Èéṣe Tí Ìbẹ̀rù Fi Gbá Aráyé Mú?
TA NÍ fẹ́ láti máa gbé nínú ìbẹ̀rù? Ẹnìkan ti kò là tí kò ṣagbe ń fẹ́ ààbò, láìsí híhalẹ̀ mọ́ ìwàláàyè tàbí àwọn ohun-ìní rẹ̀. Nípa báyìí, ọ̀pọ̀ ń kó kúrò ní àwọn agbègbè tí ó kún fún ìwà-ọ̀daràn. Síbẹ̀, àwọn ìdí fún ìbẹ̀rù ṣì wà níbi gbogbo.
Ewu láti inú àwọn ohun-ìjà alágbára átọ́míìkì àti ìjàm̀bá ẹ̀rọ adíwọ̀n ìbúgbàù átọ́míìkì ru ìbẹ̀rù pé a óò pa aráyé run sókè. Ìwà-ipá tí ń gasókè fíofío ń mú kí ìbẹ̀rù pọ̀ síi. Ẹ̀rù ń ba ọ̀pọ̀lọpọ̀ pé àrùn AIDS yóò di àjàkálẹ̀ àrùn tí ń ṣekúpani jùlọ ti ọ̀rúndún. Ìbàyíká wa jẹ́ wà lára àwọn okùnfà mìíràn fún ìbẹ̀rù. Àwọn ìbẹ̀rù yìí ha ṣe pàtàkì níti gidi bí? Ǹjẹ́ a sì lè retí láé láti gbé nínú ayé kan láìsí irú ìbẹ̀rù bẹ́ẹ̀?
Ìbẹ̀rù Kárí Ayé Ṣe Pàtàkì
Ìbẹ̀rù tí ó gbilẹ̀ káàkiri lónìí ṣe pàtàkì nítorí ohun tí a sọtẹ́lẹ̀ nínú Bibeli. Nínú àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ nípa àwọn ọjọ́ ìkẹyìn, Jesu Kristi sọ nípa àwọn ipò tí yóò fa ìbẹ̀rù. Ó wí pé: “Orílẹ̀-èdè yoo dìde sí orílẹ̀-èdè ati ìjọba sí ìjọba, àìtó oúnjẹ ati ìmìtìtì-ilẹ̀ yoo sì wà lati ibi kan dé ibòmíràn.” Jesu tún sọ nípa “pípọ̀ sí i ìwà-àìlófin.” Láti 1914 wá, àwọn ogun, ìyàn, ìmìtìtì-ilẹ̀, àti ìwà-àìlófin tí a kò rí irú rẹ̀ rí ti yọrísí ìbẹ̀rù ńlá àti ìpàdánù ìwàláàyè.—Matteu 24:7-14, NW.
Àní ìṣarasíhùwà àwọn ènìyàn pàápàá ń mú ìbẹ̀rù wá lónìí. Ní 2 Timoteu 3:1-4, a kà nípa àwọn ọ̀rọ̀ alásọtẹ́lẹ̀ aposteli Paulu pé: “Ṣùgbọ́n èyí ni kí o mọ̀, pé ní ìkẹyìn ọjọ́ ìgbà ewu yóò dé. Nítorí àwọn ènìyàn yóò jẹ́ olùfẹ́ ti araawọn, olùfẹ́ owó, afúnnu, agbéraga, asọ̀rọ̀ búburú, aṣàìgbọ́ràn sí òbí, aláìlọ́pẹ́, aláìmọ́, aláìnífẹ̀ẹ́, aláìlè-dáríjinni, abanijẹ́, aláìlè-kó-ra-wọn-níjàánu, òǹrorò, aláìnífẹ̀ẹ́-ohun-rere, oníkúpani, alágídí, ọlọ́kàn gíga, olùfẹ́ fàájì ju olùfẹ́ Ọlọrun lọ.” Níwọ̀n bí irú àwọn ènìyàn bẹ́ẹ̀ ti yí wa ká ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn wọ̀nyí, abájọ tí ìbẹ̀rù púpọ̀ tóbẹ́ẹ̀ fi wà!
