Àwọn Olùṣọ́-Àgùtàn Àti Àwọn Àgùtàn Nínú Ìṣàkóso Ọlọrun
“Jehofa ni Onídàájọ́ wa, Jehofa ni Olùfúnni-ní-ìlànà-òfin wa, Jehofa ni Ọba wa; òun fúnraarẹ̀ yóò gbà wá là.”—ISAIAH 33:22, NW.
1. Báwo ni a ṣe lè sọ pé àwọn Kristian ọ̀rúndún kìn-ín-ní àti àwọn Kristian lónìí wà lábẹ́ ìṣàkóso Ọlọrun?
ÌṢÀKÓSO nípasẹ̀ Ọlọrun ni theocracy túmọ̀sí. Ó wémọ́ títẹ́wọ́gba ọlá-àṣẹ Jehofa àti títẹ̀lé àwọn ìtọ́sọ́nà àti ìtọ́ni rẹ̀ nínú àwọn ìpinnu ńlá àti kékeré tí a bá ń ṣe nínú ìgbésí-ayé. Ìjọ ọ̀rúndún kìn-ín-ní jẹ́ ojúlówó ìṣàkóso Ọlọrun. Àwọn Kristian lè fi àìṣàbòsí sọ nígbà náà pé: “Jehofa ni Onídàájọ́ wa, Jehofa ni Olùfúnni-ní-ìlàna-òfin wa, Jehofa ni Ọba wa.” (Isaiah 33:22, NW) Pẹ̀lú àṣẹ́kù ẹni-àmì-òróró gẹ́gẹ́ bí òpómúléró rẹ̀, ètò-àjọ Jehofa Ọlọrun lónìí bákan náà jẹ́ ìṣàkóso Ọlọrun gidi kan.
Ní Àwọn Ọ̀nà Wo ni A Gbà Ń Tẹ̀lé Ìlànà Ìṣàkóso Ọlọrun Lónìí?
2. Kí ni ọ̀nà kan tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa gbà tẹríba fún ìṣàkóso Jehofa?
2 Báwo ni a ṣè le sọ pé ètò-àjọ Jehofa lórí ilẹ̀-ayé jẹ́ ti ìṣàkóso Ọlọrun? Nítorí pé àwọn tí wọ́n jẹ́ apákan rẹ̀ wà ní ìtẹríba fún ìṣàkóso Jehofa níti tòótọ́. Wọ́n sì ń tẹ̀lé ìdarí Jesu Kristi, ẹni náà tí Jehofa ti gbégorí ìtẹ́ gẹ́gẹ́ bí Ọba. Fún àpẹẹrẹ, ní àkókò òpin, àṣẹ tààràtà yìí tí ó ti ọ̀dọ̀ Ọlọrun Alákòóso Ńlá wá ní a sọ́ fún Jesu: “Tẹ dòjé rẹ bọ̀ ọ́, kí o sì máa kórè: nítorí àkókò àti kórè dé, nítorí ìkórè ayé ti gbó tán.” (Ìfihàn 14:15) Jesu ṣègbọràn ó sì gba ẹrù-iṣẹ́ kíkórè ilẹ̀-ayé. Àwọn Kristian ń ṣètìlẹ́yìn fún Ọba wọn nínú iṣẹ́ ńlá yìí nípa fífi ìtara wàásù ìhìnrere náà ati sísọni di ọmọ-ẹ̀yìn. (Matteu 28:19; Marku 13:10; Iṣe 1:8) Nípa ṣíṣe bẹ́ẹ̀, àwọn pẹ̀lú jẹ́ alábàáṣiṣẹ́pọ̀ pẹ̀lú Jehofa, Ọlọrun Alákòóso Ńlá náà.—1 Korinti 3:9.
3. Báwo ni àwọn Kristian ṣe ń tẹríba fún ìṣàkóso Ọlọrun nínú àwọn ọ̀ràn tí ó jẹmọ́ ìwàrere?
3 Nínú ìwà, pẹ̀lú, àwọn Kristian ń tẹríba fún ìṣàkóso Ọlọrun. Jesu wí pé: “Ẹni tí ó bá ń ṣe òtítọ́ níí wá sí ìmọ́lẹ̀, kí iṣẹ́ rẹ̀ kí ó lè fi ara hàn pé, a ṣe wọ́n nípa ti Ọlọrun.” (Johannu 3:21) Lónìí, iyàn tí kò lópin wà nípa àwọn ọ̀pá-ìdiwọ̀n ìwàhíhù, ṣùgbọ́n àwọn awuyewuye wọ̀nyí kò ní àyè kankan láàárín àwọn Kristian. Wọ́n fi ojú wo ohun tí Jehofa bá sọ pé kò bá ìwàrere mú gẹ́gẹ́ bí èyí tí kò bá ìwàrere mú, wọ́n sì yẹra fún un bí ẹni pé ó jẹ́ òkùnrùn aṣekúpani tí ń gbèèràn! Wọ́n ń bójútó ìdílé wọn, wọ́n ń ṣègbọràn sí àwọn òbí wọn, wọ́n sì wà ní ìtẹríba fún àwọn aláṣẹ gíga jù pẹ̀lú. (Efesu 5:3-5, 22-33; 6:1-4; 1 Timoteu 5:8; Titu 3:1) Nípa báyìí, wọ́n ń hùwà lọ́nà tí ó bá ìlànà ìṣàkóso Ọlọrun mu, ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú Ọlọrun.
