ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w94 8/15 ojú ìwé 11-15
  • A Níláti Kọ́kọ́ Wàásù Ìhìnrere Yìí

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • A Níláti Kọ́kọ́ Wàásù Ìhìnrere Yìí
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìyàtọ̀ Láàárín Wọn àti Àwọn Àwùjọ Àlùfáà Kristẹndọm
  • Èéṣe tí A Fi Níláti Kọ́kọ́ Wàásù Ìhìnrere?
  • Ìhìnrere àti Ìfẹ́ Jehofa
  • Ìhìnrere àti Agbára Jehofa
  • Ìhìnrere àti Ọgbọ́n Jehofa
  • Ìhìnrere àti Ìdájọ́ Òdodo Ọlọrun
  • Báwo Ni A Ti Kárí Ayé Lọ́nà Gbígbòòrò Tó?
  • Kí Ni Ń Sún Àwọn Ẹlẹ́rìí náà Ṣiṣẹ́?
  • “Ẹ Lọ, Kí Ẹ sì Máa Sọ Àwọn Ènìyàn Gbogbo Orílẹ̀-Èdè Di Ọmọ Ẹ̀yìn”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2016
  • Lílò Tí Jehofa Ń Lo “Ìwà-òmùgọ̀” Lati Gba Awọn Wọnni Ti Wọn Gbagbọ Là
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
  • ‘Àwọn Tí Ń mú Ìhìn Rere Ohun Tí Ó Dára Jù Wá’
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2005
  • Gbogbo Kristẹni Tòótọ́ Ni Ajíhìnrere
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2002
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
w94 8/15 ojú ìwé 11-15

A Níláti Kọ́kọ́ Wàásù Ìhìnrere Yìí

“A níláti kọ́kọ́ wàásù ìhìnrere naa ní gbogbo awọn orílẹ̀-èdè.” ​—⁠MARKU 13:10, NW.

1, 2. Kí ni àmì ìdánimọ̀ fún àwọn Ẹlẹ́rìí, èésìtiṣe?

ÈÉṢE tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa fi ń wàásù nìṣó láìdáwọ́dúró? Dájúdájú a mọ̀ wá kárí-ayé fún iṣẹ́-òjíṣẹ́ ìtagbangba wa, yálà ó jẹ́ láti ilé dé ilé, ní àwọn òpópónà, tàbí nígbà tí a bá ń ṣe àwọn ìkésíni láìjẹ́-bí-àṣà. Ní gbogbo àkókò yíyẹ, a ń fi ara wa hàn gẹ́gẹ́ bí Ẹlẹ́rìí a sì ń gbìyànjú pẹ̀lú ọgbọ́n láti bánisọ̀rọ̀ nípa ìhìnrere náà tí a kà sí ìṣúra. Ní tòótọ́, a lè sọ pé iṣẹ́-òjíṣẹ́ yìí ni àmì ìdánimọ̀ wa!​—⁠Kolosse 4:⁠6.

2 Wulẹ̀ ronú nípa rẹ̀ ná​—⁠nígbàkigbà tí àwọn ènìyàn bá rí àwùjọ àwọn ọkùnrin, obìnrin, àti àwọn ọmọdé ní àdúgbò wọn tí wọ́n múra ṣémúṣémú pẹ̀lú àpò ìfàlọ́wọ́, kí ni èrò àkọ́kọ́ tí ó sábà máa ń wá sí wọn lọ́kàn? Ó ha máa ń jẹ́, ‘Óò, àwọn Katoliki (tàbí onísìn Orthodox) ni wọ́n tún ń bọ̀wá yìí o!’ tàbí, ‘Àwọn onísìn Pentecostal (tàbí Baptist) ni wọ́n tún ń bọ̀wá yìí o!’ Bẹ́ẹ̀kọ́. Àwọn ènìyàn mọ̀ pé irú àwọn ìsìn bẹ́ẹ̀ kò ní odiidi mẹ́ḿbà ìdílé tí ń ṣe iṣẹ́-òjíṣẹ́ ilé-dé-ilé. Bóyá àwọn àwùjọ ìsìn kan ń rán àwọn “míṣọ́nnárì” díẹ̀ lọ sí àwọn àgbègbè pàtó kan láti ṣiṣẹ́ ọdún méjì níbẹ̀, ṣùgbọ́n àwọn mẹ́ḿbà wọn ní gbogbogbòò kìí kópa nínú irú iṣẹ́-òjíṣẹ́ èyíkéyìí bẹ́ẹ̀. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa nìkanṣoṣo ni a mọ̀ kárí-ayé fún ìtara wọn nínú bíbá àwọn ẹlòmíràn sọ̀rọ̀ nípa ìhìn-iṣẹ́ wọn ní gbogbo àkókò yíyẹ. A sì tún mọ̀ wọ́n mọ àwọn ìwé ìròyìn wọn, Ilé-Ìṣọ́nà àti Jí!​—⁠Isaiah 43:​10-⁠12; Iṣe 1:⁠8.

