ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w94 10/1 ojú ìwé 15-20
  • Fífi Ìfẹ́ Ṣe Olùṣọ́ Àgùtàn Agbo Ọlọrun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Fífi Ìfẹ́ Ṣe Olùṣọ́ Àgùtàn Agbo Ọlọrun
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àpẹẹrẹ Olùṣọ́ Àgùtàn Rere Naa
  • Awọn Òǹrorò Olùṣọ́ Àgùtàn ní Israeli
  • Awọn Olùṣọ́ Àgùtàn Onífẹ̀ẹ́ Ninu Ìjọ Kristian
  • Bọ̀wọ̀ fún Ìlò Òmìnira Ìfẹ́-Inú
  • Ẹ̀yin Olùṣọ́ Àgùntàn, Ẹ Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Àwọn Olùṣọ́ Àgùntàn Ńlá Náà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2013
  • Ṣègbọràn sí Àwọn Olùṣọ́ Àgùntàn tí Jèhófà Yàn
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2013
  • Fifi Jẹlẹnkẹ Bojuto Awọn Agutan Ṣiṣeyebiye Ti Jehofa
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
  • “Ẹ Máa Ṣe Olùṣọ́ Àgùntàn Agbo Ọlọ́run Tí Ń bẹ Lábẹ́ Àbójútó Yín”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2011
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
w94 10/1 ojú ìwé 15-20

Fífi Ìfẹ́ Ṣe Olùṣọ́ Àgùtàn Agbo Ọlọrun

“Ẹ máa ṣe olùṣọ́ àgùtàn agbo Ọlọrun tí ń bẹ lábẹ́ àbójútó yín.” ​—⁠1 PETERU 5:⁠2, NW.

1, 2. Kí ni ànímọ́ Jehofa tí ó gba iwájú jùlọ, bawo ni ó sì ṣe fi ara rẹ̀ hàn?

LÁTÒKÈDÉLẸ̀ ninu Ìwé Mímọ́, a mú kí ó ṣe kedere pé ìfẹ́ ni àmì ànímọ́ Ọlọrun tí ó gba iwájú julọ. “Ọlọrun jẹ́ ìfẹ́,” ni ìwé 1 Johannu 4:8 (NW) wí. Níwọ̀n bí ó ti ń fi ìfẹ́ rẹ̀ hàn ninu ìṣesí, 1 Peteru 5:7 sọ pé Ọlọrun “ń ṣe ìtọ́jú yín.” Ninu Bibeli a fi ọ̀nà tí Jehofa ń gbà ṣe àbójútó awọn ènìyàn rẹ̀ wé ọ̀nà tí olùṣọ́ àgùtàn onífẹ̀ẹ́ kan ń gbà ṣe àbójútó awọn àgùtàn rẹ̀ lọ́nà jẹ̀lẹ́ńkẹ́: “Kíyèsí i, Oluwa Jehofa . . . óò bọ́ ọ̀wọ́-ẹran rẹ̀ bí olùṣọ́ àgùtàn: yoo sì fi apá rẹ̀ kó awọn ọ̀dọ́-àgùtàn, yoo sì kó wọn sí àyà rẹ̀, yoo sì rọra da awọn tí ó lóyún.” (Isaiah 40:​10, 11) Ẹ wo bí a ti tu Dafidi ninu tó tí ó fi lè sọ pé: “Oluwa ni Olùṣọ́ àgùtàn mi; emi kì yoo ṣe aláìní”!​—⁠Orin Dafidi 23:⁠1.

2 Ó ha báamu pé Bibeli fi awọn ènìyàn tí Ọlọrun fi ojúrere hàn sí wé àgùtàn, níwọ̀n bí ó ti jẹ́ pé awọn àgùtàn kìí ṣèyọnu, wọn a máa tẹríba, wọn sì jẹ́ onígbọràn sí olùṣọ́ àgùtàn wọn tí ó bìkítà. Gẹ́gẹ́ bí Olùṣọ́ Àgùtàn onífẹ̀ẹ́, Jehofa ń bìkítà délẹ̀-délẹ̀ nipa awọn ènìyàn rẹ̀ ẹni-bí-àgùtàn. Ó fi í hàn nipa pípèsè fún wọn nipa ti ara ati nipa ti ẹ̀mí ati nipa ṣíṣe amọ̀nà wọn gba inú “awọn ọjọ́ ìkẹyìn” lílekoko ti ayé búburú yii kọjá lọ sínú ayé titun òdodo rẹ̀ tí ń bọ̀.​—⁠2 Timoteu 3:​1-5, 13, NW; Matteu 6:31-⁠34; 10:28-⁠31; 2 Peteru 3:⁠13.