4. Ìṣarasíhùwà tí kò tọ́ wo ni Adamu àti Efa àti Saulu fihàn, báwo sì ni àwọn Kristian ṣe fi ìṣarasíhùwà tí ó yàtọ̀ hàn?
4 Adamu àti Efa pàdánù Paradise nítorí pé wọ́n fẹ́ láti ṣe àwọn ìpinnu fúnraawọn nípa ohun tí ó tọ́ àti ohun tí kò tọ́. Òdìkejì pátápátá gbáà ni Jesu fẹ́. Ó sọ pé: “Èmi kò wá ìfẹ́ ti èmi tìkáraàmi, bíkòṣe ìfẹ́ ti ẹni tí ó rán mi.” Ohun kan náà ni àwọn Kristian ń wá. (Johannu 5:30; Luku 22:42; Romu 12:2; Heberu 10:7) Saulu, ọba àkọ́kọ́ ní Israeli, ṣègbọràn sí Jehofa—ṣùgbọ́n kìí ṣe lẹ́kùn-ún-rẹ́rẹ́. Nítorí èyí a kọ̀ ọ́ sílẹ̀. Samueli sọ fún un pé: “Ìgbọràn sàn ju ẹbọ lọ, ìfetísílẹ̀ sì sàn ju ọ̀rá àgbò lọ.” (1 Samueli 15:22) Ó ha bá ìṣàkóso Ọlọrun mu láti ṣe ìfẹ́-inú Jehofa dé ìwọ̀n àyè kan, bóyá nípa ṣíṣe déédéé nínú iṣẹ́ wíwàásù tàbí nínú wíwá sí ìpàdé, kí a sì wá juwọ́sílẹ̀ nínú àwọn ọ̀ràn ìwàrere tàbí ní àwọn ọ̀nà mìíràn kan lẹ́yìn náà bí? Dájúdájú bẹ́ẹ̀kọ́! A ń làkàkà láti “ṣe ìfẹ́ Ọlọrun láti inú wá.” (Efesu 6:6; 1 Peteru 4:1, 2) Láìdàbí Saulu, a jọ̀wọ́ araawa pátápátá fún ìṣàkóso Ọlọrun.
Ìṣàkóso Ọlọrun kan ní Òde-Òní
5, 6. Báwo ni Jehofa ṣe ń bá aráyé lò lónìí, kí sì ni ìfọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú ìṣètò yìí ń yọrísí?
5 Ní ìgbà àtijọ́, Jehofa ṣàkóso ó sì ṣí àwọn òtítọ́ payá nípasẹ̀ àwọn ẹnìkọ̀ọ̀kan, bí àwọn wòlíì, ọba, àti àwọn aposteli. Lónìí, ọ̀ràn kò tún rí bẹ́ẹ̀ mọ́; kò tún sí àwọn wòlíì tàbí aposteli tí a mísí mọ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, Jesu sọ pé nígbà wíwàníhìn-ín òun bí ọba, òun yóò fi ẹgbẹ́ àwọn ọmọlẹ́yìn olùṣòtítọ́ kan hàn yàtọ̀, “ẹrú olùṣòtítọ́ àti ọlọ́gbọ́n-inú” kan, yóò sì yàn án ṣe olórí gbogbo ohun-ìní rẹ̀. (Matteu 24:45-47; Isaiah 43:10) Ní ọdún 1919 ẹrú yẹn ni a mọ̀ sí àṣẹ́kù àwọn Kristian ẹni-àmì-òróró. Láti ìgbà náà wá, bí Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ti ń ṣojú fún un, ó ti jẹ́ ọ̀gangan ibi ìkóríjọ fún ìṣàkóso Ọlọrun lórí ilẹ̀-ayé. Káàkiri ayé, Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso ni àwọn Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka, àwọn alábòójútó arìnrìn-àjò, àti àwọn alàgbà ìjọ ń ṣojú fún.
