Èrè Jobu—Orísun kan Fún Ìrètí
“OLUWA . . . bùkún ìgbẹ̀yìn Jobu ju ìṣáájú rẹ̀ lọ.”—JOBU 42:12.
1. Kí ni Jehofa ń ṣe fún àwọn ènìyàn rẹ̀, àní nígbà tí àdánwò bá ti sọ wọn di aláìlágbára gan-an?
JEHOFA “di olùsẹ̀san fún awọn wọnnì tí ń fi taratara wá a.” (Heberu 11:6, NW) Ó tún sún àwọn ènìyàn rẹ̀ olùfọkànsìn láti jẹ́rìí tìgboyà-tìgboyà, kódà bí àdánwò bá ti sọ wọ́n di aláìlágbára bí òkú. (Jobu 26:5; Ìṣípayá 11:3, 7, 11) Ìyẹn jásí òtítọ́ nínú ọ̀ràn ti Jobu tí ìyà ń jẹ. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn olùtùnú èké mẹ́tẹ̀ẹ̀ta náà ṣáátá rẹ̀, ìbẹ̀rù ènìyàn kò mú kí ó panumọ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó jẹ́rìí láìṣojo.
2. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ti jìyà inúnibíni àti ìnira, báwo ni àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ṣe ń la àwọn àdánwò wọn já?
2 Ọ̀pọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí fún Jehofa lóde-òní ti jìyà irú inúnibíni àti ìnira tí ó gogò bẹ́ẹ̀ débi pé wọ́n ti súnmọ́ bèbè ikú. (2 Korinti 11:23) Bí ó ti wù kí ó rí, bíi ti Jobu, wọ́n ti fi ìfẹ́ fún Ọlọrun hàn wọ́n sì ti ṣòdodo. (Esekieli 14:14, 20) Wọ́n tún ti la àwọn àdánwò wọn já pẹ̀lú ìpinnu láti mú inú Jehofa dùn, a ti fún wọn lókun láti jẹ́rìí láìṣojo, wọ́n sì kún fún ojúlówó ìrètí.
Jobu Jẹ́rìí Láìṣojo
3. Irú ìjẹ́rìí wo ni Jobu fúnni nínú ọ̀rọ̀ àsọparí rẹ̀?
3 Nínú ọ̀rọ̀ àsọparí rẹ̀, Jobu jẹ́rìí tí ó tún bùáyà ju èyí tí ó ti ṣe ṣáájú lọ. Ó pa àwọn olùtùnú èké rẹ̀ lẹ́nu mọ́ pátápátá. Pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ tí kò báradé tí ń gúnnilára, ó wí pé: “Báwo ni ìwọ ń ṣe gba apá ẹni tí kò ní agbára?” (Jobu 26:2) Jobu gbé Jehofa ga, ẹni tí agbára rẹ̀ fi àgbáálá ilẹ̀-ayé wa rọ̀ sí ojú òfo ní òfuurufú tí ó sì fi àwọsánmà tí omi kún dẹ́dẹ́ rọ̀ sí orí ilẹ̀-ayé. (Jobu 26:7-9) Síbẹ̀, Jobu wí pé irú àwọn nǹkan àràmàǹdà bẹ́ẹ̀ ‘wulẹ̀ jẹ́ ìṣẹ́tí àwọn ọ̀nà Jehofa.’—Jobu 26:14, NW.
4. Kí ni Jobu sọ nípa ìwàtítọ́, èésìtiṣe tí òun fi lè sọ̀rọ̀ lọ́nà bẹ́ẹ̀?
4 Bí ó ti ní ìdánilójú pé òun jẹ́ aláìmọwọ́mẹsẹ̀, Jobu polongo pé: “Títí èmi óò fi kú èmi kì yóò ṣí ìwà òtítọ́ mi kúrò lọ́dọ̀ mi.” (Jobu 27:5) Ní òdìkejì sí àwọn ẹ̀sùn èké tí wọ́n fi kàn án, òun kò ṣe ohunkóhun tí ó yẹ fún ohun tí ó ṣubú tẹ̀ ẹ́. Jobu mọ̀ pé Jehofa kìí tẹ́tísí àdúrà àwọn apẹ̀yìndà ṣùgbọ́n yóò san èrè fún àwọn olùpa ìwàtítọ́ mọ́. Èyí lè rán wa létí dáradára pé láìpẹ́ ìjì Armageddoni yóò gba àwọn ènìyàn búburú kúrò ní ibùjókòó agbára wọn, wọn kì yóò sì lè yèbọ́ lọ́wọ́ Ọlọrun tí kìí dá ẹni ibi sí. Títí di ìgbà náà, àwọn ènìyàn Jehofa yóò máa rìn nínú ìwàtítọ́ wọn.—Jobu 27:11-23.
