Ọlọrun Náà Tí Kò Lè Ṣèké Tì Mí Lẹ̀yìn
GẸ́GẸ́ BÍ MARY WILLIS TI SỌ Ọ́
Ìyọrísí ìkìmọ́lẹ̀ àgbáyé ti dé àwọn àrọ́ko ní Western Australia ní 1932. Ní ọdún yẹn, nígbà tí mo jẹ́ ẹni ọdún 19 péré, èmi àti Ellen Davies gba iṣẹ́ àyànfúnni kan tí ó kárí ààlà ilẹ̀ tí ó gbòòrò tó 100,000 kìlómítà níbùú lóòró. Ibi tí ó yẹ kí a ti bẹ̀rẹ̀ ni ìlú kékeré Wiluna, tí ó wà ní nǹkan bíi 950 kìlómítà ní àríwá ìlà-oòrùn ilé wa ní Perth, olú-ìlú Western Australia.
LÓJÚ ọ̀nà wa lọ síbẹ̀, èmi àti Ellen rí araawa tí a jọ wà nínú ọkọ̀ àgbérìn ojú irin pẹ̀lú ẹ̀ṣọ́ rélùwéè oníwà-bí-ọ̀rẹ́ kan. Bí ọkọ̀ ojú irin náà ti ń dúró ní ibùdó kọ̀ọ̀kan lójú ọ̀nà, ẹ̀ṣọ́ náà ń fi pẹ̀lú inúrere sọ fún wa bí a ó ti dúró pẹ́ tó níbẹ̀. Èyí fún wa ní àǹfààní láti sọ̀kalẹ̀ kí a sì jẹ́rìí fún àwọn ènìyàn tí wọ́n ń gbé ní àwọn ibi ìtẹ̀dósí rélùwéè tí ó dádó wọ̀nyẹn. Ní àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀ a dé ìlú Wiluna náà lákòókò ìjì eruku níbi tí àwọn awakùsà ń gbé.
Bí ó ti wù kí ó rí, ibùdúró rélùwéè ní Wiluna fẹ́rẹ̀ẹ́ tó kìlómítà mẹ́ta sí àárín ìlú. Kò sí èyíkéyìí tí ó taagun nínú àwa méjèèjì, a sì ní àwọn páálí ìwé mẹ́ta tí ó wúwo àti àwọn àpò ìfàlọ́wọ́ méjì. Kí ni à bá ṣe o? A so páálí kan rọ̀ mọ́ ara igi, ẹnìkọ̀ọ̀kan sì di ìhà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ mú lára igi náà. Lọ́nà yìí ni a gbà gbé àwọn páálí náà, lọ́kọ̀ọ̀kan. A pààrà tó ìgbà méje kí a tó gbé àwọn páálí mẹ́ta àti àpò ìfàlọ́wọ́ wa náà kọjá kìlómítà mẹ́ta sí àárín ìlú. A ń dúró sinmi lemọ́lemọ́ nítorí pé ọwọ́ wa dáranjẹ̀ gan-an.
Láìka eruku, ọwọ́ tí ó dáranjẹ̀, àti ẹsẹ̀ tí àárẹ̀ ti mú náà sí, a gbádùn ìpèníjà àti ìdágbálé náà. Àwa méjèèjì ní ìmọ̀lára pé Jehofa wà pẹ̀lú wa, pé ó ń tì wá lẹ́yìn láti kojú ìbẹ̀rẹ̀ tí ń dánniwò lẹ́nu ìwàásù ní àwọn ibi àdádó. Níti tòótọ́, kò pẹ́ tí a fi rí ìbùkún rẹ̀ lórí iṣẹ́ wa nítorí ìsapá wa nínú ìrìn-àjò yẹn yọrísí gbígbà tí Bob Horn tí ó jẹ́ ọ̀dọ́ gba òtítọ́ Bibeli. A láyọ̀ pé Bob lè lo ọdún díẹ̀ nínú iṣẹ́-ìsìn Beteli àti pé ó ń báa lọ láti máa ṣiṣẹ́sin Jehofa pẹ̀lú ìṣòtítọ́ fún nǹkan tí ó tó 50 ọdún títí di ìgbà ikú rẹ̀ ní 1982.
