ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w03 8/1 ojú ìwé 23-27
  • Aláyọ̀ ni Ẹni Tí Jèhófà Jẹ́ Ọlọ́run Rẹ̀

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Aláyọ̀ ni Ẹni Tí Jèhófà Jẹ́ Ọlọ́run Rẹ̀
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2003
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Mo Rí Òtítọ́ Bíbélì
  • Mímú Iṣẹ́ Ìsìn Mi sí Jèhófà Gbòòrò
  • Mo Rí Inú Rere Onífẹ̀ẹ́ Jèhófà Gbà
  • Jèhófà Mú Kó Dàgbà ní Ìhà Àríwá
  • Mo Padà sí Kánádà
  • “Inú Rere Rẹ Onífẹ̀ẹ́ Sàn Ju Ìyè”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
  • Mo Gbádùn Bí Mo Ṣe Kẹ́kọ̀ọ́ Nípa Jèhófà àti Bí Mo Ṣe Ń Kọ́ Àwọn Èèyàn Nípa Ẹ̀
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2022
  • Ìpinnu Tó Tọ́ Yọrí Sí Ìbùkún Jálẹ̀ Ìgbésí Ayé Mi
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
  • Aṣálẹ̀ kan Di Ilẹ̀ Ẹlẹ́tùlójú
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2003
w03 8/1 ojú ìwé 23-27

Ìtàn Ìgbésí Ayé

Aláyọ̀ ni Ẹni Tí Jèhófà Jẹ́ Ọlọ́run Rẹ̀

GẸ́GẸ́ BÍ TOM DIDUR ṢE SỌ Ọ́

A ti rẹ́ǹtì gbọ̀ngàn ìlú. Nǹkan bí ọ̀ọ́dúnrún èèyàn là ń retí níbi àpéjọ náà nílùú Porcupine Plains, Saskatchewan ní Kánádà. Ìrì dídì bẹ̀rẹ̀ sí já bọ́ lọ́jọ́ Wednesday, nígbà tó fi máa di ọjọ́ Friday, ńṣe nibi gbogbo ṣú dùdù. Òtútù tó ń wọni lára dénú eegun ń mú gan-an. Èèyàn méjìdínlọ́gbọ̀n ló wá síbẹ̀, àwọn ọmọdé díẹ̀ wà lára wọn. Àpéjọ tí mo kọ́kọ́ lọ rèé lẹ́yìn tí mo di alábòójútó àyíká. Ẹni ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n ni mí nígbà yẹn, ara mi sì ti wà lọ́nà gan-an. Kí n tó sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ níbẹ̀ fún yín, ẹ jẹ́ kí n kọ́kọ́ ṣàlàyé bí àǹfààní iṣẹ́ ìsìn tí kò lẹ́gbẹ́ yìí ṣe tẹ̀ mí lọ́wọ́.

ÈMI lo ṣìkeje nínú ọmọ mẹ́jọ tí àwọn obí mi bí, ọkùnrin sì ni gbogbo wa. Bill lẹ̀gbọ́n pátápátá, wọ́n wá bí Metro, John, Fred, Mike àti Alex lé e. Ọdún 1925 ni wọ́n bí mi, Wally sì ni àbígbẹ̀yìn. Ibi tá à ń gbé kò jìnnà sílùú Ukraina, ní Manitoba, níbi táwọn òbí mi, Michael àti Anna Didur, ti ní oko kékeré kan. Ilé iṣẹ́ ọkọ̀ rélùwéè ni bàbá mi ti ń ṣiṣẹ́, òun ló ń bójú tó apá kan ọ̀nà ojú irin. Oko làwá ń gbé nítorí pé ilé gbági-mọ́gi tó wà láwọn ọ̀nà ojú irin tó jìnnà sáàárín ìlú kì í ṣe ibi tó bójú mu fún ẹni tó bá ní ìdílé ńlá. Bàbá kì í fi bẹ́ẹ̀ gbélé, Màmá ló sì máa ń bójú tó wa. Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, ó máa ń lọ lo ọ̀sẹ̀ kan tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ lọ́dọ̀ Bàbá, àmọ́ ó rí i dájú pé a mọ bá a ti í ṣoúnjẹ àtàwọn iṣẹ́ ilé mìíràn. Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì Gíríìkì là ń lọ, nítorí náà lára àwọn ohun tí Màmá kọ́ wa láti kékeré ni kíkọ́ àdúrà lákọ̀ọ́sórí àti ṣíṣe àwọn ààtò mìíràn.

