ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w94 1/15 ojú ìwé 10-15
  • Jehofa Ń Ṣàkóso—Nípasẹ̀ Ìṣàkóso Ọlọrun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Jehofa Ń Ṣàkóso—Nípasẹ̀ Ìṣàkóso Ọlọrun
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • A Bí Ìṣàkóso Ọlọrun Kan
  • Ọlá-Àṣẹ Lábẹ́ Ìṣàkóso Ọlọrun
  • Àwọn Ìṣe àti Ìwà tí Kò bá Ìlànà Ìṣàkóso Ọlọrun Mu
  • Òpin Ìṣàkóso Ọlọrun Kan
  • Ìṣàkóso Ọlọrun Titun Kan
  • Fara Mọ́ Ìṣàkóso Ọlọ́run Tímọ́tímọ́
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
  • Àwọn Olùṣọ́-Àgùtàn Àti Àwọn Àgùtàn Nínú Ìṣàkóso Ọlọrun
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
  • Ṣíṣe Oluṣọ-agutan Pẹlu Atobilọla Ẹlẹdaa Wa
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
  • Ìṣàkóso Jèhófà Ló Dára Jù Lọ!
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2010
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
w94 1/15 ojú ìwé 10-15

Jehofa Ń Ṣàkóso​—⁠Nípasẹ̀ Ìṣàkóso Ọlọrun

“Jehofa yóò jẹ́ ọba fún àkókò títílọgbére.”​—⁠ORIN DAFIDI 146:⁠10, NW.

1, 2. (a) Èéṣe tí ìsapá ènìyàn síhà agbára ìṣàkóso fi kùnà? (b) Irú àkóso wo ni ó jẹ́ ọ̀kanṣoṣo tí ó ti yọrísírere nítòótọ́?

LÁTI ìgbà Nimrodu wá, àwọn ènìyàn ti gbìyànjú àwọn ọ̀nà yíyàtọ̀síra láti ṣàkóso ẹgbẹ́-àwùjọ ènìyàn. Àwọn ìjọba bóofẹ́-bóokọ̀, ìjọba ọba-àjẹbí-aláṣẹ, ìjọba ẹlẹ́ni kéréje, àti onírúurú àwọn ìjọba dẹmọ ti wà. Jehofa ti gba gbogbo wọn láàyè. Nítòótọ́, níwọ̀nbí ó ti jẹ́ pé Ọlọrun ni ìpẹ̀kun Orísun gbogbo ọlá-àṣẹ, ní èrò-ìtúmọ̀ kan ó fi àwọn alákòóso yíyàtọ̀síra náà sí àwọn ipò-àyè wọn tí ó ní ààlà. (Romu 13:⁠1) Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, gbogbo ìsapá ènìyàn síhà àkóso ti kùnà. Kò sí alákòóso ènìyàn kan tí ó tíì mú ẹgbẹ́-àwùjọ wíwàpẹ́títí kan, tí ó fẹsẹ̀múlẹ̀, tí ó sì bá ìdájọ́ òdodo mú wá rí. Ní gbogbo ìgbà ṣáá ni ó jẹ́ pé, “ẹnìkan ń ṣe olórí ẹnìkejì fún ìfarapa rẹ̀.”​—⁠Oniwasu 8:⁠9.

2 Èyí ha níláti yà wá lẹ́nu bí? Dájúdájú bẹ́ẹ̀kọ́! Ènìyàn aláìpé ni a kò dá láti ṣàkóso ara rẹ̀. “Ọ̀nà ènìyàn kò sí ní ipa ara rẹ̀: kò sí ní ipá ènìyàn tí ń rìn, láti tọ́ ìṣísẹ̀ rẹ̀.” (Jeremiah 10:23) Ìdí rẹ̀ nìyẹn tí ó fi jẹ́ pé, jálẹ̀ gbogbo ọ̀rọ̀-ìtàn ènìyàn, kìkì irú àkóso kan ni ó ti yọrísírere nítòótọ́. Èwo nìyẹn? Ìṣàkóso Ọlọrun lábẹ́ Jehofa Ọlọrun. Nínú èdè Griki ti ìgbà tí a kọ Bibeli, “ìṣàkóso Ọlọrun” (theocracy) túmọ̀sí “ìṣàkóso” (rule) [kraʹtos] “nípasẹ̀ Ọlọrun” (by God) [the·osʹ]. Àkóso wo ni ó tún lè sàn ju ti Jehofa Ọlọrun fúnraarẹ̀ lọ?​—⁠Orin Dafidi 146:⁠10.

