Àfikún Nínú Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso
PẸ̀LÚ èrò mímú kí àwọn òṣìṣẹ́ Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso ti Àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa gbòòrò síi, bẹ̀rẹ̀ láti July 1, 1994, mẹ́ḿbà mìíràn ni a ti fikún àwọn alàgbà 11 tí wọ́n ń ṣiṣẹ́sìn nísinsìnyí. Mẹ́ḿbà titun náà ni Gerrit Lösch.
Arákùnrin Lösch wọnú iṣẹ́-ìsìn alákòókò kíkún ní November 1, 1961, ó sì kẹ́kọ̀ọ́yege ní kíláàsì kọkànlélógójì ti Watchtower Bible School of Gilead. Ó ṣiṣẹ́sìn nínú iṣẹ́ àyíká àti agbègbè ní Austria láti ọdún 1963 sí 1976. Ó gbéyàwó ní ọdún 1967, lẹ́yìn náà òun pẹ̀lú aya rẹ̀, Merete, tún ṣiṣẹ́sìn fún ọdún 14 gẹ́gẹ́ bíi mẹ́ḿbà ìdílé Beteli ti Austria ní Vienna. A gbé wọn wá sí orílé-iṣẹ́ Society ní Brooklyn, New York, ní ọdún mẹ́rin sẹ́yìn, níbi tí Arákùnrin Lösch ti ṣiṣẹ́sìn ní Ọ́fíìsì Ìṣekòókárí àti gẹ́gẹ́ bí olùṣèrànlọ́wọ́ fún Ìgbìmọ̀ Iṣẹ́-Ìsìn. Pẹ̀lú onírúurú ìrírí tí ó ní nínú pápá ní Europe àti ìmọ̀ tí ó ní nínú èdè German, Gẹ̀ẹ́sì, Romanian, àti Italian, yóò lè ṣe ìrànwọ́ tí ó níyelórí fún iṣẹ́ tí Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso ń ṣe.