Jehofa Ń Fòyebánilò!
“Ọgbọ́n tí ó wá lati òkè . . . ń fòyebánilò.”—JAKỌBU 3:17, NW.
1. Báwo ni àwọn kan ti ṣe fi Ọlọrun hàn gẹ́gẹ́ bí aláìfòyebánilò, kí sì ni ìmọ̀lára rẹ nípa irú ojú-ìwòye bẹ́ẹ̀ nípa Ọlọrun?
IRÚ Ọlọrun wo ni ìwọ ń sìn? Ìwọ ha gbàgbọ́ pé òun jẹ́ Ọlọrun tí kìí gba ti ẹlòmíràn rò, tí ó lekoko lórí ọ̀ràn ìdájọ́ òdodo, oníkanra àti aláìṣeéyípadà nínú ìhùwàsí rẹ̀ bí? Lójú alátùn-ún-ṣe ìsìn Protestant náà John Calvin, bí Ọlọrun ti níláti jẹ́ nìyẹn. Calvin jẹ́wọ́ pé Ọlọrun ní “ìwéwèé ayérayé tí kò ṣeé yípadà” nípa olúkúlùkù ènìyàn, ní ṣíṣe yíyàn ṣáájú fún ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn yálà wọ́n yóò wàláàyè títíláé nínú ayọ̀ tàbí a óò dá wọn lóró títí ayérayé nínú iná ọ̀run àpáàdì. Rò ó wò ná: Bí èyí bá jẹ́ òtítọ́, kò sí ohun tí o lè ṣe láé, bí ó ti wù kí o gbìyànjú kára tó, tí yóò yí ìwéwèé aláìṣeéyípadà tí Ọlọrun ti ní tipẹ́tipẹ́ nípa rẹ àti ọjọ́-ọ̀la rẹ padà. Irú Ọlọrun tí kìí fòyebánilò bẹ́ẹ̀ yóò ha fà ọ́ mọ́ra bí?—Fiwé Jakọbu 4:8.
2, 3. (a) Báwo ni a ṣe lè ṣàkàwé àìfòyebánilò àwọn ètò ìgbékalẹ̀ àti ètò-àjọ ẹ̀dá ènìyàn? (b) Báwo ni ìran Esekieli nípa kẹ̀kẹ́-ẹṣin òkè-ọ̀run ti Jehofa ṣe ṣípayá ìmọwọ́ọ́yípadà Rẹ̀?
2 Ẹ wo bí ó ti tù wá lára tó láti kẹ́kọ̀ọ́ pé Ọlọrun Bibeli ń fòyebánilò lọ́nà títayọlọ́lá! Àwọn ènìyàn ni wọ́n máa ń nítẹ̀sí láti jẹ́ aláìṣeéyípadà tí wọ́n sì máa ń lekoko, nítorí tí wọ́n jẹ́ aláìpé kìí ṣe Ọlọrun. Ètò-àjọ àwọn ènìyàn lè ṣòro láti bójútó bí àwọn ọkọ̀ rélùwéè akẹ́rù. Nígbà tí ọkọ̀ rélùwéè akẹ́rù kan bá forílé ibi tí ìdènà kan wà lójú irin, kìí ṣeéṣe láti darí rẹ̀ sí ibòmíràn, ó sì máa ń ṣòro gan-an láti dúró. Agbára tí ń ti àwọn ọkọ̀ rélùwéè kan sáré pọ̀ débi pé ó ń gbà wọ́n ju kìlómítà kan lọ kí wọ́n tó lè dúró lẹ́yìn tí wọ́n bá ti tẹ ìdákọ̀ró! Bákan náà, ọkọ̀ gbàgbàrà agbépo kan lè máa rìn nìṣó fún kìlómítà mẹ́jọ mìíràn síi lẹ́yìn tí a bá ti paná ẹ́ńjìnnì rẹ̀. Kódà bí a bá mú kí wọ́n fẹ̀yìn rìn pàápàá, ó ṣì lè rin ìrìn kìlómítà mẹ́ta síi lórí omi. Ṣùgbọ́n nísinsìnyí ṣàgbéyẹ̀wò ọkọ̀ kan tí ń múni kún fún ìbẹ̀rù ọlọ́wọ̀ ju méjì wọ̀nyí lọ, ọ̀kan tí ń ṣàpẹẹrẹ ètò-àjọ Ọlọrun.