Ìyàtọ̀ Láàárín Wọn àti Àwọn Àwùjọ Àlùfáà Kristẹndọm

3, 4. Báwo ni a ti sábà máa ń fi àwọn àwùjọ àlùfáà Kristẹndọm hàn lọ́dọ̀ àwọn oníròyìn?

3 Ní ìyàtọ̀ gedegbe, ohun tí a ń gbọ́ nínú ìròyìn ti ṣí i payá lọ́pọ̀ ìgbà léraléra pé ọ̀pọ̀ lára àwọn àwùjọ àlùfáà ní àwọn ilẹ̀ kan jẹ́ abọ́mọdélòpọ̀, arẹ́nijẹ oníwà pálapàla, àti oníjìbìtì. Àwọn iṣẹ́ ti ara àti ọnà ìgbà gbé ìgbésí-ayé wọn tí ń nánilówó rékọjá ààlà farahàn kedere fún gbogbo ènìyàn láti rí. Gbajúmọ̀ akọ̀wé orin kan sọ ọ́ dáradára nínú orin rẹ̀ tí ó ní àkọlé náà “Ǹjẹ́ Jesu Yóò Ha So Rolex [aago-ọwọ́ oníwúrà tí ó gbówólórí] Mọ́wọ́ Lákòókò Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Rẹ̀ Lórí Tẹlifíṣọ̀n Bí?” Ó béèrè ìbéèrè náà pé: “Jesu yóò ha jẹ́ olóṣèlú bí Ó bá padà wá sórí Ilẹ̀-Ayé bí? Kí ó ní ilé rẹ̀ kejì ní Palm Springs [àdúgbò àwọn ọlọ́rọ̀ ní California] kí ó sì gbìyànjú láti fi bí ọrọ̀ Rẹ̀ ti pọ̀ tó pamọ́ bí?” Ẹ wò bí àwọn ọ̀rọ̀ Jakọbu ti bá a mú wẹ́kú tó: “Ẹ̀yin ti gbé ninu fàájì lórí ilẹ̀-ayé ẹ sì ti kówọnú adùn ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara. Ẹ ti bọ́ ọkàn-àyà yín sanra ní ọjọ́ ìfikúpa.”​—⁠Jakọbu 5:5, NW; Galatia 5:​19-⁠21.

4 Ìṣewọléwọ̀de àwọn àwùjọ àlùfáà pẹ̀lú àwọn olóṣèlú àti kíkópa nínú àwọn ìdìbò gẹ́gẹ́ bí olùnàgà fún àǹfààní ipò òṣèlú pàápàá fihàn pé wọ́n jẹ́ akọ̀wé àti Farisi òde-òní. Ní àkókò kan náà, ní àwọn orílẹ̀-èdè bíi United States àti Canada, owó gọbọi tí wọ́n ń ná nítorí ìṣẹjọ́ ní kóòtù àti ìdájọ́ lòdìsí àwọn àwùjọ àlùfáà, tí ó jẹ́ ìyọrísí ìwàkíwà wọn pẹ̀lú àwọn ọmọdé àti àwọn àgbàlagbà ti mú kí àpò àwùjọ àwọn ìsìn gbẹ táútáú.​—⁠Matteu 23:​1-⁠3.

5. Èéṣe tí ẹ̀rí kò fihàn pé àwọn àwùjọ àlùfáà Kristẹndọm ni “olùṣòtítọ́ àti ọlọ́gbọ́n-inú ẹrú”?