3. Bawo ni onipsalmu naa ṣe ṣàpèjúwe ọ̀nà tí Jehofa ń gbà ṣe àbójútó awọn àgùtàn rẹ̀?

3 Ṣàkíyèsí àbójútó onífẹ̀ẹ́ ti Jehofa fún awọn àgùtàn rẹ̀: “Ojú Oluwa ń bẹ lára awọn olódodo, etí rẹ̀ sì ṣí sí igbe wọn. . . . Awọn olódodo ń ké, Oluwa sì gbọ́, ó sì yọ wọn jáde ninu ìṣẹ́ wọn gbogbo. Oluwa ń bẹ létí ọ̀dọ̀ awọn tíí ṣe oníròbìnújẹ́ ọkàn; ó sì gba irú awọn tíí ṣe onírora ọkàn là. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni ìpọ́njú olódodo; ṣugbọn Oluwa gbà á ninu wọn gbogbo.” (Orin Dafidi 34:​15-⁠19) Ẹ wo ìtùnú ńláǹlà naa tí Olùṣọ́ Àgùtàn Àgbáyé ń pèsè fún awọn ènìyàn rẹ̀ ẹni-bí-àgùtàn!

Àpẹẹrẹ Olùṣọ́ Àgùtàn Rere Naa

4. Ipa wo ni Jesu ń kó ninu ṣíṣe àbójútó agbo Ọlọrun?

4 Jesu, Ọmọkùnrin Ọlọrun, kẹ́kọ̀ọ́ dáradára lati ọ̀dọ̀ Baba rẹ̀, nitori tí Bibeli pe Jesu ní “olùṣọ́ àgùtàn rere.” (Johannu 10:​11-⁠16) Iṣẹ́-ìsìn rẹ̀ ṣíṣekókó fún agbo Ọlọrun ni a kọsílẹ̀ ninu Ìfihàn orí 7. Ní ẹsẹ 9 (NW) awọn ìránṣẹ́ Ọlọrun ní ọjọ́ tiwa ni a pè ní “ogunlọ́gọ̀ ńlá kan . . . lati inú gbogbo awọn orílẹ̀-èdè ati ẹ̀yà ati ènìyàn ati ahọ́n.” Lẹ́yìn naa ni ẹsẹ 17 (NW) sọ pé: “Ọ̀dọ́ Àgùtàn [Jesu] . . . yoo máa ṣe olùṣọ́ àgùtàn wọn, yoo sì máa fi wọ́n mọ̀nà lọ sí awọn ìsun omi ìyè. Ọlọrun yoo sì nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú wọn.” Jesu fi awọn àgùtàn Ọlọrun mọ̀nà lọ síbi omi òtítọ́ tí ń sinni lọ sí ìyè àìnípẹ̀kun. (Johannu 17:⁠3) Kíyèsi pé Jesu ni a pè ní “Ọ̀dọ́ Àgùtàn,” tí ń fi awọn ànímọ́ bíi ti àgùtàn tí oun ní hàn, bí oun ti jẹ́ àpẹẹrẹ ṣíṣe pàtàkì jùlọ ti ìtẹríba fún Ọlọrun.

5. Ìmọ̀lára wo ni Jesu ní nipa awọn ènìyàn?

5 Lórí ilẹ̀-ayé Jesu gbé láàárín awọn ènìyàn ó sì rí ipò amúnikáàánú wọn. Bawo ni ó ṣe dáhùnpadà sí ipò ọ̀ràn ìṣòro wọn? “Àánú wọn ṣe é, nitori tí àárẹ̀ mú wọn, wọ́n sì tú káàkiri bí awọn àgùtàn tí kò ní olùṣọ́.” (Matteu 9:36) Awọn àgùtàn tí kò ní olùṣọ́ àgùtàn a máa jìyà pupọ lọ́wọ́ awọn adọdẹpẹranjẹ, bí awọn àgùtàn tí wọn ni olùṣọ́ àgùtàn tí kò bìkítà ti ń jìyà. Ṣugbọn Jesu bìkítà gan-⁠an ni, nitori tí ó sọ pé: “Ẹ wá sọ́dọ̀ mi gbogbo ẹyin tí ń ṣíṣẹ̀ẹ́, tí a sì di ẹrù wúwo lé lórí, emi ó sì fi ìsinmi fún yín. Ẹ gba àjàgà mi sí ọrùn yín, kí ẹ sì máa kọ́ ẹ̀kọ́ lọ́dọ̀ mi; nitori onínú tútù ati onírẹ̀lẹ̀ ọkàn ni emi; ẹ̀yin ó sì rí ìsinmi fún ọkàn yín. Nitori àjàgà mi rọrùn, ẹrù mi sì fúyẹ́.”​—⁠Matteu 11:​28-⁠30.

