Fara Mọ́ Ìṣàkóso Ọlọ́run Tímọ́tímọ́
“Jèhófà ni Onídàájọ́ wa, Jèhófà ni Ẹni tí ń fún wa ní ìlànà àgbékalẹ̀, Jèhófà ni Ọba wa.”—AÍSÁYÀ 33:22.
1. Èé ṣe tí ìjọba fi jẹ́ ọ̀ràn tí ó jẹ ọ̀pọ̀ jù lọ ènìyàn lógún?
ÌJỌBA jẹ́ ọ̀ràn kan tí ó jẹ gbogbo ènìyàn lógún. Ìjọba rere ń mú àlàáfíà àti aásìkí wá. Bíbélì sọ pé: “Ìdájọ́ òdodo ni ọba fi ń mú kí ilẹ̀ máa bá a nìṣó ní dídúró.” (Òwe 29:4) Ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, ìjọba búburú ń yọrí sí àìṣèdájọ́ òdodo, ìwà ìbàjẹ́, àti ìninilára. “Nígbà tí ẹni burúkú bá ń ṣàkóso, àwọn ènìyàn a máa mí ìmí ẹ̀dùn.” (Òwe 29:2) Jálẹ̀ ìtàn, àwọn èèyàn ti gbìyànjú onírúurú ìjọba, ó sì bani nínú jẹ́ pé, lọ́pọ̀ ìgbà, wọ́n ti “mí ìmí ẹ̀dùn” nítorí tí àwọn alákòóso wọn ni wọ́n lára. (Oníwàásù 8:9) Ìjọba èyíkéyìí yóò ha ṣàṣeyọrí láti mú ìtẹ́lọ́rùn pípẹ́títí wá fún àwọn ọmọ abẹ́ rẹ̀ bí?
2. Èé ṣe tí “ìṣàkóso Ọlọ́run” fi jẹ́ àpèjúwe tó bá ìjọba Ísírẹ́lì ìgbàanì mu?
2 Nígbà tí òpìtàn Josephus ń kọ̀wé, ó mẹ́nu kan ìjọba kan tí kò lẹ́gbẹ́, ó wí pé: “Àwọn èèyàn kan ti fa agbára ìṣèlú gíga jù lọ lé àwọn ọba lọ́wọ́, àwọn mìíràn fà á lé àwọn ọ̀tọ̀kùlú lọ́wọ́, àwọn mìíràn sì fà á lé àwọn mẹ̀kúnnù lọ́wọ́. Àmọ́, kò sí èyíkéyìí nínú gbogbo ọ̀nà ìṣèlú yìí tí ó wu afúnnilófin wa [Mósè] rárá, ṣùgbọ́n ètò ìṣèlù kan tí a lè pè ní ‘ìṣàkóso Ọlọ́run,’ fífa gbogbo agbára àti ọlá àṣẹ lé ọwọ́ Ọlọ́run—bí a bá gbà kí a lo ọ̀rọ̀ ṣíṣàjèjì—ni ó wà nínú òfin rẹ̀.” (Against Apion, Kejì, 164 sí 165) Gẹ́gẹ́ bí ìwé atúmọ̀ èdè náà, Concise Oxford Dictionary, ti sọ, ìṣàkóso Ọlọ́run túmọ̀ sí “ìjọba tí Ọlọ́run ń ṣàkóso.” Ọ̀rọ̀ náà kò sí nínú Bíbélì, ṣùgbọ́n ó ṣàpèjúwe ìjọba Ísírẹ́lì ìgbàanì dáadáa. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wá ní ọba tí wọ́n lè fojú rí, Jèhófà gan-an ni alákòóso wọn. Wòlíì ọmọ Ísírẹ́lì náà, Aísáyà, wí pé: “Jèhófà ni Onídàájọ́ wa, Jèhófà ni Ẹni tí ń fún wa ní ìlànà àgbékalẹ̀, Jèhófà ni Ọba wa.”—Aísáyà 33:22.
Èwo Ni Ojúlówó Ìṣàkóso Ọlọ́run?
3, 4. (a) Kí ni ojúlówó ìṣàkóso Ọlọ́run? (b) Láìpẹ́, àwọn ìbùkún wo ni ìṣàkóso Ọlọ́run yóò mú wá fún aráyé?
