ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w94 9/1 ojú ìwé 8-13
  • Bí Ó Tilẹ̀ Jẹ́ Pé Erùpẹ̀ Ni Wá, Ẹ Jẹ́ Kí A Máa Tẹ̀síwájú!

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Bí Ó Tilẹ̀ Jẹ́ Pé Erùpẹ̀ Ni Wá, Ẹ Jẹ́ Kí A Máa Tẹ̀síwájú!
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìyípadà Ninu Awọn Àyíká-Ipò
  • Erùpẹ̀ Ni A Fi Dá Awọn Naa
  • Kí Ni Jíjẹ́ Erùpẹ̀ Túmọ̀sí fún Wa Lẹ́nìkọ̀ọ̀kan?
  • Kí Ló Ń Ṣẹlẹ̀ Nígbà Téèyàn Bá Kú?
    Ohun Tí Bíbélì Sọ
  • Awọn Ẹmi Ko Gbe Ki Wọn si Kú Rí Lori Ilẹ Aye
    Ẹmi Awọn Oku—Wọn Ha Le Ran ọ Lọwọ Tabi Pa Ọ Lara Bi? Wọn Ha wa Niti Gidi Bi?
  • Kí Ló Ń Ṣẹlẹ̀ Sẹ́ni Tó Bá Kú?
    Jí!—2007
  • Kí La Lè Ṣe Nípa Ìrẹ̀wẹ̀sì?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
w94 9/1 ojú ìwé 8-13

Bí Ó Tilẹ̀ Jẹ́ Pé Erùpẹ̀ Ni Wá, Ẹ Jẹ́ Kí A Máa Tẹ̀síwájú!

“Nitori tí ó mọ ẹ̀dá wa; ó rántí pé erùpẹ̀ ni wá.”​—⁠ORIN DAFIDI 103:14.

1. Bibeli ha bá òtítọ́ ìmọ̀-ìjìnlẹ̀ mu ní sísọ pé erùpẹ̀ ni a fi dá ènìyàn? Ṣàlàyé.

LỌ́NÀ ti ara-ìyára, erùpẹ̀ ni wá. “OLUWA Ọlọrun sì fi erùpẹ̀ ilẹ̀ mọ ènìyàn; ó sì mí ẹ̀mí ìyè sí ihò imú rẹ̀; ènìyàn sì di alààyè ọkàn.” (Genesisi 2:⁠7) Àpèjúwe tí kò díjú yii nipa ìṣẹ̀dá ènìyàn wà ní ìbámu pẹlu òtítọ́ ìmọ̀-ìjìnlẹ̀. Iye tí ó ju 90 lọ lára awọn èròjà tí ó parapọ̀ di ara ènìyàn ni a lè rí ninu “erùpẹ̀ ilẹ̀.” Apòògùn kan sọ nígbà kan rí pé lára àgbàlagbà kan, afẹ́fẹ́ oxygen kó ìpín 65 ninu ọgọ́rùn-⁠ún, èròjà carbon kó ìpín 18 ninu ọgọ́rùn-⁠ún, afẹ́fẹ́ hydrogen kó ìpín 10 ninu ọgọ́rùn-⁠ún, afẹ́fẹ́ nitrogen kó ìpín 3 ninu ọgọ́rùn-⁠ún, èròjà calcium kó ìpín 1.5 ninu ọgọ́rùn-⁠ún, tí ẹ̀tù phosphorus sì kó ìpín 1 ninu ọgọ́rùn-⁠ún, nígbà tí awọn yòókù jẹ́ àpapọ̀ awọn èròjà mìíràn. Bóyá awọn ìfojúdíwọ̀n wọnyi pé pérépéré kọ́ ni pàtàkì. Òtítọ́ naa kò yípadà pé: “Erùpẹ̀ ni wá”!

2. Ìmọ̀lára wo ni ọ̀nà tí Ọlọrun gbà dá ènìyàn mú kí o ní, èésìtiṣe?

