Kí Ni Ipò tí Àwọn Òkú Wà?
ÌBẸ̀RÙ àwọn òkú sinmi lórí ìpìlẹ̀-èrò kan—pé àwọn òkú ní ọkàn tàbí ẹ̀mí kan tí ń wàláàyè nìṣó lẹ́yìn ikú. Bí Bibeli bá kọ́ni lọ́nà ṣíṣe kedere pé èrò yìí jẹ́ èké, nígbà náà a jẹ́ pé a ti fẹnu ọ̀rọ̀ jóná nìyẹn nípa bóyá àwọn òkú lè pa ọ́ lára. Wàyí o, nígbà náà, kí ni Bibeli sọ?
Nípa ipò tí àwọn òkú wà, Ọ̀rọ̀ Ọlọrun sọ pé: “Nítorí alààyè mọ̀ pé àwọn óò kú; ṣùgbọ́n àwọn òkú kò mọ ohun kan, bẹ́ẹ̀ ni wọn kìí ní èrè mọ́; nítorí ìrántí wọn ti di ìgbàgbé. Ìfẹ́ wọn pẹ̀lú, àti ìríra wọn, àti ìlara wọn, ó parun nísinsìnyí; bẹ́ẹ̀ ni wọn kò sì ní ìpín mọ́ láéláé nínú ohun gbogbo tí a ń ṣe lábẹ́ oòrùn.”—Oniwasu 9:5, 6.
Lójú ìwòye yẹn, àwọn òkú ha lè ràn ọ́ lọ́wọ́ tàbí pa ọ́ lára bí? Bẹ́ẹ̀kọ́, ni Ìwé Mímọ́ wí. Àwọn òkú kò mọ ohun kan wọ́n sì wà ní ìdákẹ́jẹ́ẹ́. Kò ṣeéṣe fún wọn láti ní ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ pẹ̀lú àwọn alààyè tàbí láti sọ èrò ìmọ̀lára èyíkéyìí jáde—ti ìfẹ́ tàbí ìkórìíra—tàbí láti gbé ìgbésẹ̀ èyíkéyìí. Kò yẹ kí o ní ìbẹ̀rù èyíkéyìí fún wọn.
Àwọn kan lè sọ pé, ‘Ó dára, bẹ́ẹ̀ni, ìyẹn lè jẹ́ òtítọ́ bí o bá ń sọ̀rọ̀ nípa ikú ará ìyára. Ṣùgbọ́n ikú nípa ti ara kìí ṣe òpin ìwàláàyè; ó wulẹ̀ ń jẹ́ kí ẹ̀mí fi ara sílẹ̀ ni. Ẹ̀mí yẹn lè ran àwọn alààyè lọ́wọ́ tàbí kí ó pa wọ́n lára.’ Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn ènìyàn lórí ilẹ̀-ayé ronú lọ́nà bẹ́ẹ̀.
Fún àpẹẹrẹ, ní Madagascar ìwàláàyè ni a kà sí ìṣípòpadà kan lásán, nítorí náà wọ́n ka ààtò ìsìnkú àti híhú òkú jáde sí èyí tí ó ṣe pàtàkì ju ìgbéyàwó lọ. Wọ́n ronú pé onítọ̀hún ti ọ̀dọ̀ àwọn babańlá rẹ̀ wá ó sì padà sọ́dọ̀ wọn nígbà tí ó kú. Nípa báyìí, ilé àwọn alààyè ni a ń fi igi àti bíríkì alámọ̀ kọ́, àwọn ohun èèlò ìkọ́lé tí kìí pẹ́ bàjẹ́ bí àkókò ti ń lọ, nígbà tí ó jẹ́ pé àwọn ibojì, “ilé” àwọn òkú, sábà máa ń wuyì tí ó sì ń tọ́jọ́ jù bẹ́ẹ̀ lọ. Níbi ìhú-òkú-jáde, àwọn ìdílé àti ọ̀rẹ́ ronú pé a óò bùkún fún àwọn, àwọn obìnrin sì gbàgbọ́ pé bí àwọn bá fi ọwọ́ kan egungun ìbátan tí ó ti kú náà, àwọn yóò kúrò ní ipò àgàn. Ṣùgbọ́n, lẹ́ẹ̀kan síi, kí ni Ọ̀rọ̀ Ọlọrun sọ?
