Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
Nígbà tí àwọn ọmọ-ogun Saulu jẹ ẹran tẹ̀jẹ̀tẹ̀jẹ̀, èéṣe tí a kò fìyà ikú jẹ wọ́n, níwọ̀n bí ó ti jẹ́ pé ìjìyà tí a filélẹ̀ nínú Òfin Ọlọrun nìyẹn?
Àwọn ọkùnrin wọ̀nyí nítòótọ́ rú òfin Ọlọrun lórí ẹ̀jẹ̀, ṣùgbọ́n a ti lè fi àánú hàn sí wọ́n nítorí pé wọ́n ní ọ̀wọ̀ fún ẹ̀jẹ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn ìbá ti túbọ̀ jẹ́ aláápọn nínú fífi irú ọ̀wọ̀ bẹ́ẹ̀ hàn.
Gbé ipò-ọ̀ràn náà yẹ̀wò. Àwọn ọmọ Israeli lábẹ́ Ọba Saulu àti ọmọkùnrin rẹ̀ Jonatani ń jagun pẹ̀lú àwọn Filistini. Nígbà tí ó ṣe ‘àwọn ọkùnrin Israeli rí ìpọ́njú’ lójú ogun, Saulu fi ìwàǹwára jẹ́jẹ̀ẹ́ pé àwọn ọkùnrin òun kò níláti jẹun títí tí wọn yóò fi ṣẹ́gun ọ̀tá. (1 Samueli 14:24) Láìpẹ́ ẹ̀jẹ́ rẹ̀ dá wàhálà sílẹ̀.
Àwọn ọkùnrin rẹ̀ ń ṣẹ́gun nínú ogun kan tí wọ́n ń fi agbára kíkankíkan jà, ṣùgbọ́n ìsapá atánnilókun náà ṣe ìpalára tirẹ̀. Wọ́n jìyà lọ́wọ́ ebi ó sì rẹ̀ wọ́n pátápátá. Kí ni wọ́n ṣe lábẹ́ ipò lílégbákan bẹ́ẹ̀? “Àwọn ènìyàn sáré sí ìkógun náà, wọ́n sì mú àgùtàn, àti màlúù, àti ọmọ-màlúù, wọ́n sì pa wọ́n sórí ilẹ̀: àwọn ènìyàn náà sì jẹ wọ́n tẹ̀jẹ̀tẹ̀jẹ̀.”—1 Samueli 14:32.
Ìyẹn jẹ́ ní rírú òfin Ọlọrun nípa ẹ̀jẹ̀, níwọ̀n bí àwọn kan nínú àwọn ènìyàn Saulu tí sọ fún un, ní wíwí pé: “Kíyèsí i, àwọn ènìyàn náà dẹ́ṣẹ̀ sí Oluwa, ní èyí tí wọ́n jẹ ẹ̀jẹ̀.” (1 Samueli 14:33) Bẹ́ẹ̀ni, Òfin wí pé nígbà tí a bá dúḿbú àwọn ẹran, ẹ̀jẹ̀ náà ni a gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ó ro kí a tó jẹ ẹran náà. Ọlọrun kò fi dandangbọ̀n béèrè pé kí a gbé àwọn ìgbésẹ̀ aláṣerégèé láti ro ẹ̀jẹ̀ náà. Nípa gbígbé àwọn ìgbésẹ̀ tí ó lọ́gbọ́nnínú níti ríro ẹ̀jẹ̀ dànù, àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lè fi ọ̀wọ̀ hàn fún ìjẹ́pàtàkì ẹ̀jẹ̀. (Deuteronomi 12:15, 16, 21-25) Ẹ̀jẹ̀ ẹran ni a lè lò lọ́nà ti ìrúbọ lórí pẹpẹ, ṣùgbọ́n a kò gbọ́dọ̀ jẹ ẹ́. A lè fìyà ikú jẹni fún mímọ̀ọ́mọ̀ rú òfin, nítorí tí a sọ fún àwọn ènìyàn Ọlọrun pé: “Ẹ̀yin kò gbọ́dọ̀ jẹ ẹ̀jẹ̀ ẹrankẹ́ran: nítorí pé ẹ̀jẹ̀ ni ẹ̀mí ara gbogbo: ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ ẹ́ ni a óò ké kúrò.”—Lefitiku 17:10-14.
Àwọn ọmọ-ogun Ọba Saulu ha mọ̀ọ́mọ̀ rú Òfin bí? Wọ́n ha ń fi àìka nǹkan sí pátápátá hàn fún òfin àtọ̀runwá lórí ẹ̀jẹ̀ bí?—Fiwé Numeri 15:30.