Ohun tí Ayé Yìí Lè Retí
Jesu fi àkókò yìí wé àwọn ọjọ́ ìkẹyìn ayé ti àkókò Noa. Láìsí iyèméjì, ìbẹ̀rù ga nígbà yẹn, nítorí pé àkọsílẹ̀ ọ̀rọ̀ ìtàn Bibeli sọ pé: “Ayé sì bàjẹ́ níwájú Ọlọrun, ayé sì kún fún ìwà-agbára.” Fún ìdí yìí, “Ọlọrun sì wí fún Noa pé, Òpin gbogbo ènìyàn dé iwájú mi; nítorí tí ayé kún fún ìwà-agbára.” (Genesisi 6:11, 13) Ayé búburú yẹn ní ìwà-ipá gan-an tóbẹ́ẹ̀ tí Ọlọrun fi mú òpin dé bá a nípasẹ̀ Ìkún-Omi kárí ayé. Bí ó ti wù kí ó rí, láti inú ìfẹ́, Jehofa Ọlọrun pa Noa olódodo àti ìdílé rẹ̀ mọ́.—2 Peteru 2:5.
Nítorí náà kí ni ayé oníwà-ipá ti ìsinsìnyí lè retí? Ó dára, Ọlọrun kórìíra àìlọ́wọ̀ fún ire àwọn ẹlòmíràn lọ́nà tí ó fi ìwà-ipá hàn. Èyí ṣe kedere láti inú àwọn ọ̀rọ̀ onipsalmu náà pé: “Oluwa ń dán olódodo wò: ṣùgbọ́n ènìyàn búburú àti ẹni tí ń fẹ́ ìwà agbára, ọkàn rẹ̀ kórìíra.” (Orin Dafidi 11:5) Jehofa mú òpin débá ayé oníwà-ipá ti ọjọ́ Noa. Wàyí o, nítorí náà, àwa kò ha níláti retí pé kí Ọlọrun mú òpin débá ayé yìí tí ìwà-ipá ẹlẹ́rùjẹ̀jẹ̀ ń kó ìyọlẹ́nu bá bí?
A mísí aposteli Peteru látọ̀runwá láti sọ̀rọ̀ nípa wíwàníhìn-ín Kristi àti láti sàsọtẹ́lẹ̀ àjálù-ibi fún ayé búburú ìsinsìnyí. Ó kọ̀wé pé: “Nígbà ọjọ́ ìkẹyìn, àwọn ẹlẹ́gàn yóò dé pẹ̀lú ẹ̀gàn wọn, wọn óò máa rìn nípa ìfẹ́ araawọn, wọn ó sì máa wí pé, Níbo ni ìlérí wíwá rẹ̀ gbé wà? láti ìgbà tí àwọn baba ti sùn, ohun gbogbo ń lọ bí wọ́n ti wà rí láti ìgbà ọjọ́ ìwà.” Lẹ́yìn náà ni Peteru lo ọ̀rọ̀ náà “àwọn ọ̀run” láti dúró fún ètò-ìgbékalẹ̀ ìṣàkóso aláìpé lórí aráyé àti ọ̀rọ̀ náà “ayé” fún ẹgbẹ́ àwùjọ aláìṣòdodo ti ẹ̀dá ènìyàn. “Nítorí,” ni òun sọ, “wọ́n mọ̀ọ́mọ̀ ṣe àìfẹ́ẹ́mọ̀, pé nípa ọ̀rọ̀ Ọlọrun ni àwọn ọ̀run ti wà láti ìgbà àtijọ́, àti tí ilẹ̀ yọrí jáde nínú omi, tí ó sì dúró nínú omi: nípa èyí tí omi bo ayé tí ó wà nígbà náà [ọjọ́ Noa], tí ó sì ṣègbé. Ṣùgbọ́n àwọn ọ̀run àti ayé, tí ń bẹ nísinsìnyí, nípa ọ̀rọ̀ kan náà ni a ti tòjọ bí ìṣúra fún iná, a pa wọ́n mọ́ de ọjọ́ ìdájọ́ àti ìparun àwọn aláìwà-bí-Ọlọ́run.”—2 Peteru 3:3-7.