Láti Wiluna a wàásù ní àwọn ibi ìtẹ̀dósí nínú ìrìn-àjò wa tí ó ju 725 kìlómítà títí dé Geraldton ní bèbè etíkun. Láti ibẹ̀ a darí padà wá sí Perth. Ní àwọn alẹ́ ọjọ́ díẹ̀ a sùn ní àwọn iyàrá gbayawu tí àwọn èrò ń dúró sí de rélùwéè àti lẹ́ẹ̀kan pàápàá nínú ìdì koríko ní ẹ̀gbẹ́ ọ̀nà ojú irin.
A mú aṣọ ìrọ̀rí kan dání nínú èyí tí a di àwọn bisikí àgbéléṣe ti a fi ìyẹ̀fun àlìkámà ṣe sí. Lájorí oúnjẹ wa nìyí fún apá ìdajì àkọ́kọ́ nínú ìrìn-àjò wa. Ní àwọn ìgbà mìíràn a ń rí oúnjẹ wa nípa fífọ abọ́ àti ilẹ̀ ní àwọn ilé àrójẹ àti ní àwọn iyàrá oúnjẹ àjọjẹ. Ní àwọn ìgbà mìíràn àwa yóò ṣiṣẹ́ lábẹ́ oòrùn mímú ganrínganrín ní ṣíṣa pòpòǹdó tàbí ẹ̀wà. Ọrẹ láti ọ̀dọ̀ àwọn olùfìfẹ́hàn tí wọ́n gba ìwé-ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli ṣèrànwọ́ níti àwọn ìnáwó wa.
Ohun tí ó fún mi lókun láti pa ìgbàgbọ́ mọ́ nínú Jehofa kí n sì fi tayọ̀tayọ̀ kojú ọ̀pọ̀ àwọn ipò tí ó ṣòro ní àwọn ọjọ́ wọnnì ni àpẹẹrẹ àti ìdálẹ́kọ̀ọ́ tí mo rígbà látilẹ̀ wá láti ọ̀dọ̀ màmá mi.
Ogún-Ìní Kristian Kan
Màmá mi ní ìgbàgbọ́ lílágbára nínú Ẹlẹ́dàá kan, tipẹ́tipẹ́ sẹ́yìn dé ìgbà tí mo lè rántí, òun máa ń bá àwa ọmọ sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀. Bí ó ti wù kí ó rí, a dán ìgbàgbọ́ rẹ̀ wò lọ́nà tí ń kẹ́dùn báni nípa ikú ẹ̀gbọ́n wa ọkùnrin ẹni ọdún méje nínú ìjàm̀bá ọlọ́ràn bíbaninínújẹ́ kan ní ilé-ẹ̀kọ́. Ṣùgbọ́n dípò kí inú rẹ̀ korò sí Ọlọrun, màmá fi taratara bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ nínú Bibeli. Ó fẹ́ láti kẹ́kọ̀ọ́, bí ó bá ṣeéṣe, ìdí náà fún irú àwọn ọ̀ràn ìbìnújẹ́ bẹ́ẹ̀. Ìwákiri rẹ̀ fún òtítọ́ Bibeli ni a san èrè fún, ó sì ṣàpẹẹrẹ ìyàsímímọ́ rẹ̀ sí Ọlọrun òtítọ́, Jehofa, nípasẹ̀ ìrìbọmi ní ìbẹ̀rẹ̀ àwọn ọdún 1920.
Láti ìgbà náà lọ, àwọn ìjíròrò rẹ̀ pẹ̀lú wa sábà máa ń tẹnumọ́ bí àwọn ìlérí Ọlọrun ti dájú tó. Nígbà gbogbo ni ó máa ń rọ̀ wá láti fi sọ́kàn pé ohunkóhun yòówù tí ó lè ṣẹlẹ̀, ‘Ọlọrun kò lè ṣèké.’ (Titu 1:2) Gẹ́gẹ́ bí ìyọrísí èyí, èmi àti àbúrò mi obìnrin àti méjì nínú àwọn ẹ̀gbọ́n wa ọkùnrin, papọ̀ pẹ̀lú ìdílé wa àti àwọn ọmọ ọmọ, jẹ́ olùyin Jehofa Ọlọrun lónìí. Méjì nínú àwọn ọmọkùnrin àbúrò mi obìnrin, Alan àti Paul Mason, ń ṣiṣẹ́sìn gẹ́gẹ́ bí alábòójútó arìnrìn-àjò.
