Ìmọ̀-Ìjìnlẹ̀, Ìsìn, Ati Wíwá Òtítọ́ Kiri
“Òtítọ́ naa pé ọ̀pọ̀ ìsìn èké ti tànkálẹ̀ . . . ní ipa kan lórí mí.”—Charles Darwin
NÍ ÌBẸ̀RẸ̀ ọ̀rúndún kọkàndínlógún, ìmọ̀-ìjìnlẹ̀ ati ìsìn gbádùn ipò-ìbátan ọlọ́rẹ̀ẹ́sọ́rẹ̀ẹ́. Ìwé naa Darwin: Before and After, sọ pé, “Àní ninu awọn ìwé ìmọ̀-ìjìnlẹ̀ pàápàá awọn òǹkọ̀wé kò lọ́tìkọ̀ lati sọ̀rọ̀ nipa Ọlọrun lọ́nà kan tí ó hàn kedere pé ó bá ìwà ẹ̀dá mu tí ó sì jẹ́ látọkànwá.”
Ìwé Origin of Species tí Darwin ṣe ṣèrànwọ́ lati yí ìyẹn padà. Ìmọ̀-ìjìnlẹ̀ ati ẹfolúṣọ̀n wá lẹ̀dí àpò pọ̀ èyí tí ó fa àìka ìsìn—ati Ọlọrun—sí. Sir Julian Huxley sọ pé, “Ní ríronú lọ́nà ti ẹfolúṣọ̀n kò pọndandan mọ́ bẹ́ẹ̀ ni kò sì yẹ lati ronú nipa ẹlẹ́dàá kan mọ́.”
Lónìí àbá-èrò-orí ẹfolúṣọ̀n ni wọn ń sọ pé ó jẹ́ ìpìlẹ̀ tí ó ṣe pàtàkì fún ìmọ̀-ìjìnlẹ̀. Fred Hoyle onímọ̀ physics fi ìdí pàtàkì kan fún ipò-ìbátan naa hàn ní sísọ pé: “Ṣíṣèdíwọ́ fún pípadà sí níní ojú-ìwòye aláṣerégèé tí ó ti kọjá nipa ìsìn jẹ awọn onímọ̀-ìjìnlẹ̀ tí wọn tòròpinpin mọ́ ojú-ìwòye ìjímìjí lógún ju ríretí òtítọ́ lọ.” Irú awọn àṣerégèé wo ni ó ti mú kí ìsìn kó ìmọ̀-ìjìnlẹ̀ nírìíra tóbẹ́ẹ̀?
Ìsìn Ba Orúkọ Ìṣẹ̀dá Jẹ́
Ninu ohun tí wọn lérò pé ó jẹ́ ìgbìyànjú lati dìrọ̀mọ́ Bibeli, awọn “ẹlẹ́kọ̀ọ́ ẹlẹ́dàá-ń-bẹ”—tí pupọ ninu wọn ti wọnú àjọṣepọ̀ pẹlu awọn arinkinkin mọ́ ìlànà ìsìn Protẹstanti—ti tẹnumọ́ ọn pé kò tíì tó 10,000 ọdún tí a dá ayé ati àgbáyé wa. Ojú-ìwòye aláṣerégèé yii ti fa ìfiniṣẹ̀sín lati ọ̀dọ̀ awọn onímọ̀ nipa ìpele ilẹ̀ òkúta ati ẹ̀dá ilẹ̀ ayé, onímọ̀ nipa gbangba ojúde òfúúrufú, ati physics, nitori pé ó tako ìṣàwárí wọn.
