Máa Yin Jèhófà Lójoojúmọ́
1. Kí ló máa ń wu àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run láti ṣe, kí sì nìdí?
1 Ọba Dáfídì sọ pé ó wu òun láti máa yin Jèhófà “láti òwúrọ̀ ṣúlẹ̀,” àní fún àkókò tí ó lọ kánrin. (Sáàmù 145:2, 7, 21) Ọ̀pọ̀ nǹkan ló wà tó yẹ káwa náà máa torí ẹ̀ yin Jèhófà látòwúrọ̀ ṣúlẹ̀.—Sáàmù 37:10; 145:14, 18; 2 Pét. 3:13.
2. Báwo làwọn ìdílé ṣe lè máa yin Jèhófà lójoojúmọ́?
2 Nínú Ilé Wa: A ní àwọn ìwé tó ń gbéni ró tá a lè lò fún àwọn ìjíròrò tẹ̀mí tó jíire nígbà tá a bá ń ṣàyẹ̀wò ẹsẹ ojoojúmọ́, tá a bá ń ṣe Ìjọsìn Ìdílé àti nígbà tá a bá ń múra àwọn ìpàdé ìjọ sílẹ̀. Ó tiẹ̀ ti mọ́ àwọn ìdílé kan lára láti máa jẹun pa pọ̀, ó kéré tán, lẹ́ẹ̀kan lóòjọ́. Ìyẹn máa ń mú kí wọ́n sinmẹ̀dọ̀, kí wọ́n fara balẹ̀ fọ̀rọ̀ jomi toro ọ̀rọ̀, ó sì tún ń fún wọn láǹfààní láti máa yin Jèhófà. Báwọn òbí bá ń báwọn ọmọ wọn jíròrò lọ́nà yìí, á ràn wọ́n lọ́wọ́ gidigidi láti tọ́ àwọn ọmọ náà dàgbà nínú “ìbáwí àti ìlànà èrò orí Jèhófà.”—Éfé. 6:4; Diu. 6:5-7.
3. Àǹfààní wo la ní tá a bá wà pẹ̀lú àwọn ará?
3 Pẹ̀lú Àwọn Ará: Tá a bá wà lóde ẹ̀rí tàbí láwọn ìpàdé ìjọ, àǹfààní ńláǹlà máa ń ṣí sílẹ̀ fún àwa àtàwọn tá a jọ jẹ́ Kristẹni láti jùmọ̀ yin Jèhófà. (Òwe 15:30; Fílí. 4:8; Héb. 13:15) Níwọ̀n bí gbogbo wa ti nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, kò gbọ́dọ̀ ṣòro fún wa láti máa sọ̀rọ̀ ìmọrírì látọkànwá nípa oore rẹ̀ tá a bá ń bára wa sọ̀rọ̀.—Sáàmù 106:1.
4. Àwọn ọ̀nà míì wo lo lè gbà yin Jèhófà?
4 Tá A Bá Ń Bá Àwọn Tí Ẹ̀sìn Wọn Yàtọ̀ sí Tiwa Sọ̀rọ̀: Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ipò nǹkan lè ṣàì jẹ́ kó rọrùn fún wa láti máa lọ sóde ẹ̀rí lójoojúmọ́, wíwulẹ̀ sọ̀rọ̀ ṣókí nípa Jèhófà àtàwọn ète rẹ̀ fáwọn tá a jọ ń ṣiṣẹ́, àwọn ọmọléèwé wa, àtàwọn míì tá a bá bá pàdé, lè mú àwọn tó fẹ́ mọ òtítọ́ lọ́kàn le. (Sáàmù 27:14; 1 Pét. 3:15) Nígbà tí arábìnrin kan ń rìnrìn àjò nínú ọkọ̀ òfuurufú, ó wàásù fún ẹni tí wọ́n jọ wà nínú ọkọ̀ náà, ọ̀rọ̀ tí ẹni náà gbọ́ tù ú nínú ó sì fún un níṣìírí gan-an débi pé ó fún arábìnrin náà ní àdírẹ́sì àti nọ́ńbà fóònù rẹ̀, kí wọ́n lè máa kàn síra wọn. Bí wàhálà ṣe ń pọ̀ sí i nínú ayé tí ipò àwọn nǹkan sì ń burú sí i, àwọn èèyàn Jèhófà ń bá a nìṣó láti máa mú “ìhìn rere ohun tí ó dára jù” tọ àwọn tó fẹ́ gbọ́ lọ. Èyí ń mú àwọn míì lọ́kàn le ó sì ń jẹ́ kí wọ́n máa yin Jèhófà.—Aísá. 52:7; Róòmù 15:11.
5. Kí nìdí tó fi wù wá láti máa yin Jèhófà, kí sì nìyẹn lè yọrí sí?
5 Ó máa ń mú Jèhófà lọ́kàn yọ̀ gan-an bó bá ń gbọ́ báwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ṣe ń yìn ín lójoojúmọ́! Bíi tàwọn iṣẹ́ ọwọ́ Jèhófà tá a lè fojú rí ní àyíká wa, ìyìn lè máa tú jáde lẹ́nu àwa náà nínú ilé, nínú ìjọ, àti nígbà tá a bá ń báwọn míì tí ò tíì máa yin Jèhófà bíi tiwa sọ̀rọ̀.—Sáàmù 19:1-4.