5. Báwo ni Jobu ṣe túmọ̀ ọgbọ́n tòótọ́?
5 Ronú nípa àwọn ọlọgbọ́n-ayé mẹ́tẹ̀ẹ̀ta náà tí wọ́n ń tẹ́tísí Jobu bí ó ṣe ń fihàn pé ènìyàn ti lo òye rẹ̀ láti fi wá wúrà, fàdákà, àti àwọn ohun ṣíṣeyebíye mìíràn nínú ilẹ̀ àti nínú òkun. Ó wí pé, “Iye ọgbọ́n sì ju òkúta rubi lọ.” (Jobu 28:18) Àwọn olùtùnú èké Jobu kò lè rí ọgbọ́n tòótọ́ rà. Ẹlẹ́dàá ìjì, òjò, mànàmáná, àti àrá ni orísun rẹ̀. Níti gidi, “ẹ̀rù” ọlọ́wọ̀ fún “Oluwa, èyí ni ọgbọ́n, àti láti jáde kúrò nínú ìwà-búburú èyí ni òye!”—Jobu 28:28.
6. Èéṣe tí Jobu fi sọ̀rọ̀ nípa ìgbésí-ayé rẹ̀ ìṣáájú?
6 Láìka ìjìyà rẹ̀ sí, Jobu kò ṣíwọ́ ṣíṣiṣẹ́sin Jehofa. Dípò kíkẹ̀yìn sí Ọ̀gá Ògo Jùlọ, ọkùnrin oníwàtítọ́ yìí yánhànhàn fún “ìbárẹ́ tímọ́tímọ́ tí ó ti ní ṣáájú pẹ̀lú Ọlọrun.” (Jobu 29:4, NW) Kìí ṣe pé Jobu ń fọ́nnu nígbà tí ó sọ nípa bí òun ṣe ‘gba tálákà tí ń sọkún, tí òun mú òdodo wọ̀, tí òun sì ṣe baba fún àwọn tálákà.’ (Jobu 29:12-16) Kàkà bẹ́ẹ̀, òun ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn ohun tí ó jẹ́ òtítọ́ nínú ìgbésí-ayé rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ olùṣòtítọ́ ti Jehofa. Ìwọ ha ti ní irú àkọsílẹ̀ rere bẹ́ẹ̀ bí? Gẹ́gẹ́ bí a ti lè retí, Jobu ń járọ́ àwọn ẹ̀sùn èké tí àwọn ẹlẹ̀tàn àgàbàgebè mẹ́tẹ̀ẹ̀ta náà fi kàn án pẹ̀lú.
7. Irú ènìyàn wo ní Jobu ti jẹ́ rí?
7 Àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin tí Jobu ‘kí yóò tilẹ̀ to bàbá wọn pẹ̀lú àwọn ajá agbo-ẹran rẹ̀’ fi í ṣẹ̀sín. Wọ́n kẹ́gàn rẹ̀ wọ́n sì bẹ́tọ́ síi lára. Bí ojú ṣe pọ́n ọn tó nì, wọn kò gba ti Jobu rò rárá. (Jobu 30:1, 10, 30) Nítorí pé òun fi tọkàn-tọkàn sin Jehofa délẹ̀-délẹ̀, bí ó ti wù kí ó rí, ó ní ẹ̀rí-ọkàn mímọ́ tónítóní ó sì lè sọ pé: “Kí a díwọ̀n mi nínú ìwọ̀n òdodo, kí Ọlọrun lè í mọ ìdúróṣinṣin mi.” (Jobu 31:6) Jobu kìí ṣe alágbèrè tàbí oníbékebèke, bẹ́ẹ̀ ni kò sì kùnà rí láti ran àwọn aláìní lọ́wọ́. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òun jẹ́ ọlọ́rọ̀ tẹ́lẹ̀rí, kò fìgbà kan rí gbẹ́kẹ̀lé ọrọ̀ nípa ti ara. Jù bẹ́ẹ̀ lọ, Jobu kò lọ́wọ́ nínú ìbọ̀rìṣà nípa jíjọ́sìn àwọn nǹkan aláìlẹ́mìí, irú bí òṣùpá. (Jobu 31:26-28) Ní gbígbẹ́kẹ̀lé Ọlọrun, ó fi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀ gẹ́gẹ́ bí olùpa ìwàtítọ́ mọ́. Láìka gbogbo ìjìyà rẹ̀ àti àwọn olùtùnú èké tí ń bẹ níkàlẹ̀ sí, Jobu ṣe ìgbèjà tí ó fòye hàn ó sì ṣe ìjẹ́rìí tí ó jíire. Bí àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ ti ń wá sópin, ó yíjú sí Ọlọrun gẹ́gẹ́ bí Onídàájọ́ rẹ̀ àti Olùsẹ̀san.—Jobu 31:35-40.
