Kí La Lè Ṣe Nípa Ìrẹ̀wẹ̀sì?
BÁWO la ṣe lè borí ìrẹ̀wẹ̀sì? Ìbéèrè táa sábà ń bi ọ̀pọ̀ àwọn alábòójútó arìnrìn-àjò, tó ń bẹ ìjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà wò nìyí. Ìdáhùn wọn lè jẹ́ ká rídìí ohun tí ń fa ìrẹ̀wẹ̀sì, a ó sì lè mọ ojútùú tó wà fún ipò yìí, ipò kan tó jẹ́ pé kò sí Kristẹni tí kò lè ṣẹlẹ̀ sí.
Mímọ ohun tí ń fa ìrẹ̀wẹ̀sì nìkan kò tó láti lè borí rẹ̀, ṣùgbọ́n díẹ̀ lára àwọn àmì rẹ̀ ni, àìkìífẹ́-gbàdúrà tàbí àìkìífẹ́-dákẹ́kọ̀ọ́, pípa ìpàdé jẹ, àìnítara, àti ṣíṣe bí ẹni fà sẹ́yìn fún àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ ẹni. Ọ̀kan lára àmì tó ń jẹ́ ká tètè mọ̀ gan-an ni kí ìtara èèyàn bẹ̀rẹ̀ sí dín kù fún iṣẹ́ ajíhìnrere. Ẹ jẹ́ a ṣàyẹ̀wò àwọn àmì ọ̀hún, lẹ́yìn náà, ká wá wá ojútùú sí i.
Ìrẹ̀wẹ̀sì Nínú Iṣẹ́ Ajíhìnrere Wa
Jésù Kristi mọ ìṣòro tó wé mọ́ pípa àṣẹ náà mọ́ pé kí a sọni di ọmọ ẹ̀yìn. (Mátíù 28:19, 20) Ó rán àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ jáde gẹ́gẹ́ bí “àgùntàn sáàárín àwọn ìkookò,” ó mọ̀ pé iṣẹ́ ìwàásù tí wọ́n ń ṣe yóò fa inúnibíni. (Mátíù 10:16-23) Síbẹ̀, èyí ò tó ohun tó lè fa ìrẹ̀wẹ̀sì. Ká sòótọ́, ńṣe ni inúnibíni máa ń fún àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run tí wọ́n ti gbára lé Jèhófà nípasẹ̀ àdúrà ní okun.—Ìṣe 4:29-31; 5:41, 42.
Kódà nígbà tí a kò fi bẹ́ẹ̀ ṣe inúnibíni gbígbóná janjan sáwọn ọmọlẹ́yìn Kristi pàápàá, ìgbà gbogbo kọ́ là ń gbà wọ́n láyè láti wàásù. (Mátíù 10:11-15) Bákan náà, iṣẹ́ ìwàásù àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í fìgbà gbogbo rọrùn lónìí.a Lójú ọ̀pọ̀ ènìyàn, ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run jẹ́ ọ̀ràn ara ẹni tí wọn kì í fẹ́ jíròrò pẹ̀lú ẹlòmíràn. Àwọn ẹlòmíì kì í fẹ́ gbọ́ ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn tí wọ́n bá lẹ́tanú sí. Ó dájú pé, ìdágunlá, àìmésojáde, tàbí onírúurú ìṣòro mìíràn lè jẹ́ orísun ìrẹ̀wẹ̀sì tó ń páni láyà. Báwo la ṣe lè borí àwọn ìṣòro wọ̀nyí?
Mímú Èso Tó Dára Ju ti Àtẹ̀yìnwá Jáde
Lọ́nà kan, ayọ̀ tí a máa ń rí nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa ní í ṣe pẹ̀lú èso tí ó ń tibẹ̀ jáde. Nígbà náà, báwo ni iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa ṣe lè túbọ̀ méso jáde? Ó dáa, “apẹja ènìyàn” ni wá. (Máàkù 1:16-18) Ní Ísírẹ́lì láyé ọjọ́un, òru làwọn apẹja máa ń pẹja kí wọ́n bàa lè rí ẹja tó pọ̀ pa. Àwa pẹ̀lú ní láti yẹ ìpínlẹ̀ wa wò dáadáa, kí a bàa lè lọ ‘pẹja’ nígbà tí àwọn èèyàn tó pọ̀ jù lọ bá wà nílé, tí wọ́n á sì fetí sí iṣẹ́ wa. Èyí lè jẹ́ ní ọwọ́ ìrọ̀lẹ́, ó lè jẹ́ òpin ọ̀sẹ̀, tàbí láwọn ìgbà mìíràn. Gẹ́gẹ́ bí alábòójútó arìnrìn-àjò kan ti sọ, èyí máa ń ṣiṣẹ́ níbi tí àwọn ènìyàn ti ń ṣiṣẹ́ láti àárọ̀ ṣúlẹ̀. Ó ṣàkíyèsí pé ìjẹ́rìí ìrọ̀lẹ́ máa ń méso tó dára jáde. Jíjẹ́rìí nípasẹ̀ tẹlifóònù tàbí lọ́nà tí kì í ṣe bí àṣà tún lè jẹ́ ká dé ọ̀dọ̀ ọ̀pọ̀ ènìyàn.
