“Inú Rere Rẹ Onífẹ̀ẹ́ Sàn Ju Ìyè”
Gẹ́gẹ́ bí Calvin H. Holmes ṣe sọ ọ́
December ọdún 1930 ni, mo sì ṣẹ̀ṣẹ̀ parí fífún wàrà àwọn màlúù ni Dádì dé sílé láti ibi tí ó ti lọ ṣe ìbẹ̀wò sọ́dọ̀ aládùúgbò kan tí ó wà nítòsí. Bí ó ti fa ìtẹ̀jáde aláwọ̀ aró kan jáde láti inú àpò rẹ̀, ó wí pé: “Ìwé tí Wyman yá mi nìyí.” A pe àkọlé rẹ̀ ní Idande, tí Watch Tower Bible and Tract Society tẹ̀ jáde. Dádì, tí ó jẹ́ pé agbára káká ni ó fi ń ka ohunkóhun, ka ìwé yẹn títí di ọ̀gànjọ́.
LẸ́YÌN náà, Dádì yá àwọn ìwé mìíràn, pẹ̀lú irú àwọn àkọlé bíi Light àti Ilàjà, tí àwọn òǹṣèwé kan náà tẹ̀ jáde. Ó rí ògbólógbòó Bíbélì Màmá, ó sì ń bá a nìṣó títí di ọ̀gànjọ́ òru láti fi ìmọ́lẹ̀ àtùpà oníkẹrosín kàwé. Dádì yí pa dà gidigidi. Ní ìgbà òtútù yẹn, ó bá wa sọ̀rọ̀ fún ọ̀pọ̀ wákàtí—ìyá mi, àwọn àbúrò mi obìnrin mẹ́ta, àti èmi—bí a ti pagbo yí ògbólógbòó àdògán wa ká.
Dádì sọ pé Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ni a ń pe àwọn tí ń ṣe ìwé wọ̀nyí àti pé, bí wọ́n ṣe sọ, a ń gbé ní “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn.” (Tímótì Kejì 3:1-5) Ó ṣàlàyé pé a kì yóò pa ilẹ̀ ayé run ní òpin ayé ṣùgbọ́n pé lábẹ́ Ìjọba Ọlọ́run, a óò sọ ọ́ di párádísè kan. (Pétérù Kejì 3:5-7, 13; Ìṣípayá 21:3, 4) Ìyẹn dùn mọ́ mi gidigidi.
Dádì bẹ̀rẹ̀ síí bá mi sọ̀rọ̀ bí a ti ń ṣiṣẹ́ pa pọ̀. Mo rántí pé a ń bó èèpo ọkà ni nígbà tí ó ṣàlàyé pé Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run. (Orin Dáfídì 83:18) Nípa báyìí, nígbà ìrúwé ọdún 1931, nígbà tí mo jẹ́ ọmọ ọdún 14 péré, mo mú ìdúró mi fún Jèhófà àti Ìjọba rẹ̀. Mo gbàdúrà sí Jèhófà nínú ògbólógbòó ọgbà èso tí ó wà lẹ́yìn ilé, mo sì ṣèlérí tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ pé èmi yóò sìn ín títí láé. Ìfẹ́ inú rere ti àgbàyanu Ọlọ́run wa ti gún ọkàn àyà mi ní kẹ́ṣẹ́.—Orin Dáfídì 63:3.
A gbé ní oko kan tí ó jẹ́ nǹkan bí 30 kìlómítà sí St. Joseph, Missouri, U.S.A., tí kò sì tó kìlómítà 65 sí Kansas City. Ilé kékeré tí a fi igi kọ́ tí baba ńlá mi kọ́ sínú oko náà ní ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rúndún kọkàndínlógún ni a bí Dádì sí.
Ìdánilẹ́kọ̀ọ́ fún Iṣẹ́ Òjíṣẹ́
Ní ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn ọdún 1931, ìdílé wa gbọ́ ọ̀rọ̀ àsọyé fún gbogbo ènìyàn náà, “Ìjọba Náà, Ìrètí Ayé,” lórí rédíò, èyí tí Joseph Rutherford, ààrẹ Watch Tower Society nígbà yẹn, sọ ní àpéjọpọ̀ kan ní Columbus, Ohio. Ó ru ọkàn àyà mi sókè, mo sì láyọ̀ láti ṣàjọpín pẹ̀lú Dádì nínú pípín ìwé kékeré tí ó ní ọ̀rọ̀ àsọyé pàtàkì fún gbogbo ènìyàn yìí nínú láàárín àwọn ojúlùmọ̀ wa.