3. Kí ni àwọn àpẹẹrẹ ìjímìjí díẹ̀ nípa wíwà ìṣàkóso Ọlọrun lórí ilẹ̀-ayé?

3 Ìṣàkóso Ọlọrun lo agbára ìdarí fún àkókò kúkúrú ní Edeni, títí di ìgbà tí Adamu àti Efa ṣọ̀tẹ̀ lòdìsí Jehofa. (Genesisi 3:​1-6, 23) Ní àkókò Abrahamu, ó dàbí ẹni pé ìṣàkóso Ọlọrun kan ti wà ní ìlú-ńlá Salemu, tí ó ní Melkisedeki gẹ́gẹ́ bí ọba-òun-àlùfáà. (Genesisi 14:​18-⁠20; Heberu 7:​1-⁠3) Bí ó ti wù kí ó rí, ìṣàkóso Ọlọrun àkọ́kọ́ tí ó jẹ́ ti orílẹ̀-èdè lábẹ́ Jehofa Ọlọrun ni a fìdí rẹ̀ múlẹ̀ ní aginjù Sinai ní ọ̀rúndún kẹrìndínlógún B.C.E. Báwo ni ìyẹn ṣe wáyé? Báwo sì ni àkóso ti ìṣàkóso Ọlọrun yẹn ṣe ṣiṣẹ́?

A Bí Ìṣàkóso Ọlọrun Kan

4. Báwo ni Jehofa ṣe gbé orílẹ̀-èdè ìṣàkóso Ọlọrun ti Israeli kalẹ̀?

4 Ní 1513 B.C.E., Jehofa gba àwọn ọmọ Israeli sílẹ̀ kúrò nínú ìsìnrú ní Egipti ó sì pa àwọn ẹgbẹ́-ọmọ-ogun Farao tí ń lépa wọn run nínú Òkun Pupa. Lẹ́yìn náà ni Ó darí àwọn ọmọ Israeli lọ sí Òkè Sinai. Nígbà tí wọ́n dóbùdó sí ẹsẹ̀ òkè-ńlá náà, Ọlọrun sọ fún wọn nípasẹ̀ Mose pé: “Ẹ̀yin ti rí ohun tí mo ti ṣe sí àwọn ará Egipti, àti bí mo ti rù yín ní apá-ìyẹ́ idì, tí mo sì mú yín tọ araàmi wá. Ǹjẹ́ nísinsìnyí, bí ẹ̀yin bá fẹ́ gba ohùn mi gbọ́ nítòótọ́, tí ẹ ó sì pa májẹ̀mú mi mọ́, nígbà náà ni ẹ̀yin óò jẹ́ ìṣúra fún mi ju gbogbo ènìyàn lọ.” Àwọn ọmọ Israeli dáhùnpadà pé: “Ohun gbogbo tí OLUWA wí ni àwa ó ṣe.” (Eksodu 19:​4, 5, 8) Májẹ̀mú kan ni a dá, a sì bí Israeli orílẹ̀-èdè ìṣàkóso Ọlọrun.​—⁠Deuteronomi 26:​18, 19.

5. Báwo ni a ṣe lè sọ pé Jehofa ṣàkóso ní Israeli?

5 Ṣùgbọ́n, ní ọ̀nà wo ni Jehofa tí ojú ènìyàn kò lè rí gbà ṣàkóso Israeli? (Eksodu 33:20) Níti pé Jehofa ni ó fún orílẹ̀-èdè náà ní àwọn òfin àti ẹgbẹ́-àlùfáà rẹ̀. Àwọn wọnnì tí wọ́n ṣègbọràn sí àwọn òfin náà tí wọ́n sì jọ́sìn ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ìṣètò tí a paláṣẹ látọ̀runwá ṣiṣẹ́sin Ọlọrun Alákòóso Ńlá náà, Jehofa. Ní àfikún síi, àlùfáà àgbà ní Urimu àti Tummimu, nípasẹ̀ èyí tí Jehofa Ọlọrun ń pèsè ìtọ́sọ́nà nígbà tí àwọn ọ̀ràn pàjáwìrì bá ṣẹlẹ̀. (Eksodu 28:​29, 30) Síwájú síi, àwọn àgbà ọkùnrin tí wọ́n tóótun jẹ́ aṣojú fún Jehofa nínú ìṣàkóso Ọlọrun náà wọ́n sì ń rí síi pé Òfin Ọlọrun ni a fisílò. Bí a bá gbé àkọsílẹ̀ díẹ̀ lára àwọn ọkùnrin wọ̀nyí yẹ̀wò, àwa yóò ní òye tí ó sànjù nípa bí àwọn ènìyàn ṣe níláti tẹríba fún ìṣàkóso Ọlọrun.

Ọlá-Àṣẹ Lábẹ́ Ìṣàkóso Ọlọrun

6. Èéṣe tí ó fi jẹ́ ìpèníjà fún àwọn ènìyàn láti di ọlá-àṣẹ mú nínú ìṣàkóso Ọlọrun, irú àwọn ènìyàn wo ni a sì nílò fún ẹrù-iṣẹ́ yìí?