6. Ìgbatẹnirò wo ni Jesu fihàn fún awọn ẹni tí a ń nilára?

6 Asọtẹ́lẹ̀ Bibeli sọtẹ́lẹ̀ pé Jesu yoo fi tìfẹ́tìfẹ́ bá awọn ènìyàn lò: “Jehofa . . . ti fi àmì òróró yàn mí . . . lati ṣe àwòtán awọn oníròbìnújẹ́ ọkàn . . . lati tu gbogbo awọn tí ń gbààwẹ̀ ninu.” (Isaiah 61:​1, 2; Luku 4:​17-⁠21) Jesu kò pẹ̀gàn awọn òtòṣì ati aláìríbátiṣé rí. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó mú Isaiah 42:3 (NW) ṣẹ pé: “Kò sí esùsú kan tí a tẹ̀fọ́ tí oun yoo rúnjégé; bí ó sì ṣe ti òwú àtùpà tí a fi ọ̀gbọ̀ ṣe tí ń jò bàìbàì, oun kì yoo fẹ́ ẹ pa.” (Fiwé Matteu 12:​17-⁠21.) Awọn tí a pọ́nlójú dàbí awọn esùsú tí a tẹ̀fọ́, wọn rí bí òwú àtùpà tí kò ní pẹ́ kú nitori àìsí epo. Ní mímọ ipò ìkáàánú wọn dájú, Jesu fi ìyọ́nú hàn fún wọn ó sì fi okun ati ìrètí kún inú wọn, ní wíwò wọn sàn nipa ti ara ati nipa ti ẹ̀mí.​—⁠Matteu 4:⁠23.

7. Níbo ni Jesu ń darí awọn ènìyàn tí wọn bá dáhùnpadà sí ìkésíni rẹ̀ sí?

7 Awọn ẹni-bí-àgùtàn dáhùnpadà sí ìkésíni Jesu ní ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ. Ìkọ́ni rẹ̀ fanilọ́kànmọ́ra gan-⁠an débi pé awọn ìjòyè òṣìṣẹ́ tí a rán wá lati mú un jábọ̀ pé: “Kò sí ẹni tí ó tíì sọ̀rọ̀ bí ọkùnrin yii rí.” (Johannu 7:46) Họ́wù, awọn alágàbàgebè aṣáájú ìsìn ṣàròyé pé: “Ẹ wo bí gbogbo ayé tí ń wọ́ tọ̀ ọ́”! (Johannu 12:19) Ṣugbọn Jesu kò fẹ́ ọlá tabi ògo fún araarẹ̀. Ó darí awọn ènìyàn sí Baba rẹ̀. Ó kọ́ wọn lati ṣiṣẹ́sin Jehofa lati inú ìfẹ́ tí wọn ní fún awọn ànímọ́ Rẹ̀ fífanimọ́ra pé: “Kí iwọ kí ó fi gbogbo àyà rẹ, ati gbogbo ọkàn rẹ, ati gbogbo agbára rẹ, ati gbogbo inú rẹ fẹ́ Oluwa Ọlọrun rẹ.”​—⁠Luku 10:​27, 28.

8. Bawo ni ìgbọràn tí awọn ènìyàn Ọlọrun ń fifún un ṣe yàtọ̀ sí èyí tí awọn ẹlòmíràn ń fi fún awọn alákòóso ayé?

8 Ògo Jehofa yọ níti pé ipò ọba-aláṣẹ àgbáyé rẹ̀ ni awọn ènìyàn ẹni-bí-àgùtàn ń ṣètìlẹ́yìn fún, nitori ìfẹ́ wọn fún un. Wọn fi tìfẹ́-inú tìfẹ́-inú yàn lati ṣiṣẹ́sìn ín nitori ìmọ̀ tí wọn ní nipa awọn ànímọ́ rẹ̀ onífẹ̀ẹ́. Ẹ sì wo bí èyí ti yàtọ̀ sí ti awọn aṣáájú ayé yii tí awọn ọmọ-abẹ́ wọn ń ṣègbọràn sí wọn kìkì lati inú ìbẹ̀rù, tabi tipátipá, tabi nitori pé wọn ní awọn ète ìsúnniṣe fífarasin kan! A kò jẹ́ sọ ohun tí a sọ nipa poopu Ṣọ́ọ̀ṣì Roman Katoliki kan láé nipa Jehofa tabi nipa Jesu pé: “Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn késáàfúlà fún un, gbogbo ènìyàn bẹ̀rù rẹ̀, kò sí ẹni tí ó fẹ́ràn rẹ̀.”​—⁠Vicars of Christ​—⁠The Dark Side of the Papacy, lati ọwọ́ Peter De Rosa.