5 Lọ́nà títọ́, Jesu lè sọ fún àwọn àwùjọ àlùfáà tí ọjọ́ rẹ̀ pé: “Ègbé ni fún yín, ẹ̀yin akọ̀wé àti Farisi, àgàbàgebè; nítorí tí ẹ̀yin dàbí ibojì funfun, tí ó dára ní òde, ṣùgbọ́n nínú wọ́n kún fún egungun òkú, àti fún ẹ̀gbin gbogbo. Gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yin pẹ̀lú farahàn ní òde bí olódodo fún ènìyàn, ṣùgbọ́n nínú ẹ kún fún àgàbàgebè àti ẹ̀ṣẹ̀.” Nípa báyìí, Ọlọrun kò fi iṣẹ́ náà láti wàásù ìhìnrere rán àwọn àwùjọ àlùfáà Kristẹndọm, yálà Katoliki, Protestanti, Orthodox, tàbí ìsìn aládàáni. Wọn kò tíì fẹ̀ríhàn pé wọ́n jẹ́ “olùṣòtítọ́ àti ọlọgbọ́n-inú ẹrú.”​—⁠Matteu 23:27, 28; 24:45-⁠47, NW.

Èéṣe tí A Fi Níláti Kọ́kọ́ Wàásù Ìhìnrere?

6. Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ wo ni wọ́n máa tó ṣẹlẹ̀?

6 Nínú ẹ̀dà ìtúmọ̀ ṣókí tirẹ̀ nípa àṣẹ Jesu láti wàásù ìhìnrere ní gbogbo orílẹ̀-èdè, Marku nìkanṣoṣo ni ó lo ọ̀rọ̀ náà “kọ́kọ́.” (Marku 13:10, NW; fiwé Matteu 24:14.) Ẹ̀dà ìtumọ̀ ti J. B. Phillips kà pé: “Nítorí kí òpin tó dé a gbọ́dọ̀ polongo ìhìnrere náà fún gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè.” Lílo “kọ́kọ́” gẹ́gẹ́ bí aṣàpọ́nlé ọ̀rọ̀-ìṣe túmọ̀sí pé àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ mìíràn yóò tẹ̀lé iṣẹ́ ìjíhìnrere kárí-ayé náà. Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ wọ̀nyẹn yóò ní nínú ìpọ́njú ńlá tí a ṣèlérí náà àti ìṣàkóso òdodo ti Kristi lórí ayé titun náà. ​—⁠Matteu 24:​21-⁠31; Ìfihàn 16:14-⁠16; 21:1-⁠4.

7. Èéṣe tí Ọlọrun fi fẹ́ kí a kọ́kọ́ wàásù ìhìnrere náà?

7 Nítorí náà èéṣe tí Ọlọrun fi fẹ́ kí a kọ́kọ́ wàásù ìhìnrere náà? Ìdí kan ni pé òun jẹ́ Ọlọrun ìfẹ́, ìdájọ́ òdodo, ọgbọ́n, àti agbára. Nínú ìmúṣẹ àwọn gbólóhùn Jesu tí a kọsílẹ̀ nínú Matteu 24:14 àti Marku 13:10, a lè rí ìfihànjáde wíwọnilọ́kàn ti àwọn ànímọ́ Jehofa. Ní ṣókí, ẹ jẹ́ kí a ṣàyẹ̀wò wọn níkọ̀ọ̀kan kí a sì rí bí wọ́n ṣe tanmọ́ ìwàásù ìhìnrere náà.

Ìhìnrere àti Ìfẹ́ Jehofa

8. Báwo ni wíwàásù ìhìnrere náà ṣe jẹ́ ìfihàn ìfẹ́ Ọlọrun? (1 Johannu 4:​7-⁠16)

8 Báwo ni wíwàásù ìhìnrere náà ṣe fi ìfẹ́ Ọlọrun hàn? Ṣáájú ohun gbogbo, nítorí pé kìí ṣe ìhìn-iṣẹ́ tí a retí pé kí ó wà fún kìkì ẹ̀yà ìran tàbí àwùjọ kanṣoṣo péré. Ó jẹ́ ìhìnrere fùn “gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè.” Ọlọrun nífẹ̀ẹ́ ìdílé ènìyàn, tóbẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí ó fi rán Ọmọkùnrin bíbí kanṣoṣo rẹ̀ sí ilẹ̀-ayé láti jẹ́ ẹbọ ìràpadà fún ẹ̀ṣẹ̀ gbogbo aráyé, kìí ṣe fún ẹ̀yà ìran kanṣoṣo péré. Aposteli Johannu kọ̀wé pé: “Ọlọrun nífẹ̀ẹ́ ayé tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí ó fi fi Ọmọkùnrin bíbí rẹ̀ kanṣoṣo fúnni, kí olúkúlùkù ẹni tí ó bá ń lo ìgbàgbọ́ ninu rẹ̀ má baà parun ṣùgbọ́n kí ó lè ní ìyè àìnípẹ̀kun. Nitori Ọlọrun rán Ọmọkùnrin rẹ̀ jáde sí ayé, kì í ṣe kí ó lè ṣèdájọ́ ayé, bíkòṣe kí a lè gba ayé là nípasẹ̀ rẹ̀.” (Johannu 3:​16, 17, NW) Dájúdájú ìhìnrere náà, ìhìniṣẹ́ kan tí ń ṣèlérí ayé titun ti àlàáfíà, ìṣọ̀kan, àti ìdájọ́ òdodo, jẹ́ ẹ̀rí ìfẹ́ Ọlọrun.​—⁠2 Peteru 3:⁠13.

