Fífayọ̀ Tẹríba Fún Ọlá-Àṣẹ
“Ẹ di onígbọràn lati inú ọkàn-àyà wá.”—ROMU 6:17, NW.
1, 2. (a) Ẹ̀mí wo ni ó hàn gbangba nínú ayé lónìí, kí sì ni orísun àti ìyọrísí rẹ̀ lónìí? (b) Báwo ni àwọn ìránṣẹ́ Jehofa tí wọ́n ti ṣèyàsímímọ́ ṣe fihàn pé àwọn yàtọ̀?
“Ẹ̀MÍ tí ń ṣiṣẹ́ nísinsìnyí ninu awọn ọmọ àìgbọ́ràn” hàn gbangba lọ́nà tí ń múnijígìrì nínú ayé lónìí. Ó jẹ́ ẹ̀mí ìdádúrólómìnira aláìníjàánu, tí ó ní orísun rẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Satani, “olùṣàkóso ọlá-àṣẹ afẹ́fẹ́.” Ẹ̀mí yìí, “afẹ́fẹ́” yìí, tàbí ìṣarasíhùwà ajẹgàbalénilórí ti ìmọtara-ẹni-nìkan àti àìgbọ́ràn, ń lo “ọlá-àṣẹ,” tàbí agbára, lórí ọ̀pọ̀ jùlọ aráyé. Èyí jẹ́ ìdí kan tí ayé fi ń ní ìrírí ohun tí a pè ní yánpọnyánrin ọlá-àṣẹ.—Efesu 2:2.
2 Lọ́nà tí ó múniláyọ̀, àwọn ìránṣẹ́ Jehofa olùṣèyàsímímọ́ lónìí kò fi “afẹ́fẹ́,” tàbí ẹ̀mí ọ̀tẹ̀ tí a ti sọdèérí yìí kún inú ẹ̀dọ̀fóró tẹ̀mí wọn. Wọ́n mọ̀ pé “ìrunú Ọlọrun ń bọ̀ wá sórí awọn ọmọ àìgbọ́ràn.” Aposteli Paulu fikún un pé: “Nitori naa ẹ máṣe di alábàápín pẹlu wọn.” (Efesu 5:6, 7, NW) Kàkà bẹ́ẹ̀, àwọn Kristian tòótọ́ ń sakun láti “kún fún ẹ̀mí [Jehofa],” wọ́n sì ń mu láti inú “ọgbọ́n tí ó wá lati òkè,” tí ó “mọ́níwà, lẹ́yìn náà ó lẹ́mìí-àlàáfíà, ó ń fòyebánilò, ó múra tán lati ṣègbọràn.”—Efesu 5:17, 18; Jakọbu 3:17, NW.
Ìtẹríba Onímùúratán fún Ipò Ọba Aláṣẹ Jehofa
3. Kí ni kọ́kọ́rọ́ náà sí ìtẹríba onímùúratán, ẹ̀kọ́ àríkọ́gbọ́n ńlá wo sì ni ọ̀rọ̀-ìtàn fi kọ́ wa?
3 Mímọyì ọlá-àṣẹ tí ó bófinmu ní àmọ̀jẹ́wọ́ ni kọ́kọ́rọ́ náà sí ìtẹríba onímùúratán. Ìtàn ìran ènìyàn fihàn pé kíkọ ipò ọba aláṣẹ Jehofa sílẹ̀ kò mú ayọ̀ wá. Irú ìkọ̀sílẹ̀ bẹ́ẹ̀ kò mú ayọ̀ wá fún Adamu àti Efa, tàbí fún olùdásílẹ̀ ìṣọ̀tẹ̀ wọn, Satani Eṣu. (Genesisi 3:16-19) Nínú ipò ìrẹ̀sílẹ̀ tí ó wà ní lọ́wọ́lọ́wọ́, Satani ní “ìbínú ńlá” nítorí ó mọ̀ pé àkókò òun kúrú. (Ìfihàn 12:12) Àlàáfíà àti ayọ̀ aráyé, bẹ́ẹ̀ni, ti gbogbo aráyé pátá, sinmilórí mímọyì ipò ọba aláṣẹ òdodo Jehofa ní àmọ̀jẹ́wọ́ kárí-ayé.—Orin Dafidi 103:19-22.
4. (a) Irú ìtẹríba àti ìgbọ́ràn wo ni Jehofa fẹ́ kí àwọn ìránṣẹ́ òun fihàn? (b) Kí ni a gbọ́dọ̀ mú wa gbàgbọ́ dájú, báwo sì ni onípsalmu náà ṣe sọ èyí jáde?
