ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 12/95 ojú ìwé 1
  • Múra Sílẹ̀, Kí O Sì Gbádùn Àwọn Ìpàdé Ìjọ

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Múra Sílẹ̀, Kí O Sì Gbádùn Àwọn Ìpàdé Ìjọ
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1995
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìpàdé Máa Ń Ṣe Àwọn Ọ̀dọ́ Láǹfààní
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2000
  • Ọ̀nà Wo Ló Dáa Jù Láti Gbà Múra Ìpàdé Ìjọ Sílẹ̀?
    Àwọn Wo Ló Ń Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà Lóde Òní?
  • Bá A Ṣe Lè Jàǹfààní Tó Kún Rẹ́rẹ́ Nínú Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn Pápá
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2006
  • Àwọn Ìpàdé Ń Runi Lọ́kàn Sókè sí Iṣẹ́ Àtàtà
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1997
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1995
km 12/95 ojú ìwé 1

Múra Sílẹ̀, Kí O Sì Gbádùn Àwọn Ìpàdé Ìjọ

1 Gẹ́gẹ́ bí ẹgbẹ́ ará, a máa ń fi ọgbọ́n pé jọ déédéé fún àwọn ìpàdé wa ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀. (1 Tim. 4:15, 16) Báwo ni a ṣe lè gbádùn, kí a sì jàǹfààní jù lọ nínú wọn?

2 A ní láti ya àkókò sọ́tọ̀ déédéé fún mímúra sílẹ̀ fún àwọn ìpàdé. Ó lè ṣeé ṣe fún àwọn kan láti lo àkókò tí ó pọ̀ láti múra sílẹ̀ ju àwọn mìíràn lọ. Bí ó ti wù kí ó rí, bí ó ti wù kí ọwọ́ wa dí tó, ó bọ́gbọ́n mu láti wá àkókò láti múra àwọn ìpàdé sílẹ̀. Mímúra sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìdílé ṣàǹfààní lọ́pọ̀lọpọ̀.—Efe. 5:15, 16.

3 Fún Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọrun: Sakun láti máa bá ìtòlẹ́sẹẹsẹ Bibeli kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ lọ. (Joṣ. 1:8) Ṣàyẹ̀wò àwọn àkójọpọ̀ ọ̀rọ̀ tí a óò kárí, kí o sì mú àwọn ìtẹ̀jáde tí a nílò lọ́wọ́, kí o baà lè máa fojú bá ìwé lọ pẹ̀lú olùbánisọ̀rọ̀ náà. Ronú lórí àwọn ọ̀nà tí o lè gbà lo ìsọfúnni yìí nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ.

4 Fún Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn: Yẹ ìtòlẹ́sẹẹsẹ tí a là sílẹ̀ nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa wò. Ka àwọn ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ tí a óò jíròrò. Bí a óò bá gbé ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ láti inú Ilé-Ìṣọ́nà tàbí ìtẹ̀jáde mìíràn yẹ̀ wò, wá a, kí o sì kà á. Bí a óò bá ṣàṣefihàn àwọn ìgbékalẹ̀ fún iṣẹ́ ìsìn pápá, ṣàyẹ̀wò àwọn wọ̀nyí ṣáájú, kí o baà lè ṣe tán láti lò wọ́n nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ.

5 Fún Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé-Ìṣọ́nà: Ka ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ náà ṣáájú, kíyè sí àwọn ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè náà. Yíyẹ àwọn ẹsẹ ìwé mímọ́ tí a tọ́ka sí wò yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti túbọ̀ lóye ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ náà. Ṣíṣàṣàrò lórí bí ẹ̀kọ́ náà ṣe bá ohun tí o ti mọ̀ tẹ́lẹ̀ mu, yóò mú ìmọ̀ rẹ gbòòrò sí i. Wéwèé láti kópa nínú ìkẹ́kọ̀ọ́ náà, nípa mímúra àlàyé ṣókí sílẹ̀ lórí ìpínrọ̀ kan tàbí méjì. Ọ̀nà pàtàkì kan nìyí láti sọ “ìpolongo ìrètí wa ní gbangba” di mímọ̀.—Heb. 10:23.

6 Fún Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ: Lákọ̀ọ́kọ́, yẹ àkójọpọ̀ náà wò dáradára; gbé àkòrí àti àwọn ìsọ̀rí rẹ̀ yẹ̀wò. Lẹ́yìn náà, bí o ti ń kà á, kíyè sí àwọn lájorí èrò rẹ̀. Ṣàyẹ̀wò àwọn ẹsẹ Bibeli tí a fi tì í lẹ́yìn. Gbìyànjú láti dáhùn àwọn ìbéèrè náà ní ọ̀rọ̀ tìrẹ. Lẹ́yìn tí o bá ti múra ẹ̀kọ́ náà sílẹ̀, ṣàtúnyẹ̀wò rẹ̀ nínú ọkàn rẹ. Gbìyànjú láti rántí àwọn kókó àti ọ̀nà tí a gbà gbé e kalẹ̀.—2 Tim. 2:15.

7 Gbádùn Àwọn Ìpàdé Náà: Láti lè gbádùn àwọn ìpàdé náà tẹ́rùn, ó ṣe pàtàkì láti tètè dé, kí o baà lè ṣàjọpín nínú àdúrà ìbẹ̀rẹ̀, ní bíbéèrè fún ẹ̀mí Jehofa. Ìwọ yóò tún jàǹfààní láti inú àwọn orin Ìjọba tí ń tuni lára. Bí o kò bá ní àwọn ọmọ kékeré tàbí ìdí mìíràn fún jíjókòó sí ọwọ́ ẹ̀yìn, nínú gbọ̀ngàn, dájúdájú, ìwọ yóò rí i pé, bí o bá jókòó sọ́wọ́ iwájú, kò ní fi bẹ́ẹ̀ sí ohun tí yóò pín ọkàn rẹ níyà, ìwọ yóò sì túbọ̀ jàǹfààní láti inú ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà. Àwọn òbí tí wọ́n ní àwọn ọmọ kékeré, tí wọn yóò ní láti gbé jáde nígbà tí ìpàdé bá ń lọ lọ́wọ́, lè dín pínpín ọkàn àwọn ènìyàn níyà kù, nípa jíjókòó nítòsí ẹnu ọ̀nà àti sápá ẹ̀yìn.

8 Làkàkà láti ṣí àwọn ẹsẹ ìwé mímọ́ tí a ń kà. Èyí yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti rántí ohun tí o gbọ́. Ṣíṣàjọpín ohun tí o kọ́ pẹ̀lú ìdílé àti àwọn ọ̀rẹ́ rẹ yóò tẹ ìsọfúnni náà mọ́ ọkàn rẹ. Fífi àwọn àbá wọ̀nyí sílò yóò mú kí àwọn ìpàdé túbọ̀ nítumọ̀, kí wọ́n sì túbọ̀ gbádùn mọ́ wa, wọn yóò sì ‘ru wá lọ́kàn sókè sí ìfẹ́ ati sí awọn iṣẹ́ àtàtà’ ní tòótọ́.—Heb. 10:24, 25.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́