Mo Láyọ̀ Ninu Ojúlówó Ẹgbẹ́-Àwọn-Ará Kárí-Ayé
GẸ́GẸ́ BÍ WILLIE DAVIS TI SỌ Ọ́
Ní 1934 Ìlọsílẹ̀ Ètò Ọrọ̀-Ajé Ńlá ń bá aráyé fínra, orílẹ̀-èdè United States sì ń jà fitafita pẹlu àìfararọ ètò ọrọ̀-ajé. Lẹ́yìn òde Ibùdó Ìfojúsọ́nà fún Ìpèsè Ìrànlọ́wọ́ ní Cleveland, Ohio, ìjàkadì kan ṣẹlẹ̀ láàárín ọlọ́pàá kan ati ẹnìkan tí ó jẹ́wọ́ jíjẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú Kọmunist. Ọlọ́pàá naa yìnbọn pa ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú Kọmunist naa, ati Vinnie Williams, ìyá-ìyá mi tí ó dúró sítòsí.
AWỌN ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú Kọmunist gbìyànjú lati sọ ìpànìyàn wọnyi di ọ̀ràn ẹ̀yà-ìran, níwọ̀n bí ìyá-ìyá mi ti jẹ́ aláwọ̀ dúdú tí ọlọ́pàá náà sì jẹ́ aláwọ̀ funfun. Wọ́n ṣe ìpínkiri awọn lẹ́tà ìròyìn tí ó ní awọn àkọlé bíi “Ọlọ́pàá Cleveland tí Ó Jẹ́ Elérò Ẹ̀yà-Ìran Tèmi Lọ̀gá” ati “Ẹ Gbẹ̀san Ìpànìyàn Wọnyi.” Awọn ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú Kọmunist ṣètò wọn sì bójútó ìsìnkú ìyá-ìyá mi. Fọ́tò awọn tí wọn gbé òkú naa lọ sí itẹ́ wà lọ́wọ́ mi—gbogbo wọn jẹ́ aláwọ̀ funfun wọn sì jẹ́ mẹ́ḿbà ẹgbẹ́ òṣèlú náà. Ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ná ìkúùkù sókè lọ́nà kan tí wọn tẹ́wọ́gbà lẹ́yìn naa gẹ́gẹ́ bí àmì ìṣàpẹẹrẹ Agbára Aláwọ̀ Dúdú.
Nígbà tí ìyá-ìyá mi kú, ọmọbìnrin rẹ̀ ṣì lóyún mi sínú, a sì bí mi ní oṣù mẹ́rin lẹ́yìn naa. Mo dàgbà di ẹni tí ó ní ìṣòro ọ̀rọ̀-sísọ. N kò lè sọ̀rọ̀ láì kólòlò, nitori naa mo gba ìtọ́jú ìṣègùn lórí ọ̀rọ̀-sísọ nígbà tí mo kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ ilé-ẹ̀kọ́.
Awọn òbí mi pínyà nígbà tí mo di ọmọ ọdún márùn–ún, ìyá mi sì tọ́ emi ati ẹ̀gbọ́n mi obìnrin dàgbà. Nígbà tí mo di ọmọ ọdún mẹ́wàá, mo bẹ̀rẹ̀ síi ta wòsìwósì káàkiri lẹ́yìn ilé-ẹ̀kọ́ lati ṣèrànwọ́ níti ìnáwó ìdílé. Ọdún méjì lẹ́yìn naa mo bẹ̀rẹ̀ sí ṣiṣẹ́ ṣáájú ati lẹ́yìn ilé-ẹ̀kọ́, ní dídi ẹni pàtàkì tí ń mowó wọlé wá fún ìdílé. Nígbà tí wọn gba Màmá sílé ìwòsàn tí ó sì pọndandan pé kí a ṣe ọ̀wọ́ awọn iṣẹ́-abẹ fún un, mo fi ilé-ẹ̀kọ́ sílẹ̀ mo sì bẹ̀rẹ̀ síi ṣiṣẹ́ nìkan.