Ní ìgbà ìrúwé ọdún 1932, mo lọ sí ìpàdé Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fún ìgbà àkọ́kọ́. Aládùúgbò wa ké sí èmi àti Dádì láti wá tẹ́tí sí ọ̀rọ̀ àsọyé kan ní St. Joseph láti ẹnu George Draper, alábòójútó arìnrìn-àjò kan ti Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Nígbà tí a débẹ̀, ìpàdé náà ti kọjá ìlàjì, mo sì wá àyè láti jókòó sẹ́yìn J. D. Dreyer, tí ẹ̀yìn rẹ̀ gba igbá, ẹni tí yóò wá kó ipa pàtàkì nínú ìgbésí ayé mi.
Ní September ọdún 1933, mo bá Dádì lọ sí àpéjọ kan ní Kansas City, níbi tí mo ti kọ́kọ́ nípìn-ín nínú ìwàásù ìta gbangba. Dádì fún mi ní ìwé kékeré mẹ́ta, ó sì fún mi nítọ̀ọ́ni láti sọ pé: “Mo jẹ́ ọ̀kan lára Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí ń wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run. Kò sí iyè méjì pé o ti gbóhùn Judge Rutherford lórí rédíò. Àwọn ibùdó tí ó ju 300 lọ máa ń gbé àwọn ọ̀rọ̀ àsọyé rẹ̀ sáfẹ́fẹ́ lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀.” Lẹ́yìn náà, n óò fi ìwé kékeré lọni. Ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ yẹn, bí mo ti ń fún wàrà àwọn màlúù nínú oko, mo ronú pé èyí jẹ́ ọjọ́ mánigbàgbé jù lọ nínú ìgbésí ayé mi.
Kò pẹ́ kò jìnnà, ìgbà òtútù dé, ìrìn àjò wa sì láàlà. Ṣùgbọ́n, láìpẹ́ lẹ́yìn ìyẹn, Arákùnrin Dreyer àti aya rẹ̀ ṣèbẹ̀wò, wọ́n sì béèrè bí èmi yóò bá fẹ́ láti wá sí ilé wọn ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ Saturday kí n sì sùn níbẹ̀. Ìrìn kìlómítà mẹ́wàá lọ sí ilé Dreyer yẹ fún ìsapá bẹ́ẹ̀ nítorí ó ṣeé ṣe fún mi láti bá wọn lọ sẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ ní ọjọ́ kejì, mo sì lọ sí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́ ní St. Joseph ní ọjọ́ kejì. Láti ìgbà yẹn, ẹ̀ẹ̀kọ̀ọ̀kan ni mo ń pa nínípìn-ín nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ ní àwọn ọjọ́ Sunday jẹ. Ìdánilẹ́kọ̀ọ́ àti ìmọ̀ràn Arákùnrin Dreyer ṣeyebíye púpọ̀.
Ní September 2, 1935, ó ṣeé ṣe fún mi lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn láti fi ẹ̀rí ìyàsímímọ́ mi hàn fún Jèhófà nípasẹ̀ ìrìbọmi ní àpéjọ kan ní Kansas City.
Ìbẹ̀rẹ̀ Iṣẹ́ Ìgbésí Ayé Kan
Ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 1936, mo kọ̀wé béèrè láti sìn gẹ́gẹ́ bí aṣáájú ọ̀nà, tàbí òjíṣẹ́ alákòókò kíkún, a sì fi orúkọ mi sára orúkọ àwọn tí ń wá alábàáṣiṣẹ́ tí ó jẹ́ aṣáájú ọ̀nà. Kò pẹ́ lẹ́yìn ìyẹn, mo gba lẹ́tà kan láti ọ̀dọ̀ Edward Stead ti Arvada, Wyoming. Ó ṣàlàyé pé àga arọ ni òun ń lò, òun sì ń fẹ́ ìrànwọ́ láti ṣe aṣáájú ọ̀nà. Mo tẹ́wọ́ gba ìfilọni rẹ̀ lọ́gán, a sì yàn mí gẹ́gẹ́ bí aṣáájú ọ̀nà ní April 18, 1936.
