Gbígbógunti Ìwàmú Ẹ̀sẹ̀ Lórí Ẹran-Ara Ẹlẹ́ṣẹ̀
“Gbígbé èrò-inú ka orí ẹran-ara túmọ̀ sí ikú, ṣugbọn gbígbé èrò-inú ka orí ẹ̀mí túmọ̀ sí ìyè ati àlàáfíà.”—ROMU 8:6, NW.
1. Ète wo ni a dá àwọn ènìyàn fún?
“ỌLỌRUN dá ènìyàn ní àwòrán rẹ̀, ní àwòrán Ọlọrun ni ó dá a; àti akọ àti abo ni ó dá wọn.” (Genesisi 1:27) Àwòrán kan jẹ́ àfihàn ohun kan tí ó ṣeé fojúrí tàbí orísun kan. Nípa báyìí, àwọn ènìyàn ni a dá láti jẹ́ olùgbé ògo Ọlọrun yọ. Nípa ṣíṣàgbéyọ àwọn ànímọ́ Ọlọrun—bí ìfẹ́, ìwàrere-ìṣeun, ìdájọ́-òdodo, àti ipò-tẹ̀mí—nínú gbogbo ìdáwọ́lé wọn, wọ́n ń mú ìyìn àti ọlá wá fún Ẹlẹ́dàá, pẹ̀lú ayọ̀ àti ìtẹ́lọ́rùn fún araawọn.—1 Korinti 11:7; 1 Peteru 2:12.
2. Báwo ni tọkọtaya àkọ́kọ́ ṣe kùnà láti dójú ìlà?
2 Tọkọtaya ènìyàn àkọ́kọ́, tí a dá ní pípé, ni a mú gbaradì dáradára fún ipa-iṣẹ́ yìí. Bí àwọn jígí tí a mú dán gbinrin gbinrin, wọ́n dáńgájíá láti gbé ògo Ọlọrun yọ pẹ̀lú ìdányanran àti ìpéye kíkún. Bí ó ti wù kí ó rí, wọ́n mú kí a kó àbààwọ́n bá ìdángbinrin yẹn nígbà tí wọ́n mọ̀ọ́mọ̀ yàn láti ṣàìgbọ́ràn sí Ẹlẹ́dàá àti Ọlọrun wọn. (Genesisi 3:6) Lẹ́yìnwá ìgbà náà, kò ṣeéṣe fún wọn mọ́ láti gbé ogo Ọlọrun yọ lọ́nà pípé pérépéré. Wọ́n kùnà ògo Ọlọrun, ní kíkùnà ète tí a tìtorí rẹ̀ dá wọn ní àwòrán Ọlọrun. Ní èdè mìíràn, wọ́n dẹ́ṣẹ̀.a
3. Báwo ni ẹ̀ṣẹ̀ ti rí níti gidi?
3 Èyí ràn wá lọ́wọ́ láti lóye bí ẹ̀ṣẹ̀ ṣe rí níti gidi, èyí tí ń ba bí ènìyàn ti ń gbé ìrísí àti ògo Ọlọrun yọ jẹ́. Ẹ̀ṣẹ̀ ń sọ ènìyàn di aláìmọ́, ìyẹn ni pé, ẹni tí kò mọ́ tí a sì ti kó àbààwọ́n bá lọ́nà tẹ̀mí àti ti ìwàrere. Bí gbogbo aráyé ti jẹ́ àtọmọdọ́mọ Adamu àti Efa, a bí wọn gẹ́gẹ́ bí ẹni tí a ti kó àbààwọ́n bá tí wọ́n sì wà ní ipò àìmọ́, ní kíkùnà láti dójú ìlà ohun tí Ọlọrun retí láti ọ̀dọ̀ wọn gẹ́gẹ́ bí ọmọ rẹ̀. Kí sì ní àbájáde rẹ̀? Bibeli ṣàlàyé pé: “Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀ṣẹ̀ ti ti ipa ọ̀dọ̀ ènìyàn kan wọ ayé, àti ikú nípa ẹ̀ṣẹ̀; bẹ́ẹ̀ ni ikú sì kọjá sórí ènìyàn gbogbo, láti ọ̀dọ̀ ẹni tí gbogbo ènìyàn ti dẹ́ṣẹ̀.”—Romu 5:12; fiwé Isaiah 64:6.
