ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w94 10/1 ojú ìwé 3-4
  • Bibeli—Kí Ni Ìníyelórí Rẹ̀ Gidi?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Bibeli—Kí Ni Ìníyelórí Rẹ̀ Gidi?
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Gbogbo Ìwé Mímọ́ Ni Ó Ṣàǹfààní fún Kíkọ́ni
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1995
  • Bíbélì—Ìwé Kan Tó Wá Látọ̀dọ̀ Ọlọ́run
    Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an?
  • Ẹ̀kọ́ Òtítọ́ Tínú Ọlọ́run Dùn Sí
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2005
  • Ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Ni Bíbélì Ti Wá
    Kí Ni Bíbélì Kọ́ Wa?
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
w94 10/1 ojú ìwé 3-4

Bibeli—Kí Ni Ìníyelórí Rẹ̀ Gidi?

“BIBELI jẹ́ ohun ìjìnlẹ̀ kan, ìwé kan tí a kò fẹ́ kí a lóye rẹ̀,” ni onílé kan sọ. Òmíràn sọ pé: “Mo mọ̀ pé Bibeli jẹ́ ìwé pàtàkì kan, ṣugbọn emi kò mọ pupọ nipa rẹ̀. Ó ṣòro lati lóye.”

Ìwé ìròyìn The Toronto Star sọ pé, “Ọ̀pọ̀ awọn Kristian kò mọ . . . pupọ nipa Bibeli.” Ọ̀dọ́mọbìnrin onísìn Katoliki kan ṣàlàyé pé: “Níní Bibeli mú inú mi dùn. Ó ń mú àlàáfíà ọkàn wá.” Apẹja kan sọ pé, “Bibeli dàbí ìdarí kan tí ń tọ́ ẹnìkan sọ́nà la òkun ìgbésí-ayé tí ń rugùdù tí ó sì jẹ́ oníjì já sí ibi aláìléwu kan.” Gẹ́gẹ́ bí onísìn Hindu tẹ́lẹ̀rí kan ti sọ, “Bibeli jẹ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọrun ati ẹ̀bùn kan fún aráyé ó sì jẹ́ egbòogi ìwòsàn fún awọn ìjìyà nípa tẹ̀mí.”

Awọn èrò lórí ìníyelórí tòótọ́ ti Bibeli pọ lọ́pọ̀lọpọ̀ wọn sì pín sí onírúurú. Ṣugbọn, kí ni ìníyelórí rẹ̀ gidi?

Bibeli ni ìwé tí ó ṣe pàtàkì jùlọ tí ó sì ní ìpínkiri gbígbòòrò jùlọ tí ó wà. Awọn ìdáhùn sí awọn ìṣòro tí ń pinnilẹ́mìí jùlọ tí ènìyàn tíì nírìírí rẹ̀ rí tabi tí yoo ṣì dojúkọ ń bẹ ninu awọn ojú-ewé rẹ̀. Ìgbéṣẹ́ awọn ìmọ̀ràn rẹ̀ kò ní alábàádọ́gba. Kó sì ohun tí ó tayọ awọn ọ̀pá ìdiwọ̀n ìwàrere tí ó gbẹnusọ fún. Ìhìn-iṣẹ́ rẹ̀ lágbára ó sì ṣàǹfààní. Ó yẹ kí a mú ìwé tí ìníyelórí rẹ̀ kò ní àfiwé yii kúrò ninu pẹpẹ ìkówèésí wa kí a farabalẹ̀ kíyèsi kí a sì ṣàyẹ̀wò rẹ̀ fínnífínní.

A lè ṣí Bibeli pẹlu ìgbẹ́kẹ̀lé kíkún pé ó péye, ó ṣeé gbáralé, ó sì jóòótọ́ délẹ̀délẹ̀. Awọn ìtàn ohun tí ó ṣẹlẹ̀ tí a kọsílẹ̀ sínú rẹ̀ ni awọn ìtàn ayé jẹ́rìí sí. Léraléra, àwárí awọn awalẹ̀pìtàn kín ìjẹ́gidi ati ìjóòótọ́ Bibeli lẹ́yìn. Ìṣòótọ́ nǹkan bí awọn 40 òǹkọ̀wé Bibeli fi wọn hàn yàtọ̀ pé wọn jẹ́ aláìlábòsí ati olùpàwàtítọ́mọ́. Ìṣọ̀kan tí ó wà ninu Bibeli fihàn pé kò pilẹ̀ṣẹ̀ lati ọ̀dọ̀ ènìyàn. Awọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí a kọsílẹ̀ sínú rẹ̀ jẹ́ gidi. Awọn ènìyàn tí ó sọ̀rọ̀ nipa wọn jẹ́ gidi. Awọn ibi ati ọ̀gangan-ibi tí ó tọ́ka sí jẹ́ gidi. Síwájú síi, Bibeli ní awọn àsọtẹ́lẹ̀ títayọ ninu tí ó fi Jehofa Ọlọrun hàn gẹ́gẹ́ bí Òǹṣèwé Bibeli lọ́nà tí kò mú iyèméjì dání.​—⁠2 Peteru 1:⁠21.

