ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w94 11/1 ojú ìwé 2-4
  • Ìjìyà Ẹ̀dá Ènìyàn—Yóò Ha Dópin Láé Bí?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìjìyà Ẹ̀dá Ènìyàn—Yóò Ha Dópin Láé Bí?
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìyà
    Jí!—2015
  • Ohun Tí Bíbélì Sọ
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2017
  • Ìbéèrè Kẹta: Kí Nìdí Tí Ọlọ́run Fi Jẹ́ Kí Ìyà Máa Jẹ Mí?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2012
  • Ìtùnú Fáwọn Tó Ń Jìyà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2003
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
w94 11/1 ojú ìwé 2-4

Ìjìyà Ẹ̀dá Ènìyàn—Yóò Ha Dópin Láé Bí?

ÀWỌN ìran àrídíjì tí ó wáyé lẹ́yìn tí bọ́m̀bù kan búgbàù nínú ọjà kíkúnfọ́fọ́ kan ní Sarajevo; ìpakúpa àti rògbòdìyàn ní Rwanda; àwọn ọmọdé tí ebi ti fẹ́rẹ̀ẹ́ pakú tí wọ́n ń béèrè fún oúnjẹ ní Somalia; àwọn ìdílé tí jìnnìjìnnì bá tí wọ́n ń ronú iye dúkìá tí wọ́n ti pàdánù lẹ́yìn tí ìmìtìtì-ilẹ̀ ṣẹlẹ̀ ní Los Angeles; àwọn aláìlólùrànlọ́wọ́ òjìyà omíyalé ní Bangladesh. Irú àwọn ìran tí ń fi ìjìyà ẹ̀dá ènìyàn hàn bẹ́ẹ̀ ń farahàn lójoojúmọ́ lórí tẹlifíṣọ̀n tàbí nínú ìwé ìròyìn àti ìwé agbéròyìnjáde.

Ìyọrísí tí ń baninínújẹ́ nípa ìjìyà ẹ̀dá ènìyàn ni pé ó ń mú kí àwọn ènìyàn kan sọ ìgbàgbọ́ nínú Ọlọrun nù. Gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ kan tí àwùjọ àwọn onísìn Ju tí ń gbé ní United States tẹ̀ jáde, “Ìwà-ibi tí ó wà káàkiri tí fìgbà gbogbo jẹ́ ìdínà tí ó burú jùlọ fún ìgbàgbọ́.” Àwọn òǹkọ̀wé náà tọ́kasí ikú tí ó wáyé ní àwọn ibùdó ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ Nazi bíi ti Auschwitz àti èyí tí bọ́m̀bù fà irú èyí tí ó búgbàù lé Hiroshima lórí. Àwọn òǹṣèwé náà sọ pé, “Ọ̀ràn nípa bí Ọlọrun òdodo àti alágbára ṣe lè fàyègba pípa ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ẹ̀mí tí kò mọwọ́mẹsẹ̀ rẹ́ ráúráú, ti kó ìdààmú bá àwọn olùfọkànsìn ó sì ti kó ìdàrúdàpọ̀ ọkàn bá wọn.”

Ó baninínújẹ́ pé, àwọn ìròyìn ìṣẹ̀lẹ̀ akópayàbáni tí kò mọ́wọ́ dúró lè sọ èrò-ìmọ̀lára ẹ̀dá ènìyàn dòkú. Níwọ̀n bí àwọn ọ̀rẹ́ àti ẹbí kò bá ti faragbá nínú rẹ̀, agbára káká ni ìjìyà àwọn ẹlòmíràn fi ń mú wọn káàánú.