Ìwàmú Ẹ̀ṣẹ̀ Lórí Ẹran-Ara Ẹlẹ́ṣẹ̀
4-6. (a) Ojú wo ni ọ̀pọ̀ jùlọ ènìyàn fi ń wo ẹ̀ṣẹ̀ lónìí? (b) Kí ni àbájáde ojú-ìwòye òde-òní nípa ẹ̀ṣẹ̀?
4 Ọ̀pọ̀ jùlọ ènìyàn lónìí kò ronú pé àwọn fúnraawọn jẹ́ aláìmọ́, ẹni tí a kó àbààwọ́n bá, tàbí ẹlẹ́ṣẹ̀. Ní tòótọ́, ẹ̀ṣẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ kan, ti fẹ́rẹ̀ẹ́ pòórá pátápátá nínú èdè ìsọ̀rọ̀ ọ̀pọ̀ jùlọ ènìyàn. Kàkà bẹ́ẹ̀ wọn yóò sọ̀rọ̀ nípa àwọn àṣìṣe, àìgbọ́n, àti àṣìsọ. Ṣùgbọ́n ẹ̀ṣẹ̀ ńkọ́? Ekukáká! Alan Wolfe, ọ̀jọ̀gbọ́n onímọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa àjọṣepọ̀ ẹgbẹ́-òun-ọ̀gbà ṣàkíyèsí pé kódà lójú àwọn tí wọ́n tilẹ̀ jẹ́wọ́ pé àwọn ní ìgbàgbọ́ nínú Ọlọrun pàápàá, “àwọn ẹ̀kọ́ rẹ̀ wémọ́ ọ̀wọ́ àwọn èrò ìgbàgbọ́ ti ìwàrere dípò kí ó jẹ́ àkójọ òfin ìwàhíhù, ‘àwọn àbá 10 náà’ dípò kí ó jẹ́ àwọn òfin 10.”
5 Kí ni àbájáde ọ̀nà ìgbàronú yìí? Sísẹ́, tàbí ó kérétán ṣíṣàì ka ìjẹ́gidi ẹ̀ṣẹ̀ sí. Èyí ti pèsè ìran àwọn ènìyàn kan tí agbára ìmòye wọn nípa ohun tí ó dára àti ohun tí ó burú ti di èyí tí a gbégbòdì gidigidi, tí wọ́n lérò pé àwọn lómìnira láti gbé àwọn ọ̀pá ìdíwọ̀n ìhùwà tiwọn kalẹ̀ tí wọ́n sì lérò pé kò sí ẹni tí yóò yẹ̀ wọ́n lọ́wọ́ wò fún ohunkóhun tí wọ́n bá yàn láti ṣe. Lójú irú àwọn ènìyàn bẹ́ẹ̀, nínímọ̀lára pé ọkàn ẹni kò dáni lẹ́bi ni ọ̀pá ìdíwọ̀n ìdájọ́ kanṣoṣo náà tí a lè fi pinnu yálà ipa-ọ̀nà ìgbésẹ̀ kan tọ̀nà tàbí kò tọ̀nà.—Owe 30:12, 13; fiwé Deuteronomi 32:5, 20.
6 Fún àpẹẹrẹ, nínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò kan lórí tẹlifíṣọ̀n, àwọn ọ̀dọ́ ni a késí láti sọ ohun tí ó jẹ́ ojú-ìwòye wọn nípa àwọn ẹ̀ṣẹ̀ méje náà tí a sọ pé wọ́n lè yọrísí ikú.b Olùkópa kan polongo pé, “Ìgbéraga kìí ṣe ẹ̀ṣẹ̀. Ó yẹ kí o ní èrò rere nípa araàrẹ.” Nípa ti ìmẹ́lẹ́, òmíràn wí pé: “Ó dára láti wà bẹ́ẹ̀ nígbà mìíràn. . . . Nígbà mìíràn ó dára láti ṣèdẹ̀ra kí o sì fún araàrẹ ní ìsinmi.” Oníròyìn náà tilẹ̀ pèsè àlàyé ṣókí yìí: ‘Àwọn ẹ̀ṣẹ̀ méje tí ó lè yọrísí ikú náà kìí ṣe ìwà ibi ṣùgbọ́n, kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n jẹ́ àwọn agbára amúnilápàpàǹdodo méje tí àwọn ènìyàn ní káàkiri àgbáyé èyí ti ó lè kó ìyọlẹ́nu báni tàbí kí ó gbádùnmọ́ni lọ́nà gíga.’ Bẹ́ẹ̀ni, ìmọ̀lára ẹ̀bi ti pòórá pẹ̀lú ìpòórá ẹ̀ṣẹ̀, nítorí pé, ó ṣetán, ẹ̀bi jẹ́ òdìkejì gan-an fún nínímọ̀lára pé ọkàn ẹni kò dáni lẹ́bi.—Efesu 4:17-19.