Ìhìnrere àti Agbára Jehofa

9. Èéṣe tí Jehofa kò fi lo àwọn ìsìn lílágbára ti Kristẹndọm láti wàásù ìhìnrere?

9 Báwo ni agbára Jehofa ṣe farahàn nípasẹ̀ ìwàásù ìhìnrere? Rò ó wò ná, ta ni ó ti lò láti mú iṣẹ́ àfiránni yìí ṣẹ? Ṣe àwọn ètò-àjọ ìsìn Kristẹndọm tí wọ́n lágbára jùlọ ni, àwọn bíi Ṣọ́ọ̀ṣì Roman Katoliki tàbí àwọn ẹ̀ya ìsìn Protestanti tí wọ́n lókìkí? Bẹ́ẹ̀kọ́, ìlọ́wọ́ wọn nínú òṣèlú sọ wọ́n di aláìtóótun fún iṣẹ́ àyànfúnni náà. (Johannu 15:19; 17:14; Jakọbu 4:⁠4) Ọrọ̀ tí ó ṣeéṣe kí wọ́n ní àti àwọn àjọṣepọ̀ àti agbára ìdarí wọn lórí àwọn ẹgbẹ́ ọ̀tọ̀kùlú ọlọ́lá tí ń ṣàkóso kò wú Jehofa Ọlọrun lórí, bẹ́ẹ̀ sì ni ẹ̀kọ́ ìsìn wọn tí a gbékarí ẹ̀kọ́ àtọwọ́dọ́wọ́. Agbára ènìyàn ni a kò nílò láti mú kí ìfẹ́ Ọlọrun di ṣíṣe.​—⁠Sekariah 4:⁠6.

10. Ta ni Ọlọrun ti yàn láti ṣe iṣẹ́ ìwàásù?

10 Gẹ́gẹ́ bí aposteli Paulu ti sọ ọ́ nínú lẹ́tà rẹ̀ sí ìjọ Korinti ni ó rí: “Ẹ sá wo ìpè yín, ará, bí ó tí ṣe pé kìí ṣe ọ̀pọ̀ àwọn ọlọ́gbọ́n ènìyàn nípa ti ara, kìí ṣe ọ̀pọ̀ àwọn alágbára, kìí ṣe ọ̀pọ̀ àwọn ọlọ́lá ni a pè: ṣùgbọ́n Ọlọrun ti yan àwọn ohun wèrè ayé láti fi dààmú àwọn ọlọ́gbọ́n; Ọlọrun sì ti yan àwọn ohun àìlera ayé láti fi dààmú àwọn ohun tí ó ní agbára; àti àwọn ohun ayé tí kò níyìn, àti àwọn ohun tí a ń kẹ́gàn, ni Ọlọrun sì ti yàn, àní, àwọn ohun tí kò sí, láti sọ àwọn ohun tí ó wà di asán: kí ó máṣe sí ẹlẹ́ran-ara tí yóò ṣògo níwájú rẹ̀.”​—⁠1 Korinti 1:​26-⁠29.

11. Àwọn òtítọ́ wo nípa àwọn Ẹlẹ́rìí ni ó ti mú kí wọ́n jẹ́ aláìlẹ́gbẹ́?