4 Síbẹ̀, nítorí àwọn ànímọ́ rẹ̀ tí ó wàdéédéé lọ́nà àgbàyanu, ìgbọ́ràn tí kò ti ọkàn wá kò tẹ́ Jehofa lọ́rùn. Alágbára ni òun, óò, bẹ́ẹ̀ ni! Ṣùgbọ́n òun kìí ṣe òṣìkà agbonimọ́lẹ̀. Òun jẹ́ Ọlọrun ìfẹ́, ó sì fẹ́ kí àwọn ẹ̀dá rẹ̀ ọlọ́gbọ́nlóye fi pẹ̀lú ìmúratán ṣègbọràn sí òun, láti inú ìfẹ́ wá. Ó fẹ́ kí wọ́n tẹríba fún ipò ọba aláṣẹ òun nítorí pé wọ́n fi tọkàntọkàn yàn láti fi araawọn sábẹ́ ọlá-àṣẹ òdodo rẹ̀ tí ó bófinmu, wọ́n sì níláti gbàgbọ́ dájú pé kò lè sí ohun tí ó sàn jù fún wọn ju pé kí wọ́n ṣègbọràn síi títíláé. Irú ènìyàn tí Jehofa fẹ́ nínú àgbáyé rẹ̀ ṣàjọpín ìmọ̀lára bíi ti onipsalmu náà tí ó kọ̀wé pé: “Òfin Oluwa pé, ó ń yí ọkàn padà: ẹ̀rí Oluwa dánilójú, ó ń sọ òpè di ọlọgbọ́n. Ìlànà Oluwa tọ́, ó ń mú ọkàn yọ̀: àṣẹ Oluwa ni mímọ́, ó ń ṣe ìmọ́lẹ̀ ojú. Ẹ̀rù Oluwa mọ́, pípé ni títíláé; ìdájọ́ Oluwa ni òtítọ́, òdodo ni gbogbo wọn.” (Orin Dafidi 19:7-9) Ìgbọ́kànlé kíkún nínú títọ̀nà àti jíjẹ́ òdodo ipò ọba aláṣẹ Jehofa—èyí ni ó gbọ́dọ̀ jẹ́ ìṣarasíhùwà wa bí a bá fẹ́ láti gbé nínú ayé titun ti Jehofa.
Fífayọ̀ Tẹríba fún Ọba Wa
5. Báwo ni a ṣe san èrè fún Jesu nítorí ìgbọràn rẹ̀, kí ni a sì ń fi pẹ̀lú ìmúratán jẹ́wọ́?
5 Kristi Jesu fúnraarẹ̀ jẹ́ àpẹẹrẹ gíga jùlọ níti ìtẹríba fún Baba rẹ̀ ọ̀run. A kà pé “ó rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ ó sì di onígbọràn títí dé ikú, bẹ́ẹ̀ ni, ikú lórí òpó igi oró.” Paulu fikún un pé: “Fún ìdí yii gan-an pẹlu ni Ọlọrun fi gbé e sí ipò gíga tí ó sì fi inúrere fún un ní orúkọ tí ó lékè gbogbo orúkọ mìíràn, kí ó baà lè jẹ́ pé ní orúkọ Jesu ni kí gbogbo eékún máa tẹ̀ba ti awọn wọnnì tí ń bẹ ní ọ̀run ati awọn wọnnì tí ń bẹ lórí ilẹ̀-ayé ati awọn wọnnì tí ń bẹ lábẹ́ ilẹ̀, kí gbogbo ahọ́n sì máa jẹ́wọ́ fihàn ní gbangba wálíà pé Jesu Kristi ni Oluwa fún ògo Ọlọrun Baba.” (Filippi 2:8-11, NW) Bẹ́ẹ̀ni, a ń fi tayọ̀tayọ̀ tẹ eékún wa ba níwájú Aṣáájú àti Ọba wa tí ń jọba náà Kristi Jesu.—Matteu 23:10.
6. Báwo ni Jesu ti ṣe fihàn pé òun jẹ́ ẹlẹ́rìí àti aṣáájú fún àwọn àwùjọ orílẹ̀-èdè, báwo sì ni “ìṣàkóso ọmọ-aládé” rẹ̀ ṣe ń báa nìṣó lẹ́yìn ìpọ́njú ńlà náà?