Kí n tó lọ láti dara pọ̀ mọ́ Arákùnrin Stead, ìyá mi bá mi sọ̀rọ̀ níkọ̀kọ̀. Ó béèrè pé: “Ọmọ, ṣé ó dá ọ lójú pé ohun tí o fẹ́ ṣe nìyí?”
Mo fèsì pé: “Ìgbésí ayé kì yóò yẹ ní gbígbé bí mo bá ṣe ohun mìíràn.” Mo ti wá mọ̀ pé ìfẹ́ inú rere Jèhófà ṣe pàtàkì ju ohunkóhun mìíràn lọ.
Ṣíṣe aṣáájú ọ̀nà pẹ̀lú Ted, bí a ti ń pe Arákùnrin Stead, jẹ́ ìdánilẹ́kọ̀ọ́ àtàtà. Ó kún fún ìtara, ó sì máa ń gbé ìhìn iṣẹ́ Ìjọba náà kalẹ̀ lọ́nà kan tí ń fani mọ́ra gidigidi. Ṣùgbọ́n, gbogbo ohun tí Ted lè ṣe ni kí ó kọ ìwé, kí ó sì sọ̀rọ̀; làkúrègbé oríkèé ara ti mú kí àwọn oríkèé rẹ gan paali. Mo máa ń jí ní kùtùkùtù òwúrọ̀, tí n óò wẹ̀ ẹ́, tí n óò sì bá a fá irùngbọ̀n rẹ̀, n óò se oúnjẹ àárọ̀, n óò sì fi oúnjẹ nù ún. Lẹ́yìn náà, n óò wọṣọ fún un, n óò sì mú un gbára dì fún iṣẹ́ ìsìn. Ní ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn yẹn, a ṣe aṣáájú ọ̀nà ní Wyoming àti Montana, a ń pàgọ́ síta lóru. Ted máa ń sùn sínú ilé àkànṣe tí a kọ́ sórí ọkọ̀ ẹrù rẹ̀ kékeré, èmi sì máa ń sùn nílẹ̀ẹ́lẹ̀. Lẹ́yìn náà lọ́dún yẹn, mo ṣí lọ sí ìhà gúúsù láti ṣe aṣáájú ọ̀nà ní Tennessee, Arkansas, àti Mississippi.
Ní September ọdún 1937, mo lọ sí àpéjọpọ̀ ńlá mi àkọ́kọ́ ní Columbus, Ohio. Níbẹ̀, a ṣètò láti mú ipò iwájú nínú iṣẹ́ ìwàásù nípa lílo ohun èlò agbóhùnjáde. A pe ọ̀kọ̀ọ̀kan ìgbà tí a ba lo ohun èlò agbóhùnjáde ní ìgbékalẹ̀ kan. Lóṣù kan, mo ní tó 500 ìgbékalẹ̀, ó sì ju 800 ènìyàn tí ó tẹ́tí sílẹ̀. Lẹ́yìn jíjẹ́rìí ní ọ̀pọ̀ ìlú ìhà ìlà oòrùn Tennessee, Virginia, àti Ìwọ̀ Oòrùn Virginia, a ké sí mi láti sìn gẹ́gẹ́ bí aṣáájú ọ̀nà àkànṣe ní ipò tuntun mìíràn, ní bíbá ìránṣẹ́ ìpínlẹ̀ àgbègbè, gẹ́gẹ́ bí a ti ń pe àwọn alábòójútó arìnrìn-àjò nígbà náà, ṣiṣẹ́.
Mo ṣèbẹ̀wò sí àwọn ìjọ àti àwùjọ àdádó ní Ìwọ̀ Oòrùn Virginia—ní lílo ọ̀sẹ̀ méjì sí mẹ́rin pẹ̀lú ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn—tí mo sì mú ipò iwájú nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ pápá. Lẹ́yìn náà, ní January ọdún 1941, a yàn mí sípò gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ ìpínlẹ̀ àgbègbè. Nígbà yẹn, Màmá àti àwọn arábìnrin mi mẹ́ta—Clara, Lois, àti Ruth—ti mú ìdúró wọn fún Ìjọba náà. Nítorí náà, gbogbo ìdílé wa lọ sí àpéjọpọ̀ ńlá ní St. Louis pa pọ̀ ní ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn yẹn.
