Àwọn Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn Fún December
Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní December 4
Orin 181
10 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò. Àwọn Ìfilọ̀ tí a ṣà yàn láti inú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa.
15 min: “Yin Jehofa Lójoojúmọ́.” Ìbéèrè àti ìdáhùn. Ka gbogbo ìpínrọ̀. Jẹ́ kí akéde kan tàbí méjì sọ ìrírí afúnniníṣìírí, tí wọ́n gbádùn nígbà tí wọ́n ń jẹ́rìí láìjẹ́-bí-àṣà.
20 min: “Fífi Ìwé Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí Lọni.” Alàgbà jíròrò àwọn apá fífani mọ́ra tí ó wà nínú ìwé dáradára yìí, ó sì ṣètò fún àwọn àṣefihàn kúkúrú mélòó kan, tí ń fi bí a ṣe lè lo àwọn àbá inú ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ náà, nínú pápá hàn. Rọ gbogbo àwùjọ láti ṣàjọpín lópin ọ̀sẹ̀.
Orin 224 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní December 11
Orin 201
13 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò. Ní ṣókí, ṣàyẹ̀wò àwọn ìdí tí ó fi yẹ kí a wéwèé láti ní ìpín kíkún, tí ó sì ní ìtumọ̀, nínú iṣẹ́ ìsìn pápá. Dípò lílo nǹkan bíi wákàtí kan, nígbà tí o bá jáde, èé ṣe tí o kò fi ṣètò láti lo wákàtí méjì, mẹ́ta tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ, bí ó bá ṣeé ṣe? Àṣeyọrí sábà máa ń sinmi lórí ṣíṣètò àwọn ìpadàbẹ̀wò ṣáájú àkókò, àti ṣíṣètò láti bá àwọn tí wọ́n wéwèé láti lo wákàtí méjì, mẹ́ta tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ ṣiṣẹ́.
15 min: Àwọn àìní àdúgbò. Tàbí ọ̀rọ̀ àsọyé tí a gbé karí ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ náà, “Èrè Ìtẹpẹlẹmọ́,” nínú Ilẹ́-Ìṣọ́nà ti August 1, 1995, ojú ìwé 25 sí 29.
17 min: “Múra Sílẹ̀, Kí O Sì Gbádùn Àwọn Ìpàdé Ìjọ.” Ọ̀rọ̀ àsọyé àti ìjíròrò. Ké sí akéde kan tàbí méjì láti sọ ohun tí wọ́n ṣe, tí ó ràn wọ́n lọ́wọ́ láti gbádùn àwọn ìpàdé, kí wọ́n sì jàǹfààní kíkún rẹ́rẹ́ láti inú wọn.
Orin 28 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní December 18
Orin 139
12 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò àti ìròyìn ìnáwó. Fúnni ní àbá díẹ̀ lórí bí a ṣe lè fọgbọ́n dáhùn padà sí àwọn ìkíni ọdún. Ṣèfilọ̀ àwọn ètò tí a ṣe fún ìjẹ́rìí àkànṣe ní December 25.
15 min: “Jẹ́ Kí Ìlọsíwájú Rẹ Fara Hàn Kedere.” Ìbéèrè àti ìdáhùn.
18 min: “Mímúra Sílẹ̀ fún Ìpadàbẹ̀wò Tí Ó Gbéṣẹ́.” Ìjíròrò ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn. Fi àṣefihàn kúkúrú mélòó kan kún un.
Orin 44 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní December 25
Orin 88
5 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò. Bí a óò bá yí àkókò ìpàdé yín padà ní January 1, fún gbogbo àwùjọ níṣìírí láti ti ìṣètò náà lẹ́yìn ní kíkún, nípa ṣíṣe àtúnṣebọ̀sípò tí ó yẹ. (Wo Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti December 1994, ojú ìwé 2.) Ṣèfilọ̀ àwọn ètò tí a ṣe fún ìjẹ́rìí àkànṣe ní January 1.
12 min: Ṣàtúnyẹ̀wò “Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Àpéjọ Àyíká Tuntun.”
13 min: Àpótí Ìbéèrè. Ìjíròrò lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn. Ka gbogbo ìpínrọ̀.
15 min: “Ireti—Idaabobo Ṣiṣekoko Ninu Ayé Amúnirẹ̀wẹ̀sì Kan.” Ìjíròrò ẹ̀rọ̀ ẹ̀kọ̀ inú Ilé-Ìṣọ́nà ti April 15, 1993, ojú ìwé 10.
Orin 3 àti àdúrà ìparí.