Kí Ni Ó Ti Ṣẹlẹ̀ Sí Ọlá-àṣẹ?
ÀWỌN onírònú ènìyàn rí àìní náà fún ọlá-àṣẹ. Láìsí ìgbékalẹ̀ irú ọlá-àṣẹ kan, ní kíákíá ni ẹgbẹ́ àwùjọ ẹ̀dá ènìyàn yóò di júujùu. Nípa báyìí, ìwé-ẹ̀kọ́ àkàkọ́gbọ́n kan lédè French nípa àwọn ìlànà òfin sọ pé: “Nínú àwùjọ ẹ̀dá ènìyàn èyíkéyìí, ìṣọ̀wọ́ àwọn ènìyàn méjì ni a lè rí: àwọn tí ń pàṣẹ àti àwọn tí ń ṣègbọràn, àwọn tí ń fúnni ní ìtọ́ni àti àwọn tí ń faramọ́ ọn, àwọn aṣáájú àti àwọn mẹ́ḿbà, àwọn olùṣàkóso àti àwọn tí a ń ṣàkóso. . . . Wíwà ọlá-àṣẹ ni a lè kíyèsí nínú ẹgbẹ́ àwùjọ ẹ̀dá-ènìyàn èyíkéyìí.”a
Bí ó ti wù kí ó rí, ìṣarasíhùwà sí ọlá-àṣẹ ti yípadà láti ìgbà Ogun Àgbáyé Kejì àti ní pàtàkì láti àwọn ọdún 1960 wá. Ní ṣíṣàlàyé lórí sáà yẹn, ìwé French náà Encyclopædia Universalis sọ nípa “yánpọnyánrin àwọn aṣòdìsí ẹgbẹ́ àwọn aláṣẹ àti àwọn aṣòdìsí ọlá-àṣẹ.” Irú yánpọnyánrin bẹ́ẹ̀ kò jẹ́ ìyàlẹ́nu fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bibeli. Aposteli Paulu sọtẹ́lẹ̀ pé: “Rántí, sànmánì ìkẹyìn ayé yìí níláti jẹ́ àkókò rúkèrúdò! Àwọn ènìyàn kì yóò nífẹ̀ẹ́ ohunkóhun bíkòṣe araawọn àti owó; wọn yóò jẹ́ olùṣògo, olùfẹgẹ̀, àti ẹlẹ́ẹ̀kẹ́-èébú; aṣàìgbọ́ràn sí òbí . . . ; wọn yóò jẹ́ aláìṣeérọ̀lọ́kàn nínú ìkórìíra wọn, . . . aláìṣeéṣàkóso àti oníwà-ipá, . . . tí ń wú fùkẹ̀ nítorí ìjọra-ẹni-lójú. Wọn yóò nífẹ̀ẹ́ adùn wọn ju Ọlọrun wọn lọ.”—2 Timoteu 3:1-4, The Revised English Bible.
Yánpọnyánrin Bá Ọlá-Àṣẹ
Àsọtẹ́lẹ̀ yìí ṣàpèjúwe ọjọ́ àti sànmánì wa dáradára. Ọlá-àṣẹ ni a ń pèníjà ní ìpele ipò gbogbo—ìdílé, ilé-ẹ̀kọ́ fún gbogbo ènìyàn, yunifásítì, ìdáwọ́lé iṣẹ́-ajé, àkóso ìbílẹ̀ àti ti orílẹ̀-èdè. Ìyípadà tegbòtigàgá níti ìbálòpọ̀, àwọn orin ọlọ́rọ̀ wótòwótò rírọrùn jùlọ, ìwọ́de àwọn ọmọ ilé-ẹ̀kọ́, ìyanṣẹ́lódì àwọn díẹ̀ nínú ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́, àìgbàfúnjọba, àti àwọn ìwà ìdáyàfoni ni gbogbo wọn jẹ́ àmì ìwólulẹ̀ ọ̀wọ̀ fún ọlá-àṣẹ.