A Mú Mi Mọ Ẹgbẹ́-Àwọn-Ará
Ní 1944 ọ̀kan lára awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa fún aya mọ̀lẹ́bí mi kan ní ìwé naa “Otitọ Yio Sọ Nyin Di Ominira,” mo sì darapọ̀ ninu ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli tí a bẹ̀rẹ̀ pẹlu rẹ̀. Ní ọdún yẹn gan-an ni mo bẹ̀rẹ̀ síi lọ sí Ilé-Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́-Òjíṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọrun ní Ìjọ Eastside. Olùkọ́ ilé-ẹ̀kọ́ naa, Albert Cradock, ní ìṣòro ọ̀rọ̀-sísọ kan naa bíi tèmi, ṣugbọn ó ti kẹ́kọ̀ọ́ lati káwọ́ rẹ̀. Ẹ wo bí ó ti jẹ́ ìṣírí fún mi tó!
Awọn ọmọ ilẹ̀ Italy, Poland, Hungary, ati Ju ni wọn pọ̀ jù ní àdúgbò wa, awọn ènìyàn láti inú àwùjọ ẹ̀yà wọnyi ati òmíràn ni wọn sì wà ninu ìjọ naa. Emi ati aya mọ̀lẹ́bí mi wà lára awọn Adúláwọ̀ ará America tí ó kọ́kọ́ darapọ̀ mọ́ ìjọ tí à bá kúkú pè ní ti awọn aláwọ̀ funfun yii, ṣugbọn awọn Ẹlẹ́rìí naa kò fi ẹ̀tanú ẹ̀yà-ìran hàn sí wa rí. Níti tòótọ́, wọn máa ń gbà mí lálejò déédéé lati wá jẹun ninu ilé wọn.
Ní 1956, mo ṣílọ sí apá ìhà gúúsù United States lati ṣiṣẹ́sìn níbi tí àìní fún awọn òjíṣẹ́ gbé pọ̀ jù. Nígbà tí mo padà sí àríwá ní ìgbà ẹ̀rùn kan fún àpéjọpọ̀ àgbègbè, ọ̀pọ̀ lára awọn ará ní Cleveland bẹ̀ mí wò wọn sì sọ̀rọ̀ nipa ọkàn-ìfẹ́ ọlọ́yàyà tí wọn ní ninu awọn ìgbòkègbodò mi. Ìdàníyàn wọn kọ́ mi ní ẹ̀kọ́ tí ó ṣe kókó kan: “Máṣe máa mójútó ire ara-ẹni ninu kìkì awọn ọ̀ràn ti ara yín nìkan, ṣugbọn ire ara-ẹni ti awọn ẹlòmíràn pẹlu.”—Filippi 2:4, NW.
Iṣẹ́-Òjíṣẹ́ Alákòókò Kíkún tí A Mú Gbòòrò Síi
Lẹ́yìn ṣíṣiṣẹ́ fún ọdún mẹ́ta ninu iṣẹ́ ìwàásù alákòókò kíkún gẹ́gẹ́ bí aṣáájú-ọ̀nà, ní November 1959, a késí mi lati ṣiṣẹ́sìn ní Beteli ti Brooklyn, orílé-iṣẹ́ àgbáyé ti awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ní New York. A yàn mí sí Ẹ̀ka-Iṣẹ́ Ìkẹ́rùráńṣẹ́. Alábòójútó ẹ̀ka-iṣẹ́ mi, Klaus Jensen, ati alábàágbé mi, William Hannan, tí awọn méjèèjì jẹ́ aláwọ̀ funfun, di baba nipa tẹ̀mí fún mi. Ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn ti sìn fún ohun tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó 40 ọdún ní Beteli nígbà tí emi dé.
Ní apá ìbẹ̀rẹ̀ awọn ọdún 1960, awọn mẹ́ḿbà ìdílé Beteli jẹ́ nǹkan bíi 600, nǹkan bíi 20 sì jẹ́ Adúláwọ̀ ará America. Nígbà yẹn, ìjà ẹ̀yà-ìran ti bẹ̀rẹ̀ síí rugùdù ní United States, àjọṣepọ̀ ẹ̀yà-ìran sì ti di onímẹ̀lọmẹ̀lọ. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, Bibeli kọ́ni pé “Ọlọrun kìí ṣe ojúsàájú,” awa pẹlu kò sì gbọdọ̀ jẹ́ bẹ́ẹ̀. (Iṣe 10:34, 35) Awọn ìjíròrò tẹ̀mí tí a ń ní nídìí tábìlì Beteli lóròòwúrọ̀ ṣiṣẹ́ lati fi okun fún ìpinnu wa lati tẹ́wọ́gba ojú-ìwòye Ọlọrun lórí irú awọn ọ̀ràn bẹ́ẹ̀.—Orin Dafidi 19:7.