3 Ní ohun tí ó rékọjà 2,600 ọdún sẹ́yìn, Jehofa fi ìran kan tí ó yàwòrán ètò-àjọ Rẹ̀ òkè-ọ̀run ti àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí hàn wòlíì Esekieli. Ó jẹ́ kẹ̀kẹ́-ẹṣin tí títóbi rẹ̀ múni kún fún ìbẹ̀rù ọlọ́wọ̀, “Kẹ̀kẹ́” Jehofa fúnraarẹ̀ tí ó máa ń wà lábẹ́ àbójútó rẹ̀ nígbà gbogbo. Èyí tí ó gbádùnmọ́ni jùlọ ni ọ̀nà tí ó ń gbà yí. Àwọn àgbá kẹ̀kẹ́ gìrìwò náà ní ìhà mẹ́rin wọ́n sì kún fún ojú, nítorí náà wọ́n lè rí ibi gbogbo wọ́n sì lè yí ipa-ọ̀nà wọn padà lọ́gán, láìdúró tàbí yípadà. Kò sì sí ìdí kan fún kẹ̀kẹ́ gìrìwò yìí láti máa fà tìì gẹ́gẹ́ bí ọkọ̀ gbàgbàrà agbépo tàbí ọkọ̀ rélùwéè akẹ́rù kan. Ó lè sáré bíi kíkọ mànàmáná, kí ó sì yípadà bìrí! (Esekieli 1:1, 14-28) Jehofa yàtọ̀ sí Ọlọrun tí Calvin wàásù rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí kẹ̀kẹ́-ẹsin Rẹ̀ ti yàtọ̀ sí àwọn ẹ̀rọ àtọwọ́dá tí ìrìn wọn kò dánmọ́rán tó. Òun mọwọ́ọ́yípadà lọ́nà pípé pérépéré. Mímọrírì apá ẹ̀ka yìí nínú àkópọ̀ ànímọ́ Jehofa yẹ kí ó ràn wá lọ́wọ́ láti máa báa lọ ní mímọwọ́ọ́yípadà kí a sì yẹra fún ìdẹkùn àìfòyebánilò.
Jehofa—Ẹni tí Ó Mọwọ́ọ́yípadà Jùlọ Lágbàáyé
4. (a) Ní ọ̀nà wo ni orúkọ Jehofa gan-an gbà ṣí i payá pé òun jẹ́ Ọlọrun tí ó mọwọ́ọ́yípadà? (b) Kí ni díẹ̀ lára àwọn orúkọ oyè tí a lò fún Jehofa Ọlọrun, èésìtiṣe tí wọ́n fi ṣe wẹ́kú?
4 Orúkọ Jehofa gan-an fi ìmọwọ́ọ́yípadà rẹ̀ hàn. Ní olówuuru “Jehofa” túmọ̀sí “Òun Mú Kí Ó Wà.” Ẹ̀rí fihàn pé èyí túmọ̀sí pé Jehofa mú kí òun fúnra òun di Olùmú gbogbo àwọn ìlérí òun ṣẹ. Nígbà tí Mose bi Ọlọrun léèrè orúkọ rẹ̀, Jehofa ṣe kúlẹ̀kúlẹ̀ àlàyé lórí ìtumọ̀ rẹ̀ lọ́nà yìí: “Èmi yóò jásí ohun tí èmi yóò jásí.” (Eksodu 3:14, NW) Ìtumọ̀ Rotherham sọ ọ́ lọ́nà tí ó ṣe kedere pé: “Èmi Yóò Di ohunkóhun yòówù tí ó bá wù mí.” Jehofa ń jásí, tàbí ń yàn láti jẹ́, ohunkóhun tí ó bá yẹ láti mú àwọn ète àti ìlérí òdodo rẹ̀ ṣẹ. Nípa báyìí, òun ń jẹ́ ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn orúkọ oyè wíwúnilórí, bí Ẹlẹ́dàá, Baba, Oluwa Ọba-Aláṣẹ, Olùṣọ́-Àgùtàn, Oluwa àwọn ọmọ-ogun, Olùgbọ́ Àdúrà, Onídàájọ́, Atóbilọ́lá Olùkọ́ni, Olùràpadà. Ó ti sọ araarẹ̀ di gbogbo ìwọ̀nyí àti púpọ̀ síi kí ó baà lè mú àwọn ète onífẹ̀ẹ́ rẹ̀ ṣẹ.—Isaiah 8:13; 30:20; 40:28; 41:14; Orin Dafidi 23:1; 65:2; 73:28; 89:26; Awọn Onidajọ 11:27; tún wo New World Translation, Àfikún 1J.
5. Èéṣe tí a kò fi níláti parí èrò pé ìmọwọ́ọ́yípadà Jehofa túmọ̀ ní tààràtà sí pé ànímọ́ rẹ̀ tàbí àwọn ọ̀pá-ìdíwọ̀n rẹ̀ ń yípadà?