Níbi ìpàdé àpínsọ ọ̀rọ̀ àsọyé kan tí Àjọ Ètò Ẹ̀kọ́ Ìmọ̀ Ìjìnlẹ̀ Ìṣèlú ti France àti àwọn oníwèé ìròyìn ojoojúmọ́ náà Le Monde ti Paris ṣètò fún, Ọ̀jọ̀gbọ́n Yves Mény wí pé: “Ọlá-àṣẹ lè wà kìkì bí a bá fi ìbófinmu tì í lẹ́yìn.” Ìdí kan fún yánpọnyánrin tí ó bá ọlá-àṣẹ lónìí ni pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ń ṣiyèméjì nípa ìbófinmu àwọn wọnnì tí ń bẹ nípò. Ìyẹn ni pé, wọ́n ṣiyèméjì nípa ẹ̀tọ́ wọn láti ní ọlá-àṣẹ lọ́wọ́. Ìwádìí-èrò kan ṣípayá pé ní kùtùkùtù àwọn ọdún 1980, ìpín 9 nínú ọgọ́rùn-ún iye àwọn olùgbé United States, ìpín 10 nínú ọgọ́rùn-ún ní Australia, ìpín 24 nínú ọgọ́rùn-ún ní Britain, ìpín 26 nínú ọgọ́rùn-ún ní France, àti ìpín 41 nínú ọgọ́rùn-ún ní India ka ìjọba wọn sí èyí tí kò bófinmu.
Ìwákiri Ènìyàn fún Ọlá-Àṣẹ tí Ó Bófinmu
Gẹ́gẹ́ bí Bibeli ti sọ, ní ìpilẹ̀ṣẹ̀ ènìyàn wà lábẹ́ ọlá-àṣẹ tààràtà láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun. (Genesisi 1:27, 28; 2:16, 17) Bí ó ti wù kí ó rí, láti ìbẹ̀rẹ̀ wá, ẹ̀dá ènìyàn béèrè fún ẹ̀tọ́ òmìnira ìwàhíhù lọ́wọ́ Ẹlẹ́dàá wọn. (Genesisi 3:1-6) Níwọ̀n bí wọ́n ti kọ ìṣàkóso Ọlọrun, tàbí àkóso Ọlọrun sílẹ̀, wọ́n níláti wá àwọn ètò-ìgbékalẹ̀ mìíràn fún ọlá-àṣẹ. (Oniwasu 8:9) Àwọn kan fi tipátipá gbé ọlá-àṣẹ wọn kanilórí. Níti wọn, agbára ni wọ́n kà sí ẹ̀tọ́ tí wọ́n ní. Ó ti tẹ́ wọn lọ́rùn pé wọ́n ní agbára tó láti múni ṣe ìfẹ́-inú wọn. Ṣùgbọ́n, ọ̀pọ̀ jùlọ nímọ̀lára àìní náà láti mú ẹ̀tọ́ wọn láti ṣàkóso bófinmu.
Láti ìgbà ìjímìjí wá àwọn alákòóso púpọ̀ ṣe èyí yálà nípa sísọ pé àwọn jẹ́ ọlọrun tàbí pé àwọn ti gba agbára àwọn láti ọ̀dọ̀ àwọn ọlọrun. Èyí ni èrò àròsọ àtọwọ́dọ́wọ́ náà tí ń bẹ lẹ́yìn “ipò mímọ́ ọlọ́wọ̀ ti àwọn ọba,” tí àwọn alákòóso ìjímìjí kan ní Mesopotamia àti àwọn Farao Egipti ìgbàanì jẹ́wọ́ rẹ̀.