Awọn Òǹrorò Olùṣọ́ Àgùtàn ní Israeli

9, 10. Ṣàpèjúwe awọn aṣáájú Israeli ìgbàanì ati ti ọ̀rúndún kìn-⁠ín-ní.

9 Láìdàbí Jesu, awọn aṣáájú ìsìn Israeli ní ọjọ́ rẹ̀ kò ní ìfẹ́ kankan fún awọn àgùtàn. Wọn dàbí awọn tí wọn ṣàkóso ní ilẹ̀ Israeli nipa awọn ẹni tí Jehofa sọ pé: “Ègbé ni fún awọn olùṣọ́ àgùtàn Israeli, tí ń bọ́ ara wọn, awọn olùṣọ́ àgùtàn kì bá bọ́ ọ̀wọ́-ẹran? . . . Ẹyin kò mú aláìlera lára le, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò mú èyí tí kò sàn ní ara dá, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò di èyí tí a ṣá lọ́gbẹ́, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò tún mú èyí tí a ti lé lọ padà bọ̀, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò wá èyí tí ó sọnù, ṣugbọn ipá ati ìkà ni ẹ ti fi ń ṣe àkóso wọn.”​—⁠Esekieli 34:​2-⁠4.

10 Bíi ti awọn olùṣọ́ àgùtàn olóṣèlú wọnnì, awọn aṣáájú ìsìn Ju ti ọ̀rúndún kìn-⁠ín-ní jẹ́ ọlọ́kàn líle. (Luku 11:​47-⁠52) Lati ṣàkàwé èyí, Jesu sọ nipa Ju kan tí a jàlólè, lù, tí a sì pa ni àpaàpatán lẹ́bàá ojú-ọ̀nà. Àlùfáà ọmọ Israeli kan ń kọjá lọ, ṣugbọn nígbà tí ó rí Ju naa, ó bá ẹ̀gbẹ́ òdìkejì ojú-ọ̀nà naa kọjá lọ. Ọmọ Lefi kan ṣe bẹ́ẹ̀ pẹlu. Lẹ́yìn naa ẹnìkan tí kìí ṣe ọmọ Israeli, ara Samaria kan tí a tẹ́ḿbẹ́lú, tọ̀ ọ́ wá ó sì fi àánú hàn sí òjìyà ìpalára naa. Ó di ọgbẹ́ rẹ̀, ó gbé e lé orí ẹranko kan ó gbé e lọ sí ilé-èrò, ó sì tọ́jú rẹ̀. Ó sanwó fún olùtọ́jú ilé-èrò naa ó sì wí pé oun yoo padà wá lati san iyekíye tí ó bá ṣẹ́kù.​—⁠Luku 10:​30-⁠37.

11, 12. (a) Bawo ni ìwà burúkú awọn aṣáájú ìsìn ṣe dé ògógóró rẹ̀ ní ọjọ́ Jesu? (b) Kí ni awọn ará Romu ṣe fún awọn aṣáájú ìsìn naa nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín?

11 Awọn aṣáájú ìsìn ọjọ́ Jesu níwà ìbàjẹ́ débi pé nígbà tí Jesu jí Lasaru dìde kúrò ninu ikú, olórí àlùfáà ati awọn Farisi pé ìgbìmọ̀ Sanhẹdirin jọ wọn sì wí pé: “Kí ni awa ń ṣe? nitori ọkùnrin yii [Jesu] ń ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ iṣẹ́-àmì. Bí awa bá jọ̀wọ́ rẹ̀ bẹ́ẹ̀, gbogbo ènìyàn ni yoo gbà á gbọ́: awọn ará Romu yoo sì wá gba ilẹ̀ ati orílẹ̀-èdè wa pẹlu.” (Johannu 11:​47, 48) Wọn kò bìkítà nipa awọn ohun rere tí Jesu ti ṣe fún ọkùnrin tí ó kú naa. Ipò tiwọn ni ó jẹ wọn lógún. Nitori naa “lati ọjọ́ naa lọ ni wọn ti jọ gbìmọ̀pọ̀ lati pa [Jesu].”​—⁠Johannu 11:⁠53.

12 Lati fikún ìwà burúkú wọn, nígbà naa ni olórí àlùfáà “gbìmọ̀ kí wọn lè pa Lasaru pẹlu; nitori pé nípasẹ̀ rẹ̀ ni ọ̀pọ̀ ninu awọn Ju jáde lọ, wọn sì gba Jesu gbọ́.” (Johannu 12:​10, 11) Ìsapá onímọtara-ẹni-nìkan wọn lati dáàbòbo ipò wọn jásí pàbó, nitori tí Jesu ti sọ fún wọn pé: “A fi ilé yin sílẹ̀ fún yin ní ahoro.” (Matteu 23:38) Ní ìmúṣẹ awọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn, ninu ìran yẹn awọn ará Romu wá wọ́n sì gba “ilẹ̀ ati orílẹ̀-èdè,” ati ìwàláàyè wọn pẹlu.

