ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w94 10/1 ojú ìwé 21-25
  • Aṣálẹ̀ kan Di Ilẹ̀ Ẹlẹ́tùlójú

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Aṣálẹ̀ kan Di Ilẹ̀ Ẹlẹ́tùlójú
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ogún-Ìní Tẹ̀mí Kan
  • Ṣíṣàjọpín Ninu Iṣẹ́ Ìwàásù
  • Fífúnrúgbìn Lẹ́bàá Òkun
  • Iṣẹ́-Ìsìn tí Ń Bá A Lọ Pẹlu Alábàáṣègbéyàwó Kan
  • Bíborí Àtakò
  • Fífarada Wàhálà Lójú Òkun
  • Awọn Àtúnṣebọ̀sípò Síwájú Síi
  • Ilẹ̀ naa Ti Di Ẹlẹ́tùlójú
  • Ọkọ̀ Rì Ní Erékùṣù Kan
    Ìwé Ìtàn Bíbélì
  • Aláyọ̀ ni Ẹni Tí Jèhófà Jẹ́ Ọlọ́run Rẹ̀
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2003
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
w94 10/1 ojú ìwé 21-25

Aṣálẹ̀ kan Di Ilẹ̀ Ẹlẹ́tùlójú

GẸ́GẸ́ BÍ ARTHUR MELIN TI SỌ Ọ́

Ọjọ́ kan tí ó mọ́ kedere ní ìgbà ìrúwé ọdún 1930 ni, mo wà lórí ìdúró níbi pèpéle ìdíkọ̀ kan ní Prince Rupert, British Columbia. Bí mo ṣe ń wo ọkọ̀ ojú-omi kékeré naa tí ó wà ní ìsàlẹ̀ òkun, mo ṣe kàyéfì pé, ‘Níbo ni gbogbo omi naa gbà lọ?’ Èyí ni ìgbà àkọ́kọ́ ti emi yoo nírìírí ìgbì-òkun Ìwọ̀-Oòrùn Etíkun Pacific níbi tí ìtẹ́jú òkun ti lè lọ sílẹ̀ dé mítà méje láàárín wákàtí mẹ́fà péré. Ṣugbọn bawo ni ọ̀dọ́mọkùnrin kan tí ó dàgbà ninu ọ̀dàn ṣe wá wà ní bèbè Agbami-Òkun Pacific?

ATI késí mi lati mú àǹfààní iṣẹ́-ìsìn alákòókò kíkún mi fún Jehofa gbòòrò síi nipa dídarapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ awọn atukọ̀ tí ó wà ninu ọkọ̀ ojú-omi kékeré naa Charmian. Iṣẹ́ àyànfúnni wa jẹ́ lati ṣí ọ̀nà iṣẹ́ ìwàásù ní àgbègbè àdádó etíkun ìwọ̀ oòrùn lati Vancouver sí Alaska. Ilẹ̀ gbalasa yii ní ọ̀pọ̀ ibùsọ̀ etíkun tí ó jẹ́ tí British Columbia ninu, tí ó ti ṣaláìní awọn ògbóṣáṣá olùyin Jehofa. Kìkì ibi tí ó yàtọ̀ ni àwùjọ kéréje awọn akéde Ìjọba ní ìlú Prince Rupert.

Ara mi ti wà lọ́nà lati tètè bẹ̀rẹ̀, nitori naa bí mo ti ń sọ̀kalẹ̀ ninu ọkọ̀ oju-irin, kíámọ́sá mo doríkọ ibi pèpéle ìdíkọ̀ naa lati rí ọkọ oju-omi kékeré naa Charmian kí n sì pàdé ẹgbẹ́ awọn atukọ̀ naa, Arne ati Christina Barstad. Kò sí ẹnìkankan ninu ọkọ̀, nitori naa mo fi ibẹ̀ sílẹ̀. Nígbà tí mo padà lọ lọ́jọ́ naa, ẹ̀rù bà mi. Ó dàbí ẹni pé agbami-òkun ń gbẹ!

Ṣugbọn kí ni ó wá yọrísí iṣẹ́ àyànfúnni gbígbádùnmọ́ni yii?