Níní ìfaradà nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ máa ń mú èso tó dára jáde. Ní Ìlà Oòrùn Yúróòpù àti ní àwọn orílẹ̀-èdè ilẹ̀ Áfíríkà kan, iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba náà ń tẹ̀ síwájú dáadáa, èyí sì ti yọrí sí ìbísí ńlá. Bákan náà, ọ̀pọ̀ ìjọ la ti dá sílẹ̀ láwọn àgbègbè táa ti gbà pé kò lè méso jáde tipẹ́tipẹ́ tàbí ní ìpínlẹ̀ táa ń kárí lóòrèkóòrè pàápàá. Ṣùgbọ́n, tí àgbègbè tìrẹ bá jẹ́ èyí tí kì í mú irú èsò bẹ́ẹ̀ jáde ńkọ́?
Níní Ẹ̀mí Tó Dáa
Táa bá ní góńgó tí Jésù gbé kalẹ̀ lọ́kàn yóò ràn wá lọ́wọ́ láti má ṣe rẹ̀wẹ̀sì nígbà táwọn èèyàn bá dágunlá sí iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa. Kristi fẹ́ káwọn ọmọ ẹ̀yìn òun wá àwọn ẹni yíyẹ kàn, kì í ṣe ìyílọ́kànpadà ti irúwá-ògìrìwá. Ọ̀pọ̀ ìgbà ló sọ pé àwọn tó pọ̀ jù lọ ni kò ní gba ìhìn rere náà, gẹ́gẹ́ bí àwọn tó pọ̀ jù lọ lára àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kò ti tẹ́tí sí àwọn wòlíì ìgbàanì.—Ìsíkíẹ́lì 9:4; Mátíù 10:11-15; Máàkù 4:14-20.
Àwọn tí “àìní wọn nípa ti ẹ̀mí ń jẹ lọ́kàn” ni wọ́n ń tẹ́wọ́ gba “ìhìn rere ìjọba yìí.” (Mátíù 5:3; 24:14) Wọ́n fẹ́ sin Ọlọ́run lọ́nà tó fẹ́. Nítorí náà, ìyọrísí ìgbòkègbodò wa ní í ṣe pẹ̀lú ọkàn-àyà àwọn ènìyàn ju ọ̀nà tí a gbà ń gbé ìhìn iṣẹ́ náà kalẹ̀. Àmọ́ ṣá o, a ní láti ṣe gbogbo ohun tí a lè ṣe láti mú kí ìhìn rere náà fani mọ́ra. Síbẹ̀, ọwọ́ Ọlọ́run ni àbájáde rẹ̀ wà, nítorí Jésù wí pé: “Kò sí ènìyàn kankan tí ó lè wá sọ́dọ̀ mi láìjẹ́ pé Baba, tí ó rán mi, fà á.”—Jòhánù 6:44.
Iṣẹ́ ajíhìnrere wa ń jẹ́ káwọn èèyàn mọ orúkọ Jèhófà. Yálà àwọn ènìyàn gbọ́ tàbí wọn kò gbọ́, ìgbòkègbodò ìwàásù wa ń fi kún ìyàsímímọ́ orúkọ mímọ́ tí Jèhófà ní. Láfikún sí i, nípasẹ̀ iṣẹ́ ajíhìnrere wa, a ń fi hàn pé ọmọ ẹ̀yìn Kristi ni wá, a sì ní àǹfààní láti lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ tó ṣe pàtàkì jù lọ tó ń lọ lọ́wọ́ lọ́jọ́ wa lónìí.—Mátíù 6:9; Jòhánù 15:8.
Ìrẹ̀wẹ̀sì àti Àjọse Wa Pẹ̀lú Àwọn Ẹlòmíràn
Àwọn àjọṣe kan láàárín ènìyàn, yálà nínú ìdílé tàbí nínú ìjọ, lè fa ìrẹ̀wẹ̀sì. Fún àpẹẹrẹ, tí ẹnì kan bá rò pé àwọn èèyàn ò lóye irú ẹni tí òun jẹ́. Àìpé àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wa pẹ̀lú lè mú wa rẹ̀wẹ̀sì. Lẹ́ẹ̀kan sí i, Ìwé Mímọ́ lè ràn wá lọ́wọ́ gidigidi.