6 Nípa Kristi Aṣáájú wa, Jehofa sọtẹ́lẹ̀ pé: “Sáwò ó! Èmi ti fi í fúnni gẹ́gẹ́ bí ẹlẹ́rìí fún àwọn àwùjọ orílẹ̀-èdè, gẹ́gẹ́ bí aṣáájú àti apàṣẹ fún àwọn àwùjọ orílẹ̀-èdè.” (Isaiah 55:4, NW) Nípasẹ̀ iṣẹ́-òjíṣẹ́ rẹ̀ lórí ilẹ̀-ayé àti nípa dídarí iṣẹ́ ìwàásù náà láti ọ̀run lẹ́yìn ikú àti àjíǹde rẹ̀, Jesu ti fi araarẹ̀ hàn pé òun jẹ́ “ẹlẹ́rìí olóòótọ́ àti olódodo” ti Baba rẹ̀ fún gbogbo àwọn ènìyàn orílẹ̀-èdè. (Ìfihàn 3:14; Matteu 28:18-20) Irúfẹ́ àwọn àwùjọ orílẹ̀-èdè bẹ́ẹ̀ ni a ń ṣojú fún pẹ̀lú iye àwọn “ogunlọ́gọ̀ ńlá,” tí ń pọ̀ síi tí wọn yóò la “ìpọ́njú ńlá” náà já lábẹ́ ipò aṣáájú ti Kristi. (Ìfihàn 7:9, 14, NW) Ṣùgbọ́n ipò aṣáájú Jesu kò parí síbẹ̀. “Ìṣàkóso ọmọ-aládé” rẹ̀ yóò wà fún ẹgbẹ̀rún ọdún. Fún àwọn ènìyàn onígbọràn, òun yóò gbé ní ìbámu pẹ̀lú orúkọ rẹ̀ ti “Àgbàyanu Olùgbaninímọ̀ràn, Ọlọrun Alágbára, Baba Ayérayé, Ọmọ-Aládé Àlàáfíà.”—Isaiah 9:6, 7, NW; Ìfihàn 20:6.
7. Bí a bá fẹ́ kí Kristi Jesu ṣe aṣáájú wa lọ síbi “orísun omi ìyè,” kí ni a gbọ́dọ̀ ṣe láìjáfara, kí ni yóò sì mú kí Jesu àti Jehofa fẹ́ràn wa?
7 Bí a bá fẹ́ láti jàǹfààní láti ibi “orísun omi ìyè” níbi ti Ọ̀dọ́-Àgùtàn náà, Kristi Jesu, ń darí àwọn ẹ̀dá ènìyàn ọlọ́kàn títọ́ lọ, a gbọ́dọ̀ fi ẹ̀rí hàn láìjáfara pé a fi tayọ̀tayọ̀ tẹríba fún ọlá-àṣẹ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Ọba nípa ọ̀nà ìgbàhùwà wa. (Ìfihàn 7:17; 22:1, 2; fiwé Orin Dafidi 2:12.) Jesu wí pé: “Bí ẹ̀yin bá fẹ́ràn mi, ẹ ó pa òfin mi mọ́. Ẹni tí ó bá ní òfin mi, tí ó bá sì ń pa wọ́n mọ́, òun ni ẹni tí ó fẹ́ràn mi: ẹni tí ó bá sì fẹ́ràn mi, a óò fẹ́ràn rẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Baba mi wá, èmi ó sì fẹ́ràn rẹ̀.” (Johannu 14:15, 21) Ìwọ ha fẹ́ kí Jesu àti Baba rẹ̀ fẹ́ràn rẹ bí? Nígbà náà tẹríba fún ọlá-àṣẹ wọn.
Àwọn Alábòójútó Ń Fayọ̀ Ṣègbọràn
8, 9. (a) Kí ni Kristi ti pèsè fún gbígbé ìjọ ró, ni ọ̀nà wo sì ni àwọn ọkùnrin wọ̀nyí lè gbà jẹ́ àpẹẹrẹ fún agbo? (b) Báwo ni a ṣe ṣàpẹẹrẹ ìtẹríba àwọn Kristian alábòójútó nínú ìwé Ìfihàn, báwo ni wọ́n sì ṣe lè béèrè fún “ọkàn-àyà onígbọràn” nígbà tí wọ́n bá ń bójútó àwọn ọ̀ràn ìdájọ́?
8 ‘Ìjọ wà ní ìtẹríba fún Kristi.’ Gẹ́gẹ́ bí Alábòójútó rẹ̀, ó ti pèsè “awọn ẹ̀bùn ninu ènìyàn” fún “gbígbé” ìjọ ró. (Efesu 4:8, 11, 12; 5:24) Àwọn àgbà ọkùnrin nípa tẹ̀mí yìí ni a sọ fún láti ‘ṣe olùṣọ́ àgùtàn agbo Ọlọrun tí ń bẹ lábẹ́ àbójútó wọn,’ kìí ṣe ‘bí ẹni ń jẹ oluwa lé awọn wọnnì tí wọ́n jẹ́ ogún Ọlọrun lórí, ṣugbọn ní dídi àpẹẹrẹ fún agbo.’ (1 Peteru 5:1-3, NW) Ti Jehofa ni agbo náà, Kristi sì ni “olùṣọ́ àgùtàn àtàtà” rẹ̀. (Johannu 10:14, NW) Níwọ̀n bí àwọn alábòójútó náà ti ń retí ìfọwọ́sowọ́pọ̀ onímùúratán gẹ́gẹ́ bí ó ti yẹ láti ọ̀dọ̀ àwọn àgùtàn tí Jehofa àti Kristi ti fi sábẹ́ àbójútó wọn, àwọn fúnraawọn gbọ́dọ̀ jẹ́ àpẹẹrẹ àtàtà níti ìtẹríba.—Iṣe 20:28.