Alexander Ńlá, àwọn ọba Heleni tí wọ́n jẹ tẹ̀lé e, àti ọ̀pọ̀ lára àwọn olú-ọba Romu pẹ̀lú tún jẹ́wọ́ pé àwọn jẹ́ ọlọrun tí wọ́n sì béèrè pé kí a jọ́sìn àwọn pàápàá. Ètò ìgbékalẹ̀ lábẹ́ irú àwọn alákòóso bẹ́ẹ̀ ni a mọ̀ sí “ìsìn-awo àwọn alákòóso,” ète wọn sì ni láti mú ọlá-àṣẹ alákòóso náà lágbára lórí àpapọ̀ àwọn ènìyàn tí wọ́n ṣẹ́gun. Kíkọ̀ láti jọ́sìn alákòóso ni a dẹ́bi fún gẹ́gẹ́ bí ìgbésẹ̀ kan ní ìlòdìsí Ìjọba Orílẹ̀-Èdè. Nínú ìwé náà The Legacy of Rome Ọ̀jọ̀gbọ́n Ernest Barker kọ̀wé pé: “Sísọ àwọn olú-ọba [Romu] di ọlọrun, àti ìtúúbáfọ́ba tí òun ń rígbà nítorí ọlá-àṣẹ àtọ̀runwá rẹ̀, ni ó ṣe kedere pé ó jẹ́ ìpìlẹ̀, tàbí bí ó ti wù kí ó jẹ́, ohun náà tí ó so ilẹ̀-ọba náà papọ̀.”
Èyí jẹ́ òtítọ́ síbẹ̀ àní lẹ́yìn ìgbà tí Olú-Ọba Constantine (tí ó ṣàkóso ní 306 sí 337 C.E.) mú “Ìsìn Kristian” bófinmu tí Olú-Ọba Theodosius Kìn-ín-ní (tí ó ṣàkóso ní 379 sí 395 C.E.) sì tẹ́wọ́gbà á lẹ́yìn náà gẹ́gẹ́ bí ìsìn Ìjọba Orílẹ̀-Èdè ti Ilẹ̀-Ọba Romu. Díẹ̀ lára àwọn olú-ọba náà tí wọ́n jẹ́ “Kristian” ni a jọ́sìn gẹ́gẹ́ bí ọlọrun títí tí ó fi di ọ̀rúndún karùn-ún C.E.
“Agbára Méjì,” “Idà Méjì”
Bí ìlànà àkóso póòpù ti túbọ̀ ń lágbára síi, àwọn ìṣòro láàárín Ṣọ́ọ̀ṣì àti ìjọba Orílẹ̀-Èdè di èyí tí ó légbákan. Nípa báyìí, ní òpin ọ̀rúndún karùn-ún C.E., Popu Gelasius Kìn-ín-ní gbé ìlànà “agbára méjì” kalẹ̀: ọlá-àṣẹ mímọ́ ọlọ́wọ̀ ti àwọn póòpù tí ó jùmọ̀ wà pẹ̀lú agbára kábíyèsí ti àwọn ọba—ti àwọn ọba sì wà lábẹ́ tí àwọn póòpù. Lẹ́yìn náà ni ìlànà yìí dàgbàsókè di ẹ̀kọ́ ìgbàgbọ́ “idà méjì”: “Idà tẹ̀mí ni àwọn póòpù fúnraawọn ń fi agbára lò, ní yíyan idà ti ìlú fún àwọn alákòóso tí kìí ṣe aláṣẹ ní ṣọ́ọ̀ṣì, ṣùgbọ́n bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀ àwọn alákòóso gbọ́dọ̀ lo idà ti ìlú ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ìtọ́sọ́nà póòpù.” (The New Encyclopædia Britannica) Lórí ìpìlẹ̀ ẹ̀kọ́-ìgbàgbọ́ yìí, ní àwọn Sànmánì Agbedeméjì, Ṣọ́ọ̀ṣì Katoliki jẹ́wọ́ níní ẹ̀tọ́ náà láti dádé fún àwọn olú-ọba àti àwọn ọba kí wọ́n baà lè mú ọlá-àṣẹ wọn bófinmu, ní títipa báyìí mú kí àròsọ àtọwọ́dọ́wọ́ ti “ipò mímọ́ ọlọ́wọ̀ ti àwọn ọba” máa wà títílọ kánrin.