Ìfẹ́-Ọkàn tí Mo Kọ́kọ́ Ní Láti Jíhìnrere
Èmi kò mọ̀wé dáradára mo sì fi ilé-ẹ̀kọ́ sílẹ̀ ní 1926, nígbà tí mo jẹ́ ẹni ọdún 13. Síbẹ̀, mo ti mú ìfẹ́-ọkàn tí ó lágbára dàgbà láti ṣàjọpín ohun tí mo ti kọ́ nípa Bibeli pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn. Bàbá mi rò pé nkò mọ̀wé tó láti ran ẹnikẹ́ni lọ́wọ́, ṣùgbọ́n Màmá wí pé: “Bí o bá wulẹ̀ ń sọ fún àwọn ènìyàn nípa ogun Armagedoni tí ń bọ̀wá nìkan àti pé àwọn ọlọ́kàn-tútù yóò jogún ilẹ̀-ayé, ìyẹn yóò fọnrere Ìjọba Ọlọrun.” Nítorí náà mo bẹ̀rẹ̀ síí kópa nínú iṣẹ́ ìwàásù ẹnu-ọ̀nà dé ẹnu-ọ̀nà nígbà tí n kò tíì pé ogun ọdún, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé nkò ṣèrìbọmi títí di ọdún 1930. Láìpẹ́ lẹ́yìn náà, mo bẹ̀rẹ̀ ìjíhìnrere alákòókò kíkún ní agbègbè tí ó yí Perth ká.
Ní ọdún tí ó tẹ̀lé e, 1931, a bẹ̀rẹ̀ síí lo orúkọ wa titun Ẹlẹ́rìí Jehofa. Bí ó ti wù kí ó rí, ọ̀pọ̀ àwọn onílé tako lílò tí a ń lo orúkọ mímọ́ ọlọ́wọ̀ ti Ọlọrun wọ́n sì dáhùnpadà lọ́nà lílekoko. Síbẹ̀ mo ń báa lọ nínú iṣẹ́-òjíṣẹ́ náà láìka àwọn ìbápàdé tí kò dùnmọ́ni náà sí. Mo ní ìdánilójú pé Ọlọrun kò ṣèké nígbà tí ó ṣèlérí pé àwọn ìránṣẹ́ òun lè ‘gbáralé okun tí òun ń pèsè.’—1 Peteru 4:11; Filippi 4:13.
Dídá “Ogunlọ́gọ̀ Ńlá” Mọ̀ Yàtọ̀
Ní 1935, mo rí iṣẹ́-àyànfúnni gbà sí apá òdìkejì kọ́ńtínẹ́ǹtì Australia fífẹ̀ salalu. Nípa báyìí, fún ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìnwá ìgbà náà mo ṣiṣẹ́sìn gẹ́gẹ́ bí òjíṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà yíká àgbègbè New England ti ìpínlẹ̀ New South Wales, nǹkan bíi 4,000 kìlómítà sí ibùgbé mi tẹ́lẹ̀ ní Perth.
Títí di ìgbà náà mo ti ń jẹ àwọn ohun ìṣàpẹẹrẹ ti búrẹ́dì aláìwú àti wáìnì pupa nibi Ìṣe-Ìrántí ọdọọdún ti ikú Jesu. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a ka èyí sí ohun yíyẹ láti ṣe, ní pàtàkì jùlọ fún àwọn onítara òjíṣẹ́ alákòókò-kíkún, èmi kò gbàgbọ́ dájú rí pé mo ní ìrètí ti òkè ọ̀run. Lẹ́yìn náà, ní 1935, a mú un ṣe kedere fún wa pé ogunlọ́gọ̀ ńlá kan tí ó ní ìrètí gbígbé títíláé lórí ilẹ̀-ayé ni a ti ń kójọ. Ọ̀pọ̀ nínú wa yọ̀ láti lóye pé a jẹ́ apákan ogunlọ́gọ̀ ńlá yẹn, a sì ṣíwọ́ jíjẹ àwọn ohun ìṣàpẹẹrẹ náà. (Johannu 10:16; Ìfihàn 7:9) Òtítọ́ Bibeli ń mọ́lẹ̀ síwájú àti síwájú síi, àní gẹ́gẹ́ bí Jehofa ti ṣèlérí.—Owe 4:18.