Ìdílé ńlá nípa tẹ̀mí ni “gbogbo ẹgbẹ́ àwọn ará” yíká ayé jẹ́. (1 Pétérù 2:17) Ṣùgbọ́n ìmọ̀lára pé èèyàn jẹ́ apá kan ìjọ tó wà níṣọ̀kan lè pòórá nígbà tí ìṣòro bá dé nítorí èdè àìyedè. Ó hàn gbangba pé, àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní ní irú ìṣòro bẹ́ẹ̀, ìdí ni pé àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù rán wọn létí léraléra láti máa gbé papọ̀ ní ìṣọ̀kan. Fún àpẹẹrẹ, ó rọ àwọn Kristẹni obìnrin méjì nì—Yúódíà àti Síńtíkè—pé kí wọ́n yanjú aáwọ̀ tó wà láàárín wọn.—1 Kọ́ríńtì 1:10; Éfésù 4:1-3; Fílípì 4:2, 3.
Bó bá jẹ́ ìṣòro táa ní nìyí, báwo la ṣe lè mú kí iná ìfẹ́ àtọkànwá táa ní fún àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa máa jó sí i? Nípa rírán ara wa létí pé Kristi kú fún wọn àti pé bí a ṣe ń lo ìgbàgbọ́ nínú ẹbọ ìràpadà rẹ̀ làwọn náà ṣe ń lò ó. Ẹ jẹ́ a tún rántí pé ọ̀pọ̀ arákùnrin wa ló múra tán láti fara wé Jésù Kristi nípa fífi ẹ̀mí wọn wewu nítorí tiwa.
Lọ́dún díẹ̀ sẹ́yìn, ní Paris, ní ilẹ̀ Faransé, ṣe ni ọ̀dọ́ Ẹlẹ́rìí kan yára gbé àpò kan tí bọ́ǹbù wà nínú rẹ̀, tí ẹnì kan gbé síta Gbọ̀ngàn Ìjọba. Bó ṣe gbé e, ló feré gé e, ó sáré sọ̀ kalẹ̀ lórí ọ̀pọ̀ àtẹ̀gùn kó tó jù ú sínú odò kan, níbi tí bọ́ǹbù náà ti dún. Nígbà táa béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ ohun tó sún un láti fi ẹ̀mí rẹ̀ wewu tó bẹ́ẹ̀, ó fèsì pé: “Mo rí i pé ẹ̀mí wa wà nínú ewu. Nítorí náà, mo wá rò ó pé ó sàn kí èmi nìkan kú ju kí gbogbo wa kú.”b Ẹ wo irú ìbùkún ńlá tó jẹ́ láti ní irú alábàákẹ́gbẹ́ bẹ́ẹ̀ tó ṣe tán láti tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù tímọ́tímọ́!
Ní àfikún sí i, a lè ronú jinlẹ̀ lórí ẹ̀mí ìfọwọ́sowọ́pọ̀ tó wà láàárín àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ nígbà Ogun Àgbáyé Kejì.c Láìpẹ́ yìí, àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa tó wà ní Màláwì fi ìṣòtítọ́ di ìgbàgbọ́ wọn mú ṣinṣin gẹ́gẹ́ bí Kristẹni tòótọ́. Ǹjẹ́ èrò náà pé tíṣòro bá dé, bẹ́ẹ̀ làwọn ará tó wà nínú ìjọ àdúgbò wa yóò ṣe kò yẹ kó sún wa láti gbójú fo èdè àìyedè tàbí àìgbọra-ẹni-yé tó lè wáyé lójoojúmọ́ tàbí ó kéré tán, kó dín in kù? Báa bá ní ẹ̀mí Kristi, àjọṣe wa lójoojúmọ́ pẹ̀lú àwọn olùjọsìn ẹlẹgbẹ́ wa yóò jẹ́ orísun ìtura fún wa, kò ní máa kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá wa.
Ìrònú Tí Ń Kó Ìrẹ̀wẹ̀sì Báni
“Ìfojúsọ́nà tí a sún síwájú ń mú ọkàn-àyà ṣàìsàn, ṣùgbọ́n igi ìyè ni ohun tí a fọkàn fẹ́ nígbà tí ó bá dé ní ti tòótọ́.” (Òwe 13:12) Lójú àwọn kan tí wọ́n jẹ́ ìránṣẹ́ Jèhófà, òpin ètò àwọn nǹkan ìsinsìnyí ti ń pẹ́ jù. Gẹ́gẹ́ bí àkókò tí à ń gbé yìí, ‘ti le koko jù, tí ó sì nira láti bá lò,’ fún ọ̀pọ̀ àwọn aláìgbàgbọ́, bẹ́ẹ̀ náà ló rí fún àwọn Kristẹni pẹ̀lú.—2 Tímótì 3:1-5.