6 Àwọn wọnnì tí wọ́n wà ní ipò ọlá-àṣẹ ní Israeli ní àǹfààní ńlá, ṣùgbọ́n ìpèníjà ni fún wọn láti pa ìwàdéédéé wọn mọ́. Wọ́n níláti ṣọ́ra kí iyì ara wọn máṣe di èyí tí ó ṣe pàtàkì ju ìsọdimímọ́ orúkọ Jehofa. Gbólóhùn onímìísí náà pé “kò sí ní ipá ènìyàn tí ń rìn, láti tọ́ ìṣísẹ̀ rẹ̀” jẹ́ òtítọ́ nípa àwọn ọmọ Israeli bí ó ti rí fún gbogbo aráyé yòókù. Israeli gbilẹ̀ kìkì nígbà tí àwọn àgbà ọkùnrin bá rántí pé Israeli wà lábẹ́ ìṣàkóso Ọlọrun àti pé wọ́n níláti ṣe ìfẹ́-inú Jehofa, kìí ṣe tiwọn. Láìpẹ́ lẹ́yìn ìdásílẹ̀ ilẹ̀ Israeli, àna Mose, Jetro, ṣàpèjúwe irú àwọn ọkùnrin tí wọ́n níláti jẹ́ lọ́nà tí ó dára, ìyẹn ni, “àwọn ọkùnrin tí ó tó, tí ó bẹ̀rù Ọlọrun, àwọn ọkùnrin olóòótọ́, tí ó kórìíra ojúkòkòrò.”​—⁠Eksodu 18:⁠21.

7. Ní àwọn ọ̀nà wo ni Mose gbà jẹ́ àpẹẹrẹ rere níti ẹnìkan tí ó di ọlá-àṣẹ mú lábẹ́ Jehofa Ọlọrun?

7 Ẹni tí ó kọ́kọ́ lo ọlá-àṣẹ gíga ní Israeli ni Mose. Òun jẹ́ àpẹẹrẹ rere níti ẹni tí ó lo ọlá-àṣẹ ìṣàkóso Ọlọrun. Lóòótọ́, ní àkókò-ìṣẹ̀lẹ̀ kan àìlera ti ẹ̀dá farahàn. Bí ó ti wù kí ó rí, nígbà gbogbo ni Mose gbíyèlé Jehofa. Nígbà tí ìbéèrè bá dìde nípa ọ̀ràn tí a kò tíì pinnu rẹ̀, òun máa ń wá ìtọ́sọ́nà Jehofa. (Fiwé Numeri 15:​32-⁠36.) Báwo ni Mose ṣe kọ ìdẹwò láti lo ipò gíga tí ó ní fún ògo araarẹ̀? Ó dára, bí òun tilẹ̀ jẹ́ aṣáájú fún orílẹ̀-èdè tí ó ní àràádọ́ta-ọ̀kẹ́ ènìyàn, “ó ṣe ọlọ́kàntútù ju gbogbo ènìyàn lọ tí ń bẹ lórí ilẹ̀.” (Numeri 12:⁠3) Kò ní àwọn ìlépa-àṣeyọrí ti ara-ẹni ṣùgbọ́n ó ń ṣàníyàn nípa ògo ti Ọlọrun. (Eksodu 32:​7-⁠14) Mose tún ní ìgbàgbọ́ lílágbára. Ní sísọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ kí ó tó di aṣáájú orílẹ̀-èdè, aposteli Paulu sọ pé: “Ó dúró ṣinṣin bí ẹni tí ó ń rí ẹni àìrí.” (Heberu 11:27) Ní kedere, Mose kò gbàgbé rí pé Jehofa ni Alákòóso tòótọ́ fún orílẹ̀-èdè náà. (Orin Dafidi 90:​1, 2) Ẹ wo àpẹẹrẹ rere tí ìyẹn jẹ́ fún wa lónìí!

8. Àṣẹ wo ni Jehofa fifún Joṣua, èésìtiṣe tí èyí fi yẹ fún àfiyèsí?

8 Nígbà tí ẹ̀rí fihàn pé ìṣàbójútó Israeli ti pọ̀ jù fún Mose nìkanṣoṣo, Jehofa fi ẹ̀mí rẹ̀ sára 70 àwọn àgbà ọkùnrin tí wọn yóò ṣètìlẹ́yìn fún un láti máa ṣèdájọ́ orílẹ̀-èdè náà. (Numeri 11:​16-⁠25) Ní àwọn ọdún ẹ̀yìnwá ìgbà náà ìlú-ńlá kọ̀ọ̀kan yóò ní àwọn àgbà ọkùnrin tirẹ̀. (Fiwé Deuteronomi 19:12; 22:15-⁠18; 25:7-⁠9.) Lẹ́yìn tí Mose kú, Jehofa fi Joṣua ṣe aṣáájú orílẹ̀-èdè náà. A lè ronú pé pẹ̀lú àǹfààní yìí, Joṣua ní púpọ̀ láti ṣe. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, Jehofa sọ fún un pé ohun kan wà tí kò gbọ́dọ̀ gbójúfòdá láé: “Ìwé òfin yìí kò gbọ́dọ̀ kúrò ní ẹnu rẹ, ṣùgbọ́n ìwọ ó máa ṣe àṣàrò nínú rẹ̀ ní ọ̀sán àti ní òru, kí ìwọ kí ó lè kíyèsí àti ṣe gẹ́gẹ́ bí gbogbo èyí tí a kọ sínú rẹ̀.” (Joṣua 1:⁠8) Ṣàkíyèsí pé bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Joṣua ti sìn fún ohun tí ó ju 40 ọdún sẹ́yìn, ó gbọ́dọ̀ máa báa lọ ní kíka Òfin náà. Àwa pẹ̀lú gbọ́dọ̀ máa kẹ́kọ̀ọ́ láti inú Bibeli kí a sì tu ọkàn wa lára níti àwọn òfin àti ìlànà Jehofa​—⁠láìka bí ó ti pẹ́ tó tí a ti ń ṣiṣẹ́sìn tàbí bí àwọn àǹfààní tí a ni ti pọ̀ tó sí.​—⁠Orin Dafidi 119:​111, 112.