5 Nígbà náà, èyí ha túmọ̀sí pé ànímọ́ tàbí àwọn ọ̀pá-ìdíwọ̀n Ọlọrun máa ń yípadà bí? Bẹ́ẹ̀kọ́; gẹ́gẹ́ bí Jakọbu 1:17 ti sọ ọ́, ‘kò sí ìyípadà tàbí òjìji àyídà lọ́dọ̀ rẹ̀.’ Ìtakora ha wà níhìn-ín bí? Kò sí rárá. Fún àpẹẹrẹ, òbí onífẹ̀ẹ́ wo ni kìí yíwọ́padà nínú àwọn ipa-iṣẹ́ rẹ̀ láti lè mú kí àwọn ọmọ jàǹfààní? Láàárín ọjọ́ kan ṣúlẹ̀, òbí kan lè jẹ́ olùgbaninímọ̀ràn, olùgbọ́únjẹ, olùtọ́jú-ilé, olùkọ́, olùfúnni ní ìbáwí, ọ̀rẹ́, atọ́kọ̀ṣe, olùtọ́jú aláìsàn—ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà gùn lọ jàn-àn-ràn jan-an-ran. Òbí kìí yí àkópọ̀ ànímọ́ rẹ̀ padà nígbà tí ó bá ń bójútó àwọn ipa-iṣẹ́ wọ̀nyí; ó wulẹ̀ máa ń yíwọ́padà láti mú araarẹ̀ bá àìní tí ó wà mu ni. Bẹ́ẹ̀ náà ni ó rí pẹ̀lú Jehofa ṣùgbọ́n ní ìwọ̀n kan tí ó gbòòrò yéye. Kò sí ìdíwọ̀n fún ohun tí ó lè sọ araarẹ̀ dì láti ṣàǹfààní fún àwọn ẹ̀dá rẹ̀. Ìjìnlẹ̀ ọgbọ́n rẹ̀ ń ṣeni ní háà nítòótọ́!—Romu 11:33.
Ìfòyebánilò Àmì Ọgbọ́n Àtọ̀runwá
6. Kí ni àwọn ìtumọ̀ olówuuru àti ìtumọ̀ abẹ́nú ti ọ̀rọ̀ Griki náà tí Jakọbu lò fún ṣíṣàpèjúwe ọgbọ́n àtọ̀runwá?
6 Ọmọ-ẹ̀yìn náà Jakọbu lo ọ̀rọ̀ fífanimọ́ra kan láti ṣàpèjúwe ọgbọ́n Ọlọrun tí ó mọwọ́ọ́yípadà lọ́nà gíga jùlọ yìí. Ó kọ̀wé pé: “Ọgbọ́n tí ó wá lati òkè . . . ń fòyebánilò.” (Jakọbu 3:17, NW) Ọ̀rọ̀ Griki náà tí ó lò níhìn-ín (e·pi·ei·kesʹ) ṣòro láti túmọ̀. Àwọn olùtúmọ̀ ti lo àwọn ọ̀rọ̀ bíi “ẹni pẹ̀lẹ́,” “afàánúhàn,” “alámùúmọ́ra,” àti “olùgbatẹnirò.” Bibeli New World Translation túmọ̀’ rẹ̀ sí “fòyebánilò,” pẹ̀lú àkíyèsí ẹsẹ̀ ìwé tí ń fihàn pé ìtumọ̀ rẹ̀ ní olówuuru ni “jíjuwọ́sílẹ̀.”a Ọ̀rọ̀ náà tún gbé ìtumọ̀ ṣíṣàì rinkinkin mọ́ àwọn ọ̀rọ̀ inú òfin jáde, kí a máṣe mógìírí tàbí lekoko jù. Ọ̀mọ̀wèé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ William Barclay ṣàlàyé nínú New Testament Words pé: “Ohun ìpìlẹ̀ tí ó sì ṣekókó jùlọ nípa epieikeia ni pé ó pilẹ̀ṣẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun. Bí Ọlọrun bá rinkinkin mọ́ ẹ̀tọ́ rẹ̀, bí Ọlọrun kò bá lo ohunkóhun fún wa bíkòṣe àwọn ọ̀pá-ìdíwọ̀n aláìṣeéyípadà ti òfin, níbo ni àwa ìbá wà? Ọlọrun ni àpẹẹrẹ gíga jùlọ ti ẹnìkan tí ó jẹ́ epieikēs tí ó sì ń bá àwọn ẹlòmíràn lò pẹ̀lú epieikeia.”