Awọn Olùṣọ́ Àgùtàn Onífẹ̀ẹ́ Ninu Ìjọ Kristian

13. Ta ni Jehofa ṣèlérí lati rán lati ṣe olùṣọ́ àgùtàn agbo rẹ̀?

13 Dípò awọn òǹrorò olùṣọ́ àgùtàn, onímọtara-ẹni-nìkan, Jehofa yoo gbé Olùṣọ́ Àgùtàn Rere naa, Jesu, dìde lati ṣe àbójútó agbo Rẹ̀. Ó tún ṣèlérí lati gbé awọn olùṣọ́ àgùtàn ọmọ-abẹ́ dìde lati bójútó awọn àgùtàn: “Emi óò gbé olùṣọ́ àgùtàn dìde fún wọn, tí yoo bọ́ wọn: wọn kì yoo sì bẹ̀rù mọ́.” (Jeremiah 23:⁠4) Nipa bayii, gẹ́gẹ́ bí ó ti rí ninu awọn ìjọ Kristian ti ọ̀rúndún kìn-⁠ín-ní bẹ́ẹ̀ pẹlu ni ó rí lónìí, a ń ṣe “ìyànsípò awọn àgbà ọkùnrin lati ìlú-ńlá dé ìlú-ńlá.” (Titu 1:5, NW) Ti awọn àgbà ọkùnrin nipa tẹ̀mí wọnyi tí wọn dójú ìlà awọn ohun tí Ìwé Mímọ́ béèrè fún ni lati “ṣe olùṣọ́ àgùtàn agbo Ọlọrun.”​—⁠1 Peteru 5:​2, NW; 1 Timoteu 3:​1-⁠7; Titu 1:​7-⁠9.

14, 15. (a) Ìṣarasíhùwà wo ni ó ṣòro fún awọn ọmọ-ẹ̀yìn lati mú dàgbà? (b) Kí ni Jesu ṣe lati fihàn wọn pé ìránṣẹ́ onírẹ̀lẹ̀ ọkàn ni ó yẹ kí awọn alàgbà jẹ́?

14 Ní ṣíṣe àbójútó awọn àgùtàn, awọn alàgbà, “ju gbogbo rẹ̀ lọ” gbọ́dọ̀ ní “ìfẹ́ tí ó gbóná” fún wọn. (1 Peteru 4:⁠8) Ṣugbọn awọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu níláti kọ́ nipa èyí, níwọ̀n bí iyì ati ipò ti gbà wọn lọ́kàn jù. Nitori naa nígbà tí ìyá awọn ọmọ-ẹ̀yìn méjì naa wí fún Jesu pé: “Jẹ́ kí awọn ọmọ mi méjèèjì kí ó máa jókòó, ọ̀kan ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ, ọ̀kan ní ọwọ́ òsì ní ìjọba rẹ,” awọn ọmọ-ẹ̀yìn yòókù bínú. Jesu wí fún wọn pé: “Awọn ọba Keferi a máa lo agbára lórí wọn, ati awọn ẹni-ńlá ninu wọn a máa fi ọlá tẹrí wọn ba. Ṣugbọn kì yoo rí bẹ́ẹ̀ láàárín yin: ṣugbọn ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ pọ̀ ninu yín, ẹ jẹ́ kí ó ṣe ìránṣẹ́ yín.”​—⁠Matteu 20:​20-⁠28.

15 Ní àkókò mìíràn, lẹ́yìn tí awọn ọmọ-ẹ̀yìn naa ti “ń ba ara wọn jiyàn pé, ta ni ẹni tí ó pọ̀ jù,” Jesu wí fún wọn pé: “Bí ẹnikẹ́ni bá ń fẹ́ ṣe ẹni iwájú, oun naa ni yoo ṣe ẹni ìkẹyìn gbogbo wọn, ati ìránṣẹ́ gbogbo wọn.” (Marku 9:​34, 35) Ìrẹ̀lẹ̀ èrò-inú ati ìmúratán lati ṣiṣẹ́sìn níláti di apákan àkópọ̀ ànímọ́ wọn. Síbẹ̀ awọn ọmọ-ẹ̀yìn ń báa nìṣó lati máa ní ìṣòro pẹlu awọn èròǹgbà wọnnì, nitori pé ní alẹ́ ọjọ́ naa gan-⁠an tí ó ṣáájú ikú Jesu, níbi oúnjẹ alẹ́ tí ó jẹ kẹ́yìn, “awuyewuye gbígbóná janjan kan” ṣẹlẹ̀ láàárín wọn nipa ẹni naa tí ó tóbi jùlọ! Ìyẹn wáyé bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Jesu ti fihàn wọn bí alàgbà kan ṣe gbọ́dọ̀ máa ṣiṣẹ́sin agbo; ó ti rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ ó sì ti wẹ ẹsẹ̀ wọn. Ó wí pé: “Ǹjẹ́ bí emi tíí ṣe Oluwa ati Olùkọ́ni yín bá wẹ ẹsẹ̀ yin, ó tọ́ kí ẹyin pẹlu sì máa wẹ ẹsẹ̀ ara yín. Nitori mo ti fi àpẹẹrẹ fún yin, kí ẹyin kí ó lè máa ṣe gẹ́gẹ́ bí mo ti ṣe sí yin.”​—⁠Luku 22:24, NW; Johannu 13:​14, 15.