9. Kí ni ó ṣẹlẹ̀ ní Israeli ní àkókò àwọn onídàájọ́?

9 Ọ̀wọ́ àwọn onídàájọ́ tẹ̀lé e lẹ́yìn Joṣua. Lọ́nà tí kò múniláyọ̀, lemọ́lemọ́ ni àwọn ọmọ Israeli “ṣe búburú níwájú OLUWA,” ní àkókò tiwọn. (Awọn Onidajọ 2:11) Nípa àkókò àwọn onidajọ, àkọsílẹ̀ náà sọ pé: “Ní ọjọ́ wọnnì ọba kan kò sí ní Israeli: olúkúlùkù ń ṣe èyí tí ó tọ́ ní ojú ara rẹ̀.” (Awọn Onidajọ 21:25) Ẹnìkọ̀ọ̀kan ń ṣe àwọn ìpinnu tirẹ̀ nípa ìwà àti ìjọsìn, ọ̀rọ̀-ìtàn sì fihàn pé ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ Israeli ṣe àwọn ìpinnu búburú. Wọ́n ṣúbu sínú ìjọsìn òrìṣà wọ́n sì hu àwọn ìwà-ọ̀daràn bíburú jù ní àwọn ìgbà mìíràn. (Awọn Onidajọ 19:​25-⁠30) Ṣùgbọ́n, àwọn kan fi ìgbàgbọ́ àwòfiṣàpẹẹrẹ hàn.​—⁠Heberu 11:​32-⁠38.

10. Báwo ni àkóso ṣe yípadà tegbòtigaga ní Israeli ní àkókò Samueli, kí ni ó sì ṣamọ̀nà sí èyí?

10 Ní àkókò ìgbésí-ayé Samueli, onídàájọ́ tí ó gbẹ̀yìn, Israeli kó sínú yánpọnyánrin níti àkóso. Bí àwọn orílẹ̀-èdè ọ̀tá tí ó yí wọn ká tí ọba ń ṣàkóso ti nípa lé wọn lórí, àwọn ọmọ Israeli ronú pé àwọn pẹ̀lú ń fẹ́ ọba kan. Wọ́n gbàgbé pé wọ́n ti ní Ọba kan tẹ́lẹ̀, pé àkóso wọn jẹ́ ti ìṣàkóso Ọlọrun. Jehofa sọ fún Samueli pé: “Ìwọ kí wọ́n kọ̀, ṣùgbọ́n èmi ni wọ́n kọ̀ láti jẹ́ ọba lórí wọn.” (1 Samueli 8:⁠7) Àpẹẹrẹ wọn rán wa létí bí ó ti rọrùn tó láti pàdánù ojú-ìwòye wa tẹ̀mí kí ayé tí ó yí wa ká sì nípa lé wa lórí.​—⁠Fiwé 1 Korinti 2:​14-⁠16.

11. (a) Láìka ìyípadà nínú àkóso sí, báwo ní a ṣe lè sọ pé Israeli ń báa lọ ní jíjẹ́ ìṣàkóso Ọlọrun lábẹ́ àwọn ọba? (b) Àṣẹ wo ni Jehofa fifún àwọn ọba Israeli, pẹ̀lú ète wo sì ni?