2 Yàtọ̀ sí Jehofa ta ni ó lè ṣẹ̀dá awọn ìṣẹ̀dá dídíjú bẹ́ẹ̀ lati inú erùpẹ̀ lásán? Iṣẹ́ Ọlọrun pé kò sì ní àbàwọ́n, nitori naa ó dájú pé yíyàn rẹ̀ lati dá ènìyàn lọ́nà yii kò fa àròyé. Ní tòótọ́, pé Ẹlẹ́dàá Atóbilọ́lá naa lè dá ènìyàn lati inú erùpẹ̀ ilẹ̀ ní ọ̀nà tí ó kún fún ìbẹ̀rù ọlọ́wọ̀ tí ó sì yanilẹ́nu mú kí ìmọrírì wa fún agbára aláìláàlà, òye-iṣẹ́, ati ọgbọ́n ṣíṣeémúlò Rẹ̀ pọ̀ síi.​—⁠Deuteronomi 32:4 NW, àkíyèsí-ẹsẹ̀-ìwé; Orin Dafidi 139:⁠14.

Ìyípadà Ninu Awọn Àyíká-Ipò

3, 4. (a) Kí ni Ọlọrun kò nílọ́kàn níti dídá tí ó dá ènìyàn lati inú erùpẹ̀? (b) Kí ni Dafidi ń tọ́ka sí ní Orin Dafidi 103:14, bawo sì ni àyíká-ọ̀rọ̀ naa ṣe ràn wá lọ́wọ́ lati dé ìparí èrò yii?

3 Awọn ẹ̀dá erùpẹ̀ ní ààlà. Bí ó ti wù kí ó rí, Ọlọrun kò ní in lọ́kàn rí, pé kí iwọnyi dẹ́rùpani tabi kí ó káni lọ́wọ́ kò rékọjá ààlà. Kò ní in lọ́kàn pé kí wọ́n ṣokùnfà ìrẹ̀wẹ̀sì tabi yọrísí àìláyọ̀. Síbẹ̀, gẹ́gẹ́ bí àyíká ọ̀rọ̀ Dafidi ninu Orin Dafidi 103:14 ti fihàn, awọn ààlà tí ẹ̀dá ènìyàn ní lè fa ìrẹ̀wẹ̀sì kí ó sì yọrísí àìláyọ̀. Èéṣe? Nígbà tí Adamu ati Efa ṣàìgbọràn sí Ọlọrun, wọn mú ipò tí ó yípadà bá ìdílé wọn ọjọ́-ọ̀la. Nígbà naa jíjẹ́ tí wọn jẹ́ erùpẹ̀ gbé èrò titun yọ.a

4 Dafidi ń sọ̀rọ̀ nipa awọn àlèébù ẹ̀dá ènìyàn tí àìpé àjogúnbá ṣokùnfà rẹ̀, kìí ṣe nipa awọn ààlà àdánidá tí awọn ẹ̀dá ènìyàn pípé tí a dá lati inú erùpẹ̀ pàápàá yoo ti ní. Bí kò bá jẹ́ bẹ́ẹ̀ oun kì bá tí sọ nipa Jehofa pé: “Ẹni tí ó dárí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì; ẹni tí ó sì tán gbogbo àrùn rẹ, ẹni tí ó ra ẹ̀mí rẹ kúrò ninu ìparun; [ẹni tí] kìí ṣe sí wa gẹ́gẹ́ bí ẹ̀ṣẹ̀ wa; bẹ́ẹ̀ ni kìí san án fún wa gẹ́gẹ́ bí àìṣedéédéé wa.” (Orin Dafidi 103:2-⁠4, 10) Bí a tilẹ̀ jẹ́ erùpẹ̀, kání awọn ẹ̀dá ènìyàn pípé ń bá ìṣòtítọ́ nìṣó ni, wọn kì bá tí ṣìnà, dẹ́ṣẹ̀, débi tí wọn yoo fi nílò ìdáríjì; bẹ́ẹ̀ ni wọn kì bá tí ní awọn àrùn tí ń fẹ́ ìwòsàn. Ju gbogbo rẹ̀ lọ, kì bá tí sí ìdí fún wọn lati sọ̀kalẹ̀ lọ sí ipò òkú níbi tí a ti lè gbà wọn padà kìkì nípasẹ̀ àjíǹde.

5. Èéṣe tí kò fi ṣòro fún wa lati lóye awọn ọ̀rọ̀ Dafidi?