3 Láti ìgbà tí Josephus ti ṣẹ̀dá ọ̀rọ̀ náà, ọ̀pọ̀ àwùjọ ni a ti ṣàpèjúwe gẹ́gẹ́ bí èyí tí ń lo ìṣàkóso Ọlọ́run. Àwọn kan lára wọn fara hàn gẹ́gẹ́ bí èyí tí kò rara gba nǹkan, tí ó jẹ́ agbawèrèmẹ́sìn, àti òǹrorò aninilára. Wọ́n ha jẹ́ ojúlówó ìṣàkóso Ọlọ́run bí? Kì í ṣe lọ́nà tí Josephus gbà lo ọ̀rọ̀ náà. Ìṣòro náà ni pé a ti fẹ ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ náà, “ìṣàkóso Ọlọ́run,” lójú. Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ náà, World Book Encyclopedia, túmọ̀ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí “oríṣi ìjọba kan tí àlùfáà tàbí àwùjọ àlùfáà ti ń ṣàkóso orílẹ̀-èdè, níbi tí àwọn mẹ́ńbà ẹgbẹ́ àlùfáà náà ti ní àṣẹ lórí ọ̀ràn aráàlú àti ti ẹ̀sìn.” Àmọ́ ṣá o, ojúlówó ìṣàkóso Ọlọ́run kì í ṣe ìjọba àwọn àlùfáà. Ní gidi, ó jẹ́ ìṣàkóso láti ọwọ́ Ọlọ́run, ìjọba tí Ẹlẹ́dàá àgbáyé, Jèhófà Ọlọ́run, gbé kalẹ̀.
4 Láìpẹ́, gbogbo ayé yóò wà lábẹ́ ìṣàkóso Ọlọ́run, ìbùkún ńlá ni ìyẹn á mà jẹ́ o! “Ọlọ́run fúnra rẹ̀ yóò sì wà pẹ̀lú [aráyé]. Yóò sì nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú wọn, ikú kì yóò sì sí mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sí ọ̀fọ̀ tàbí igbe ẹkún tàbí ìrora mọ́. Àwọn ohun àtijọ́ ti kọjá lọ.” (Ìṣípayá 21:3, 4) Kò sí ìṣàkóso àwọn àlùfáà èyíkéyìí nípasẹ̀ àwọn ènìyàn aláìpé tí ó lè mú irú ayọ̀ bẹ́ẹ̀ wá. Ìṣàkóso láti ọwọ́ Ọlọ́run nìkan ni ó lè ṣe é. Nítorí èyí, àwọn Kristẹni tòótọ́ kì í gbìyànjú láti gbé ìṣàkóso Ọlọ́run kalẹ̀ nípa lílo ìgbésẹ̀ ìṣèlú. Wọ́n ń fi sùúrù dúró de Ọlọ́run láti gbé ìṣàkóso rẹ̀ kalẹ̀ kárí ayé nígbà tí ó bá tó àkókò lójú rẹ̀ àti ní ọ̀nà tirẹ̀.—Dáníẹ́lì 2:44.
5. Níbo ni ojúlówó ìṣàkóso Ọlọ́run wà lónìí, àwọn ìbéèrè wo sì ni ó dìde nípa rẹ̀?
5 Àmọ́ ṣá o, ní báyìí ná, ojúlówó ìṣàkóso Ọlọ́run wà lẹ́nu iṣẹ́. Níbo? Láàárín àwọn tí wọ́n fínnúfíndọ̀ fi ara wọn sábẹ́ ìṣàkóso Ọlọ́run, tí wọ́n sì ń fọwọ́ sowọ́ pọ̀ láti ṣe ìfẹ́ rẹ̀. A ti kó irú àwọn olóòótọ́ bẹ́ẹ̀ jọ sí “ilẹ̀” tẹ̀mí rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí “orílẹ̀-èdè” tẹ̀mí tí ó kárí ayé. Àwọn ni ìyókù “Ísírẹ́lì Ọlọ́run” àti àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ wọn tí wọ́n lé ní mílíọ̀nù márùn-ún àbọ̀. (Aísáyà 66:8; Gálátíà 6:16) Àwọn wọ̀nyí wà lábẹ́ Jésù Kristi, Ọba ọ̀run tí Jèhófà Ọlọ́run, “Ọba ayérayé,” gbé gorí ìtẹ́. (1 Tímótì 1:17; Ìṣípayá 11:15) Lọ́nà wo ni ètò àjọ yìí gbà ń lo ìlànà ìṣàkóso Ọlọ́run? Ojú wo ni àwọn mẹ́ńbà rẹ̀ fi ń wo ọlá àṣẹ àwọn ìjọba ayé? Báwo sì ni àwọn ènìyàn tí ń lo ọlá àṣẹ láàárín àwùjọ wọn nípa tẹ̀mí ṣe ń lo ìlànà ìṣàkóso Ọlọ́run?