6 Ìfọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú ètò-àjọ ìṣàkóso Ọlọrun jẹ́ apá ṣíṣekókó nínú jíjuwọ́sílẹ̀ ní ìtẹríba fún ìṣàkóso Ọlọrun. Irú ìfọwọ́sowọ́pọ̀ bẹ́ẹ̀ ń ṣiṣẹ́ fún ìṣọ̀kan àti ètò kárí-ayé nínú “gbogbo ẹgbẹ́ àwọn ará.” (1 Peteru 2:17, NW) Lẹ́yìn náà, èyí ń mu inú Jehofa, tí “kìí ṣe Ọlọrun ohun rúdurùdu, ṣùgbọ́n ti àlàáfíà,” dùn.—1 Korinti 14:33.
Àwọn Alàgbà Nínú Ìṣàkóso Ọlọrun
7. Èéṣe tí a fi lè sọ pé àwọn alàgbà Kristian ni a yànsípò lọ́nà tí ó bá ìlànà ìṣàkóso Ọlọrun mu?
7 Gbogbo àwọn àgbà ọkùnrin tí a yànsípò ń mú àwọn ohun-àbéèrè-fún tí a là lẹ́sẹẹsẹ nínú Bibeli fún ipò alábòójútó, tàbí àgbà ọkùnrin ṣẹ, láìka ipò ọlá-àṣẹ wọn sí. (1 Timoteu 3:1-7; Titu 1:5-9) Síwájú síi, àwọn ọ̀rọ̀ Paulu sí àwọn alàgbà ní Efesu ní ìfisílò fún gbogbo àwọn alàgbà: “Ẹ kíyèsára yín, àti sí gbogbo agbo tí Ẹ̀mí Mímọ́ fi yín ṣe alábòójútó rẹ̀, láti máa [ṣolùṣọ́-àgùtàn, NW] ìjọ Ọlọrun.” (Iṣe 20:28) Bẹ́ẹ̀ni, àwọn alàgbà ni a fi ẹ̀mí mímọ́, tí ń ti ọ̀dọ̀ Jehofa Ọlọrun wá, yànsípò. (Johannu 14:26) Ìyànsípò wọn bá ìlànà ìṣàkóso Ọlọrun mú. Jù bẹ́ẹ̀ lọ, wọ́n ń ṣolùṣọ́-àgùtàn agbo Ọlọrun. Ti Jehofa ni agbo náà, kìí ṣe ti àwọn alàgbà. Ó wà lábẹ́ ìṣàkóso Ọlọrun.
8. Kí ni àpapọ̀ ẹrù-iṣẹ́ àwọn alàgbà lónìí?
8 Nínú lẹ́tà rẹ̀ sí àwọn ará Efesu, aposteli Paulu la àpapọ̀ ẹrù-iṣẹ́ àwọn alàgbà lẹ́sẹẹsẹ, ní wíwí pé: “Ó sì ti fi àwọn kan fúnni bí aposteli; àti àwọn mìíràn bíi wòlíì; àti àwọn mìíràn bí [ajíhìnrere, NW], àti àwọn mìíràn bí olùṣọ́-àgùtàn àti olùkọ́ni; fún àṣepé àwọn ènìyàn mímọ́ fún iṣẹ́-ìránṣẹ́, fún ìmúdàgbà ara Kristi.” (Efesu 4:11, 12) Àwọn aposteli àti àwọn wòlíì kò sí mọ́ lẹ́yìn ìgbà-ọmọdé-jòjòló “ara Kristi.” (Fiwé 1 Korinti 13:8.) Ṣùgbọ́n ọwọ́ àwọn alàgbà ṣì dí fún iṣẹ́ ìjíhìnrere, ṣíṣolùṣọ́-àgùtàn, àti kíkọ́ni.—2 Timoteu 4:2; Titu 1:9.
9. Báwo ni àwọn alàgbà ṣe níláti múra araawọn sílẹ̀ láti ṣojú fún ìfẹ́-inú Ọlọrun nínú ìjọ?
9 Níwọ̀n bí theocracy ti jẹ́ ìṣàkóso Ọlọrun, àwọn alàgbà tí wọ́n gbéṣẹ́ mọ ìfẹ́-inú Ọlọrun ní àmọ̀dunjú. Joṣua ni a pàṣẹ fún láti máa ka Òfin lójoojúmọ́. Àwọn alàgbà pẹ̀lú gbọ́dọ̀ máa kẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Mímọ́ déédéé kí wọ́n sì máa yẹ̀ ẹ́ wò kí wọ́n sì tún mọ àwọn ìwé-ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli tí ẹrú olùṣòtítọ́ àti ọlọ́gbọ́n-inú náà tẹ̀jáde ní àmọ̀dunjú. (2 Timoteu 3:14, 15) Èyí ní nínú àwọn ìwé-ìròyìn Ilé-Ìṣọ́nà àti Jí! àti àwọn ìtẹ̀jáde mìíràn tí ó fihàn bí àwọn ìlànà Bibeli ṣe bá àwọn ipò-ọ̀ràn pàtó kan mu.a Bí ó ti wù kí ó rí, nígbà tí ó ṣe pàtàkì fún alàgbà kan láti mọ́ àwọn ìtọ́sọ́nà tí a tẹ̀jáde nínú ìwé-ìkẹ́kọ̀ọ́ Watch Tower Society kí ó sì tẹ̀lé wọn, ó tún níláti mọ àwọn ìlànà Ìwé Mímọ́ tí ń bẹ lẹ́yìn wọn ní àmọ̀dunjú. Nígbà náà ni òun yóò wà ní ipò láti fi àwọn ìtọ́sọ́nà Ìwé Mímọ́ sílò pẹ̀lú òye àti ìyọ́nú.—Fiwé Mika 6:8.