Bí ó ti wù kí ó rí, a kò gbọ́dọ̀ da èyí pọ̀ mọ́ ẹ̀tọ́ àtọ̀runwá tí a fẹnu lásán pè ní ti àwọn ọba, ìdàgbàsókè kan tí a wéwèé rẹ̀ lẹ́yìn náà láti sọ àwọn alákòóso òṣèlú dòmìnira kúrò lọ́wọ́ ìtẹríba fún ìlànà àkóso póòpù. Àbá èrò-orí ẹ̀tọ́ àtọ̀runwá náà gbà pé ní tààràtà láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun wá ni àwọn ọba ti rí ọlá-àṣẹ wọn láti ṣàkóso gbà, kìí ṣe nípasẹ̀ póòpù ti Romu. Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ New Catholic Encyclopedia sọ pé: “Ní àkókò kan nígbà tí póòpù ń lo agbára tẹ̀mí àti èyí tí ó jẹ́ ti ara pàápàá lé àwọn olórí orílẹ̀-èdè lágbàáyé lórí, èrò nípa ẹ̀tọ́ àtọ̀runwá fi àwọn ọba ti ìpínlẹ̀ orílẹ̀-èdè sí àyè ipò kan láti dá ọlá-àṣẹ wọn láre gẹ́gẹ́ bí èyí tí ó jẹ́ ti àtọ̀runwá bíi ti póòpù.”b
Àròsọ Àtọwọ́dọ́wọ́ ti Ọwọ́ Ènìyàn Ni Ọlá-Àṣẹ Wà
Bí àkókò ti ń kọjá lọ, àwọn ènìyàn dámọ̀ràn orísun ọlá-àṣẹ mìíràn. Ọ̀kan ni pé ọwọ́ ènìyàn ni ọlá-àṣẹ wà. Ọ̀pọ̀ gbàgbọ́ pé èrò yìí wá láti Greece. Bí ó ti wù kí ó rí, ìjọba dẹmọ ti Griki ìgbàanì ni a ń ṣe ní kìkì àwọn ìpínlẹ̀ adájọbaṣe díẹ̀, àti pé nínú ìwọ̀nyí pẹ̀lú kìkì àwọn ọlọ̀tọ̀ tí wọ́n jẹ́ ọkùnrin ni wọ́n dìbò. Àwọn obìnrin, ẹrú, àti àtìpó olùgbé—tí a fojúbu iye wọn sí ìdajì sí nǹkan bí ìdámẹ́rin nínú márùn-ún lára àwọn olùgbé ìlú—ni a yọ sílẹ̀. Agbára káká ni ọlá-àṣẹ fi wà lọ́wọ́ ènìyàn!
Ta ni ṣagbátẹrù èrò náà pé ọwọ́ ènìyàn ni ọlá-àṣẹ wà? Lọ́nà tí ó yanilẹ́nu, àwọn ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn Roman Katoliki ni wọ́n mú un wọlé wá ní Sànmánì Agbedeméjì. Ní ọ̀rúndún kẹtàlá, Thomas Aquinas gbà pé nígbà tí ipò ọba aláṣẹ jẹ́ ti Ọlọrun, a ti gbé e wọ àwọn ènìyàn. Èrò yìí jásí èyí tí ó gbajúmọ̀. Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ New Catholic Encyclopedia sọ pé: “Èrò pé àwọn ènìyàn jẹ́ orísun ọlá-àṣẹ yìí ni ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ àwọn ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn Katoliki ti ọ̀rúndún kẹtàdínlógún tìlẹ́yìn.”