Mo Rí Òtítọ́ Bíbélì

Lati kékeré ló ti máa ń wù mí pé kí n lóye Bíbélì. Aládùúgbò mi kan tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń wá sílé wa nígbà gbogbo ó sì máa ń ka àwọn ẹsẹ Bíbélì tó sọ nípa Ìjọba Ọlọ́run, Amágẹ́dọ́nì àti ìrètí ayé tuntun fún wa. Màmá kò nífẹ̀ẹ́ sóhun tí ọ̀gbẹ́ni náà ń sọ rárá, àmọ́ Mike àti Alex nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ rẹ̀. Kódà, ohun tí wọ́n kọ́ ló mú kí wọ́n sọ pé ẹ̀rí ọkàn àwọn kò gba àwọn láyè láti wọṣẹ́ ológun nígbà Ogun Àgbáyé Kejì. Èyí ló fà á tí wọ́n fi ju Mike sẹ́wọ̀n fúngbà díẹ̀ tí wọ́n sì fi Alex sí àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ tó wà ní Ontario. Nígbà tó ṣe, Fred àti Wally náà tẹ́wọ́ gba òtítọ́. Àmọ́ ṣá, àwọn ẹ̀gbọ́n mi ọkùnrin mẹ́ta ṣì fàáké kọ́rí. Fún odidi ọdún bíi mélòó kan ni Màmá fi ta ko òtítọ́, àmọ́ ìyàlẹ́nu ló jẹ́ fún gbogbo wa pé òun náà wá bẹ̀rẹ̀ sí sin Jèhófà nígbà tó yá. Ẹni ọdún mẹ́tàlélọ́gọ́rin ni nígbà tó ṣèrìbọmi. Ó sì kú lẹ́ni ọdún mẹ́rìndínlọ́gọ́rùn-ún. Bàbá wa náà kò ṣàtakò sí òtítọ́ títí tó fi kú.

Nígbà tí mo wà lọ́mọ ọdún mẹ́tàdínlógún, mo lọ sílùú Winnipeg láti wáṣẹ́ kí n sì tún lè wà lọ́dọ̀ àwọn tó lè kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Wọ́n fòfin de àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nígbà náà, àmọ́ wọ́n ṣì ń ṣèpàdé déédéé. Inú ilé àdáni kan ni mo ti kọ́kọ́ bá wọn ṣèpàdé. Àwọn ohun tí mo kọ́kọ́ gbọ́ ṣàjèjì sí mi gan-an nítorí pé inú ẹ̀sìn Kátólíìkì ti Gíríìkì ni wọ́n ti tọ́ mi dàgbà. Àmọ́ ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, mo bẹ̀rẹ̀ sí lóye ìdí tí ètò pé àwọn kan ni àlùfáà àwọn kan ni ọmọ ìjọ kò fi bá Ìwé Mímọ́ mu àti ìdí tí inú Ọlọ́run kò fi dùn sí báwọn àlùfáà ṣe ń ṣètìlẹ́yìn fún ogun. (Aísáyà 2:4; Mátíù 23:8-10; Róòmù 12:17, 18) Gbígbé nínú Párádísè lórí ilẹ̀ ayé jẹ́ ohun tó bọ́gbọ́n mú lójú mi ju pé kéèyàn lọ máa gbé ní ibi jíjìn kan títí ayé.

Nígbà tó sì ti wá dá mi lójú pé òtítọ́ rèé, mo ya ara mi sí mímọ́ fún Jèhófà mo sì ṣèrìbọmi nílùú Winnipeg lọ́dún 1942. Wọ́n mú òfin tí wọ́n fi de àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Kánádà kúrò lọ́dún 1943, iṣẹ́ ìwàásù sì tún bẹ̀rẹ̀ ní rẹbutu. Òtítọ́ Bíbélì náà túbọ̀ ń wọ̀ mí lọ́kàn sí i. Mo láǹfààní láti jẹ́ ìránṣẹ́ ìjọ bákan náà ni mo lọ́wọ́ nínú pípolongo àsọyé fún gbogbo èèyàn àti wíwàásù láwọn ìpínlẹ̀ tá ò yàn fúnni. Àwọn àpéjọ ńláńlá tí mo máa ń lọ ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà jẹ́ kí n tètè tẹ̀ síwájú gan-an nípa tẹ̀mí.