A Kò Pète Ikú fún Aráyé
Ó dùnmọ́ni láti ṣàkíyèsí pé Jehofa Ọlọrun dá ènìyàn láti wàláàyè, ó sì sọ̀rọ̀ nípa ikú pé ó jẹ́ kìkì àbájáde àìgbọràn. (Genesisi 2:17) Ó mà ṣe o, ọkùnrin àti obìnrin àkọ́kọ́ dẹ́sẹ̀, àti ní ìyọrísí rẹ̀, ẹ̀ṣẹ̀ tànkálẹ̀ dé ọ̀dọ̀ gbogbo ìran aráyé gẹ́gẹ́ bí ogún tí ń ṣekúpani. (Romu 5:12) Nítorí náà ìwọ lè sọ pé ikú tí di òtítọ́ tí kò ṣeé yẹ sílẹ̀ nípa ìwàláàyè láti ìgbà àìgbọràn tọkọtaya ènìyàn àkọ́kọ́, bẹ́ẹ̀ni, òtítọ́ ríronilára nípa ìwàláàyè. A dá wa láti wàláàyè, èyí tí ó ṣàlàyé lọ́nà kan ìdí rẹ̀ tí ó fi ṣòro fún àìmọye àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ènìyàn láti gbá pé ikú jẹ́ òpin.
Gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ Bibeli ti sọ, Satani gbìyànjú láti tan tọkọtaya ènìyàn àkọ́kọ́ jẹ lórí ọ̀ràn ikú nípa títako ìkìlọ̀ Ọlọrun pé àìgbọràn yóò mú ikú wá. (Genesisi 3:4) Ṣùgbọ́n, bí àkókò ti ń kọjá lọ, ó farahàn lọ́nà tí ó ṣe kedere pé àwọn ènìyàn ń kú gẹ́gẹ́ bí Ọlọrun ti sọ ọ́ gan-an. Nípa báyìí, láti ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún sẹ́yìn Satani ti ń fi irọ́ mìíràn dáhùnpadà—pé apá kan lára ènìyàn tí ó jẹ́ ẹ̀mí ń bá ìwàláàyè nìṣó lẹ́yìn ikú ara. Irú ìtànjẹ bẹ́ẹ̀ bá Satani Eṣu mu, ẹni tí Jesu ṣàpèjúwe gẹ́gẹ́ bí “bàbá èké.” (Johannu 8:44) Ní òdìkejì, ìdáhùn Ọlọrun nípa ikú jẹ́ ìlérí kan.
Ìlérí Wo?
Ó jẹ́ ìlérí àjíǹde fún ọ̀pọ̀lọpọ̀. Ọ̀rọ̀ Griki náà tí a túmọ̀ sí “àjíǹde” ni a·naʹsta·sis. Lóréfèé ó túmọ̀ sí “pípadà dìde lẹ́ẹ̀kan síi,” ó sì tọ́ka sí gbígbé dìde kúrò nínú ikú. Bẹ́ẹ̀ni, ènìyàn ń dùbúlẹ̀ sínú ikú, ṣùgbọ́n Ọlọrun lè fi agbára rẹ̀ gbé ènìyàn dìde lẹ́ẹ̀kan síi. Ènìyàn ń sọ ìwàláàyè nù, ṣùgbọ́n Ọlọrun lè dá ìwàláàyè rẹ̀ padà fún un. Ọmọkùnrin Ọlọrun, Jesu Kristi, wí pé “wákàtí naa ń bọ̀ ninu èyí tí gbogbo awọn wọnnì tí wọ́n wà ninu awọn ibojì ìrántí yoo gbọ́ ohùn rẹ̀ wọn yoo sì jáde wá.” (Johannu 5:28, 29, NW) Aposteli Paulu sọ̀rọ̀ nípa “ìrètí” rẹ̀ “sọ́dọ̀ Ọlọrun . . . pé àjíǹde awọn olódodo ati awọn aláìṣòdodo yoo wà.” (Iṣe 24:15, NW) Jobu, olùṣòtítọ́ ìránṣẹ́ Ọlọrun ṣáájú àkókò àwọn Kristian, pẹ̀lú polongo ìrètí rẹ̀ nínú àjíǹde: “Bí ènìyàn bá kú yóò sì tún yè bí? gbogbo ọjọ́ ìgbà tí a là sílẹ̀ fún mi ni èmi óò dúró dè, títí àmúdọ̀tun mi yóò fi dé. Ìwọ [Ọlọrun] ìbá pè, èmi ìbá sì dá ọ lóhùn.”—Jobu 14:14, 15.