Fífi Ẹ̀mí Kristian Ṣiṣẹ́sìn
10. Ìṣarasíhùwà búburú wo ni àwọn alàgbà níláti ṣọ́ra fún, àti lọ́nà wo?
10 Ní nǹkan bí ọdún 55 C.E., aposteli Paulu kọ lẹ́ta rẹ̀ àkọ́kọ́ sí ìjọ tí ó wà ní Korinti. Ọ̀kan nínú àwọn ìṣòro tí ó bójútó níí ṣe pẹ̀lú àwọn ọkùnrin kan tí wọ́n ń fẹ́ láti jẹ́ sàràkí ènìyàn nínú ìjọ. Paulu kọ̀wé pé: “A sáà tẹ́ yín lọ́rùn nísinsìnyí, a sáà ti sọ yín di ọlọ́rọ̀ nísinsìnyí, ẹ̀yin ti ń jọba láìsí wa: ìbá sì wù mí kí ẹ̀yin kí ó jọba, kí àwa kí ó lè jùmọ̀ jọba pẹ̀lú yín.” (1 Korinti 4:8) Ní ọ̀rúndún kìn-ín-ní C.E., gbogbo àwọn Kristian ni wọ́n ní ìrètí ṣíṣàkóso pẹ̀lú Jesu gẹ́gẹ́ bí ọba àti àlùfáà. (Ìfihàn 20:4, 6) Ṣùgbọ́n, ó ṣe kedere pé àwọn kan ní Korinti gbàgbé pé kò sí àwọn ọba nínú ìṣàkóso Ọlọrun ti àwọn Kristian lórí ilẹ̀-ayé. Dípò kí wọ́n hùwà bí àwọn ọba ayé yìí, àwọn Kristian olùṣọ́-àgùtàn mú ìrẹ̀lẹ̀-ọkàn dàgbà, ànímọ́ kan tí ó dùn mọ́ Jehofa nínú.—Orin Dafidi 138:6; Luku 22:25-27.
11. (a) Àwọn àpẹẹrẹ ìrẹ̀lẹ̀-ọkàn títayọ díẹ̀ wo ni a ní? (b) Ojú-ìwòye wo nípa araawọn ni àwọn alàgbà àti gbogbo àwọn Kristian yòókù níláti ní?
11 Ìrẹ̀lẹ̀-ọkàn ha jẹ́ àìlera bí? Kìí ṣe bẹ́ẹ̀ lọ́nàkọnà! A ṣàpèjúwe Jehofa fúnraarẹ̀ pé ó jẹ́ onírẹ̀lẹ̀-ọkàn. (Orin Dafidi 18:35) Àwọn ọba Israeli ṣáájú àwọn ẹgbẹ́-ọmọ-ogun lọ sójú ogun wọ́n sì ṣàkóso orílẹ̀-èdè náà lábẹ́ Jehofa. Síbẹ̀, ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn níláti ṣọ́ra “kí àyà rẹ̀ kí ó má baà gbéga ju àwọn arákùnrin rẹ̀ lọ.” (Deuteronomi 17:20) Jesu tí a jí dìde náà jẹ́ Ọba ti òkè ọ̀run. Bí ó ti wù kí ó rí, nígbà tí ó wà lórí ilẹ̀-ayé ó wẹ ẹsẹ̀ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀. Ẹ wo bí ìrẹ̀lẹ̀-ọkàn náà ti tó! Ní fífihàn pé ó fẹ́ kí àwọn aposteli rẹ̀ bákan-náà jẹ́ onírẹ̀lẹ̀-ọkàn, ó wí pé: “Ǹjẹ́ bí èmi tíí ṣe Oluwa ati Olùkọ́ni yín bá wẹ ẹsẹ̀ yín, ó tọ́ kí ẹ̀yin pẹ̀lú sì máa wẹ ẹsẹ̀ ara yín.” (Johannu 13:14; Filippi 2:5-8) Gbogbo ògo àti ìyìn níláti lọ sọ́dọ̀ Jehofa, kìí ṣe sọ́dọ̀ ènìyàn èyíkéyìí. (Ìfihàn 4:11) Yálà wọ́n jẹ́ alàgbà tàbí bẹ́ẹ̀kọ́, gbogbo àwọn Kristian níláti ronú nípa araawọn lójú-ìwòye àwọn ọ̀rọ̀ Jesu pé: “Aláìlérè ọmọ-ọ̀dọ̀ ni wá: èyí tíí ṣe iṣẹ́ wa láti ṣe, ni àwa ti ṣe.” (Luku 17:10) Ojú-ìwòye èyíkéyìí tí ó bá yàtọ̀ sí èyí kò bá ìlànà ìṣàkóso Ọlọrun mu.