5 Nitori pé a jẹ́ aláìpé, gbogbo wa ti nírìírí awọn ohun tí Dafidi sọ̀rọ̀ nipa rẹ̀. Nígbà gbogbo ni a ń mọ̀ nipa awọn ààlà wa nitori àìpé. Wọn ń mú wa banújẹ́ nígbà mìíràn tí ó bá dàbí ẹni pé wọn ba ìbátan wa pẹlu Jehofa ati awọn Kristian arákùnrin wa jẹ́. A ń kábàámọ̀ pé àìpé wa ati awọn ìkìmọ́lẹ̀ aye Satani máa ń mú wa sọ̀rètínù nígbà mìíràn. Níwọ̀n bí ìṣàkóso Satani ti ń yára kógbá sílé, ayé rẹ̀ ń lo ìkìmọ́lẹ̀ pupọ ju ti ìgbàkígbà rí lọ lórí gbogbo ènìyàn lápapọ̀ ati ní pàtàkì lórí awọn Kristian.​—⁠Ìfihàn 12:⁠12.

6. Èéṣe tí awọn Kristian kan fi lè rẹ̀wẹ̀sì, bawo sì ni Satani ṣe lè lo àǹfààní irú ìmọ̀lára yii?

6 O ha ń nímọ̀lára pé gbígbé ìgbésí-ayé bíi Kristian túbọ̀ ń nira síi bí? A ti gbọ́ tí awọn Kristian kan ń sọ pé bí awọn ṣe ń pẹ́ ninu òtítọ́ síi tó bẹ́ẹ̀ ni ó dàbí ẹni pé awọn ń dí aláìpé síi tó. Bí ó ti wù kí ó rí, ó ṣeéṣe jùlọ pé, wọn túbọ̀ ń kíyèsí síwájú ati síwájú síi awọn àìpé tiwọn fúnraawọn ati àìṣeéṣe wọn lati gbé ní ìbámu pẹlu awọn ọ̀pá-ìdiwọ̀n pípé ti Jehofa ní ọ̀nà tí yoo tẹ́ wọn lọ́rùn. Ṣugbọn, níti gidi, ó ti ṣeéṣe kí èyí jẹ́ ìyọrísí bíbá a nìṣó ní dídàgbà ninu ìmọ̀ ati ìmọrírì fún awọn ohun òdodo tí Jehofa béèrè fún. Ó ṣe kókó pé, kí a máṣe fàyègba irú àkíyèsí bẹ́ẹ̀ lati kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá wa dé àyè mímú ìfẹ́ Eṣu ṣẹ. Lati ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún wá ó ti gbìyànjú léraléra lati lo ìrẹ̀wẹ̀sì lati mú kí awọn ìránṣẹ́ Jehofa pa ìjọsìn tòótọ́ tì. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ojúlówó ìfẹ́ fún Ọlọrun, ati “ìkórìíra pátápátá” fún Eṣu, ti sún ọ̀pọ̀ ninu wọn lati máṣe ṣe bẹ́ẹ̀.​—⁠Orin Dafidi 139:21, 22, NW; Owe 27:⁠11.

7. Ní ọ̀nà wo ni a fi lè dàbí Jobu nígbà mìíràn?

7 Síbẹ̀, awọn ìránṣẹ́ Jehofa lè rẹ̀wẹ̀sì nígbà mìíràn. Àìní ìtẹ́lọ́rùn pẹlu àṣeyọrí wa tún lè fà á. Awọn kókó abájọ tí ó wémọ́ ti ara tabi àjọṣepọ̀ tí kò lọ déédéé pẹlu awọn mẹ́ḿbà ìdílé, ọ̀rẹ́, tabi òṣìṣẹ́ ẹlẹgbẹ́ ẹni lè wémọ́ ọn. Jobu olùṣòtítọ́ rẹ̀wẹ̀sì tóbẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí ó fi bẹ Ọlọrun pé: “Áà iwọ ìbá fi mí pamọ́ ní ipò-òkú, kí iwọ kí ó fi mí pamọ́ ní ìkọ̀kọ̀, títí ìbínú rẹ̀ yoo fi rékọjá, iwọ ìbá lànà ìgbà kan sílẹ̀ fún mi, kí o sì rántí mí.” Ó dára, bí awọn àyíká-ipò lílekoko bá lè sún Jobu, “ọkùnrin tí í ṣe olóòótọ́, tí ó sì dúró ṣinṣin, ẹni tí ó bẹ̀rù Ọlọrun, tí ó sì kórìíra ìwà búburú,” lati rẹ̀wẹ̀sì gidigidi, kò yanilẹ́nu pé ohun kan-naa lè ṣẹlẹ̀ sí wa.​—⁠Jobu 1:8, 13-⁠19; 2:7-⁠9, 11-⁠13; 14:⁠13.

8. Èéṣe tí ìrẹ̀wẹ̀sì ẹ̀ẹ̀kọ̀ọ̀kan fi lè jẹ́ àmì dídájú pàtó?