11 Àwọn mẹ́ḿbà díẹ̀ tí wọ́n jẹ́ ọlọ́rọ̀ ni àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ní nínú ètò-àjọ wọn ó sì dájú pé wọ́n kò ní àwọn alágbára níti òṣèlú. Àìdásí tọ̀tún-tòsì wọn nínú àwọn ọ̀ràn òṣèlú láìgbagbẹ̀rẹ́ túmọ̀sí pé wọn kò lè lo agbára ìdarí kankan níti òṣèlú. Ní òdìkejì ẹ̀wẹ̀, lọ́pọ̀ ìgbà ni wọ́n ti jẹ́ òjìyà ìpalára lọ́wọ́ inúnibíni bíburú jáì tí àwọn aṣáájú ìsìn àti òṣèlú ru sókè ní ọ̀rúndún ogún yìí. Síbẹ̀, lójú inúnibíni rírorò tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn ìjọba Nazi, Fascist, Kọmunist, ìfẹ́-orílẹ̀-èdè ẹni, àti ìsìn èké, gbé dìde lòdìsí wọn, kìí ṣe pé àwọn Ẹlẹ́rìí náà ń wàásù ìhìnrere ní gbogbo ayé nìkan ni ṣùgbọ́n lọ́nà tí ó yanilẹ́nu wọ́n tún ti pọ̀ síi ní iye.​—⁠Isaiah 60:⁠22.

12. Èéṣe tí àwọn Ẹlẹ́rìí fi ń ṣàṣeyọrí?

12 Kí ni àwọn Ẹlẹ́rìí gbà pé ó jẹ́ orísun àṣeyọrí wọn? Jesu ṣèlérí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Ẹ̀yin ó gba agbára, nígbà tí Ẹ̀mí Mímọ́ bá bà lé yín: ẹ ó sì máa ṣe ẹlẹ́rìí mi ní Jerusalemu, àti ní gbogbo Judea, àti ní Samaria, àti títí dé òpin ilẹ̀-ayé.” Nítorí náà, kí ni ohun náà gan-⁠an tí yóò jẹ́ orísun àṣeyọrí wọn? Jesu wí pé: “Ẹ̀yin ó gba agbára, nígbà tí Ẹ̀mí Mímọ́ bá bà lé yín.” Bákan náà lónìí, agbára láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun ni ó ti jẹ́ kọ́kọ́rọ́ náà sí àṣeyọrí àwọn Ẹlẹ́rìí nínú iṣẹ́-òjíṣẹ́ wọn kárí-ayé, kìí ṣe agbára ènìyàn. Ní lílo àwọn ènìyàn tí wọ́n dàbí ohun àìlera jùlọ, Ọlọrun ń ṣe àṣeparí iṣẹ́ ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ títóbi jùlọ náà nínú ọ̀rọ̀ ìtàn.​—⁠Iṣe 1:8; Isaiah 54:⁠13.

Ìhìnrere àti Ọgbọ́n Jehofa

13. (a) Èéṣe tí àwọn Ẹlẹ́rìí fi ń fínnú-fíndọ̀ ṣiṣẹ́sìn láìjẹ́ pé a ń sanwó fún wọn? (b) Ọ̀nà wo ni Jehofa ti gbà dáhùn ìṣáátá Satani?

13 Àwọn olùyọ̀ọ̀da ara-ẹni ni wọ́n ń wàásù ìhìnrere náà. Jesu wí pé: “Ọ̀fẹ́ ni ẹ̀yin gbà, ọ̀fẹ́ ni kí ẹ fi fúnni.” (Matteu 10:⁠8) Nítorí náà, kò sí èyíkéyìí nínú àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa tí ń gba owó-oṣù fún ṣíṣiṣẹ́sin Ọlọrun, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò sì wá a. Níti tòótọ́, wọn kìí tilẹ̀ gba ìdáwó ní àwọn ìpàdé wọn. Wọ́n láyọ̀, nípasẹ̀ iṣẹ́-ìsìn àìmọtara-ẹni-nìkan onífọkànsìn wọn, láti mú kí Ọlọrun pèsè ìdáhùn fún ẹni tí ń fẹ̀sùnkàn án, Satani Eṣu. Ẹni ẹ̀mí tí ó jẹ́ alátakò Ọlọrun yìí ti sọ nítòótọ́ pé àwọn ènìyàn kì yóò ṣiṣẹ́sin Ọlọrun pẹ̀lú ète ìsúnniṣe tí kò ní ìmọtara-ẹni-nìkan. Nínú ọgbọ́n rẹ̀ Jehofa ti pèsè ìdáhùn pelemọ sí ìṣáátá Satani​—⁠àràádọ́ta-ọ̀kẹ́ àwọn Kristian Ẹlẹ́rìí olùṣòtítọ́ tí wọ́n ń wàásù ìhìnrere náà láti ilé dé ilé, ní àwọn òpópónà, àti láìjẹ́ bí àṣà.​—⁠Jobu 1:8-⁠11; 2:3-⁠5; Owe 27:⁠11.