Elihu Tú Kẹ̀kẹ́ Ọ̀rọ̀
8. Ta ni Elihu, báwo sì ni ó ṣe fi ọ̀wọ̀ àti ìgboyà hàn?
8 Lẹ́bàá ibẹ̀ ni ọ̀dọ́mọkùnrin náà Elihu wà, àtọmọdọ́mọ Nahori ọmọkùnrin Busi tí ó sì tipa bẹ́ẹ̀ jẹ́ ẹbí ọ̀rẹ́ Jehofa náà Abrahamu. (Isaiah 41:8) Elihu fi ọ̀wọ̀ hàn fún àwọn àgbàlagbà nípa títẹ́tísí apá méjèèjì nínú ìjiyàn náà. Síbẹ̀, ó sọ̀rọ̀ tìgboyà-tìgboyà nípa àwọn ọ̀ràn tí wọ́n ti kùnà. Fún àpẹẹrẹ, ìbínú rẹ̀ sí Jobu fàru “nítorí tí ó dá araarẹ̀ láre kàkà kí ó dá Ọlọrun láre.” Èyí tí ó pe àfiyèsí jùlọ ni ìrunú Elihu tí ó darí lòdìsí àwọn olùtùnú èké náà. Àwọn gbólóhùn ọ̀rọ̀ wọn jọbí ẹni ń gbé Ọlọrun ga ṣùgbọ́n níti gidi wọ́n kẹ́gàn rẹ̀ nípa gbígbè sẹ́yìn Satani nínú àríyànjiyàn náà. ‘Nítorí pé ọ̀rọ̀ kún inú rẹ̀ láti sọ’ tí ẹ̀mí mímọ́ sì ń sún un ṣiṣẹ́, Elihu jẹ́ ẹlẹ́rìí aláìṣègbè fún Jehofa.—Jobu 32:2, 18, 21.
9. Báwo ni Elihu ṣe ta Jobu lólobó nípa ìmúpadàbọ̀sípò?
9 Dídá araarẹ̀ láre ti wá jẹ Jobu lógún ju ti Ọlọrun lọ. Ní tòótọ́, ó ti bá Ọlọrun jìjàdù. Ṣùgbọ́n, bí àtikú Jobu ṣe ń súnmọ́lé, a ta á lólobó nípa ìmúpadàbọ̀sípò kan. Báwo ni èyí ṣe wáyé? Ó dára, a sún Elihu láti sọ pé Jehofa ṣojúrere sí Jobu nípa ìhìn-iṣẹ́ yìí: “Gbà á kúrò nínu ìlọ sínú ihò, èmi ti rí ìràpadà! Ara rẹ̀ yóò sì jàyọ̀yọ̀ ju ti ọmọ kékeré, yóò sì tún padà sí ọjọ́ ìgbà èwe rẹ̀.”—Jobu 33:24, 25.