Kò pẹ́ lẹ́yìn àpéjọpọ̀ náà, a fi tó àwọn ìránṣẹ́ ìpínlẹ̀ àgbègbè létí pé iṣẹ́ ìpínlẹ̀ àgbègbè yóò dópin ní òpin November ọdún 1941. Ní oṣù tí ó tẹ̀ lé e, United States wọnú Ogun Àgbáyé Kejì. A yàn mí sí iṣẹ́ ìsìn aṣáájú ọ̀nà àkànṣe, tí ó ń béèrè lílo wákàtí 175 lóṣù nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́.
Àwọn Àǹfààní Àkànṣe Ti Iṣẹ́ Ìsìn
Ní July ọdún 1942, mo rí lẹ́tà kan gbà tí ó béèrè bóyá èmi yóò fẹ́ láti sìn ní ilẹ̀ òkèèrè. Lẹ́yìn tí mo ti dáhùn pé bẹ́ẹ̀ ni, a ké sí mi sí Bẹ́tẹ́lì, orílé-iṣẹ́ àgbáyé ti Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Brooklyn, New York. Nǹkan bí 20 àpọ́nkùnrin ni a pè wá fún ìdánilẹ́kọ̀ọ́ àkànṣe nígbà kan náà.
Nathan H. Knorr, tí ó jẹ́ ààrẹ Watch Tower Society nígbà náà ṣàlàyé pé ìgbòkègbodò iṣẹ́ ìwàásù ti lọ sílẹ̀ àti pé a óò dá wa lẹ́kọ̀ọ́ láti fún àwọn ìjọ lókun nípa tẹ̀mí. Ó wí pé: “Kì í ṣe pé a fẹ́ mọ ìṣòro tí ó wà nínú ìjọ nìkan ni, ṣùgbọ́n a fẹ́ mọ ohun tí ẹ ṣe nípa rẹ̀.”
Nígbà tí a fi wà ní Bẹ́tẹ́lì, Fred Franz, tí ó di ààrẹ lẹ́yìn Arákùnrin Knorr ní ọdún 1977, sọ ọ̀rọ̀ àsọyé kan nínú èyí tí ó ti sọ pé: “Ogun Àgbáyé Kejì yóò parí, iṣẹ́ ìwàásù gíga lọ́lá yóò sì ṣí sílẹ̀. Dájúdájú, a óò ṣì kó àràádọ́ta ọ̀kẹ́ jọ sínú ètò àjọ Jèhófà!” Ọ̀rọ̀ àsọyé yẹn yí èrò mi pa dà pátápátá. Nígbà tí a pín iṣẹ́ àyànfúnni, mo gbọ́ pé èmi ni yóò bẹ gbogbo ìjọ tí ó wà ní ìpínlẹ̀ Tennessee àti Kentucky wò. A pè wá ní ìránṣẹ́ fún àwọn ará, ìyẹn jẹ́ orúkọ kan tí ó ti wá yí pa dà sí alábòójútó àyíká.
Mo bẹ̀rẹ̀ síí bẹ àwọn ìjọ wò ní October 1, 1942, nígbà tí mo ṣì jẹ́ ẹni ọdún 25 péré. Nígbà yẹn, ẹsẹ̀ tàbí gígun ẹṣin ni ọ̀nà kan ṣoṣo láti dé àwọn ìjọ kan. Nígbà míràn, mo máa ń sùn nínú iyàrá kan náà pẹ̀lú ìdílé tí ó gbà mí lálejò.
Nígbà tí mo ń bẹ Ìjọ Greeneville wò ní Tennessee ní July ọdún 1943, mo rí ìkésíni kan gbà láti wá sí kíláàsì kejì ti Watchtower Bible School of Gilead. Ní ilé ẹ̀kọ́ Gilead, mo kọ́ ohun tí ó túmọ̀ sí ní ti gidi “láti fún àwọn ohun tí a gbọ́ ní àfiyèsí tí ó ju ti àtẹ̀yìnwá lọ” àti láti máa ní “púpọ̀ rẹpẹtẹ láti ṣe nígbà gbogbo nínú iṣẹ́ Olúwa.” (Hébérù 2:1; Kọ́ríńtì Kíní 15:58) Oṣù márùn-ún ti ìtòlẹ́sẹẹsẹ ilé ẹ̀kọ́ náà kọjá lọ kánmọ́, ọjọ́ ìkẹ́kọ̀ọ́yege sì dé ní January 31, 1944.