14. Kí ni “ọgbọ́n tí ó farasin” èyí tí Paulu tọ́kasí?

14 Ẹ̀rí mìíràn nípa ọgbọ́n Ọlọrun ní mímú kí a wàásù ìhìnrere náà ni pé ìlérí Ìjọba náà fúnraarẹ̀ jẹ́ ìfihàn ọgbọ́n Ọlọrun. Aposteli Paulu kọ̀wé pé: “Ṣùgbọ́n àwa ń sọ̀rọ̀ ọgbọ́n láàárín àwọn tí ó pé: ṣùgbọ́n kìí ṣe ọgbọ́n ti ayé yìí, tàbí ti àwọn olórí ayé yìí, tí ó di asán: ṣùgbọ́n àwa ń sọ̀rọ̀ ọgbọ́n Ọlọrun ní ìjìnlẹ̀, àní ọgbọ́n tí ó farasin, èyí tí Ọlọrun ti lànà sílẹ̀ ṣáájú ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé fún ògo wa.” “Ọgbọ́n tí ó farasin” náà ń tọ́kasí ọ̀nà ọlọgbọ́n ti Ọlọrun lò láti fòpin sí ìṣọ̀tẹ̀ tí ó bẹ̀rẹ̀ ní Edeni. Ọgbọ́n àṣírí mímọ́ ọlọ́wọ̀ yẹn ni a ṣípayá nínú Jesu Kristi, ẹni tí kò ṣeé fọwọ́ rọ́ sẹ́yìn níti ìhìnrere Ìjọba Ọlọrun.a​—⁠1 Korinti 2:​6, 7; Kolosse 1:26-⁠28.

Ìhìnrere àti Ìdájọ́ Òdodo Ọlọrun

15. Báwo ni a ṣe mọ̀ pé Jehofa jẹ́ Ọlọrun onídàájọ́ òdodo? (Deuteronomi 32:4; Orin Dafidi 33:⁠5)

15 Ní pàtàkì ní ìsopọ̀ pẹ̀lú ìdájọ́ òdodo ni a rí ìjẹ́pàtàkì ọ̀rọ̀ náà “kọ́kọ́” tí ó wà ní Marku 13:10. Jehofa jẹ́ Ọlọrun onídàájọ́ òdodo tí ó kún fún ìṣeun-ìfẹ́. Ó sọ nípasẹ̀ wòlíì rẹ̀ Jeremiah pé: “Ṣùgbọ́n kí ẹnikẹ́ni tí yóò bá máa ṣògo, kí ó ṣe é nínú èyí pé: òun ní òye, òun sì mọ̀ mí; pé, Èmi ni Oluwa tí ń ṣe àánú àti [ìdájọ́ òdodo, NW] àti òdodo ní ayé: nítorí inú mi dùn nínú ohun wọ̀nyí, ni Oluwa wí.”​—⁠Jeremiah 9:⁠24.

