Ìwàláàyè Lẹ́yìn Ikú—Báwo, Níbo, Nígbà Wo?
ẸLẸ́DÀÁ ènìyàn àti Olùfúnni-ní-Ìyè fúnni ní ẹ̀rí ìdánilójú tirẹ̀ pé ikú ẹ̀dá ènìyàn kò fi dandan fòpin sí ìwàláàyè títí láé. Síwájú sí i, Ọlọ́run mú un dá wa lójú pé ó ṣeé ṣe, kì í ṣe láti wà láàyè lẹ́ẹ̀kan sí i fún ìwàláàyè míràn tí ó kúrú, bí kò ṣe láti wà láàyè pẹ̀lú ìfojúsọ́nà ṣíṣàì dojú kọ ikú mọ́ láé! Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ ọ́ lọ́nà ṣíṣe kedere, àní pẹ̀lú ìgbọ́kànlé pé: “Ó [Ọlọ́run] . . . ti pèsè ẹ̀rí ìfọwọ́sọ̀yà kan fún gbogbo ènìyàn ní ti pé ó ti jí i [Kristi Jésù] dìde kúrò nínú òkú.”—Ìṣe 17:31.
Àmọ́ ṣáá o, èyí ṣì fi àwọn ìbéèrè pàtàkì mẹ́ta sílẹ̀ láìdáhùn: Báwo ni ẹni tí ó ti kú ṣe lè padà di alààyè? Nígbà wo ni èyí yóò ṣẹlẹ̀? Níbo ni ìwàláàyè tuntun yẹn yóò ti wáyé? Jákèjádò ayé, a ti dáhùn àwọn ìbéèrè yìí lọ́nà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, ṣùgbọ́n kọ́kọ́rọ́ pàtàkì sí pípinnu ohun tí ó jẹ́ òtítọ́ nípa ọ̀ràn náà jẹ́ láti ní òye tí ó péye nípa ohun tí ń ṣẹlẹ̀ sí ẹ̀dá ènìyàn nígbà tí wọ́n bá kú.
Àìleèkú Ha Ni Ìdáhùn Náà Bí?
Ìgbàgbọ́ tí ó wọ́pọ̀ ni pé apá kan lára gbogbo ẹ̀dá ènìyàn jẹ́ àìleèkú àti pé kìkì ara wọn ni ó ń kú. Dájúdájú, ìwọ yóò ti gbọ́ irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀. Apá yìí tí a sọ pé ó jẹ́ àìleèkú ni a tọ́ka sí ní onírúurú ọ̀nà bí “ọkàn” tàbí “ẹ̀mí.” A sọ pé ó máa ń là á já nígbà tí ara bá kú, ó sì ń báa nìṣó láti wà láàyè níbòmíràn. Ní tòótọ́, irú ìgbàgbọ́ bẹ́ẹ̀ kò pilẹ̀ ṣẹ̀ nínú Bíbélì. Lóòótọ́, àwọn ènìyàn ìgbàanì nínú Bíbélì Lédè Hébérù wọ̀nà fún ìwàláàyè lẹ́yìn ikú, ṣùgbọ́n kì í ṣe nípasẹ̀ pé kí apá kan wọn tí ó jẹ́ àìleèkú là á já. Wọ́n fi ìgbọ́kànlé wọ̀nà fún dídi alààyè ní ọjọ́ iwájú lórí ilẹ̀ ayé nípasẹ̀ iṣẹ́ ìyanu ti àjíǹde.