7. Gẹ́gẹ́ bí Bibeli ti sọ, báwo ni ẹ̀ṣẹ̀ ṣe ń nípalórí ènìyàn?
7 Ní ìyàtọ̀ gedegbe sí gbogbo èyí, Bibeli sọ ní kedere pé: “Gbogbo ènìyàn ni ó sáà ti ṣẹ̀, tí wọ́n sì kùnà ògo Ọlọrun.” (Romu 3:23) Kódà aposteli Paulu jẹ́wọ́ pé: “Èmi mọ̀ pé kò sí ohun rere kan tí ń gbé inú mi, èyíinì [ni] nínú araàmi: nítorí ìfẹ́ ohun tí ó dára ń bẹ fún mi, ṣùgbọ́n ọ̀nà àtiṣe é ni èmi kò rí. Nítorí ire tí èmi fẹ́ èmi kò ṣe: ṣùgbọ́n búburú tí èmi kò fẹ́, èyíinì ni èmi ń ṣe.” (Romu 7:18, 19) Kìí ṣe pé Paulu ń fi ìkáàánú ara-ẹni ṣayọ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, nítorí pé ó mọ bí aráyé ti kùnà ògo Ọlọrun tó, ó ń nímọ̀lára ìwàmú ẹ̀ṣẹ̀ lórí ẹran-ara ẹlẹ́ṣẹ̀ lọ́nà tí ó túbọ̀ lekoko. Ó polongo pé, “Èmi ẹni òṣì! ta ni yóò gbà mí lọ́wọ́ ara ikú yìí?”—Romu 7:24.
8. Àwọn ìbéèrè wo ní a níláti bí araawa? Èéṣe?
8 Kí ni ojú-ìwòye rẹ nípa ọ̀ràn yìí? Ìwọ lè gbà pé gẹ́gẹ́ bí àtọmọdọ́mọ Adamu, ìwọ jẹ́ aláìpé, gẹ́gẹ́ bí gbogbo ènìyàn mìíràn ti jẹ́. Ṣùgbọ́n báwo ni ìmọ̀ yẹn ṣe nípalórí ìrònú àti ọ̀nà ìgbésí-ayé rẹ? Ìwọ ha tẹ́wọ́gbà á gẹ́gẹ́ bí ohun kan tí kò ṣeéyípadà tí o sì wulẹ̀ ń bá a lọ láti ṣe ohun tí ó bá ti wá sọ́kàn rẹ lọ́nà ti ẹ̀dá bí? Tàbí o ha ń sapá lemọ́lemọ́ láti gbéjàko ìwàmú ẹ̀ṣẹ̀ lórí ẹran-ara ẹlẹ́ṣẹ̀, ní lílàkàkà láti gbé ògo Ọlọrun yọ lọ́nà dídán yanranyanran bí ó bá ti lè ṣeéṣe tó nínú gbogbo ohun tí o ń ṣe? Èyí níláti jẹ́ ohun tí ẹnìkọ̀ọ̀kan wa ní ìdàníyàn pàtàkì fún nítorí ohun tí Paulu sọ pé: “Awọn wọnnì tí wọ́n wà ní ìbámu pẹlu ẹran-ara gbé èrò-inú wọn ka orí awọn ohun ti ẹran-ara, ṣugbọn awọn wọnnì tí wọ́n wà ní ìbámu pẹlu ẹ̀mí gbé e ka orí awọn ohun ti ẹ̀mí. Nitori gbígbé èrò-inú ka orí ẹran-ara túmọ̀ sí ikú, ṣugbọn gbígbé èrò-inú ka orí ẹ̀mí túmọ̀ sí ìyè ati àlàáfíà.”—Romu 8:5, 6, NW.
Gbígbé Èrò-Inú Ka Orí Ẹran-Ara
9. Èéṣe tí ó fi jẹ́ pé “gbígbé èrò-inú ka orí ẹran-ara túmọ̀sí ikú”?
