràn án lọ́wọ́. Onínúure ni Jèhófà, bẹ́ẹ̀ náà sì ni Ọmọ rẹ̀. (Róòmù 2:4; 2 Kọ́ríńtì 10:1) Gbogbo ìránṣẹ́ Ọlọ́run àti Kristi ló gbọ́dọ̀ jẹ́ onínúure. (Míkà 6:8; Kólósè 3:12) Kódà nígbà kan rí, àwọn kan tí kì í ṣe olùjọsìn Ọlọ́run pàápàá “fi àrà ọ̀tọ̀ inú rere ẹ̀dá ènìyàn hàn.” (Ìṣe 27:3; 28:2) Nítorí náà, ó dájú pé a óò jẹ́ onínúure tá a bá ń “rìn nípa ẹ̀mí.”

16. Mẹ́nu kan díẹ̀ nínú àwọn ipò tó ti yẹ ká rí i pé a fi inú rere hàn.

16 A lè fi inú rere hàn síni, àní títí kan ìgbà tẹ́nì kan bá ṣe ohun tó ń bí wa nínú, bóyá ó sọ ọ̀rọ̀ tí ò dáa sí wa tàbí ó hùwà àìgbatẹnirò sí wa. Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Ẹ fi ìrunú hàn, síbẹ̀ kí ẹ má ṣẹ̀; ẹ má ṣe jẹ́ kí oòrùn wọ̀ bá yín nínú ipò ìbínú, bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ má ṣe fi àyè sílẹ̀ fún Èṣù. . . . Ẹ di onínúrere sí ara yín lẹ́nì kìíní-kejì, ní fífi ìyọ́nú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ hàn, kí ẹ máa dárí ji ara yín fàlàlà gan-an gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run pẹ̀lú ti tipasẹ̀ Kristi dárí jì yín fàlàlà.” (Éfésù 4:26, 27, 32) Ó tún wá ṣe pàtàkì gan-an pé ká máa ṣe inú rere sáwọn tó wà nínú ìṣòro. Àmọ́ ṣá o, tí ẹnì kan bá ń rìn ní bèbè ohun tó lè mú kó ṣubú kúrò lọ́nà “ohun rere àti òdodo àti òtítọ́,” síbẹ̀ tí alàgbà kan dákẹ́ tí kò fi ohun tí Bíbélì wí kìlọ̀ fẹ́ni náà torí kó máa bàa bínú, ìyẹn kì í ṣe inúure.—Éfésù 5:9.

17, 18. Kí ni ìwà rere jẹ́, ipa wo ló sì yẹ kí ó kó nígbèésí ayé wa?

17 Ìwà rere ni pé kéèyàn ní ìwà funfun, kó ní ìwà tó dára gan-an tàbí kó jẹ́ni rere. Ọlọ́run ló jẹ́ ẹni rere jù lọ. (Sáàmù 25:8; Sekaráyà 9:17) Jésù jẹ́ oníwà funfun, ìwà rẹ̀ dára gan-an ni. Síbẹ̀, nígbà tẹ́nì kan pè é ní “Olùkọ́ Rere,” kò fara mọ́ lílò tó lo ọ̀rọ̀ náà “Rere” fóun gẹ́gẹ́ bí orúkọ. (Máàkù 10:17, 18) Ìdí rẹ̀ sì ni pé ó mọ̀ pé Ọlọ́run lẹni rere jù lọ.

18 Ẹ̀ṣẹ̀ tá a ti jogún kì í jẹ́ ká lè máa ṣe rere bá a ṣe fẹ́. (Róòmù 5:12) Síbẹ̀, a ṣì lè jẹ́ ẹni rere tá a bá bẹ Ọlọ́run pé kó ‘kọ́ wa ní ìwà rere.’ (Sáàmù 119:66) Pọ́ọ̀lù sọ fáwọn onígbàgbọ́ bíi tiẹ̀ tó wà nílùú Róòmù pé: “Èmi fúnra mi pẹ̀lú gbà nípa yín, ẹ̀yin ará mi, pé ẹ̀yin fúnra yín kún fún ìwà rere pẹ̀lú, gẹ́gẹ́ bí ẹ ti kún fún ìmọ̀ gbogbo.” (Róòmù 15:14) Àwọn alábòójútó nínú ìjọ gbọ́dọ̀ jẹ́ “olùfẹ́ ohun rere.” (Títù 1:7, 8) Bí ẹ̀mí Ọlọ́run bá ń darí wa, a óò jẹ́ni táwọn èèyàn mọ̀ sí ẹni tó ń ṣe rere, Jèhófà yóò sì ‘rántí wa fún rere tá à ń ṣe.’—Nehemáyà 5:19; 13:31.