Ábúráhámù babańlá jẹ́ àpẹẹrẹ títayọ lọ́lá ní ti ẹnì kan tí ó ní ìgbàgbọ́ nínú àjíǹde àwọn òkú ní ọjọ́ iwájú. Nígbà tí ó ń ṣàpèjúwe mímúratán tí Ábúráhámù múra tán láti fi ọmọ rẹ̀, Aísíìkì rúbọ, Hébérù 11:17-19 sọ fún wa pé: “Nípa ìgbàgbọ́ ni Ábúráhámù, nígbà tí a dán an wò, kí a kúkú sọ pé ó ti fi Aísíìkì rúbọ tán, . . . ṣùgbọ́n ó ṣírò pé Ọlọ́run lè gbé e dìde àní kúrò nínú òkú; láti ibẹ̀ ó sì tún rí i gbà lóòótọ́ ní ọ̀nà àpèjúwe,” níwọ̀n bí Ọlọ́run kò ti fi dandan lé e pé kí a fi Aísíìkì rúbọ. Ní jíjẹ́rìí síwájú sí i nípa ìgbàgbọ́ ìjímìjí láàárín àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé wọn yóò padà di alààyè lẹ́ẹ̀kan sí i ní ọjọ́ iwájú (dípò níní ìwàláàyè tí ń bá a nìṣó lójú ẹsẹ̀ nínú ilẹ̀ àkóso ẹ̀mí), wòlíì Hóséà kọ̀wé pé: “Èmi óò rà wọ́n padà lọ́wọ́ agbára isà òkú; Èmi óò rà wọ́n padà lọ́wọ́ ikú.”—Hóséà 13:14.
Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, nígbà wo ni èrò nípa àjogúnbá àìleèkú ẹ̀dá ènìyàn wọnú ìrònú àti ìgbàgbọ́ àwọn Júù? Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ náà, Encyclopaedia Judaica, sọ pé, “ó ṣeé ṣe kí ó jẹ́ pé ẹ̀kọ́ nípa àìleèkú ọkàn wọnú Ìsìn Àwọn Júù lábẹ́ agbára ìdarí Gíríìkì.” Síbẹ̀síbẹ̀, títí di àkókò Kristi, àwọn Júù olùfọkànsìn ṣì gbà gbọ́ nínú àjíǹde ọjọ́ iwájú, wọ́n sì wọ̀nà fún un. A lè rí èyí kedere nínú ìjíròrò Jésù pẹ̀lú Màtá nígbà tí arákùnrin rẹ̀, Lásárù, kú pé: “Nítorí náà Màtá wí fún Jésù pé: ‘Olúwa, ká ní o ti wà níhìn-ín ni arákùnrin mi kì bá tí kú.’ . . . Jésù wí fún un pé: ‘Arákùnrin rẹ yóò dìde.’ Màtá wí fún un pé: ‘Mo mọ̀ pé yóò dìde nínú àjíǹde ní ìkẹyìn ọjọ́.’”—Jòhánù 11:21-24.
Ipò Tí Àwọn Òkú Wà
Níhìn-ín pẹ̀lú, kò sí ìdí láti méfòó ọ̀ràn náà. Òtítọ́ Bíbélì tí ó ṣe kedere ni pé àwọn òkú “ń sùn,” láìmọ ohunkóhun, láìní ìmọ̀lára tàbí ìmọ̀ rárá. Nínú Bíbélì, a kò gbé irú òtítọ́ bẹ́ẹ̀ kalẹ̀, lọ́nà dídíjú, tí ó ṣòro láti yéni. Gbé àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí ó rọrùn láti lóye wọ̀nyí yẹ̀ wò: “Nítorí alààyè mọ̀ pé àwọn óò kú; ṣùgbọ́n àwọn òkú kò mọ ohun kan . . . Ohunkóhun tí ọwọ́ rẹ rí ní ṣíṣe, fi agbára rẹ ṣe é; nítorí tí kò sí ète, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ìmọ̀, tàbí ọgbọ́n, ní isà òkú níbi tí ìwọ́ ń rè.” (Oníwàásù 9:5, 10) “Ẹ má ṣe gbẹ́kẹ̀ yín lé àwọn ọmọ aládé, àní lé ọmọ ènìyàn, lọ́wọ́ ẹni tí kò sí ìrànlọ́wọ́. Ẹ̀mí rẹ̀ jáde lọ, ó padà sí erùpẹ̀ rẹ̀; ní ọjọ́ náà gan-an, ìrò inú rẹ̀ run.”—Orin Dáfídì 146:3, 4.