9 Kí ni Paulu nílọ́kàn nígbà tí ó wí pé “gbígbé èrò-inú ka orí ẹran-ara túmọ̀ sí ikú”? Ọ̀rọ̀ náà “ẹran-ara” ni a sábà máa ń lò nínú Bibeli láti tọ́kasí ènìyàn nínú ipò àìpé rẹ̀, ‘tí a lóyún rẹ̀ nínú ẹ̀ṣẹ̀’ gẹ́gẹ́ bí àtọmọdọ́mọ Adamu ọlọ̀tẹ̀. (Orin Dafidi 51:5; Jobu 14:4) Nípa báyìí, Paulu ń fún àwọn Kristian ní ìṣílétí láti máṣe gbé èrò-inú wọn karí àwọn ìtẹ̀sí tí ó kún fún ẹ̀ṣẹ̀, àwọn òòfà-ọkàn, àti àwọn ìfẹ́-ọkàn àìpé, ti ẹran-ara ẹlẹ́ṣẹ̀. Èésìtiṣe tí kò fi gbọ́dọ̀ rí bẹ́ẹ̀? Níbòmíràn Paulu sọ ohun tí àwọn iṣẹ́ ti ara jẹ́ fún wa ó wá fi ìkìlọ̀ náà kún un pé: “Àwọn tí ń ṣe nǹkan báwọ̀nnì kì yóò jogún ìjọba Ọlọrun.”—Galatia 5:19-21.
10. Kí ni “gbígbé èrò-inú kà” túmọ̀sí?
10 Ṣùgbọ́n ìyàtọ̀ gidigidi kò ha wà láàárín gbígbé èrò-inú karí ohun kan àti sísọ ọ́ dàṣà? Lóòótọ́, ríronú nípa ohun kan kìí fìgbà gbogbo jálẹ̀ sí ṣíṣe ohun náà. Bí ó ti wù kí ó rí, gbígbé èrò-inú karí ohun kan ju wíwulẹ̀ ronú ṣákálá nípa rẹ̀ lọ. Ọ̀rọ̀ náà ti Paulu lò ni phroʹne·ma ní èdè Griki, ó sì túmọ̀sí “ọ̀nà ìgbàronú, ibi tí a (gbé-) èrò-inú (-kà), . . . ìfojúsùn, ìnàgàsí, ìlàkàkà.” Nítorí náà, “gbígbé èrò-inú ka orí ẹran-ara” túmọ̀sí jíjẹ́ ẹni tí àwọn ìfẹ́-ọkàn tí ẹran-ara ẹlẹ́ṣẹ̀ ń darí, jẹgàba lé, jọbalé, tí ó sì ń fagbárasún.—1 Johannu 2:16.
11. Báwo ni Kaini ṣe gbé èrò-inú ka orí ẹran-ara, kí sì ni ìyọrísí rẹ̀?
11 Kókó náà ni a mú ṣe kedere nínú ipa-ọ̀nà tí Kaini tẹ̀lé. Nígbà tí owú àti ìbínú rusókè nínú ọkàn-àyà Kaini, Jehofa Ọlọrun kìlọ̀ fún un pé: “Èéṣe ti inú fi ń bí ọ? èésìtiṣe tí ojú rẹ fi rẹ̀wẹ̀sì? Bí ìwọ bá ṣe rere, ara kì yóò ha yá ọ? bí ìwọ kò bá sì ṣe rere, ẹ̀ṣẹ̀ ba ní ẹnu-ọ̀nà, lọ́dọ̀ rẹ ni ìfẹ́ rẹ̀ yóò máa fà sí, ìwọ ó sì máa ṣe alákòóso rẹ̀.” (Genesisi 4:6, 7) Yíyàn kan wà níwájú Kaini. Òun yóò ha “ṣe rere.” ìyẹn ni pé, fi èrò-inú, ìfojúsùn, àti ìnàgàsí rẹ̀ sínú ohun kan tí ó dára bí? Tàbí yóò ha máa báa lọ ní gbígbé èrò-inú ka orí ẹran-ara kí ó sì pa èrò-inú rẹ̀ pọ̀ sórí àwọn ìtẹ̀sí búburú tí ó farapamọ́ sínú ọkàn-àyà rẹ̀? Gẹ́gẹ́ bí Jehofa ti ṣàlàyé, ẹ̀ṣẹ̀ “ba ní ẹnu-ọ̀nà,” ní dídúró làti fò mọ́ Kaini kí ó sì pa á run bí òun yóò bá fàyègbà á. Dípò kí ó gbógunti àwọn ìfẹ́-ọkàn ti ẹran-ara rẹ̀ ‘kí ó sì mú wọn wá sábẹ́ àkóso,’ Kaini yọ̀ọ̀da fún un láti borí òun—sí òpin oníjàábá.