12. Èéṣe tí ìfẹ́ fi jẹ́ ànímọ́ ṣíṣekókó fún àwọn Kristian alàgbà láti múdàgbà?
12 Papọ̀ pẹ̀lú ìrẹ̀lẹ̀-ọkàn, àwọn Kristian alàgbà mú ìfẹ́ dàgbà. Aposteli Johannu fi ìjẹ́pàtàkì ìfẹ́ hàn nígbà tí ó sọ pé: “Ẹni tí kò bá ní ìfẹ́ kò mọ Ọlọrun: nítorí pé ìfẹ́ ni Ọlọrun.” (1 Johannu 4:8) Àwọn ẹnìkọ̀ọ̀kan tí wọ́n jẹ́ aláìnífẹ̀ẹ́ kò bá ìlànà ìṣàkóso Ọlọrun mu. Wọn kò mọ Jehofa. Nípa ti Ọmọkùnrin Ọlọrun, Bibeli wí pé: “Fífẹ́ tí [Jesu] fẹ́ àwọn tirẹ̀ tí ó wà ní ayé, ó fẹ́ wọn títí dé òpin.” (Johannu 13:1) Nígbà tí ó ń bá àwọn ọkùnrin 11 tí wọn yóò jẹ́ apákan ẹgbẹ́ olùṣàkóso nínú ìjọ Kristian sọ̀rọ̀, Jesu wí pé: “Èyí ni òfin mi, pé kí ẹ̀yin kí ó fẹ́ràn ara yín, gẹ́gẹ́ bí mo ti fẹ́ràn yín.” (Johannu 15:12) Ìfẹ́ jẹ́ àmì tí a fi ń dá àwọn Kristian tòótọ́ mọ̀ yàtọ̀. Ó ń fa àwọn oníròbìnújẹ́-ọkàn, àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀, àti àwọn òǹdè tẹ̀mí tí wọn ń yánhànhàn fún òmìnira mọ́ra. (Isaiah 61:1, 2; Johannu 13:35) Àwọn alàgbà gbọ́dọ̀ jẹ́ àwòfiṣàpẹẹrẹ nínú fífi í hàn.
13. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ìṣòro lè nira lónìí, báwo ni alàgbà kan ṣe lè jẹ́ agbára ìdarí fún rere nínú ipò-ọ̀ràn gbogbo?
13 Lónìí, àwọn alàgbà ni a sábà máa ń késí láti bójútó àwọn ìṣòro lílọ́júpọ̀. Àwọn ìṣòro ìgbéyàwó lè jẹ́ èyí tí ó ta gbòǹgbò jinlẹ̀ tí ó sì ń báa lọ títí. Àwọn ọ̀dọ́ ní àwọn ìṣòro tí ó lè ṣòro fún àwọn àgbà láti lóye. Àwọn àìsàn èrò-ìmọ̀lára sábà máa ń ṣòro láti lóye. Alàgbà kan tí irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ dojúkọ lè ṣaláìní ìdánilójú nípa ohun tí ó yẹ láti ṣe. Ṣùgbọ́n ó lè ní ìgbọ́kànlé pé bí òun bá fi tàdúrà-tàdúrà gbójúlé ọgbọ́n Jehofa, bí òun bá ṣe ìwádìí nínú Bibeli àti nínú ìsọfúnni tí ẹrú olùṣòtítọ́ àti ọlọ́gbọ́n-inú náà tẹ̀jáde, àti bí òun bá fí ìrẹ̀lẹ̀-ọkàn àti ìfẹ́ bá àwọn àgùtàn lò, òun yóò jẹ́ agbára ìdarí fún rere kódà nínú àwọn ipò-ọ̀ràn tí ó ṣòro jùlọ pàápàá.
14, 15. Àwọn gbólóhùn-ọ̀rọ̀ díẹ̀ wo ní ń fihàn pé Jehofa ti fi ọ̀pọ̀ àwọn alàgbà rere bùkún àwọn ènìyàn rẹ̀?