Ètò Àjọ Tí Ń Lo Ìlànà Ìṣàkóso Ọlọ́run
6. Báwo ni Ọlọ́run ṣe lè máa ṣàkóso ètò àjọ ènìyàn tí a lè fojú rí?
6 Báwo ni Jèhófà, tí ń gbé nínú ọ̀run tí a kò lè fojú rí, ṣe lè máa ṣàkóso ètò àjọ ènìyàn? (Sáàmù 103:19) Ó ṣeé ṣe nítorí pé àwọn tí wọ́n wà nínú ètò àjọ náà ń tẹ̀ lé ìmọ̀ràn tí a mí sí náà, pé: “Fi gbogbo ọkàn-àyà rẹ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, má sì gbára lé òye tìrẹ.” (Òwe 2:6; 3:5) Wọ́n jẹ́ kí Ọlọ́run ṣàkóso wọn bí wọ́n ti ń pa “òfin Kristi” mọ́, tí wọ́n sì ń fi àwọn ìlànà onímìísí inú Bíbélì sílò nínú ìgbésí ayé wọn ojoojúmọ́. (Gálátíà 6:2; 1 Kọ́ríńtì 9:21; 2 Tímótì 3:16; wo Mátíù 5:22, 28, 39; 6:24, 33; 7:12, 21.) Láti ṣe èyí, wọ́n gbọ́dọ̀ jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. (Sáàmù 1:1-3) Gẹ́gẹ́ bí àwọn ‘ọlọ́kàn-rere’ ará Bèróà ìjelòó, wọ́n kì í tẹ̀ lé ènìyàn, ṣùgbọ́n wọ́n ń ṣàwárí nígbà gbogbo nínú Bíbélì nípa ohun tí wọ́n ti kọ́. (Ìṣe 17:10, 11; Sáàmù 119:33-36) Wọ́n ń gbàdúrà bíi ti onísáàmù náà pé: “Kọ́ mi ní ìwà rere, ìlóyenínú àti ìmọ̀ pàápàá, nítorí pé mo ti lo ìgbàgbọ́ nínú àwọn àṣẹ rẹ.”—Sáàmù 119:66.
7. Kí ni ìṣètò ipò àbójútó nínú ìṣàkóso Ọlọ́run?
7 Nínú ètò àjọ kọ̀ọ̀kan, àwọn kan gbọ́dọ̀ wà tí yóò máa lo ọlá àṣẹ tàbí pèsè ìtọ́sọ́nà. Ti Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kò yàtọ̀, wọ́n sì ń tẹ̀ lé ètò ọlá àṣẹ tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù lànà rẹ̀ sílẹ̀ pé: “Orí olúkúlùkù ọkùnrin ni Kristi; ẹ̀wẹ̀, orí obìnrin ni ọkùnrin; ẹ̀wẹ̀, orí Kristi ni Ọlọ́run.” (1 Kọ́ríńtì 11:3) Ní ìbámu pẹ̀lú èyí, kìkì àwọn ọkùnrin tí ó tóótun nìkan ní ń sìn gẹ́gẹ́ bí alàgbà nínú ìjọ. Bí ó sì tilẹ̀ jẹ́ pé Jésù—“orí olúkúlùkù ọkùnrin”—ń bẹ ní ọ̀run, “àwọn tí ó ṣẹ́ kù” nínú àwọn arákùnrin rẹ̀ ẹni àmì òróró, tí wọ́n ní ìrètí láti ṣàkóso pẹ̀lú rẹ̀ ní ọ̀run, ṣì wà lórí ilẹ̀ ayé. (Ìṣípayá 12:17; 20:6) Àwọn wọ̀nyí ni wọ́n para pọ̀ jẹ́ “ẹrú olóòótọ́ àti olóye.” Àwọn Kristẹni ń fi ìtẹríba wọn hàn fún Jésù, àti fún orí Jésù, Jèhófà, nípa títẹ́wọ́gba àbójútó tí “ẹrú” náà ń ṣe. (Mátíù 24:45-47; 25:40) Lọ́nà yìí, ìṣàkóso Ọlọ́run wà létòlétò. “Ọlọ́run kì í ṣe Ọlọ́run rúdurùdu, bí kò ṣe ti àlàáfíà.”—1 Kọ́ríńtì 14:33.