Èéṣe tí àwọn ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn ṣọ́ọ̀ṣì kan nínú èyí tí àwọn ènìyàn kò ti lẹ́nu ọ̀rọ̀ rárá láti yan póòpù, bíṣọ́ọ̀bù, tàbí àlùfáà fi níláti gbé èrò náà pé ọwọ́ ènìyàn ni ọlá-àṣẹ wà lárugẹ? Nítorí pé àwọn ọba kan ní ilẹ̀ Europe túbọ̀ ń di alára àìbalẹ̀ lábẹ́ ọlá-àṣẹ póòpù. Àbá-èrò-orí náà pé ọwọ́ ènìyàn ni ọlá-àṣẹ wà fún póòpù ní agbára náà láti rọ olú-ọba tàbí ọba aládé kan lóyè bí ó bá dàbí ohun tí ó pọndandan. Àwọn òpìtàn Will àti Ariel Durant kọ̀wé pé: “Lára àwọn olùgbèjà àbá-èrò-orí náà pé ọwọ́ ènìyàn ni ọlá-àṣẹ wà ní a rí ọ̀pọ̀ àwọn onísìn Jesuit, tí wọ́n rí ọ̀nà kan láti gba sọ ọlá-àṣẹ ti ọba di aláìlágbára ní ìfiwéra pẹ̀lú ti póòpù nínú ojú-ìwòye yìí. Kádínà Bellarmine ṣàlàyé pé, bí ọlá-àṣẹ àwọn ọba bá ti ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn wá, tí ó sì tipa bẹ́ẹ̀ wà lábẹ́ agbára wọn, ó ṣe kedere pé ó rẹlẹ̀ sí ọlá-àṣẹ ti àwọn póòpù . . . Luis Molina, ará Spain kan tí ó jẹ́ onísìn Jesuit, parí èrò pé àwọn ènìyàn, gẹ́gẹ́ bí orísun ọlá-àṣẹ ti ayé, lè rọ ọba aláìṣòdodo kan lóyè lọ́nà tí ó bá ìdájọ́ òdodo mu—ṣùgbọ́n nípasẹ̀ ọ̀nà ìgbàṣiṣẹ́ tí ó wà létòlétò.”
Àmọ́ ṣáá o, “ọ̀nà ìgbàṣiṣẹ́ tí ó wà létòlétò” náà ni póòpù níláti ṣètò fun. Ní fífìdí ẹ̀rí èyí múlẹ̀, ìwé Katoliki náà Histoire Universelle de l’Eglise Catholique lédè French fa ọ̀rọ̀ Biographie universelle yọ, èyí tí ó sọ pé: “Bellarmine . . . kọ́ni gẹ́gẹ́ bí ẹ̀kọ́ ìgbàgbọ́ wíwọ́pọ̀ ti Katoliki pé àwọn ọmọkùnrin ọba ń rí agbára wọn gbà láti inú yíyàn àwọn ènìyàn, àti pé àwọn ènìyàn náà lè lo ẹ̀tọ́ yìí kìkì lábẹ́ agbára ìdarí póòpù.” (Ìkọ̀wé wínníwínní jẹ́ tiwa.) Àbá-èrò-orí náà pé ọwọ́ ènìyàn ni ọlá-àṣẹ wà wá tipa báyìí di irin-iṣẹ́ kan tí póòpù lè lò láti lo agbára ìdarí lórí yíyàn àwọn alákòóso àti, bí ó bá yẹ bẹ́ẹ̀, kí ó mú kí a rọ̀ wọ́n lóyè. Ní àwọn àkókò tí ó túbọ̀ jẹ́ ti lọ́ọ́lọ́ọ́, ó ti fàyègba ẹgbẹ́ àwọn àlùfáà olùṣàkóso láti lo agbára ìdarí lórí àwọn Katoliki olùdìbò nínú àwọn ìjọba dẹmọ tí a ti ń ṣojúfúnni.
Nínú ìjọba dẹmọ ti òde-òní ìṣàkóso kan tí ó bófinmu ni a gbékarí ohun tí a ń pè ní “ìfohùnṣọ̀kan àwọn tí a ń ṣàkóso.” Ṣùgbọ́n, ó dára tán, èyí jẹ́ “ìfohùnṣọ̀kan àwọn tí ó pọ̀ jùlọ,” àti pé nítorí ẹ̀mí àgunlá àwọn olùdìbò àti békebèke òṣèlú, “àwọn tí ó pọ̀ jùlọ” yìí níti gidi sábà máa ń jẹ́ kìkì àwọn tí ó kéré jùlọ lára àwọn olùgbé ìlú. Lónìí, “ìfohùnṣọ̀kan àwọn tí a ń ṣàkóso” sábà máa ń túmọ̀sí “gbígbà láìjampata, tàbí ìjuwọ́sílẹ̀, àwọn tí a ń ṣàkóso.”
