ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w00 3/1 ojú ìwé 5-7
  • Ọlọ́run Máa Ń Gbọ́ Àdúrà

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ọlọ́run Máa Ń Gbọ́ Àdúrà
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2000
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àwọn Àpẹẹrẹ ti Òde Òní
  • Bóo Bá Rò Pé Oò Tóótun Láti Gbàdúrà Ńkọ́?
  • “Ẹ Kọ Ojú Ìjà sí Eṣu, Oun Ó Sì Sá Kúrò Lọ́dọ̀ Yín”
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
  • Ẹ̀yin Ọ̀dọ́, Ẹ Mú Kí Ìfẹ́ Yín Láti Sin Jèhófà Jinlẹ̀ Sí I
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2010
  • Èé Ṣe Tó Fi Yẹ Kóo Máa Gbàdúrà?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2000
  • Kọ̀nílíù Gba Ẹ̀mí Mímọ́
    Àwọn Ẹ̀kọ́ Tó O Lè Kọ́ Látinú Bíbélì
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2000
w00 3/1 ojú ìwé 5-7

Ọlọ́run Máa Ń Gbọ́ Àdúrà

Kọ̀nílíù jẹ́ ẹnì kan tó ń wójú rere Ọlọ́run nípa gbígba àdúrà àtọkànwá nígbà gbogbo. Ìyẹn nìkan kọ́, ó tún lo ipò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọ̀gágun lọ́nà rere. Gẹ́gẹ́ bí Bíbélì ti wí, “ó . . . ń fi ọ̀pọ̀ ẹ̀bùn àánú” fún àwọn ènìyàn tó ṣaláìní.—Ìṣe 10:1, 2.

NÍGBÀ yẹn lọ́hùn-ún, àwọn Júù, àwọn aláwọ̀ṣe, àti àwọn ara Samáríà ló wà nínú ìjọ Kristẹni. Kọ̀nílíù jẹ́ Kèfèrí aláìkọlà, kì í sì í ṣe mẹ́ńbà ìjọ Kristẹni. Ìyẹn ha túmọ̀ sí pé àwọn àdúrà rẹ̀ já sásán bí? Rárá o. Jèhófà Ọlọ́run kíyè sí Kọ̀nílíù àti iṣẹ́ rẹ̀ tó ń bá àdúrà rìn.—Ìṣe 10:4.

Lábẹ́ ìdarí áńgẹ́lì, a fojú Kọ̀nílíù mọ ìjọ Kristẹni. (Ìṣe 10:30-33) Ìyọrísí rẹ̀ ni pé, òun àti agboolé rẹ̀ láǹfààní láti di Kèfèrí aláìkọlà táa kọ́kọ́ gbà sínú ìjọ Kristẹni. Ní àwọn ọdún díẹ̀ lẹ́yìn ìgbà yẹn, Jèhófà Ọlọ́run rí i pé ó yẹ láti kọ ìrírí Kọ̀nílíù sínú Bíbélì. Kò sí àní-àní pé, ó ṣe ọ̀pọ̀ ìyípadà láti mú kí ìgbésí ayé rẹ̀ bá ìlànà Ọlọ́run mu pátápátá. (Aísáyà 2:2-4; Jòhánù 17:16) Ìṣírí ńlá ló yẹ kí ìrírí Kọ̀nílíù jẹ́ fún àwọn ènìyàn orílẹ̀-èdè gbogbo tí wọ́n ń fẹ́ ojú rere Ọlọ́run lónìí. Gbé àwọn àpẹẹrẹ díẹ̀ yẹ̀ wò.