Nígbà tí mo ṣì ń ṣiṣẹ́sìn ní Beteli ti Brookyln mo bá Lois Ruffin, aṣáájú-ọ̀nà kan lati Richmond, Virginia pàdé, a sì ṣègbéyàwó ní 1964. Ìpinnu wa ni lati máa báa nìṣó ninu iṣẹ́-òjíṣẹ́ alákòókò kíkún, nitori naa lẹ́yìn ìgbéyàwó wa, a padà lọ sí apá ìhà gúúsù ní United States. A kọ́kọ́ ṣiṣẹ́sìn gẹ́gẹ́ bí aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe, a sì késí mi lẹ́yìn naa ní 1965, lati wọnú iṣẹ́ àyíká. Fún ọdún mẹ́wàá tí ó tẹ̀lé e, a bẹ awọn ìjọ wò ní awọn ìpínlẹ̀ Kentucky, Texas, Louisiana, Alabama, Georgia, North Carolina, ati Mississippi.
Ìdánwò kan fún Ẹgbẹ́-Àwọn-Ará Wa
Awọn ọdún ìyípadà ńláǹlà ni ìwọ̀nyẹn jẹ́. Ṣáájú kí a tó sílọ sí Gúúsù, awọn ẹ̀yà-ìran ti pín sí ẹlẹ́gbẹ́jẹgbẹ́. Òfin kà á léèwọ̀ fún awọn aláwọ̀ dúdú láti lọ si ilé-ẹ̀kọ́ kan naa, jẹun ní ilé-àrójẹ kan naa, sùn ní hòtẹ́ẹ̀lì kan naa, rajà ní ilé-ìtajà kan naa, kí wọn sì mu omi lati inú orísun kan naa pẹlu awọn aláwọ̀ funfun. Ṣugbọn ní 1964 Ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin ti United States ṣe ìgbéjáde Òfin Ẹ̀tọ́ Òmìnira tí ó de àìbánilò lọ́gbọọgba ní awọn ibi tí ó jẹ́ ti gbogbogbòò, títíkan ọkọ̀ wíwọ̀. Nitori naa kò tún sí ìdí kankan tí ó bófinmu mọ́ fún ìpín sí ẹlẹ́gbẹẹgbẹ́ ẹ̀yà-ìran.
Nitori naa ìbéèrè naa ni pé, Ǹjẹ́ awọn arákùnrin ati arábìnrin wa tí ń bẹ ní awọn ìjọ tí gbogbo ènìyàn ti jẹ́ aláwọ̀ dúdú ati aláwọ̀ funfun yóò ha sọ araawọn dọ̀kan kí wọn sì fi ìfẹ́ ati ìfẹ́ni hàn sí araawọn bí, tabi ìkìmọ́lẹ̀ lati àárín àwùjọ ati awọn ìmọ̀lára tí ó ti wọ akínyẹmí ara lọ látẹ̀yìnwá yóò ha sún wọn lati kọ ìsọdọ̀kan sílẹ̀? Ìpèníjà ni ó jẹ́ lati kọbiara sí àṣẹ Ìwé Mímọ́ naa: “Níti ìfẹ́ ará, ẹ máa fi ìyọ́nú fẹ́ràn ara yín: níti ọlá, ẹ máa fi ẹnìkejì yín ṣáájú.”—Romu 12:10.
Lati ìgbà láéláé, ojú-ìwòye tí ó gba iwájú jùlọ, ní pàtàkì jùlọ ní Gúúsù, ni pé awọn aláwọ̀ dúdú rẹlẹ̀ sí awọn aláwọ̀ funfun. Níti tòótọ́ ni ó jẹ́ pé gbogbo apá-ìhà ẹgbẹ́ àwùjọ pátá, títíkan awọn ṣọ́ọ̀ṣì ti mú kí ojú-ìwòye yii wọ awọn ènìyàn lọ́kàn ṣinṣin. Nitori naa kò rọrùn fún awọn aláwọ̀ funfun kan lati wo awọn aláwọ̀ dúdú gẹ́gẹ́ bí ọ̀gbà. Níti tòótọ́, àkókò ìdánwò ni ìyẹn jẹ́ fún ẹgbẹ́-àwọn-ará wa—fún awọn aláwọ̀ dúdú ati funfun.