Àròsọ Àtọwọ́dọ́wọ́ ti Ọwọ́ Orílẹ̀-Èdè Ni Ọlá-Àṣẹ Wà
Àròsọ àtọwọ́dọ́wọ́ nípa ipò mímọ́ ọlọ́wọ̀ ti àwọn ọba tí àwọn póòpù ìjímìjí ṣagbátẹrù rẹ̀ ní ìyọrísí òdìkejì lórí ìlànà àkóso póòpù nígbà tí ó yípadà di ẹ̀tọ́ àtọ̀runwá ti àwọn ọba. Lọ́nà kan náà àbá-èrò-orí náà pé ọwọ́ ènìyàn ni ọlá-àṣẹ wà tún tapadà sórí Ṣọ́ọ̀ṣì Katoliki. Ní ọ̀rúndún kẹtàdínlógún àti ìkejìdínlógún, àwọn ọlọ́gbọ́n ìmọ̀-ọ̀ràn ti ayé, bí àwọn ọkùnrin ilẹ̀ England náà Thomas Hobbes àti John Locke àti ọkùnrin ilẹ̀ France Jean-Jacques Rousseau, ronú padà sẹ́yìn lórí àbá-èrò náà pé ọwọ́ ènìyàn ni ọlá-àṣẹ wà. Wọ́n mú àwọn ẹ̀dà ìtumọ̀ àbá-èrò-orí nípa “àdéhùn ẹgbẹ́-òun-ọ̀gbà” dàgbà láàárín àwọn olùṣàkóso àti àwọn tí a ń ṣàkóso. Àwọn ìlànà wọn ni a kò gbékarí ẹ̀kọ́ ìsìn bíkòṣe “òfin àdánidá,” èròǹgbà náà sì parí sí àwọn èrò tí ó pa Ṣọ́ọ̀ṣì Katoliki àti ìlànà àkóso póòpù lára lọ́nà tí ó léwu.
Kété lẹ́yìn ikú Rousseau, Ìyíìpilẹ̀dà Ilẹ̀ France bẹ́sílẹ̀. Ìyíìpilẹ̀dà yìí ba àwọn èrò pàtó kan nípa ìbófinmu jẹ́, ṣùgbọ́n ó dá titun sílẹ̀, èrò pé ọwọ́ orílẹ̀-èdè ni ọlá-àṣẹ wà. The New Encyclopædia Britannica ṣàlàyé pé: “Àwọn ọmọ ilẹ̀ France kọ̀ láti tẹ́wọ́gba ẹ̀tọ́ àtọ̀runwá tí àwọn ọba ní, ìgòkè ipò-ọba àwọn ọ̀tọ̀kùlú, àwọn àǹfààní Ṣọ́ọ̀ṣì Roman Katoliki.” Ṣùgbọ́n, gbédègbẹ́yọ̀ Britannica sọ pé, “Ìyíìpilẹ̀dà náà ti mú kí ìhùmọ̀ titun náà, orílẹ̀-èdè adájọbaṣe, dàgbà di ńlá.” Àwọn ayíìpilẹ̀dà náà nílò “ìhùmọ̀” titun yìí. Èéṣe?