Àwọn Àpẹẹrẹ ti Òde Òní

Ọ̀ṣọ́ọ́rọ́ obìnrin kan wà ní Íńdíà tó nílò ìtùnú lójú méjèèjì. Ọmọ ọdún mọ́kànlélógún ni nígbà tó relé ọkọ, ó sì ti bímọ méjì. Ṣùgbọ́n kò pẹ́ lẹ́yìn tó bímọ kejì, ni ọkọ rẹ̀ kú. Ló wá di opó ọ̀sán gangan ní ọmọ ọdún mẹ́rìnlélógún, ó sì ń tọ́jú ọmọdébìnrin kékeré jòjòló, ọmọ oṣù méjì àti ọmọdékùnrin kan, ọmọ oṣù méjìlélógún lọ́wọ́. Áà, ó nílò ìtùnú lóòótọ́! Ibo ni kó wá yíjú sí báyìí o? Lóru ọjọ́ kan, ọkàn rẹ̀ bà jẹ́ gan-an, ló bá gbàdúrà, ó ní: “Baba wa ọ̀run, dákun wá fi Ọ̀rọ̀ rẹ̀ tù mí nínú.”

Ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, àlejò kan kàn dé bá a ni. Ẹni yìí jẹ́ ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ní ọjọ́ yẹn, iṣẹ́ òjíṣẹ́ ilé dé ilé tí arákùnrin náà ń ṣe kò rọrùn fún un nítorí pé ìwọ̀nba èèyàn díẹ̀ ló gbà á láyè pé kí ó bá àwọn sọ̀rọ̀. Àárẹ̀ mú un, ìrẹ̀wẹ̀sì bá a, ló bá pinnu pé òun á kúkú máa lọ sílé, àmọ́ ó kàn ṣáà dà á rò pé kí òun bẹ ilé kan wò sí i. Ibi tó ti pàdé ọ̀dọ́bìnrin opó yìí nìyẹn o. Ó pe arákùnrin yìí wọlé, ó sì gba ìtẹ̀jáde tó ṣàlàyé Bíbélì lọ́wọ́ rẹ̀. Obìnrin náà rí ìtùnú nínú kíka ìtẹ̀jáde náà àti láti inú ọ̀rọ̀ tí Ẹlẹ́rìí náà bá a jíròrò. Ó kọ́ nípa ìlérí Ọlọ́run láti jí àwọn òkú dìde àti nípa Ìjọba Ọlọ́run, èyí tí yóò mú párádísè wá sórí ilẹ̀ ayé láìpẹ́. Èyí tó ṣe pàtàkì jù lọ ni pé, ó wá mọ Ọlọ́run tòótọ́ náà, Jèhófà, ẹni tó ti gbọ́ àdúrà rẹ̀, ó sì nífẹ̀ẹ́ rẹ̀.

Nora, ẹni tó ń gbé ní ìlú George, ní Gúúsù Áfíríkà, ya oṣù kan sọ́tọ̀ láti ṣe iṣẹ́ ajíhìnrere alákòókò kíkún. Kó tó bẹ̀rẹ̀, ó gbàdúrà tọkàntọkàn sí Jèhófà, ó ní kó ran òun lọ́wọ́, kí òun lè rí ẹni tó fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lóòótọ́. Ilé ẹnì kan tó ti fìwọ̀sí lọ Nora nígbà kan tó ṣèbẹ̀wò síbẹ̀ wà lára àgbègbè tí a yàn fún un. Tìgboyà-tìgboyà, Nora tún padà lọ sí ilé náà. Ó yà á lẹ́nu láti rí i pé ẹlòmíràn ti kó wá síbẹ̀, orúkọ onítọ̀hún ni Noleen. Ìyẹn nìkan kọ́, Noleen àti ìyá rẹ̀ pàápàá ti ń gbàdúrà sí Ọlọ́run pé kó ran àwọn lọ́wọ́ láti lóye Bíbélì. Nora ṣàlàyé pé: “Nígbà tí mo fi ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ̀ wọ́n, inú wọ́n dùn sí i.” Noleen àti ìyá rẹ̀ tẹ̀ síwájú lọ́nà tó yára kánkán. Kò pẹ́ kò jìnnà, àwọn méjèèjì bẹ̀rẹ̀ sí dara pọ̀ mọ́ Nora nínú iṣẹ́ ìwòsàn nípa tẹ̀mí tó ń ṣe.