8 Ẹ wo bí ó ṣe tuninínú tó lati mọ̀ pé Jehofa ń wo ọkàn-àyà wa kìí sìí gbójúfo awọn ète ìsúnniṣe rere! Oun kì yoo kọ awọn wọnnì tí wọn ń tiraka tọkàntọkàn lati ṣe ohun tí ó wù ú sílẹ̀ láé. Ní tòótọ́, ìrẹ̀wẹ̀sì ẹ̀ẹ̀kọ̀ọ̀kan, lè jẹ́ àmì dídájú pàtó, tí ń fihàn pé a kò fọwọ́ dẹngbẹrẹ mú iṣẹ́-ìsìn wa sí Jehofa. Bí a bá wòye rẹ̀ lati orí kókó yii, ẹnìkan tí kò fìgbàkan jìjàkadì pẹlu ìrẹ̀wẹ̀sì lè má kíyèsí awọn àìlera rẹ̀ nipa tẹ̀mí bíi ti awọn ẹlòmíràn. Rántí: “Ẹni tí ó bá rò pé oun dúró, kí ó kíyèsára, kí ó má ba ṣubú.”​—⁠1 Korinti 10:12; 1 Samueli 16:⁠7; 1 Awọn Ọba 8:39; 1 Kronika 28:⁠9.

Erùpẹ̀ Ni A Fi Dá Awọn Naa

9, 10. (a) Ìgbàgbọ́ ta ni ó dára kí awọn Kristian farawé? (b) Bawo ni Mose ṣe dáhùnpadà sí iṣẹ́ àyànfúnni rẹ̀?

9 Heberu orí 11 ṣe ìtòlẹ́sẹẹsẹ orúkọ ọ̀pọ̀ awọn ẹlẹ́rìí fún Jehofa ṣáájú awọn Kristian tí wọn lo ìgbàgbọ́ lílágbára. Awọn Kristian ọ̀rúndún kìn-⁠ín-ní ati ti òde-òní ti ṣe bákan naa. Awọn ẹ̀kọ́ tí a lè kọ́ lára wọn kò ṣeé díyelé. (Fiwé Heberu 13:7.) Fún àpẹẹrẹ, ìgbàgbọ́ ta ni awọn Kristian lè farawé ju ti Mose lọ? A késí i lati polongo ìhìn-iṣẹ́ ìdájọ́ fún alákòóso lílágbára jùlọ ní àkókò tirẹ̀, Farao ti Egipti. Lónìí, awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa gbọ́dọ̀ kéde irú ìhìn-iṣẹ́ ìdájọ́ kan-naa lòdìsí ìsìn èké ati awọn ètò-àjọ mìíràn tí wọn jẹ́ alátakò sí Ìjọba Kristi tí a ti fìdí rẹ̀ múlẹ̀.​—⁠Ìfihàn 16:​1-⁠15.

10 Gẹ́gẹ́ bí Mose ti fihàn, mímú iṣẹ́-àyànfúnni yii ṣẹ kò rọrùn. Ó béèrè pé, “Ta ni èmi, tí èmi óò fi tọ Farao lọ, ati tí èmi óò fi lè mú awọn ọmọ Israeli jáde lati Egipti wá?” A lè lóye ìmọ̀lára jíjẹ́ àìtóótun rẹ̀. Ó tún ṣàníyàn nipa bí awọn ọmọ Israeli ẹlẹgbẹ́ oun yoo ṣe hùwàpadà: “Wọn kì yoo gbà mí gbọ́, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yoo fetísí ohùn mi.” Nígbà naa ni Jehofa ṣàlàyé fún un bí yoo ṣe fi ẹ̀rí ọlá-àṣẹ tí ó ní hàn, ṣugbọn Mose ní ìṣòro mìíràn. Ó wí pé: “Oluwa, èmi kìí ṣe ẹni ọ̀rọ̀-sísọ nígbà àtijọ́ wá, tabi lati ìgbà tí o ti ń bá ìránṣẹ́ rẹ sọ̀rọ̀: ṣugbọn olóhùn wúwo ni mí.”​—⁠Eksodu 3:11; 4:1, 10.

11. Bawo ni a ṣe lè dáhùnpadà sí awọn ojúṣe wa níti ìṣàkóso Ọlọrun gẹ́gẹ́ bíi ti Mose, ṣugbọn nipa lílo ìgbàgbọ́, kí ni a lè ní ìdánilójú rẹ̀?