Àwọn Ọ̀nà Ìwàásù Titun
Ní agbedeméjì àwọn ọdún 1930, a bẹ̀rẹ̀ síí lo ẹ̀rọ tí ń lu àwo rẹ́kọ́ọ̀dù nínú iṣẹ́-òjíṣẹ́ wa. Nípa báyìí, àwọn kẹ̀kẹ́ ológeere wa lílágbára ni a níláti so ìkẹ́rù mọ́ níwájú àti lẹ́yìn kìí ṣe fún ẹ̀rọ tí ń lu àwo rẹ́kọ́ọ̀dù náà nìkan bíkòṣe fún àwọn rẹ́kọ́ọ̀dù náà àti àwọn àpò ìkówèé wa pẹ̀lú. Mo níláti lo ìṣọ́ra gidigidi nígbà tí kẹ̀kẹ́ mi bá ti kún fún ẹrù nítorí pé bí ó ba ṣubú lulẹ̀, ó ti wúwo jù fún mi láti gbé nàró!
Ní nǹkan bí àkókò yẹn ni a bẹ̀rẹ̀ ohun tí a ń pè ní ìtòlọ́wọ̀ọ̀wọ́-yan láti fúnni ní ìsọfúnni. Bí a ti ń rìn lọ ní àwọn òpópónà ńlá nínú ìlú, a gbé àwọn ìsọfúnni àgbékiri, tàbí àmì tí a tẹ̀ sórí pátákó kọ́rùn, èyí tí ń ṣe ìgbéjáde àwọn ọ̀rọ̀ amóríwú tí ń pàfiyèsí ẹni. Mo rí iṣẹ́ yìí gẹ́gẹ́ bí ìdánwò ìgbàgbọ́ kan ní pàtàkì, pàápàá jùlọ nígbà tí a fi àṣẹ ọba mú mi tí a sì tì mí mọ́ inú iyàrá ẹ̀wọ̀n kékeré kan mọ́jú ní ìlú Lismore. Ìtẹ́nilógo ni ó jẹ́ fún mi nígbà tí a mú mi lọ sí kóòtù ní ọjọ́ kejì láìtilẹ̀ yọ̀ǹda fún mi láti ya irun mi! Ṣùgbọ́n lẹ́ẹ̀kan síi Jehofa gbé mi ró gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣèlérí. Ọ̀ràn ẹjọ́ náà ni a túká nítorí pé ẹ̀sùn kanṣoṣo tí ọlọ́pàá olókùn méjì náà tí ó fi àṣẹ mú mi fi sùn ni pé ìwé ìsọfúnni tí mo gbé kọ́rùn ṣe láìfí sí ìsìn òun.
Padà sí Ìwọ̀-Oòrùn
Ní ìbẹ̀rẹ̀ àwọn ọdún 1940, iṣẹ́ ìwàásù aṣáájú-ọ̀nà mi gbé mi padà lọ sí àwọn ìlú orílẹ̀-èdè ní Western Australia. Níhìn-ín ni mo ti ń báa lọ láti máa gbádùn àwọn ìrírí mánigbàgbé àti àwọn ìbùkún tẹ̀mí. Nígbà tí mo ṣì wà lẹ́nu iṣẹ́-àyànfúnni mi ní Northam, mo bá ìyàwó ilé tí ọwọ́ rẹ̀ dí kan, Flo Timmins pàdé, ní nǹkan bíi kìlómítà mọ́kànlá jìnnà sí ìlú. Ó gba ìwé náà Reconciliation, kò sì pẹ́ púpọ̀ tí o fi di Ẹlẹ́rìí tí a yàsímímọ́ fún Jehofa Ọlọrun. Ó ṣì jẹ́ aláápọn nínú iṣẹ́-ìsìn Ìjọba, ọmọdébìnrin rẹ̀, tí ó ṣì jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́rin nígbà náà, dàgbà di òjíṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe kan.
Ṣùgbọ́n àwọn ìrírí mìíràn tí kò ṣeé gbàgbé wà. Lẹ́ẹ̀kan rí, èmi àti alábàáṣiṣẹ́ mi ń sọdá afárá kan ní Northam nínú kẹ̀kẹ́ àfẹṣinfà wa, nígbà tí ẹṣin náà ṣàdéédéé fi eré gée, ní gbígbé wa sáré lọ́nà tí ń kó jìnnìjìnnì báni rékọjá omi Odò Avon tí ń yí gbirigbiri lápá ìsàlẹ̀. Lẹ́yìn ohun tí ó ju kìlómítà kan lọ, ẹṣin náà dẹwọ́ eré sísá.