Ṣùgbọ́n, yàtọ̀ sí ohun tí àwọn aláìgbàgbọ́ kan ń sọ, ó yẹ kí àwọn Kristẹni máa yọ̀ pé àwọn fojú rí “àmì” wíwàníhìn-ín Jésù, èyí tó hàn nínú ipò lílekoko ti òde òní, èyí sì ń fi hàn pé láìpẹ́ Ìjọba Ọlọ́run yóò mú òpin dé bá ètò àwọn nǹkan búburú yìí. (Mátíù 24:3-14) Kódà nígbà tí ipò náà bá ń burú sí i—ó sì dájú pé yóò burú sí i nígbà “ìpọ́njú ńlá”—ó yẹ kí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ wọ̀nyí jẹ́ orísun ayọ̀ fún wa nítorí pé wọ́n ń pòkìkí pé ayé tuntun Ọlọ́run ń bọ̀.—Mátíù 24:21; 2 Pétérù 3:13.
Bí Kristẹni kan bá ń rò pé àkókò tí Ìjọba náà yóò dá sí ọ̀ràn tó ń lọ lọ́wọ́ lónìí kò tí ì tó, èyí lè mú kí irú ẹni bẹ́ẹ̀ máa ya àkókò púpọ̀ sí i sọ́tọ̀ fún lílépa ọrọ̀ àlùmọ́nì. Bó bá lọ jẹ́ kí iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ àti eré ìnàjú gba àkókò àti agbára òun, yóò ṣòro fún un gan-an láti ṣojúṣe rẹ̀ dáadáa nípa ohun tí Ìwé Mímọ́ là sílẹ̀ fún un. (Mátíù 6:24, 33, 34) Irú ẹ̀mí bẹ́ẹ̀ máa ń fayé súni, ó sì ń múni rẹ̀wẹ̀sì. Alábòójútó arìnrìn-àjò kan sọ pé: “Àlá tí kò lè ṣẹ ni, téèyàn bá rò pé òun lè gbé ètò tuntun kalẹ̀ nínú ètò àwọn nǹkan ìsinsìnyí.”
Méjì Nínú Àwọn Ojútùú Tó Gbéṣẹ́ Jú Lọ
Gbàrà tí a bá ti ṣàyẹ̀wò ara wa, báwo wá ni ẹnì kan ṣe lè rí ojútùú tó gbéṣẹ́? Ìdákẹ́kọ̀ọ́ ni ọ̀kan lára ọ̀nà tó gbéṣẹ́ jù lọ. Èé ṣe? Alábòójútó arìnrìn-àjò kan sọ pé: “Ó ń rán wa létí pé a ṣáà ní láti máa ṣe ohun tó yẹ ká ṣe.” Òmíràn tún ṣàlàyé pé: “Táa bá ń wàásù bí ẹni pé a ń fipá mú wa ṣe é, tó bá yá, ìyẹn á jẹ́ kí iṣẹ́ náà di ohun tó nira.” Ṣùgbọ́n ìdákẹ́kọ̀ọ́ tó gbéṣẹ́ máa ń ràn wá lọ́wọ́ láti ní ojú ìwòye tó ṣe pàtó nípa ojúṣe wa bí a ti ń sún mọ́ òpin. Lọ́nà kan náà, léraléra ni Ìwé Mímọ́ ń rán wa létí ìjẹ́pàtàkì jíjẹ oúnjẹ tẹ̀mí dáadáa láti lè ní ayọ̀ tòótọ́ nínú ṣíṣe ìfẹ́ Ọlọ́run.—Sáàmù 1:1-3; 19:7-10; 119:1, 2.