Ṣugbọn kí ni Bibeli sọ níti gidi? “Ní àtètèkọ́ṣe Ọlọrun dá ọ̀run oun ayé.” (Genesisi 1:1) Kò mẹnuba àkókò tí ó gbà ní pàtó. Kò tilẹ̀ mẹ́nukan “ọjọ́ kìn-ín-ní” ìṣẹ̀dá rárá ṣáájú Genesisi 1:3-5. “Ọ̀run oun ayé” ti wà ṣáájú kí “ọjọ́” kìn-ín-ní yii tó bẹ̀rẹ̀. Nitori naa, awọn ọ̀run ati ayé ha lè ti wà fún àràádọ́ta ọ̀kẹ́ lọ́nà àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ọdún, gẹ́gẹ́ bí awọn onímọ̀-ìjìnlẹ̀ ti sọ bí? Wọn lè tó bẹ́ẹ̀ dáradára. Bibeli kò wulẹ̀ sọ àkókò tí ó gbà ní pàtó.
Àṣerégèé mìíràn tí ìsìn ṣe ni bí awọn kan ṣe túmọ̀ ‘awọn ọjọ́’ mẹ́fà ti ìṣẹ̀dá. Awọn arinkinkin mọ́ ìlànà kan tẹnumọ́ ọn pé awọn ọjọ́ wọnyi jẹ́ ọjọ gidi, tí wọn sì fi ìṣẹ̀dá ayé mọ sí sáá oníwákàtí 144. Èyí gbé iyèméjì dìde ninu awọn onímọ̀-ìjìnlẹ̀, nitori wọn ronú pé èrò yii takora pẹlu àyẹ̀wò ṣíṣe kedere tí ìmọ̀-ìjìnlẹ̀ ṣe.
Bí ó ti wù kí ó rí, ìtumọ̀ tí awọn arinkinkin mọ́ ìlànà Bibeli—kìí ṣe Bibeli fúnraarẹ̀—ni ó takora pẹlu ìmọ̀-ìjìnlẹ̀. Bibeli kò sọ pé “ọjọ́” ìṣẹ̀dá kọ̀ọ̀kan jẹ́ wákàtí 24 ní gígùn; nítòótọ́, ó fi gbogbo ‘awọn ọjọ́’ wọnyi kún “ọjọ́” gígùn síi “tí OLUWA Ọlọrun dá ayé oun ọ̀run,” tí ó fihàn pé kìí ṣe gbogbo ‘awọn ọjọ́’ tí a gbékarí Bibeli ni wọn jẹ́ kìkì wákàtí 24. (Genesisi 2:4) Awọn kan ti lè jẹ́ ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún ní gígùn.a
Nipa bayii, awọn ẹlẹ́kọ̀ọ́ ẹlẹ́dàá-ń-bẹ ati awọn tí ó rinkinkin mọ́ ìlànà ìsìn ti ba orúkọ èrò naa pé ẹlẹ́dàá-ń-bẹ jẹ́. Awọn ẹ̀kọ́ wọn nipa ọjọ-orí àgbáyé ati gígùn ‘awọn ọjọ́’ ìṣẹ̀dá kò sí ní ìbámu pẹlu yálà ìmọ̀-ìjìnlẹ̀ tí ó bọ́gbọ́nmu tabi pẹlu Bibeli. Bí ó ti wù kí ó rí, awọn àṣerégèé mìíràn tún wà tí ó mú kí ìsìn kó awọn onímọ̀-ìjìnlẹ̀ nírìíra.