14 Jehofa ti fi àwọn ‘ẹ̀bùn nínú ènìyàn’ bùkún ètò-àjọ rẹ̀ lọ́nà jaburata. (Efesu 4:8) Láti ìgbà dé ìgbà, Watch Tower Society ń gba àwọn lẹ́tà amọ́kànyọ̀ tí ń jẹ́rìí sí ìfẹ́ tí àwọn alàgbà onírẹ̀lẹ̀-ọkàn tí wọ́n ń fi ìyọ́nú ṣolùṣọ́ àwọn àgùtàn Ọlọrun fihàn. Fún àpẹẹrẹ, alàgbà ìjọ kan kọ̀wé pé: “Èmi kò lè rántí ìbẹ̀wò alábòójútó àyíká kan tí ó nípa lórí mi tàbí tí a ṣì ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ nínú ijọ ju èyí lọ. Alábòójútó àyíká náà ràn mí lọ́wọ́ láti rí ìjẹ́pàtàkì ẹ̀mí-ìrònú onífojúsọ́nà-fún-rere nígbà tí mó bá ń bá àwọn ará lò, pẹ̀lú ìtẹnumọ́ lórí gbígbóríyìn fúnni.”
15 Arábìnrin kan tí ó níláti rìnrìn-àjo lọ sí ilé-ìwòsàn kan tí ó jìnnà láti gba ìtọ́jú kọ̀wé pé: “Ẹ wò bí ó ti finilọ́kànbalẹ̀ tó láti pàdé alàgbà kan ní alẹ́ àkọ́kọ́ tí ó kún fún ìdàníyàn yẹn ní ilé-ìwòsàn kan tí ó jìnnà gan-an sí ilé! Òun àti àwọn arákùnrin mìíràn lo àkókò púpọ̀ pẹ̀lú mi. Kódà àwọn ènìyàn ayé tí wọ́n mọ̀ nípa ohun tí mo ń là kọjá nímọ̀lára pé kìbá tí ṣeéṣe fún mi láti yè é láìsí ìtùnú, ìtọ́jú, àti àdúrà àwọn arákùnrin onífẹ̀ẹ́ àti olùfọkànsìn wọnnì.” Arábìnrin mìíràn kọ̀wé pé: “Mo wàláàyè lónìí nítorí pé ẹgbẹ́ àwọn alàgbà fi sùúrù tọ́ mi sọ́nà jálẹ̀ ìjàkadì mi la ìsoríkọ́ líléwu-jọjọ já. . . . Arákùnrin kan àti aya rẹ̀ kò mọ ohun tí wọ́n lè sọ fún mi. . . . Ṣùgbọ́n ohun tí ó ru ìmọ̀lára mi sókè jùlọ ni pé bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn kò lóye ohun tí mo ń là kọjá pátápátá, wọ́n fi tìfẹ́tìfẹ́ ṣe ìtọ́jú mi.”
16. Ọ̀rọ̀-ìyànjú wo ni Peteru fifún àwọn alàgbà?
16 Bẹ́ẹ̀ni, ọ̀pọ̀ àwọn alàgbà ń fi ọ̀rọ̀-ìyànjú aposteli Peteru sílò pé: “Ẹ máa tọ́jú agbo Ọlọrun tí ń bẹ láàárín yín, ẹ máa bójútó o, kìí ṣe àfipáṣe, bíkòṣe tìfẹ́tìfẹ́; bẹ́ẹ̀ ni kìí ṣe ọ̀rọ̀ èrè ìjẹkújẹ, ṣùgbọ́n pẹ̀lú ọkàn tí ó múratán. Bẹ́ẹ̀ ni kìí ṣe bí ẹni tí ń lo agbára lórí ìjọ, ṣùgbọ́n kí ẹ ṣe ara yín ní àpẹẹrẹ fún agbo.” (1 Peteru 5:1-3) Ẹ wo ìbùkún tí irúfẹ́ àwọn alàgbà tí ń tẹ̀lé ìlànà ìṣàkóso Ọlọrun bẹ́ẹ̀ jẹ́!