12. Kí ni a níláti ṣe kí a má baà rìn “ní ọ̀nà Kaini”?
12 Àwa ńkọ́ lónìí? Dájúdájú àwa kò fẹ́ láti rìn “ní ọ̀nà Kaini,” gẹ́gẹ́ bí Juda ti kédàárò nípa àwọn kan lára àwọn Kristian ọ̀rúndún kìn-ín-ní. (Juda 11) A kò gbọ́dọ̀ wá àwíjàre láé kí a sì ronú pé títẹ́ ìfẹ́-ọkàn wa lọ́rùn fún ìgbà díẹ̀ tàbí títẹ àwọn ìlànà lójú fẹ́ẹ́rẹ́fẹ́ níhìn-ín lọ́hùn-ún kò léwu. Ní òdìkejì, ó yẹ kí a wà lójúfò láti mọ agbára ìdarí èyíkéyìí tí ó jẹ́ aláìwà-bí-Ọlọ́run àti èyí tí ń sọnidìbàjẹ́ tí ó ti lè wá sínú ọkàn-àyà àti èrò-inú wa kí a sì yára mú un kúrò ṣáájú kí ó tó fi gbòǹgbò múlẹ̀. Gbígbógunti ìwàmú ẹ̀ṣẹ̀ lórí ẹran-ara ẹlẹ́ṣẹ̀ ń bẹ̀rẹ̀ láti inú.—Marku 7:21.
13. Báwo ni a ṣe lè ti ‘ọwọ́ ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ẹnìkan fà á lọ’?
13 Fún àpẹẹrẹ, ìwọ lè fojú gánní ìran kan tí ń múnigbọ̀nrìrì tàbí tí ó banilẹ́rù tàbí àwòrán kan tí ń runisókè tàbí tí ń ru ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ sókè ní pàtàkì. Ó lè jẹ́ àwòrán nínú ìwé tàbí ìwé-ìròyìn kan, ìran kan lórí àwòrán sinimá tàbí tẹlifíṣọ̀n, ìpolówó ọjà kan níbi tí a lẹ̀ ẹ́ mọ́, tàbí ní ojúkorojú gan-an. Kò pọndandan fún ìyẹn nínú araarẹ̀ láti fa ìdágìrì, níwọ̀n bí ó ti lè—tí ó sì máa—ń ṣẹlẹ̀. Bí ó ti wù kí ó rí, àwòrán tàbí ìran yìí lè dàbí èyí tí ń dúró pẹ́ nínú èrò-inú tí ó sì ń padà wá sọ́kàn láti ìgbà dé ìgbà, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé rírí i lè má pẹ́ ju ìṣẹ́jú àáyá díẹ̀ lọ. Kí ni ìwọ máa ń ṣe nígbà tí ìyẹn bá ṣẹlẹ̀? Ìwọ ha ń gbégbèésẹ̀ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ láti gbógunti ìrònú yẹn kí o sì mú un kúrò nínú èrò-inú rẹ bí? Tàbí o ń yọ̀ọ̀da fún un láti gbé inú èrò-inú rẹ, bóyá ní fífi ọkàn tún ìrírí náà dàrò ní gbogbo ìgbà tí ìrònú náà bá jẹyọ? Láti ṣe èyí tí a sọ gbẹ̀yìn yìí jẹ́ láti fi ara wewu mímú kí ìsokọ́ra àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí Jakọbu ṣàpèjúwe bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́: “Olúkúlùkù ni a ń dánwò, nígbà tí a bá ti ọwọ́ ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ araarẹ̀ fà á lọ tí a sì tàn án jẹ. Ǹjẹ́, ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ náà nígbà tí ó bá lóyún, a bí ẹ̀ṣẹ̀: àti ẹ̀ṣẹ̀ náà nígbà tí ó bá sì dàgbà tán, a bí ikú.” Ìdí rẹ̀ nìyẹn tí Paulu fi wí pé: “Gbígbé èrò-inú ka orí ẹran-ara túmọ̀ sí ikú.”—Jakọbu 1:14, 15; Romu 8:6, NW.