Ogún-Ìní Tẹ̀mí Kan

Ìmọrírì mi fún awọn ohun tẹ̀mí bẹ̀rẹ̀ lati ilé ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Alberta, Canada. Baba mi ti rí ìwé-àṣàrò-kúkúrú kan tí Charles Taze Russell ti Zion’s Watch Tower Tract Society kọ tí ó yí ìgbésí-ayé rẹ̀ padà gidigidi. Baba bẹ̀rẹ̀ síí wàásù fún awọn aládùúgbò rẹ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé iṣẹ́ àgbẹ̀ tí ó ń ṣe ní Calmar, Alberta, ń gba àkókò. Ìyẹn jẹ́ ní ọgọ́rùn-⁠ún ọdún sẹ́yìn, ní apá ìbẹ̀rẹ̀ awọn ọdún 1890.

Inú ìdílé awọn olùbẹ̀rù Ọlọrun yii ni a bí mi sí ní February 20, 1905, ìkẹjọ ninu awọn ti wọn wá di arákùnrin ati arábìnrin mẹ́wàá nígbẹ̀yìn gbẹ́yín. Baba, ati awọn mìíràn ninu àwùjọ awọn ara Sweden yii, di alábàákẹ́gbẹ́pọ̀ pẹlu International Bible Students. Láìpẹ́ láìjìnnà, wọn kọ ibi ìpàdé kan, tí a wá pè ní Gbọ̀ngàn Ìjọba lẹ́yìn naa. Ó jẹ́ ọ̀kan lára àkọ́kọ́ irú rẹ̀ ní Canada.

Iṣẹ́ oko kò dí wa lọ́wọ́ rí lati máṣe péṣẹ̀ sí awọn ìpàdé Kristian, tí díẹ̀ lára wọn ṣe ìgbéjáde awọn ọ̀rọ̀-àsọyé lati ẹnu awọn olùbánisọ̀rọ̀ tí ń ṣèbẹ̀wò tí Watch Tower Society rán jáde. Awọn ọ̀rọ̀-àsọyé wọnyi gbin ìfẹ́-ọkàn onítara lati ṣàjọpín ninu iṣẹ́ ìwàásù sí wa ninu. Gẹ́gẹ́ bí ìyọrísí èyí, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ gbogbo awọn tí ń bẹ ninu ìdílé wa ni wọn ti fi ìdúróṣinṣin rìn ninu ìmọ́lẹ̀ òtítọ́ Bibeli.

Ṣíṣàjọpín Ninu Iṣẹ́ Ìwàásù

Ní apá ìbẹ̀rẹ̀ awọn ọdún 1920, a fún mi ní iṣẹ́ àyànfúnni ìjẹ́rìí mi àkọ́kọ́. Tèmi ni lati pín awọn ìwé ìkésíni wá síbi ọ̀rọ̀-àsọyé fún gbogbo ènìyàn lati ẹnu-ọ̀nà dé ẹnu-ọ̀nà ní ìlú-ńlá Edmonton. Bí mo ti dádúró síbẹ̀ ní ọjọ́ yẹn, mo kọ ẹ̀kọ́ kan tí ó ṣeyebíye: Gbẹ́kẹ̀lé Jehofa. (Owe 3:​5, 6, NW) Ẹ wo bí mo ti láyọ̀ tó lati ṣàṣeparí iṣẹ́ àyànfúnni àkọ́kọ́ yẹn pẹlu ìrànlọ́wọ́ Jehofa!

Ìgbẹ́kẹ̀lé mi ninu ètò-àjọ Jehofa tí ó ṣeé fojúrí ati ninu ẹgbẹ́ olùṣòtítọ́ ati ọlọ́gbọ́n-⁠inú ẹrú rẹ̀ túbọ̀ ń pọ̀ síi bí a tí ń tànmọ́lẹ̀ òye púpọ̀ síi sórí Ọ̀rọ̀ òtítọ́ rẹ̀. Ọ̀pọ̀ àṣà Kristẹndọm, bíi ayẹyẹ Keresimesi ati ọjọ́ ìbí, ni a patì. Ìgbàlà ara-ẹni kò tún gbà wá lọ́kàn mọ́; kàkà bẹ́ẹ̀, ìwàásù Ìjọba bẹ̀rẹ̀ síi gba ipò pàtàkì. Gbogbo èyí ní ipa jíjinlẹ̀ lórí ìgbésí-ayé mi. Nitori naa láìpẹ́ pupọ lẹ́yìn tí mo ti ya ìgbésí-ayé mi sí mímọ́ fún Jehofa ní April 23, 1923, mo fi iṣẹ́-òjíṣẹ́ alákòókò kíkún ṣe góńgó mi.