8. Báwo ni àwọn Kristẹni alàgbà ṣe ń kọ́wọ́ ti ìlànà ìṣàkóso Ọlọ́run?
8 Àwọn Kristẹni alàgbà fara mọ́ ìlànà ìṣàkóso Ọlọ́run nítorí pé wọ́n mọ̀ pé àwọn yóò jíhìn nípa bí wọn ṣe lo ìwọ̀n ọlá àṣẹ tí a fún wọn fún Jèhófà. (Hébérù 13:17) Bí ó bá sì di ti ṣíṣe ìpinnu, ọgbọ́n Ọlọ́run ni wọ́n gbára lé, kì í ṣe ọgbọ́n tiwọn. Lọ́nà yìí, wọ́n ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù. Òun ni ọkùnrin tí ó gbọ́n jù lọ tí ó tí ì gbé lórí ilẹ̀ ayé. (Mátíù 12:42) Síbẹ̀síbẹ̀, ó wí fún àwọn Júù pé: “Ọmọ kò lè ṣe ẹyọ ohun kan ní àdáṣe ti ara rẹ̀, bí kò ṣe kìkì ohun tí ó rí tí Baba ń ṣe.” (Jòhánù 5:19) Àwọn alàgbà tún ní irú ẹ̀mí ìrònú tí Dáfídì Ọba ní. Ó lo ọlá àṣẹ tí ó lágbára nínú ìṣàkóso Ọlọ́run. Síbẹ̀, ó fẹ́ rin ọ̀nà Jèhófà, kì í ṣe ọ̀nà ara rẹ̀. Ó gbàdúrà pé: “Jèhófà, fún mi ní ìtọ́ni ní ọ̀nà rẹ, kí o sì ṣamọ̀nà mi ní ipa ọ̀nà ìdúróṣánṣán.”—Sáàmù 27:11.
9. Ní ti ìrètí tí ó yàtọ̀ síra àti àǹfààní ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tí a ní nínú ìṣàkóso Ọlọ́run, ojú ìwòye wíwà déédéé wo ni àwọn Kristẹni olùṣèyàsímímọ́ ní?
9 Àwọn kan ti kọminú pé bóyá a ń ṣe ojúsàájú pé àwọn ọkùnrin tí ó tóótun nìkan ni ó ń lo ọlá àṣẹ nínú ìjọ tí àwọn obìnrin tí ó tóótun kò sì lè ṣe bẹ́ẹ̀, àwọn kan sì ń ṣiyèméjì pé bóyá ó jẹ́ ojúsàájú pé kí àwọn kan ní ìrètí ọ̀run, kí àwọn yòókù sì ní ìrètí ti ayé. (Sáàmù 37:29; Fílípì 3:20) Ṣùgbọ́n, àwọn Kristẹni tí ó ti ṣèyàsímímọ́ mọ̀ pé àwọn ètò wọ̀nyí wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Wọ́n ń tẹ̀ lé ìṣàkóso Ọlọ́run. Bí àwọn kan bá kọminú nípa irú ọ̀ràn bẹ́ẹ̀, yóò jẹ́ àwọn tí kò mọ ìlànà Bíbélì. Yàtọ̀ sí èyí, àwọn Kristẹni mọ̀ pé bí ó bá di ọ̀ràn ìgbàlà, bákan náà ni ọkùnrin àti obìnrin ṣe rí lójú Jèhófà. (Gálátíà 3:28) Fún àwọn Kristẹni tòótọ́, jíjẹ́ olùjọsìn Ọba Aláṣẹ àgbáyé ni àǹfààní pàtàkì jù lọ tí wọ́n lè ní, wọ́n sì láyọ̀ láti wà ní àyè èyíkéyìí tí Jèhófà bá fi wọ́n sí. (Sáàmù 31:23; 84:10; 1 Kọ́ríńtì 12:12, 13, 18) Síwájú sí i, ìyè àìnípẹ̀kun, ì bá à jẹ́ lọ́run tàbí ní párádísè ilẹ̀ ayé, jẹ́ ìrètí àgbàyanu ní tòótọ́.
10. (a) Ìṣarasíhùwà rere wo ni Jónátánì fi hàn? (b) Báwo ni àwọn Kristẹni lónìí ṣe ń fi ìwà tí ó jọ ti Jónátánì hàn?
10 Lọ́nà yìí, Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà jọ Jónátánì, olùbẹ̀rù Ọlọ́run, ọmọ Sọ́ọ̀lù Ọba. Jónátánì ì bá ti jẹ́ ọba rere gan-an. Ṣùgbọ́n, nítorí àìṣòótọ́ Sọ́ọ̀lù, Jèhófà yan Dáfídì láti jẹ́ ọba kejì ní Ísírẹ́lì. Jónátánì ha torí bẹ́ẹ̀ bínú bí? Rárá o. Ó di ọ̀rẹ́minú Dáfídì, àní ó tún dáàbò bò ó lọ́wọ́ Sọ́ọ̀lù. (1 Sámúẹ́lì 18:1; 20:1-42) Lọ́nà kan náà, àwọn tí wọ́n ní ìrètí ti ilẹ̀ ayé kì í jowú àwọn tí ó ní ìrètí ti ọ̀run. Àwọn Kristẹni tòótọ́ kì í sì í jowú àwọn tí ń lo ọlá àṣẹ ti ìṣàkóso Ọlọ́run nínú ìjọ. Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n ń “fún wọn ní ìkàsí tí ó ju àrà ọ̀tọ̀ lọ nínú ìfẹ́,” wọ́n mọ̀ pé wọ́n ń ṣe iṣẹ́ takuntakun nítorí àwọn arákùnrin àti arábìnrin wọn nípa tẹ̀mí.—1 Tẹsalóníkà 5:12, 13.