Àṣìlò Agbára
Jálẹ̀ gbogbo ọ̀rọ̀-ìtàn, ìsìn ti jẹ́ okùnfà fun ọ̀pọ̀ àìsí ìdájọ́-òdodo. Fún àpẹẹrẹ, láàárín awọn Sànmánnì Agbedeméjì, ẹ̀kọ́ ìgbàgbọ́ ìṣẹ̀dá ni a lọ́po lati wá ìdáláre fún títì tí Ṣọ́ọ̀ṣì ti ìjẹgàba ilẹ̀ Europe lẹ́yìn. Ohun tí wọn dọ́gbọ́n túmọ̀ rẹ̀ sí ni pé àṣẹ àtọ̀runwá ni a fi gbé ẹ̀dá ènìyàn sí ipò èyíkéyìí, yálà ọlọ́rọ̀ tabi òtòṣì. Ìwé The Intelligent Universe ṣàlàyé pé: “Awọn ọ̀dọ́mọkùnrin awọn ọlọ́rọ̀ ni a sọ fún pé ‘ètò-ìgbékalẹ̀ Ọlọrun’ ni fún wọn lati gba díẹ̀ lára ogún-ìní ìdílé tabi lati máṣe gbà níbẹ̀ rárá, ọkùnrin òṣìṣẹ́ ni a sì ń rọ̀ léraléra lati jẹ́ kí ‘ipò tí Ọlọrun fi sí’ tẹ́ ẹ lọ́rùn.”
Abájọ nígbà naa tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ fi ń bẹ̀rù ati padà sí “awọn àṣerégèé ti ìsìn tí ó ti kọjá”! Dípò kí ó tẹ́ àìní tẹ̀mí ènìyàn lọ́rùn, ìsìn ti fìgbà gbogbo fi í ṣe ìrẹ́nijẹ. (Esekieli 34:2) Ọ̀rọ̀ olóòtú kan ninu ìwé ìròyìn India Today ṣàlàyé pé: “Pẹlu irú àkọsílẹ̀ tí ó ti ní ní awọn sànmánnì tí ó ti kọjá, ó jẹ́ ìyàlẹ́nu pé ìsìn ṣì ṣeé gbáralé. . . . Awọn ẹ̀dá ènìyàn ti dá ẹ̀ṣẹ̀ rírínilára jùlọ sí awọn ẹ̀dá ẹlẹgbẹ́ wọn . . . lórúkọ Ẹlẹ́dàá Onípò Àjùlọ.”
Ìròyìn bíburú jáì nipa ìsìn èké ní ipa pupọ lórí ìrònú Darwin. Ó kọ̀wé pé, “Kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ ni mo bẹ̀rẹ̀ síí sọ ìgbàgbọ́ nù ninu ìsìn Kristian gẹ́gẹ́ bí ìfihàn àtọ̀runwá. Òtítọ́ naa pé ọ̀pọ̀ ìsìn èké ti tàn káàkiri ibi pupọ jùlọ ní ayé lọ́nà yíyára kánkán ti ní ipa kan lórí mi.”
Ìjagunmólú Ìsìn Tòótọ́
Àgàbàgebè ìsìn kò jẹ́ titun sí ayé yii mọ́. Jesu sọ fún awọn aṣáájú ìsìn ọjọ́ rẹ̀ tí agbára ń pa bí ọtí pé: “Ẹ farahàn bí ènìyàn dáradára ní òde—ṣugbọn ninu ẹ kún fun ìdíbọ́n ati ìwà ìkà.”—Matteu 23:28, Phillips.
Bí ó ti wù kí ó rí, ojúlówó ìsìn Kristian “kì í ṣe apákan ayé.” (Johannu 17:16, NW) Awọn mẹ́ḿbà rẹ̀ kìí lọ́wọ́ ninu ìsìn dídíbàjẹ́ ati òṣèlú; bẹ́ẹ̀ ni a kò fi ọgbọ́n-ìmọ̀-ọ̀ràn tí ń sẹ́ wíwà Ẹlẹ́dàá ṣì wọ́n lọ́nà. Aposteli Paulu kọ̀wé pé, “ọgbọ́n ayé yii wèrè ni lọ́dọ̀ Ọlọrun.”—1 Korinti 3:19.