16. Ní ọdún 1899, àlàyé wo ni Ilé-Ìṣọ́nà ṣe lórí ànímọ́ tí ó ṣe pàtàkì jùlọ fún awọn alàgbà?

16 Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ti ń fìgbà gbogbo kọ́ni pé bí ó ṣe yẹ kí awọn alàgbà rí nìyí. Ní nǹkan bí ọ̀rúndún kan sẹ́yìn, Ilé-Ìṣọ́nà ti April 1, 1899 (Gẹ̀ẹ́sì) fún awọn ọ̀rọ̀ Paulu ní 1 Korinti 13:​1-⁠8 ní àfiyèsí lẹ́yìn naa ni ó sọ pé: “Aposteli naa ṣàlàyé lọ́nà ṣíṣe kedere pé ìmọ̀ ati sísọ̀rọ̀ lọ́nà dídáṣáká níwájú gbogbo ènìyàn kọ ni awọn ìdánwò síṣekókó jùlọ, ṣugbọn pé kí ìfẹ́ yẹn wọ inú ọkàn-àyà lọ kí ó sì gbòòrò dé gbogbo apá ìgbésí-ayé, kí ó máa ṣiṣẹ́ ninu ara kíkú wa, kí ó sì máa darí rẹ̀, ni ìdánwò tòótọ́ naa​—⁠ẹ̀rí tòótọ́ naa fún ipò-ìbátan àtọ̀runwá wa. . . . Àmì ànímọ́ gbígba iwájú jùlọ naa tí a gbọ́dọ̀ retí lati rí lára olúkúlùkù ẹni tí a bá tẹ́wọ́gbà gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ ṣọ́ọ̀ṣì naa, lati ṣèránṣẹ́ ninu awọn ohun mímọ́, ju ohun gbogbo yòókù lọ níláti jẹ́ ẹ̀mí ìfẹ́.” Ó sọ pé awọn ọkùnrin tí wọn kì yoo fi ìfẹ́ ṣiṣẹ́sìn “jẹ́ eléwu olùkọ́, ó sì ṣeéṣe jùlọ kí wọn ṣeni ní ibi pupọ ju ire lọ.”​—⁠1 Korinti 8:⁠1.

17. Bawo ni Bibeli ṣe tẹnumọ́ awọn ànímọ́ tí awọn alàgbà gbọ́dọ̀ ní?

17 Nipa bayii, awọn àgbà ọkùnrin kò gbọdọ̀ “lo agbára lórí” awọn àgùtàn. (1 Peteru 5:⁠3) Kàkà bẹ́ẹ̀, tiwọn ni lati mú ipò iwájú ninu jíjẹ́ ‘onínúrere sí . . . ẹnìkínní kejì, ní fífi ìyọ́nú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ hàn.’ (Efesu 4:​32, NW) Paulu tẹnumọ́ ọn pé: “Ẹ gbé ọkàn ìyọ́nú wọ̀, ìṣeun, ìrẹ̀lẹ̀, inú tútù, ìpamọ́ra. . . . Ati borí gbogbo nǹkan wọnyi, ẹ gbé ìfẹ́ wọ̀, tíí ṣe àmùrè ìwà pípé.”​—⁠Kolosse 3:​12-⁠14.

18. (a) Àpẹẹrẹ rere wo ni Paulu fi lélẹ̀ ninu ìbálò rẹ̀ pẹlu awọn àgùtàn? (b) Èéṣe tí awọn alàgbà kò gbọdọ̀ fojú tín-⁠ín-rín àìní awọn àgùtàn?