Ojú Tí Ìṣàkóso Ọlọ́run Fi Ń Wo Ìṣàkóso Ayé
11. Ojú wo ni àwọn Kristẹni tí ń fara wọn sábẹ́ ìṣàkóso Ọlọ́run fi ń wo àwọn aláṣẹ ayé?
11 Bí ó bá jẹ́ pé abẹ ìṣàkóso Ọlọ́run ni Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà wà, ojú wo ni wọ́n fi ń wo àwọn alákòóso orílẹ̀-èdè? Jésù wí pé àwọn ọmọlẹ́yìn òun kò ní jẹ́ “apá kan ayé.” (Jòhánù 17:16) Àmọ́ ṣá o, àwọn Kristẹni mọ gbèsè tí wọ́n jẹ “Késárì,” ìyẹn ni ìjọba ayé. Jésù wí pé wọ́n ní láti “san àwọn ohun ti Késárì padà fún Késárì, ṣùgbọ́n àwọn ohun ti Ọlọ́run fún Ọlọ́run.” (Mátíù 22:21) Gẹ́gẹ́ bí Bíbélì ti sọ, “a gbé” ìjọba ènìyàn “dúró sí àwọn ipò wọn aláàlà láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run.” Jèhófà, Orísun gbogbo ọlá àṣẹ, yọ̀ǹda pé kí àwọn ìjọba wà, ó sì ń retí pé kí wọ́n ṣe rere sí àwọn tí ó wà lábẹ́ ìṣàkóso wọn. Nígbà tí wọ́n bá ṣe bẹ́ẹ̀, wọ́n jẹ́ “òjíṣẹ́ Ọlọ́run.” Àwọn Kristẹni wà lábẹ́ ìjọba ilẹ̀ tí wọ́n ń gbé “ní tìtorí ẹ̀rí-ọkàn [wọn].” (Róòmù 13:1-7) Àmọ́ ṣá o, bí orílẹ̀-èdè náà bá béèrè ohun tí ó lòdì sí òfin Ọlọ́run, Kristẹni yóò “ṣègbọràn sí Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí olùṣàkóso dípò àwọn ènìyàn.”—Ìṣe 5:29.
12. Nígbà tí àwọn aláṣẹ bá ṣenúnibíni sí àwọn Kristẹni, àpẹẹrẹ ta ni wọ́n ń tẹ̀ lé?
12 Bí àwọn aláṣẹ ìjọba bá ṣenúnibíni sí àwọn Kristẹni ńkọ́? Nígbà náà, wọn yóò tẹ̀ lé àpẹẹrẹ àwọn Kristẹni ìjímìjí, tí wọ́n fara da àkókò inúnibíni ńláǹlà. (Ìṣe 8:1; 13:50) Àwọn ìdánwò ìgbàgbọ́ yìí kì í ṣe ohun tí wọn kò retí, níwọn bí Jésù ti kìlọ̀ pé wọn yóò ṣẹlẹ̀. (Mátíù 5:10:12; Máàkù 4:17) Síbẹ̀, àwọn Kristẹni ìjímìjí wọ̀nyẹn kò gbẹ̀san lára àwọn tó ṣe inúnibíni sí wọn; bẹ́ẹ̀ sì ni ìgbàgbọ́ wọn kò mì lábẹ́ pákáǹleke. Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù: “Nígbà tí a ń kẹ́gàn rẹ̀, kò bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́gàn padà. Nígbà tí ó ń jìyà, kò bẹ̀rẹ̀ sí halẹ̀ mọ́ni, ṣùgbọ́n ó ń bá a nìṣó ní fífi ara rẹ̀ lé ọwọ́ ẹni tí ń ṣe ìdájọ́ lọ́nà òdodo.” (1 Pétérù 2:21-23) Bẹ́ẹ̀ ni, àwọn ìlànà Kristẹni borí ogun Sátánì.—Róòmù 12:21.
13. Báwo ni Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ṣe hùwà padà sí inúnibíni àti ọ̀rọ̀ ìbanijẹ́ tí àwọn mìíràn sọ nípa wọn?