10. Títí dé ìwọ̀n àyè wo ni a óò dán Jobu wò, ṣùgbọ́n kí ni a lè ní ìdánilójú nípa rẹ̀ lójú-ìwòye 1 Korinti 10:13?
10 Elihu tọ́ Jobu sọ́nà fún sísọ pé kò sí èrè kankan nínú rírí ìdùnnú nínú dídi ìwàtítọ́ mú pẹ̀lú Ọlọrun. Elihu wí pé: “Ódoódì fún Ọlọrun tí ìbá fi hùwà búburú, àti fún Olodumare, tí yóò fi ṣe àìṣedéédéé! Nítorí pé ẹ̀san iṣẹ́ ènìyàn ni yóò san fún un.” Jobu fi ìwàǹwára hùwà láti lè tẹnumọ́ òdodo araarẹ̀, ṣùgbọ́n ó ṣe bẹ́ẹ̀ láìní ìmọ̀ pípéye àti òye jíjinlẹ̀. Elihu fikún un pé: “Ìfẹ́ mi ni kí a dán Jobu wò dé òpin, nítorí ìdáhùn rẹ̀ nípa ọ̀nà ènìyàn búburú.” (Jobu 34:10, 11, 35, 36) Bákan náà, ìgbàgbọ́ àti ìwàtítọ́ wa ni a lè fi hàn délẹ̀-délẹ̀ kìkì bí a bá “dán” wa “wò dé òpin” ní àwọn ọ̀nà kan. Ṣùgbọ́n, Bàbá wa ọ̀run onífẹ̀ẹ́ kì yóò jẹ́ kí a dán wa wò rékọjá ohun tí a lè faradà lọ.—1 Korinti 10:13.
11. Nígbà tí a bá dán wa wò gidigidi, kí ni a níláti rántí?
11 Bí Elihu ti ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ, ó fihàn lẹ́ẹ̀kan síi pé Jobu ń tẹnumọ́ òdodo araarẹ̀ jù. Atóbilọ́lá Ẹlẹ́dàá wa ni a níláti darí àfiyèsí sí. (Jobu 35:2, 6, 10) Ọlọrun “kìí dá ẹ̀mí ènìyàn búburú sí, ṣùgbọ́n ó fi òtítọ́ fún àwọn tálákà,” ní Elihu wí. (Jobu 36:6) Kò sí ẹni tí ó lè gbé ìbéèrè dìde sí ọ̀nà Ọlọrun kí ó sì sọ pé òun ti jẹ́ olódodo. Ó galọ́lá ju bí a ṣe lè mọ̀ lọ, àwọn ọdún rẹ̀ sì jẹ́ àwámáridìí tí kò lópin. (Jobu 36:22-26) Nígbà tí a bá dán ọ wò gidigidi, rántí pé Ọlọrun wa tí ó wà títí-ayé jẹ́ olódodo yóò sì san èrè fún wa fún àwọn ìgbòkègbodò àfòtítọ́ṣe wa tí ń mú ìyìn wá fún un.
12. Kí ni àwọn ọ̀rọ̀ àsọparí Elihu fihàn nípa bí Ọlọrun yóò ṣe mú ìdàjọ́ ṣẹ lórí àwọn ènìyàn búburú?
12 Bí Elihu ṣe ń sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, ìjì kan ń gbárajọ. Bí ó ti ń súnmọ́tòsí, ọkàn-àyà rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí lù kìkì àyà rẹ̀ sì já. Ó sọ̀rọ̀ nípa àwọn nǹkan ńláǹlà tí Jehofa ti ṣe ó sì wí pé: “Jobu dẹtí sílẹ̀ sí èyí, dúró jẹ́, kí o sì ro iṣẹ́ ìyanu Ọlọrun.” Bíi ti Jobu, ó yẹ kí a gbé àwọn iṣẹ́ ìyanu Ọlọrun àti iyì amúnikúnfún ìbẹ̀rù ọlọ́wọ̀ rẹ̀ yẹ̀wò. Elihu wí pé: “Nípa ti Olodumare àwa kò lè wádìí rẹ̀ rí, ó rékọjá ní ipá, òun kìí ba ìdájọ́ àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ òtítọ́ jẹ́. Nítorí náà ènìyàn a máa bẹ̀rù rẹ̀.” (Jobu 37:1, 14, 23, 24) Àwọn ọ̀rọ̀ àsọparí Elihu rán wa létí pé nígbà tí Ọlọrun yóò bá mú ìdájọ́ ṣẹ lórí àwọn ènìyàn búburú láìpẹ́, òun kì yóò fojú tẹ́ḿbẹ́lú ìdájọ́-òdodo àti òdodo, òun yóò sì pa àwọn wọnnì tí ń bẹ̀rù rẹ̀ mọ́ gẹ́gẹ́ bí àwọn tí ń fi tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ jọ́sìn rẹ̀. Ẹ wo irú àǹfààní tí ó jẹ́ láti wà lára irú àwọn olùpa ìwàtítọ́ mọ́ bẹ́ẹ̀ tí wọ́n mọ Jehofa gẹ́gẹ́ bí Ọba-Aláṣẹ Àgbáyé! Lo ìfaradà bíi ti Jobu, má sì ṣe jẹ́ kí Eṣu fà ọ́ lọ kúrò ní ibi tí a ti ń bùkún fún ọ láàárín àwọn ọ̀pọ̀ ènìyàn aláyọ̀ wọ̀nyí.