18 Paulu kọ́ lati ṣe èyí, ní sísọ pé: “Awa ń ṣe pẹ̀lẹ́ lọ́dọ̀ yín, gẹ́gẹ́ bí abiyamọ tí ń tọ́jú awọn ọmọ oun tìkáraarẹ̀: Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ bí awa ti ní ìfẹ́ inúrere sí yìn, inú wa dùn jọjọ lati fún yin kìí ṣe ìhìnrere Ọlọrun nìkan, ṣugbọn ẹ̀mí awa tìkáraawa pẹlu, nitori tí ẹyin jẹ́ ẹni ọ̀wọ́n fún wa.” (1 Tessalonika 2:​7, 8) Ní ìbámu pẹlu ìyẹn, ó wí pé: “Ẹ máa tu awọn aláìlọ́kàn ninu, ẹ máa ran awọn aláìlera lọ́wọ́, ẹ máa mú sùúrù fún gbogbo ènìyàn.” (1 Tessalonika 5:14) Irú ìṣòro yòówù kí ó jẹ́ tí awọn àgùtàn lè mú tọ̀ wọn wá, awọn alàgbà níláti rántí Owe 21:13: “Ẹnikẹ́ni tí ó bá di etí rẹ̀ sí igbe olùpọ̀njú, oun tìkáraarẹ̀ yoo ké pẹlu: ṣugbọn a kì yoo gbọ́ ọ.”

19. Èéṣe ti awọn alàgbà onífẹ̀ẹ́ fi jẹ́ ìbùkún, bawo sì ni awọn àgùtàn ṣe ń dáhùnpadà sí irú ìfẹ́ bẹ́ẹ̀?

19 Awọn àgbà ọkùnrin tí ń fi tìfẹ́-tìfẹ́ ṣe olùṣọ́ àgùtàn agbo jẹ́ ìbùkún fún awọn àgùtàn. Isaiah 32:2 sọtẹ́lẹ̀ pé: “Ẹnìkan yoo sì jẹ́ bí ibi ìlùmọ́ kúrò lójú ẹ̀fúùfù, ati ààbò kúrò lọ́wọ́ ìjì; bí odò omi ní ibi gbígbẹ, bí òjìji àpáta ńlá ní ilẹ̀ gbígbẹ.” Ó jẹ́ ayọ̀ wa lati mọ̀ pé ọ̀pọ̀ ninu awọn alàgbà wa lónìí bá àwòrán rírẹwà ti ìtunilára yii mu. Wọn ti kọ́ lati fi ìlànà tí ó tẹ̀lé e yii sílò: “Níti ìfẹ́ ará, ẹ máa fi ìyọ́nú fẹ́ràn ara yín: níti ọlá, ẹ máa fi ẹnìkejì yin ṣáájú.” (Romu 12:10) Nígbà tí awọn alàgbà bá fi irú ìfẹ́ ati ìrẹ̀lẹ̀ ọkàn yii hàn, awọn àgùtàn ń dáhùnpadà nipa ‘bíbu ọlá fún wọn gidigidi ninu ìfẹ́ nitori iṣẹ́ wọn.’​—⁠1 Tessalonika 5:​12, 13.

Bọ̀wọ̀ fún Ìlò Òmìnira Ìfẹ́-Inú

20. Èéṣe tí awọn alàgbà fi gbọ́dọ̀ bọ̀wọ̀ fún òmìnira ìfẹ́-inú?

20 Jehofa dá ẹ̀dá ènìyàn pẹlu òmìnira ìfẹ́-inú lati ṣe awọn ìpinnu tiwọn. Nígbà tí ó jẹ́ ti awọn alàgbà lati fúnni ní ìmọ̀ràn àní kí wọn tilẹ̀ bániwí, kìí ṣe tiwọn lati tẹ́rígba ẹrù-iṣẹ́ fún ìgbésí-ayé tabi ìgbàgbọ́ ẹlòmíràn. Paulu wí pé: “Kìí ṣe nitori tí àwa jẹgàba lórí ìgbàgbọ́ yin, ṣugbọn àwa jẹ́ olùrànlọ́wọ́ ayọ̀ yín: nitori ẹ̀yin dúró nipa ìgbàgbọ́.” (2 Korinti 1:24) Bẹ́ẹ̀ni, “olúkúlùkù ni yoo ru ẹrù ti ara rẹ̀.” (Galatia 6:⁠5) Jehofa ti fún wa ní òmìnira púpọ̀ láàárín ààlà awọn òfin ati ìlànà rẹ̀. Nipa bayii awọn alàgbà gbọ́dọ̀ yẹra fún gbígbé awọn òfin kalẹ̀ nibi tí a kò bá ti tẹ awọn ìlànà Ìwé Mímọ́ lójú. Wọn sì níláti yàgò fún ìtẹ̀sí èyíkéyìí lati sọ èrò tiwọn fúnni gẹ́gẹ́ bí ohun tí a níláti gbà láìjampata tabi kí wọn jẹ́ kí ẹ̀mí ìgbéraga wọn rusókè nígbà tí ẹnìkan kò bá gbà pẹlu irú ojú-ìwòye bẹ́ẹ̀.​—⁠2 Korinti 3:17; 1 Peteru 2:⁠16.