Síbẹ̀, èyí kò túmọ̀sí pé awọn Kristian tòótọ́ jẹ́ ọ̀gbẹ̀rì níti ìmọ̀-ìjìnlẹ̀. Ní òdìkejì ẹ̀wẹ̀, ìmọ̀-ìjìnlẹ̀ ru ìfẹ́ awọn mẹ́ḿbà ìsìn tòótọ́ sókè. A sọ fún wòlíì Isaiah ìjímìjí pé, “Gbé ojú [rẹ] sókè síbi gíga, kí [o] sì wò, ta ni ó dá nǹkan wọnyi”? (Isaiah 40:26) Bákan naa, lati túbọ̀ lóye Ẹlẹ́dàá síi, a rọ Jobu lati wá awọn ohun àgbàyanu inú ìṣẹ̀dá ati ti àgbáyé kiri.—Jobu, ori 38 sí 41.
Bẹ́ẹ̀ni, awọn wọnnì tí wọn gbàgbọ́ ninu Ẹlẹ́dàá ń wo ìṣẹ̀dá pẹlu ìbẹ̀rù tí ó kún fún ọ̀wọ̀. (Orin Dafidi 139:14) Síwájú síi, wọn gba ohun tí Ẹlẹ́dàá naa, Jehofa Ọlọrun, sọ gbọ́ nipa ìrètí àgbàyanu fún ọjọ́-ọ̀la. (Ìfihàn 21:1-4) Nípasẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli, àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ń kẹ́kọ̀ọ́ pé ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ènìyàn tabi ọjọ́-ọ̀la rẹ̀ kò sinmi lé èèṣì lásán. Jehofa ní ète tí ó mú kí ó dá ènìyàn, ète yẹn yoo sì ní ìmúṣẹ—sí ìbùkún gbogbo ènìyàn onígbọràn. A rọ̀ ọ́ lati yẹ ọ̀ràn naa wò fúnraàrẹ.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Wo Ji!, October 22, 1985, ojú-ìwé 6 sí 9, ati Insight on the Scriptures, Ìdìpọ̀ 1, ojú-ìwé 545, tí a tẹ̀jáde lati ọwọ́ Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc. Fún àlàyé síwájú síi lórí èrò-ìgbàgbọ́ ẹlẹ́dàá-ń-bẹ ati ìforígbárí rẹ̀ pẹlu ìmọ̀-ìjìnlẹ̀ ati Bibeli, wo awọn ìtẹ̀jáde Ji! March 8, 1983, ojú-ìwé 12 sí 15, ati March 22, 1983, ojú-ìwé 12 sí 15 (Gẹ̀ẹ́sì).
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 6]
WỌN HA JẸ́ ÒPÈ SÍ Ẹ̀RÍ NAA BÍ?
NORMAN MACBETH agbẹjọ́rò kan kọ̀wé ninu ìwé rẹ̀ Darwin Retried—An Appeal to Reason tí ó ṣe ní 1971 pé, “Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa pàápàá ti lọ jìnnà gan-an ninu ẹ̀kọ́ nipa awọn ẹ̀dá abẹ̀mí.” Nígbà tí ó ka ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ kan ninu Jí! lórí kókó ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n, Macbeth kọ̀wé pé: “Ẹnu yà mí lati rí i pé ó kún fún lámèyítọ́ tí a fi ọgbọ́n féfé ṣe nipa àbá-èrò-orí Darwin.” Ní ṣíṣàkíyèsí ìwádìí jíjinlẹ̀ ati ìtọ́ka sí ọ̀rọ̀ awọn tí wọn jẹ́ abẹnugan lórí kókó ẹ̀kọ́ naa lọ́nà yíyèkooro, òǹṣèwé naa wá sí ìparí èrò pé: “Kò tọ̀nà fún Simpson mọ́ lati máa sọ pé: ‘. . . awọn wọnnì tí wọn kò gbàgbọ́ ninu rẹ̀ [ẹfolúṣọ̀n] ni gbogbo ènìyàn fẹ́rẹ̀ẹ́ lè rí gẹ́gẹ́ bí òpè sí ẹ̀rí ìmọ̀-ìjìnlẹ̀.’”
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
A kò fi ọjọ́-ọ̀la aráyé sílẹ̀ fún èèṣì lásán