Ọ̀rọ̀ Jèhófà Yè
Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Jóòbù
ILẸ̀ Úsì tó wà nílẹ̀ Arébíà lóde òní ni Jóòbù ń gbé nígbà tó wà láyé. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó ń gbé nílẹ̀ Íjíbítì nígbà náà pọ̀ gan-an. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jóòbù kì í ṣe ọmọ Ísírẹ́lì, Jèhófà Ọlọ́run ló ń sìn. Bíbélì sọ nípa rẹ̀ pé: “Kò sí ẹnì kankan tí ó dà bí rẹ̀ ní ilẹ̀ ayé, ọkùnrin aláìlẹ́bi àti adúróṣánṣán, tí ó bẹ̀rù Ọlọ́run, tí ó sì ń yà kúrò nínú ohun búburú.” (Jóòbù 1:8) Ó ní láti jẹ́ pé àkókò kan lẹ́yìn ikú Jósẹ́fù ọmọ Jákọ́bù àti ṣáájú kí Mósè tó di wòlíì ni Jóòbù gbé láyé. Àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà méjèèjì náà jẹ́ àpẹẹrẹ tó ta yọ.
Àwọn kan sọ pé ó ní láti jẹ́ pé Mósè ló kọ ìwé Jóòbù. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ìgbà tí Mósè lo ogójì ọdún ní Mídíánì, èyí tí kò jìnnà sí ilẹ̀ Úsì ló mọ̀ nípa Jóòbù. Ó lè jẹ́ pé àkókò táwọn ọmọ Ísírẹ́lì wà nítòsí Úsì, nígbà tí ìrìn-àjò tí wọ́n rìn fún ogójì ọdún nínú aginjù ti fẹ́rẹ̀ẹ́ parí, ni Mósè gbọ́ nípa ìgbẹ̀yìn ayé Jóòbù.a Ọ̀nà tí wọ́n gbà kọ ìtàn Jóòbù dára débi pé àwọn kan gbà pé àgbà ìtàn ni. Àmọ́, ó tiẹ̀ tún jù bẹ́ẹ̀ lọ torí pé ó dáhùn àwọn ìbéèrè bíi: Kí nìdí táwọn èèyàn rere fi ń jìyà? Kí nìdí tí Jèhófà fi gba ìwà burúkú láyè? Ǹjẹ́ ó ṣeé ṣe fún àwọn ẹ̀dá aláìpé láti jẹ́ olóòótọ́ sí Ọlọ́run? Níwọ̀n bí ìwé Jóòbù ti jẹ́ ara Ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run mí sí, ọ̀rọ̀ inú rẹ̀ yè ó sì ń sa agbára, àní láyé òde òní pàápàá.—Hébérù 4:12.
“KÍ ỌJỌ́ TÍ A BÍ MI KÍ Ó ṢÈGBÉ”
Lọ́jọ́ kan Sátánì sọ fún Ọlọ́run pé tọkàntọkàn kọ́ ni Jóòbù fi ń sìn ín. Jèhófà ò bá Sátánì jiyàn lórí ohun tó sọ, ó sì gbà á láyè láti mú onírúurú àjálù bá Jóòbù. Àmọ́ pẹ̀lú gbogbo ẹ̀ náà, Jóòbù ò “bú Ọlọ́run.”—Jóòbù 2:9.
Àwọn ọ̀rẹ́ Jóòbù mẹ́ta wá sọ́dọ̀ rẹ̀ “láti wá bá a kẹ́dùn.” (Jóòbù 2:11) Wọ́n jókòó tì í láìsọ ẹyọ ọ̀rọ̀ kan títí Jóòbù fi fọhùn tó ní: “Kí ọjọ́ tí a bí mi kí ó ṣègbé.” (Jóòbù 3:3) Ó ní ì bá sàn kí ayé òun dà bíi ti “àwọn ọmọ tí kò rí ìmọ́lẹ̀,” ìyẹn àwọn ọmọ tí wọ́n bí lókùú.—Jóòbù 3:11, 16.