Mímú Iṣẹ́ Ìsìn Mi sí Jèhófà Gbòòrò

Ní 1950, mo di òjíṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà, mo sì bẹ̀rẹ̀ sí sìn gẹ́gẹ́ bí alábòójútó àyíká ní oṣù December ọdún náà. Mo láǹfààní láti gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ nítòsí Toronto, látọ̀dọ̀ Charlie Hepworth, tó jẹ́ arákùnrin onírìírí àti adúróṣinṣin. Mo tún láyọ̀ láti lo ọ̀sẹ̀ tó kẹ́yìn nínú ìdálẹ́kọ̀ọ́ mi pẹ̀lú ẹ̀gbọ́n mi Alex, tóun náà wà lẹ́nu iṣẹ́ àyíká nílùú Winnipeg.

Gẹ́gẹ́ bí mo ṣe sọ níbẹ̀rẹ̀, mi ò lè gbàgbé àpéjọ àyíká tí mo kọ́kọ́ lọ. Ara mi ò balẹ̀ pẹ̀lú bí mo ṣe ń ronú lórí bí àpéjọ náà á ṣe rí. Àmọ́ ṣá, alábòójútó àgbègbè wa, ìyẹn Arákùnrin Jack Nathan fún gbogbo wa níṣẹ́ ṣe ó sì múnú wa dùn. A ṣe ìtòlẹ́sẹẹsẹ àpéjọ náà, àwọn tá a fún níṣẹ́ sì ṣiṣẹ́ wọn. Bí ẹnì kan ṣe ń parí iṣẹ́ rẹ̀ ni ẹlòmíràn ń bẹ̀rẹ̀ tirẹ̀, a sọ ìrírí, a ṣàṣefihàn ìwàásù ilé-dé-ilé, a ṣe ti ìpadàbẹ̀wò, bẹ́ẹ̀ náà la tún ṣe àṣefihàn bá a ṣe ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. A kọ àwọn orin Ìjọba Ọlọ́run. Oúnjẹ pọ̀ rẹpẹtẹ. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ wákàtí méjì méjì là ń mu kọfí tá a sì ń jẹ ìpápánu. Àwọn kan sùn sórí bẹ́ǹṣì, àwọn kan sun orí pèpéle nígbà táwọn mìíràn sùn sílẹ̀ẹ́lẹ̀. Nígbà tó fi máa di ọjọ́ Sunday, ìrì dídì tó ń já bọ́ náà ti rọlẹ̀ díẹ̀, èyí sì jẹ́ káwọn mẹ́rìndínlọ́gọ́rùn-ún wá gbọ́ àsọyé fún gbogbo èèyàn. Ìrírí yìí kọ́ mi láti ní ìfaradà nígbà tí ipò nǹkan bá le koko.

Iṣẹ́ àyíká tún gbé mi lọ sí àríwá Alberta, British Columbia àti Yukon Territory, àwọn ilẹ̀ tí oòrùn ti ń ràn ní òrugànjọ́. Mo rìnrìn àjò gba Ọ̀nà Márosẹ̀ Alaska tó ṣe gbágungbàgun, láti Odò Dawson ní British Columbia lọ sí Whitehorse ní Yukon (tó jìn tó egbèje kìlómítà ó lé mẹ́tàdínlọ́gọ́rin), èèyàn gbọ́dọ̀ jẹ́ onípamọ́ra àti oníṣọ̀ọ́ra kó tó lè wàásù láwọn àgbègbè yìí. Òbítíbitì ìrì dídì, àwọn gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè tó ń yọ̀ àti ojú ọjọ́ to máa ń ṣú dùdù nítorí ìrì dídì tó ń fẹ́ kiri máa ń fẹ́ mú nǹkan súni.