Ní awọn ìgbà otútù nini ti àkókò ọ̀gìnnìtìn inú ọ̀dàn, a ń fi ọkọ̀ àfẹṣinfà jẹ́rìí ní awọn agbègbè àrọ́ko. Nígbà kan rí mo lo ọ̀sẹ̀ méjì pẹlu àwùjọ kan ninu ohun tí a ń pè ní iṣẹ́ ninu ọkọ̀ àgbérìn. Awọn àkànṣe ọkọ̀ wọnyi jásí èyí tí ó gbéṣẹ́ fún jíjẹ́rìí ninu ilẹ̀ ọ̀dàn gbalasa ti awọn ará Canada. Lójú awọn ìṣòro ìṣúnná-owó, ipò ojú-ọjọ́ tí kò dára, ati ọ̀nà jíjìn lati rìn, mo tiraka lati lo ìforítì ninu iṣẹ́-òjíṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà lóòrèkóòrè ní Alberta fún nǹkan bí ọdún mẹ́ta títí di ọjọ́ mánigbàgbé yẹn ní 1930 nígbà tí a késí mi lati ṣiṣẹ́sìn ní Ìwọ̀Oòrùn Etíkun Pacific. Níwọ̀n bí n kò ti mọ ohunkóhun nipa òkun tabi ọkọ̀ ojú-omi kékeré, ìkésíni yẹn tojúsú mi.

Ó dára, kò pẹ́ lẹ́yìn tí mo dé sí Prince Rupert tí ibẹ̀ fi mọ́ mi lára pẹlu awọn alábàáṣiṣẹ́pọ̀ mi titun ninu ọkọ̀ ojú-omi kékeré naa. Arákùnrin Barstad jẹ́ atukọ̀ tí ó dáńgájíá, níwọ̀n bí ó ti ṣiṣẹ́ ẹ̀ja pípatà rí fún ọ̀pọ̀ ọdún. Ọdún mẹ́fà tí ó tẹ̀lé e jẹ́ àkókò ìwàásù kíkankíkan, ní lílọ káàkiri etíkun omi British Columbia lati Vancouver sí Alaska. Ẹ̀kọ́ mìíràn tí mo kọ́ ni pé: Máa fìgbà gbogbo tẹ́wọ́gba iṣẹ́ àyànfúnni tí ó ba ti ọ̀dọ̀ Jehofa wá, má sì ṣe fàsẹ́yìn.

Fífúnrúgbìn Lẹ́bàá Òkun

Èbúté wa àkọ́kọ́ nígbà ìrúwé ọdún 1930 yẹn ni Ketchikan, Alaska, níbi tí a kó 60 páálí ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli lọ. Fún awọn ọ̀sẹ̀ mélòókan, a ti ṣèbẹ̀wò sí gbogbo ilé tí ó wà ní Ketchikan, Wrangell, Petersburg, Juneau, Skagway, Haines, Sitka, ati awọn abúlé mìíràn tí wọn wà káàkiri. Tẹ̀lé e, a kárí gbogbo etíkun British Columbia, a sì parí rẹ̀ ṣáájú ìgbà ẹ̀rùn. Awọn ibùdó àdádó tí a ti ń gé gẹdú, awọn ibùdó tí a ti ń ṣe ẹja alágolo, abúlé awọn ará India, awọn ìletò, pẹlu awọn ahéré àdádó ati awọn adẹdò, ni a bẹ̀wò. Ní awọn ìgbà mìíràn ó máa ń nira lati kúrò lọ́dọ̀ awọn olùṣọ́ ilé-iṣẹ́ tí ń darí ọkọ òkun tí wọn dánìkanwà awọn ẹni tí ń fẹ ẹnìkan lati bá sọ̀rọ̀.