Nígbà náà, ó yéni, ìdí tí Jésù Kristi fi tọ́ka sí ikú gẹ́gẹ́ bí oorun. Àpọ́sítélì Jòhánù ṣàkọsílẹ̀ ìjíròrò kan láàárín Jésù àti àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Ó wí fún wọn pé: ‘Lásárù ọ̀rẹ́ wa ti lọ sinmi, ṣùgbọ́n mo ń rìnrìn àjò lọ sí ibẹ̀ láti jí i kúrò lójú oorun.’ Nítorí náà àwọn ọmọ ẹ̀yìn wí fún un pé: ‘Olúwa, bí ó bá jẹ́ pé ó lọ sinmi ni, ara rẹ̀ yóò dá.’ Ṣùgbọ́n, Jésù sọ̀rọ̀ nípa ikú rẹ̀. Ṣùgbọ́n wọ́n lérò pé ó ń sọ̀rọ̀ nípa sísinmi nínú oorun. Nítorí náà, ní àkókò yẹn Jésù wí fún wọn láìfọ̀rọ̀ bọpo bọyọ̀ pé: ‘Lásárù ti kú.’”—Jòhánù 11:11-14.
Ẹni Náà Lódindi Kú
Bí ẹ̀dá ènìyàn ṣe ń kú kan ẹni náà lódindi, kì í ṣe pé ara nìkan ní ń kú. Ní ìbámu pẹ̀lú àwọn gbólóhùn ṣíṣe kedere, tí ó bá Bíbélì mu, a gbọ́dọ̀ dé ìparí èrò pé ènìyàn kò ní àìleèkú ọkàn tí ó lè là á já nígbà tí ara rẹ̀ bá kú. Ìwé Mímọ́ fi hàn kedere pé ọkàn lè kú. “Kíyè sí i, gbogbo ọkàn ni tèmi; gẹ́gẹ́ bí ọkàn bàbá ti jẹ́ tèmi, bẹ́ẹ̀ ni tèmi ni ọkàn ọmọ pẹ̀lú; ọkàn tí ó bá ṣẹ̀, òun óò kú.” (Ìsíkẹ́ẹ̀lì 18:4) Kò sí ibi tí a ti sọ nípa àwọn ọ̀rọ̀ náà “àìleèkú” tàbí “ipò àìleèkú” gẹ́gẹ́ bí ohun tí aráyé jogún.
Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ náà, New Catholic Encyclopedia, pèsè ìsọfúnni fífani lọ́kàn mọ́ra, tí ń lani lóye yìí, lórí àwọn ọ̀rọ̀ Hébérù àti ọ̀rọ̀ Gíríìkì tí a túmọ̀ sí “ọkàn” nínú Bíbélì pé: “Ọkàn nínú ML [Májẹ̀mú Láéláé] jẹ́ nepeš, nínú MT [Májẹ̀mú Tuntun] [psy·kheʹ]. . . . Nepeš wá láti inú orísun ìpìlẹ̀ tí ó ṣeé ṣe kí ó túmọ̀ sí láti mí, àti nípa báyìí . . . níwọ̀n bí èémí ti fi ìyàtọ̀ sáàárín alààyè òun òkú, nepeš túmọ̀ sí ìwàláàyè tàbí ara ẹni tàbí lọ́nà rírọrùn, ìwàláàyè ẹnì kọ̀ọ̀kan. . . . Kò sí ìpínyà kankan ara àti ọkàn nínú ML. Ọmọ Ísírẹ́lì rí gbogbo nǹkan ní kedere, bí wọ́n ṣe rí látòkè délẹ̀, ó sì tipa báyìí ka ènìyàn sí ẹnì kan, kì í sì í ṣe bí ohun alápá púpọ̀. Ọ̀rọ̀ náà, nepeš, bí ọ̀rọ̀ wa, ọkàn, tilẹ̀ túmọ̀ rẹ̀, kò fìgbà kankan túmọ̀ sí ọkàn gẹ́gẹ́ bí èyí tí ó yàtọ̀ sí ara tàbí sí ẹnì kọ̀ọ̀kan. . . . Ọ̀rọ̀ náà, [psy·kheʹ] ni ọ̀rọ̀ inú MT tí ó ní ìtumọ̀ kan náà pẹ̀lú nepeš. Ó lè túmọ̀ sí orísun ìwàláàyè, ìwàláàyè fúnra rẹ̀, tàbí ohun alààyè náà.”