Ìdáhùn Àwọn Ìbéèrè Tó Jẹ Yọ:
1:4—Ṣé àwọn ọmọ Jóòbù máa ń ṣe ọjọ́ ìbí wọn ni? Rárá o. Ọ̀rọ̀ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ làwọn Hébérù ń lò fún “ọjọ́” àti “ọjọ́ ìbí,” ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ méjèèjì sì yàtọ̀ síra. (Jẹ́nẹ́sísì 40:20) Nínú Jóòbù 1:4, “ọjọ́” ni ọ̀rọ̀ tí Bíbélì lò, èyí tó dúró fún àkókò tó wà láàárín ìgbà tí oòrùn là àti ìgbà tí oòrùn wọ̀. Ó jọ pé àwọn ọmọkùnrin Jóòbù méjèèje máa ń pàdé lẹ́ẹ̀kan lọ́dún láti ṣe ìpàdé ìdílé ọlọ́jọ́ méje. Ní ‘ọjọ́ tó bá ti yí kan’ ọmọ kan, yóò gba àwọn yòókù lálejò, yóò sì se àsè ńlá nínú ilé rẹ̀.
1:6; 2:1—Àwọn wo ni Jèhófà gbà láyè kó wọlé wá láti dúró níwájú rẹ̀? Lára àwọn tó dúró níwájú Jèhófà ni Ọ̀rọ̀, ìyẹn Ọmọ bíbí kan ṣoṣo Ọlọ́run; àwọn áńgẹ́lì olóòótọ́; àtàwọn áńgẹ́lì aláìgbọràn táwọn náà jẹ́ ‘ọmọ Ọlọ́run,’ tí Sátánì Èṣù wà lára wọn. (Jòhánù 1:1, 18) Kété lẹ́yìn tí Ọlọ́run fìdí Ìjọba rẹ̀ múlẹ̀ lọ́dún 1914 ni Jésù lé Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ kúrò lọ́run. (Ìṣípayá 12:1-12) Jèhófà gbà wọ́n láyè láti wọlé wá síwájú rẹ̀ pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn áńgẹ́lì yòókù kí gbogbo ẹ̀dá ọ̀run lè mọ̀ nípa ohun tí Sátánì ń sọ pé Jèhófà kọ́ ló yẹ kó jẹ́ ọba aláṣẹ ayé òun ọ̀run, kí wọ́n sì tún mọ àwọn ọ̀ràn míì tí ohun tí Sátánì ń sọ yìí dá sílẹ̀.
1:7; 2:2—Ṣé Jèhófà fúnra rẹ̀ ló bá Sátánì sọ̀rọ̀? Bíbélì ò sọ kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa bí Jèhófà ṣe ń bá àwọn áńgẹ́lì sọ̀rọ̀. Àmọ́, nínú ìran kan tí wòlíì Mikáyà rí, ó rí áńgẹ́lì kan tó ń bá Jèhófà sọ̀rọ̀ lójúkojú. (1 Àwọn Ọba 22:14, 19-23) Nítorí náà, ó jọ pé ńṣe ni Jèhófà bá Sátánì sọ̀rọ̀ láìsí agbọ̀rọ̀sọ kankan.
1:21—Báwo ni Jóòbù ṣe lè padà sínú “ikùn ìyá” rẹ̀? Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé “láti inú ekuru ilẹ̀” ni Jèhófà Ọlọ́run ti dá èèyàn, ńṣe ni Jóòbù lo ọ̀rọ̀ náà, “ìyá” nínú ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ láti tọ́ka sí ilẹ̀.—Jẹ́nẹ́sísì 2:7.