11 Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, a lè ní irú ìmọ̀lára tí Mose ní. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a mọ awọn ojúṣe wa níti ìṣàkóso Ọlọrun, a lè máa ṣe kàyéfì pé báwo ni a ṣe lè ṣe wọn. ‘Ta ni mo jẹ́ tí mo fi níláti bá awọn ènìyàn sọ̀rọ̀, awọn kan jẹ́ onípò gíga níti ẹgbẹ́-òun-ọ̀gbà, ọrọ̀-ajé, tabi ipò ẹ̀kọ́, kí n sì rò pé mo lè kọ́ wọn ní ọ̀nà Ọlọrun? Bawo ní awọn arákùnrin mi nipa tẹ̀mí yoo ṣe hùwàpadà nígbà tí mo bá sọ̀rọ̀ ìlóhùnsí ní awọn ìpàdé Kristian tabi tí mo bá gbé ọ̀rọ̀ kalẹ̀ lati orí pèpéle ninu Ilé-Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́-Òjíṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọrun? Wọn kì yoo ha rí awọn àìtóótun mi bí?’ Ṣugbọn rántí pé, Jehofa wà pẹlu Mose ó sì mú un gbaradì fún iṣẹ́-àyànfúnni rẹ̀ nitori pé Mose lo ìgbàgbọ́. (Eksodu 3:12; 4:2-⁠5, 11, 12) Bí a bá ṣàfarawé ìgbàgbọ́ Mose, Jehofa yoo wà pẹlu wa yoo sì mú wa gbaradì fún iṣẹ́ wa pẹlu.

12. Bawo ni ìgbàgbọ́ Dafidi ṣe lè fún wa ní ìṣírí láìka ìrẹ̀wẹ̀sì nitori awọn ẹ̀ṣẹ̀ tabi àìdójú-ìwọ̀n sí?

12 Ẹnikẹ́ni tí ó bá nímọ̀lára ìjákulẹ̀ tabi ìrẹ̀wẹ̀sì nitori ẹ̀ṣẹ̀ tabi àìdójú-ìwọ̀n lè fi pẹlu ìdánilójú gbà pẹlu Dafidi pé: “Nitori tí mo jẹ́wọ́ ìrékọjá mi: nígbà gbogbo ni ẹ̀ṣẹ̀ mi sì ń bẹ níwájú mi.” Ní bíbẹ Jehofa, Dafidi tún sọ pé: “Pa ojú rẹ mọ́ kúrò lára ẹ̀ṣẹ̀ mi, kí ìwọ kí ó sì nu gbogbo àìṣedéédéé mi nù kúrò.” Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, kò gba ìrẹ̀wẹ̀sì láyè láé lati já ìfẹ́-ọkàn rẹ̀ lati sin Jehofa gbà. “Máṣe ṣá mi tì kúrò níwájú rẹ; kí o má sì ṣe gba Ẹ̀mí mímọ́ rẹ lọ́wọ́ mi.” Ó ṣe kedere pé “erùpẹ̀” ni Dafidi, ṣugbọn Jehofa kò fi í sílẹ̀, nitori pé Dafidi lo ìgbàgbọ́ ninu ìlérí Jehofa lati máṣe gan “ìròbìnújẹ́ ati ìrora àyà.”​—⁠Orin Dafidi 38:1-⁠9; 51:3, 9, 11, 17.

13, 14. (a) Èéṣe tí a kò fi níláti di ọmọlẹ́yìn ènìyàn? (b) Bawo ni àpẹẹrẹ Paulu ati Peteru ṣe fihàn pé awọn pàápàá jẹ́ erùpẹ̀?

13 Ṣugbọn, ṣàkíyèsí pé, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a níláti wo “àwọ̀sánmà tí ó kún tó bayii fún awọn ẹlẹ́rìí” gẹ́gẹ́ bí ìṣírí lati “fi sùúrù súré ìje tí a gbé ka iwájú wa,” a kò sọ fún wa pé kí a di ọmọlẹ́yìn wọn. A sọ fún wa lati tẹ̀lé ipasẹ̀ “Jesu olùpilẹ̀ṣẹ̀ ati aláṣepé ìgbàgbọ́ wa,” kìí ṣe ti awọn ẹ̀dá ènìyàn aláìpé​—⁠àní kìí tilẹ̀ ṣe awọn aposteli olùṣòtítọ́ ti ọ̀rúndún kìn-⁠ín-ní.⁠—​Heberu 12:1, 2; 1 Peteru 2:⁠21.