21. Kí ni a lè rí kọ́ lati inú ìṣarasíhùwà Paulu sí Filemoni?

21 Nígbà tí a ju Paulu sẹ́wọ̀n ní Romu, ṣàkíyèsí bí ó ṣe bójútó ọ̀rọ̀ Filemoni, olówó ẹrú kan tí ó jẹ́ Kristian ní Kolosse ní Asia Minor. Ẹrú Filemoni tí ń jẹ́ Onesimu sálọ sí Romu, ó di Kristian, ó sì ń ran Paulu lọ́wọ́. Paulu kọ̀wé sí Filemoni pé: “Emi ìbá fẹ́ lati dá a dúró fún ara mi pé ní ipò rẹ kí oun lè máa bá a nìṣó ní ṣíṣe ìránṣẹ́ fún mi ninu awọn ìdè ẹ̀wọ̀n tí mo ń múmọ́ra nitori ìhìnrere. Ṣugbọn láìsí ìjọ́hẹn rẹ emi kò fẹ́ lati ṣe ohunkóhun, kí ìṣe rẹ dídára má baà jẹ́ bí ẹni pé lábẹ́ àfipáṣe, bíkòṣe lati inú ìfẹ́-àtinúwá ti iwọ fúnra rẹ.” (Filemoni 13, 14, NW) Paulu dá Onesimu padà, ní sísọ pé kí Filemoni bá a lò gẹ́gẹ́ bíi Kristian arákùnrin. Paulu mọ̀ pé agbo naa kìí ṣe ti oun; ti Ọlọrun ni. Oun kìí ṣe ọ̀gá rẹ̀ bíkòṣe ìránṣẹ́ rẹ̀. Paulu kò pàṣẹ fún Filemoni; ó bọ̀wọ̀ fún òmìnira ìfẹ́-inú rẹ̀.

22. (a) Bawo ni awọn alàgbà ṣe níláti lóye ipò wọn sí? (b) Irú ètò-àjọ wo ni Jehofa ń mú dàgbàsókè?

22 Bí ètò-àjọ Ọlọrun ti ń gbilẹ̀, awọn alàgbà pupọ síi ni a ń yànsípò. Awọn, ati awọn alàgbà tí wọn ní ìrírí jù wọn lọ, gbọ́dọ̀ lóye pé ipò wọn jẹ́ ti iṣẹ́-ìsìn tí a ń fi ìrẹ̀lẹ̀-ọkàn ṣe. Ní ọ̀nà yii, bí Ọlọrun ti ń sún ètò-àjọ rẹ̀ síhà ayé titun naa, yoo maa gbilẹ̀ nìṣó gẹ́gẹ́ bí oun ti fẹ́​—⁠létòlétò dáradára, ṣugbọn láìfi ìfẹ́ ati ìyọ́nú rúbọ nitori ìjáfáfá. Nipa bayii, ètò-àjọ rẹ̀ yoo máa báa nìṣó lati fa awọn ẹni-bí-àgùtàn mọ́ra awọn tí wọn yoo rí ẹ̀rí àrídájú pé “ohun gbogbo ni ó ń ṣiṣẹ́ pọ̀ sí rere fún awọn tí ó fẹ́ Ọlọrun.” Ìyẹn ni a níláti retí lọ́dọ̀ ètò-àjọ kan tí a fi ìfẹ́ pilẹ̀ rẹ̀, nitori pé “ìfẹ́ kì í kùnà láé.”​—⁠Romu 8:28; 1 Korinti 13:⁠8, NW.

Bawo Ni Iwọ Yoo Ṣe Dáhùn?

◻ Bawo ni Bibeli ṣe ṣàpèjúwe àbójútó Jehofa fún awọn ènìyàn rẹ̀?

◻ Ipa wo ni Jesu kó ninu ṣíṣe àbójútó agbo Ọlọrun?

◻ Àmì ànímọ́ pàtàkì wo ni awọn alàgbà gbọ́dọ̀ ní?

◻ Èéṣe tí awọn alàgbà fi gbọ́dọ̀ gba ti òmìnira ìfẹ́-inú awọn àgùtàn rò?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]

Jesu, “olùṣọ́ àgùtàn rere,” fi ìyọ́nú hàn

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]

Awọn aṣáájú ìsìn oníwà ìbàjẹ́ gbìmọ̀pọ̀ lati pa Jesu

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́