13 Bákan náà ló rí lónìí. Ní ọ̀rúndún ogún, Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti jìyà ńláǹlà lọ́wọ́ àwọn alákòóso bóofẹ́bóokọ̀—gan-an gẹ́gẹ́ bí Jésù ti sọ tẹ́lẹ̀. (Mátíù 24:9, 13) Ní àwọn ilẹ̀ kan, àwọn tí ń sún àwọn aláṣẹ láti gbógun ti àwọn Kristẹni olùfọkànsìn wọ̀nyí ti tan irọ́ àti èké kálẹ̀. Síbẹ̀, láìka irú “ìròyìn búburú” bẹ́ẹ̀ sí, Àwọn Ẹlẹ́ríì ti fi ara wọn hàn gẹ́gẹ́ bí òjíṣẹ́ Ọlọ́run nípasẹ̀ ìwà rere wọn. (2 Kọ́ríńtì 6:4, 8) Nígbà tó bá ṣeé ṣe, wọ́n máa ń fọ̀ràn wọn lọ àwọn òṣìṣẹ́ ọba, wọ́n sì ń pẹjọ́ sí kóòtù ilẹ̀ náà kí wọ́n lè fi hàn pé àwọn kò mọwọ́mẹsẹ̀ nínú ẹ̀sùn ìwà àìtọ́ náà. Wọ́n ń lo ọ̀nà èyíkéyìí tí ó bá ṣí sílẹ̀ fún wọn láti gbèjà ìhìn rere náà ní gbangba. (Fílípì 1:7) Ṣùgbọ́n lẹ́yìn tí wọ́n bá ti fi ẹsẹ̀ òfin tọ̀ ọ́ dé ibi tí agbára òfin mọ, wọ́n a fi ọ̀ràn náà lé Jèhófà lọ́wọ́. (Sáàmù 5:8-12; Òwe 20:22) Bí ó bá pọndandan, bíi ti àwọn Kristẹni ìjímìjí, ẹ̀rù kò bà wọ́n láti jìyà nítorí òdodo.—1 Pétérù 3:14-17; 4:12-14, 16.
Fi Ògo Ọlọ́run sí Ipò Kìíní
14, 15. (a) Kí ni ohun àkọ́kọ́ fún àwọn tí ó kọ́wọ́ ti ìlànà ìṣàkóso Ọlọ́run? (b) Nígbà wo ni Sólómọ́nì fi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀ ní ti ìrẹ̀lẹ̀ nínú ipò àbójútó rẹ̀?
14 Nígbà tí Jésù kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ láti gbàdúrà, ohun àkọ́kọ́ tí ó mẹ́nu kàn ni yíya orúkọ Jèhófà sí mímọ́. (Mátíù 6:9) Ní ìbámu pẹ̀lú èyí, àwọn tí ń gbé lábẹ́ ìṣàkóso Ọlọ́run ń wá ògo Ọlọ́run, kì í ṣe ògo tara wọn. (Sáàmù 29:1, 2) Bíbélì ròyìn pé ní ọ̀rúndún kìíní, èyí jẹ́ òkúta ìkọ̀sẹ̀ fún àwọn kan tí wọ́n kọ̀ láti tẹ̀ lé Jésù nítorí pé “wọ́n nífẹ̀ẹ́ ògo ènìyàn,” wọ́n fẹ́ kí àwọn ènìyàn máa fògo fún wọ́n. (Jòhánù 12:42, 43) Ní tòótọ́, ó ń béèrè ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ láti fi Jèhófà ṣáájú ìjẹ́pàtàkì ti ara ẹni.
15 Sólómọ́nì fi ẹ̀mí rere hàn lọ́nà yìí. Fi ọ̀rọ̀ tí ó sọ nígbà ìyàsímímọ́ tẹ́ńpìlì ológo tí ó kọ́ wé ti ọ̀rọ̀ tí Nebukadinésárì sọ nípa ilé ńlá tí òun náà kọ́. Pẹ̀lú ìgbéraga ńláǹlà, Nebukadinésárì yangàn pé: “Bábílónì Ńlá kọ́ yìí, tí èmi fúnra mi fi okun agbára ńlá mi kọ́ fún ilé ọba àti fún iyì ọlá ọba tí ó jẹ́ tèmi?” (Dáníẹ́lì 4:30) Ní òdì kejì, Sólómọ́nì fi ìrẹ̀lẹ̀ fojú kéré àṣeyọrí rẹ̀, ní sísọ pé: “Ọlọ́run yóò ha máa bá aráyé gbé lórí ilẹ̀ ayé ní tòótọ́ bí? Wò ó! Ọ̀run, bẹ́ẹ̀ ni, ọ̀run àwọn ọ̀run, kò lè gbà ọ́; nígbà náà, áńbọ̀sìbọ́sí ilé yìí tí mo kọ́?” (2 Kíróníkà 6:14, 15, 18; Sáàmù 127:1) Sólómọ́nì kò gbé ara rẹ̀ ga. Ó mọ̀ pé aṣojú lásán ni òun jẹ́ fún Jèhófà, ó sì kọ̀wé pé: “Ìkùgbù ha ti dé bí? Nígbà náà, àbùkù yóò dé; ṣùgbọ́n ọgbọ́n wà pẹ̀lú àwọn amẹ̀tọ́mọ̀wà.”—Òwe 11:2.