Àwọn Àgùtàn Nínú Ìṣàkóso Ọlọrun
17. Dárúkọ àwọn ànímọ́ díẹ̀ tí ó yẹ kí gbogbo mẹ́ḿbà ìjọ mú dàgbà.
17 Bí ó ti wù kí ó rí, kìí ṣe kìkì àwọn alàgbà ni wọ́n wà nínú ìṣàkóso Ọlọrun. Bí àwọn olùṣọ́-àgùtàn bá gbọ́dọ̀ tẹ̀lé ìlànà ìṣàkóso Ọlọrun, àwọn àgùtàn gbọ́dọ̀ ṣe bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú. Ní àwọn ọ̀nà wo? Ó dára, ìlànà kan náà tí ń ṣamọ̀nà àwọn olùṣọ́-àgùtàn ni ó gbọ́dọ̀ ṣamọ̀nà àwọn àgùtàn. Gbogbo Kristian pátá, kìí ṣe àwọn alàgbà nìkan, ni wọ́n gbọ́dọ̀ jẹ́ onírẹ̀lẹ̀-ọkàn bí wọ́n bá níláti gba ìbùkún Jehofa. (Jakọbu 4:6) Ẹni gbogbo nínú ìjọ gbọ́dọ̀ mú ìfẹ́ dàgbà nítorí pé láìsí i àwọn ìrúbọ tí a ń ṣe fún Jehofa kò ní mú inú rẹ̀ dùn. (1 Korinti 13:1-3) Àti pé gbogbo wa, kìí ṣe àwọn alàgbà nìkan, níláti “kún fún ìmọ̀ pípéye nípa ìfẹ́-inú [Jehofa] nínú ọgbọ́n gbogbo àti ìfinúmòye ti Ẹ̀mí.”—Kolosse 1:9, NW.
18. (a) Èéṣe tí ìmọ̀ oréfèé lásán nípa òtítọ́ kò fi tó? (b) Báwo ni gbogbo wa ṣe lè kún fún ìmọ̀ pípéye?
18 Tàgbà-tèwe bákan-náà pẹ̀lú ni àwọn ìpinnu tí ó ṣòro ń dojúkọ nígbà gbogbo bí wọn ti ń gbìyànjú láti dúró gẹ́gẹ́ bí olùṣòtítọ́ láìka gbígbé nínú ayé Satani sí. Ìtẹ̀sí ayé níti aṣọ, orin, àwòrán sinimá, àti ìwé ń pe ipò tẹ̀mí àwọn kan níjà. Ìmọ̀ òtítọ́ oréfèé kò tó láti ràn wá lọ́wọ́ láti di ìdúródéédéé wa mú. Láti ní ìdánilójú dídúró gẹ́gẹ́ bí olùṣòtítọ́, a gbọ́dọ̀ kún fún ìmọ̀ pípéye. A nílò ìwòyemọ̀ àti ọgbọ́n tí Ọ̀rọ̀ Ọlọrun nìkanṣoṣo lè fi fún wa. (Owe 2:1-5) Èyí túmọ̀sí mímú àṣà ìkẹ́kọ̀ọ́ dídára dàgbà, ṣíṣàṣàrò lórí ohun tí a ń kọ́, àti fífi í sílò. (Orin Dafidi 1:1-3; Ìfihàn 1:3) Paulu ń kọ̀wé sí gbogbo àwọn Kristian, kìí ṣe àwọn alàgbà nìkan, nígbà tí ó wí pé: “Oúnjẹ líle ni fún àwọn tí ó dàgbà, àwọn ẹni nípa ìrírí, tí wọ́n ń lo ọgbọ́n wọn láti fi ìyàtọ̀ sáàárín rere àti búburú.”—Heberu 5:14.
Àwọn Olùṣọ́-Àgùtàn àti Àwọn Àgùtàn Ń Ṣiṣẹ́ Papọ̀
19, 20. Àwọn ọ̀rọ̀-ìyànjú wo ni a fifún gbogbo wa láti fọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn alàgbà, èésìtiṣe?
19 Ní àkótán, a níláti sọ pé ẹ̀mí tí ó jẹ́ ti ìṣàkóso Ọlọrun níti tòótọ́ ni àwọn wọnnì tí wọ́n ń fọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn alàgbà ń fihàn. Paulu kọ̀wé sí Timoteu pé: “Àwọn alàgbà tí ó ṣe àkóso dáradára ni kí a kà yẹ sí ọlá ìlọ́po méjì, pẹ̀lúpẹ̀lù àwọn tí ó ṣe làálàá ní ọ̀rọ̀ àti ní kíkọ́ni.” (1 Timoteu 5:17; 1 Peteru 5:5, 6) Àǹfààní àgbàyanu kan ní ipò alàgbà jẹ́, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ jùlọ nínú àwọn alàgbà jẹ́ onídìílé tí wọn ń lọ sẹ́nu iṣẹ́ oúnjẹ-òòjọ́ wọn lójoojúmọ́ tí wọ́n sì ní aya àti àwọn ọmọ láti tọ́jú. Nígbà tí wọ́n láyọ̀ láti ṣiṣẹ́sìn, iṣẹ́-ìsìn wọn rọrùn ó sì túbọ̀ ń mú èrè wá nígbà tí ìjọ bá fọwọ́sowọ́pọ̀, tí wọn kò lekoko tí wọn kò sì béèrè fún àfiyèsí tí ó pọ̀ ju bí ó ti yẹ lọ.—Heberu 13:17.