2:9—Kí ló ṣeé ṣe kó sún aya Jóòbù sọ pé kí ọkọ òun bú Ọlọ́run kó sì kú? Gbogbo àdánù tó bá Jóòbù ló kan ìyàwó rẹ̀. Ó ní láti dùn ún gan-an bó ṣe ń rí i tí ọkọ rẹ̀ tí ara rẹ̀ le koko tẹ́lẹ̀ di ẹni tí àìsàn burúkú kan sọ dìdàkudà. Yàtọ̀ síyẹn, ó ti pàdánù àwọn ọmọ rẹ̀ ọ̀wọ́n. Gbogbo èyí lè ti jẹ́ kí ọkàn rẹ̀ dà rú gan-an débi tí kò fi fọkàn sí ohun tó ṣe pàtàkì jù, ìyẹn àjọṣe wọn pẹ̀lú Ọlọ́run.
Ẹ̀kọ́ Tá A Rí Kọ́:
1:8-11; 2:3-5. Ìtàn Jóòbù jẹ́ ká rí i pé yàtọ̀ sí pé kéèyàn máa sọ̀rọ̀ tó dára kó sì máa hùwà tó bójú mu, ẹni tó bá jẹ́ oníwà títọ́ ní láti rí i pé kì í ṣe tìtorí àwọn àǹfààní tòun máa rí lòun ṣe ń sin Jèhófà.
1:21, 22. Tá a bá jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà, yálà nígbà tí nǹkan rọgbọ tàbí nígbà tí nǹkan ò rọgbọ, a ó lè fi hàn pé òpùrọ́ ni Sátánì.—Òwe 27:11.
2:9, 10. Ìgbàgbọ́ wa ní láti dúró sán-ún bíi ti Jóòbù, kódà bí àwọn ìgbòkègbodò wa nínú ètò Ọlọ́run ò bá tiẹ̀ ṣe pàtàkì lójú àwọn aráalé àti mọ̀lẹ́bí wa tàbí tí wọ́n bá fẹ́ mú wa ṣe ohun tó lòdì sí ìgbàgbọ́ wa tàbí pé wọ́n fẹ́ mú ká kúrò nínú ètò pàápàá.
2:13. Àwọn ọ̀rẹ́ Jóòbù kò ní ọ̀rọ̀ ìtùnú kankan láti sọ fún un nípa Ọlọ́run àtàwọn ìlérí rẹ̀ nítorí pé ojú èèyàn ẹlẹ́ran ara ni wọ́n fi ń wo nǹkan.
“ÈMI KÌ YÓÒ MÚ ÌWÀ TÍTỌ́ MI KÚRÒ LỌ́DỌ̀ MI!”
Ohun táwọn ọ̀rẹ́ Jóòbù mẹ́tẹ̀ẹ̀ta ń sọ ni pé, Jóòbù ti ní láti ṣe ohun kan tó burú gan-an ni Ọlọ́run ṣe ń fìyà tó pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ jẹ ẹ́. Élífásì ló kọ́kọ́ sọ̀rọ̀. Lẹ́yìn tirẹ̀ ni Bílídádì wá sọ̀rọ̀, ó sì fọ̀rọ̀ gún Jóòbù lára ju Élífásì lọ. Kékeré ni ọ̀rọ̀ ti Bílídádì tún wá jẹ́ lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọ̀rọ̀ kòbákùngbé tí Sófárì sọ.
Jóòbù ò fara mọ́ àlàyé òdì táwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ ń ṣe. Níwọ̀n bí kò ti mọ ìdí tí Ọlọ́run fi ń jẹ́ kí òun jìyà, ó bẹ̀rẹ̀ sí dá ara rẹ̀ láre. Síbẹ̀, Jóòbù nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run. Ó sọ pé: “Títí èmi yóò fi gbẹ́mìí mì, èmi kì yóò mú ìwà títọ́ mi kúrò lọ́dọ̀ mi!”—Jóòbù 27:5.
Ìdáhùn Àwọn Ìbéèrè Tó Jẹ Yọ:
7:1; 14:14—Kí ni “òpò àpàpàǹdodo” túmọ̀ sí? Ìnira Jóòbù pọ̀ débi pé ó ronú pé ìgbésí ayé ti le jù, ó sì kà á sí òpò àpàpàǹdodo tí ń tánni lókun. (Jóòbù 10:17) Jóòbù tún ka àkókò téèyàn fi wà nínú Ṣìọ́ọ̀lù, ìyẹn láti ìgbà téèyàn ti kú títí dìgbà téèyàn máa jíǹde, sí òpò àpàpàǹdodo torí pé ńṣe lèèyàn wà níbẹ̀ ní ọ̀ranyàn.