Ìgbéyàwó àti Ìdílé Kan
Ní 1950, mo fẹ́ Arthur Willis, tí òun pẹ̀lú ti jẹ́ aṣáájú-ọ̀nà fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún. A fìdíkalẹ̀ sí ìlú Pingelly tí ó wà ní Ìwọ̀-Oòrùn Australia, níbi tí a ti fi ọmọkùnrin kan, Bentley, àti ọmọbìnrin kan Eunice, bùkún wa. Nígbà tí ó kù díẹ̀ kí àwọn ọmọ náà parí ilé-ẹ̀kọ́, Arthur pinnu láti wọṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà lẹ́ẹ̀kan síi. Àpẹẹrẹ rere ti baba wọn fún àwọn ọmọ wa méjèèjì níṣìírí láti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà déédéé ní gbàrà tí wọ́n di ẹni tí ó tóótun.
Arthur sábà máa ń mú àwọn ọmọ lọ sí àwọn agbègbè àrọ́ko jíjìnnà réré láti wàásù. Nílàrè nílàrè, òun yóò mú wọn lọ́ fún ọ̀sẹ̀ kan tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ ní ìgbà kan, ní gbígbé lábẹ́ àgọ́ ní alẹ́ ọjọ́ kọ̀ọ̀kan. Ní àwọn ìgbà tí wọn kò bá sí nílé wọ̀nyí, èmi a dúró sílé láti bójútó iṣẹ́-ajé ohun ọ̀ṣọ́ ilé tí ìdílé ń ṣe, ní mímú kí ó ṣeéṣe fún àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta láti ṣe aṣáájú-ọ̀nà.
Iṣẹ́-Òjíṣẹ́ Láàárín Àwọn Ọmọ Ìbílẹ̀ Australia
Ní òwúrọ̀ ọjọ́ kan ní kété lẹ́yìn tí ìdílé padà dé láti ọ̀kan nínú àwọn ìrìn-àjò ránpẹ́ wọn lọ sí àrọ́ko, a gba àlejò kan tí a kò retí. Ọmọ Ìbílẹ̀ Australia kan ni, tí ó béèrè pé: “Kí ni mo lè ṣe láti padà?” Lákọ̀ọ́kọ́ ó rú wa lójú. Lẹ́yìn náà Arthur mọ̀ ọ́n sí ọkùnrin kan tí a ti yọlẹ́gbẹ́ kúrò nínú ìjọ Kristian fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún ṣáájú nítorí ìmùtípara. Láti ìgbà náà wá ni ó ti mú ìfùsì tí ń dániníjì dàgbà fún ọtí àmupara àti fún jíjẹ gbèsè.
Arthur ṣàlàyé ohun tí ó gbọ́dọ̀ ṣe fún un láti di ẹni tí a gbà padà sínú ètò-àjọ mímọ́ ti Jehofa. Ó lọ kúrò wọ́ọ́rọ́wọ́ láìsọ ọ̀rọ̀ púpọ̀, gbogbo wa sì ṣe kàyéfì nípa ohun tí yóò ṣe. Ohun tí ó ṣẹlẹ̀ ní àwọn oṣù díẹ̀ tí ó tẹ̀lé e rékọjá ohun tí ẹnikẹ́ni nínú wa retí. Àwọn ìyípadà tí ọkùnrin náà ṣe fẹ́rẹ̀ẹ́ má ṣeé gbàgbọ́! Kìí ṣe pé ó ń padàbọ̀sípò kúrò nínú ìṣòro ọtí mímu rẹ̀ nìkan ni ṣùgbọ́n ó tún ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ àwọn ènìyàn ní àgbègbè náà, ní rírán wọn léti gbèsè rẹ̀, lẹ́yìn náà ni ó sì san gbèsè tí ó jẹ! Lónìí òun tún jẹ́ arákùnrin nínú ìgbàgbọ́ lẹ́ẹ̀kan síi, ó sì ṣiṣẹ́sìn fún àkókò kan gẹ́gẹ́ bí òjíṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà.