20 Aposteli Paulu wí pé: “Ẹ máa rántí àwọn wọnnì tí ń mú ipò iwájú láàárín yín, tí wọ́n ti sọ ọ̀rọ̀ Ọlọrun fún yín, bí ẹ sì ti ń gbé bí ìwà wọn ti jásí ròwò ẹ máa farawé ìgbàgbọ́ wọ́n.” (Heberu 13:7, NW) Bẹ́ẹ̀kọ́, Paulu kò fún àwọn ará ní ìṣírí láti máa tọ àwọn alàgbà lẹ́yìn. (1 Korinti 1:12) Títọ ènìyàn lẹ́yìn kò bá ìlànà ìṣàkóso Ọlọrun mú. Ṣùgbọ́n ó dájú pé ó bá ọgbọ́n mu láti ṣàfarawé ìgbàgbọ́ pípegedé ti alàgbà kan tí ń hùwà ní ìbámu pẹ̀lú ìlànà ìṣàkóso Ọlọrun, tí ó jẹ́ aláápọn nínú iṣẹ́ ìjíhìnrere, tí ó ń wá sí àwọn ìpàdé déédéé, tí ó sì ń fi ìrẹ̀lẹ̀-ọkàn àti ìfẹ́ bá ìjọ lò.
Ẹ̀rí kan sí Ìgbàgbọ́
21. Báwo ni àwọn Kristian ṣe ń fi ìgbàgbọ́ lílágbára bíi ti Mose hàn?
21 Nítòótọ́, wíwà ètò-àjọ ìṣàkóso Ọlọrun kan ní àkókò ìjẹràbàjẹ́ gan-an yìí nínú ọ̀rọ̀-ìtàn ènìyàn jẹ́ ẹ̀rí sí agbára Ọlọrun Alákòóso Ńlá náà. (Isaiah 2:2-5) Ó tún jẹ́ ẹ̀rí sí ìgbàgbọ́ àwọn Kristian ọkùnrin, obìnrin, àti àwọn ọmọdé tí iye wọn fẹ́rẹ̀ẹ́ tó million márùn-ún, tí wọ́n ń jìjàkadì pẹ̀lú àwọn ìṣòro ìgbésí-ayé ojoojúmọ́ ṣùgbọ́n tí wọn kò jẹ́ gbàgbé pé Jehofa ni Alákòóso wọn. Gan-an gẹ́gẹ́ bí Mose ti “dúróṣinṣin bí ẹni tí ó ń rí ẹni àìrí,” bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn Kristian lónìí ní irú ìgbàgbọ́ lílágbára bẹ́ẹ̀. (Heberu 11:27) Wọ́n ní àǹfààní láti gbé lábẹ́ ìṣàkóso Ọlọrun, wọ́n sì ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Jehofa fún èyí lójoojúmọ́. (Orin Dafidi 100:4, 5) Bí wọ́n ti ń ní ìrírí agbára ìgbàlà Jehofa, wọ́n láyọ̀ láti polongo pé: “Jehofa ni Onídàájọ́ wa, Jehofa ni Olùfúnni-ní-ìlànà-òfin wa, Jehofa ni Ọba wa; òun fúnraarẹ̀ yóò gbà wá là.”—Isaiah 33:22, NW.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Lára irú àwọn ìtẹ̀jáde bẹ́ẹ̀ ni ìwé náà “Ẹ Kiyesi Ara Yin àti si Gbogbo Agbo,” èyí tí ó ní àwọn ìtọ́sọ́nà tí ó bá Ìwé Mímọ́ mu nínú tí a sì fún àwọn alábòójútó tí a yànsípò, tàbí àwọn alàgbà.
Kí Ni Bibeli Fihàn?
◻ Ní ọ̀nà wo ni àwọn Kristian ń gbà tẹríba fún ìṣàkóso Ọlọrun?
◻ Báwo ni a ṣe ṣètò ìṣàkóso Ọlọrun lónìí?
◻ Ní àwọn ọ̀nà wo ni àwọn alàgbà níláti gbà múra araawọn sílẹ̀ láti mú àwọn ẹrù-iṣẹ́ wọn ṣẹ?
◻ Àwọn ànímọ́ Kristian wo ni wọ́n ṣekókó fún àwọn alàgbà láti mú dàgbà kí wọ́n sì fihàn?
◻ Lábẹ́ ìṣàkóso Ọlọrun, ipò-ìbátan wo ni ó níláti wà láàárín àwọn àgùtàn àti àwọn olùṣọ́-àgùtàn?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]
Adamu àti Efa pàdánù Paradise nítorí pé wọ́n fẹ́ láti ṣe àwọn ìpinnu fúnraawọn nípa ohun tí ó tọ́ àti ohun tí kò tọ́
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
Bí alàgbà kan bá fi ìrẹ̀lẹ̀-ọkàn àti ìfẹ́ bá àwọn àgùtàn lò, nígbà gbogbo ni òun yóò máa jẹ́ agbára ìdarí fún rere