7:9, 10; 10:21; 16:22—Ǹjẹ́ àwọn ohun tí Jóòbù sọ nínú àwọn ẹsẹ wọ̀nyí fi hàn pé Jóòbù ò gbà pé àjíǹde wà? Ọ̀rọ̀ wọ̀nyí jẹ́ ká mọ ohun tó máa tó ṣẹlẹ̀ sí Jóòbù. Kí wá ló ní lọ́kàn? Ó lè jẹ́ pé ohun tí Jóòbù ní lọ́kàn ni pé, kò sí ìkankan lára àwọn tí wọ́n jọ wà láyé nígbà yẹn tó máa rí òun mọ́ tóun bá ti kú. Èrò wọn ni pé Jóòbù ò ní padà sí ilé rẹ̀ mọ́ bẹ́ẹ̀ ni kò ní sí ẹni tó máa mọ̀ ọ́n mọ́ títí dìgbà tí Ọlọ́run bá sọ pé àkókò tó fún un láti jíǹde. Ó sì tún lè jẹ́ pé ohun tí Jóòbù ní lọ́kàn ni pé, kò sẹ́ni tó lè fúnra rẹ̀ kúrò nínú Ṣìọ́ọ̀lù. Jóòbù 14:13-15 jẹ́ ká rí i kedere pé Jóòbù ń retí pé Ọlọ́run máa jí òun dìde lọ́jọ́ iwájú.
10:10—Báwo ni Jèhófà ṣe ‘da Jóòbù jáde gẹ́gẹ́ bí wàrà, tó sì mú un dì gẹ́gẹ́ bí wàràkàṣì’? Ńṣe ni Jóòbù lo ewì láti fi ṣàpèjúwe bí Ọlọ́run ṣe mú kí Jóòbù di ọlẹ̀ níkùn ìyá rẹ̀.
19:20—Kí ni Jóòbù ní lọ́kàn nígbà tó sọ pé “bí awọ eyín mi ni mo sì fi yèbọ́”? Bí Jóòbù ṣe sọ pé òun yè bọ́ pẹ̀lú awọ eyín, èyí tó jẹ́ pé, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé kò sí nǹkan kan tó bò ó, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ńṣe ni Jóòbù ń sọ pé òun yè bọ́ láìsí ohunkóhun tó bá òun yè bọ́.
Ẹ̀kọ́ Tá A Rí Kọ́:
4:7, 8; 8:5, 6; 11:13-15. Bí ẹnì kan bá wà nínú ìṣòro, kò yẹ ká kàn gbà pé ńṣe ni onítọ̀hún ń jèrè iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ tàbí pé Ọlọ́run ò fi ojú rere wò ó.
4:18, 19; 22:2, 3. Orí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ló yẹ ká máa gbé ìmọ̀ràn tá a bá fẹ́ fúnni kà, kì í ṣe orí èrò tara wa.—2 Tímótì 3:16.
10:1. Ìkorò ọkàn Jóòbù pọ̀ débi pé kò ronú pé àwọn nǹkan mìíràn tún wà tó tún lè fa ìṣòro tó dé bá òun. Kò yẹ ká bọkàn jẹ́ jù bí a bá wà nínú ìṣòro, pàápàá nígbà tá a ti mọ ohun tí Èṣù sọ lórí ọ̀rọ̀ ìwà títọ́ àwa ẹ̀dá èèyàn.
14:7, 13-15; 19:25; 33:24. Ìrètí pé àwọn òkú yóò jíǹde lè fún wa lókun nígbà tá a bá wà nínú ìṣòro èyíkéyìí tí Sátánì bá mú bá wa.