11 Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, Jehofa gba ohun tí àwọn ọmọ Israeli béèrè fún ó sì yan ọba wọn méjì àkọ́kọ́, Saulu àti Dafidi. Israeli ń báa lọ láti máa wà lábẹ́ ìṣàkóso Ọlọrun, tí Jehofa ń ṣàkóso. Kí àwọn ọba rẹ̀ baà rántí èyí, a sọ ọ́ di dandan fún ọ̀kọ̀ọ̀kan nínú wọn láti ṣe ẹ̀dà tirẹ̀ nínú Òfin kí ó sì máa kà á lójoojúmọ́, “kí ó lè máa kọ́ àti bẹ̀rù OLUWA Ọlọrun rẹ̀, láti máa pa gbogbo òfin yìí mọ́ àti ìlànà wọ̀nyí, láti máa ṣe wọ́n: kí àyà rẹ̀ kí ó má baà gbéga ju àwọn arákùnrin rẹ̀ lọ.” (Deuteronomi 17:​19, 20) Bẹ́ẹ̀ni, Jehofa nífẹ̀ẹ́-ọkàn síi pé àwọn wọnnì tí wọ́n ní ọlá-àṣẹ nínú ìṣàkóso Ọlọrun tí ó jẹ́ tirẹ̀ kò níláti gbé araawọn ga àti pé àwọn ìgbégbèésẹ̀ wọn níláti gbé Òfin rẹ̀ yọ.

12. Àkọsílẹ̀ ìṣòtítọ́ wo ni Ọba Dafidi ní?

12 Ọba Dafidi ní ìgbàgbọ́ títayọ nínú Jehofa, Ọlọrun sì dá májẹ̀mú náà pé yóò di baba ìlà àwọn ọba tí yóò wà títíláé. (2 Samueli 7:16; 1 Awọn Ọba 9:5; Orin Dafidi 89:29) Ìtẹríba onírẹ̀lẹ̀-ọkàn Dafidi fún Jehofa yẹ ní fífarawé. Ó sọ pé: “Ọba yóò máa yọ̀ ní agbára rẹ, Oluwa; àti ní ìgbàlà rẹ, yóò ti yọ̀ pọ̀ tó!” (Orin Dafidi 21:⁠1) Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Dafidi kùnà ní àwọn ìgbà mìíràn nítorí àìlera ti ẹran-ara, gẹ́gẹ́ bí ìlànà àfilélẹ̀ ó gbójúlé okun Jehofa, kìí ṣe lé okun ti araarẹ̀.

Àwọn Ìṣe àti Ìwà tí Kò bá Ìlànà Ìṣàkóso Ọlọrun Mu

13, 14. Kí ni díẹ̀ lára àwọn ìgbésẹ̀ tí kò bá ìlànà ìṣàkóso Ọlọrun mú tí àwọn olùrọ́pò Dafidi gbé?

13 Kìí ṣe gbogbo àwọn aṣáájú àwọn ọmọ Israeli ni wọ́n dàbí Mose àti Dafidi. Ọ̀pọ̀ fi àìbọ̀wọ̀ bíburú lílékenkà hàn fún ìṣètò ìṣàkóso Ọlọrun, ní fífi àyè gba ìjọsìn èké ní Israeli. Kódà, ní àwọn ìgbà mìíràn díẹ̀ nínú àwọn alákòóso tí wọ́n jẹ́ olùṣòtítọ́ hùwà lọ́nà tí kò bá ìlànà ìṣàkoso Ọlọrun mu. Ọ̀ràn ti Solomoni tí a fi ọgbọ́n ńláǹlà àti aásìkí jíǹkí, báninínújẹ́ gidigidi. (1 Awọn Ọba 4:​25, 29) Síbẹ̀, láìka òfin Jehofa sí, ó fẹ́ aya púpọ̀ ó sì fàyègba ìjọsìn òrìṣà ní Israeli. Lọ́nà tí ó hàn gbangba, ìṣàkóso Solomoni jẹ́ atẹnilóríba ní àwọn ọdún rẹ̀ tí ó kẹ́yìn.​—⁠Deuteronomi 17:​14-⁠17; 1 Awọn Ọba 11:1-⁠8; 12:⁠4.

14 Rehoboamu ọmọkùnrin Solomoni dojúkọ ìbéèrè dandangbọ̀n kan pé kí ó mú ẹrù àwọn ọmọ-abẹ́ rẹ̀ fúyẹ́. Dípò kí ó fi ìwàtútù bójútó ipò-ọ̀ràn náà, ó fi jàgídíjàgan lo ọlá-àṣẹ rẹ̀​—⁠ó si pàdánù 10 nínú ẹ̀yà 12 náà. (2 Kronika 10:​4-⁠17) Jeroboamu ni ọba àkọ́kọ́ nínú ìjọba ẹ̀yà-mẹ́wàá tí ó yapa kúrò náà. Nínú ìsapá kan láti ríi dájú pé ìjọba rẹ̀ kò ní darapọ̀ mọ́ orílẹ̀-èdè ọmọ-ìyá rẹ̀ lẹ́ẹ̀kan síi, ó gbé ìjọsìn ọmọ-màlúù kalẹ̀. Èyí ti lè dàbí ìgbésẹ̀ ọlọgbọ́n kan lọ́nà ti ìṣèlú, ṣùgbọ́n ó fi ìwà-àìkàsí bíburú jáì hàn fún ìṣàkóso Ọlọrun. (1 Awọn Ọba 12:​26-⁠30) Lẹ́yìn náà, ní ìparí ìwàláàyè gígùn ti iṣẹ́-ìsìn tí ó fi ìṣòtítọ́ ṣe, Ọba Asa gba ìgbéraga láàyè láti kó àbààwọ́n bá àkọsílẹ̀ rẹ̀. Ó fi ojú wòlíì náà tí ó mú ìmọ̀ràn láti ọ̀dọ̀ Jehofa tọ̀ ọ́ wá gbolẹ̀. (2 Kronika 16:​7-⁠11) Bẹ́ẹ̀ni, àní àwọn ènìyàn ọlọ́jọ́-pípẹ́ pàápàá nílò ìmọ̀ràn nígbà mìíràn.