Jehofa Dá Jobu Lóhùn
13, 14. (a) Kí ni Jehofa bẹ̀rẹ̀ síi bi Jobu léèrè ọ̀rọ̀ nípa rẹ̀? (b) Àwọn kókó wo ni a rí fàyọ láti inú àwọn ìbéèrè mìíràn tí Ọlọrun bí Jobu?
13 Ẹ wo bí ẹnu yóò ti ya Jobu tó nígbà tí Jehofa báa sọ̀rọ̀ láti inú àjàyíká-ìjì! Àmúwá Ọlọrun ni ìjì yẹn jẹ́, ní ìyàtọ̀sí ìjì líle tí Satani lò láti wo ilé náà tí ó sì pa àwọn ọmọ Jobu. Jobu kò lè fọhùn bí Ọlọrun ṣe ń béèrè pé: “Níbo ni ìwọ wà nígbà tí mo fi ìpìlẹ̀ ayé sọlẹ̀? . . . Ta ni ó fi òkúta igun rẹ̀ lé ilẹ̀? Nígbà tí àwọn ìràwọ̀ òwúrọ̀ jùmọ̀ kọrin pọ̀, tí gbogbo àwọn ọmọ Ọlọrun ń hó ìhó ayọ?” (Jobu 38:4, 6, 7) Jehofa dojú ìbéèrè kan tẹ̀lé òmíràn kọ Jobu nípa òkun, aṣọ rẹ̀ tí ó fi àwọsánmà ṣe, ọ̀yẹ̀, ibodè ikú, iná àti òkùnkùn, àti àwọn ìdìpọ̀ ìràwọ̀. Jobu kò lè sọ ohunkóhun nígbà tí a bi í pé: “Ìwọ mọ ìlànà-ìlànà ọ̀run?”—Jobu 38:33.
14 Àwọn ìbéèrè mìíràn fihàn pé ṣáájú kí a tó dá ènìyàn kí a sì tó fi í jọba lórí ẹja, ẹyẹ, ẹranko, àti ohun tí ń rákò, Ọlọrun ti ń pèsè fún wọn—láìsí ìrànlọ́wọ́ tàbí ìmọ̀ràn ènìyàn èyíkéyìí. Àwọn ìbéèrè Jehofa síwájú síi fi àwọn ẹ̀dá bíi àgbọ̀nrín, ẹyẹ ògòǹgò, àti ẹṣin hàn. A bi Jobu pé: “Idì a máa fi àṣẹ rẹ fò lọ sókè, kí ó sì lọ tẹ́ ìtẹ́ rẹ̀ sí òkè gíga?” (Jobu 39:27) Dájúdájú bẹ́ẹ̀kọ́! Ronú nípa ìhùwàpadà Jobu nígbà tí Ọlọrun bi í pé: “Ẹni tí ń bá Olodumare jà, yóò ha kọ́ ọ ní ẹ̀kọ́?” Abájọ tí Jobu fi wí pé: “Kíyésí i, ẹ̀gbin ni èmi; ohùn kí ni èmi ó dá? èmi ó fi ọwọ́ mi lè ẹnu mi.” (Jobu 40:2, 4) Níwọ̀n bí Jehofa ti máa ń fìgbà gbogbo tọ̀nà, bí a bá dán wa wò láé láti ráhùn nípa rẹ̀, a níláti ‘fi ọwọ́ wa lé ẹnu wa.’ Àwọn ìbéèrè Ọlọrun pẹ̀lú gbé ipò-àjùlọ, iyì, àti okun rẹ̀ ga, bí àwọn ẹ̀dá rẹ̀ ti fihàn.
Behemotu àti Lefiatani
15. Ẹranko wo ni a lérò ní gbogbogbòò pé Behemotu jẹ́, kí sì ni díẹ̀ lára àwọn ànímọ́ rẹ̀?
