ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 11/95 ojú ìwé 8
  • Gbogbo Ìwé Mímọ́ Ni Ó Ṣàǹfààní fún Kíkọ́ni

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Gbogbo Ìwé Mímọ́ Ni Ó Ṣàǹfààní fún Kíkọ́ni
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1995
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Fífi Ìwé Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun Lọni
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1997
  • Àwọn Ọ̀nà Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Tá A Dámọ̀ràn fún Lílò Lóde Ẹ̀rí
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2005
  • Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Ń Pèsè Ìtọ́sọ́nà
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1996
  • Bá A Ṣe Lè Lo Ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni Láti Wàásù
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2006
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1995
km 11/95 ojú ìwé 8

Gbogbo Ìwé Mímọ́ Ni Ó Ṣàǹfààní fún Kíkọ́ni

1 Ọ̀pọ̀ èrò yíyàtọ̀ síra ni ó wà nípa ìníyelórí Bibeli. Bí ó ti wù kí ó rí, ó dá wa lójú pé, ìdáhùn sí àwọn ìṣòro aráyé tí ń pinni lẹ́mìí, ní àfikún sí ìtọ́ni tí ó ṣeé gbára lé fún ìgbésẹ̀ ara ẹni wa nínú ìgbésí ayé, ń bẹ nínú rẹ̀. (Owe 3:5, 6) Ọgbọ́n tí ń bẹ nínú ìmọ̀ràn rẹ̀ kò láfiwé. Àwọn ìlànà ìwà rere tí ó gbé lárugẹ kò lọ́gàá. Ìhìn iṣẹ́ rẹ̀ lágbára, “ó sì lè fi òye mọ ìrònú ati awọn ìpètepèrò ọkàn-àyà.” (Heb. 4:12) Báwo ni a ṣe lè jẹ́ kí ìwé yìí tẹ àwọn ènìyàn lọ́wọ́, kí wọ́n baà lè fún un ní àyẹ̀wò kínníkínní? O lè fẹ́ láti gbìyànjú díẹ̀ lára àwọn àbá tí ó tẹ̀ lé e yìí, nígbà tí o bá ń fi Ìwé Mímọ́ Kristian Lédè Griki ní Ìtumọ̀ Ayé Titun lọni ní November.

2 Níwọ̀n bí ọ̀pọ̀ ènìyàn yóò ti fẹ́ láti lóye Bibeli, o lè lo ọ̀nà ìgbàyọsíni yìí:

◼ “Ìwé ìròyìn kan sọ pé: ‘Ọ̀pọ̀ Kristian kò mọ ohun púpọ̀ nípa Bibeli.’ Ẹlòmíràn sọ pé: ‘Bibeli jẹ́ ohun ìjìnlẹ̀, ìwé tí a kò lè lóye.’ Kí ni èrò rẹ? A ha lè lóye Bibeli bí?” [Jẹ́ kí ó fèsì.] Ka Joṣua 1:8, kí o sì máa bá ọ̀rọ̀ rẹ lọ báyìí: “Ó bọ́gbọ́n mu pé kí ènìyàn lóye Bibeli. Ó ṣe kókó. O lè lóye Ìwé Mímọ́ Kristian Lédè Griki nípa lílo ìtumọ̀ ayé tuntun yìí, tí ìwọ yóò rí i pé ó rọrùn láti lóye.” Fi Bibeli náà lọ̀ ọ́ fún iye tí a ń fi síta.

3 Àbá mìíràn tí o lè gbà yẹ̀ wò nìyí:

◼ “Gbogbo ìgbà tí a bá ka ìwé ìròyìn tàbí tí a bá fetí sí ìròyìn ni a máa ń gbọ́ nípa àwọn ìṣòro amúnisoríkọ́, tí ń mú wa ṣàníyàn. [Mẹ́nu kan ìṣẹ̀lẹ̀ adaniláàmú kan tí a ròyìn rẹ̀ láìpẹ́ nínú ìròyìn.] Àwọn ìṣòro wọ̀nyí yóò ha wá sí òpin nígbà kankan bí? [Jẹ́ kí ó fèsì.] Jẹ́ kí n fi ìdí tí a fi lè gbára lé Bibeli hàn ọ́.” Fi àwọn kókó pàtàkì tí ó wà nínú ìwé àṣàrò kúkúrú náà, Idi Tí O Fi Lè Gbẹkẹle Bibeli, hàn án. Yọ̀ọ̀da láti padà wá jíròrò bí ó ti ṣe kàmàmà tó pé àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bibeli ń ní ìmúṣẹ nínú àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí ń ṣẹlẹ̀ ní lọ́ọ́lọ́ọ́ nínú ayé.

4 Níwọ̀n bí ọ̀pọ̀ ti mọ̀ nípa àwọn iṣẹ́ ìyanu Jesu, o lè gbìyànjú ọ̀nà ìgbàyọsíni yìí:

◼ “Ọ̀pọ̀ ènìyàn mọ̀ nípa àwọn iṣẹ́ ìyanu tí Jesu ṣe nígbà iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé. Ṣùgbọ́n, a ha lè rí ẹ̀kọ́ kọ́ láti inú àwọn iṣẹ́ ìyanu wọ̀nyí bí?” [Jẹ́ kí ó fèsì.] Ka Matteu 15:30, 31. Ṣàlàyé pé, àwọn iṣẹ́ ìyanu Jesu kọjá fífi agbára dárà. Wọ́n ń rọni láti ṣe rere, láti fi ẹ̀mí ọ̀làwọ́ hàn, àti láti fi ìyọ́nú hàn. Jù bẹ́ẹ̀ lọ, wọ́n jẹ́ àpẹẹrẹ àwọn ohun tí yóò ṣàṣeparí rẹ̀ nínú Ìṣàkóso Ẹlẹ́gbẹ̀rún Ọdún rẹ̀. Fi Ìwé Mímọ́ Kristian Lédè Griki ní Ìtumọ̀ Ayé Titun lọ̀ ọ́, fún iye tí a ń fi síta, kí o sì yọ̀ọ̀da láti padà wá fún ìjíròrò síwájú sí i.

5 Atóbilọ́lá Olùkọ́ wa ti rí sí i pé ìmọ̀ nípa ìfẹ́ inú rẹ̀ wà nítòsí fún gbogbo ẹni tí ó bá fẹ́ mọ̀ ọ́n. Ríran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ láti mọrírì ìníyelórí tòótọ́ tí Bibeli ní, jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ohun tí ó dára jù lọ tí a lè ṣe láti ràn wọ́n lọ́wọ́; ó lè gba ẹ̀mí wọn là.—Owe 1:32, 33.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́