9 Ní ọ̀rúndún kìn-ín-ní, àwọn alábòójútó tí wọ́n jẹ́ ẹni-àmì-òróró ni a fihàn lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ pé wọ́n wà “ní,” tàbí “lórí,” ọwọ́ ọ̀tún Kristi, èyí tí ó túmọ̀sí ìtẹríba wọn fún un gẹ́gẹ́ bí Orí ìjọ. (Ìfihàn 1:16, 20; 2:1) Kò dínkù sì ìyẹn lónìí, àwọn alábòójútó láàárín ìjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa gbọ́dọ̀ tẹríba fún ìtọ́sọ́nà Kristi kí wọ́n sì ‘rẹ araawọn sílẹ̀ lábẹ́ ọwọ́ agbára Ọlọrun.’ (1 Peteru 5:6) Nígbà tí a bá késí wọn láti bójútó àwọn ọ̀ràn ìdájọ́, gẹ́gẹ́ bíi ti Solomoni ní àwọn ọdún tí ó fi jẹ́ olùṣòtítọ́, wọ́n gbọ́dọ̀ gbàdúrà sí Jehofa pé: “Fi ọkàn ìmòye fún ìránṣẹ́ rẹ láti ṣe ìdájọ́ àwọn ènìyàn rẹ, láti mọ ìyàtọ̀ rere àti búburú.” (1 Awọn Ọba 3:9) Ọkàn-àyà onígbọràn yóò sún alàgbà kan láti rí àwọn nǹkan gẹ́gẹ́ bí Jehofa àti Kristi Jesu ti ń rí wọn kí ó baà lè jẹ́ pé ìpinnu tí a ṣe lórí ilẹ̀-ayé farajọra tímọ́tímọ́ pẹ̀lú èyí tí a ṣe ní ọ̀run.—Matteu 18:18-20.
10. Báwo ni gbogbo àwọn alábòójútó ṣe lè sakun láti ṣàfarawé Jesu nínú ọ̀nà tí ó gbà bá àwọn àgùtàn lò?
10 Àwọn alábòójútó arìnrìn-àjò àti àwọn alàgbà ìjọ bákan náà yóò sakun láti farawé Kristi ní ọ̀nà tí ó gbà bá àwọn àgùtàn lò. Láìdàbí ti àwọn Farisi, Jesu kò gbé ìlànà rẹpẹtẹ tí ó ṣòro láti tẹ̀lé kanilórí. (Matteu 23:2-11) Ó sọ fún àwọn ẹni bí àgùtàn pé: “Ẹ wá sọ́dọ̀ mi gbogbo ẹ̀yin tí ń ṣíṣẹ̀ẹ́, tí a sì di ẹrù wúwo lélórí, èmi ó sì fi ìsinmi fún yín. Ẹ gba àjàgà mi sí ọrùn yín, kí ẹ sì máa kọ́ ẹ̀kọ́ lọ́dọ̀ mi; nítorí onínú tútù àti onírẹ̀lẹ̀ ọkàn ni èmi; ẹ̀yin ó sì rí ìsinmi fún ọkàn yín. Nítorí àjàgà mi rọrùn, ẹrù mi sì fúyẹ́.” (Matteu 11:28-30) Nígbà tí ó jẹ́ òtítọ́ pé Kristian kọ̀ọ̀kan gbọ́dọ̀ “ru ẹrù ti ara rẹ̀,” àwọn alábòójútó gbọ́dọ̀ rántí àpẹẹrẹ Jesu kí wọ́n sì ran àwọn arákùnrin wọn lọ́wọ́ láti nímọ̀lára pé ẹrù iṣẹ́ Kristian wọn “rọrùn,” “fúyẹ́,” ó sì jẹ́ ohun ayọ̀ láti rù.—Galatia 6:5.
Ìtẹríba fún Ìlànà Ìṣàkóso Ọlọrun
11. (a) Báwo ni ẹnìkan ṣe lè bọ̀wọ̀ fún ipò orí síbẹ̀ kí ó má tẹ̀lé ìlànà ìṣàkóso Ọlọrun niti gidi? Ṣàkàwé. (b) Kí ni ó túmọ̀sí láti jẹ́ olùtẹ̀lé ìlànà ìṣàkóso Ọlọrun níti tòótọ́?