15 Tẹ̀lé èyí ni Jehofa tún mẹ́nukan Behemotu, tí a lérò ní gbogbogbòò pé ó jẹ́ erinmi. (Jobu 40:15-24) Bí ó ti pẹtẹrí nítorí ìtóbi fàkìà-fakia rẹ̀, ìwọ̀n bíbùáyà, àti awọ rẹ̀ yíyi, ẹran jewéjewé yìí ‘ń jẹ ewéko tútù.’ Ìbàdí àti fọ́nrán-iṣan ikùn rẹ̀ ní orísun agbára àti okun rẹ̀. Àwọn egungun ẹsẹ̀ rẹ̀ le koránkorán bí “ògùṣọ̀ idẹ.” Behemotu kìí bẹ̀rù nínú ìṣàn omi lílágbára ṣùgbọ́n ó máa ń lúwẹ̀ẹ́ ní ìdojúkọ ìṣàn omi.
16. (a) Bí a ṣe ṣàpèjúwe Lefiatani ẹ̀dá wo ni ó bá mu, kí sì ni àwọn òtítọ́ díẹ̀ nípa rẹ̀? (b) Kí ni ohun tí agbára Behemotu àti Lefiatani lè fihàn nípa mímú àwọn iṣẹ́ àyànfúnni ṣẹ nínú iṣẹ́-ìsìn Jehofa?
16 Ọlọrun tún bi Jobu pé: “Ìwọ lè fi ìwọ̀ fa Lefiatani [ọ̀nì ńlá] jáde, tàbí ìwọ lè mú ahọ́n rẹ̀ nínú okùn?” Bí a ṣe ṣàpèjúwe Lefiatani bá ọ̀nì mu. (Jobu 41:1-34) Kìí ba ẹnikẹ́ni dá májẹ̀mú àlàáfíà, kò sì sí ẹ̀dá ènìyàn ọlọgbọ́n kan tí yóò lórí-láyà tóbẹ́ẹ̀ tí yóò fi tọ́jà ẹran afàyàfà yìí. Ọfà kìí lé e sá, bẹ́ẹ̀ ni “ó rẹ́rìn-ín sí ìmísí ọ̀kọ̀.” Lefiatani ti inú bá ń bí a máa mú kí omi hó bíi omi inú ìkòkò tí a fi ń se ohun ìkunra. Òtítọ́ náà pé Lefiatani àti Behemotu lágbára fíìfíì ju Jobu lọ ràn án lọ́wọ́ láti rẹ araarẹ̀ sílẹ̀. Àwa pẹ̀lú gbọ́dọ̀ fi tìrẹ̀lẹ̀-tìrẹ̀lẹ̀ gbà pé a kò lágbára nínú araawa. A nílò ọgbọ́n àti okun tí Ọlọrun ń fúnni láti lè dọ́gbọ́n yẹra fún àwọn eyín-oró Satani, Ejo náà, àti láti lè mú iṣẹ́ àyànfúnni wa ṣẹ nínú iṣẹ́-ìsìn Jehofa.—Filippi 4:13; Ìṣípayá 12:9.
17. (a) Ọ̀nà wo ni Jobu gbà “rí Ọlọrun”? (b) Ẹ̀rí kí ni àwọn ìbéèrè tí Jobu kò lè dáhùn fihàn, báwo sì ni èyí ṣe lè ràn wá lọ́wọ́?
17 Lẹ́yìn rírẹ ọkàn rẹ̀ sílẹ̀ pátápátá, Jobu mọ̀ pé òun ti ní ojú-ìwòye tí ó lòdì ó sì gbà pé òun ti sọ̀rọ̀ láìní ìmọ̀. Síbẹ̀, ó ti fí ìgbàgbọ́ hàn pé òun yóò “rí Ọlọrun.” (Jobu 19:25-27) Báwo ni ìyẹn ṣe lè ṣẹlẹ̀, níwọ̀n bí kò ti sí ènìyàn kan tí ó lè rí Jehofa tíí sìí wàláàyè? (Eksodu 33:20) Níti tòótọ́, Jobu rí ìfihàn agbára àtọ̀runwá, ó gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọrun, a sì ṣí ojú òye rẹ̀ sí òtítọ́ nípa Jehofa. Nítorí náà Jobu ‘ronúpìwàdà ṣe tótó nínú ekuru àti eérú.’ (Jobu 42:1-6) Ọ̀pọ̀ àwọn ìbéèrè tí kò lè dáhùn ti fi ipò-àjùlọ Ọlọrun hàn ó sì ti fi bí ènìyàn ṣe kéré tó hàn, àní ẹnìkan tí ó jẹ́ olùfọkànsin Jehofa bíi ti Jobu pàápàá. Èyí ràn wá lọ́wọ́ láti rí i pé a kò níláti gbé àwọn ìfẹ́-ọkàn wa lékè ìsọdimímọ́ orúkọ Jehofa àti ìdáláre ipò ọba-aláṣẹ rẹ̀. (Matteu 6:9, 10) Dídi ìwàtítọ́ mú sí Jehofa àti bíbọlá fún orúkọ rẹ̀ ni ó gbọ́dọ̀ jẹ́ ohun tí ó jẹ wá lógún jùlọ.