Ìyàlẹ́nu ló jẹ́ fún mi nígbà tí mo rí bí òtítọ́ náà ṣe gbilẹ̀ dé Ìhà Àríwá Jíjìnnà Réré. Lọ́jọ́ kan báyìí, èmi àti Walter Lewkowicz lọ sí ilé kékeré kan tó wà nítòsí abúlé Lower Post ní British Columbia, lójú Ọ̀nà Márosẹ̀ Alaska nítòsí ẹnubodè Yukon. A mọ̀ pé ẹnì kan wà nínú ilé kékeré náà nítorí pé à ń rí ìtànṣán iná látojú fèrèsé kékeré ilé ọ̀hún. Nǹkan bí aago mẹ́sàn-án alẹ́ ni, a sì kanlẹ̀kùn. Ohùn ọkùnrin la gbọ́ tó ní ká wọlé, a sì ṣe bẹ́ẹ̀. Ìyàlẹ́nu ńlá gbáà ló jẹ́ fún wa nígbà tá a wọlé tá a sì rí bàbá arúgbó kan tó dùbúlẹ̀ sórí bẹ́ẹ̀dì alágbèékà tó sì ń ka ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́! Kódà, ó ní ìtẹ̀jáde tó tuntun ju èyí tá à ń pín kiri lọ pàápàá. Ó sọ pé nípasẹ̀ ìfìwéránṣẹ́ lòun fi ń ráwọn ìwé náà gbà. Nítorí pé ó ti lé ní ọjọ́ mẹ́jọ gbáko báyìí táwa ò ti sí níbi tí ìjọ wà, a ò tíì ní àwọn ìwé ìròyìn tó dé kẹ́yìn lọ́wọ́. Ọkùnrin náà sọ fún wa pé Fred Berg lorúkọ òun, pé ọjọ́ ti pẹ́ tóun ti ń gba àwọn ìwé wa àmọ́ ìgbà àkọ́kọ́ táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa wálé òun nìyẹn. Fred ò jẹ́ ká lọ lọ́jọ́ náà. A fi ọ̀pọ̀ òtítọ́ látinú Ìwé Mímọ́ hàn án a sì ṣètò pé káwọn Ẹlẹ́rìí mìíràn tí wọ́n máa ń gba àgbègbè náà kọjá lóòrèkóòrè máa dé ọ̀dọ̀ rẹ̀.

Ọ̀pọ̀ ọdún ni mo fi sìn láwọn àyíká kéékèèké mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Àwọn àyíká náà nasẹ̀ láti ìlú Grande Prairie ní Alberta, lágbègbè ìlà oòrùn títí lọ dé Kodiak, ní Alaska ní ìwọ̀ oòrùn, jíjìn rẹ̀ lé ní ẹgbẹ̀rún mẹ́ta àtààbọ̀ [3,500] kìlómítà.

Ó wú mi lórí gan-an láti rí i pé gbogbo èèyàn ni Jèhófà máa ń fi inú rere rẹ̀ onífẹ̀ẹ́ hàn sí, wọn ì báà wà láwọn àgbègbè àdádó tàbí níbòmíràn, àti pé ẹ̀mí Ọlọ́run ló máa ń sún àwọn tó bá ní ọkàn títọ́ fún ìyè àìnípẹ̀kun ṣe ohun tó bá yẹ. Ọ̀kan lára irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ ni Henry Lepine, láti ìlú Dawson City, Yukon tí wọ́n ń pè ní ìlú Dawson báyìí. Àgbègbè àdádó ni Henry ń gbé. Kódà, kò tíì kúrò lágbègbè tí wọ́n ti ń wa góòlù yìí fún ohun tó lé ní ọgọ́ta ọdún. Àmọ́, ẹ̀mí Jèhófà mú kí bàbá arúgbó tó jẹ́ ẹni ọdún mẹ́rìnlélọ́gọ́rin yìí rin ìrìn àjò tó lé ní ẹgbẹ̀jọ kìlómítà lọ sílùú Anchorage fún àpéjọ àyíká, bẹ́ẹ̀ sì rèé kò tíì lọ sípàdé ìjọ kankan rí. Ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà wú u lórí gan-an, ìfararora náà tún mú kí inú rẹ̀ dùn púpọ̀. Nígbà tí Henry padà sílùú Dawson City, ó dúró gẹ́gẹ́ bí olóòótọ́ títí tó fi kú. Ọ̀pọ̀ àwọn tó mọ Henry ló ń ṣe kàyéfì nípa ohun tó lè mú kí bàbá arúgbó yìí rin ìrìn àjò tó gùn bẹ́ẹ̀. Mímọ̀ tí wọ́n fẹ́ mọ̀dí ọ̀rọ̀ náà mú káwọn àgbàlagbà bíi mélòó kan tẹ́wọ́ gba òtítọ́. Lọ́nà kan ṣáá, Henry wàásù.