11 Ìṣàkóso Ọlọrun jẹ́ àkóso nípasẹ̀ Ọlọrun. Ó wémọ́ ìlànà ipò-orí tí a làsílẹ̀ nínú 1 Korinti 11:3. Ṣùgbọ́n ó túmọ̀sí púpọ̀ ju ìyẹn lọ. Ó lè dàbí ẹni pé ẹnìkan ń fi ọ̀wọ̀ hàn fún ìpò-orí síbẹ̀ kí ó má tẹ̀lé ìlànà ìṣàkóso Ọlọrun ní èrò ìtumọ̀ kíkún tí ọ̀rọ̀ náà ní. Báwo ni èyí ṣe lè rí bẹ́ẹ̀? Láti ṣàkàwé, ìjọba dẹmọ jẹ́ ìṣàkóso láti ọwọ́ àwọn ènìyàn wá, olùṣèjọba dẹmọ ni a sì ti túmọ̀ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí “ènìyàn kan tí ó gbàgbọ́ nínú àwọn ọ̀pá ìdíwọ̀n ìjọba dẹmọ.” Ọkùnrin kan lè jẹ́wọ́ pé olùṣèjọba dẹmọ ni òun, kí ó kópa nínú àwọn ìdìbò, kí ó tilẹ̀ jẹ́ akíkanjú olóṣèlú. Ṣùgbọ́n bí kò bá ka ẹ̀mí tí ń bá ìjọba dẹmọ rìn àti àwọn ìlànà tí ó wémọ́ ọn sí, a ha lè sọ pé nítòótọ́ ni ó jẹ́ olùṣèjọba dẹmọ bí? Lọ́nà kan náà, láti jẹ́ olùtẹ̀lé ìlànà ìṣàkóso Ọlọrun nítòótọ́, ẹnìkan gbọ́dọ̀ ṣe rékọjá fífi ẹnu lásán tẹríba fún ipò-orí. Ó gbọ́dọ̀ ṣàfarawé àwọn ọ̀nà àti ànímọ́ Jehofa. Nítòótọ́ ni Jehofa gbọ́dọ̀ máa ṣàkóso rẹ̀ ní gbogbo ọ̀nà. Níwọ̀n bí ó sì ti jẹ́ pé Jehofa ti gbé ọlá-àṣẹ kíkún lé Ọmọkùnrin rẹ̀ lọ́wọ́, jíjẹ́ olùtẹ̀lé ìlànà ìṣàkóso Ọlọrun tún túmọ̀sí ṣíṣàfarawé Jesu pẹ̀lú.
12, 13. (a) Ní pàtàkì, kí ni ó wémọ́ jíjẹ́ olùtẹ̀lé ìlànà ìṣàkóso Ọlọrun? (b) Ǹjẹ́ ìtẹríba fún ìlànà ìṣàkóso Ọlọrun wémọ́ ṣíṣègbọràn sí àwọn ìlànà rẹpẹtẹ bí? Ṣàkàwé.
12 Rántí, Jehofa fẹ́ ìtẹríba onímùúratán tí a súnṣiṣẹ́ nípasẹ̀ ìfẹ́. Ọ̀nà tí òun gbà ń darí àgbáyé nìyẹn. Òun gan-an ni ògidi àpẹẹrẹ ìfẹ́. (1 Johannu 4:8) Kristi Jesu jẹ́ “ìtànṣán ògo rẹ̀, àti àwòrán òun tìkáraarẹ̀.” (Heberu 1:3) Ó béèrè pé kí àwọn ọmọlẹ́yìn òun tòótọ́ nífẹ̀ẹ́ araawọn. (Johannu 15:17) Nítorí náà kìí ṣe títẹríba nìkan ni jíjẹ́ olùtẹ̀lé ìṣàkóso Ọlọrun túmọ̀sí bíkòṣe jíjẹ́ onífẹ̀ẹ́ pẹ̀lú. A lè ṣe àkópọ̀ ọ̀rọ̀ náà gẹ́gẹ́ bí ó ti tẹ̀lé e yìí: Ìṣàkóso Ọlọrun jẹ́ àkóso nípasẹ̀ Ọlọrun; Ọlọrun jẹ́ ìfẹ́; nítorí náà ìṣàkóso Ọlọrun jẹ́ ìṣàkóso nípasẹ̀ ìfẹ́.