14 Aposteli Paulu ati Peteru, awọn ọwọ̀n ninu ìjọ Kristian, kọsẹ̀ nígbà mìíràn. Paulu kọ̀wé pé, “Nitori ire tí èmi fẹ́ èmi kò ṣe: ṣugbọn búburú tí èmi kò fẹ́, èyíinì ni èmi ń ṣe. . . . Èmi ẹni òṣì!” (Romu 7:​19, 24) Peteru pẹlu ní àkókò kan tí ó dá ara rẹ̀ lójú jù sọ fún Jesu pé: “Bí gbogbo ènìyàn tilẹ̀ kọsẹ̀ lára rẹ, èmi kì yoo kọsẹ̀ láé.” Nígbà tí Jesu kìlọ̀ fún Peteru pé yoo sẹ́ Oun ní ìgbà mẹ́ta, Peteru fi pẹlu ìkùgbùù tako Ọ̀gá rẹ̀, ní fífọ́nnu pé: “Bí ó tilẹ̀ di ati bá ọ kú, èmi kò jẹ́ sẹ́ ọ.” Síbẹ̀ ó sẹ́ Jesu, àṣìṣe kan tí ó mú kí ó sọkún kíkorò. Bẹ́ẹ̀ni, erùpẹ̀ ní Paulu ati Peteru.​—⁠Matteu 26:​33-⁠35.

15. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé erùpẹ̀ ni wá, awọn ìṣírí wo ni a ní tí ó lè mú kí a tẹ̀síwájú?

15 Síbẹ̀síbẹ̀, láìka awọn àlèébù wọn sí, Mose, Dafidi, Paulu, Peteru, ati awọn mìíràn bíi tiwọn jagunmólú. Èéṣe? Nitori pé wọn lo ìgbàgbọ́ lílágbára ninu Jehofa, wọn gbẹ́kẹ̀lé e pátápátá, wọn sì rọ̀ mọ́ ọn láìka awọn ìfàsẹ́yìn sí. Wọn gbáralé e lati pèsè “agbára tí ó rékọjá ìwọ̀n ti ẹ̀dá.” Ó sì ṣe bẹ́ẹ̀, láì jẹ́ kí wọn ṣubú rékọjá àtilè kọ́fẹpadà. Bí a bá ń báa nìṣó ní lílo ìgbàgbọ́, awa lè ní ìdánilójú pé nígbà tí a bá gbé ọ̀ràn tiwa yẹ̀wò, yoo wà ní ìbámu pẹlu awọn ọ̀rọ̀ naa pé: “Ọlọrun kìí ṣe aláìṣòdodo tí yoo fi gbàgbé iṣẹ́ yín ati ìfẹ́ tí ẹ̀yin fihàn sí orúkọ rẹ̀.” Ẹ wo irú ìṣírí tí èyí fún wa lati máa tẹ̀síwájú láìka òtítọ́ naa sí pé a jẹ́ erùpẹ̀!​—⁠2 Korinti 4:⁠7, NW; Heberu 6:⁠10.

Kí Ni Jíjẹ́ Erùpẹ̀ Túmọ̀sí fún Wa Lẹ́nìkọ̀ọ̀kan?

16, 17. Nígbà tí ó bá di ọ̀ràn ìdájọ́, bawo ní Jehofa ṣe ń lo ìlànà tí a ṣàlàyé ninu Galatia 6:⁠4?

16 Ìrírí ti kọ́ ọ̀pọ̀ òbí ati olùkọ́ ní ọgbọ́n tí ó wà ninu ṣíṣèdájọ́ awọn ọmọ tabi akẹ́kọ̀ọ́ ní ìbámu pẹlu agbára ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn, kìí ṣe ní ìbámu pẹlu ẹ̀gbọ́n tabi àbúrò tabi ọmọ ilé-ẹ̀kọ́ ẹlẹgbẹ́ wọn. Èyí wà ní ìbámu pẹlu ìlànà Bibeli tí a ti sọ fún awọn Kristian lati tẹ̀lé: “Kí olúkúlùkù kí ó yẹ iṣẹ́ ara rẹ̀ wò, nígbà naa ni yoo sì ní ohun ìṣògo nipa ti ara rẹ̀ nìkan, kì yoo sì ṣe nipa ti ọmọnìkejì rẹ̀.”​—⁠Galatia 6:⁠4.