Nípa báyìí, o lè rí i pé nígbà ikú, ẹni tí ó wà láàyè tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀ náà, tàbí ọkàn tí ó wà láàyè náà, di aláìsí. Ará padà di “erùpẹ̀” tàbí padà di àwọn ohun ìpìlẹ̀ ilẹ̀ ayé, yálà ní dídi erùpẹ̀ díẹ̀díẹ̀ nípasẹ̀ sísin òkú àti jíjẹrà lẹ́yìn náà tàbí mímú un yára kánkán nípasẹ̀ dídáná sun òkú. Jèhófà sọ fún Ádámù pé: “Erùpẹ̀ sáà ni ìwọ, ìwọ óò sì padà di erùpẹ̀.” (Jẹ́nẹ́sísì 3:19) Nígbà náà, báwo ni ìwàláàyè lẹ́yìn ikú yóò ṣe ṣeé ṣe? Ó jẹ́ nítorí pé Ọlọ́run ní àwọn ẹni tí ó ti kú nínú agbára ìrántí tirẹ̀. Jèhófà ní agbára ìyanu àti agbára ìṣe láti dá ẹ̀dá ènìyàn, nítorí náà, kò yẹ kí ó yani lẹ́nu pé ó lè fi àkọsílẹ̀ nípa bátànì ìwàláàyè ẹnì kọ̀ọ̀kan pamọ́ nínú agbára ìrántí rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni, gbogbo ṣíṣeé ṣe pé kí ẹni yẹn wà láàyè lẹ́ẹ̀kan sí i kù sọ́wọ́ Ọlọ́run.
Èyí ni ìtúmọ̀ gidi ti ọ̀rọ̀ náà, “ẹ̀mí,” tí a sọ̀rọ̀ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí èyí tí ó padà sọ́dọ̀ Ọlọ́run tí ó fi í fúnni. Ní ṣíṣàpèjúwe àbájáde yìí, òǹkọ̀wé onímìísí tí ó kọ ìwé Oníwàásù ṣàlàyé pé: “Nígbà náà ni erùpẹ̀ yóò padà sí ilẹ̀ bí ó ti wà rí, ẹ̀mí yóò sì padà tọ Ọlọ́run tí ó fi í fúnni.”—Oníwàásù 12:7.
Ọlọ́run nìkan ni ó lè mú kí ẹnì kan wà láàyè. Nígbà tí Ọlọ́run dá ènìyàn ní Édẹ́nì, tí ó sì mí “èémí ìyè” sí ihò imú rẹ̀, ní àfikún sí fífi afẹ́fẹ́ kún ẹ̀dọ̀ fóró Ádámù, Jèhófà mú kí agbára ìwàláàyè mú kí àwọn sẹ́ẹ̀lì ara rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í ṣiṣẹ́. (Jẹ́nẹ́sísì 2:7) Nítorí pé àwọn òbí lè tàtaré agbára ìwàláàyè yìí sí àwọn ọmọ wọn nípasẹ̀ ìlóyún àti ìbímọ, lọ́nà títọ́, a lè sọ pé Ọlọ́run ni ó fún ẹ̀dá ènìyàn ní ìwàláàyè, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, dájúdájú, a rí i gbà nípasẹ̀ àwọn òbí.
Àjíǹde—Àkókò Aláyọ̀
A kò gbọdọ̀ ṣi àjíǹde lóye pé ó jẹ́ àtúnwáyé, èyí tí kò ní ìtìlẹyìn nínú Ìwé Mímọ́. Àtúnwáyé ni ìgbàgbọ́ náà pé lẹ́yìn tí ẹnì kan bá kú, a óò tún un bí sínú ìwàláàyè kan tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀-lé. Èyí ni a sọ pé ó lè wà ní ipò ìwàláàyè gíga tàbí ipò ìwàláàyè rírẹlẹ̀ ní ìfiwéra pẹ̀lú ìwàláàyè tí ẹnì kan ní ṣáájú, ní sísinmi lórí àkọsílẹ̀ tí a gbà gbọ́ pé ẹni yẹn ní nígbà ìwàláàyè ìṣáájú yẹn. Ní ìbámu pẹ̀lú ìgbàgbọ́ yìí, a lè “tún” ẹnì kan “bí” gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá ènìyàn tàbí gẹ́gẹ́ bí ẹranko. Ìyẹ́n forí gbárí pátápátá pẹ̀lú ohun tí Bíbélì fi kọ́ni.