Síbẹ̀, òtítọ́ náà pé a lágbára láti ní ìyọ́nú, ó kérétán fún àwọn olólùfẹ́ wa, yẹ kí ó sọ ohun kan fún wa nípa Olùṣẹ̀dá wa. Bibeli sọ pé a dá ènìyàn “ní àwòrán Ọlọrun” àti “gẹ́gẹ́ bí ìrí [rẹ̀].” (Genesisi 1:​26, 27) Èyí kò túmọ̀sí pé bí Ọlọrun ṣe rí gẹ́lẹ́ ní ẹ̀dá ènìyàn rí. Ó tì o, nítorí pé Jesu Kristi ṣàlàyé pé “Ọlọrun jẹ́ Ẹ̀mí,” bẹ́ẹ̀ sì ni “ẹ̀mí kò ní ẹran-ara àti egungun.” (Johannu 4:24, NW; Luku 24:39, NW) Dídá tí a dá wa ní ìrí Ọlọrun tọ́kasí agbára tí a ní láti lè fi àwọn ànímọ́ tí ó jọ ti Ọlọrun hàn. Nítorí náà, níwọ̀n bí àwọn ẹ̀dá ènìyàn olórí pípé ti lè ní ìyọ́nú fún àwọn tí ń jìyà, a gbọ́dọ̀ parí èrò pé Ẹlẹ́dàá ènìyàn, Jehofa Ọlọrun, jẹ́ oníyọ̀ọ́nú àti pé ó ń nímọ̀lára jíjinlẹ̀ fún àwọn ẹ̀dá ènìyàn tí ń jìyà.​—⁠Fiwé Luku 11:⁠13.

Ọ̀nà kan tí Ọlọrun ti gbà fi ìyọ́nú rẹ̀ hàn ni nípa pípèsè àlàyé kan tí a kọ fún aráyé nípa ohun tí ó fa sábàbí ìjìyà. Èyí ni òun ti ṣe nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀, Bibeli. Bibeli fihàn ní kedere pé Ọlọrun dá ènìyàn láti gbádùn ìgbésí-ayé rẹ̀, kìí ṣe láti jìyà. (Genesisi 2:​7-⁠9) Ó tún ṣí i payá pé àwọn ẹ̀dá ènìyàn àkọ́kọ́ ni wọ́n mú ìjìyà wá sórí araawọn nípa kíkọ ìlànà òdodo Ọlọrun sílẹ̀.​—⁠Deuteronomi 32:​4, 5; Romu 5:⁠12.

Pẹ̀lú gbogbo èyí, Ọlọrun ṣì ní ìyọ́nú fún àwọn ẹ̀dá ènìyàn tí ń jìyà. Èyí ni a fihàn kedere nínú ìlérí rẹ̀ láti mú òpin débá ìjìyà ẹ̀dá ènìyàn. “Wò ó! Àgọ́ Ọlọrun wà pẹlu aráyé, oun yoo sì máa bá wọn gbé, wọn yoo sì máa jẹ́ ènìyàn rẹ̀. Ọlọrun fúnra rẹ̀ yoo sì wà pẹlu wọn. Oun yoo sì nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú wọn, ikú kì yoo sì sí mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì yoo sí ọ̀fọ̀ tabi igbe ẹkún tabi ìrora mọ́. Awọn ohun àtijọ́ ti kọjá lọ.”​—⁠Ìṣípayá 21:​3, 4, NW; tún wo Isaiah 25:⁠8; 65:17-⁠25; Romu 8:​19-⁠21.

Àwọn ìlérí àgbàyanu wọ̀nyí jẹ́rìí sí i pé Ọlọrun mọ ìjìyà ẹ̀dá ènìyàn lára àti pé ó ti pinnu láti mú òpin dé bá a. Ṣùgbọ́n, lákọ̀ọ́kọ́ ná kí ni ohun náà gan-⁠an tí ó fa ìjìyà ẹ̀dá ènìyàn, èésìtiṣe ti Ọlọrun fi fàyègbà á láti máa bá a nìṣó títí di ọjọ́ wa?

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 2]

Ẹ̀yìn ìwé àti ojú-ìwé 32: Alexandra Boulat/Sipa Press

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 3]

Kevin Frayer/Sipa Press

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́