Ìlérí ṣíṣe kedere náà nípa àjíǹde kò ha já irọ́ èròǹgbà náà pé àwọn òkú wàláàyè nínú ẹ̀mí bí? Bí àwọn òkú bá wàláàyè tí wọ́n sì ń gbádùn ìwàláàyè ní ọ̀run tàbí nínú ayé àwọn ẹ̀mí kan, kí ni yóò jẹ́ ète àjíǹde? Wọn kì yóò ha ti gba èrè tàbí kádàrá wọn bí? Ẹ̀kọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọrun ṣí i payá pé àwọn òkú ti kú níti tòótọ́, wọn kò mọ nǹkankan, wọ́n ń sùn títí ìgbà ìjídìde ńlá náà nípasẹ̀ àjíǹde nínú ayé titun—paradise kan—tí Jehofa, Bàbá wa onífẹ̀ẹ́ ṣèlérí. Ṣùgbọ́n bí ikú kò bá túmọ̀sí ìyàsọ́tọ̀ ara kúrò nínú ẹ̀mí tí ẹ̀mí kìí sì wàláàyè nìṣó, kí ni nípa ti àwọn ìbánisọ̀rọ̀pọ̀ tí ó dàbí ẹni pé ó ń wá láti ayé ẹ̀mí?
Àwọn Ìbánisọ̀rọ̀pọ̀ Láti Ilẹ̀-Àkóso Ẹ̀mí
A ti ròyìn àìníye àwọn ipò ọ̀ràn nípa ìbánisọ̀rọ̀pọ̀ tí a tànmọ́-ọ̀n pé ó wá láti ilẹ̀-àkóso ẹ̀mí. Kí ni ìpilẹ̀ṣẹ̀ wọn níti gidi? Bibeli kìlọ̀ fún wa pé “Satani fúnraarẹ̀ ń da agọ̀ borí gẹ́gẹ́ bí angẹli ìmọ́lẹ̀. Nítorí náà ohun tí ó rọrùn ni ó jẹ́ fún àwọn aṣojú rẹ̀ láti da agọ̀ borí gẹ́gẹ́ bí aṣojú ohun rere.” (2 Korinti 11:14, 15, The New English Bible) Bẹ́ẹ̀ni, láti lè túbọ̀ tan àwọn ènìyàn jẹ kí ó sì ṣì wọ́n lọ́nà ní bọ́sẹ́, àwọn ẹ̀mí-èṣù (àwọn angẹli ọlọ̀tẹ̀) ti ní ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ pẹ̀lú àwọn alààyè, wọ́n sì máa ń díbọ́n nígbà mìíràn pé àwọn lè rannilọ́wọ́.
Aposteli Paulu fúnni ní ìkìlọ̀ síwájú síi nípa ìgbétáásì ìtànjẹ yìí pé: “Awọn kan yoo yẹsẹ̀ kúrò ninu ìgbàgbọ́, ní fífi àfiyèsí sí awọn gbólóhùn àsọjáde onímìísí tí ń ṣinilọ́nà ati awọn ẹ̀kọ́ ẹ̀mí-èṣù.” (1 Timoteu 4:1, NW) Nítorí náà ìdáhùnpadà èyíkéyìí tí a bá kà sí ti àwọn òkú ti ṣeéṣe kí ó wá láti ọ̀dọ̀ àwọn ẹ̀mí-èṣù tí wọ́n ń da agọ̀ bojú gẹ́gẹ́ bí “aṣojú ohun rere” tí wọ́n sì ń gbé irọ́ kan tí ó jẹ́ ti ìsìn lárugẹ, ní sísọ àwọn ènìyàn di ẹrú fún ìgbàgbọ́-nínú-ohun-asán tí ń ṣamọ̀nà wọn kúrò nínú òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọrun.