7. Báwo ni Jehofa ṣe fi ìfòyebánilò hàn nínú ọgbà Edeni?
7 Ronú nípa àkókò náà nígbà tí aráyé ṣọ̀tẹ̀ lòdìsí ipò ọba-aláṣẹ Jehofa. Báwo ni ìbá ti rọrùn tó fún Ọlọrun láti mú ikú wá sórí àwọn aláìlọ́pẹ́ ọlọ̀tẹ̀ mẹ́ta wọnnì—Adamu, Efa, àti Satani! Ẹ sì wo bí ìrora ọkàn náà lọ́wọ́ èyí tí òun ìbá ti gba ara rẹ̀ kalẹ̀ ìbá ti pọ̀ tó! Ta ni ìbá sì jẹ́ jiyàn pé òun kò ní ẹ̀tọ́ láti béèrè fún irúfẹ́ ìdájọ́ òdodo ṣíṣe pàtó bẹ́ẹ̀? Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, Jehofa kò yọ̀ọ̀da kí ètò-àjọ rẹ̀ òkè-ọ̀run tí ó dàbí kẹ̀kẹ́-ẹṣin dúró gbagidi sínú ọ̀pá-ìdíwọ̀n ìdájọ́-òdodo kan tí kò ṣeé yípadà, tí kò sì ṣeé mú bá ipò mú. Nítorí náà kẹ̀kẹ́-ẹṣin yẹn kò yí gbirigbiri lu ìdílé ẹ̀dá ènìyàn àti gbogbo ìfojúsọ́nà fún ọjọ́-ọ̀la aláyọ̀ ti aráyé kí ó sì tẹ̀ wọ́n rẹ́. Ní òdìkejì sí ìyẹn, Jehofa fọgbọ́ndarí kẹ̀kẹ́-ẹṣin rẹ̀ pẹ̀lú ìyárakánkán bíi ti kíkọ mànàmáná. Ní kété lẹ́yìn ìṣọ̀tẹ̀ náà, Jehofa Ọlọrun ṣe ìlàlẹ́sẹẹsẹ onígbà-pípẹ́ kan ti o nawọ́ àánú àti ìrètí sí gbogbo àwọn àtọmọdọ́mọ Adamu.—Genesisi 3:15.
8. (a) Báwo ni ojú-ìwòye aláṣìṣe tí Kristẹndọm ní nípa ìfòyebánilò ṣe yàtọ̀ sí ojúlówó ìfòyebánilò ti Jehofa? (b) Èéṣe tí a fi lè sọ pé ìfòyebánilò Jehofa kò túmọ̀ ní tààràtà sí pé òun lè fi àwọn ìlànà àtọ̀runwá bánidọ́rẹ̀ẹ́?
8 Bí ó ti wù kí ó rí, ìfòyebánilò Jehofa kò túmọ̀ ní tààràtà sí pé òun lè fi àwọn ìlànà àtọ̀runwá bánidọ́rẹ̀ẹ́. Àwọn ṣọ́ọ̀ṣì Kristẹndọm ìwòyí lè ronú pé àwọn ń fòyebánilò nígbà tí wọ́n bá fojútín-ín-rín ìwà pálapàla kìkì nítorí àti wá ojúrere àwọn agbo wọn oníwà wíwọ́. (Fiwé 2 Timoteu 4:3.) Jehofa kìí rú àwọn òfin tirẹ̀ fúnraarẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kìí fi àwọn ìlànà rẹ̀ bánidọ́rẹ̀ẹ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó fi ìmúratán hàn láti juwọ́sílẹ̀, láti mú ara rẹ̀ bá àwọn àyíká ipò mu, kí ó baà lè fi àwọn ìlànà wọnnì sílò pẹ̀lú ìdájọ́-òdodo àti àánú. Nígbà gbogbo ni ó ń rántí láti mú ìfisílò ìdájọ́-òdodo àti agbára rẹ̀ wà déédéé pẹ̀lú ìfẹ́ àti ọgbọ́n ìfòyebánilò rẹ̀. Ẹ jẹ́ kí a ṣàgbéyẹ̀wò àwọn ọ̀nà mẹ́ta tí Jehofa ń gbà fi ìfòyebánilò hàn.
‘Múra Láti Dáríjì’
9, 10. (a) Kí ni ‘mímúra láti dáríjì’ níí ṣe pẹ̀lú ìfòyebánilò? (b) Báwo ni Dafidi ṣe jàǹfààní láti inú ìmúratán Jehofa láti dáríjì, èésìtiṣe?
9 Dafidi kọ̀wé pé: “Nítorí ìwọ, Oluwa, o ṣeun, o sì múra àti dáríjì; o sì pọ̀ ní àánú fún gbogbo àwọn tí ń képè ọ́.” (Orin Dafidi 86:5) Nígbà tí a túmọ̀ Ìwé Mímọ́ Lédè Heberu sí èdè Griki, ọ̀rọ̀ náà fún “múra láti dáríjì” ni a túmọ̀ sí e·pi·ei·kesʹ, tàbí “ìfòyebánilò.” Nítòótọ́, mímúra láti dáríjì kí a sì fi àánú hàn ni ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ ọ̀nà tí ó ṣekókó náà láti fi ìfòyebánilò hàn.