Ní ríronú lọ́nà kan náà, Paulu ṣàlàyé pé Kristi àti àwọn angẹli alágbára rẹ̀ yóò “san ẹ̀san fún àwọn tí kò mọ Ọlọrun, tí wọn kò sì gba ìhìnrere Jesu Oluwa wa gbọ́: àwọn ẹni tí yóò jìyà ìparun àìnípẹ̀kun.” (2 Tessalonika 1:6-9) Ìwé tí ó kẹ́yìn nínú Bibeli sọ̀rọ̀ nípa kíkó àwọn orílẹ̀-èdè jọpọ̀ “sí ogun ọjọ́ ńlá Ọlọrun Olodumare” ó sì mú un dá wa lójú pé Jehofa yóò “run àwọn tí ń pa ayé run.”—Ìfihàn 11:18; 16:14-16.
Àkókò fún Ayọ̀, Kìí Ṣe Ìbẹ̀rù
Dípò kí àyà wa máa já nítorí ohun tí Bibeli sọtẹ́lẹ̀ nípa ayé yìí, àwọn adúróṣinṣin ènìyàn ní ìdí fún ayọ̀. Láìpẹ́ ni Jehofa yóò mú òpin débá ayé búburú yìí, ṣùgbọ́n èyí ni a óò ṣe fún ire àwọn wọnnì tí wọ́n fẹ́ràn òdodo. Kí ni yóò tẹ̀lé ìmúwásópin ètò-ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan ìsinsìnyí látọ̀runwá? Họ́wù, ètò-ìgbékalẹ̀ titun kan lábẹ́ Ìjọba ọ̀run ti Ọlọrun, èyí tí Jesu kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ láti gbàdúrà fún! Ó wí pé: “Nítorí náà báyìí ni kí ẹ̀yin máa gbàdúrà: Baba wa tí ń bẹ ní ọ̀run; Kí a bọ̀wọ̀ fún orúkọ rẹ. Kí ìjọba rẹ dé; Ìfẹ́ tìrẹ ni kí a ṣe, bíi ti ọ̀run, bẹ́ẹ̀ ni ní ayé.” (Matteu 6:9, 10) Àwọn ìyípadà wo ni a lè retí nígbà tí ìfẹ́-inú Ọlọrun bà di ṣíṣe lórí ilẹ̀-ayé?
Ogun àti àwọn ìdáyàfoni rẹ̀ yóò ti wá sópin. Orin Dafidi 46:9 sọ pé: “Ó [Jehofa Ọlọrun] mú ọ̀tẹ̀ tán dé òpin ayé; ó ṣẹ́ ọrun, ó sì ké ọ̀kọ̀ méjì; ó sì fi kẹ̀kẹ́ ogun jóná.” Nígbà náà ni àwọn ènìyàn “óò jókòó olúkúlùkù lábẹ́ àjàrà rẹ̀ àti lábẹ́ igi ọ̀pọ̀tọ́ rẹ̀; ẹnìkan kì yóò sì dáyàfò wọ́n.”—Mika 4:4.
Àwọn òkùnrùn tí wọ́n lè ṣekúpani kò tún ní fa ìbẹ̀rù kí wọ́n sì gba ìwàláàyè mọ́. Ìlérí àtọ̀runwá náà ni pé: “Àwọn ará ibẹ̀ kì yóò wí pé, Oótù ń pa mi.” (Isaiah 33:24) Ẹ wo ìdí kan tí èyí jẹ́ fún ayọ̀!