Ọ̀rọ̀ náà, “àjíǹde” ni a túmọ̀ láti inú ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà, a·naʹsta·sis, tí ó túmọ̀ ní òwuuru sí “dídìde lẹ́ẹ̀kan sí i.” (Àwọn olùtumọ̀ èdè Gíríìkì sí èdè Hébérù ti túmọ̀ a·naʹsta·sis ní lílo àwọn ọ̀rọ̀ Hébérù náà, techi·yathʹ ham·me·thimʹ, tí ó túmọ̀ sí “sísọ òkú di alààyè.”) Àjíǹde ni mímú kí bátànì ìwàláàyè ẹnì kọ̀ọ̀kan bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ lẹ́ẹ̀kan sí i nínú, bátànì ìwàláàyè tí Ọlọ́run ti fi pa mọ́ sínú agbára ìrántí rẹ̀. Ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí ó jẹ́ ìfẹ́ inú Ọlọ́run fún ẹnì kọ̀ọ̀kan, a óò mú ẹni náà padà bọ̀ sípò sínú ara ẹ̀dá ènìyàn tàbí sínú ara ẹ̀mí; síbẹ̀ yóò ṣì ní ànímọ́ ara ẹni rẹ̀, ní níní àkópọ̀ ìwà kan náà àti agbára ìrántí gẹ́gẹ́ bí ó ti rí nígbà tí ó fi kú.
Bẹ́ẹ̀ ni, Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa irú àjíǹde méjì. Ọ̀kan jẹ́ àjíǹde sí ọ̀run pẹ̀lú ara ẹ̀mí; èyí wà fún ìwọ̀nba kéréje ní ìfiwéra. Jésù Kristi ní irú àjíǹde bẹ́ẹ̀. (Pétérù Kìíní 3:18) Ó sì fi hàn pé àwọn tí a yàn nínú àwọn tí ń tẹ̀ lé ipasẹ̀ rẹ̀ yóò ní irú ìrírí bẹ́ẹ̀, bẹ̀rẹ̀ látorí àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ olùṣòtítọ́, àwọn tí ó ṣèlérí fún pé: “Mo ń bá ọ̀nà mi lọ láti pèsè ibì kan sílẹ̀ fún yín. . . . Èmí tún ń bọ̀ wá èmi yóò sì gbà yín sí ilé sọ́dọ̀ ara mi dájúdájú, pé níbi tí mo bá wà kí ẹ̀yin pẹ̀lú lè wà níbẹ̀.” (Jòhánù 14:2, 3) Bíbélì tọ́ka sí èyí gẹ́gẹ́ bí “àjíǹde èkíní,” èkíní ní ti àkókò àti ní ti ipò. Ìwé Mímọ́ ṣàpèjúwe àwọn tí a tipa báyìí jíǹde sí ìyè ti ọ̀run, pé wọ́n jẹ́ àlùfáà Ọlọ́run, wọ́n sì ń ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba pẹ̀lú Kristi Jésù. (Ìṣípayá 20:6) “Àjíǹde èkíní” yìí wà fún iye kéréje kan, àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ fúnra wọn sì fi hàn pé kìkì 144,000 ni a óò yàn nínú àwọn ọkùnrin àti àwọn obìnrin olùṣòtítọ́. Wọn yóò ti ní láti fẹ̀rí ìwà títọ́ wọn sí Jèhófà Ọlọ́run àti Kristi Jésù hàn títí di ìgbà ikú wọn, lẹ́yìn tí wọ́n ti jẹ́ ògbóṣáṣá nínú jíjẹ́rìí fún àwọn ẹlòmíràn nípa ìgbàgbọ́ wọn.—Ìṣípayá 14:1, 3, 4.