Nítorí pé lábẹ́ ètò ìgbékalẹ̀ náà Rousseau ti gbẹnusọ pé, gbogbo àwọn ọlọ̀tọ̀ yóò lẹ́nu ọ̀rọ̀ bákan náà nínú yíyan àwọn alákòóso. Èyí ìbá ti yọrísí ìjọba dẹmọ tí a gbékarí ẹ̀tọ́ gbogbo ènìyàn láti dìbò—ohun kan tí àwọn aṣáájú Ìyíìpilẹ̀dà Ilẹ̀ France kò fojúrere hàn sí. Ọ̀jọ̀gbọ́n Duverger ṣàlàyé pé: “Ní pàtó ó jẹ́ láti yẹra fún ìyọrísí yìí, tí a kà sí èyí tí kò yẹ, pé, láti 1789 sí 1791, àwọn abẹnugan tí wọ́n jẹ́ mẹ́ḿbà Ìgbìmọ̀ Atófinṣe hùmọ̀ àbá-èrò-orí pé ọwọ́ orílẹ̀-èdè ni ọlá-àṣẹ wà. Wọ́n ka àwọn ènìyàn sí apákan ‘Orílẹ̀-Èdè,’ èyí tí wọ́n kà sí ohun kan tí ó wà ní ààyè ọ̀tọ̀, tí ó yàtọ̀ sí àwọn apá tí ó ní nínú. Nípasẹ̀ àwọn aṣojú rẹ̀, Orílẹ̀-Èdè nìkanṣoṣo ni a fún ní agbára láti lo ọlá-àṣẹ . . . Bí ó tilẹ̀ ní ìrísí bíi ti dẹmọ, ẹ̀kọ́ ìgbàgbọ́ pé ọwọ́ orílẹ̀-èdè ni ọlá-àṣẹ wà níti tòótọ́ kò bá ìlànà dẹmọ mu rárá nítorí pé a lè lò ó níti gidi láti dáre fún irú ìjọba èyíkéyìí kan, ní pàtàkì ìjọba alágbára àìláàlà lọ́wọ́ ẹnìkan ṣoṣo.” (Ìkọ̀wé wínníwínní jẹ́ tirẹ̀.)
Ìsapá Ẹ̀dá Ènìyàn Jásí Pàbó
Ìtẹ́wọ́gba Orílẹ̀-Èdè Adájọbaṣe gẹ́gẹ́ bí orísun tí ó bófinmu fún ọlá-àṣẹ jálẹ̀ sí ìfẹ́ orílẹ̀-èdè ẹni. Gbédègbẹ́yọ̀ The New Encyclopædia Britannica sọ pé: “Ìfẹ́ orílẹ̀-èdè ẹni ni a sábà máa ń rò pé ọjọ́ rẹ̀ ti pẹ́ púpọ̀; nígbà mìíràn a máa ń fi àṣìṣe kà á sí kókó abájọ wíwà títílọ kan nínú ìwà tí ó jẹmọ́ òṣèlú. Níti gidi, àwọn ìyíìpilẹ̀dà ti ilẹ̀ America àti ti ilẹ̀ France ni a lè kà sí àwọn ọ̀nà lílágbára tí ó gbà farahàn lákọ̀ọ́kọ́.” Láti ìgbà àwọn ìyíìpilẹ̀dà wọ̀nyẹn, ìfẹ́ orílẹ̀-èdè ẹni ti gbèèràn dé àwọn ilẹ̀ America, Europe, Africa, àti Asia. Àwọn ogun rírorò ni a ti mú bófinmu ní orúkọ ìfẹ́ orílẹ̀-èdè ẹni.
Òpìtàn ilẹ̀ Britain náà Arnold Toynbee kọ̀wé pé: “Ẹ̀mí Ìfẹ́ Orílẹ̀-Èdè Ẹni jẹ́ ọtí wáìnì titun dídíbà tí ó sì kan ti Dẹmọ nínú ìgò ògbólógbòó ti Kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà. . . . Ìfohùnṣọ̀kan ṣíṣàjèjì yìí láàárín Dẹmọ àti Kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà ti lágbára lọ́pọ̀lọpọ̀ nínú ìṣèlú tí a ń ṣe ní Ayé Ìwọ̀-Oòrùn òde-òní tiwa ju Dẹmọ fúnraarẹ̀ lọ.” Ìfẹ́ orílẹ̀-èdè ẹni kò tíì pèsè ayé alálàáfíà kan. Toynbee wí pé: “Lẹ́yìn àlàfo àkókò tí ó kéré jùlọ, àwọn Ogun Ìfẹ́ Orílẹ̀-Èdè Ẹni tẹ̀lé àwọn Ogun Ìsìn; àti pé ní Ayé Ìwọ̀-Oòrun òde-òní tiwa ẹ̀mí ìgbónára ẹhànnà ti ìsìn àti ẹ̀mí ìgbónára ẹhànnà ti orílẹ̀-èdè jẹ́ ọ̀kan náà lọ́nà tí ó farahàn kedere wọ́n sì jẹ́ ìfẹ́ onígbòónára olubi kan náà.”