Òpin Ìṣàkóso Ọlọrun Kan

15. Nígbà tí Jesu wà lórí ilẹ̀-ayé, báwo ni àwọn aṣáájú àwọn Ju ṣe kùnà gẹ́gẹ́ bí ẹni pàtàkì tí ó ní ọlá-àṣẹ nínú ìṣàkóso Ọlọrun?

15 Nígbà tí Jesu Kristi wà lórí ilẹ̀-ayé, Israeli ṣì wà lábẹ́ ìṣàkóso Ọlọrun. Ṣùgbọ́n, ó baninínújẹ́ pé ọ̀pọ̀ nínú àwọn àgbà ọkùnrin rẹ̀ tí wọ́n ṣeé fi ẹrù iṣẹ́ lé lọ́wọ́ ni wọn kò gbé àwọn nǹkan tẹ̀mí lé ọkàn. Nítòótọ́ wọ́n kùnà láti mú ọkàntútù tí Mose fihàn dàgbà. Jesu tọ́ka sí ìwà-ìbàjẹ́ tẹ̀mí wọn nígbà tí ó sọ pé: “Àwọn akọ̀wé pẹ̀lú àwọn Farisi jókòó ní ipò Mose: nítorí náà ohunkóhun gbogbo tí wọ́n bá wí pé kí ẹ kíyèsí, ẹ máa kíyèsí wọn kí ẹ sì máa ṣe wọ́n; ṣùgbọ́n ẹ má ṣe gẹ́gẹ́ bí ìṣe wọn: nítorí tí wọn a máa wí, ṣùgbọ́n wọn kìí ṣe.”​—⁠Matteu 23:​2, 3.

16. Báwo ni àwọn aṣáájú àwọn Ju ní ọ̀rúndún kìn-⁠ín-⁠ní ṣe fihàn pé àwọn kò ní ọ̀wọ̀ fún ìṣàkóso Ọlọrun?

16 Lẹ́yìn tí wọ́n ti fi Jesu lé Pontiu Pilatu lọ́wọ́ tán, àwọn aṣáájú àwọn Ju fihàn bí wọ́n ti ṣáko lọ jìnnà tó sí ìtẹríba fún ìṣàkóso Ọlọrun. Pilatu wádìí ọ̀ràn Jesu wò ó sì wá sí ìparí èrò pé ó jẹ́ aláìmọwọ́mẹsẹ̀. Ní mímú Jesu jáde wá síwájú àwọn Ju, Pilatu wí pé: “Ẹ wò ó! Ọba yín!” Nígbà tí àwọn Ju pariwo gèè pé kí a pa Jesu, Pilatu béèrè pé: “Èmi yóò ha kan ọba yín mọ́gi?” Àwọn olórí àlùfáà dáhùn pé: “Àwa kò ní ọba kankan bíkòṣe Kesari.” (Johannu 19:​14, 15, NW) Wọ́n jẹ́wọ́ Kesari gẹ́gẹ́ bí ọba, kìí ṣe Jesu, ‘tí ó wá ní orúkọ Jehofa’!​—⁠Matteu 21:⁠9, NW.

17. Èéṣe tí Israeli ti ara fi ṣíwọ́ láti máa jẹ́ orílẹ̀-èdè tí ó wà lábẹ́ ìṣàkóso Ọlọrun?

17 Nípa kíkọ Jesu, àwọn Ju kọ ìṣàkóso Ọlọrun, nítorí pé òun ni yóò jẹ́ ẹni pàtàkì náà nínú àwọn ìṣètò ìṣàkóso Ọlọrun ní ọjọ́-iwájú. Jesu jẹ́ kábíyèsí ọmọkùnrin Dafidi tí yóò jọba títíláé. (Isaiah 9:​6, 7; Luku 1:33; 3:23, 31) Nípa báyìí, àwọn ọmọ Israeli nípa ti ara ṣíwọ́ láti máa jẹ́ àyànfẹ́ orílẹ̀-èdè Ọlọrun.​—⁠Romu 9:​31-⁠33.

Ìṣàkóso Ọlọrun Titun Kan

18. Ìṣàkóso Ọlọrun titun wo ni a bí ní ọ̀rúndún kìn-⁠ín-⁠ní? Ṣàlàyé.