16. Báwo ni a ṣe lè ṣàkàwé rẹ̀ pé ìdájọ́ òdodo béèrè pé kí a kọ́kọ́ kìlọ̀?

16 Báwo ni a ṣe fi ìdájọ́ òdodo Jehofa hàn níti wíwàásù ìhìnrere? Ẹ jẹ́ kí a ṣàkàwé rẹ̀ pẹ̀lú ìyá kan tí ó dín àkàrà àjẹpọ́nnulá kan fún jíjẹ nígbà tí àwọn àlejò bá dé ní ọjọ́rọ̀. Bí ó bá fi í silẹ̀ lórí tábìlì ilé ìdáná láìbá àwọn ọmọ rẹ̀ sọ nǹkankan nípa ìgbà tí wọn yóò jẹ ẹ́, kí ni yóò jẹ́ ìtẹ̀sí àwọn ọmọ náà lọ́nà tí ẹ̀dá? Gbogbo wa ti jẹ́ ọmọdé nígbà kan rí! Ọmọdé a fẹ́ láti tọ́ àkàrà náà wò ṣáá ni! Bí ó bá jẹ́ pé màmá kùnà láti fúnni ní ìkìlọ̀ tí ó yẹ ńkọ́, kò ní ní ìdí tí ó lágbára tó láti fúnni ní ìbáwí. Ní ọwọ́ mìíràn ẹ̀wẹ̀, bí ó bá sọ ní kedere pé àkàrà náà ni a ṣì máa jẹ nígbà tí àwọn àlejò bá dé àti nítorí náà kí a máṣe fọwọ́kàn án, nígbà náà òun tí fúnni ní ìkìlọ̀ lọ́nà ṣíṣe kedere. Bí ṣíṣe àìgbọ́ràn bá wà, òun lẹ́tọ̀ọ́ láti gbé ìgbésẹ̀ onídùúrógbọnyin àti èyí tí ó bá ìdájọ́ òdodo mu.​—⁠Owe 29:⁠15.

17. Báwo ni Jehofa ṣe ń fi ìdájọ́ òdodo hàn lọ́nà àkànṣe láti ọdún 1919 wá?

17 Nínú ìdájọ́ òdodo rẹ̀, Jehofa kì yóò gbé ìgbésẹ̀ ìdájọ́ lòdìsí ètò ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan búburú yìí láìjẹ́ pé ó kọ́kọ́ fúnni ní ìkìlọ̀ tí ó yẹ. Nítorí náà, ní pàtàkì jùlọ láti 1919, lẹ́yìn tí ogun àgbáyé kìn-ín-⁠ní ti mú “ìroragógó wàhálà” wá, Jehofa ti mú kí àwọn Ẹlẹ́rìí rẹ̀ lọ jákèjádò ilẹ̀-ayé ní fífi tìtara-tìtara polongo ìhìnrere náà. (Matteu 24:​7, 8, 14, NW) Àwọn orílẹ̀-èdè kò lè fi pẹ̀lú ẹ̀tọ́ jẹ́wọ́ pé àwọn kò mọ̀ nípa ìkìlọ̀ aláìlẹ́gbẹ́ yìí.

Báwo Ni A Ti Kárí Ayé Lọ́nà Gbígbòòrò Tó?

18. (a) Ẹ̀rí wo ni ó wà nípa ìgbòkègbodò àwọn Ẹlẹ́rìí ní àwọn àgbègbè àdádó? (b) Àwọn àpẹẹrẹ mìíràn wo ni o mọ̀ nípa rẹ̀?

18 Ìtọ́kasí kan nípa ìgbéṣẹ́ iṣẹ́ ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ kárí-ayé yìí ni a lè rí láti inú ìwé náà Last Places​—⁠A Journey in the North. Òǹkọ̀wé rẹ̀ ròyìn pé nígbà tí òun yẹ erékùṣù Foula, ọ̀kan nínú àwọn Erékùṣù Shetland ní àríwá Scotland tí ó wà ní àdádó wò nínú àwòrán atọ́ka òkun, àwòrán atọ́ka náà fihàn pé “yíká gbogbo erékùṣù náà pátá ni WKS (àwọn àwókù ọkọ̀), RKS (àwọn àpáta), LDGS (àwọn àpáta yíyọgọnbu), àti OBS (àwọn ohun ìdíwọ́) wà.” Ìwọ̀nyí “ń kìlọ̀ fún àwọn tí ń gbèrò láti di awakọ̀ òkun láti takété. Omi òkun tí ó yí Foula ká jẹ́ pápá-ìwakùsà kan tí ń dániníjì, èyí tí ó mú kí erékùṣù náà jẹ́ ibi àrísá fún àwọn atukọ̀ ọlọ́pọ́n, àwọn atukọ̀ òòjọ́, àti àwùjọ àwọn òṣìṣẹ́ lábẹ́ Ọbabìnrin ilẹ̀ England, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé​—⁠mo mọ̀ láàárín ìwọ̀nba ọjọ́ díẹ̀ síi⁠—​pé kò lé àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa sá.” Ó ń báa nìṣó pé: “Gan-⁠an bí ó ti jẹ́ pé wọ́n ń lọ jákèjádò àwọn àdúgbò onílé ẹgẹrẹmìtì ní àwọn ìlú-ńlá àti ní Àgbáyé Kẹta láti wá àwọn tí wọ́n lè yí lọ́kàn padà rí, bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú ni wọ́n ń mú àwọn ènìyàn wọnú ìsìn wọn ní Foula tí ó wà ní àdádó.” Ó jẹ́wọ́ pé Andrew olùgbé kan ní àdúgbò, ní a fi ẹ̀dà Ilé-Ìṣọ́nà kan sílẹ̀ lẹ́nu ọ̀nà rẹ̀ ní oṣù díẹ̀ sẹ́yìn. Lẹ́yìn náà ó fikún un pé: “Ní ọ̀sẹ̀ kan lẹ́yìn náà èmi tún rí ẹ̀dà kan [Jí! ní èdè Danish] ní Faeroes [àwọn erékùṣù North Sea] àti ní oṣù méjì lẹ́yìn náà ẹ̀dà kan [Ilé-Ìṣọ́nà ní èdè Danish] ní Nuuq, Greenland.” Ẹ wo ẹ̀rí híhàn kedere tí èyí jẹ́ sí ìgbòkègbodò onítara ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ní àwọn ẹkùn ìhà àríwá wọ̀nyẹn!