Nípasẹ̀ àwọn àròsọ àtọwọ́dọ́wọ́ ti “ipò mímọ́ ọlọ́wọ̀ ti àwọn ọba,” “ẹ̀tọ́ àtọ̀runwá ti àwọn ọba,” “èrò náà pé ọwọ́ ènìyàn ni ọlá-àṣẹ wà,” àti “èrò náà pé ọwọ́ orílẹ̀-èdè ni ọlá-àṣẹ wà,” àwọn alákòóso ti gbìdánwò láti mú ọlá-àṣẹ tí wọ́n ní lórí àwọn ẹ̀dá ènìyàn ẹlẹgbẹ́ wọn bófinmu. Bí ó ti wù kí ó rí, lẹ́yìn tí ó ti gbé àkọsílẹ̀ àwọn alákòóso ẹ̀dá ènìyàn yẹ̀wò, Kristian kan kò ní yíyàn mìíràn ju pé kí ó tẹ́wọ́gba èrò náà tí Solomoni sọjáde pé: “[Ènìyàn] ń ṣe olórí ẹnìkejì fún ìfarapa rẹ̀.”—Oniwasu 8:9.
Dípò jíjọ́sìn Ìjọba Orílẹ̀-Èdè lọ́nà òṣèlú, àwọn Kristian ń jọ́sìn Ọlọrun wọ́n sì mọ̀ pé nínú rẹ̀ ni orísun bíbófinmu fún gbogbo ọlá-àṣẹ wà. Wọ́n gbà pẹ̀lú Dafidi onípsalmu náà tí ó sọ pé: “Tìrẹ, Yahweh, ni ìtóbilọ́lá ọláńlá, agbára, ògo-ẹwà, gígùn ọjọ́ àti ògo, tìrẹ ni ohun gbogbo ní ọ̀run àti lórí ilẹ̀-ayé. Tìrẹ ni ipò ọba-aláṣẹ, Yahweh; ìwọ jẹ́ ẹni tí a gbéga, onípò àjùlọ lórí ènìyàn gbogbo.” (1 Kronika 29:11, The New Jerusalem Bible) Síbẹ̀, nítorí ọ̀wọ̀ fún ìfẹ́-inú Ọlọrun, wọ́n fi ọ̀wọ̀ yíyẹ hàn fún ọlá-àṣẹ ní àwọn pápá ti ayé àti tẹ̀mí. Bí ó ti ṣeéṣe fún wọn gan-an àti bí wọ́n ṣe lè ṣe èyí tayọ̀tayọ̀ ni a óò gbéyẹ̀wò nínú àwọn ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ méjì tí ó tẹ̀lé e.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ìwé Droit constitutionnel et institutions politiques, láti ọwọ́ Maurice Duverger.
b Gbédègbẹ́yọ̀ The Catholic Encyclopedia sọ pé: “‘Ẹ̀tọ́ àtọ̀runwá ti àwọn ọba’ yìí (tí ó yàtọ̀ gan-an sí ẹ̀kọ́-ìgbàgbọ́ náà pé gbogbo ọlá-àṣẹ, yálà ti ọba tàbí ti orílẹ̀-èdè aláààrẹ, wá láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun), ni Ṣọ́ọ̀ṣì Katoliki kò tíì fọwọ́sí. Lákòókò Ìṣàtúnṣe ó di irú kan tí ó kógunti ìgbàgbọ́ Katoliki, àwọn ọba aládé bíi Henry Kẹjọ, àti James Kìn-ín-ní ti England lọ́nà tí ó rékọjá ààlà, ní sísọ pé àwọn ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ọlá-àṣẹ tẹ̀mí àti ti ìlú.”
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Ṣọ́ọ̀ṣì Katoliki jẹ́wọ́ pé òun ní ẹ̀tọ́ náà láti dádé fún àwọn olú-ọba àti ọba
[Credit Line]
Consecration of Charlemagne: Bibliothèque Nationale, Paris