ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w94 9/1 ojú ìwé 26
  • “Ẹ Kọ Ojú Ìjà sí Eṣu, Oun Ó Sì Sá Kúrò Lọ́dọ̀ Yín”

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • “Ẹ Kọ Ojú Ìjà sí Eṣu, Oun Ó Sì Sá Kúrò Lọ́dọ̀ Yín”
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ọlọ́run Máa Ń Gbọ́ Àdúrà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2000
  • Mo Fi Àwọn Nǹkan Sílẹ̀ Kí N Lè Tẹ̀ Lé Jésù
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2017
  • “Láti Ẹnu Àwọn Ìkókó”
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
w94 9/1 ojú ìwé 26

Àwọn Olùpòkìkí Ìjọba Ròyi̇̀n

“Ẹ Kọ Ojú Ìjà sí Eṣu, Oun Ó Sì Sá Kúrò Lọ́dọ̀ Yín”

NÍ Ọ̀RÚNDÚN kìn-ín-⁠ní, àwùjọ awọn olùfọkànsìn fún “idán pípa” ní Efesu dáhùnpadà sí ìhìn-iṣẹ́ Kristian naa nipa sísun awọn ìwé idán wọn ní gbangba. (Iṣe 19:19, NW) Iye tí a ṣírò awọn ìwé wọnyi sí jẹ́ 50,000 owó ẹyọ fàdákà. Bí àkọsílẹ̀ Bibeli bá tọ́kasí denarius, ẹyọ-owó fàdákà tí awọn ara Romu, àpapọ̀ iye owó naa yóò ti jẹ́ ₦814,000 ó kérétán!

Awọn pupọ wà lónìí tí wọn ti fìgbà kan rí ní awọn ìwé tí ó nííṣe pẹlu ohun ìjìnlẹ̀ awo ṣugbọn tí wọn fi irú ìpinnu tí ó farajọ ti awọn ará Efesu ìgbàanì hàn. Gbé ìrírí yii yẹ̀wò tí ó wá lati Canada.

Ní nǹkan bí ọdún márùn-⁠ún sẹ́yìn, ọ̀kan lára awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ń wàásù lati ilé-dé-ilé nígbà tí obìnrin kan tí ń jẹ́ Nora fà á wọnú ilé ní tààràtà lẹ́nu ọ̀nà kan. Lati ọ̀pọ̀ ọdún gígùn tí ó ti ń wá ohun tẹ̀mí kiri, Nora ti ṣe àkójọ ọgọ́rọ̀ọ̀rún awọn ìwé ìsìn ati ti ìbẹ́mìílò, ṣugbọn ó fẹ́ lati mọ ohun tí Bibeli ní lati sọ nípa ìrètí tí ó wà fún awọn òkú. Ẹlẹ́rìí naa nawọ́ ìwé-àṣàrò-kúkúrú naa Ireti Wo ni Ó Wà fun Awọn Ololufẹ Tí Wọn Ti Kú? sí i. A dáhùn awọn ìbéèrè Nora, ó sì ṣe àsansílẹ̀-owó fún ìwé ìròyìn Ilé-Ìṣọ́nà ati Jí!

Lẹ́yìn naa ó ṣí lọ kúrò kò sì ní ìfarakanra pẹlu awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa mọ́. Bí ó ti wù kí ó rí, ó ń báa lọ lati máa rí awọn ìwé ìròyìn naa gbà nípasẹ̀ ìfìwéránṣẹ́ ní àdírẹ́sì rẹ̀ titun. Ó tún kọ̀wé béèrè fún díẹ̀ lára awọn ìtẹ̀jáde tí a gbékarí Bibeli èyí tí a mẹ́nukàn ninu awọn ìwé ìròyìn naa. Lẹ́yìn àkókò díẹ̀, ọ̀kan lára awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa wá sẹ́nu ọ̀nà rẹ̀. Bí ó ti ní ìwúrí pé Ẹlẹ́rìí naa lọ tààràtà sínú Bibeli nígbà tí ó ń dáhùn awọn ìbéèrè rẹ̀, Nora gbà á tọwọ́tẹsẹ̀ ó sì késí i kí ó padà wá fún awọn ìjíròrò síwájú síi.

Bí ó ti wù kí ó rí, ó ṣòro fún Ẹlẹ́rìí naa lati tún fojúkan Nora. Ó pààrà ọ̀dọ̀ rẹ̀ ní awọn àkókò yíyàtọ̀síra lóòjọ́ ati ní awọn àkókò yíyàtọ̀síra láàárín ọ̀sẹ̀ láìbá a. Ṣugbọn, nígbà tí ó yá, ìtẹpẹlẹ rẹ̀ mérè wá, ó sì kórè awọn ìyọrísí rere. Wọn bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli déédéé, èyí tí Nora fi dandan lé pé kí a máa ṣe ní ìgbà mẹ́ta lọ́sẹ̀. Awọn nǹkan tí ó ń kọ́ sún un lati bá awọn ọ̀rẹ́ ati mẹ́ḿbà ìdílé sọ̀rọ̀, èyí tí ó yọrísí bíbèèrè tí mẹ́ta lára wọn béèrè fún ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli pẹlu awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa.

Nípasẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ Nora wá mọrírì rẹ̀ pé ọ̀pọ̀ awọn ìsìn èké àti wòlíì èké ni ó wà ṣugbọn ọ̀nà kanṣoṣo ní ń sinni lọ sí ìyè. Ó ti ń wá ìdáhùn sí awọn ìbéèrè rẹ̀ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún lọ́dọ̀ awọn ìsìn èké, ṣugbọn lẹ́yìn kíkẹ́kọ̀ọ́ ohun tí Bibeli ní lati sọ nípa awọn ẹ̀mí-èṣù, ó hùwà bíi ti awọn ara Efesu ìgbàanì tí a mẹ́nukàn nínú Iṣe 19:19. Ó gbá ibi àkójọ ìwé kíkà rẹ̀ mọ́ tónítóní, ó sì gbà á ní ọjọ́ mélòókan lati run iye awọn ìwé tí ó ju ẹgbẹ̀rún lọ tí wọ́n níí ṣe pẹlu ohun ìjìnlẹ̀ awo ati awọn ẹ̀kọ́ ìsìn èké. Lára awọn ìwé tí ó run, iye-owó àpapọ̀ awọn ìwé mẹ́rin kan ju ₦17,600 lọ!

Ní kedere, awọn ẹ̀mí-èṣù fìtínà Nora fún nǹkan bí ọ̀sẹ̀ méjì níwọ̀n bí ìgbésẹ̀ rẹ̀ kò ti tẹ́ wọn lọ́rùn. Bí ó ti wù kí ó rí, kò ṣeéṣe fún awọn ẹ̀mí-èṣù búburú wọnyi lati dá a lẹ́kun títẹ̀síwájú pẹlu ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli rẹ̀ ati ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ rẹ̀ pẹlu ètò-àjọ Jehofa òde-òní.

Irúfẹ́ awọn ìrírí bẹ́ẹ̀ ṣàkàwé òtítọ́ awọn ọ̀rọ̀ Bibeli pé: “Nítorí naa ẹ tẹríba fún Ọlọrun. Ẹ kọ ojú ìjà sí Eṣu, oun ó sì sá kúrò lọ́dọ̀ yín.”​—⁠Jakọbu 4:⁠7.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́