13 Alàgbà kan lè ronú pé láti tẹ̀lé ìlànà ìṣàkóso Ọlọrun, àwọn ará gbọ́dọ̀ ṣègbọràn sí gbogbo onírúurú ìlànà. Àwọn alàgbà kan ti gbé àwọn ìlànà kalẹ̀ láti inú àwọn ìdámọ̀ràn tí “olùṣòtítọ́ àti ọlọ́gbọ́n-inú ẹrú” náà ń fifúnni láti ìgbà dé ìgbà. (Matteu 24:45, NW) Fún àpẹẹrẹ, a ti dámọ̀ràn nígbàkan rí pé nítorí kí a lè tètè máa mọ àwọn ará nínú ìjọ, ó lè jẹ́ ohun tí ó dára láti máṣe máa jókòó sórí ìjókòó kan náà ní Gbọ̀ngàn Ìjọba nígbà gbogbo. Èyí ni a nílọ́kàn pé kí ó jẹ́ ìmọ̀ràn gbígbéṣẹ́, kìí ṣe ìlànà kàn-ń-pá. Ṣùgbọ́n àwọn alàgbà kan lè ní ìtẹ̀sí láti sọ ọ́ di ìlànà kan kí wọ́n sì nímọ̀lára pé àwọn wọnnì tí wọn kò tẹ̀lé e jẹ́ aláìtẹ̀lé ìlànà ìṣàkóso Ọlọrun. Síbẹ̀, àwọn ìdí rere púpọ̀ lè wà ti arákùnrin tàbí arábìnrin kan fi lè yàn láti jókòó ní agbègbè pàtó kan. Bí alàgbà kan kìí bá fi tìfẹ́tìfẹ́ gba àwọn nǹkan rò, òun fúnraarẹ̀ ha ń tẹ̀lé ìlànà ìṣàkóso Ọlọrun nítòótọ́ bí? Láti jẹ́ olùtẹ̀lé ìlànà ìṣàkóso Ọlọrun, “ẹ máa fi ìfẹ́ ṣe gbogbo nǹkan yín.”—1 Korinti 16:14.
Fífi Ayọ̀ Ṣiṣẹ́sìn
14, 15. (a) Báwo ni alàgbà kan ṣe lè fi ayọ̀ àwọn arákùnrin tàbí arábìnrin kan dù wọ́n nínú ṣíṣiṣẹ́sin Jehofa, èésìtiṣe tí èyí kò fi ní bá ìlànà ìṣàkóso Ọlọrun mu? (b) Báwo ni Jesu ṣe fihàn pé òun mọrírì ìfẹ́ tí iṣẹ́-ìsìn wa fihàn, dípò bí ó ti pọ̀ tó? (d) Kí ni àwọn alàgbà níláti gbéyẹ̀wò?
14 Jíjẹ́ olùtẹ̀lé ìlànà ìṣàkóso Ọlọrun tún túmọ̀sí fífi ayọ̀ ṣiṣẹ́sin Jehofa. Jehofa jẹ́ “Ọlọrun aláyọ̀.” (1 Timoteu 1:11) Ó fẹ́ kí àwọn olùjọ́sìn rẹ̀ ṣiṣẹ́sin òun tayọ̀tayọ̀. Àwọn wọnnì tí wọ́n jẹ́ arinkinkin mọ́ ìlànà níláti rántí pé lára àwọn ìlànà tí a fifún Israeli láti “máa kíyèsí láti máa ṣe” ni èyí tí ó tẹ̀lée yìí: “Kí ìwọ kí ó sì máa yọ̀ níwájú OLUWA Ọlọrun rẹ nínú ohun gbogbo tí ìwọ fi ọwọ́ rẹ lé.” (Deuteronomi 12:1, 18) Ohunkóhun yòówù kí a dáwọ́lé nínú iṣẹ́-ìsìn Jehofa gbọ́dọ̀ jẹ́ ohun ayọ̀, kìí ṣe ti ẹrù-ìnira. Àwọn alábòójútó lè ṣe púpọ̀ láti mú kí àwọn ará láyọ̀ láti ṣe ohun tí wọ́n bá lè ṣe nínú ṣíṣiṣẹ́sin Jehofa. Ní òdìkejì, bí àwọn alàgbà kò bá ṣọ́ra, wọ́n lè fi ayọ̀ du díẹ̀ lára àwọn ará. Fún àpẹẹrẹ, bí wọ́n bá ń ṣe ìfiwéra, tí wọ́n ń gbóríyìn fún àwọn wọnnì tí wọ́n ti dé ìpíndọ́gba wákàtí tí ìjọ lò láti jẹ́rìí tàbí tí wọ́n kọjá rẹ̀ tí ó sì wá dọ́gbọ́n túmọ̀sí pé wọ́n ń fi òfíntótó bá àwọn wọnnì tí wọn kò dé orí ìpíndọ́gba wí, kí ni yóò jẹ́ ìmọ̀lára àwọn wọnnì tí wọ́n ní ìdí tí ó fẹsẹ̀múlẹ̀ fún ríròyìn àkókò tí ó dínkù? Èyí kì yóò ha mú kí wọ́n nímọ̀lára ẹ̀bi lọ́nà tí kò yẹ kí ó sì fi ayọ̀ wọn dù wọ́n bí?