Kí Ni Ń Sún Àwọn Ẹlẹ́rìí náà Ṣiṣẹ́?

19, 20. (a) Kí ní ń sún àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa láti máa wàásù nìṣó? (b) Àwọn ìbéèrè wo ni a óò dáhùn tẹ̀lé e?

19 Àmọ́ ṣáá o, wíwàásù fún àwọn àjèjì láti ilé dé ilé kìí ṣe ọ̀ràn tí ó rọrùn, láìka iye ọdún tí ẹnìkan ti lè jẹ́ Ẹlẹ́rìí sí. Nígbà náà kí ni ń sún àwọn Kristian wọ̀nyí ṣiṣẹ́? Ìyàsímímọ́ Kristian wọn àti níní òye náà pé wọn yóò jíhìn. Paulu kọ̀wé pé: “Nítorí pé bí mo ti ń wàásù ìhìnrere, èmi kò ní ohun tí èmi ó fi ṣògo: nítorí pé àìgbọ́dọ̀máṣe wà lórí mi; àní, mo gbé! bí èmi kò bá wàásù ìhìnrere.” Àwọn Kristian tòótọ́ ní ìhìn-iṣẹ́ kan tí ó túmọ̀sí ìyè, nítorí náà báwo ni wọ́n ṣe lè pa á mọ́ sọ́dọ̀ ara wọn nìkan? Ìlànà náà gan-⁠an nípa jíjẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ fún kíkùnà láti fúnni ní ìkìlọ̀ ní àkókò ewu jẹ́ ìdí tí ń súnni láti wàásù ìhìnrere.​—⁠1 Korinti 9:16; Esekieli 3:​17-⁠21.

20 Nígbà náà, báwo ni a ṣe ń wàásù ìhìnrere náà? Kí ni kọ́kọ́rọ́ náà sí àṣeyọrí àwọn Ẹlẹ́rìí? Àwọn apá-ẹ̀ka wo nínú iṣẹ́-òjíṣẹ́ àti ètò-àjọ wọn ní ó ń ṣèrànwọ́ láti mú kí a dá wọn mọ̀ gẹ́gẹ́ bí ìsìn tòótọ́? Ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ wa tí ó tẹ̀lé e yóò dáhùn àwọn ìbéèrè wọnnì.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Fún àlàyé síwájú síi nípa ọgbọ́n Ọlọrun àti “sacred secret” (àṣírí mímọ́ ọlọ́wọ̀), wo Insight on the Scriptures, Ìdìpọ̀ II, ojú-ìwé 1190, tí a tẹ̀jáde láti ọwọ́ Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc.

Ìwọ Ha Rántí Bí?

◻ Kí ni ó fi àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa hàn yàtọ̀ sí àwọn àwùjọ àlùfáà?

◻ Báwo ni ìwàásù ṣe fi ìfẹ́, agbára, àti ọgbọ́n Ọlọrun hàn?

◻ Báwo ni wíwàásù ìhìnrere náà ṣe fi ìdájọ́ òdodo Ọlọrun hàn?

◻ Kí ni ń sún àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa láti máa báa nìṣó nínú iṣẹ́-òjíṣẹ́ wọn?

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]

Bí ó ti wù kí àwọn ènìyàn wà ní àdádó tó, àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ń fẹ́ láti dé ọ̀dọ̀ wọn

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́