18 Bí ó ti wù kí ó rí, kíkọ̀ tí Ọlọrun kọ Israeli nípa ti ara sílẹ̀ kìí ṣe òpin ìṣàkóso Ọlọrun lórí ilẹ̀-ayé. Nípasẹ̀ Jesu Kristi, Jehofa fìdí ìṣàkóso Ọlọrun titun kan múlẹ̀. Èyí ni ìjọ Kristian tí a fòróróyàn, èyí tí ó jẹ́ orílẹ̀-èdè titun kan níti gàsíkíá. (1 Peteru 2:⁠9) Aposteli Paulu pè é ní “Israeli Ọlọrun,” àti ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀ àwọn mẹ́ḿbà rẹ̀ wá “láti inú ẹ̀yà gbogbo, àti èdè gbogbo, àti inú ènìyàn gbogbo, àti orílẹ̀-èdè gbogbo.” (Galatia 6:16; Ìfihàn 5:​9, 10) Nígbà tí wọ́n wà ní ìtẹríba fún àwọn alákòóso ènìyàn lábẹ́ èyí tí wọ́n ń gbé, àwọn mẹ́ḿbà ìṣàkóso Ọlọrun titun yìí ni Ọlọrun ń ṣàkóso nítòótọ́. (1 Peteru 2:​13, 14, 17) Láìpẹ́ lẹ́yìn ìbí ìṣàkóso Ọlọrun titun náà, àwọn alákòóso Israeli ti ara gbìyànjú láti fipá mú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn díẹ̀ láti ṣíwọ́ ṣíṣègbọràn sí àṣẹ kan tí Jesu ti fifún wọn. Kí ni ìdáhùnpadà náà? “Àwa kò gbọ́dọ̀ má gbọ́ ti Ọlọrun ju ti ènìyàn lọ.” (Iṣe 5:29) Nítòótọ́, ojú-ìwòye kan tí ó bá ìlànà ìṣàkóso Ọlọrun mu ni ìyẹn jẹ́!

19. Ní ọ̀nà wo ni a fi lè sọ pé ìjọ Kristian ọ̀rúndún kìn-⁠ín-⁠ní jẹ́ ìṣàkóso Ọlọrun?

19 Ṣùgbọ́n, báwo ni ìṣàkóso Ọlọrun titun náà ṣe ṣiṣẹ́? Ó dára, Ọba kan wà, Jesu Kristi, tí ń ṣojú fún Ọlọrun Alákòóso Ńlá náà, Jehofa Ọlọrun. (Kolosse 1:13) Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọba náà kò ṣeé fojúrí nínú àwọn ọ̀run, ìṣàkóso rẹ̀ jẹ́ gidi sí àwọn ọmọ-abẹ́ rẹ̀, ọ̀rọ̀ rẹ̀ ni ó sì ń ṣàkóso ìgbésí-ayé wọn. Níti àbójútó tí ó ṣeé fojúrí, àwọn àgbà ọkùnrin tí wọ́n tóótun nípa tẹ̀mí ni a yànsípò. Ní Jerusalemu àwùjọ irú àwọn ènìyàn bẹ́ẹ̀ ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí ẹgbẹ́ olùṣàkóso kan. Àwọn alàgbà arìnrìn-àjò, bíi Paulu, Timoteu, àti Titu ni wọ́n ń ṣojú fún ẹgbẹ́ náà. Ìjọ kọ̀ọ̀kan ni a sì ń bójútó nípasẹ̀ ẹgbẹ́ àwọn àgbà ọkùnrin, tàbí àwọn alàgbà. (Titu 1:⁠5) Nígbà tí ìṣòro lílekoko kan bá dìde, àwọn alàgbà máa ń fọ̀rànlọ ẹgbẹ́ olùṣàkóso tàbí ọ̀kan nínú àwọn aṣojú rẹ̀, bíi Paulu. (Fiwé Iṣe 15:2; 1 Korinti 7:1; 8:1; 12:⁠1.) Síwájú síi, mẹ́ḿbà kọ̀ọ̀kan nínú ìjọ ń ṣe ipa kan nínú títi ìṣàkóso Ọlọrun náà lẹ́yìn. Ẹnìkọ̀ọ̀kan ni ó ní ẹrù-iṣẹ́ níwájú Jehofa láti fi àwọn ìlànà Ìwé Mímọ́ sílò nínú ìgbésí-ayé rẹ̀.​—⁠Romu 14:​4, 12.