Àpẹẹrẹ mìíràn tó fi agbára àdúrà hàn ni ti tọkọtaya kan tó ń gbé ní Johannesburg, ìlú ńlá kan ní Gúúsù Áfíríkà. Lálẹ́ ọjọ́ Saturday kan lọ́dún 1996, ìgbéyàwó Dennis àti Carol fẹ́ forí ṣánpọ́n. Ní paríparí rẹ̀, wọ́n pinnu láti gbàdúrà fún ìrànlọ́wọ́, wọ́n sì ṣe bẹ́ẹ̀ títí di òrugànjọ́. Ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, ní aago mọ́kànlá òwúrọ̀, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà méjì kan ilẹ̀kùn wọn. Dennis ló lọ ṣílẹ̀kùn, ó ní kí wọ́n dúró ná, kí òun lọ pé ìyàwó òun wá. Ni Dennis bá lọ kìlọ̀ fún Carol pé bó bá lọ pe àwọn Ẹlẹ́rìí wọlé pẹ́nrẹ́n, wọn ò ní lọ bọ̀rọ̀ o. Carol rán Dennis létí ohun tí àwọn ti ń gbàdúrà fún, ó ní, ó lè jẹ́ pé Ọlọ́run ló gbọ́ àdúrà àwọn. Ká má fọ̀rọ̀ gùn, wọ́n ní kí àwọn Ẹlẹ́rìí wọlé, ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì sì bẹ̀rẹ̀ nínú ìwé Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun. Ohun tí Dennis àti Carol kọ́ dùn mọ́ wọn jọjọ. Ní ọ̀sán ọjọ́ yẹn gan-an ni wọ́n lọ sí ìpàdé fún ìgbà àkọ́kọ́ ní Gbọ̀ngàn Ìjọba Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ládùúgbò wọn. Nípa lílo ìmọ̀ tí wọ́n ti gbà láti inú Bíbélì, Dennis àti Carol rí ojútùú sí ìṣòro ìgbéyàwó wọn. Ní báyìí, wọ́n ti ṣe ìrìbọmi, wọ́n ń fi tayọ̀tayọ̀ yin Jèhófà, wọ́n sì ń sọ nípa àwọn ohun tí wọ́n gbà gbọ́, tí a gbé ka Bíbélì, fún àwọn aládùúgbò wọn déédéé.

Bóo Bá Rò Pé Oò Tóótun Láti Gbàdúrà Ńkọ́?

Àwọn kan tí wọn kì í ṣe alágàbàgebè lè rò pé àwọn ò tóótun láti gbàdúrà nítorí ìgbésí ayé burúkú tí wọ́n ń gbé. Jésù Kristi sọ ìtàn ọkùnrin kan tó jẹ́ irú èèyàn bẹ́ẹ̀, ó jẹ́ agbowó òde, ẹni táwọn èèyàn ò kà sí. Nígbà tí ọkùnrin yìí wọnú àgbàlá tẹ́ńpìlì, ó gbà pé òun ò yẹ lẹ́ni tí ń wà níbi tí àwọn èèyàn ti sábà máa ń gbàdúrà. “Ó dúró ní òkèèrè . . . ó sáà ń lu igẹ̀ rẹ̀ ṣáá, ó ń wí pé, ‘Ọlọ́run, fi oore ọ̀fẹ́ hàn sí èmi ẹlẹ́ṣẹ̀.’” (Lúùkù 18:13) Gẹ́gẹ́ bí ohun tí Jésù sọ, a gbọ́ ẹ̀bẹ̀ ọkùnrin yìí. Èyí fi hàn pé olóore ni Jèhófà Ọlọ́run, ó sì ń fẹ́ láti ran àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ tí wọ́n fi tọkàntọkàn ronú pìwà dà lọ́wọ́.