Ó múniláyọ̀ pé, ní àbárèbábọ̀, ìdáhùnpadà yíyanilẹ́nu wà fún pípa awọn ìjọ wa pọ̀. Awọn ojú-ìwòye tí a ti fìṣọ́ra kọ́ni fún ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún nipa àjùlọ ẹ̀yà-ìran kò tètè parẹ́ kúrò. Síbẹ̀, nígbà tí pípa ìjọ pọ̀ bẹ̀rẹ̀, awọn ará wa tí ọ̀pọ̀ jùlọ nínú wọn yọ̀ lati tún pàdé papọ̀, fi ọkàn rere gbà á.
Lọ́nà tí ó ru ọkàn-ìfẹ́ sókè, lọ́pọ̀ ìgbà ni awọn tí kìí tilẹ̀ ṣe Ẹlẹ́rìí fọwọ́sowọ́pọ̀ pẹlu pípa awọn ìjọ pọ̀. Fún àpẹẹrẹ, ní Lanett, Alabama, a bi awọn aládùúgbò tí wọn wà lẹ́bàá Gbọ̀ngàn Ìjọba bí wọn bá ní ohun kan lòdì sí kí awọn aláwọ̀ dúdú máa wá sí awọn ìpàdé. Obìnrin àgbàlagbà kan tí ó jẹ́ aláwọ̀ funfun bọ arákùnrin aláwọ̀ dúdú kan lọ́wọ́, ní sísọ pé: “Ẹ máa wá sí àdúgbò wa níbí kí ẹ sì sin Ọlọrun yín gẹ́gẹ́ bí ẹ ti fẹ́!”
Awọn Arákùnrin Olùṣòtítọ́ ní Ethiopia
Inú wa dún ní 1974 lati gba ìdánilẹ́kọ̀ọ́ olóṣù márùn-ún àbọ̀ gẹ́gẹ́ bí míṣọ́nnárì ní Watchtower Bible School of Gilead ní New York City. Lẹ́yìn naa ni a yàn wá sí orílẹ̀-èdè Africa naa Ethiopia. Kò tíì pẹ́ tí wọn rọ Haile Selassie, olú-ọba, lóyè tí wọn sì fi í sábẹ́ ìhámọ́. Níwọ̀n bí iṣẹ́ ìwàásù wa ti wà lábẹ́ ìfòfindè, a mọrírì ìsúnmọ́ra pẹ́kípẹ́kí ti ẹgbẹ́-àwọn-ará Kristian wa.
A gbé pẹlu ọ̀pọ̀ lára awọn wọnnì tí a fi sẹ́wọ̀n lẹ́yìn naa nitori fífi tí wọn faramọ́ ìjọsìn tòótọ́ a sì ṣiṣẹ́sìn lọ́dọ̀ wọn. Díẹ̀ lára awọn ọ̀rẹ́ wa ọ̀wọ́n ni a tilẹ̀ ṣekúpa. Adera Teshome jẹ́ alàgbà ẹlẹgbẹ́ mi ninu ìjọ kan ní olú-ìlú Ethiopia, Addis Ababa.a Lẹ́yìn ọdún mẹ́ta lẹ́wọ̀n, wọn pà á. Lọ́nà tí ó bá ìwà ẹ̀dá mu, aya rẹ̀ banújẹ́ gidigidi. Ẹ wo bí ó ti dùnmọ́ni tó ní ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn naa lati rí i tí ó ń yọ̀ ṣìnkìn bí ó ti ń ṣiṣẹ́sìn gẹ́gẹ́ bí aṣáájú-ọ̀nà!
Worku Abebe, arákùnrin olùṣòtítọ́ mìíràn, ni a dájọ́ ìjìyà ikú fún ní ìgbà mẹ́jọ.b Ṣugbọn a kò mú un láyà pami rí! Nígbà tí mo rí i kẹ́yìn, ó fi etí rẹ̀ tí awọn ẹ̀ṣọ́ ọgbà ẹ̀wọ̀n ti fi ìdí ìbọn fọ́ hàn mí. Ó sọ lọ́nà àwàdà pé ìdí ìbọn ni mo ń jẹ lówùúrọ̀, lọ́sàn-án, ati lálẹ́. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ti kú tipẹ́tipẹ́, awọn ará ṣì ń rántí rẹ̀ tìfẹ́tìfẹ́.