15 Ìwọ̀nba wákàtí tí àwọn kan lè yọ̀ǹda fún ìjẹ́rìí ní gbangba lè dúró fún ìsapá tí ó pọ̀ ju ọ̀pọ̀ wákàtí tí àwọn mìíràn lò fún wíwàásù, bí a bá wo ti ọjọ́-orí kékeré, ìlera sísàn jù, àti àwọn àyíká ipò mìíràn. Ní ọ̀nà yìí, àwọn alàgbà kò níláti dá wọn lẹ́jọ́. Nítòótọ́, Jesu ni Baba fi “ọlá-àṣẹ láti ṣe ìdájọ́” fún. (Johannu 5:27, NW) Jesu ha fòfíntótó bá opó aláìní náà wí nítorí pé ọrẹ tí ó múwá kéré sí ìpíndọ́gba bí? Bẹ́ẹ̀kọ́, ó ní ẹ̀mí ìmọ̀lára nípa ohun tí àwọn owó idẹ wẹ́wẹ́ méjì náà ná an níti gidi. Wọ́n jẹ́ ‘ohun gbogbo tí ó ní, àní gbogbo ìní rẹ̀.’ Ẹ wo ìfẹ́ jíjinlẹ̀ fún Jehofa tí wọ́n dúró fún! (Marku 12:41-44) Àwọn alàgbà ha níláti ní ẹ̀mí ìmọ̀lára tí ó dínkù fún ìsapá onífẹ̀ẹ́ ti àwọn wọnnì tí gbogbo wákàtí tí wọ́n ní dínkù sí “ìpíndọ́gba” bí? Bí a bá ń sọ̀rọ̀ nípa ìfẹ́ fún Jehofa, irú àwọn ìsapá bẹ́ẹ̀ lè rékọjá ìpíndọ́gba fíìfíì!
16. (a) Bí àwọn alábòójútó bá lo iye kan nínú àwọn ọ̀rọ̀-àsọyé wọn, èéṣe tí wọ́n fi nílò ìwòyemọ̀ àti ìwàdéédéé dídára? (b) Ọ̀nà dídára jùlọ wo ni a lè gbà ran àwọn ará lọ́wọ́ láti mú iṣẹ́-ìsìn wọn bísíi?
16 Ǹjẹ́ ó yẹ kí a yí àwọn ọ̀rọ̀ àkíyèsí wọ̀nyí padà sí “ìlànà” titun kan pe iye kan—àní ìpíndọ́gba pàápàá—ni a kò gbọ́dọ̀ mẹ́nukàn mọ́ bí? Kìí ṣe bẹ́ẹ̀ rárá! Kókó náà ni pé àwọn alábòójútó gbọ́dọ̀ wàdéédéé lórí ọ̀ràn fífún àwọn ará ní ìṣírí láti mú iṣẹ́-òjíṣẹ́ wọn gbòòrò síi àti ríràn wọ́n lọ́wọ́ láti fi ayọ̀ ṣe ohun tí wọ́n bá lè ṣe. (Galatia 6:4) Nínú àkàwé Jesu nípa tálẹ́ǹtì, ọ̀gá náà fi àwọn ohun-ìní rẹ̀ lé àwọn ẹrú rẹ̀ lọ́wọ́ “olúkúlùkù gẹ́gẹ́ bí agbára rẹ̀.” (Matteu 25:14, 15) Àwọn alàgbà bákan náà níláti gba ohun tí agbára akéde Ìjọba kọ̀ọ̀kan ká yẹ̀wò. Èyí béèrè fún ìwòyemọ̀. Ó lè jẹ́ pé ìṣírí láti ṣe púpọ̀ síi ni àwọn kan nílò níti gidi. Wọ́n lè mọrírì ìrànlọ́wọ́ láti ṣètò ìgbòkègbodò wọn lọ́nà tí ó túbọ̀ sunwọ̀n síi. Bí ó ti wù kí ó rí, bí a bá lè ràn wọ́n lọ́wọ́ láti fi ayọ̀ ṣe ohun tí wọ́n bá lè ṣe, ó ṣeéṣe pé kí ayọ̀ náà fún wọn lókun láti mú ìgbòkègbodò Kristian wọn pọ̀ síi níbi tí ó bá ti ṣeéṣe.—Nehemiah 8:10; Orin Dafidi 59:16; Jeremiah 20:9.
Àlàáfíà tí Ń Wá Láti Inú Fífayọ̀ Tẹríba
17, 18. (a) Báwo ni fífayọ̀ tẹríba ṣe lè mú àlàáfíà àti òdodo wá fún wa? (b) Kí ni ó lè jẹ́ tiwa bí a bá fiyèsí àwọn àṣẹ Ọlọrun níti gidi?