Kò yẹ kí a parí èrò sí bẹ́ẹ̀. Ìròyìn náà sọ pé wọ́n ‘ń pa àwọn ẹran náà sórí ilẹ̀: àwọn ènìyàn náà sì jẹ wọ́n tẹ̀jẹ̀tẹ̀jẹ̀.’ Nítorí náà wọ́n ti lè ṣe ìsapá mélòókan láti ro ẹ̀jẹ̀ náà dànù. (Deuteronomi 15:23) Síbẹ̀, nínú ipò àárẹ̀ pátápátá àti ìjìyà lọ́wọ́ ebi tí wọ́n wà, wọn kò so àwọn ẹran tí wọ́n ti dúḿbú náà rọ̀ kí wọ́n sì jẹ́ kí àkókò tí ó pọ̀ tó kọjá fún ìrodànù ẹ̀jẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ó ti yẹ. Wọn dúḿbú àwọn àgùtàn àti màlúù náà “sórí ilẹ̀,” èyí tí ó lè má jẹ́ kí ẹ̀jẹ̀ ro dáradára. Wọ́n sì yára gé ẹran lára àwọn ẹran tí wọ́n dú náà tí wọ́n ti lè wà nílẹ̀ nínú ẹ̀jẹ̀. Fún ìdí yìí, bí wọ́n ba tilẹ̀ ní ṣíṣègbọràn sí òfin Ọlọrun lọ́kàn, wọn kò ṣe bẹ́ẹ̀ ní àwọn ọ̀nà tí ó yẹ tàbí dé ipò àyè tí ó pọ̀ tó.
Ìyọrísí náà ni pé “àwọn ènìyàn náà sì jẹ wọ́n tẹ̀jẹ̀ tẹ̀jẹ̀,” èyí tí ó jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀. Saulu mọ èyí ó sì pàṣẹ pé kí a yí òkúta ńlá kan wá sọ́dọ̀ òun. Ó pàṣẹ fún àwọn ọmọ-ogun náà pé: “Kí olúkúlùkù ọkùnrin mú màlúù tirẹ̀ tọ̀ mí wá, àti olúkúlùkù ọkùnrin àgùtàn rẹ̀, kí ẹ sì pa wọ́n níhìn-ín, kí ẹ sì jẹ, kí ẹ má sì ṣẹ̀ sí Oluwa, ní jíjẹ ẹ̀jẹ̀.” (1 Samueli 14:33, 34) Àwọn ọmọ-ogun tí wọ́n jẹ̀bi náà ṣègbọràn, “Saulu sì tẹ́ pẹpẹ kan fún Oluwa.”—1 Samueli 14:35.
Ó ṣeéṣe kí dídúḿbú àwọn ẹranko náà lórí òkúta mú kí ẹ̀jẹ̀ ro dáradára. Ẹ̀ran láti ara àwọn ẹranko náà ní wọn yóò lọ jẹ́ níbòmíràn yàtọ̀ sí ibi tí a ti dúḿbú wọn. Saulu ti lè lo díẹ̀ lára ẹ̀jẹ̀ tí ó ro sílẹ̀ náà lórí pẹpẹ fún wíwá àánú Ọlọrun sórí àwọn wọnnì tí wọ́n ti ṣẹ̀. Ó hàn gbangba pé Jehofa fi àánú hàn sí wọn, nítorí pé ó mọ ìsapá tí àwọn ọmọ-ogun náà ti ṣe bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ti rẹ̀ wọ́n tí ebi sì ti pa wọ́n gidigidi. Ọlọrun tún lè ti gbé e yẹ̀wò pé ẹ̀jẹ́ tí Saulu fi ìwàǹwára jẹ́ ni ó ti àwọn ọkùnrin rẹ̀ sínú ipò-ọ̀ràn ìgbékútà.
Àkọsílẹ̀ yìí fihàn níti gidi pé ipò-ọ̀ràn pàjáwìrì kìí ṣe àwáwí fún ṣíṣàìka òfin àtọ̀runwá sí. Ó tún níláti ràn wá lọ́wọ́ láti rí àìní náà fún ìrònú tí a fìṣọ́ra ṣe ṣáájú kí a tó jẹ́ ẹ̀jẹ̀, nítorí pé ẹ̀jẹ̀ tí a fi ìwàǹwára jẹ́ lè fa ìṣoro fún àwa gan-an alára àti fún àwọn ẹlòmíràn.—Oniwasu 5:4-6.