Nígbà tí ó yá, Society fún wa ní ẹ̀rọ tí ń lu àwo rẹ́kọ́ọ̀dù tí ó ṣeé gbé lọ́wọ́ ati awọn àsọyé Bibeli tí a gbohùn wọn sílẹ̀. A ń gbe iwọnyi lọ́wọ́, pẹlu awọn ìwé, Bibeli ati awọn ìwé ìròyìn. Ní ọ̀pọ̀ ìgbà a níláti gbé wọn lọ́wọ́ bí a ti ń tiraka lati rìn lórí awọn àpáta etíkun. Nígbà tí ìgbì-òkun bá rọlẹ̀, ó máa ń béèrè pé kí a wọ́ wọn kọjá lórí awọn àkàbà hẹ́gẹhẹ̀gẹ kọjá lọ síbi pèpéle ìdíkọ̀ nígbà mìíràn. Mo láyọ̀ fún títọ́ ti ara tí mo ti rí gbà nígbà tí mo wà ní ọ̀dọ́ tí mo ń ṣiṣẹ́ níbi ìdèko ní ilẹ̀ ọ̀dàn.

Ẹ̀rọ tí a ń lò fún bíbá gbogbogbòò sọ̀rọ̀ tí ó wà ninu ọkọ̀ ojú-omi kékeré wa jẹ́ irin-iṣẹ́ lílágbára kan ninu títan ìhìnrere Ìjọba naa kálẹ̀. Níwọ̀n bí omi ti ń gbé ìró naa jìnnà, awọn àsọyé naa ni a sábà máa ń gbọ́ ní ọ̀pọ̀ ibùsọ̀. Nígbà kan tí a dúró ní ibi ìyawọlẹ̀ omi àdádó kan ní Erékùsù Vancouver, a gbé àwo ọ̀kan lára awọn àsọyé Bibeli wọnyi sí i. Awọn tí ń gbé ninu lọ́hùn-⁠ún sọ fún wa ní ọjọ́ kejì pé: “Ní àná a gbọ ìwàásù kan ní tààràtà lati ọ̀run!”

Ní àkókò mìíràn tọkọtaya àgbàlagbà kan sọ pé awọn gbọ orin tí ń gbà inú ihò èéfín wọn wọlé wá. ṣugbọn nígbà tí wọn jáde síta wọn kò gbọ́ ohunkóhun. Nígbà tí wọn padà wọlé, wọn gbọ́ ìró ohùn. Kí ni ó fa ìyẹn? Tóò, nígbà tí wọn wà níta, a tí ń pààrọ̀ àwo rẹ́kọ́ọ̀dù naa. A kọ́kọ́ ń gbé orin sí i lati fa àfiyèsí awọn ènìyàn mọ́ra, ki a tó wá gbé àsọyé Bibeli síi.

Ní àkókò ìṣẹ̀lẹ̀ mìíràn síbẹ̀, nígbà tí a dúró sí erékùṣù kan láàárín abúlé awọn ará India, awọn ọmọdékùnrin ìbílẹ̀ méjì kan tukọ̀ wá lati mọ ibi tí ohùn naa ti ń wá. Awọn kan ní erékùṣù naa rò pé ohùn awọn òkú wọn tí wọn ti jí sáyé ni!

Kìí ṣe ohun tí kò wọ́pọ̀ lati fi ọgọ́rùn-⁠ún ìwé síta lóòjọ́ lọ́dọ̀ awọn wọnnì tí ń ṣiṣẹ́ ní ibi àdádó tí wọn ti ń ṣe ẹja alágolo. Láìsí ìpínyà tóbẹ́ẹ̀, wọ́n ní àkókò lati ronú nipa awọn nǹkan tẹ̀mí. Àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀ ọ̀pọ̀ lára awọn ẹni àdádó wọnyi di Ẹlẹ́rìí. Ninu ìrìn-àjò tí ó tẹ̀lé e, a fojúsọ́nà fún bíbẹ̀ wọn wò fún ‘ìṣepàṣípààrọ̀ ìṣírí.’​—⁠Romu 1:12, NW.