14. Kí ni ó ń kò wá lóju lójoojúmọ́, báwo ni a sì ṣe níláti hùwàpadà?
14 Bí ó ti jẹ́ pé a ń gbé nínú ayé kan nínú èyí tí a ti ń fògo fún ìwàpálapàla ìbálòpọ̀, ìwà ọ̀daràn, àti ìfẹ́ ọrọ̀-àlùmọ́nì—tí a sì ń gbé e jáde ní gbangba wálíà àti ní fàlàlà nínú àwọn ìwé, ìwé ìròyìn, àwòrán sinimá, àwọn ìtòlẹ́sẹẹsẹ tẹlifíṣọ̀n, àti àwọn orin gbígbajúmọ̀—níti gidi ni àwọn ìrònú àti èrò-ọkàn tí kò tọ́ ń rọ́lù wá lójoojúmọ́. Kí ni ìhùwàpadà rẹ? Gbogbo èyí ha ń pa ọ́ lẹ́rìn-ín tí ó sì ń dá ọ lárayá bí? Tàbí ìmọ̀lára rẹ ha rí bíi ti Loti olódodo, “ẹni tí ìwà wọ̀bìà àwọn ènìyàn búburú bà nínú jẹ́ . . . [tí] ìwà búburú wọn ń ba ọkàn òtítọ́ rẹ̀ jẹ́”? (2 Peteru 2:7, 8) Láti kẹ́sẹjárí nínú gbígbéjàko ìwàmú ẹ̀ṣẹ̀ lórí ẹran-ara ẹlẹ́ṣẹ̀, a gbọ́dọ̀ pinnu láti ṣe gẹ́gẹ́ bí onípsalmu náà ti ṣe: “Èmi kì yóò gbé ohun búburú síwájú mi: èmi kórìíra iṣẹ́ àwọn tí ó yapa, kì yóò fi ara mọ́ mi.”—Orin Dafidi 101:3.
Gbígbé Èrò-Inú Ka Orí Ẹ̀mí
15. Ìrànwọ́ wo ni a ní láti gbógunti ìwàmú ẹ̀ṣẹ̀ lórí wa?
15 Ohun kan tí ó lè ràn wá lọ́wọ́ láti gbéjàko ìwàmú ẹ̀ṣẹ̀ lórí ẹran-ara ẹlẹ́ṣẹ̀ ni ohun tí Paulu ń báa nìṣó láti sọ pé: “Gbígbé èrò-inú ka orí ẹ̀mí túmọ̀ sí ìyè ati àlàáfíà.” (Romu 8:6, NW) Nípa báyìí, dípò kí a jẹ́ kí ẹran-ara jọba lé wa lórí, a gbọ́dọ̀ jẹ́ kí èrò-inú wa wá sábẹ́ agbára ìdarí ẹ̀mí kí àwọn nǹkan ti ẹ̀mí sì mú kí ó dàgbàsókè. Kí ni àwọn nǹkan náà? Ní Filippi 4:8 (NW), Paulu ṣe àkọsílẹ̀ wọn: “Lákòótán, ẹ̀yin ará, ohun yòówù tí ó jẹ́ òótọ́, ohun yòówù tí ó jẹ́ ti ìdàníyàn ṣíṣe pàtàkì, ohun yòówù tí ó jẹ́ òdodo, ohun yòówù tí ó jẹ́ mímọ́níwà, ohun yòówù tí ó dára ní fífẹ́, ohun yòówù tí a ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ dáadáa, ìwà funfun yòówù tí ó bá wà, ohun yòówù tí ó bá sì wà tí ó yẹ fún ìyìn, ẹ máa bá a lọ ní gbígba nǹkan wọnyi rò.” Ẹ jẹ́ kí a wò ó fínnífínní kí a sì túbọ̀ ní òye nípa ohun tí a níláti máa báa nìṣó láti gbéyẹ̀wò.
16. Àwọn ànímọ́ wo ni Paulu fún wa ní ìṣírí láti ‘máa báa lọ ní gbígbàrò,’ kí sì ni ọ̀kọ̀ọ̀kan ní nínú?
16 Lákọ̀ọ́kọ́ ná, Paulu ṣe àkọsílẹ̀ àwọn ànímọ́ ìwàrere mẹ́jọ ó sì lo ọ̀rọ̀ náà “yòówù” ṣáájú ọ̀kọ̀ọ̀kan. Gbólóhùn yìí fihan pé a kò ká àwọn Kristian lọ́wọ́kò láti máa ronú lórí kìkì àwọn nǹkan tí ó jẹ́ ti Ìwé Mímọ́ tàbí àwọn ọ̀ràn ti ẹ̀kọ́-ìgbàgbọ́ ní gbogbo ìgbà. Ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn kókó-ẹ̀kọ́ gbígbòòrò tàbí àwọn àkòrí ní ń bẹ tí a lè gbé èrò-inú wa kà. Ṣùgbọ́n ohun tí ó ṣe pàtàkì ni pé wọ́n gbọ́dọ̀ kúnjú òṣùwọ̀n àwọn ànímọ́ ìwàrere tí Paulu là sílẹ̀. Ọ̀kọ̀ọ̀kan nínú ọ̀wọ́ àwọn “ohun” tí Paulu tọ́kasí yẹ fún àfiyèsí wa. Ẹ jẹ́ kí a gbé wọn yẹ̀wò ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé.
