ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w95 11/15 ojú ìwé 24-25
  • Iná Wọn Kò Kú

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Iná Wọn Kò Kú
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ẹ Jẹ́ Onígboyà Bíi Jeremáyà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
  • “Ọkàn tí Àárẹ̀ Mú Ni Èmi Yóò Tẹ́ Lọ́rùn ní Kíkún”
    Ọ̀rọ̀ Tí Ọlọ́run Bá Wa Sọ Nípasẹ̀ Jeremáyà
  • “Mo Ti Fi Ọ̀rọ̀ Mi sí Ẹnu Rẹ”
    Ọ̀rọ̀ Tí Ọlọ́run Bá Wa Sọ Nípasẹ̀ Jeremáyà
  • Ǹjẹ́ O Máa Ń Béèrè Lójoojúmọ́ Pé, “Jèhófà Dà?”
    Ọ̀rọ̀ Tí Ọlọ́run Bá Wa Sọ Nípasẹ̀ Jeremáyà
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
w95 11/15 ojú ìwé 24-25

Iná Wọn Kò Kú

NÍ ÀKÓKÒ Bibeli, àwọn olùṣòtítọ́ Ẹlẹ́rìí fún Jehofa wà tí wọ́n nírìírí ìfàsẹ́yìn àti ìṣòro. Wọ́n dojú kọ àtakò àti ìjákulẹ̀ híhàn gbangba. Síbẹ̀, wọn kò torí ìrẹ̀wẹ̀sì juwọ́ sílẹ̀. Ní ti gidi, iná wọn kò kú.

Fún àpẹẹrẹ, a fún wòlíì Jeremiah ni iṣẹ́ jíjẹ́ wòlíì Ọlọrun fún Juda, orílẹ̀-èdè apẹ̀yìndà. Ó lu koro ìkìlọ̀ nípa ìparun tí ń bọ̀ sórí Jerusalemu. (Jeremiah 1:11-19) Gẹ́gẹ́ bí ìyọrísí rẹ̀, ọ̀pọ̀ ìgbà ni àwọn ará ìlú Jeremiah, tí wọ́n kà á sí akígbe àjálù kò ó lójú.

Àlùfáà náà Paṣuri, olórí olùtọ́jú ní ilé Ọlọrun, lu Jeremiah nígbà kan nítorí ohun tí ó ṣọ tẹ́lẹ̀, ó sì kàn án mọ́ àbà. Pẹ̀lú ohun tí ó dà bí ìfàsẹ́yìn yìí, Jeremiah wí pé: “Èmi di ẹni ìyọṣùtì sí lójoojúmọ́, gbogbo wọn ní ń gàn mí! Nítorí láti ìgbà tí mo ti sọ̀rọ̀, èmi kígbe, mo ké, Ìwà agbára, àti ìparun, nítorí a sọ ọ̀rọ̀ Oluwa di ohun ẹ̀gàn àti ìtìjú fún mi lójoojúmọ́.” Ìrẹ̀wẹ̀sì bá wòlíì náà, débi tí ó fi sọ pé: “Èmi kì yóò múni rántí rẹ̀ [Jehofa], èmi kì yóò sì sọ ọ̀rọ̀ ní orúkọ rẹ̀ mọ́.”—Jeremiah 20:1, 2, 7-9.

Bí ó ti wù kí ó rí, Jeremiah kò juwọ́ sílẹ̀ fún ìrẹ̀wẹ̀sì. Nígbà tí ó ń sọ nípa “ọ̀rọ̀ Jehofa,” ó polongo pé: “[Ó] ń bẹ bí iná tí ń jó nínú mi tí a sé mọ́ inú egungun mi, ó sì rẹ̀ mí láti pa á mọ́ra, èmi kò lè ṣe é.” (Jeremiah 20:8, 9) Nítorí tí a sún un lọ́nà lílágbára láti sọ̀rọ̀ Ọlọrun, ẹ̀mí mímọ́ mú Jeremiah dúró, ó sì mú iṣẹ́ àṣẹ rẹ̀ ṣẹ.