17 Fífayọ̀ tẹríba fún ipò ọba aláṣẹ Jehofa tí ó bófinmu ń mú àlàáfíà ńlá wá fún wa. Onipsalmu náà sọ nínú àdúrà sí Jehofa pé: “Àlàáfíà púpọ̀ ni àwọn tí ó fẹ́ òfin rẹ ní: kò sì sí ohun ìkọ̀sẹ̀ fún wọn.” (Orin Dafidi 119:165) Nípa ṣíṣègbọràn sí òfin Ọlọrun, a ń ṣe araawa ní àǹfààní. Jehofa sọ fún Israeli pé: “Báyìí ni Oluwa wí, Olùràpadà rẹ, Ẹni-Mímọ́ Israeli: Èmi ni Oluwa Ọlọrun rẹ, tí ó kọ́ ọ fún èrè, ẹni tí ó tọ́ ọ ní ọ̀nà tí ìwọ ìbá máa lọ. Ìbáṣepé ìwọ fi etí sí òfin mi! nígbà náà ní àlàáfíà rẹ ìbá dàbí odò, àti òdodo rẹ bí ìgbì omi òkun.”—Isaiah 48:17, 18.
18 Ẹbọ ìràpadà Kristi mú àlàáfíà pẹ̀lú Ọlọrun wá fún wa. (2 Korinti 5:18, 19) Bí a bá ní ìgbàgbọ́ nínú ẹ̀jẹ̀ Kristi tí ń rà wá padà tí a sì fi tọkàntọkàn sakun láti gbógunti àwọn àìlera wa láti ṣe ìfẹ́-inú Ọlọrun, àwa yóò rí ìtura kúrò nínú àwọn ìmọ̀lára ẹ̀bi. (1 Johannu 3:19-23) Irú ìgbàgbọ́ bẹ́ẹ̀, tí a fi iṣẹ́ tìlẹ́yìn, ń fún wa ní ìdúró òdodo níwájú Jehofa àti ìrètí àgbàyanu ti líla “ìpọ́njú ńlá” já àti gbígbé títíláé nínú ayé titun ti Jehofa. (Ìfihàn 7:14-17; Johannu 3:36; Jakọbu 2:22, 23) Gbogbo èyí lè jẹ́ tiwa ‘kìkì bí àwa yóò bá fiyèsí àwọn àṣẹ Ọlọrun.’
19. Lórí kí ni ayọ̀ wa nísinsìnyí àti ìrètí wa fún ìyè àìnípẹ̀kun sinmilé, báwo sì ni Dafidi ṣe sọ ohun tí a gbàgbọ́ látọkànwá jáde?
19 Bẹ́ẹ̀ni, ayọ̀ wa nísinsìnyí àti ìrètí ìyè ayérayé wa lórí paradise ilẹ̀-ayé wépọ̀ mọ́ fífayọ̀ tẹríba wa fún ọlá-àṣẹ Jehofa gẹ́gẹ́ bí Oluwa Ọba Aláṣẹ àgbáyé. Ǹjẹ́ kí a lè máa ṣàjọpín ìmọ̀lára Dafidi títí gbére, ẹni tí ó sọ pé: “Tìrẹ Oluwa ni títóbi, àti agbára, àti ògo, àti ìṣẹ́gun, àti ọlá-ńlá: nítorí ohun gbogbo ní ọ̀run àti ní ayé tìrẹ ni; ìjọba ni tìrẹ, Oluwa, a sì gbé ọ lékè ní orí fún ohun gbogbo. Ǹjẹ́ nísinsìnyí, Ọlọrun wa, àwa dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ, a sì yin orúkọ ògo rẹ̀.”—1 Kronika 29:11, 13.
Àwọn Kókó Láti Rántí
◻ Irú ìtẹríba àti ìgbọ́ràn wo ni Jehofa fẹ́ kí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ fihàn?
◻ Báwo ni a ṣe san èrè fún Jesu nítorí ìgbọ́ràn rẹ̀, kí sì ni a gbọ́dọ̀ fihàn nípa ọ̀nà tí a ń gbà hùwà?
◻ Báwo ni gbogbo àwọn alábòójútó ṣe gbọ́dọ̀ ṣàfarawé Jesu nínú ọ̀nà tí ó gbà bá àwọn àgùtàn lò?
◻ Kí ni ó wémọ́ títẹ̀lé ìlànà ìṣàkóso Ọlọrun?
◻ Àwọn ìbùkún wo ni fífayọ̀ tẹríba ń mú wá fún wa?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]
Àwọn alàgbà ń fún ìjọ ní ìṣírí láti fi tayọ̀tayọ̀ ṣe ohunkóhun tí wọ́n lè ṣe
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
Inú Jehofa máa ń dún sí àwọn wọnnì tí wọ́n ṣègbọràn sí i láti inú ọkàn-àyà wá