Iṣẹ́-Ìsìn tí Ń Bá A Lọ Pẹlu Alábàáṣègbéyàwó Kan

Ní 1931, mo fẹ àbúrò Christina Barstad, Anna. Lẹ́yìn naa a ń bá ṣíṣe aṣáájú-ọ̀nà wa lọ papọ̀ ninu ọkọ̀ ojú-omi kékeré naa a sì ti jọ gbádùn ọ̀pọ̀ awọn ìrírí tí ń mú èrè wá lati awọn ọdún wọnyi wá. Awọn ẹja àbùùbùtán, kìnnìún òkun, seali, ẹja porpoise, ìgalà, beari, ati idì jẹ́ awọn alábàákẹ́gbẹ́ wa ní òdìkejì awọn òkè gígalọ́lá, awọn ìyawọlẹ̀ omi kéékèèké, ati awọn ìyawọlẹ̀ omi píparọ́rọ́, tí igi kédárì, igi pine, ati igi firi ti Douglas pagbo yíká. Lọ́pọ̀ ìgbà ni a ń ran awọn ìgalà tí àárẹ̀ ti mú ati awọn ọmọ wọn lọ́wọ́ ninu ìgbìyànjú wọn lati wẹ̀ sọdá iṣàn omi tí ń yára kánkán kí wọn baà lè bọ́ lọ́wọ́ awọn apẹranjẹ.

Ní ọ̀sán ọjọ́ kan a gán-⁠ánní idì apárí kan tí ń fò ní bàm̀balẹ̀ sọdá omi, ó fi èékánná rẹ̀ di ẹja salmoni ńlá kan mú ṣinṣin. Ẹja naa ti tóbi jù fún un lati fà jáde pátápátá kúrò ninu omi, nitori naa idì naa forílé etíkun níbi tí ó ń wọ ẹja salmoni naa lọ. Frank Franske, mẹ́ḿbà ẹgbẹ́ awa atukọ̀ naa, rí ṣíṣeéṣe naa pé kí ó gbé e ó sì sáré gba ojú-ọ̀na etíkun naa kọjá lati pàdé idì tí àárẹ̀ ti ń mú naa ó sì dẹ́kufì mọ́ ọn tí ó fi gbé ẹja naa jù sílẹ̀. Ẹgbẹ́ awọn atukọ aṣáájú-ọ̀nà wa fi ẹja salmoni aládìídùn naa ṣe oúnjẹ alẹ́ ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ yẹn, idì naa sì tipa bẹ́ẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ ṣíṣàjọpín, àní bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé pẹlu ìlọ́tìkọ̀ ni.

Ní erékùṣù kékeré kan ní ìpẹ̀kun àríwá Erékùṣù Vancouver, tọkọtaya kan tí ń jẹ́ Thuot gba òtítọ́ Bibeli. Èyí ọkọ jẹ́ aṣetinú-ẹni, tí kò mọ̀ọ́kọ-mọ̀ọ́kà, tí ó gbọ́n tán lójú araarẹ̀ tí ó sì ti lé ní ẹni 90 ọdún, èyí aya sì ti lé ní ẹni 80 ọdún. Bí ó ti wù kí ó rí, ọkùnrin naa ní ọkàn-ìfẹ́ ninu òtítọ́ débi pé ó rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ ó sì gbà kí aya oun kọ́ oun lati kàwé. Láìpẹ́ ó ṣeéṣe fún un lati dá kẹ́kọ̀ọ́ Bibeli ati awọn ìtẹ̀jáde Society. Ní èyí tí ó dín ní ọdún mẹ́ta lẹ́yìn naa, mo láyọ̀ lati baptisi awọn méjèèjì ní ilé wọn ní erékùṣù àdádó, ní lílo ọkọ̀ ojú-omi wa tí a ń fi àjẹ̀ wà gẹ́gẹ́ bí ìkùdu ìrìbọmi!