Ní jíjẹ́rìí síi pé àwọn òkú kò lè sọ ohunkóhun, ṣe ohunkóhun, tàbí nímọ̀lára èyíkéyìí, Orin Dafidi 146:3, 4 sọ pé: “Ẹ máṣe gbẹ́kẹ̀ yín lé àwọn ọmọ-aládé, àní lé ọmọ ènìyàn, lọ́wọ́ ẹni tí kò sí ìrànlọ́wọ́. Ẹ̀mí rẹ̀ jáde lọ, ó padà sí erùpẹ̀ rẹ̀; ní ọjọ́ náà gan-an, ìrò inú rẹ̀ run.” Kí ni ẹ̀mí náà tí ó “jáde lọ”? Ó jẹ́ agbára ìwàláàyè ẹni náà tí a ń gbéró nípa mímí. Nítorí náà, nígbà tí ẹni tí ó kú náà bá ṣíwọ́ láti máa mí, agbára ìmòye ẹni tí ó ti kú náà kò tún ṣiṣẹ́ mọ́. Ó kọjá sínú ipò àìmọ nǹkankan mọ́ rárá. Nítorí náà kò ṣeéṣe fún un láti máa lo agbára ìdarí lórí àwọn alààyè.
Ìdí rẹ̀ nìyẹn tí Bibeli fi fi ikú ènìyàn wé ti ẹranko, ní sísọ pé àwọn méjèèjì ń wà nínú ipò àìmọ nǹkankan nígbà ikú wọ́n sì ń padà sínú erùpẹ̀ láti inú èyí tí a ti mú wọn jáde. Oniwasu 3:19, 20 sọ pé: “Ohun tí ń ṣe ọmọ ènìyàn ń ṣe ẹran; àní ohun kan náà ni ó ń ṣe wọ́n: bí èkínní ti ń kú bẹ́ẹ̀ ni èkejì ń kú; nítòótọ́ ẹ̀mí kan náà ni gbogbo wọn ní, bẹ́ẹ̀ ni ènìyàn kò ní ọlá ju ẹran lọ: nítorí pé asán ni gbogbo rẹ̀. Níbi kan náà ni gbogbo wọn ń lọ; láti inú erùpẹ̀ wá ni gbogbo wọn, gbogbo wọn sì tún padà di erùpẹ̀.”
Ní mímọ̀ pé àwọn ẹ̀mí-èṣù ń gbìyànjú láti tan àwọn ènìyàn jẹ́ nípa mímú wọn ronú pé wọ́n lè ní ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ pẹ̀lú awọn òkú kí àwọn òkú sì nípa lórí wọn, Jehofa Ọlọrun kìlọ̀ fún àwọn ènìyàn rẹ̀, àwọn ọmọ Israeli ìgbàanì pé: “Kí a máṣe rí nínú yín ẹnìkan tí . . . ń fọ àfọ̀ṣẹ, tàbí alákìíyèsí-ìgbà, tàbí aṣefàyà, tàbí àjẹ́, tàbí atujú, tàbí abá-iwin-gbìmọ̀, tàbí oṣó, tàbí abókùúlò. Nítorí pé gbogbo àwọn tí ń ṣe nǹkan wọ̀nyí ìríra ni sí OLUWA.”—Deuteronomi 18:10-12.
Lọ́nà tí ó ṣe kedere, èròǹgbà náà pé àwọn òkú lè pa wá lára kò ti ọ̀dọ̀ Ọlọrun wá. Òun jẹ́ Ọlọrun òtítọ́. (Orin Dafidi 31:5; Johannu 17:17, NW) Ó sì ní ọjọ́-ọ̀la àgbàyanu ní ìpamọ́ fún àwọn olùfẹ́ òtítọ́ tí ń sìn ín “ní ẹ̀mí àti ní òtítọ́.”—Johannu 4:23, 24, NW.