Àwọn Ọmọ Ìbílẹ̀ Australia púpọ̀ ni wọ́n wà ní Pingelly, a sì gbádùn iṣẹ́-òjíṣẹ́ tí ń tẹ́nilọ́rùn jùlọ, ní ríran àwọn ènìyàn onírẹ̀lẹ̀ ọkàn wọ̀nyí lọ́wọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọrun kí wọ́n sì tẹ́wọ́gbà á. Ẹ wo bí ó ti jẹ́ ohun tí ń fún ìgbàgbọ́ mi lókun tó pé mo ti kó ipa kan nínú ríran ọ̀pọ̀lọpọ̀ lára àwọn Ọmọ Ìbílẹ̀ Australia lọ́wọ́ ní kíkẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́!
A bẹ̀rẹ̀ ìjọ kan ní Pingelly, ọ̀pọ̀ jùlọ nínú àwọn mẹ́ḿbà rẹ̀ sì jẹ́ Ọmọ Ìbílẹ̀ Australia, ní ìbẹ̀rẹ̀. A níláti kọ́ púpọ̀ nínú wọn láti kà àti láti kọ̀wé. Ọ̀pọ̀ ẹ̀tanú wà ní ìlòdìsí wọn ní àwọn ọdún ìbẹ̀rẹ̀ wọnnì, ṣùgbọ́n ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ ni àwọn ará ìlú náà bẹ̀rẹ̀ síí fí ọ̀wọ̀ hàn fún àwọn Ọmọ Ìbílẹ̀ Australia tí wọ́n jẹ́ Ẹlẹ́rìí fún ọ̀nà ìgbésí-ayé wọn mímọ́ tónítóní àti fún jíjẹ́ ọlọ̀tọ̀ tí ó ṣeé gbẹ́kẹ̀lé.
Ìrànlọ́wọ́ Jehofa tí Kìí Kùnà
Arthur, ọkọ́ mi ọ̀wọ́n tí ó ti fi ìṣòtítọ́ ṣiṣẹ́sin Ọlọrun fún ọdún 57, kú ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 1986. Gbogbo àwọn ọkùnrin oníṣòwò tí ń bẹ ní Pingelly àti àwọn ènìyàn tí wọ́n wà ní àgbègbè náà bọ̀wọ̀ fún un dáradára. Lẹ́ẹ̀kan síi, Jehofa tì mí lẹ́yìn, ní fífún mi ní okun láti farada ìpàdánù òjijì yìí.
Ọmọkùnrin mi, Bentley, ń ṣiṣẹ́sìn gẹ́gẹ́ bí alàgbà ní àríwá Western Australia, níbi tí òun àti ìyàwó rẹ̀, Lorna, ti tọ́ ìdílé wọn dàgbà nínú òtítọ́. Orísun ayọ̀ ńlá mìíràn fún mi ni pé ọmọbìnrin mi, Eunice, ti ń báa lọ nínú iṣẹ́-ìsìn alákòókò-kíkún títí di òní yìí. Òun àti ọkọ rẹ̀, Jeff, ń ṣiṣẹ́sìn gẹ́gẹ́ bí aṣáájú-ọ̀nà. Ọ̀dọ̀ wọn ni mo ń gbé nísinsìnyí ó sì jẹ́ ìbùkún fún mi láti lè ṣe aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ títílọ.
Fún ohun tí ó ju 60 ọdún lọ, mo ti ní ìrírí ìmúṣẹ ìlérí onífẹ̀ẹ́ tí Jehofa ṣe láti fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lókun kí ó sì ràn wọ́n lọ́wọ́ láti kojú àwọn àyíká ipò èyíkéyìí tí wọ́n lè ní láti dojúkọ. Ó ń pèsè ohun gbogbo tí a ṣe aláìní bí a kò bá ṣiyèméjì nípa rẹ̀ tàbí kí a dágunlá nípa rẹ̀. A ti fún ìgbàgbọ́ mi lókun bí mo ti nímọ̀lára pé ọwọ́ Ọlọrun wà lẹ́nu iṣẹ́, mo sì ti rí bí ó ti ń fi ìbùkún rẹ̀ fúnni àní rékọjá ohun tí a lè finúmòye. (Malaki 3:10) Nítòótọ́, Ọlọrun kò lè ṣèké!
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 27]
Mary ní 1933
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29]
Mary àti Arthur nígbà tí ọjọ́ ogbó ń dé