16. Báwo ni àwọn alàgbà ti ṣe jẹ́ ìbùkún gidi nípa ṣíṣàìfògo fún ara wọn?
16 Lọ́nà kan náà, àwọn Kristẹni alàgbà ń gbé Jèhófà ga, kì í ṣe ara wọn. Wọ́n ń tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Pétérù pé: “Bí ẹnikẹ́ni bá ń ṣe ìránṣẹ́, kí ó ṣe ìránṣẹ́ bí ẹni tí ó gbára lé okun tí Ọlọ́run ń pèsè; kí a lè yin Ọlọ́run lógo nínú ohun gbogbo nípasẹ̀ Jésù Kristi.” (1 Pétérù 4:11) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣàpèjúwe “ipò iṣẹ́ alábòójútó” gẹ́gẹ́ bí “iṣẹ́ àtàtà,” kì í ṣe ipò tí a lè fi fẹlá. (1 Tímótì 3:1) A yan àwọn alàgbà láti sìn, kì í ṣe láti ṣàkóso. Olùkọ́ àti olùṣọ́ agbo àgùntàn Ọlọ́run ni wọ́n jẹ́. (Ìṣe 20:28; Jákọ́bù 3:1) Pẹ̀lú ìrẹ̀lẹ̀, àwọn alàgbà tí wọ́n ní ẹ̀mí ìfara-ẹni-rúbọ jẹ́ ìbùkún gidi fún ìjọ. (1 Pétérù 5:2, 3) “Ẹ . . . máa ka irú àwọn ènìyàn bẹ́ẹ̀ sí ẹni ọ̀wọ́n,” kí ẹ sì máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà pé ó pèsè ọ̀pọ̀ alàgbà tí ó dáńgájíá láti gbé ìṣàkóso rẹ̀ lárugẹ ní “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” wọ̀nyí.—Fílípì 2:29; 2 Tímótì 3:1.
“Ẹ Di Aláfarawé Ọlọ́run”
17. Lọ́nà wo ni àwọn tí wọ́n wà lábẹ́ ìṣàkóso Ọlọ́run gbà ń fara wé Ọlọ́run?
17 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù rọni pé: “Ẹ di aláfarawé Ọlọ́run, gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ tí í ṣe olùfẹ́ ọ̀wọ́n.” (Éfésù 5:1) Àwọn tí wọ́n ń fi ara wọn sábẹ́ ìṣàkóso Ọlọ́run ń gbìyànjú láti fara wé Ọlọ́run dé ìwọ̀n tí ó bá ṣeé ṣe tó fún ẹ̀dá ènìyàn. Fún àpẹẹrẹ, Bíbélì sọ nípa Jèhófà pé: “Àpáta náà, pípé ni ìgbòkègbodò rẹ̀, Nítorí gbogbo ọ̀nà rẹ̀ jẹ́ ìdájọ́ òdodo. Ọlọ́run ìṣòtítọ́, ẹni tí kò sí àìṣèdájọ́ òdodo lọ́dọ̀ rẹ̀; Olódodo àti adúróṣánṣán ni.” (Diutarónómì 32:3, 4) Láti fara wé Ọlọ́run lọ́nà yìí, àwọn Kristẹni ń wá òótọ́, òdodo, àti òye ìdájọ́ òdodo tí ó wà déédéé. (Míkà 6:8; 1 Tẹsalóníkà 3:6; 1 Jòhánù 3:7) Wọ́n ń yẹra fún ọ̀pọ̀ nǹkan tí ó ti di ìtẹ́wọ́gbà nínú ayé, irú bí ìwà pálapàla, ojú kòkòrò, àti ìwọra. (Éfésù 5:5) Nítorí tí àwọn ènìyàn Jèhófà ń tẹ̀ lé ọ̀pá ìdiwọ̀n Ọlọ́run, tí wọn kò tẹ̀ lé ti ènìyàn, ètò àjọ rẹ̀ jẹ́ èyí tí ń lo ìlànà ìṣàkóso Ọlọ́run, tí ó mọ́, tí ó sì pegedé.