A tún láyọ̀ lati rí ìdílé Sallis ni Powell River tí wọn dáhùnpadà sí ìhìn-iṣẹ́ Ìjọba naa. Walter ka ìwé kékeré naa War or Peace​—⁠Which? ó sì mọ̀ pé òtítọ́ ni awọn ọ̀rọ̀ inú rẹ̀ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. Ní kété lẹ́yìn naa gbogbo ìdílé naa lódindi darapọ̀ mọ́ Walter ninu òtú awọn aṣáájú-ọ̀nà ní Vancouver, níbi tí a so Charmian mọ́ ní ìgbà ẹ̀rùn. Ó jásí onítara gan-⁠an, ó sì ti fàmọ́ gbogbo ẹgbẹ́ awọn ará ní agbègbè Vancouver lati awọn ọdún wọnyi wá. Ó parí ipa-ọ̀nà ìgbésí-ayé rẹ̀ orí ilẹ̀-ayé ní 1976, ó sì fi ìdílé ńlá ti awọn Ẹlẹ́rìí sílẹ̀ ṣẹ́yìn.

Bíborí Àtakò

Awọn àwùjọ àlùfáà ní awọn abúlé awọn ará India sábà máa ń lòdìsí iṣẹ́ wa, wọ́n kà wá sí ajẹ́ranpa lórí ilẹ̀ àkóso wọn nipa tẹ̀mí. Ní Port Simpson àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì àdúgbò pàṣẹ pé kí baálẹ̀ abúlé naa ká ìṣèbẹ̀wò wá sí awọn ilé léèwọ̀. A lọ sọ́dọ̀ baálẹ̀ naa tí a sì béèrè bóyá o ronú pé àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì naa ka awọn ènìyàn rẹ̀ sí aláìmọ̀kan lati dánú rò fúnraawọn lọ́nà títọ́. A dábàá pé kí a fún awọn ènìyàn rẹ̀ ní àǹfààní lati gbọ́ ìjíròrò Ọ̀rọ̀ Ọlọrun kí wọn sì pinnu ohun tí wọn fẹ́ lati gbàgbọ́ fúnraawọn. Ìyọrísí naa ni pé: O fún wa ní ìyọ̀ǹda lati máa bá ìwàásù nìṣó ninu abúlé naa.

Baálẹ̀ abúlé mìíràn dabarú gbogbo ìgbìdánwò tí awọn mẹ́ḿbà ìgbìmọ̀ ati àwùjọ ìsìn ṣe lati dí awọn Ẹlẹ́rìí lọ́wọ́ kí wọn máṣe ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ awọn ènìyàn rẹ̀. Ó sọ pé, “Níwọ̀n ìgbà tí mo bá ṣì jẹ́ baálẹ̀, a tẹ́wọ́gba awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa níhìn-⁠ín.” Nítòótọ́, kìí ṣe ibi gbogbo ni a ti ń tẹ́wọ́gbà wá déédéé, ṣugbọn láìka àtakò sí a kò fipá mú wa rí lati fi agbègbè kan sílẹ̀. Nipa bẹ́ẹ̀ ó ṣeéṣe fún wa lati ṣàṣeparí iṣẹ́-òjíṣẹ́ wa ní gbogbo ìgbà tí a bá wakọ̀ gúnlẹ̀.

Fífarada Wàhálà Lójú Òkun

Lati awọn ọdún wọnyi wa, a dojúkọ awọn ìṣòro ìjì, ìgbì òkun, awọn àpáta tí àwòrán ìrìnnà kò fihàn, ati ní awọn ìgbà mìíràn wàhálà ẹ́ńjìnnì. Nígbà kan a sú lọ sítòsí Erékùṣù Lasqueti ju bí ó ti yẹ lọ, nǹkan bíi 160 kìlómítà sí àríwá Vancouver. A há sínú òkìtì òkúta iyùn, tí ìgbì òkun tí ń ru bọ̀ wálẹ̀ sí ká wa mọ́ ibẹ̀, tí ó sì jẹ́ pé ipò ojú ọjọ́ nìkan ni ó lè dáàbòbò wá. Bí ojú ọjọ́ bá lọ burú ni, ọkọ ojú-omi kékeré naa ìbá ti fọ́ yángá lórí awọn àpáta. Gbogbo wa sáré kọjá sórí awọn àpáta naa a sì ṣe gbogbo ohun tí a lè ṣe ninu ipò búburú naa. A jẹ oúnjẹ ọ̀sán, a lo àkókò lati ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́, a sì dúró kí ìgbì naa lọ sókè lẹ́ẹ̀kan síi.