Láìsí iyè méjì, àjíǹde àwọn òkú yóò jẹ́ àkókò ayọ̀ tí kò láàlà fún àwọn tí a jí dìde sí ìyè nínú ọ̀run. Ṣùgbọ́n, ayọ̀ náà kò tán síbẹ̀, nítorí a tún ṣèlérí àjíǹde sí ìyè níhìn-ín lórí ilẹ̀ ayé gan-an. Àwọn tí a óò jí dìde yóò dara pọ̀ mọ́ àwọn tí ó la òpin ètò ìgbékalẹ̀ búburú já, tí iye wọn kò láàlà. Lẹ́yìn wíwo iye kékeré tí wọ́n tóótun fún àjíǹde sí ọ̀run, a fi ìran nípa “ogunlọ́gọ̀ ńlá kan, èyí tí ẹnì kankan kò lè kà, láti inú gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè àti ẹ̀yà àti ènìyàn àti ahọ́n,” han àpọ́sítélì Jòhánù. Ẹ wo àkókò aláyọ̀ tí ìyẹn yóò jẹ́ nígbà tí ọ̀pọ̀ mílíọ̀nù, tàbí ọ̀pọ̀ bílíọ̀nù, bá padà di alààyè níhìn-ín lórí ilẹ̀ ayé!—Ìṣípayá 7:9, 16, 17.
Ìgbà Wo Ni Yóò Jẹ́?
Ìdùnnú àti ayọ̀ èyíkéyìí kì yóò tọ́jọ́ bí àwọn òkú bá padà wá sínú ayé kan tí ó kún fún gbọ́nmisi-omi-ò-to, ìtàjẹ̀sílẹ̀, ìbàyíkájẹ́, àti ìwà ipá—gẹ́gẹ́ bí ipò náà ti rí lónìí. Bẹ́ẹ̀ kọ́, àjíǹde gbọ́dọ̀ dúró di ìgbà tí a bá gbé “ayé tuntun” kalẹ̀. Ronú wò ná, nípa pílánẹ́ẹ̀tì kan tí a fọ̀ mọ́ tónítóní kúrò lọ́wọ́ àwọn ènìyàn àti àjọ tí ó dà bí ẹni pé títí di ìsinsìnyí, wọ́n kúndùn pípa ilẹ̀ ayé run, tí wọ́n sì ń ba ẹwà rẹ̀ ìpilẹ̀ṣẹ̀ jẹ́, ká má ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ ti ìjìyà tí kò ṣeé fẹnu sọ tí wọ́n ti mú wá sórí àwọn olùgbé rẹ̀.—Pétérù Kejì 3:13; Ìṣípayá 11:18.
Lọ́nà tí ó ṣe kedere, àkókò náà fún àjíǹde aráyé ní gbogbogbòò ṣì wà níwájú. Síbẹ̀, ìhìn rere náà ni pé, kò jìnnà mọ́. Lóòótọ́, ó gbọ́dọ̀ dúró di òpin ètò ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan búburú ìsinsìnyí. Bí ó ti wù kí ó rí, ọ̀pọ̀ yanturu ẹ̀rí fi hàn pé àkókò tí “ìpọ́njú ńlá” náà yóò bẹ́ sílẹ̀ lójijì ti sún mọ́ etílé, tí yóò dé òtéńté rẹ̀ ní “ogun ọjọ́ ńlá Ọlọ́run Olódùmarè”—tí a sábà ń pè ní Amágẹ́dọ́nì. (Mátíù 24:3-14, 21; Ìṣípayá 16:14, 16) Èyí yóò yọrí sí mímú gbogbo ìwà búburú kúrò nínú pílánẹ́ẹ̀tì, Ilẹ̀ Ayé tí ń gbádùn mọ́ni yìí. Lẹ́yìn ìyẹn, Ìṣàkóso Ẹgbẹ̀rúndún ti Kristi Jésù yóò tẹ̀ lé e, nígbà tí a óò mú ayé bọ̀ sí ipò párádísè kan ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀-lé.
Bíbélì ṣí i payá pé nígbà ìṣàkóso Ẹgbẹ̀rúndún yìí, àjíǹde àwọn ẹ̀dá ènìyàn tí ó ti kú yóò wáyé. Nígbà náà ni ìlérí tí Jésù ṣe nígbà tí ó fi wà lórí ilẹ̀ ayé yóò ní ìmúṣẹ pé: “Kí ẹnu má ṣe yà yín sí èyí, nítorí pé wákàtí náà ń bọ̀ nínú èyí tí gbogbo àwọn wọnnì tí wọ́n wà nínú àwọn ibojì ìrántí yóò gbọ́ ohùn rẹ̀ wọn yóò sì jáde wá . . . sí àjíǹde.”—Jòhánù 5:28, 29.