17 Ní ìbámu pẹlu ìlànà yii, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Jehofa ń bá awọn ènìyàn rẹ̀ lò gẹ́gẹ́ bí àwùjọ kan tí a ṣètòjọ, ó ń ṣèdájọ́ wọn lẹ́nìkọ̀ọ̀kan. Romu 14:12 sọ pé: “Olúkúlùkù wa ni yoo jíhìn araarẹ̀ fún Ọlọrun.” Jehofa mọ ohun tí ó parapọ̀ jẹ́ apilẹ̀ àbùdá awọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lẹ́nìkọ̀ọ̀kan dáradára. Ó mọ bí wọn ṣe rí níti ara-ìyára ati ti ọpọlọ, agbára wọn, okun ati àìlera àjogúnbá wọn, ibi tí agbára wọn mọ, ati ìwọ̀n àyè tí wọn ń lo agbára yii dé lati mú ìṣùpọ̀-èso Kristian jáde. Jesu ṣàlàyé nipa obìnrin opó naa tí ó ju owó idẹ wẹ́wẹ́ méjì sínú àpótí ìṣúra tẹmpili bẹ́ẹ̀ sì ni òwe àkàwé rẹ̀ nipa irúgbìn tí a fún sórí ilẹ̀ rere jẹ́ àpẹẹrẹ ìṣírí fún awọn Kristian tí wọn lè nímọ̀lára ìsoríkọ́ nitori fífi araawọn wéra pẹlu awọn mìíràn lọ́nà tí kò mọ́gbọ́ndání.​—⁠Marku 4:20; 12:​42-⁠44.

18. (a) Èéṣe tí a fi níláti pinnu ohun tí jíjẹ́ erùpẹ̀ túmọ̀sí fún ẹnìkọ̀ọ̀kan wa? (b) Èéṣe tí àyẹ̀wò ara-ẹni tí a ṣe tọkàntọkàn kò fi gbọ́dọ̀ mú wa sọ̀rètínù?

18 Ó ṣe kókó pé kí a pinnu ohun tí jíjẹ́ erùpẹ̀ túmọ̀sí ninu ọ̀ràn ẹnìkọ̀ọ̀kan wa kí a baà lè ṣiṣẹ́sìn dé gbogbo ibi tí a bá lè lo agbára wa dé. (Owe 10:⁠4; 12:24; 18:⁠9; Romu 12:⁠1) Kìkì nipa wíwà lójúfò gidigidi sí awọn àlèébù ati àìlera tiwa fúnraawa ní a fi lè wà lójúfò ṣámúṣámú sí àìní naa ati agbára wa lati lè sunwọ̀n síi. Ní ṣíṣe àyẹ̀wò ara-ẹni, ẹ máṣe jẹ́ kí a gbójúfo agbára tí ẹ̀mí mímọ́ ní lati ṣèrànwọ́ fún wa lati sunwọ̀n síi. Nípasẹ̀ rẹ̀, ni a fi dá àgbáyé, tí a kọ Bibeli, pẹ̀lúpẹ̀lù, ní àárín ayé kan tí ń kú lọ, a ti mú ẹgbẹ́ ayé titun alálàáfíà kan wá sí ojútáyé. Nitori naa ó dájú pé ẹ̀mí mímọ́ Ọlọrun ní agbára tó lati fún awọn wọnnì tí ń béèrè fún un ní ọgbọ́n ati okun tí wọn nílò lati pa ìwàtítọ́ mọ́.​—⁠Mika 3:⁠8; Romu 15:13; Efesu 3:⁠16.

19. Kí ni jíjẹ́ tí a jẹ́ erùpẹ̀ kìí ṣe àwáwí fún?

19 Ẹ wo bí ó ti tuninínú tó lati mọ̀ pé Jehofa rántí pé erùpẹ̀ ni wá! Síbẹ̀síbẹ̀, a kò níláti ronú láé pé èyí jẹ́ ìdí bíbófinmu lati dẹwọ́ tabi bóyá fún ṣíṣe ohun tí kò tọ́. Àgbẹdọ̀! Pé Jehofa rántí pé erùpẹ̀ ni wá jẹ́ ìfihàn inúrere àìlẹ́tọ̀ọ́sí rẹ̀. Ṣugbọn awa kò fẹ́ lati jẹ́ “aláìṣèfẹ́ Ọlọrun, tí . . . ń sọ inúrere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọrun wa di àwáwí fún ìwà àìníjàánu tí wọ́n sì jásí èké sí Ẹni kanṣoṣo naa tí ó ni wá tí ó sì jẹ́ Oluwa wa, Jesu Kristi.” (Juda 4, NW) Pé a jẹ́ erùpẹ̀ kìí ṣe àwáwí fún jíjẹ́ aláìṣèfẹ́ Ọlọrun. Kristian kan ń tiraka lati gbéjàko awọn ìsúnniṣe òdì lati dẹ́ṣẹ̀, ní pípọ́n araarẹ̀ lójú tí ó sì ń mú un wá sábẹ́ ìtẹríba, lati lè yẹra fún ‘mímú Ẹ̀mí Mímọ́ Ọlọrun bínú.’​—⁠Efesu 4:30; 1 Korinti 9:⁠27.