Mo Rí Inú Rere Onífẹ̀ẹ́ Jèhófà Gbà

Lọ́dún 1955, béèyàn gẹṣin nínú mi kò lè kọsẹ̀ nígbà tí mo gba ìkésíni láti wá sí kíláàsì kẹrìndínlọ́gbọ̀n ilé ẹ̀kọ́ Watchtower Bible School of Gilead. Ìdálẹ́kọ̀ọ́ yìí fún ìgbàgbọ́ mi lókun ó sì mú kí n túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà. Nígbà tí mo kẹ́kọ̀ọ́ yege, wọ́n ní kí n padà sẹ́nu iṣẹ́ àyíká ní Kánádà.

Mo sìn ní ẹkùn-ìpínlẹ̀ Ontario fún nǹkan bí ọdún kan. Ni wọ́n bá tún yànṣẹ fún mi lẹ́ẹ̀kan sí i ní ìhà Àríwá tó lẹ́wà bí òṣùmàrè. Mo ṣì lè fojú inú wo àwọn òpópó tó rí regeja, àwọn adágún omi tó jojú ní gbèsè àtàwọn òkè tó lọ salalu tí ìrì dídì sì wà lórí wọn. Nígbà ẹ̀ẹ̀rùn, ńṣe làwọn àfonífojì àti ilẹ̀ eléwéko tútù máa ń dà bíi kápẹ́ẹ̀tì tó ní oríṣiríṣi òdòdó nínú. Afẹ́fẹ́ dáradára ń bẹ níbẹ̀ omi wọn sì mọ́ lóló. Béárì, ìkookò, ẹranko moose, caribou, àtàwọn ẹranko igbó mìíràn kàn ń yan fanda kiri ni láìsí ẹnì kankan tó ń dà wọ́n láàmú.

Àmọ́ ṣá o, àwọn ìpèníjà kan wà ní Alaska —ojú ọjọ́ ò dúró sójú kan, ibẹ̀ sì tún jìnnà. Àyíká mi fẹ̀ tó ẹgbẹ̀ẹ́dógún ó lé igba kìlómítà láti ìlà oòrùn sí ìwọ̀ oòrùn. Nígbà yẹn lọ́hùn-ún, kò tíì sí ètò pé kí alábòójútó àyíká máa fi ọkọ̀ ṣe ẹsẹ̀ rìn. Àwọn ará ló máa ń yọ̀ǹda ara wọn láti fi ọkọ̀ wọn gbé mi láti ìjọ kan lọ sí òmíràn. Àmọ́ láwọn ìgbà míì, ńṣe ni mo máa juwọ́ sáwọn ọlọ́kọ̀ akẹ́rù àtàwọn arìnrìn-àjò afẹ́ pé kí wọ́n gbé mi.

Irú ìṣẹ̀lẹ̀ yìí wáyé ní Ọ̀nà Márosẹ̀ Alaska, láàárín Ìyànà Tok ní Alaska àti Mile 1202 tí wọ́n tún ń pè ní àgbègbè Scotty Creek. Ọ́fíìsì àwọn ọlọ́pàá aṣọ́bodè tó wà láàárín òpópó méjì yìí jẹ́ nǹkan bí ọgọ́jọ kìlómítà síra wọn. Mo kọjá ọ́fíìsì àwọn ọlọ́pàá aṣọ́bodè ti orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà tó wà ní Tok, ẹnì kan sì gbé mi dé nǹkan bí àádọ́ta kìlómítà. Ni ọkọ̀ kankan ò bá kọjá mọ́ o, ni mo bá fi ẹsẹ̀ rìn fún nǹkan bí wákàtí mẹ́wàá ti mo sì rin ohun tó lé ní ogójì kìlómítà. Ìgbà tó yá ni mo wá gbọ́ pé kò pẹ́ tí mo kọjá ọ̀dọ̀ àwọn ọlọ́pàá aṣọ́bodè náà làwọn ọkọ̀ ò lè kọjá mọ́ nítorí òjò yìnyín tó rọ̀ nítòsí ọ̀dọ̀ àwọn aṣọ́bodè náà. Nígbà tó fi máa di ọ̀gànjọ́ òru, òtútù àwọnilára-déegun ń mú gan-an, ibi tí mo wà síbi tó sún mọ́ jù lọ tí mo lè forí pa mọ́ sí sì tó nǹkan bí ọgọ́rin kìlómítà. Ó di dandan kí n wá ibì kan tí mo lè fara pa mọ́ sí.