Arákùnrin mìíràn tí mo tún rántí tìfẹ́tìfẹ́ ni Hailu Yemiru.c Ó fi ìfẹ́ àwòfiṣàpẹẹrẹ hàn fún aya rẹ̀. Wọn fi àṣẹ ọba mú un, ṣugbọn níwọ̀n bí ó ti lóyún tí kò sì ní pẹ́ bímọ, Hailu béèrè lọ́wọ́ awọn aláṣẹ ọgbà ẹ̀wọ̀n bí oun bá lè rọ́pò rẹ̀ ní àtìmọ́lé. Lẹ́yìn tí wọn gbà, nitori pé ó kọ̀ lati fi ìgbàgbọ́ rẹ̀ bánidọ́rẹ̀ẹ́, wọn pa á.—Johannu 15:12, 13; Efesu 5:28.
Nitori ipò òṣèlú tí ń jagọ̀ ní Ethiopia, a ṣílọ sí Kenya ní 1976. A sìn fún ọdún méje ninu iṣẹ́ arìnrìn-àjò, ní bíbẹ awọn ará wò ní ọ̀pọ̀ awọn orílẹ̀-èdè Ìlà-Oòrùn Africa—títíkan Kenya, Ethiopia, Sudan, Seychelles, Uganda, ati Tanzania. Mo tún rìnrìn-àjò lọ sí Burundi ati Rwanda ní awọn ìgbà mélòókan gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára awọn aṣojú tí a yàn lati bá awọn ìjòyè òṣìṣẹ́ sọ̀rọ̀ nipa fífi orúkọ iṣẹ́ wa sílẹ̀ lábẹ́ òfin ní awọn orílẹ̀-èdè wọnnì.
Mo láyọ̀ lati padà sí Ethiopia ní January 1992 lati lọ síbi àpéjọpọ̀ àgbègbè àkọ́kọ́ tí a ṣe níbẹ̀ lẹ́yìn tí a ti mú ìfòfindè kúrò lórí iṣẹ́ wa. Ọ̀pọ̀ lára iye tí ó ju 7,000 tí wọn pésẹ̀ kò mọ araawọn rí, níwọ̀n bí awọn ará naa ti ń pàdé ninu àwùjọ kékeré tẹ́lẹ̀rí. Ní ọjọ́ kọ̀ọ̀kan tí àpéjọpọ̀ naa fi wáyé, ọ̀pọ̀ jùlọ awọn ènìyàn ń dé ní wákàtí méjì kí ìtòlẹ́sẹẹsẹ tó bẹ̀rẹ̀ wọn sì ń dúró pẹ́ títí di ọjọ́rọ̀, ní gbígbádùn ẹgbẹ́-àwọn-ará wa onífẹ̀ẹ́.
A Ṣẹ́gun Ẹ̀mí Kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà
Fún ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún ẹ̀mí kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà ti tànkálẹ̀ jákèjádò Africa. Fún àpẹẹrẹ, ní Burundi ati Rwanda, awọn àwùjọ ẹ̀yà-ìran tí wọn pọ̀ jùlọ, Hutu ati Tutsi, ti kórìíra araawọn tipẹ́tipẹ́. Lati ìgbà tí Belgium ti fún awọn orílẹ̀-èdè wọnyi lómìnira ní 1962, awọn mẹ́ḿbà àwùjọ ẹ̀yà-ìran méjèèjì ti ń pa araawọn níwọ̀n ẹgbẹẹgbẹ̀rún lóòrèkóòrè. Nitori naa, ẹ wo bí ó ti dùnmọ́ni tó lati rí awọn mẹ́ḿbà àwùjọ ẹ̀yà-ìran wọnyi tí wọn ti di Ẹlẹ́rìí Jehofa tí wọn ń ṣiṣẹ́ papọ̀ ní àlàáfíà! Ojúlówó ìfẹ́ tí wọn fihàn sí araawọn ti fún ọ̀pọ̀ awọn mìíràn níṣìírí lati tẹ́tísílẹ̀ sí awọn òtítọ́ Bibeli.