18. Kí ni àwọn olùtùnú èké Jobu níláti ṣe?
18 Ṣùgbọ́n, kí ni nípa ti àwọn olùtùnú èké tí wọ́n jẹ́ olódodo lójú araawọn náà? Jehofa kì ba ti pa Elifasi, Bildadi, àti Sofari fún ṣíṣàì sọ òtítọ́ nípa òun, gẹ́gẹ́ bí Jobu ti ṣe, tí ohunkóhun kò sì ni tẹ̀yìn rẹ̀ yọ. Ọlọrun wí pé: “Ẹ mú akọ ẹgbọrọ màlúù méje, àti àgbò méje, kí ẹ sì tọ Jobu ìránṣẹ́ mi lọ, kí ẹ sì fi rú ẹbọ sísun fún araayín: Jobu ìránṣẹ́ mi yóò sì gbàdúrà fún yín.” Àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta náà níláti rẹ araawọn sílẹ̀ láti lè ṣe bẹ́ẹ̀. Jobu olùpa ìwàtítọ́ mọ́ ni yóò gbàdúrà fún wọn, Jehofa sì tẹ́wọ́gba àdúrà rẹ̀. (Jobu 42:7-9) Ṣùgbọ́n aya Jobu ńkọ́, ẹni tí ó rọ̀ ọ́ láti bú Ọlọrun kí ó sì kú? Ó jọbí ẹni pé a mú un padà bá Jobu rẹ́ nípasẹ̀ àánú Ọlọrun.
Àwọn Èrè Tí A Ṣèlérí Ń Fún Wa Ní Ìrètí
19. Ní ìsopọ̀ pẹ̀lú Jobu, báwo ni Jehofa ṣe fi ipò àjùlọ Rẹ̀ lórí Eṣu hàn?
19 Gẹ́rẹ́ tí Jobu jáwọ́ ṣíṣàníyàn nípa ìjìyà rẹ̀ tí a sì mú un padàbọ̀ sínú iṣẹ́-ìsìn Ọlọrun, Jehofa yí àwọn ọ̀ràn padà fún un. Lẹ́yìn tí Jobu gbàdúrà fún àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta náà, Ọlọrun ‘yí ìgbèkùn rẹ̀ padà’ ó sì fún un ní ‘gbogbo ohun tí ó ní rí ní ìṣẹ́po méjì.’ Jehofa fi ipò àjùlọ Rẹ̀ lórí Eṣu hàn nípa yíyí ọwọ amú-àìsànṣeni ti Satani padà àti wíwo Jobu sàn lọ́nà ìyanu. Bákan náà ni Ọlọrun ti àwọn ẹgbẹẹgbẹ̀fúlẹ́ ẹ̀mí-èṣù sẹ́yìn ó sì lé wọn jìnnà rere nípa fífi àwọn áńgẹ́lì Rẹ̀ adáàbòboni sọgbà yí Jobu ka lẹ́ẹ̀kan síi.—Jobu 42:10; Orin Dafidi 34:7.
