Àwọn Ìpàdé Ń Runi Lọ́kàn Sókè sí Iṣẹ́ Àtàtà
1 Lílọ sí àwọn ìpàdé ìjọ àti nínípìn-ín nínú iṣẹ́ ìsìn pápá jẹ́ apá méjì pàtàkì nínú ìjọsìn wa. Àwọn méjèèjì jọ máa ń rìn pọ̀ ni. Ọ̀kan máa ń nípa lórí ìkejì. Àwọn ìpàdé Kristẹni ń runi lọ́kàn sókè sí iṣẹ́ àtàtà, èyí tí ó sì jẹ́ àtàtà jù lọ nínú wọn ni iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba àti sísọni di ọmọlẹ́yìn. (Héb. 10:24) Bí a bá jáwọ́ nínú lílọ sí àwọn ìpàdé, láìpẹ́, a lè ṣíwọ́ wíwàásù nítorí pé a kì yóò ru wá lọ́kàn sókè láti ṣe bẹ́ẹ̀.
2 Ní àwọn ìpàdé ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀, a máa ń gba ìtọ́ni nípa tẹ̀mí tí a pète pé kí ó sún wa láti wàásù. A ń tẹnu mọ́ ìjẹ́kánjúkánjú àwọn àkókò fún wa lemọ́lemọ́, tí ó ń sún wa láti mú ìhìn iṣẹ́ agbẹ̀mílà ti Bíbélì lọ́ sọ́dọ̀ àwọn ẹlòmíràn. A ń fún wa níṣìírí a sì ń fún wa lókun láti fara dà nínú iṣẹ́ ìwàásù náà. (Mát. 24:13, 14) Nípa lílo àǹfààní àwọn àkókò tí ó ṣí sílẹ̀ láti dáhùn ní àwọn ìpàdé, sísọ ìgbàgbọ́ wa jáde níwájú àwọn ẹlòmíràn yóò túbọ̀ mọ́ wa lára. (Héb. 10:23) Nípa fíforúkọsílẹ̀ nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọ́run, a ń gba ìdánilẹ́kọ̀ọ́ láti túbọ̀ jẹ́ òjíṣẹ́ tí ó jáfáfá kí a sì mú òye ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ wa sunwọ̀n sí i.—2 Tím. 4:2.
3 Bí Àwọn Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn Ṣe Ń Ru Wá Lọ́kàn Sókè Láti Wàásù: Gbogbo wa ni a ń fún níṣìírí láti máa ka àkójọpọ̀ ọ̀rọ̀ tí ó wà nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ṣáájú àkókò. Ìsọfúnni yìí yóò wá wọ̀ wá lọ́kàn bí a ti ń pésẹ̀ sí Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn tí a sì ń rí àwọn àṣefihàn tí a ń ṣe lórí pèpéle. Nígbà tí a bá wà nínú iṣẹ́ ìsìn pápá, a lè ronú lórí ohun ti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa sọ, kí a rántí àwọn àṣefihàn tí a ṣe, kí a sì tipa bẹ́ẹ̀ fúnni ní ìjẹ́rìí tí ó túbọ̀ gbéṣẹ́. Èyí ti jẹ́ ìrírí ọ̀pọ̀ àwọn akéde.
4 Láti ṣiṣẹ́ lórí ohun tí a gbọ́ ní Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn, àwọn kan máa ń bá àwọn mìíràn ṣàdéhùn láti jọ nípìn-ín nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́. Àwọn akéde yóò ṣì rántí àwọn kókó tí wọ́n lè lò nínú pápá, a ó sì ru wọ́n lọ́kàn sókè láti gbìyànjú wọn wò nítorí pé àwọn ìpàdé wọ̀nyí ti fún wọn níṣìírí láti nípìn-ín nínú iṣẹ́ ìwàásù lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀.—Héb. 10:25.
5 Kò sí àfidípò fún àwọn ìpàdé Kristẹni wa, níbi tí a ti ń kóra jọ pẹ̀lú àwọn ẹlẹgbẹ́ wa olùjọsìn, tí a sì ti ń ru wá lọ́kàn sókè sí àwọn iṣẹ́ àtàtà. Bí iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa yóò bá gbèrú, a ní láti máa pésẹ̀ déédéé sí àwọn ìpàdé ìjọ. Ǹjẹ́ ki a fi ìmọrírì hàn fún ìpèsè àgbàyanu yìí láti ọ̀dọ̀ Jèhófà nípa ‘ṣíṣàì máa ṣá ìpéjọpọ̀ ara wa tì.’—Héb. 10:25.