18. Kí ni ànímọ́ títayọ jù lọ tí Ọlọ́run ní, báwo sì ni àwọn Kristẹni ṣe ń fi ànímọ́ yìí hàn?
18 Èyí tí ó tayọ jù lọ nínú àwọn ànímọ́ Jèhófà Ọlọ́run ni ìfẹ́. Àpọ́sítélì Jòhánù sọ pé: “Ọlọ́run jẹ́ ìfẹ́.” (1 Jòhánù 4:8) Níwọ̀n bí ìṣàkóso Ọlọ́run ti jẹ́ ìjọba tí Ọlọ́run ń darí, ó dúró fún ìṣàkóso onífẹ̀ẹ́. Jésù wí pé: “Nípa èyí ni gbogbo ènìyàn yóò fi mọ̀ pé ọmọ ẹ̀yìn mi ni yín, bí ẹ bá ní ìfẹ́ láàárín ara yín.” (Jòhánù 13:35) Ètò àjọ ti ìṣàkóso Ọlọ́run ti fi ìfẹ́ àrà ọ̀tọ̀ hàn ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn tí ó nira wọ̀nyí. Nígbà ìjà ìpẹ̀yàrun ní Áfíríkà, Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi ìfẹ́ hàn sí gbogbo ènìyàn, láìka ẹ̀yà tí wọ́n jẹ́ sí. Nígbà ogun tí ó jà ní Yugoslavia tẹ́lẹ̀ rí, Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí ó wà ní gbogbo àgbègbè ran ẹnì kìíní kejì lọ́wọ́, nígbà tí àwọn àwùjọ ẹ̀sìn mìíràn sì lọ́wọ́ nínú ìpẹ̀yàrun náà. Lẹ́nì kọ̀ọ̀kan, Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń làkàkà láti fi ìmọ̀ràn Pọ́ọ̀lù náà sílò pé: “Kí ẹ mú gbogbo ìwà kíkorò onínú burúkú àti ìbínú àti ìrunú àti ìlọgun àti ọ̀rọ̀ èébú kúrò lọ́dọ̀ yín pa pọ̀ pẹ̀lú gbogbo ìwà búburú. Ṣùgbọ́n kí ẹ di onínúrere sí ara yín lẹ́nì kìíní-kejì, ní fífi ìyọ́nú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ hàn, kí ẹ máa dárí ji ara yín fàlàlà gan-an gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run pẹ̀lú ti tipasẹ̀ Kristi dárí jì yín fàlàlà.”—Éfésù 4:31, 32.
19. Àwọn ìbùkún wo ni ó wà nísinsìnyí, tí yóò sì wà ní ọjọ́ ọ̀la fún àwọn tí ń fara wọn sábẹ́ ìṣàkóso Ọlọ́run?
19 Àwọn tí wọ́n fara wọn sábẹ́ ìṣàkóso Ọlọ́run ń gbádùn ìbùkún yabuga-yabuga. Wọ́n wà ní àlàáfíà pẹ̀lú Ọlọ́run àti àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ wọn. (Hébérù 12:14; Jákọ́bù 3:17) Ìgbésí ayé wọn nítumọ̀. (Oníwàásù 12:13) Wọ́n ní ààbò nípa tẹ̀mí àti ìrètí tí ó dájú fún ọjọ́ ọ̀la. (Sáàmù 59:9) Ní tòótọ́, wọ́n ń gbádùn ìtọ́wò bí yóò ti rí nígbà tí gbogbo aráyé bá wà lábẹ́ ìṣàkóso Ọlọ́run. Nígbà náà, Bíbélì sọ pé, “wọn kì yóò ṣe ìpalára èyíkéyìí, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò fa ìparun èyíkéyìí ní gbogbo òkè ńlá mímọ́ mi; nítorí pé, ṣe ni ilẹ̀ ayé yóò kún fún ìmọ̀ Jèhófà bí omi ti bo òkun.” (Aísáyà 11:9) Àkókò ológo ńláǹlà ni ìyẹn yóò mà jẹ́ o! Ǹjẹ́ kí gbogbo wa lè mú kí àyè wa nínú Párádísè ọjọ́ ọ̀la yẹn dájú nípa fífara mọ́ ìṣàkóso Ọlọ́run tímọ́tímọ́ nísinsìnyí.
Ìwọ Ha Lè Ṣàlàyé Bí?
◻ Kí ni ojúlówó ìṣàkóso Ọlọ́run, ibo sì ni a ti lè rí i lónìí?
◻ Báwo ni àwọn ènìyàn ṣe ń fara wọn sábẹ́ ìṣàkóso Ọlọ́run nínú ìgbésí ayé wọn?
◻ Ní àwọn ọ̀nà wo ni gbogbo àwọn tí ó wà lábẹ́ ìṣàkóso Ọlọ́run gbà ń fi ògo Ọlọ́run ṣáájú ti ara wọn?
◻ Kí ni díẹ̀ lára àwọn ànímọ́ Ọlọ́run tí àwọn tí ó fara mọ́ ìṣàkóso rẹ̀ ń fara wé?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]
Sólómọ́nì fi ògo Ọlọ́run ṣáájú ti ara rẹ̀