Bákan naa, awọn àwùjọ ẹ̀yà ní Kenya máa ń ní awọn aáwọ̀ tiwọn. Ẹ wo bí èyí ṣe yàtọ̀ tó láàárín ẹgbẹ́-àwọn-ará Kristian ti awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ní Kenya! Iwọ lè rí awọn ènìyàn tí wọn wá lati inú awọn àwùjọ ẹ̀yà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tí wọn ń fi ìsopọ̀ṣọ̀kan jọ́sìn ní awọn Gbọ̀ngàn Ìjọba. Ó ti jẹ́ ayọ̀ mi lati rí i tí ọ̀pọ̀ lára awọn wọnyi pa ìkórìíra ẹ̀yà-ìran wọn tì, tí wọn sì fi ojúlówó ìfẹ́ hàn sí awọn arákùnrin ati arábìnrin wọn tí wọn ti inú àwùjọ ẹ̀yà mìíràn wá.
A Láyọ̀ Nitori Ẹgbẹ́-Àwọn-Ará Wa
Bí mo ti ń bojúwẹ̀yìn wo iye tí o rékọjá 50 ọdún ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ pẹlu ètò-àjọ Ọlọrun, ìmoore fún Jehofa ati Ọmọkùnrin rẹ̀, Jesu Kristi, kún inú ọkàn-àyà mi. Ó ti jẹ́ ohun àgbàyanu nítòótọ́ lati kíyèsí ohun tí wọn ti gbéṣe lórí ilẹ̀-ayé! Rárá, ipò awọn nǹkan kò ti fìgbà gbogbo jẹ́ pípé láàárín awọn ènìyàn Ọlọrun, bẹ́ẹ̀ sì ni kò rí bẹ́ẹ̀ lónìí. Ṣugbọn a kò lè retí pé ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún tí ayé Satani fi kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ ẹ̀yà-ìran-tèmi-lọ̀gá ni a óò parẹ́ kúrò ní ọ̀sán kan òru kan. Ó ṣetán, aláìpé ṣì ni wá.—Orin Dafidi 51:5.
Bí mo ti ń fi ètò-àjọ Jehofa wé ayé, ọkàn-àyà mi ń kún àkúnwọ́sílẹ̀ fún ìmọrírì fún ojúlówó ẹgbẹ́-àwọn-ará wa kárí-ayé. Mo ṣì ń fi tìfẹ́tìfẹ́ rántí awọn arákùnrin wọnnì ní Cleveland, tí gbogbo wọn jẹ́ aláwọ̀ funfun, tí wọn tọ́ mi dàgbà ninu òtítọ́. Bí mo sì ti ń rí i tí awọn arákùnrin wa ní ìhà gúúsù United States, ati funfun ati dúdú, ń fi ìfẹ́ ará àtọkànwá rọ́pò ẹ̀tanú wọn, ọkàn mi ń kún fún ayọ̀. Lẹ́yìn naa, lílọ sí Africa ati fífi ojú ara mi rí bí Ọ̀rọ̀ Jehofa ṣe lè pa ìkórìíra ẹ̀yà rẹ́ mú kí ń túbọ̀ mọrírì ẹgbẹ́-àwọn-ará wa kárí-ayé síi.
Níti tòótọ́, Ọba Dafidi ìgbà àtijọ́ sọ dáradára nígbà tí ó wí pé: “Kíyèsí i, ó ti dára ó sì ti dùn tó fún awọn ará lati máa jùmọ̀ gbé ní ìrẹ́pọ̀.”—Orin Dafidi 133:1.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Fọ́tò Adera Teshome ati Hailu Yemiru farahàn ní ojú-ìwé 177 ninu 1992 Yearbook of Jehovah’s Witnesses; ìrírí Worku Abebe ni a sọ ní ojú-ìwé 178 sí 181.
b Fọ́tò Adera Teshome ati Hailu Yemiru farahàn ní ojú-ìwé 177 ninu 1992 Yearbook of Jehovah’s Witnesses; ìrírí Worku Abebe ni a sọ ní ojú-ìwé 178 sí 181.
c Fọ́tò Adera Teshome ati Hailu Yemiru farahàn ní ojú-ìwé 177 ninu 1992 Yearbook of Jehovah’s Witnesses; ìrírí Worku Abebe ni a sọ ní ojú-ìwé 178 sí 181.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Ìsìnkú ìyá-ìyá mi
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]
Awọn ará Tutsi ati Hutu tí wọ́n jẹ́ Ẹlẹ́rìí ṣiṣẹ́ papọ̀ ní àlàáfíà
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]
Pẹlu aya mi, Lois