Àwọn alàgbà lè ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ láti borí ìrẹ̀wẹ̀sì nípa ṣíṣèbẹ̀wò olùṣọ́ àgùntàn tó ń fúnni níṣìírí sọ́dọ̀ wọn. Ní àwọn àkókò tí wọ́n bá ṣèbẹ̀wò abẹ́lé yìí, àwọn alàgbà lè jẹ́ ká mọ̀ pé àwọn mọrírì ipa tí olúkúlùkù wa ń kó àti pé olúkúlùkù wa ló ní àyè pàtàkì kan láàárín àwọn ènìyàn Jèhófà. (1 Kọ́ríńtì 12:20-26) Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ rẹ̀, alàgbà kan wí pé: “Kí wọ́n lè mọ̀ bí wọ́n ti ṣe pàtàkì tó, mo máa ń rán wọn létí àṣeyọrí tí wọ́n ti ṣe sẹ́yìn. Mo máa ń jẹ́ kó yé wọn pé wọ́n ṣeyebíye lójú Jèhófà àti pé tìtorí wọn la ṣe ta ẹ̀jẹ̀ Ọmọ rẹ̀ sílẹ̀. Gbogbo ìgbà ni èrò yìí máa ń dùn mọ́ wọn. Gbàrà tí a bá ti fi ẹsẹ Bíbélì tì í lẹ́yìn, àwọn tó ti rẹ̀wẹ̀sì máa ń wà ní ipò láti gbé góńgó tuntun kalẹ̀, irú bí àdúrà ìdílé, ìkẹ́kọ̀ọ́ àti Bíbélì kíkà.”—Hébérù 6:10.
Nígbà ìbẹ̀wò olùṣọ́ àgùntàn, àwọn alàgbà gbọ́dọ̀ ṣọ́ra kí wọ́n má lọ jẹ́ káwọn èèyàn máa rò pé Ọlọ́run kò ṣeé tẹ́ lọ́rùn. Kàkà bẹ́ẹ̀, àwọn alàgbà lè ṣèrànwọ́ láti jẹ́ kí àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wọn lóye pé ẹrù àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù fúyẹ́ gan-an. Ní àbárèbábọ̀, wọ́n a wá rí i pé iṣẹ́ ìsìn Kristẹni wa, iṣẹ́ tí ń máyọ̀ wá ni.—Mátíù 11:28-30.
Lílé Ìrẹ̀wẹ̀sì Lọ
Ohun yòówù kó fà á, ìrẹ̀wẹ̀sì jẹ́ àrùn burúkú táa gbọ́dọ̀ gbógun tì. Àmọ́, rántí pé àwa nìkan kọ́ la ó ja ìjà náà. Báa bá rẹ̀wẹ̀sì, ẹ jẹ́ a gba ìrànwọ́ láti ọ̀dọ̀ àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ wa, pàápàá jù lọ àwọn alàgbà. Nípa ṣíṣe bẹ́ẹ̀, a óò lè dín ìrẹ̀wẹ̀sì náà kù.
Ju gbogbo rẹ̀ lọ, ó ṣe pàtàkì pé ká yíjú sí Ọlọ́run fún ìrànwọ́, ká bàa lè borí ìrẹ̀wẹ̀sì. Báa bá fi tàdúràtàdúrà gbára lé Jèhófà, yóò lè ràn wá lọ́wọ́ láti lé ìrẹ̀wẹ̀sì lọ pátápátá. (Sáàmù 55:22; Fílípì 4:6, 7) Bó ti wù kó rí, gẹ́gẹ́ bí ènìyàn rẹ̀, a lè ní irú èrò tí onísáàmù náà ní, nígbà tó kọ ọ́ lórin pé: “Aláyọ̀ ni àwọn ènìyàn tí ó mọ igbe ìdùnnú. Jèhófà, inú ìmọ́lẹ̀ ojú rẹ ni wọ́n ti ń rìn. Wọ́n ń kún fún ìdùnnú láti òwúrọ̀ ṣúlẹ̀ ní orúkọ rẹ, a sì gbé wọn ga nínú òdodo rẹ. Nítorí pé ìwọ ni ẹwà okun wọn; nípa ìfẹ́ rere rẹ ni a sì fi gbé ìwo wa ga.”—Sáàmù 89:15-17.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Wo àpilẹ̀kọ náà “Ipenija Ile-de-Ile” nínú Ile-Iṣọ Naa, November 15, 1981.
b Wo ojú ìwé 12 àti 13 Jí! July 22, 1986, tí Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., tẹ̀ jáde.
c Wo àpilẹ̀kọ náà “Mo La ‘Irin-ajo sinu Iku’ Já” nínú Ile-Iṣọ Naa ti February 15, 1981, àti “Pípa Ìwàtítọ́ Mọ́ Nígbà Ìjọba Násì ní Jámánì” nínú Jí! ti June 22, 1985 (Gẹ̀ẹ́sì).
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]
Ìbẹ̀wò olùṣọ́ àgùntàn tí ń gbéni ró tí àwọn alàgbà onífẹ̀ẹ́ bá ṣe lè ran àwọn Kristẹni lọ́wọ́ láti borí ìrẹ̀wẹ̀sì