Láti Kánádà Ó Di Belgium
A yan díẹ̀ lára wa sí Kánádà, níbi tí a ti ṣẹ̀ṣẹ̀ mú ìfòfindè kúrò lórí ìgbòkègbodò Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. A yàn mí sí iṣẹ́ arìnrìn-àjò tí ó ń béèrè rírin ìrìn àjò jíjìn láti àwọn ìjọ kan sí òmíràn. Bí mo ti ń rìnrìn àjò, ó jẹ́ ìdùnnú mi láti gbọ́ àwọn ìrírí nípa bí a ṣe ṣe iṣẹ́ ìwàásù wa ní àkókò ìfòfindè náà ní Kánádà. (Ìṣe 5:29) Ọ̀pọ̀ sọ nípa ohun tí a pè ní ìgbétáásì gbígbòòrò tí kì í ṣe ti ológun, ní àkókò tí ó jẹ́ pé ní òru ọjọ́ kan ṣoṣo, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo ilé kọ̀ọ̀kan láti ìbẹ̀rẹ̀ Kánádà dé ìparí rẹ̀ ni a fi ìwé kékeré kọ̀ọ̀kan sílẹ̀ sí. Ẹ wo ìhìn rere tí ó jẹ́ láti gbọ́ pé ní May ọdún 1945, ogun dópin ní Yúróòpù!
Nígbà ẹ̀ẹ̀rùn yẹn, nígbà tí mo ń bẹ ìjọ kan wò ní ìlú kékeré Osage, Saskatchewan, mo gba lẹ́tà kan láti ọ̀dọ̀ Arákùnrin Knorr, tí ó kà pé: “Mo ń nawọ́ àǹfààní láti lọ sí Belgium sí ọ. . . . Iṣẹ́ púpọ̀ wà láti ṣe ní orílẹ̀-èdè yẹn. Orílẹ̀-èdè kan tí ogun ti fà ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ ni, àwọn ará wa sì ń fẹ́ ìrànwọ́, ó sì dà bí ẹni pé ó bójú mu kí a rán ẹnì kan lọ láti Amẹ́ríkà láti fún wọn ní ìrànwọ́ yíyẹ àti ìtùnú tí wọ́n nílò.” Mo dá èsì pa dà lọ́gán, ní títẹ́wọ́gba iṣẹ́ àyànfúnni náà.
Ní November ọdún 1945, mo wà ní Bẹ́tẹ́lì ní Brooklyn tí mo ń kọ́ èdè Faransé pẹ̀lú Charles Eicher, arákùnrin àgbàlagbà kan tí ó jẹ́ ará Alsace. Mo tún gba ìdánilẹ́kọ̀ọ́ yíyára kánkán lórí ọ̀nà tí ẹ̀ka ń gbà ṣiṣẹ́. Kí n tó lọ sí Yúróòpù, mo ṣèbẹ̀wò ráńpẹ́ sọ́dọ̀ ìdílé mi àti àwọn ọ̀rẹ́ mi ní St. Joseph, Missouri.
Ní December 11, mo kúrò ní New York nínú ọkọ̀ òkun náà, Queen Elizabeth, mo sì dé Southampton, England, ní ọjọ́ mẹ́rin lẹ́yìn náà. Mo dúró fún oṣù kan ní ẹ̀ka ti Britain níbi tí mo ti gbà àfikún ìdánilẹ́kọ̀ọ́. Lẹ́yìn ìyẹn, ní January 15, 1946, mo ré kọjá English Channel mo sì bọ́ọ́lẹ̀ ní Ostend, Belgium. Láti ibẹ̀, mo wọ ọkọ̀ ojú irin lọ sí Brussels níbi tí gbogbo ìdílé Bẹ́tẹ́lì ti pàdé mi ní ibùdó ọkọ ojú irin.