20. Ní àwọn ọ̀nà wo ni Jehofa gbà san èrè fún Jobu tí ó sì bùkún fún un?
20 Àwọn arákùnrin, arábìnrin, àti àwọn ojúlùmọ̀ Jobu tẹ́lẹ̀rí bẹ̀rẹ̀ sí rọ́wá láti bá a jẹun, bá a kẹ́dùn, kí wọ́n sì tù ú nínú látàrí àwọn àjálù tí Jehofa ti fàyègbà láti wá sórí rẹ̀. Ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn fún Jobu ní owó àti òrùka wúrà. Jehofa bùkún ìgbẹ̀yìn Jobu ju ìṣáájú rẹ̀ lọ, débi pé ó ní 14,000 àgùtàn, 6,000 ìbakasíẹ, 1,000 àjàgà ọ̀dá-màlúù, àti 1,000 abo kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́. Jobu tún bí ọmọkùnrin méje àti ọmọbìnrin mẹ́ta, iye tí ó ní tẹ́lẹ̀rí. Àwọn ọmọbìnrin rẹ̀—Jemima, Kesia, àti Keren-happuki—ní àwọn ọmọbìnrin tí wọ́n rẹwà jùlọ ní ilẹ̀ náà, Jobu sì pín ogún fún wọn láàárín àwọn arákùnrin wọn. (Jobu 42:11-15) Jù bẹ́ẹ̀ lọ, Jobu gbé ayé fún 140 ọdún mìíràn síi ó sì rí ìran ọmọ-ọmọ rẹ̀ kẹrin. Àkọsílẹ̀ náà wá sí ìparí báyìí pé: “Bẹ́ẹ̀ni Jobu kú, ó gbó, ó sì kún fún ọjọ́.” (Jobu 42:16, 17) Gígún síwájú síi ọjọ́ ayé rẹ̀ jẹ́ iṣẹ́ ìyanu látọwọ́ Jehofa Ọlọrun.
21. Báwo ni àkọsílẹ̀ Ìwé Mímọ́ nípa Jobu ṣe ràn wá lọ́wọ́, kí sì ni a níláti pinnu láti ṣe?
21 Àkọsílẹ̀ Ìwé Mímọ́ nípa Jobu mú kí a túbọ̀ wà lójúfò síi nípa àwọn irin-iṣẹ́ Satani ó sì ràn wá lọ́wọ́ láti rí bí ipò ọba-aláṣẹ àgbáyé ṣe tanmọ́ ìwàtítọ́ ẹ̀dá ènìyàn. Bíi ti Jobu, gbogbo àwọn tí wọ́n bá nífẹ̀ẹ́ Ọlọrun ni a óò dánwò. Ṣùgbọ́n a lè lo ìfaradà bí Jobu ti ṣe. Ó ru àwọn àdánwò rẹ̀ là pẹ̀lú ìgbàgbọ́ àti ìrètí, àwọn èrè rẹ̀ sì pọ̀. Gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ Jehofa lónìí, a ní ìgbàgbọ́ àti ìrètí tòótọ́. Ẹ sì wo irú ìrètí kíkọyọyọ tí Atóbilọ́lá Olùsẹ̀san náà ti gbé síwájú wa! Fífi èrè ti ọ̀run náà sọ́kàn yóò ran àwọn ẹni-àmì-òróró lọ́wọ́ láti fi ìdúróṣinṣin sin Ọlọrun fún ìyókù ìwàláàyè wọn lórí ilẹ̀-ayé. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn tí wọ́n ní ìfojúsọ́nà ti orí ilẹ̀-ayé kì yóò kú rárá, ṣùgbọ́n àwọn tí wọ́n bá kú ni a óò fi àjíǹde sórí Paradise ilẹ̀-ayé san èrè fún, àti Jobu gan-an alára. Pẹ̀lú irú ojúlówó ìrètí bẹ́ẹ̀ ní ọkàn-àyà àti iyè-inú wa, ẹ jẹ́ kí gbogbo àwọn tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ Ọlọrun fi Satani hàn ní òpùrọ́ nípa dídúró ṣinṣin lẹ́gbẹ̀ẹ́ Jehofa gẹ́gẹ́ bí àwọn olùpa ìwàtítọ́ mọ́ àti alátìlẹyìn gbágbágbá fún ipò ọba-aláṣẹ àgbáyé rẹ̀.
Báwo Ni Ìwọ Yóò Ṣe Fèsìpadà?
◻ Kí ni díẹ̀ lára àwọn kókó tí ó gbẹ̀yìn tí Jobu sọ nínú àwọn èsì tí ó fún àwọn olùtùnú èké rẹ̀?
◻ Báwo ni Elihu ṣe fi ẹ̀rí hàn pé ẹlẹ́rìí aláìṣègbè ti Jehofa ni òun jẹ́
◻ Kí ni díẹ̀ lára àwọn ìbéèrè Ọlọrun sí Jobu, ipa wo ni wọ́n sì ni?
◻ Ìwọ ha ti jàǹfààní láti inú àkọsílẹ̀ Ìwé Mímọ́ nípa Jobu bí?
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
Àwọn gbólóhùn ọ̀rọ̀ Jehofa nípa Behemotu àti Lefiatani ṣèrànwọ́ láti rẹ ọkàn Jobu sílẹ̀