Lójú ọ̀pọ̀ ewu ati àìrọgbọ, ó jẹ́ ìgbésí-ayé dídára, tí ó sì jẹ́ aláyọ̀. Bí ó ti wù kí ó rí, ìbí awọn ọmọkùnrin wa méjèèjì mú ìyípadà ńláǹlà wa. A ń báa lọ lati gbé ninu ọkọ̀ ojú-omi kékeré naa, ṣugbọn nígbàkigbà tí a bá ti tukọ̀ lọ jìnnà dé àríwá Odò Oona, Anna ati awọn ọmọdékùnrin naa máa ń dúró ti awọn òbí rẹ̀ níbẹ̀ nígbà tí awa yòókù yoo sì tẹ̀síwájú lọ jìnnà dé àríwá sí Alaska. Lẹ́yìn naa, nígbà tí a bá padà wá sí gúúsù, Anna ati awọn ọmọ naa yoo darapọ̀ mọ́ wa.

N kò rántí kí awọn ọmọ naa ráhùn tabi ṣàìsàn. Ní gbogbo ìgbà ni wọn ń de bẹ́líìtì ààbò, a sì máa ń so okùn mọ́ wọn nígbà mìíràn. Bẹ́ẹ̀ni, awọn àkókò díẹ̀ wà tí nǹkan le.

Awọn Àtúnṣebọ̀sípò Síwájú Síi

Ní 1936 a níláti fi Charmian sílẹ̀, mo sì wá iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ ṣe. Nígbà tí ó yá a bí ọmọkùnrin kẹta. Bí àkókò tí ń lọ, mo ra ọkọ̀ ìpẹja kan, tí kìí ṣe kìkì pé ó ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà ìgbà gbọ́ bùkátà nìkan ni ṣugbọn ó tún mú kí ó ṣeéṣe fún wa lati máa bá iṣẹ́ ìwàásù nìṣó ní etíkun.

A ṣètò ilé kan sí Erékùṣù Digby, ní òdìkejì ìyawọlẹ̀ omi lati Prince Rupert, kò sì pẹ́ lẹ́yìn naa tí a fi dá ìjọ kékeré kan sílẹ̀. Nígbà Ogun Àgbáyé II, nígbà tí a fi òfin de iṣẹ́ ìwàásù awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ní Canada, a óò wọ ọkọ̀ ojú-omi kékeré kan lọ sí Prince Rupert lẹ́yìn ààjìn òru a óò sì “ṣe ìkéde kíkankíkan” ní agbègbè ìpínlẹ̀ naa ní fífi ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ sóde ní ilé kọ̀ọ̀kan. Kò sí ẹni tí ó ròyìn awọn ìsọdá ààjìn òru naa lati lọ ṣe ìpínkiri awọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí a fòfindè rí!

Ilẹ̀ naa Ti Di Ẹlẹ́tùlójú

Ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ awọn ènìyàn púpọ̀ síi bẹ̀rẹ̀ síí darapọ̀ mọ́ awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa, nígbà tí ó sì di 1948 àìní naa fún Gbọ̀ngàn Ìjọba kan ní Prince Rupert ṣe kedere. Lẹ́yìn ríra ilé ológun kan tí ó wà ní òdìkejì èbútékọ̀ naa, a tú u palẹ̀, a fi àdìlù igi líléfòó tù wọn sọdá omi, lẹ́yìn èyí tí a fi ọkọ̀ akẹ́rù gbé wọn lọ sí ibi ìkọ́lé naa. Jehofa bùkún iṣẹ́ aláápọn wa, a sì ní Gbọ̀ngàn Ìjọba tiwa.