10 Dafidi fúnraarẹ̀ mọ̀ dáradára nípa bí Jehofa ti ń fòyebánilò tó lọ́nà yìí. Nígbà tí Dafidi ṣe panṣágà pẹ̀lú Batṣeba tí ó sì ṣètò láti mú kí a pa ọkọ rẹ̀, òun àti Batṣeba ni ó tọ́ pé kí a fìyà ikú jẹ. (Deuteronomi 22:22; 2 Samueli 11:2-27) Bí ó bá jẹ́ pé àwọn onídàájọ́ ènìyàn tí ìpinnu wọn kìí yípadà ni wọ́n ti bójútó ọ̀ràn náà, ó ṣeéṣe kí àwọn méjèèjì ti pàdánù ìwàláàyè wọn. Ṣùgbọ́n Jehofa fi ìfòyebánilò (e·pi·ei·kesʹ) hàn, èyí tí ó jẹ́ pé, gẹ́gẹ́ bí ìwé atúmọ̀ ọ̀rọ̀ náà Vine’s Expository Dictionary of Biblical Words ti sọ ọ́, “ó ṣàfihàn ìgbatẹnirò náà tí ń fi ‘inúrere àti ìfòyebánilò’ wo ‘àwọn òtítọ́ tí ń bẹ nídìí ọ̀ràn kan.’” Ó ṣeéṣe kí àwọn òtítọ́ náà tí ó mú kí Jehofa ṣe ìpinnu tí ó kún fún àánú ti wémọ́ ìrònúpìwàdà olótìítọ́-inú ti àwọn oníwà-àìtọ́ náà àti àánú tí Dafidi fúnraarẹ̀ ti fihàn fún àwọn ẹlòmíràn ṣáájú. (1 Samueli 24:4-6; 25:32-35; 26:7-11; Matteu 5:7; Jakọbu 2:13) Bí ó ti wù kí ó rí, ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀nà tí Jehofa gbà ṣàpèjúwe ara rẹ̀ nínú Eksodu 34:4-7, ohun tí ó fi ìfòyebánilò hàn ni pé Jehofa yóò fún Dafidi ní ìbáwí ìtọ́ni. Ó rán wòlíì Natani sí Dafidi pẹ̀lú ìhìn-iṣẹ́ lílágbára, ní títẹ òtítọ́ náà mọ́ Dafidi lọ́kàn pé ó ti tẹ́ḿbẹ́lú ọ̀rọ̀ Jehofa. Dafidi ronúpìwàdà kò sì kú nítorí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.—2 Samueli 12:1-14.
11. Báwo ni Jehofa ṣe fi ìmúratán láti dáríjì hàn nínú ọ̀ràn ti Manasse?
11 Àpẹẹrẹ Ọba Manasse ti Juda túbọ̀ pẹtẹrí lọ́nà yìí, níwọ̀n bí Manasse, láìdàbí Dafidi, ti burú jọjọ fún àkókò gígùn. Manasse gbé àwọn àṣà ìsìn tí ń súni fún ìríra lárugẹ ní ilẹ̀ náà, títíkan ìfènìyàn rúbọ. Ó tún lè jẹ́ pé òun náà ni ó mú kí a fi “ayùn” rẹ́ wòlíì Isaiah olùṣòtítọ́ sí “méjì.” (Heberu 11:37) Láti fìyàjẹ Manasse, Jehofa yọ̀ọ̀da kí a mú un lọ sí Babiloni gẹ́gẹ́ bí òǹdè. Bí ó ti wù kí ó rí, Manasse ronúpìwàdà nínú ọgbà ẹ̀wọ̀n ó sì bẹ̀bẹ̀ fún àánú. Ní ìdáhùnpadà sí ìrònúpìwàdà olótìítọ́-inú yìí, Jehofa “múra àti dáríjì”—àní nínú ọ̀ràn tí ó légbákan yìí pàápàá.—2 Kronika 33:9-13.
Yíyí Ìgbésẹ̀ Padà Bí Àwọn Àyíká Ipò Titun Ti Ń Dìde
12, 13. (a) Nínú ọ̀ràn ti Ninefe, ìyípadà àyíká ipò wo ni ó sún Jehofa láti yí ìgbésẹ̀ rẹ̀ padà? (b) Báwo ni Jona ṣe jásí ẹni tí ìfòyebánilò rẹ̀ dínkù sí ti Jehofa Ọlọrun?
12 Ìfòyebánilò Jehofa tún farahàn nínú ìmúratán rẹ̀ láti yí ọ̀nà ìgbà gbégbèésẹ̀ kan tí ó ti gbèrò padà. Fún àpẹẹrẹ, nígbà tí wòlíì Jona rìn la àárín àwọn òpópónà Ninefe ìgbàanì kọjá, ìhìn-iṣẹ́ onímìísí rẹ̀ rọrùn gan-an: Ìlú-ńlá títóbi náà ni a óò parun níwọ̀n 40 ọjọ́. Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn àyíká ipò yípadà—lọ́nà tí ń múnijígìrì! Àwọn ará Ninefe ronúpìwàdà.—Jona, orí 3.
