Yin Jehofa Lójoojúmọ́
1 Ọlọrun wa, Jehofa, jẹ́ Ẹlẹ́dàá onífẹ̀ẹ́, àgbàyanu, Orísun gbogbo ìwàláàyè àti ayọ̀. Lójú ìwòye ìtóbilọ́lá rẹ̀, ó yẹ fún ìyìn láti ọ̀dọ̀ gbogbo àwọn ìṣẹ̀dá rẹ̀, ní tòótọ́. Lẹ́nì kọ̀ọ̀kan, a fẹ́ sọ ohun tí onipsalmu náà sọ pé: “Èmi óò . . . máa fi ìyìn kún ìyìn rẹ. Ẹnu mi yóò máa fi òdodo rẹ àti ìgbàlà rẹ hàn ní ọjọ́ gbogbo.” (Orin Da. 71:14, 15) Láti ṣe èyí, a gbọ́dọ̀ wá ọ̀nà láti yin Jehofa lójoojúmọ́, kí a sì sún wa láti sọ̀rọ̀ dáradára nípa rẹ̀, nípa òdodo rẹ̀, àti nípa ìpèsè ìgbàlà tí ó ṣe.
2 Àwọn Kristian àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ fi àpẹẹrẹ tí ó dára lélẹ̀ nínú yíyin Jehofa. Ní sísọ̀rọ̀ nípa àwọn 3,000 tí a batisí ní Pentecost, a kà ní Ìṣe 2:46, 47 pé: “Lati ọjọ́ dé ọjọ́ ni wọ́n sì ń pésẹ̀ nígbà gbogbo sí tẹmpili pẹlu ìfìmọ̀ṣọ̀kan, . . . wọ́n ń yin Ọlọrun wọ́n sì ń rí ojúrere lọ́dọ̀ gbogbo ènìyàn. . . . Jehofa [sì] ń bá a lọ lati mú awọn wọnnì tí a ń gbàlà darapọ̀ mọ́ wọn lójoojúmọ́.” Wọ́n ń kọ́ àwọn òtítọ́ àgbàyanu nípa Jehofa àti Messia rẹ̀. Ayọ̀ wọn ń gbèèràn, ó ń fún ọ̀pọ̀ sí i níṣìírí láti tẹ́tí sílẹ̀, kí wọ́n kẹ́kọ̀ọ́, kí wọ́n sì yin Jehofa.
3 Àǹfààní Ń Ṣí Sílẹ̀ Lójoojúmọ́: Lónìí, ọ̀pọ̀ ń rí i pé àwọn lè yin Jehofa lójoojúmọ́ nípa jíjẹ́rìí láìjẹ́-bí-àṣà. Ìmúrasílẹ̀ ṣáájú ń ràn wọ́n lọ́wọ́ láti túbọ̀ méso jáde. Arábìnrin kan tí ó ti pinnu láti ṣàjọpín nínú ìjẹ́rìí àìjẹ́-bí-àṣà, rí i pé ẹnì kan ti fọ́ méjì nínú gíláàsì fèrèsé ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ òun, ó sì ti jí nǹkan nínú rẹ̀. Ó pe alátùn-únṣe, ò sì múra sílẹ̀ láti jẹ́rìí fún alátùn-únṣe náà. Gbígbàdúrà fún ìdarí Jehofa wà lára ìmúrasílẹ̀ rẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí àbájáde rẹ̀, ó jẹ́rìí fún alátùn-únṣe náà fún wákàtí kan, ó sì fún un ní ìwé Walaaye Titilae.
4 Arábìnrin mìíràn máa ń ṣalábàápàdé aládùúgbò rẹ̀ kan tí wọ́n jọ máa ń kẹ́sẹ̀ rìn ní gbogbo ìgbà. Ní ìgbà kan tí wọ́n pàdé, wọ́n ní ìjíròrò jíjinlẹ̀ nípa àwọn ìṣòro ìgbésí ayé, ìyẹn sì ṣamọ̀nà sí àwọn ìjíròrò síwájú sí i. Bí àkókò ti ń lọ, ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli bẹ̀rẹ̀. Lọ́nà tí ó fani mọ́ra, aládùúgbò náà jẹ́wọ́ pé, òun kì bá tí fetí sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa, ká ní ẹnu ọ̀nà òun ni wọ́n ti wá bá òun, nítorí pé òun kò gbà gbọ́ nínú Ọlọrun tàbí Bibeli.
5 Àwọn kan máa ń ri i pé, ó ṣeé ṣe láti jẹ́rìí nígbà tí àwọn olùtajà tàbí àwọn mìíràn bá wá sí ilé wọn. Ọkùnrin kan, tí ń polówó ètò ìbánigbófò ẹ̀mí, kàn sí arábìnrin kan ní Ireland. Arábìnrin náà fi yé e pé, òun ń fojú sọ́nà fún gbígbádùn ìwàláàyè títí láé. Èrò yìí ṣàjèjì pátápátá sí ọkùnrin yìí, tí a tọ́ dàgbà gẹ́gẹ́ bíi Roman Kátólíìkì. Ó tẹ́wọ́ gba ìwé Walaaye Titilae, ó lọ sí ìpàdé ní ọ̀sẹ̀ tí ó tẹ̀ lé e, ó sì gbà láti ṣèkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli. Ọkùnrin olùtajà yìí ti di arákùnrin tí ó ti ṣe batisí nísinsìnyí.
6 Gbogbo wa gbọ́dọ̀ wà lójúfò sí àwọn àǹfààní tí ó bá ṣí sílẹ̀ láti yin Jehofa lójoojúmọ́. Ó máa ń ṣàǹfààní láti fi àwọn ìwé ìròyìn tàbí àṣàrò kúkúrú díẹ̀ síbi tí àwọn ènìyàn ti lè tètè rí i, tí a sì lè tètè fi lọ àwọn àlejò. Ó tún máa ń dára láti ní àwọn ìwé ìròyìn àti ìwé àṣàrò kúkúrú lọ́wọ́, nígbà tí a bá wọ ọkọ̀ èrò, kí a sì múra tán láti bá àwọn tí ó jókòó lẹ́gbẹ̀ẹ́ wa sọ̀rọ̀, tí ó lè yọrí sí ìjẹ́rìí. Àwọn èwe Ẹlẹ́rìí kan ní ilé ẹ̀kọ́, máa ń fi àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli sórí tábìlì wọn, pẹ̀lú ète bíbẹ̀rẹ̀ ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ pẹ̀lú ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣàkíyèsí rẹ̀, tí ó sì béèrè ìbéèrè. Ní ìtọ́kasí Ìwé Mímọ́ kan tàbí méjì tí o lè lò lọ́kàn. Gbàdúrà sí Jehofa láti ràn ọ́ lọ́wọ́. A óò bù kún ọ fún ṣíṣe bẹ́ẹ̀.—1 Joh. 5:14.