Ní 1956, mo padà wọnú òtú aṣáájú-ọ̀nà, Anna sì darapọ̀ mọ́ mi ní 1964. Lẹ́ẹ̀kan síi a bẹ̀rẹ̀ síí fi ọkọ ojú-omi ṣiṣẹ́ ní Etíkun Pacific. Fún awọn àkókò kan a tún ṣàjọpín ninu iṣẹ́ àyíká, ní ṣíṣèbẹ̀wò sí awọn ìjọ lati Erékùṣù Queen Charlotte níhà ìlà-oòrùn sọdá awọn òkè-ńlá lọ sí Fraser Lake, títí lọ jìnnà dé Prince George ati Mackenzie nígbà tí ó yá. Lati awọn ọdún wọnyi wá, a fi ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́, ọkọ̀ ojú-omi kékeré, ati ọkọ̀ òfúúrufú rìnrìn-àjò ẹgbẹẹgbẹ̀rún ibùsọ̀ jákèjádò Àríwá Ìwọ̀-Oòrùn Pacific.

Ní Prince Rupert a ti ń báa lọ lati gbádùn awọn ìrírí dídára ninu iṣẹ́-òjíṣẹ́ naa. Emi ati Anna ti kẹ́kọ̀ọ́ pẹlu awọn ẹnìkọ̀ọ̀kan tí wọn lọ sí Watchtower Bible School of Gilead tí wọn sì ṣiṣẹ́sìn gẹ́gẹ́ bí míṣọ́nnárì ní ilẹ̀ àjèjì lẹ́yìn naa. Ẹ wo bí ìdùnnú naa ti pọ̀ tó lati rí awọn ọmọ wa nipa tẹ̀mí tí wọn mú ìhìn-iṣẹ́ Ìjọba ṣíṣeyebíye naa lọ sí awọn ilẹ̀ jíjìnnà réré!

Awa méjèèjì ti lé ní 80 ọdún dáradára a sì ń kojú ìlera tí ń burú sí, ṣugbọn a ṣì láyọ̀ síbẹ̀ ninu iṣẹ́-ìsìn Jehofa. Awọn ẹwà ìṣẹ̀dá ti a ti rí ní Alaska ati British Columbia ń mú kí a rántí awọn ọdún aláyọ̀ tí a ṣìkẹ́. Síbẹ̀ ó ń mú ìdùnnú tí ó túbọ̀ pọ̀ síi wá lati rí aginjù aṣálẹ̀ nipa tẹ̀mí tẹ́lẹ̀rí ti agbègbè gbígbòòrò yii tí ń gbá yìn-⁠ìn pẹlu ọ̀pọ̀ ìjọ awọn olùyin Jehofa.

Ó ti mú ọkàn wa yọ̀ ní pàtàkì lati rí awọn ọmọ wa, ati awọn ọmọ wa nipa tẹ̀mí, tí wọn ń dàgbà tí wọn sì ń fi ìbùkún fún Jehofa. A láyọ̀ pé a ti kó ipa kékeré ninu ìdàgbàsókè tẹ̀mí ní apá ibí yii lórí ilẹ̀-ayé. Fún àpẹẹrẹ, Alaska ti ní ọ́fíìsì ẹ̀ka tirẹ̀ tí ń ṣe kòkáárí iṣẹ́ awọn ìjọ tí ó jú 25 lọ nísinsìnyí.

Níhìn-⁠ín ní Prince Rupert ní 1988, a ní àǹfààní ṣíṣe ìyàsímímọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba titun rírẹwà kan, ní àárín gbùngbùn ìlú-ńlá naa. Bẹ́ẹ̀ni, a láyọ̀, gẹ́gẹ́ bí Isaiah ti láyọ̀ ní sísọ pé: “Iwọ ti mú orílẹ̀-èdè bí síi, Oluwa, . . . iwọ ti di ẹni àyìnlógo: iwọ ti sún gbogbo ààlà síwájú.”​—⁠Isaiah 26:15.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]

Síṣiṣẹ́sìn ninu iṣẹ́ àyíká lati 1964 sí 1967

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]

Irú ọkọ̀ ojú-omi kékeré tí a fi ń jẹ́rìí ní agbègbè etíkun

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́