13 A lè rí ẹ̀kọ́ kọ́ nínú ṣíṣèfiwéra ọ̀nà tí Jehofa àti Jona gbà hùwàpadà sí ìyípadà nínú àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ yìí. Jehofa yí ipa-ọ̀nà kẹ̀kẹ́-ẹṣin òkè-ọ̀run rẹ̀ padà níti gidi. Nínú àpẹẹrẹ yìí ó yíwọ́padà, ní sísọ araarẹ̀ di olùdárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ jini dípò jíjẹ́ “akin ọkùnrin ogun.” (Eksodu 15:3, NW) Ní ọwọ́ mìíràn ẹ̀wẹ̀, Jona kò mọwọ́ọ́yípadà rárá. Dípò kí ó máa rìn ní ìṣísẹ̀ kan náà pẹ̀lú kẹ̀kẹ́-ẹṣin Jehofa, ó ṣe bíi ti ọkọ̀ ojú-irin akẹ́rù tàbí ọkọ̀ gbàgbàrà agbépo náà tí a ti mẹ́nukàn ṣáájú. Ó ti polongo ìdájọ́ ìparun, nítorí náà àfi kí wọ́n parun ṣáá ni! Bóyá ó lérò pé ìyípadà èyíkéyìí nínú ọ̀nà ìgbà gbégbèésẹ̀ yóò dójúti òun lọ́dọ̀ àwọn ará Ninefe. Ṣùgbọ́n, pẹ̀lú sùúrù, Jehofa kọ́ wòlíì rẹ̀ olóríkunkun yìí ní ẹ̀kọ́ àríkọ́gbọ́n kan tí ó jẹ́ mánigbàgbé nípa ìfòyebánilò àti àánú.—Jona, orí 4.
14. Èéṣe tí Jehofa fi yí ohun tí ó fẹ́ kí wòlíì rẹ̀ Esekieli ṣe padà?
14 Jehofa ti yí ohun tí ó fẹ́ láti ṣe padà ní àwọn ìgbà mìíràn—àní lórí àwọn ọ̀ràn tí kò fi bẹ́ẹ̀ tó nǹkan ní ìfiwéra. Fún àpẹẹrẹ, nígbà kan rí tí ó pàṣẹ fún wòlíì Esekieli láti ṣàṣefihàn àwòkẹ́kọ̀ọ́ alásọtẹ́lẹ̀ kan, àwọn ìtọ́ni Jehofa ní ìtọ́sọ́nà náà nínú pé kí Esekieli se oúnjẹ rẹ̀ lórí iná kan tí a fi ìgbẹ́ ènìyàn dá. Èyí ti pàpọ̀jù fún wòlíì náà, ẹni tí ó kébòsí pé: “Áà, Oluwa Ọlọrun!” tí ó sì bẹ̀bẹ̀ pé kí a máṣe mú kí òun ṣe ohun kan tí ó kó òun nírìíra. Jehofa kò fi ọwọ́ rọ́ àwọn ìmọ̀lára wòlíì náà tì sẹ́yìn gẹ́gẹ́ bí èyí tí kò fi ìfòyebánilò hàn; kàkà bẹ́ẹ̀, Ó yọ̀ọ̀da fún Esekieli láti lo ẹlẹ́bọ́tọ, ohun ìdáná tí ó wọ́pọ̀ jùlọ ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ilẹ̀ títí di òní olónìí.—Esekieli 4:12-15.
15. (a) Àwọn àpẹẹrẹ wo ni ó fihàn pé Jehofa ti máa ń nífẹ̀ẹ́ ìmúratán láti tẹ́tísílẹ̀ kí ó sì kọbiara sí àwọn ẹ̀dá ènìyàn? (b) Ẹ̀kọ́ wo ni èyí lè kọ́ wa?
15 Kò ha mú ọkàn yọ̀ṣẹ̀ṣẹ̀ láti ronú lórí ìrẹ̀lẹ̀-ọkàn Ọlọrun wa Jehofa? (Orin Dafidi 18:35) Òun ga lọ́pọ̀lọpọ̀ jù wá lọ; síbẹ̀ ó ń fi sùúrù tẹ́tísílẹ̀ sí àwọn ẹ̀dá ènìyàn aláìpé bákan náà ni ó sì tún ń yí ohun tí ó fẹ́ láti ṣe padà ní àwọn ìgbà mìíràn. Ó yọ̀ọ̀da fún Abrahamu láti jírẹ̀ẹ́bẹ̀ pẹ̀lú òun fún àkókò gígùn lórí ọ̀ràn tí ó jẹmọ́ ti ìparun Sodomu àti Gomorra. (Genesisi 18:23-33) Ó sì jẹ́ kí Mose gbé àwọn àtakò dìde sí ìdábàá Rẹ̀ láti pa àwọn ọmọ Israeli ọlọ̀tẹ̀ run kí ó sì sọ Mose di orílẹ̀-èdè ńlá dípò wọn. (Eksodu 32:7-14; Deuteronomi 9:14, 19; fiwé Amosi 7:1-6.) Ó tipa báyìí fi àpẹẹrẹ pípé lélẹ̀ fún àwọn ènìyàn tí wọ́n jẹ́ ìránṣẹ́ rẹ̀, tí wọ́n níláti fi irú ìmúratán kan náà láti tẹ́tísílẹ̀ sí àwọn ẹlòmíràn hàn nígbà tí ó bá bọ́gbọ́nmu tí ó sì ṣeéṣe láti ṣe bẹ́ẹ̀.—Fiwé Jakọbu 1:19.