Ìyọrísí Ìrètí Àjíǹde
Ẹ wo ìrètí àgbàyanu ti ọjọ́ iwájú tí ìfojúsọ́nà fún àjíǹde yìí jẹ́—àkókò kan nígbà tí àwọn òkú yóò padà di alààyè! Ẹ wo bí ó ti ń múni lọ́kàn le tó bí a ti ń dojú kọ àwọn ìṣòro ọjọ́ ogbó, àìsàn, àwọn àjálù àti ìbànújẹ́ tí a kò retí, àti kìkìdá pákáǹleke àti àwọn ìṣòro ìgbésí ayé lójoojúmọ́! Ó ń mú oró ikú kúrò—kì í ṣe pé ó ń mú ìbànújẹ́ kúrò pátápátá, ṣùgbọ́n, ó ń yà wá sọ́tọ̀ kúrò lára àwọn tí kò ní ìrètí fún ọjọ́ iwájú. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ ìyọrísí atuninínú yìí tí ìrètí àjíǹde ní, pẹ̀lú ọ̀rọ̀ wọ̀nyí pé: “Ẹ̀yin ará, àwa kò fẹ́ kí ẹ ṣe aláìmọ̀ nípa àwọn wọnnì tí wọ́n ń sùn nínú ikú; kí ẹ má baà kárí sọ gan-an gẹ́gẹ́ bí àwọn yòó kù tí kò ní ìrètí ti ń ṣe pẹ̀lú. Nítorí bí ó bá jẹ́ pé ìgbàgbọ́ wa ni pé Jésù kú ó sì tún dìde, bẹ́ẹ̀, pẹ̀lú, àwọn wọnnì tí wọ́n ti sùn nínú ikú nípasẹ̀ Jésù ni Ọlọ́run yóò mú wá pẹ̀lú rẹ̀.”—Tẹsalóníkà Kìíní 4:13, 14.
A ti lè nírìírí ìjótìítọ́ ọ̀rọ̀ míràn tí ọkùnrin ará Ìlà Oòrùn náà, Jóòbù sọ pé: “Ènìyán ṣòfò dànù gẹ́gẹ́ bí ohun tí ó díbàjẹ́, gẹ́gẹ́ bí ẹ̀wù tí kòkòrò jẹ. Ènìyàn tí a bí nínú obìnrin ọlọ́jọ́ díẹ̀ ni, ó sì kún fún wàhálà. Ó rú jáde gẹ́gẹ́ bí òdòdó, ó sì gbẹ dànù; gẹ́gẹ́ bí òjìji tí ń yára kọjá lọ, òun kò wà pẹ́ títí.” (Jóòbù 13:28–14:2, New International Version) Àwa pẹ̀lú mọ̀ nípa àìdánilójú ìgbésí ayé àti òtítọ́ pọ́ńbélé náà pé “ìgbà àti èèṣì” lè ṣẹlẹ̀ sí ẹnikẹ́ni nínú wa. (Oníwàásù 9:11, NW) Dájúdájú, kò sí ẹnikẹ́ni nínú wa tí èrò dídojú kọ ikú gbádùn mọ́. Síbẹ̀, ìrètí dídájú ti àjíǹde ń ṣèrànwọ́ láti mú ìbẹ̀rù jìnnìjìnnì nítorí ikú kúrò.
Nítorí náà, mọ́kàn le! Wò ré kọjá ṣíṣeé ṣe láti sùn nínú ikú sí pípadà di alààyè nípasẹ̀ iṣẹ́ ìyanu àjíǹde. Wo iwájú pẹ̀lú ìgbọ́kànlé fún ìfojúsọ́nà ìwàláàyè ọjọ́ iwájú tí kò lópin, kí o sì fi ìdùnnú mímọ̀ pé irú àkókò oníbùkún bẹ́ẹ̀ ń bẹ ní ọjọ́ iwájú tí kò jìnnà mọ́ kún èyí.