◻ “Òótọ́” ní nínú ju wíwulẹ̀ jẹ́ òtítọ́ tàbí èké. Ó túmọ̀sí jíjẹ́ olóòótọ́, adúróṣinṣin, àti aṣeégbẹ́kẹ̀lé, ohun kan tí ó jẹ́ gidi, tí kò wulẹ̀ fúnni ní ìrísí jíjẹ́ bẹ́ẹ̀ lásán.—1 Timoteu 6:20.
◻ “Tí ó jẹ́ ti ìdàníyàn ṣíṣe pàtàkì” tọ́kasí àwọn nǹkan tí ó níyì tí ó sì kún fún ọ̀wọ̀. Ó ń ṣàgbéyọ agbára ìmòye ọ̀wọ̀-ńlá, ohun kan tí ó ga fíofío, tí ó gbayì, tí ó sì lọ́lá dípò kí ó jẹ́ ti alásèé àti ẹlẹ́gàn.
◻ “Òdodo” túmọ̀sí tí ó kúnjú ìwọ̀n àwọn ọ̀pá ìdíwọ̀n Ọlọrun, kìí ṣe ti ènìyàn. Àwọn ènìyàn ayé fi àwọn èrò àìṣòdodo kún inú èrò-ọkàn wọn, ṣùgbọ́n ó yẹ kí àwa ronú lé àwọn nǹkan tí ó jẹ́ òdodo lójú Ọlọrun lórí kí a sì ní inúdídùn nínú wọn.—Fiwé Orin Dafidi 26:4; Amosi 8:4-6.
◻ “Mímọ́níwà” túmọ̀sí mímọ́gaara àti mímọ́ kìí ṣe nínú ìwà (ìbálòpọ̀ tàbí lọ́nà mìíràn) nìkan ṣùgbọ́n nínú ìrònú àti ète ìsúnniṣe pàápàá. Jakọbu sọ pé, “Ọgbọ́n tí ó wá lati òkè á kọ́kọ́ mọ́níwà.” Jesu, ẹni tí ó “mọ́ gaara,” ni Àpẹẹrẹ pípé fún wa láti gbéyẹ̀wò.—Jakọbu 3:17, NW; 1 Johannu 3:3 NW.
◻ Ohun tí ó “dára ní fífẹ́” ni èyí tí ń runisókè tí ó sì ń súnni láti ní ìfẹ́ nínú àwọn ẹlòmíràn. Ó yẹ “kí a yẹ araawa wò láti ru araawa sí ìfẹ́ àti sí iṣẹ́ rere,” dípò kí a fi èrò-inú wa sórí àwọn nǹkan tí ń ru ìkórìíra, ìbìnújẹ́ kíkorò, àti asọ̀ sókè.—Heberu 10:24.
◻ “Tí a ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ dáadáa” kò wulẹ̀ túmọ̀sí “tí a ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ ní rere” tàbí “tí ó ní ìròyìn rere” nìkan ṣùgbọ́n, ní èrò ìtumọ̀ ohun tí a ń ṣe, jíjẹ́ agbéniró àti olùgbóríyìn fúnni. A gbé èrò-inú wa karí àwọn nǹkan tí ó sunwọ̀n tí ó sì ń gbéniró dípò èyí tí ń sọni di yẹpẹrẹ tí ó sì ń ṣeni ní láìfí.—Efesu 4:29.
◻ “Ìwà funfun” ní ìpìlẹ̀ túmọ̀sí “ìwàrere-ìṣeun” tàbí “ìtayọlọ́lá níti ìwàrere,” ṣùgbọ́n ó lè túmọ̀sí irú ìtayọlọ́lá èyíkéyìí. Nípa báyìí, a lè mọrírì àwọn ànímọ́, ìtóye, àti àṣeparí ṣíṣeyebíye ti àwọn ẹlòmíràn ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ọ̀pá ìdíwọ̀n ti Ọlọrun.
◻ Àwọn nǹkan “tí ó yẹ fún ìyìn” yẹ nítòótọ́ bí ìyìn náà bá wá láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun tàbí láti ọ̀dọ̀ ọlá-àṣẹ tí òun tẹ́wọ́gbà lọ́nà yíyẹ.—1 Korinti 4:5; 1 Peteru 2:14.