Jehofa, Ọlọrun Òtítọ́ àti Ìfẹ́
Bàbá wa ọ̀run onífẹ̀ẹ́, “ẹni tí kò lè purọ́,” ti ṣèlérí pé: Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ lọ́nà àràádọ́ta ọ̀kẹ́ tí wọ́n ti kú tí a sì ti gbé sínú ibojì ni a óò jí dìde pẹ̀lú ìrètí ìyè ayérayé nínú ayé titun òdodo! (Titu 1:1, 2, NW; Johannu 5:28, NW) Ìlérí onífẹ̀ẹ́ yìí nípa àjíǹde ṣí i payá pé Jehofa ní ọkàn-ìfẹ́ jíjinlẹ̀ nínú ire aásìkí àwọn ẹ̀dá ènìyàn tí ó dá àti ìfẹ́ àtọkànwá láti fòpin sí ikú, ìkárísọ, àti ìrora. Nítorí náà kò sí ìdí fún bíbẹ̀rù àwọn òkú tàbí ṣíṣàníyàn láìnídìí nípa wọn àti nípa ìrètí tí wọ́n ní. (Isaiah 25:8, 9; Ìfihàn 21:3, 4) Ọlọrun wa onífẹ̀ẹ́ àti onídàájọ́ òdodo, Jehofa, lè jí wọn dìde yóò sì ṣe bẹ́ẹ̀, ní mímú ìrora ikú kúrò.
Ọ̀rọ̀ Ọlọrun, Bibeli, kún fún àwọn àpèjúwe nípa bí ipò àwọn nǹkan yóò ti rí lórí ilẹ̀-ayé nínú ayé titun òdodo tí a ṣèlérí yẹn. (Orin Dafidi 37:29; 2 Peteru 3:13, NW) Yóò jẹ́ àkókò àlàáfíà àti ayọ̀ àti ti ìfẹ́ fún gbogbo àwọn ènìyàn ẹlẹgbẹ́ wa. (Orin Dafidi 72:7; Isaiah 9:7; 11:6-9; Mika 4:3, 4) Gbogbo ènìyàn yóò ní ilé aláàbò, tí ó lẹ́wà, àti iṣẹ́ tí ó gbádùnmọ́ni. (Isaiah 65:21-23) Ọ̀pọ̀ àwọn ohun rere yóò wà fún gbogbo ènìyàn láti jẹ. (Orin Dafidi 67:6; 72:16) Gbogbo ènìyàn yóò gbádùn ọ̀pọ̀ yanturu ìlera. (Isaiah 33:24; 35:5, 6) Nígbà tí ó jẹ́ pé àwọn aposteli àti àwọn kéréje mìíràn tí a fikun wọn yóò ṣàkóso pẹ̀lú Jesu ní ọ̀run, Bibeli kò mẹ́nukan àwọn ipò oníbùkún fún ọkàn àwọn yòókù ní ọ̀run lẹ́yìn ikú. (Ìfihàn 5:9, 10; 20:6, NW) Èyí yóò ṣàjèjì bí àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn wọnnì tí wọ́n ti kú bá ń wàláàyè nìṣó lẹ́yìn ikú.
Ṣùgbọ́n kò ṣàjèjì bí a bá mọ ẹ̀kọ́ kedere tí Bibeli fi kọ́ni pé: Àwọn òkú ti dẹ́kun wíwàláàyè gẹ́gẹ́ bí alààyè ọkàn. Wọn kò lè pa ọ́ lára. Àwọn wọnnì tí ń bẹ nínú ibojì ìrántí wulẹ̀ ń sinmi ni, láìmọ nǹkankan títí di ìgbà àjíǹde wọn ní àkókò tí ó tọ́ lójú Ọlọrun. (Oniwasu 9:10; Johannu 11:11-14, 38-44, NW) Nígbà náà, àwọn ìrètí àti ohun tí a ń nàgà sí sinmi lórí Ọlọrun. “Àwa ó máa yọ̀, inú wa ó sì máa dùn nínú ìgbàlà rẹ̀.”—Isaiah 25:9.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Gẹ́gẹ́ bí Ọ̀rọ̀ Ọlọrun ti fihàn ní kedere, àwọn òkú kò lè ṣe ohunkóhun rárá títí di ìgbà àjíǹde