Ìfòyebánilò Nínú Lílo Ọlá-Àṣẹ
16. Báwo ni Jehofa ṣe yàtọ̀ sí ọ̀pọ̀ àwọn ẹ̀dá ènìyàn níti ọ̀nà tí òun ń gbà lo ọlá-àṣẹ rẹ̀?
16 O ha ti ṣàkíyèsí pé bí àwọn ènìyàn tí ń gba ọlá-àṣẹ púpọ̀ síi, ó dàbí ẹni pé ìfòyebánilò ọ̀pọ̀ ń dínkù? Ní ìyàtọ̀ sí èyí, Jehofa ni ó ní ipò ọlá-àṣẹ gíga jùlọ lágbàáyé, síbẹ̀ òun ni àpẹẹrẹ gíga jùlọ níti ìfòyebánilò. Ó ń lo ọlá-àṣẹ rẹ̀ ní ọ̀nà ìfòyebánilò tí kìí kùnà. Láìdàbí ọ̀pọ̀ àwọn ẹ̀dá ènìyàn, Jehofa kìí mikàn nípa ọlá-àṣẹ rẹ̀, nítorí náà kò ní ìmọ̀lára àìgbọdọ̀máṣe láti dáàbòbò ó pẹ̀lú owú—bí ẹni pé fífi ìwọ̀n ọlá-àṣẹ kan fún àwọn ẹlòmíràn lè fi tirẹ̀ wewu. Níti tòótọ́, nígbà tí ó fi jẹ́ pé òun àti ẹlòmíràn kan ni wọ́n jọ wà ní gbogbo àgbáyé, Jehofa gbé ọlá-àṣẹ gbígbòòrò lé onítọ̀hún lọ́wọ́. Ó fi Logos náà ṣe “ọ̀gá òṣìṣẹ́” rẹ̀, ní mímú kí gbogbo nǹkan wàláàyè nípasẹ̀ Ọmọkùnrin rẹ̀ olùfẹ́ láti ìgbà náà wá. (Owe 8:22, 29-31, NW; Johannu 1:1-3, 14; Kolosse 1:15-17) Lẹ́yìn náà ni ó gbé “gbogbo agbára ní ọ̀run àti ní ayé” lé e lọ́wọ́.—Matteu 28:18; Johannu 5:22.
17, 18. (a) Èéṣe tí Jehofa fi rán àwọn angẹli lọ sí Sodomu àti Gomorra? (b) Èéṣe tí Jehofa fi béèrè fún ìdámọ̀ràn lọ́wọ́ àwọn angẹli nípa bí wọn yóò ṣe tan Ahabu?
17 Bákan náà, Jehofa fi iṣẹ́ tí òun fúnraarẹ̀ lè bójútó lọ́nà tí ó sàn jù sí ìkáwọ́ àwọn ẹ̀dá rẹ̀. Fún àpẹẹrẹ, nígbà tí ó sọ fún Abrahamu pé, “Èmi ó sọ̀kalẹ̀ lọ [sí Sodomu àti Gomorra] nísinsìnyí, kí ń rí bí wọ́n tilẹ̀ ṣe, gẹ́gẹ́ bí òkìkí igbe rẹ̀, tí ó dé ọ̀dọ̀ mi,” òun kò ní i lọ́kàn pé òun fúnra òun yóò lọ síbẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, Jehofa yàn láti fúnni ní ọlá-àṣẹ, ní yíyan àwọn angẹli láti kó irú ìsọfúnni bẹ́ẹ̀ jọ fún òun. Ó fún wọn ní ọlá-àṣẹ láti ṣáájú nínú iṣẹ́ ìwádìí-òtítọ́-rí yìí kí wọ́n sì jábọ̀ padà fún òun.—Genesisi 18:1-3, 20-22.
18 Ní àkókò ìṣẹ̀lẹ̀ mìíràn, nígbà tí Jehofa pinnu láti mú ìdájọ́ ìjìyà ṣẹ sórí Ọba Ahabu búburú, Ó pe àwọn angẹli jọ síbi àpéjọ ti òkè ọ̀run láti mú ìdámọ̀ràn wá níti bí wọn yóò ṣe “tan” apẹ̀yìndà ọba náà tí yóò fi darapọ̀ nínú ìjà-ogun kan tí yóò fi òpin sí ìgbésí-ayé rẹ̀. Dájúdájú, Jehofa, Orísun gbogbo ọgbọ́n, kò nílò ìrànlọ́wọ́ láti ronúkan ọ̀nà tí ó dára jùlọ láti gbà gbégbèésẹ̀! Síbẹ̀, ó fi àǹfààní dídábàá ojútùú àti ọlá-àṣẹ náà láti gbégbèésẹ̀ lórí ẹni náà tí òun ti yàn buyì kún àwọn angẹli.—1 Awọn Ọba 22:19-22.
19. (a) Èéṣe tí Jehofa fi pààlà sí iye àwọn òfin tí òun ń ṣe? (b) Báwo ni Jehofa ṣe fi araarẹ̀ hàn gẹ́gẹ́ bí afòyebánilò nígbà tí ó bá di ti ohun tí ó retí pé kí a ṣe?