Ìgbòkègbodò Ẹ̀yìn Ogun Tí A Mú Gbòòrò Sí I
Iṣẹ́ àyànfúnni mi jẹ́ láti bójú tó iṣẹ́ Ìjọba náà ní Belgium, ṣùgbọ́n n kò tilẹ̀ lè sọ èdè ibẹ̀. Níwọ̀n nǹkan bí oṣù mẹ́fà, mo gbọ́ ìwọ̀nba èdè Faransé tí mo lè máa fi sọ̀rọ̀. Ó jẹ́ àǹfààní láti ṣiṣẹ́ ní ìfẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́ pẹ̀lú àwọn tí wọ́n ti fi ẹ̀mí wọn wewu láti máa bá iṣẹ́ ìwàásù nìṣó ní ọdún márùn-ún tí ìjọba Nazi fi ṣàkóso. A ṣẹ̀ṣẹ̀ dá àwọn kan lára wọn sílẹ̀ ní àwọn ọgbà iṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ ni.
Àwọn ará hára gàgà láti ṣètò iṣẹ́ náà kí wọ́n sì fi oúnjẹ bọ́ àwọn tí ebi òtítọ́ Bíbélì ń pa. Nítorí náà, a ṣe àwọn ètò láti ṣe àwọn àpéjọ, kí àwọn alábòójútó arìnrìn-àjò sì bẹ àwọn ìjọ wò. Nathan Knorr, Milton Henschel, Fred Franz, Grant Suiter, àti John Booth—gbogbo wọn jẹ́ aṣojú láti orílé-iṣẹ́ Brooklyn—tún ṣe ìbẹ̀wò tí ń fúnni níṣìírí sí ọ̀dọ̀ wa. Ní àwọn ọjọ́ ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ wọ̀nyẹn, mo sìn gẹ́gẹ́ bí alábòójútó àyíká, alábòójútó àgbègbè, àti alábòójútó ẹ̀ka. Ní December 6, 1952, lẹ́yìn nǹkan tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ọdún méje tí mo ti sìn ní Belgium, mo fẹ́ Emilia Vanopslaugh, tí òun pẹ̀lú ń ṣiṣẹ́ ní ẹ̀ka Belgium.
Ní oṣù díẹ̀ lẹ́yìn náà, ní April 11, 1953, a ké sí mi sí àgọ́ ọlọ́pàá àdúgbò, a sì sọ fún mi pé wíwà tí mo wà ní Belgium jẹ́ ewu fún ààbò Belgium. Mo lọ sí Luxembourg láti dúró níbẹ̀, nígbà tí mo pẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn sí Ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin ti Orílẹ̀-Èdè.
Ní February ọdún 1954, Ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin ti Orílẹ̀-Èdè Belgium ti àṣẹ náà lẹ́yìn pé wíwà mi ní orílẹ̀-èdè náà jẹ́ ewu. Ẹ̀rí tí wọ́n pèsè ni pé láti ìgbà tí mo ti dé Belgium, iye Àwọn Ẹlẹ́rìí ní orílẹ̀-èdè náà ti pọ̀ sí i gidigidi—láti orí 804 ní ọdún 1946 dé 3,304 ní ọdún 1953—àti pé, ní ìyọrísí èyí, a wu ààbò Belgium léwu nítorí pé ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ Ẹlẹ́rìí ni wọ́n ń mú ìdúró gbọn-in fún àìdásí tọ̀túntòsì Kristẹni. Nípa báyìí, a yan èmi àti Emilia sí Switzerland, níbi tí a ti bẹ̀rẹ̀ sí sìn nínú iṣẹ́ àyíká ní apá tí ń sọ èdè Faransé.
Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba—ilé ẹ̀kọ́ tí yóò máa pèsè ìdánilẹ́kọ̀ọ́ tí ó ga sí i fún àwọn Kristẹni alàgbà—ni a dá sílẹ̀ ní ọdún 1959 ní South Lansing, New York. A ké sí mi sí ibẹ̀ láti gba ìdánilẹ́kọ̀ọ́ láti kọ́ àwọn kíláàsì ilé ẹ̀kọ́ yìí ní Yúróòpù. Nígbà tí mo fi wà ní United States, mo ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ ìdílé mi ní St. Joseph, Missouri. Níbẹ̀, mo rí ìyá mi ọ̀wọ́n fún ìgbà ìkẹyìn. Ó kú ní January ọdún 1962; Dádì ti kú ní June ọdún 1955.
Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba ní Paris, ilẹ̀ Faransé, bẹ̀rẹ̀ ní March ọdún 1961, Emilia sì bá mi lọ. Àwọn alábòójútó àgbègbè, alábòójútó àyíká, alábòójútó ìjọ, àti àwọn aṣáájú ọ̀nà àkànṣe wá fún ilé ẹ̀kọ́ náà láti ilẹ̀ Faransé, Belgium, àti Switzerland. Ní àwọn oṣù 14 tí ó tẹ̀ lé e, mo darí kíláàsì 12 ti ètò ẹ̀kọ́ ọlọ́sẹ̀ mẹ́rin yìí. Tẹ̀ lé ìyẹn, ní April ọdún 1962, ẹ̀rí fi hàn pé Emilia ti lóyún.
Mímú Ara Wa Bá Àyíká Ipò Mu
A pa dà sí Geneva, Switzerland, níbi tí a ti ní àṣẹ ibùgbé títí lọ. Ṣùgbọ́n, kò rọrùn láti rí ibi tí a óò máa gbé nítorí ilé gbígbé kò tó rárá. Bẹ́ẹ̀ sì ni rírí iṣẹ́ kò rọrùn pẹ̀lú. Níkẹyìn, mo rí iṣẹ́ ní ilé ìtajà ńlá kan ní àárín gbùngbùn Geneva.
Mo ti lo ọdún 26 nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún, nítorí náà, àyíká ipò wa tí ó yí pa dà béèrè ìyípadà gidigidi. Ní ọdún 22 tí mo fi ṣiṣẹ́ ní ilé ìtajà ńlá náà, tí mo sì fi ṣèrànwọ́ láti tọ́ àwọn ọmọbìnrin wa méjèèjì, Lois àti Eunice, ìdílé wa fi àwọn ire Ìjọba náà ṣáájú nígbà gbogbo. (Mátíù 6:33) Lẹ́yìn tí mo fẹ̀yìn tì kúrò lẹ́nu iṣẹ́ ní ọdún 1985, mo bẹ̀rẹ̀ sí sìn gẹ́gẹ́ bí adelé alábòójútó àyíká.
Ìlera Emilia kò dára rárá mọ́, ṣùgbọ́n ó ń ṣe gbogbo ohun tí ó lè ṣe nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́. Lois sìn gẹ́gẹ́ bí aṣáájú ọ̀nà fún nǹkan bí ọdún mẹ́wàá. Ẹ wo ire pàtàkì nípa tẹ̀mí tí ó jẹ́ láti lè gbádùn àpéjọpọ̀ àgbáyé tí ó jẹ́ àgbàyanu jù lọ pẹ̀lú rẹ̀ ní Moscow nígbà ẹ̀ẹ̀rùn ọdún 1993! Kò pẹ́ lẹ́yìn náà, nígbà ìrìn àjò ìsinmi ní Senegal, Áfíríkà, Lois pàdánù ẹ̀mí rẹ̀ nígbà tí ó ń lúwẹ̀ẹ́ nínú òkun. Ìfẹ́ àti inú rere àwọn arákùnrin wa ní Áfíríkà àti ti àwọn míṣọ́nnárì jẹ́ ìtùnú ńlá fún mi nígbà tí mo rìnrìn àjò lọ sí Senegal láti bójú tó ìsìnkú náà. Ẹ wo bí mo ti ń yán hànhàn tó láti rí Lois nígbà àjíǹde!—Jòhánù 5:28, 29.
Mo kún fún ìmoore pé mo ti gbádùn ìtìlẹ́yìn adúróṣinṣin ti alábàákẹ́gbẹ́ onífẹ̀ẹ́ fún èyí tí ó ju ẹ̀wádún mẹ́rin lọ dáadáa. Ní tòótọ́, láìka àwọn ìrora ọkàn àti wàhálà mi sí, inú rere onífẹ̀ẹ́ ti Jèhófà ti gbádùn mọ́ mi, ó sì ti mú kí ìgbésí ayé yẹ ní gbígbé. A gún ọkàn àyà mi ní kẹ́ṣẹ́ láti pòkìkí nípa Ọlọ́run wa, Jèhófà, nínú ọ̀rọ̀ onísáàmù pé: “Nítorí pé inú rere rẹ onífẹ̀ẹ́ sàn ju ìyè, ètè mi yóò gbóríyìn fún ọ.”—Orin Dáfídì 63:3, NW.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
A mú ipò iwájú nínú iṣẹ́ ìwàásù nípa lílo ohun èlò agbóhùnjáde
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
Àwọn òbí mi ní ọdún 1936
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
Ìjẹ́rìí òpópónà ní Belgium ní ọdún 1948