20. Kí ni a lè sọ nípa ìṣàkóso Ọlọrun lẹ́yìn àkókò àwọn aposteli?

20 Paulu kìlọ̀ pé lẹ́yìn ikú àwọn aposteli, ìpẹ̀yìndà yóò dìde, ohun tí ó sì ṣẹlẹ̀ gan-⁠an nìyẹn. (2 Tessalonika 2:⁠3) Bí àkókò ti ń lọ, iye àwọn tí wọ́n jẹ́wọ́ jíjẹ́ Kristian wọ àràádọ́ta-ọ̀kẹ́ ó sì di àráádọ́ta-ọ̀kẹ́ lọ́nà ọgọ́rọ̀ọ̀rún lẹ́yìn náà. Wọ́n mú onírúurú àwọn àkóso ṣọ́ọ̀ṣì bíi ti ìṣàkóso nípasẹ̀ ẹgbẹ́ àwọn àlùfáà, ìṣàkóso nípasẹ̀ ẹgbẹ́ àwọn alàgbà, àti ìṣàkóso láti ọwọ́ àgbájọpọ́ ṣọ́ọ̀ṣì gbèrú. Bí ó ti wù kí ó rí, yálà ìwà tàbí àwọn èrò-ìgbàgbọ́ àwọn ṣọ́ọ̀ṣì wọ̀nyí kò fi agbára ìṣàkóso Jehofa hàn. Wọ́n kìí ṣe ìṣàkóso Ọlọrun!

21, 22. (a) Ọ̀nà wo ni Jehofa ti gba mú ìṣàkóso Ọlọrun padàbọ̀sípò ní àkókò òpin? (b) Àwọn ìbéèrè wo nípa ìṣàkóso Ọlọrun ni a óò dáhùn tẹ̀lé e?

21 Ní àkókò òpin ètò-ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan yìí, ìyàsọ́tọ̀ àwọn Kristian tòótọ́ kúrò lára àwọn Kristian èké yóò wà. (Matteu 13:​37-⁠43) Èyí ṣẹlẹ̀ ní 1919, ọdún ṣíṣekókó nínú ọ̀rọ̀-ìtàn ìṣàkóso Ọlọrun. Ní àkókò yẹn àsọtẹ́lẹ̀ ológo ti Isaiah 66:8 ni a múṣẹ: “Ta ni ó tíì rí irú èyí rí? Ilẹ̀ lè hu nǹkan jáde ní ọjọ́ kan bí? tàbí a ha lè bí orílẹ̀-èdè ní ẹ̀rìnkàn?” Ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè wọ̀nyẹn jẹ́ bẹ́ẹ̀ni tí ń dún lọ réré! Ní 1919 ìjọ Kristian tún wà lẹ́ẹ̀kan síi gẹ́gẹ́ bí “orílẹ̀-èdè” tí a yà sọ́tọ̀. Nítòótọ́ “ilẹ̀” ìṣàkóso Ọlọrun kan ni a bí ní ọjọ́ kan! Bí àkókò òpin ti ń tẹ̀síwájú, ètò-àjọ orílẹ̀-èdè titun yìí ni a túnṣebọ̀sípò láti mú un súnmọ́ ohun tí ó wà ní ọ̀rúndún kìn-⁠ín-⁠ní bí ó bá ti lè ṣeéṣe tó. (Isaiah 60:17) Ṣùgbọ́n ìṣàkóso Ọlọrun ni ó máa ń jẹ́ nígbà gbogbo. Nínú ìwà àti èrò-ìgbàgbọ́, ó sábà máa ń ṣàgbéyọ àwọn òfin àti ìlànà onímìísí àtọ̀runwá ti inú Ìwé Mímọ́. Ó sì máa ń wà ní ìtẹríba fún Jesu Kristi, Ọba tí a gbégorí ìtẹ́ náà.​—⁠Orin Dafidi 45:17; 72:1, 2.

22 Ìwọ ha ń kẹ́gbẹ́pọ̀ pẹ̀lú ìṣàkóso Ọlọrun yìí bí? Ìwọ ha ní ipò ọlá-àṣẹ nínú rẹ̀ bí? Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, ìwọ ha mọ ohun tí ó túmọ̀sí láti hùwà lọ́nà tí ó bá ìlànà ìṣàkóso Ọlọrun mu bí? Ìwọ ha mọ àwọn ìdẹkùn tí o níláti yẹra fún bí? Àwọn ìbéèrè méjì tí ó gbẹ̀yìn yìí ní a óò jíròrò nínú ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ tí ó tẹ̀lé e.

Ìwọ Ha Lè Ṣàlàyé Bí?

◻ Kí ni ìṣàkóso Ọlọrun jẹ́?

◻ Ní ọ̀nà wo ni Israeli gbà jẹ́ ìṣàkóso Ọlọrun?

◻ Ìṣètò wo ni Jehofa ṣe láti rán àwọn ọba létí pé Israeli wà lábẹ́ ìṣàkóso Ọlọrun?

◻ Ní ọ̀nà wo ni ìjọ Kristian gbà jẹ́ ìṣàkóso Ọlọrun, báwo sì ni a ṣe ṣètò rẹ̀?

◻ Ètò-àjọ ìṣàkóso Ọlọrun wo ni a ti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ ní àkókò wa?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12]

Níwájú Pontiu Pilatu àwọn alákòóso Ju jẹ́wọ́ Kesari dípò Ọba tí Jehofa yàn lọ́nà ti ìṣàkóso Ọlọrun

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́