19 Jehofa kìí lo ọlá-àṣẹ rẹ̀ láti lo agbára ìdarí tí kò yẹ lórí àwọn ẹlòmíràn. Nínú èyí pẹ̀lú ó fi ìfòyebánilò tí kò ní alábàádọ́gba hàn. Ó fi tìṣọ́ratìṣọ́ra pààlà sí iye àwọn òfin tí òun ń ṣe ó sì dá àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lẹ́kun láti máṣe “ré ohun tí a ti kọ̀wé rẹ̀ kọjá” nípa fífi àwọn òfin ẹlẹ́rù ìnira tí ó jẹ́ àtọwọ́dá tiwọn kún un. (1 Korinti 4:6; Iṣe 15:28; ṣèfiwéra Matteu 23:4.) Òun kò béèrè fún ìṣègbọràn lọ́nà gbundúku rí lọ́wọ́ àwọn ẹ̀dá rẹ̀, ṣùgbọ́n ó sábà máa ń pèsè ìsọfúnni tí ó pọ̀ tó láti dáàbòbò wọ́n tí ó sì ń fi yíyàn náà sílẹ̀ fún wọn, ní jíjẹ́ kí wọ́n mọ àwọn àǹfààní ṣíṣègbọràn àti àwọn àbájáde ṣíṣàìgbọràn. (Deuteronomi 30:19, 20) Dípò títipasẹ̀ ẹ̀bi, ìtìjú, tàbí ìbẹ̀rù fipá mú àwọn ènìyàn láti ṣe yíyàn, ó ń wá ọ̀nà láti dé inú ọkàn-àyà; dípò tí ìbá fi jẹ́ lọ́nà àpàpàǹdodo ó ń fẹ́ kí àwọn ènìyàn sin òun láti inú ojúlówó ìfẹ́. (2 Korinti 9:7) Gbogbo irúfẹ́ iṣẹ́-ìsìn tọkàntọkàn bẹ́ẹ̀ ń mú ọkàn-àyà Ọlọrun yọ̀, nítorí náà òun kìí ṣe ẹni tí ó “ṣòro lati tẹ́lọ́rùn” lọ́nà àìfòyebánilò.—1 Peteru 2:18, NW; Owe 27:11; fiwé Mika 6:8.
20. Báwo ni ìfòyebánilò Jehofa ṣe kàn ọ́?
20 Kò ha pẹtẹrí pé Jehofa Ọlọrun, tí ó ní agbára tí ó pọ̀ ju ti ènìyàn èyíkéyìí tí a dá, kò lo agbára yẹn lọ́nà àìfòyebánilò rí, àní kò lò ó rí láti búmọ́ àwọn ẹlòmíràn? Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn ènìyàn, tí wọ́n kéré bín-ín-tín ní ìfiwéra, ní àkọsílẹ̀ ìtàn jíjẹgàba lé ara wọn lórí. (Oniwasu 8:9) Ní kedere, ìfòyebánilò jẹ́ ànímọ́ ṣíṣeyebíye, ọ̀kan tí ń sún wa láti túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ Jehofa síi. Ìyẹn, pẹ̀lú, lè sún wa láti mú ànímọ́ yìí dàgbà fúnraawa. Báwo ni a ṣe lè ṣe bẹ́ẹ̀? Ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ tí ó tẹ̀lée yóò bójútó ọ̀ràn yìí.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Lẹ́yìn lọ́hùn-ún ní 1769, aṣàkójọ ọ̀rọ̀ John Parkhurst túmọ̀ ọ̀rọ̀ náà sí “jíjuwọ́sílẹ̀, ti ìwà ìjuwọ́sílẹ̀, jíjẹ́ ẹni pẹ̀lẹ́, oníwàtútù, onísùúrù.” Àwọn ọ̀mọ̀wèé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ mìíràn pẹ̀lú ti fúnni ní “jíjuwọ́sílẹ̀” gẹ́gẹ́ bí ìtumọ̀.
Báwo Ni Ìwọ Yóò Ṣe Dáhùn?
◻ Báwo ni orúkọ Jehofa àti ìran kẹ̀kẹ́-ẹṣin òkè-ọ̀run rẹ̀ ṣe tẹnumọ́ ìmọwọ́ọ́yípadà rẹ?
◻ Kí ni ìfòyebánilò, èésìtiṣe tí ó fi jẹ́ àmì ọgbọ́n àtọ̀runwá?
◻ Ní àwọn ọ̀nà wo ni Jehofa ti fihàn pé òun “múra àti dáríjì”?
◻ Èéṣe tí Jehofa fi yàn láti yí ìgbésẹ̀ kan tí ó ti fẹ́ láti gbé nínú àwọn ipò ọ̀ràn kan padà?
◻ Báwo ni Jehofa ṣe fi ìfòyebánilò hàn níti ọ̀nà tí ó ń gbà lo ọlá-àṣẹ?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Èéṣe tí Jehofa fi dáríji Ọba Manasse búburú?