Ran Àwọn Ẹlòmíràn Lọ́wọ́ Láti Mọrírì Ìníyelórí Bibeli
1 Jesu pèsè àwọn ohun tí àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ nílò. Luku 24:45 ròyìn pé: “Ó ṣí èrò-inú wọn payá lẹ́kùn-ún-rẹ́rẹ́ lati mòye ìtúmọ̀ Ìwé Mímọ́.” Ó mọ̀ pé, bí wọn yóò bá rí ojú rere Bàbá òun, ó ṣe kókó fún wọn láti kẹ́kọ̀ọ́, kí wọ́n sì lóye Bibeli, Ọ̀rọ̀ Ọlọrun. (Orin Da. 1:1, 2) Ète kan náà ni iṣẹ́ ìwàásù wa ní. Góńgó wa jẹ́ láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli, níbi tí a ti lè ‘kọ́ àwọn ènìyàn lati máa pa gbogbo ohun tí Jesu ti paláṣẹ mọ́.’ (Matt. 28:20) Pẹ̀lú èyí lọ́kàn, àwọn ohun tí ó tẹ̀ lé e yìí jẹ́ àbá díẹ̀ lórí àwọn ohun tí ó lè ṣèrànwọ́, nígbà tí o bá ń lọ ṣe ìpadàbẹ̀wò.
2 Bí o bá ka Joṣua 1:8 nígbà ìkésíni rẹ àkọ́kọ́, o lè mú ìjíròrò rẹ tẹ̀ síwájú ní ọ̀nà yìí:
◼ “Mo padà wá láti ṣàjọpín àwọn èrò díẹ̀ síwájú sí i lórí ìdí tí a fi sọ fún Joṣua láti ka Bibeli lójoojúmọ́, pẹ̀lú rẹ. Ìdáhùn sí èyí tí ó pọ̀ jù lọ lára ìṣòro tí ń pinni lẹ́mìí, tí ènìyàn dojú kọ tàbí tí yóò dojú kọ, ń bẹ nínú Bibeli. Ìgbéṣẹ́ ìmọ̀ràn rẹ̀ kò láfiwé. Ìhìn iṣẹ́ rẹ̀ lágbára, ó sì ṣàǹfààní. Ṣùgbọ́n, o ha rò pé, Bibeli nawọ́ ìrètí amọ́kànyọ̀, tí ó wà pẹ́ títí kankan, sí wa bí?” Ka Johannu 17:3 láti inú ìtumọ̀ ayé tuntun, kí o sì tẹnu mọ́ ìdí láti ní ìmọ̀ pípéye. Ṣètò láti padà wá fún Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli inú ilé, tí a ń ṣe déédéé.
3 Bí o bá bá ẹnì kan tí ó fi ìfẹ́ hàn nínú Bibeli sọ̀rọ̀, ó ṣeé ṣe kí ọ̀nà ìgbàyọsíni yìí gbéṣẹ́ ní bíbẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́:
◼ “Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo ẹni tí o bá bá sọ̀rọ̀ ni yóò sọ fún ọ pé, àwọn ń fẹ́ láti gbé nínú ayé alálàáfíà àti aláìléwu. Bí ó bá jẹ́ ohun tí gbogbo ènìyàn ń fẹ́ nìyẹn, èé ṣe tí a fi ní ayé tí ó kún fún wàhálà àti ìwà ipá tí ó pọ̀ tó bẹ́ẹ̀? [Jẹ́ kí ó fèsì.] Ìwé Mímọ́ Kristian Lédè Griki ní Ìtumọ̀ Ayé Titun fi ibi tí o ti lè rí ìdáhùn sí ìbéèrè náà nínú Bibeli hàn ọ́.” Ṣí i sí ojú ìwé 475, kí o sì tọ́ka sí “Awọn Àkòrí Ọ̀rọ̀ Bibeli fún Ìjíròrò” nọmba 31a: “Ẹni tí ó ń fa wàhálà ayé.” Ka 2 Korinti 4:4. Ṣàlàyé bí Ọlọrun yóò ṣe pa Eṣu run, tí yóò sì mú ayé alálàáfíà àti ayọ̀ pípẹ́ títí láé wá. Ka Ìṣípayá 21:3, 4. O lè sọ lẹ́yìn náà pé: “Nígbà tí mo bá tún padà wá, n óò fẹ́ láti fi àwọn ẹsẹ ìwé mímọ́ kan, tí ó ṣàlàyé ìdí tí o fi lè fojú sọ́nà fún ayé kan tí kò sí wàhálà, hàn ọ́.”
4 Bí ìjíròrò rẹ ìṣáájú bá dá lórí àwọn ẹ̀kọ́ tí a rí kọ́ láti inú àwọn iṣẹ́ ìyanu Jesu, nígbà tí o bá padà lọ, o lè sọ pé:
◼ “Nínú ìjíròrò wa tí ó kọjá, a kẹ́kọ̀ọ́ pé, àwọn iṣẹ́ ìyanu tí Jesu Kristi ṣe jẹ́ àpẹẹrẹ àwọn ohun tí yóò ṣàṣeparí rẹ̀ nínú Ìṣàkóso Ẹlẹ́gbẹ̀rún Ọdún rẹ̀. Ó pọn dandan láti kẹ́kọ̀ọ́ láti inú Ìwé Mímọ́ bí a bá fẹ́ jàǹfààní láti inú ìṣàkóso rẹ̀. Ìsapá àtọkànwá láti ṣe èyí dáradára lè ràn wá lọ́wọ́ láti mọrírì àwọn ohun tí Ọlọrun ní nípamọ́ fún wa. [Ka Johannu 17:3.] A ti ṣètò ìtòlẹ́sẹẹsẹ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli, tí ó ti ran ẹgbẹẹgbẹ̀rún lọ́wọ́ láti túbọ̀ kẹ́kọ̀ọ́ sí i nípa ohun tí Ọlọrun ti ṣèlérí àti bí a ṣe lè ṣe ohun tí ó ń fẹ́.” Fi ìwé Walaaye Titilae hàn án, ṣàyẹ̀wò àwọn àkòrí orí ìwé, kí o sì fi bí a ti ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli hàn án.
5 Bí o bá lè ran àwọn olótìítọ́ ọkàn lọ́wọ́ láti mọrírì ìníyelórí ńláǹlà tí Ọ̀rọ̀ Ọlọrun ní, o ti ràn wọ́n lọ́wọ́ ní ọ̀nà tí ó dára jù lọ tí ó ṣeé ṣe. Ọgbọ́n tí wọ́n lè rí kọ́ láti inú kíkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ lè jẹ́ “igi ìyè,” tí yóò fún wọn láyọ̀ púpọ̀.—Owe 3:18.