“Ìgbàgbọ́ Láìsí Àgàbàgebè”

19. Sọ ohun tí ìgbàgbọ́ jẹ́ gẹ́gẹ́ bí Hébérù 11:1 ṣe fi yé wa.

19 Ìgbàgbọ́ náà jẹ́ apá míì lára èso ti ẹ̀mí. Ìgbàgbọ́ yìí ni “ìfojúsọ́nà tí ó dáni lójú nípa àwọn ohun tí a ń retí, ìfihàn gbangba-gbàǹgbà àwọn ohun gidi bí a kò tilẹ̀ rí wọn.” (Hébérù 11:1) Tá a bá nígbàgbọ́, yóò dá wa lójú hán-únhán-ún pé gbogbo ohun tí Jèhófà ṣèlérí pátápátá ló máa ṣẹ. Ẹ̀rí tó dájú tó wà nípa àwọn ohun gidi tá ò fojú rí lágbára débi pé ẹsẹ Bíbélì yìí ka ẹ̀rí náà àti ìgbàgbọ́ sí nǹkan kan náà. Bí àpẹẹrẹ, rírí tá à ń rí àwọn ohun tí Ọlọ́run dá jẹ́ kó dá wa lójú pé Ẹlẹ́dàá wà. Irú ìgbàgbọ́ tá a máa ní nìyẹn tá a bá jẹ́ kí ẹ̀mí Ọlọ́run máa darí wa.

20. Kí ni “ẹ̀ṣẹ̀ tí ó máa ń wé mọ́ wa pẹ̀lú ìrọ̀rùn,” kí ni yóò sì jẹ́ ká lè yẹra fún ẹ̀ṣẹ̀ náà àtàwọn iṣẹ́ ti ara?

20 Bíbélì sọ pé àìnígbàgbọ́ jẹ́ “ẹ̀ṣẹ̀ tí ó máa ń wé mọ́ wa pẹ̀lú ìrọ̀rùn.” (Hébérù 12:1) A gbọ́dọ̀ gbára lé ẹ̀mí Ọlọ́run láti lè yẹra fáwọn iṣẹ́ ti ara, ìfẹ́ ọrọ̀ àtàwọn ẹ̀kọ́ èké tó ń ri ọkọ̀ ìgbàgbọ́ ẹni. (Kólósè 2:8; 1 Tímótì 6:9, 10; 2 Tímótì 4:3-5) Ẹ̀mí Ọlọ́run máa ń jẹ́ káwọn ìránṣẹ́ Jèhófà tòde òní lè ní ìgbàgbọ́ bíi táwọn ẹlẹ́rìí tó ti wà ṣáájú ìgbà Kristẹni àtàwọn míì tí Bíbélì mẹ́nu kàn. (Hébérù 11:2-40) Tá a bá sì ní “ìgbàgbọ́ láìsí àgàbàgebè,” ìgbàgbọ́ wa lè fún ìgbàgbọ́ àwọn míì lágbára.—1 Tímótì 1:5; Hébérù 13:7.

Jẹ́ Ẹni Tó Ní Ìwà Tútù àti Ìkóra-ẹni-níjàánu

21, 22. Kí ni ìwà tútù, kí sì nìdí tó fi yẹ ká jẹ́ oníwà tútù?

21 Ìwà tútù ni pé ká jẹ́ onínú tútù àti oníwà pẹ̀lẹ́. Inú tútù jẹ́ ara ànímọ́ Ọlọ́run. A mọ̀ bẹ́ẹ̀ nítorí pé Jésù, tó jẹ́ni tó fìwà jọ Jèhófà pátápátá, jẹ́ onínú tútù. (Mátíù 11:28-30; Jòhánù 1:18; 5:19) Kí ni Ọlọ́run sì fẹ́ káwa ìránṣẹ́ rẹ̀ ṣe?

22 Ọlọ́run fẹ́ kí àwa Kristẹni jẹ́ ẹni tó ń ‘fi ìwà tútù hàn sí ènìyàn gbogbo.’ (Títù 3:2) Inú tútù la fi ń ṣe iṣẹ́ ìwàásù wa. Bíbélì sọ pé káwọn tó kúnjú òṣùwọ̀n nípa tẹ̀mí máa fi “ẹ̀mí ìwà tútù” tọ́ àwọn Kristẹni tó bá hùwà àìtọ́ sọ́nà. (Gálátíà 6:1) Gbogbo àwa Kristẹni pátá la lè jẹ́ kí ẹ̀mí ìṣọ̀kan àti àlàáfíà jọba láàárín wa nípa jíjẹ́ ẹni tó ní ‘ìrẹ̀lẹ̀ ti èrò inú àti ìwà tútù.’ (Éfésù 4:1-3) Bá a sì ṣe lè jẹ́ oníwà tútù yìí ni pé ká jẹ́ kí ẹ̀mí Ọlọ́run máa darí wa ká sì máa lo ìkóra-ẹni-níjàánu.