20. (a) Ní awọn apá ìhà méjì wo ni a fi ní ‘pupọ lati ṣe ninu iṣẹ́ Oluwa’? (b) Èéṣe tí a fi ní ìdí fún ìfojúsọ́nà fún rere?

20 Nísinsìnyí, nígbà tí awọn ọdún ètò-ìgbékalẹ̀ ayé Satani ń lọ sópin, kìí ṣe àkókò lati dẹ̀rìn​—⁠kò gbọdọ̀ rí bẹ́ẹ̀ níti ọ̀ràn ìwàásù Ìjọba bẹ́ẹ̀ ni kò sì gbọdọ̀ rí bẹ́ẹ̀ níti ọ̀ràn mímú awọn ìṣùpọ̀-èso ẹ̀mí Ọlọrun dàgbà ní kíkún síi. Ninu awọn apá méjèèjì a ní ‘pupọ lati ṣe.’ Ìsinsìnyí ni àkókò naa lati tẹ̀síwájú nitori a mọ̀ pé “iṣẹ́” wa “kìí ṣe asán ninu Oluwa.” (1 Korinti 15:58) Jehofa yoo mú wa dúró, nitori tí Dafidi sọ nipa rẹ̀ pé: “Oun kì yoo jẹ́ kí ẹsẹ̀ olódodo kí ó yẹ̀ láé.” (Orin Dafidi 55:22) Ẹ wo bí ó ti jẹ́ ohun ayọ̀ pé Jehofa ń fàyègbà wá lẹ́nìkọ̀ọ̀kan lati nípìn ín ninu iṣẹ́ títóbilọ́lá jùlọ tí a tíì yàn fún awọn ẹ̀dá ènìyàn aláìpé lati ṣe rí​—⁠èyí sì jẹ́ lójú òtítọ́ naa pé erùpẹ̀ ni wá!

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Ìwé àlàyé-ọ̀rọ̀ Bibeli Herders Bibelkommentar, nígbà tí ó ń ṣàlàyé Orin Dafidi 103:⁠14, sọ pé: “Ó mọ̀ dájú pé oun dá ẹ̀dá ènìyàn lati inú erùpẹ̀ ilẹ̀, ó sì mọ awọn àìlera ati ìgbésí-ayé aláìdúrópẹ́ wọn lọ́nà ti ẹ̀dá, èyí tí ó ti ní ipa-ìdarí lílágbára lórí wọn lati ìgbà ẹ̀ṣẹ̀ ìpilẹ̀ṣẹ̀.”​—⁠Ìkọ̀wé wínníwínní jẹ́ tiwa.

Iwọ Ha Le Ṣàlàyé Bí?

◻ Bawo ni Genesisi 2:7 ati Orin Dafidi 103:14 ṣe yàtọ̀ síra ní títọ́ka sí i pé a dá awọn ènìyàn lati inú erùpẹ̀?

◻ Èéṣe tí Heberu orí 11 fi jẹ́ orísun ìṣírí fún awọn Kristian lónìí?

◻ Èéṣe tí ó fi bọ́gbọ́nmu fún wa lati lo ìlànà tí a làsílẹ̀ ninu Galatia 6:⁠4?

◻ Bawo ni Heberu 6:10 ati 1 Korinti 15:58 ṣe ṣèrànwọ́ fún wa lati máṣe fàyè sílẹ̀ fún ìrẹ̀wẹ̀sì?

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]

Awọn Kristian ń ṣàfarawé ìgbàgbọ́ awọn olùjọsìn ẹlẹgbẹ́ wọn, ṣugbọn wọn ń tẹ̀lé Aláṣepé ìgbàgbọ́ wọn, Jesu

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́