Aposteli Paulu pẹ̀lú ní ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ ìdí fún rírẹ̀wẹ̀sì, ó ha juwọ́ sílẹ̀ bí. Ó fara da ìjábá ti ìṣẹ̀dá, ọkọ̀ rírì, inúnibíni, àti ìluni. Ní àfikún sí i, ‘nǹkan tí ń rọ́ wọlé tọ̀ ọ́ láti ọjọ́ dé ọjọ́ wà níbẹ̀, àníyàn fún gbogbo àwọn ìjọ.’ (2 Korinti 11:23-28) Bẹ́ẹ̀ ni, Paulu ní láti máa kojú àwọn ìṣòro lójoojúmọ́, ní ṣíṣàníyàn nípa àwọn ìjọ tuntun tí ó ṣèrànwọ́ láti dá sílẹ̀. Jù bẹ́ẹ̀ lọ, ó jẹ́ aláìpé, ó sì ní láti bá “ẹ̀gún kan . . . ninu ẹran-ara” jìjàkadì, bóyá ojú ṣíṣú. (2 Korinti 12:7; Romu 7:15; Galatia 4:15) Àwọn kan tilẹ̀ bú Paulu lẹ́yìn, ó sì ta sí i létí.—2 Korinti 10:10.

Síbẹ̀síbẹ̀, Paulu kò yọ̀ọ̀da kí ìrẹ̀wẹ̀sì bo òun mọ́lẹ̀. Rárá, kì í ṣe àkàndá ènìyàn. (2 Korinti 11:29, 30) Kí ni kò jẹ́ kí ‘iná inú’ rẹ̀ kú? Ohun kan ni pé, ó ní àwọn alábàákẹ́gbẹ́pọ̀ tí ń tì í lẹ́yìn, àwọn kan tilẹ̀ bá a lọ sí Romu, níbi tí a ti há a mọ́lé. (Ìṣe 28:14-16) Èkejì ni pé, aposteli náà fojú tí ó wà déédéé wo ipò rẹ̀. Àwọn tí ń ṣe inúnibíni sí i, àti àwọn alátakò rẹ̀ ni wọ́n ṣàìtọ́, kì í ṣe Paulu. Bí ìgbésí ayé rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé ti ń lọ sópin, ó yẹ iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ wò lọ́nà rere, ó sì wí pé: “Lati àkókò yii lọ a ti fi adé òdodo pamọ́ dè mí, èyí tí Oluwa, onídàájọ́ òdodo, yoo fún mi gẹ́gẹ́ bí èrè-ẹ̀san ní ọjọ́ yẹn.”—2 Timoteu 4:8.

Lékè gbogbo rẹ̀, Paulu tọ Jehofa Ọlọrun lọ déédéé nínú àdúrà, ‘Oluwa sì dúró lẹ́bàá rẹ̀ ó sì fi agbára sínú rẹ̀.’ (2 Timoteu 4:17) Paulu wí pé: “Mo ní okun fún ohun gbogbo nípasẹ̀ agbára ìtóye ẹni naa tí ń fi agbára fún mi.” (Filippi 4:13) Ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ pẹ̀lú Ọlọrun àti àwọn Kristian ẹlẹgbẹ́ rẹ̀, papọ̀ pẹ̀lú ṣíṣàyẹ̀wò iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ lọ́nà rere, ran Paulu lọ́wọ́ láti máa bá a nìṣó nínú iṣẹ́ ìsìn Jehofa.

Ọlọrun mí sí Paulu láti kọ̀wé pé: “Ẹ máṣe jẹ́ kí a juwọ́sílẹ̀ ní ṣíṣe ohun tí ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀, nitori ní àsìkò yíyẹ awa yoo kárúgbìn bí a kò bá ṣàárẹ̀.” (Galatia 6:7-9) Kí ni irúgbìn tí a óò ká? Ìyè àìnípẹ̀kun. Nítorí náà, dà bíi Jeremiah, Paulu, àti ọ̀pọ̀ àwọn olùṣòtítọ́ ẹlẹ́rìí Jehofa tí a mẹ́nu kàn nínú Ìwé Mímọ́. Bẹ́ẹ̀ ni, dà bí wọn, má sì ṣe juwọ́ sílẹ̀ fún ìrẹ̀wẹ̀sì. Má ṣe jẹ́ kí iná rẹ kú.—Fi wé Matteu 5:14-16.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]

Paulu àti Jeremiah kò jẹ́ kí iná wọn kú

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́