23, 24. Kí ni ìkóra-ẹni-níjàánu, ìrànlọ́wọ́ wo ló sì máa ń ṣe fún wa?

23 Ìkóra-ẹni-níjàánu ni pé kéèyàn lè ṣàkóso ara rẹ̀ láti má ro èròkérò, láti má sọ̀rọ̀ tí ò dáa tàbí láti má ṣe ohun tí kò tọ́. Jèhófà “lo ìkóra-ẹni-níjàánu” fúngbà pípẹ́ fáwọn ará Bábílónì tó pa Jerúsálẹ́mù run. (Aísáyà 42:14) Ọmọ rẹ̀ ‘fi àwòkọ́ṣe sílẹ̀ fún wa’ bó ṣe lo ìkóra-ẹni-níjàánu nígbà tó ń jẹ onírúurú ìyà láyé. Àpọ́sítélì Pétérù sì gba àwọn Kristẹni bíi tirẹ̀ níyànjú pé kí wọ́n fi “ìkóra-ẹni-níjàánu kún ìmọ̀” wọn.—1 Pétérù 2:21-23; 2 Pétérù 1:5-8.

24 Alàgbà ìjọ gbọ́dọ̀ jẹ́ ẹni tí ń kó ara rẹ̀ níjàánu. (Títù 1:7, 8) Ká sòótọ́, gbogbo ẹni tí ẹ̀mí mímọ́ bá ń darí ló yẹ kó máa lo ìkóra-ẹni-níjàánu, kí wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ yẹra fún ìṣekúṣe, fún sísọ ọ̀rọ̀ rírùn tàbí fún ṣíṣe ohunkóhun tí Jèhófà ò fẹ́. Tá a bá jẹ́ kí ẹ̀mí Ọlọ́run sọ wá dẹni tó ní ìkóra-ẹni-níjàánu, yóò hàn nínú ọ̀rọ̀ wa àti ìwà wa.

Máa Bá A Lọ Láti Rìn Nípa Ẹ̀mí

25, 26. Tá a bá ń rìn nípa ẹ̀mí, ipa wo ló máa ní lórí àjọṣe wa pẹ̀lú àwọn èèyàn nísinsìnyí, ipa wo ló sì máa ní lórí ìrètí wa ọjọ́ ọ̀la?

25 Tá a bá ń rìn nípa ẹ̀mí, ìyẹn ni pé tá à ń jẹ́ kí ẹ̀mí Ọlọ́run máa darí wa, a óò jẹ́ni tó ń fìtara polongo Ìjọba Ọlọ́run. (Ìṣe 18:24-26) A óò dẹni tó dùn-ún bá rìn. Ní pàtàkì jù lọ, àwọn olùbẹ̀rù Ọlọ́run yóò máa rìn mọ́ wa dáadáa. Níwọ̀n bí ẹ̀mí mímọ́ sì ti ń ṣamọ̀nà wa, àá tún lè máa fún àwọn olùjọsìn Jèhófà bíi tiwa níṣìírí kí wọ́n máa rìn nípa ẹ̀mí Ọlọ́run. (Fílípì 2:1-4) Irú èèyàn bẹ́ẹ̀ ni gbogbo àwa Kristẹni sì fẹ́ jẹ́, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́?

26 Nínú ayé tí Sátánì ń darí yìí, kò rọrùn rárá láti máa rìn nípa ẹ̀mí. (1 Jòhánù 5:19) Síbẹ̀, ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn ló ń ṣe bẹ́ẹ̀ lónìí. Tá a bá fi gbogbo ọkàn wa gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, a óò gbádùn ìgbésí ayé wa nísinsìnyí, a ó sì tún lè máa rìn títí ayé nínú àwọn ọ̀nà òdodo Ọlọ́run, Ẹni tó ń fúnni ní ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ tìfẹ́tìfẹ́.—Sáàmù 128:1; Òwe 3:5, 6.

Báwo Lo Ṣe Máa Dáhùn?

• Tá a bá ń “rìn nípa ẹ̀mí,” ipa wo ló máa ní lórí àjọṣe wa pẹ̀lú Ọlọ́run àti Ọmọ rẹ̀?

• Kí làwọn ànímọ́ tó para pọ̀ jẹ́ èso ti ẹ̀mí?

• Àwọn ọ̀nà wo lèèyàn lè gbà lo èso ẹ̀mí Ọlọ́run?

• Tá a bá ń rìn nípa ẹ̀mí, ipa wo ló máa ní lórí ìgbésí ayé wa ìsinsìnyí àtohun tá à ń retí lọ́jọ́ ọ̀la?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

Ẹ̀mí Jèhófà máa ń mú ká lè nífẹ̀ẹ́ àwọn ará

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]

Máa fi inú rere hàn nípa sísọ̀rọ̀ tàbí ṣíṣe nǹkan tó máa ṣe ọmọnìkejì rẹ láǹfààní

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́