Àwọn ìbẹ̀rù tí wọ́n níí ṣe pẹ̀lú ìwà-ọ̀daràn àti ìwà-ipá pẹ̀lú yóò dí àwọn nǹkan àtijọ́. Orin Dafidi 37:10, 11 ṣèlérí pé: “Nítorí pé nígbà díẹ̀, àwọn ènìyàn búburú kì yóò sí: nítòótọ́ ìwọ óò fi ara balẹ̀ wo ipò rẹ̀, kì yóò sì sí. Ṣùgbọ́n àwọn ọlọ́kàn-tútù ni yóò jogún ayé; wọn óò sì máa ṣe inú dídùn nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àlàáfíà.”
Báwo ni a óò ṣe fi àlàáfíà tòótọ́ àti àìléwu rọ́pò ìbẹ̀rù òde-ìwòyí? Nípasẹ̀ àkóso òdodo kan—Ìjọba Ọlọrun. Nípa tí àkókò wa, Danieli 2:44 sọ pé: “Ní ọjọ́ àwọn ọba wọ̀nyí ni Ọlọrun ọ̀run yóò gbé ìjọba kan kalẹ̀, èyí tí a kì yóò lè parun títíláé: a kì yóò sì fi ìjọba náà lé orílẹ̀-èdè mìíràn lọ́wọ́, yóò sì fọ́ túútú, yóò sì pa gbogbo ìjọba wọ̀nyí run, ṣùgbọ́n òun óò dúró títí láéláé.” Ọba tí Jehofa yànsípò, Jesu Kristi, “kò lè ṣàìmá jọba títí yóò fi fi gbogbo àwọn ọ̀tá sábẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀.” (1 Korinti 15:25) Ìṣàkóso Ẹlẹ́gbẹ̀rún Ọdún ti Jesu yóò mú ète Ọlọrun ní ìpilẹ̀ṣẹ̀ ṣẹ láti mú kí àwọn ẹ̀dá ènìyàn aláyọ̀ gbé títí ayérayé nínú paradise orí ilẹ̀-ayé.—Luku 23:43; Ìfihàn 20:6; 21:1-5.
Nínú Paradise orí ilẹ̀-ayé yẹn, ìbẹ̀rù dídára kanṣoṣo yóò wà. Yóò jẹ́ “ìbẹ̀rù Oluwa.” (Owe 1:7) Níti tòótọ́, a níláti ní ìbẹ̀rù yìí nísinsìnyí pàápàá, nítorí tí ó jẹ́ ọ̀wọ̀ ńlá àti ìbẹ̀rù ọlọ́wọ̀ jíjinlẹ̀ papọ̀ pẹ̀lú ìfòyà láti máṣe mú Ọlọrun bínú nítorí pé a mọrírì ìṣeun-ìfẹ́ àti ìwàrere-ìṣeun rẹ̀. Ìbẹ̀rù yìí béèrè fún ìgbẹ́kẹ̀lé kíkún nínú Jehofa àti ìfìṣòtítọ́ ṣègbọràn sí i.—Orin Dafidi 2:11; 115:11.
Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí ń dẹ́rùbani sàmì sí ìwọ̀nyí gẹ́gẹ́ bí àwọn ọjọ́ ìkẹyìn. Bí ó ti wù kí ó rí, bí a bá fi ẹ̀rí ìfẹ́ wa fún Ọlọrun hàn, a lè yọ̀ dípò kí a kún fún ìbẹ̀rù. Àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bibeli fihàn pé ìfòpinsí ayé yìí láti ọ̀run wá ti kù sí dẹ̀dẹ̀. Ayé titun òdodo tí Jehofa Ọlọrun ṣèlérí ní yóò rọ́pò rẹ̀. (2 Peteru 3:13) Nítòótọ́, lábẹ́ àkóso Ìjọba, ayé kan láìsí ìbẹ̀rù tí kò dára máa tó wà.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 6]
AGBÁRA TÍ Ẹ̀DÀ KANṢOṢO NÍ
TOMASZ, ọ̀dọ́mọkùnrin kan láti Poland, kò sínú ìṣòro tí ó jẹmọ́ ti òfin èyí tí ó mú kí ó sá kúrò ní orílẹ̀-èdè náà. Fún oṣù mẹ́fà ni ó fi bẹ̀bẹ̀ wọ ọkọ̀ jákèjádò ilẹ̀ Europe, tí ó ń sùn nínú àgọ́ kan tí ó sì ń ṣe onírúurú iṣẹ́ gbogbo. Ní gbogbo àkókò yìí, ìbéèrè kan wà tí kò kúrò lọ́kàn rẹ̀: Kí ni ète ìgbésí-ayé?
Tomasz rí ìdáhùn sí ìbéèrè rẹ̀ nígbà tí a fún un ní ẹ̀dà Ilé-Ìṣọ́nà kan ní èdè Polish. Ó kà á fún ìgbà mélòókan ó sì mọ̀ pé ìwé ìròyìn yìí ní òtítọ́ tí òun ti ń wá kiri nínú. Tomasz bẹ̀bẹ̀ wọ ọkọ̀ la 200 kìlómítà kọjá lọ sí ọ́fíìsì ẹ̀ka Watch Tower ní Selters/Taunus, Germany. Nígbà tí ó débẹ̀ ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ Monday kan, ó na ìwé ìròyìn Ilé-Ìṣọ́nà rẹ̀ jáde ó sì wí pé: “Èmi yóò fẹ́ kí ẹnìkan túbọ̀ ṣàlàyé ohun tí ó wà nínú ìwé ìròyìn yìí fún mi. Kí ni mo níláti ṣe?”
Ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ yẹn, méjì lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa bá Tomasz sọ̀rọ̀ nípa ète ìgbésí-ayé, ní lílo Bibeli gẹ́gẹ́ bí ohun tí wọ́n gbé ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ wọn kà. Bí ó ti ní ìháragàgà láti mọ púpọ̀ síi, Tomasz ń padà lọ sí ọ́fíìsì ẹ̀ka náà lójoojúmọ́ ní ọ̀sẹ̀ yẹn, ní kíkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli àti ìwé náà Iwọ Le Walaaye Titilae ninu Paradise lori Ilẹ Aye.
Tomasz pinnu láti padà sí Poland, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó lè dojúkọ ìṣòro níbẹ̀. Nípa báyìí, ní ọjọ́ Friday, ọjọ́ mẹ́rin péré lẹ́yìn tí ó ti dé sí ọ́fíìsì ẹ̀ka Selters, Tomasz forílé ilẹ̀ ìbílẹ̀ rẹ̀. Lọ́gán ni ó bẹ̀rẹ̀ síí kẹ́kọ̀ọ́ Bibeli pẹ̀lú àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ní Poland. Tomasz ní ìtẹ̀síwájú yíyárakánkán ó sì bẹ̀rẹ̀ síí fi tìtaratìrara bá àwọn ẹlòmíràn sọ̀rọ̀ nípa ohun tí ó ń kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀. Ní October 1993, oṣù mẹ́rin péré lẹ́yìn ìbẹ̀wò rẹ̀ àkọ́kọ́ sí Selters, ó ṣèrìbọmi gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa.
Kìkì ẹ̀dà Ilé-Ìṣọ́nà kanṣoṣo ni ó ran ọ̀dọ́mọkùnrin yìí lọ́wọ́ láti ṣàwárí ète ìgbésí-ayé!
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Lábẹ́ àkóso Ìjọba nípasẹ̀ Jesu Kristi, ìbẹ̀rù kò tún ní gbá ayé mú mọ́