Bí mo ṣe ń fọgbọọgbọ́n lọ ni mo bá tajú kán rí ọkọ̀ kan tí wọ́n fi sílẹ̀ lẹ́bàá ọ̀nà, ìrì dídì sì ti fẹ́rẹ̀ẹ́ bò ó mọ́lẹ̀ tán. Mo ronú pé tí mo bá lè wọnú ọkọ̀ náà kí n sì sùn lórí àga tìmùtìmù inú rẹ̀, òtútù òru ọjọ́ náà ò ní gbẹ̀mí mi. Mo fọgbọ́n ṣe é títí tí mo fi lè ṣílẹ̀kùn rẹ̀, àmọ́ òfurugbádá ni inú ọkọ̀ náà wà, kò sí àga kankan níbẹ̀. Àmọ́ inú mi dùn nígbà tí mo rí ahéré kan lẹ́gbẹ̀ẹ́ títì. Mo ṣe wàhálà díẹ̀ kí n tó lè wọnú ahéré náà, mo wá dáná mo sì sinmi fún wákàtí bíi mélòó kan. Nígbà tí ilẹ̀ mọ́, mo rí ẹnì kan tó gbé mi dé abúlé tó wà nítòsí, ibẹ̀ ni mo ti rí oúnjẹ jẹ ti mo sì bójú tó àwọn ọmọ-ìka ọwọ́ mi tó ti dégbò yánnayànna.

Jèhófà Mú Kó Dàgbà ní Ìhà Àríwá

Àbẹ̀wò mi àkọ́kọ́ sílùú Fairbanks wúni lórí gan-an. Iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa so èso rere níbẹ̀, nǹkan bí àádọ́ta èèyàn sì wá síbi àsọyé fún gbogbo èèyàn lọ́jọ́ Sunday. A pé jọ sínú ilé kékeré tó jẹ́ ti àwọn míṣọ́nnárì níbi tí Vernor àti Lorraine Davis ń gbé. Ńṣe làwọn èèyàn ń garùn látinú ilé ìgbọ́únjẹ, látinú iyàrá tí wọ́n ń sùn àti láti ọ̀dẹ̀dẹ̀ kí wọ́n lè gbọ́ àsọyé náà. Bí àwọn èèyàn púpọ̀ ṣe wá gbọ́ àsọyé yìí jẹ́ ká mọ̀ pé iṣẹ́ ìwàásù náà á túbọ̀ fìdí múlẹ̀ nílùú Fairbanks tí Gbọ̀ngàn Ìjọba bá wà níbẹ̀. Nítorí náà, pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Jèhófà a ra ilé alágbèéká ńlá kan, ijó ni wọ́n máa ń jó nínú rẹ̀ tẹ́lẹ̀, a sì gbé e lọ ságbègbè tó dára. A gbẹ́ kànga, a ṣe ilé ìwẹ̀ àti ibi téèyàn ti lè se omi. Láàárín ọdún kan, Gbọ̀ngàn Ìjọba tó bójú mu ti wà nílùú Fairbanks. Nígbà tó ṣe, a tún ṣe ilé ìgbọ́únjẹ kan sí i, a sì wá lo gbọ̀ngàn náà fún àpéjọ àgbègbè lọ́dún 1958, èèyàn ọ̀ọ́dúnrún àti ọgbọ̀n [330] ló wá síbẹ̀.

Nígbà ẹ̀ẹ̀rùn ọdún 1960, mo fi ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ rìnrìn àjò lọ sí orílé iṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà nílùú New York láti lọ síbi ìdálẹ́kọ̀ọ́ tí wọ́n ṣètò fún gbogbo alábòójútó arìnrìn àjò ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà àti Kánádà láti rán wọn létí àwọn ohun tí wọ́n ti kọ́ tẹ́lẹ̀. Níbẹ̀, Arákùnrin Nathan Knorr àtàwọn arákùnrin mìíràn tá a fún lẹ́rù iṣẹ́ fọ̀rọ̀ wá mi lẹ́nu wò nípa bóyá ó lè ṣeé ṣe láti kọ́ ọ́fíìsì ẹ̀ka kan sí Alaska. Ni oṣù díẹ̀ lẹ́yìn náà, inú wá dùn gan-an nígbà tá a gbọ́ pé láti September 1, 1961, Alaska náà á ní ọ́fíìsì ẹ̀ka tirẹ̀. Arákùnrin Andrew K. Wagner ni wọ́n yàn pé kó máa ṣe kòkáárí iṣẹ́ ẹ̀ka yìí. Òun àti Vera ìyàwó rẹ̀ ti sìn ní Brooklyn fún ogún ọdún bákan náà ni wọ́n tún ti ṣe iṣẹ́ arìnrìn-àjò rí. A mọrírì bí Alaska ṣe ní ẹ̀ka ọ́fíìsì yìí gan-an, nítorí pé ó dín ìrìn àjò alábòójútó àyíká kù, ó sì jẹ́ kó lè gbájú mọ́ àwọn ohun tó ń fẹ́ àbójútó nínú àwọn ìjọ àti láwọn àgbègbè àdádó.