Atóbilọ́lá Olùkọ́ni wa rí i dájú pé ìmọ̀ nipa ìfẹ́-inú ati awọn ète rẹ̀ wà lárọ̀ọ́wọ́tó fún awọn wọnnì tí wọn fẹ́ lati mọ̀ nipa irú nǹkan bẹ́ẹ̀. Níti tòótọ́, Jehofa sọ fún wa ní èdè tí ó ṣe kedere pé ìfẹ́-inú oun ni pé kí gbogbo onírúurú ènìyàn kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ rẹ̀ kí wọn sì “wá sí ìmọ̀ pípéye nipa òtítọ́.” (1 Timoteu 2:​3, 4, NW; Owe 1:​5, 20-⁠33) Èyí jẹ́ ọ̀kan lára awọn ohun ṣíṣe pàtàkì jùlọ tí a lè fi ìgbésí-ayé wa ṣe. Ó jẹ́ ìpèníjà kan tí a gbọ́dọ̀ dojúkọ. Awọn Kristian ìjímìjí lóye èyí. A sún ọ̀kan ninu wọn lati sọ pé: “Èyí sí ni ohun tí mo ń ba a lọ ní gbígbàdúrà, pé kí ìfẹ́ yín lè túbọ̀ máa pọ̀ gidigidi síwájú ati síwájú pẹlu ìmọ̀ pípéye ati ìfòyemọ̀ kíkún; pé kí ẹ lè máa wádìí dájú awọn ohun tí ó ṣe pàtàkì jù.”​—⁠Filippi 1:​9, 10, NW; Kolosse 1:​9, 10.

Bibeli ni ọ̀nà tí ó gbapò iwájú jùlọ tí Ẹlẹ́dàá fi ń ta àtaré ìfẹ́-inú ati ète rẹ̀ sí ìdílé ènìyàn, ó sì ṣàlàyé bí awa lẹ́nìkọ̀ọ̀kan ṣe bá ète yẹn mu. Àkọsílẹ̀ awọn ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀ kọjá wà ninu rẹ̀, ó sì fúnni ní àwòrán ṣíṣe kedere nipa ọjọ́ ọ̀la. Bibeli ṣètòlẹ́sẹẹsẹ awọn ẹ̀kọ́ ìgbàgbọ́ títọ̀nà ó sì là wá lọ́yẹ̀ nipa ohun tí ó yẹ kí a gbàgbọ́ tabi tí kò yẹ kí a gbàgbọ́. (Iṣe 17:11; 2 Timoteu 3:​16, 17) Ó pèsè awọn ìlànà ìwàhíhù tí awọn ènìyàn gbọ́dọ̀ gbé ní ìbámu pẹlu rẹ̀, ó sì darí awọn ènìyàn sí ọ̀nà tí wọn fi lè ṣàṣeyọrísírere kí wọn sì láyọ̀. (Matteu, orí 5 sí 7) Ó tẹnumọ́ Ìjọba Ọlọrun gẹ́gẹ́ bí ìrètí kanṣoṣo fún gbogbo aráyé ó sì fihàn bí àkóso rẹ̀ ṣe jẹ́ irinṣẹ́ lati sọ orúkọ rẹ̀ di mímọ́ kí ó sì dá ipò ọba aláṣẹ rẹ̀ láre. Bibeli ṣàlàyé ipa ọ̀nà tí ó yẹ kí a tọ̀ kí a lè gbádùn ipò-ìbátan onífẹ̀ẹ́ pẹlu Jehofa, Olùfúnni-Ní-Ìyè wa.

Síwájú síi, Bibeli jẹ́ ìwé kanṣoṣo tí ó lè ṣamọ̀nà rẹ lọ síbi ẹ̀bùn títóbi jùlọ tí ènìyàn yoo gbà rí​—⁠ìyè àìnípẹ̀kun ninu paradise lórí ilẹ̀-ayé gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá ènìyàn pípé. (Romu 6:23) Ọmọkùnrin bíbí-kanṣoṣo ti Jehofa sọ fún wa pé: “Èyí túmọ̀ sí ìyè àìnípẹ̀kun, gbígbà tí wọ́n bá ń gba ìmọ̀ iwọ, Ọlọrun tòótọ́ kanṣoṣo naa sínú, ati ti ẹni naa tí iwọ rán jáde, Jesu Kristi.” (Johannu 17:3, NW) Dájúdájú ìwé kan tí ìníyelórí rẹ̀ ga tóbẹ́ẹ̀ níláti sún wa lati kọ́ nipa ohun tí a gbọ́dọ̀ ṣe lati jèrè ẹ̀bùn ìyè àìnípẹ̀kun. Bibeli jẹ́ ìwé kan tí ó yẹ kí a lóye rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ tí ó tẹ̀lé e yoo ti fihàn.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́