Gbé ìrírí ọ̀dọ́mọkùnrin ọmọ ilẹ̀ Gúúsù Áfíríkà yìí yẹ̀ wò, ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Paul. Nígbà tí Paul wà lọ́mọdé, ó máa ń bá màmá rẹ̀ lọ́ sí ìpàdé àwọn Kristẹni. Ṣùgbọ́n ní àwọn ọdún tó fi wà nílé ẹ̀kọ́ girama, ó bẹ̀rẹ̀ sí dara pọ̀ mọ́ àwọn èwe tí kò rìn ní ọ̀nà Ọlọ́run. Lẹ́yìn tó fi ilé ìwé sílẹ̀, ó ṣiṣẹ́ sójà ìjọba kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà tẹ́lẹ̀ rí ti Gúúsù Áfíríkà. Nígbà tó ṣe, láìròtẹ́lẹ̀ ni ọ̀rẹ́bìnrin rẹ̀ bá ní ọ̀rẹ́ àwọn ò lè wọ̀ mọ́. Ọ̀nà ìgbésí ayé tí kò tẹ́ Paul lọ́rùn yìí bà á nínú jẹ́ púpọ̀. Ó rántí pé: “Ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ kan, mo gbàdúrà sí Jèhófà pé kó ràn mí lọ́wọ́, bó tilẹ̀ jẹ́ pé n kò fi tọkàntọkàn gbàdúrà sí Ọlọ́run fún ọ̀pọ̀ ọdún.”

Kò pẹ́ púpọ̀ lẹ́yìn tó gbàdúrà yìí ni màmá Paul pè é pé kó wá síbi ayẹyẹ Ìṣe Ìrántí ikú Kristi tí wọ́n máa ń ṣe lọ́dọọdún. (Lúùkù 22:19) Ó ya Paul lẹ́nu pé màmá rẹ̀ sọ bẹ́ẹ̀, nítorí pé ó ti jẹ́ oníwàkiwà, tí kì í sì í fi ìfẹ́ hàn sí Bíbélì. “Mo ka ìkésíni yìí sí ọ̀nà tí Jèhófà gbà gbọ́ àdúrà mi, mo sì pinnu láti ṣe ohun tó ní kí n ṣe.” Láti ìgbà yẹn lọ ni Paul ti bẹ̀rẹ̀ sí lọ sí gbogbo ìpàdé àwọn Kristẹni. Lẹ́yìn oṣù mẹ́rin tó ti ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó tóótun láti ṣe ìrìbọmi. Ní àfikún sí i, ó pa ẹ̀kọ́ nípa ìmọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ tó ń kọ́ tì, ó sì yan iṣẹ́ ajíhìnrere alákòókò kíkún láàyò. Lónìí, Paul jẹ aláyọ̀, ìgbésí ayé tó ti gbé tẹ́lẹ̀ kò sì bà á nínú jẹ́ mọ́. Láti ọdún mọ́kànlá sẹ́yìn ló ti sìn ní ẹ̀ka ọ́fíìsì ti Watch Tower Society tó wà ní Gúúsù Áfíríkà.

Ká sòótọ́, Jèhófà Ọlọ́run máa ń gbọ́ àdúrà, òun sì ni “olùṣẹ̀san fún àwọn tí ń fi taratara wá a.” (Hébérù 11:6) Láìpẹ́, ọjọ́ ńlá Jèhófà yóò dé, yóò sì mú òpin dé bá gbogbo ìwà ibi. Ní báyìí, Jèhófà ń gbọ́ àdúrà àwọn ènìyàn rẹ̀, ó ń fún wọn lókun àti ìtọ́sọ́nà bí wọ́n ti ń fi ìtara ṣe iṣẹ́ pàtàkì náà, iṣẹ́ ìjẹ́rìí. Nípa báyìí, àràádọ́ta ọ̀kẹ́ láti inú orílẹ̀-èdè gbogbo ni a ti mú wá sínú ìjọ Kristẹni, tí a sì ti fi ìmọ̀ Bíbélì tí ń sinni lọ sí ìyè àìnípẹ̀kun bù kún wọn.—Jòhánù 17:3.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]

Àdúrà àtọkànwá tí Kọ̀nílíù gbà ló jẹ́ kí àpọ́sítélì Pétérù lọ sọ́dọ̀ rẹ̀

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]

Àdúrà ti ran ọ̀pọ̀lọpọ̀ lọ́wọ́ ní àkókò ìdààmú

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

Ó dára ká fàdúrà béèrè fún ìrànlọ́wọ́ láti lóye Bíbélì

Tọkọtaya lè fàdúrà béèrè fún ìrànlọ́wọ́ kí ìgbéyàwó wọn lè lókun

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́