Ńṣe làwọn èèyàn ń fi ìdùnnú ṣayọ̀ níhà Àríwá nígbà ẹ̀ẹ̀rùn ọdún 1962. Ìgbà yẹn la ya ẹ̀ka ilé iṣẹ́ wa tó wà ní Alaska sí mímọ́, a sì tún ṣe àpéjọ àgbègbè nílùú Juneau, Alaska. A kọ́ àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba tuntun sílùú Juneau àti ìlú Whitehorse ní Yukon, bẹ́ẹ̀ la tún dá àwọn àwùjọ tuntun púpọ̀ sílẹ̀ láwọn àgbègbè àdádó.

Mo Padà sí Kánádà

Láti ọdún bíi mélòó kan ni mo ti ń kọ̀wé sí Margareta Petras tó wà ní Kánádà. Reta, gẹ́gẹ́ báwọn èèyàn ṣe máa ń pè é, bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìsìn aṣáájú ọ̀nà lọ́dún 1947, ó kẹ́kọ̀ọ́ yege ní Gílíádì lọ́dún 1955 ó sì ń ṣe aṣáájú ọ̀nà ní ìhà ìlà oòrùn Kánádà. Mo sọ fún un pé mo fẹ́ fẹ́ ẹ, ó sì gbà. A ṣègbéyàwó nílùú Whitehorse ní February 1963. Bó ṣe dìgbà ìwọ́wé ọdún yẹn, wọ́n yanṣẹ́ àyíká fún mi lápá ìwọ̀ oòrùn Kánádà, a sì fi ayọ̀ sìn níbẹ̀ fún odindi ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n tó tẹ̀ lé e.

Nítorí àìlera, wọ́n yàn wá síṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà àkànṣe nílùú Winnipeg, Manitoba lọ́dún 1988. Èyí ní bíbójú tó Gbọ̀ngàn Àpéjọ kan fún nǹkan bí ọdún márùn-ún gbáko nínú. A ṣì ń nípìn-ín nínú iṣẹ́ aláyọ̀ ti sísọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn débi tí agbára wa lè gbé e dé. Nígbà tá a wà nínú iṣẹ́ àyíká, ọ̀pọ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì la bẹ̀rẹ̀ tá a sì fà lé àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ láti máa bá a lọ. Ní báyìí, pẹ̀lú inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Jèhófà, a bẹ̀rẹ̀ wọn a sì tún rí àfikún ìdùnnú ti rírí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ wọ̀nyí tí wọ́n tẹ̀ síwájú débi tí wọ́n fi ń ṣe ìyàsímímọ́ àti ìrìbọmi.

Ó dá mi lójú pé sísin Jèhófà ni ọ̀nà ìgbésí ayé tó dára jù lọ. Ó ń jẹ́ kí ìgbésí ayé nítumọ̀ kó sì dùn, bẹ́ẹ̀ ló tún ń mú kí ìfẹ́ wa fún Jèhófà máa jinlẹ̀ sí i lójoojúmọ́. Ohun tó ń fúnni láyọ̀ tòótọ́ rè é. Iṣẹ́ yòówù kí Ọlọ́run yàn fún wa tàbí ibi yòówù ká máa gbé, a gbà pẹ̀lú onísáàmù náà tó sọ pé: “Aláyọ̀ ni àwọn ènìyàn tí Jèhófà jẹ́ Ọlọ́run wọn!”—Sáàmù 144:15.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24, 25]

Ìgbà tí mò ń ṣiṣẹ́ àyíká

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]

Mo ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ Henry Lepine nílùú Dawson City. Èmi nìyẹn lọ́wọ́ òsì

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]

Gbọ̀ngàn Ìjọba àkọ́kọ́ nílùú Anchorage

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]

Èmi àti Reta ní 1998

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́