Ìlérí Ìyè àti Àlàáfíà
17. Àwọn ìbùkún wo ní ń jẹyọ láti inú “gbígbé èrò-inú ka orí ẹ̀mí”?
17 Nígbà tí a bá tẹ̀lé ìṣílétí Paulu tí a sì ń “bá a lọ ní gbígba nǹkan wọnyi rò,” àwa yóò kẹ́sẹjárí nínú “gbígbé èrò-inú ka orí ẹ̀mí.” Ìyọrísí náà kìí wulẹ̀ ṣe ìbùkún ìyè nìkan, ìyẹn ni pé, ìyè àìnípẹ̀kun nínú ayé titun náà tí a ṣèlérí, ṣùgbọ́n àlàáfíà pẹ̀lú. (Romu 8:6) Èéṣe? Nítorí pé èrò-inú wa ni a dáàbòbò kúrò lọ́wọ́ agbára ìdarí ibi tí àwọn nǹkan ti ara, ìjàkadì tí ń múni jẹ̀rora láàárín ẹran-ara àti ẹ̀mí gẹ́gẹ́ bí Paulu ti ṣàpèjúwe rẹ̀ kò sì tún nípa púpọ̀ lórí wa mọ́. Nípa dídènà agbára ìdarí ẹran-ara, a tún ń jèrè àlàáfíà pẹ̀lú Ọlọrun “nitori pé gbígbé èrò-inú ka orí ẹran-ara túmọ̀ sí ìṣọ̀tá pẹlu Ọlọrun.”—Romu 7:21-24; 8:7, NW.
18. Ogun wo ni Satani ń gbé dìde, báwo sì ni a ṣe lè jagunmólú?
18 Satani àti àwọn aṣojú rẹ̀ ń ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe láti sọ gbígbé tí a ń gbé ògo Ọlọrun yọ di bàìbàì. Wọ́n ń gbìyànjú láti jèrè agbára ìdarí lórí èrò-inú wa nípa fífi àwọn ìfẹ́-ọkàn ti ẹran-ara gbóguntì wọ́n, ní mímọ̀ pé èyí yóò jásí ìṣọ̀tá pẹ̀lú Ọlọrun àti ikú ní àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀. Ṣùgbọ́n a lè jagunmólú nínú ogun yìí. Bíi ti Paulu, àwa pẹ̀lú lè polongo pé: “Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọrun nípasẹ̀ Jesu Kristi Oluwa wa” fún pípèsè ọ̀nà tí a lè gbà gbógunti ìwàmú ẹ̀ṣẹ̀ lórí ẹran-ara ẹlẹ́ṣẹ̀ fún wa.—Romu 7:25.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Bibeli sábà máa ń lo ọ̀rọ̀-ìṣe Heberu náà cha·taʼʹ àti ọ̀rọ̀-ìṣe Griki náà ha·mar·taʹno láti dúró fún “ẹ̀ṣẹ̀.” Àwọn ọ̀rọ̀ méjèèjì wọ̀nyí túmọ̀sí “kùnà,” ní èrò ìtumọ̀ kíkùnà tàbí ṣíṣàì lé góńgó, àmì, tàbí ohun àfojúsùn kan bá.
b Ní ìbámu pẹ̀lú ẹ̀kọ́ àtọwọ́dọ́wọ́, àwọn ẹ̀ṣẹ̀ méje tí wọ́n lè yọrísí ikú náà ni ìgbéraga, ojúkòkòrò, ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́, ìlara, àjẹkì, ìbínú, àti ìmẹ́lẹ́.
Ìwọ Ha Lè Ṣàlàyé Bí?
◻ Kí ni ẹ̀ṣẹ̀, báwo sì ni ó ṣe lè mú ìwàmú lórí ẹran-ara àìpé dàgbà?
◻ Báwo ni a ṣe lè gbógunti “gbígbé èrò-inú ka orí ẹran-ara”?
◻ Kí ni a lè ṣe láti gbé “gbígbé èrò-inú ka orí ẹ̀mí” lárugẹ?
◻ Báwo ni “gbígbé èrò-inú ka orí ẹ̀mí” ṣe ń mú ìyè àti àlàáfíà wá?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Kaini gba àwọn ìtẹ̀sí ti ẹran-ara láyè láti jọba lé òun lórí sí ìparun rẹ̀
[Àwọ̀n àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]
Gbígbé èrò-inú ka orí ẹ̀mí túmọ̀ sí ìyè ati àlàáfíà