16:5; 19:2. Ńṣe ló yẹ ká máa fi ọ̀rọ̀ wa gbé àwọn ẹlòmíì ró, ká sì máa fi tù wọ́n nínú, kì í ṣe pé ká máa fọ̀rọ̀ gún wọn lára.—Òwe 18:21.
22:5-7. Tá a bá ń bá ẹnì kan wí lórí ẹ̀sùn tó jẹ́ pé kò sí ẹ̀rí tó dájú, irú ìbáwí bẹ́ẹ̀ kò wúlò, ó sì lè ba ẹni náà lọ́kàn jẹ́.
27:2; 30:20, 21. Kò dìgbà téèyàn bá di ẹni pípé kó tó lè jẹ́ adúróṣinṣin. Àṣìṣe ńlá ni Jóòbù ṣe bó ṣe lọ ń dá Ọlọ́run lẹ́bi.
27:5. Jóòbù fúnra rẹ̀ ló lè pinnu pé òun ò ní hu ìwà títọ́ mọ́. Ìdí ni pé ìfẹ́ téèyàn ní sí Ọlọ́run ni yóò jẹ́ kó máa hùwà títọ́. Nítorí náà, ó yẹ ká rí i pé ìfẹ́ tá a ní sí Jèhófà lágbára gan-an.
28:1-28. Àwa èèyàn mọ ibi tí ìṣúra inú ilẹ̀ wà. Bí a ṣe ń wá wọn, a lè fi ọgbọ́n walẹ̀ lọ sí àwọn ọ̀nà abẹ́lẹ̀ níbi tí ẹyẹ aṣọdẹ èyíkéyìí tó ń ríran jìnnà ò lè rí. Àmọ́ o, ìbẹ̀rù Jèhófà nìkan ló lè jẹ́ ká ní ọgbọ́n Ọlọ́run.
29:12-15. Ó yẹ ká máa fi tinútinú ran àwọn aláìní lọ́wọ́.
31:1, 9-28. Jóòbù fi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀ fún wa ní ti pé kì í bá àwọn obìnrin tage, kì í ṣe panṣágà, kì í hùwà ìrẹ́jẹ, ó máa ń ṣàánú àwọn ẹlòmíràn, kò nífẹ̀ẹ́ ọrọ̀ àlùmọ́nì, bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe abọ̀rìṣà.
‘MO RONÚ PÌWÀ DÀ NÍNÚ EKURU ÀTI EÉRÚ’
Ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Élíhù tí kò dàgbà tó àwọn tó kù wà níbẹ̀, ó ń tẹ́tí sí gbogbo ohun tí wọ́n ń sọ. Ní báyìí, ó fẹ́ tú kẹ̀kẹ́ ọ̀rọ̀. Ó bá Jóòbù wí, ó sì tún bá àwọn mẹ́ta tí wọ́n wá bà á nínú jẹ́ wí.
Gbàrà tí Élíhù parí ọ̀rọ̀ rẹ̀ ni Jèhófà dáhùn látinú ìjì ẹlẹ́fùúùfù. Kò sọ ìdí tí Jóòbù fi ń jìyà. Àmọ́ Olódùmarè bi Jóòbù ní ọ̀pọ̀ ìbéèrè kó lè mọ̀ pé alágbára ńlá àti oníbú ọgbọ́n ni òun Ọlọ́run. Jóòbù gbà pé òun kò ronú jinlẹ̀ kóun tó sọ̀rọ̀, ó wá sọ pé: ‘Mo yíhùn padà, mo sì ronú pìwà dà nínú ekuru àti eérú.’ (Jóòbù 42:6) Ọlọ́run san Jóòbù lẹ́san nítorí ìdúróṣinṣin rẹ̀ nígbà tí ìṣòro rẹ̀ dópin.
Ìdáhùn Àwọn Ìbéèrè Tó Jẹ Yọ:
32:1-3—Ìgbà wo ni Élíhù dé? Gbogbo ọ̀rọ̀ tí wọ́n sọ ni Élíhù gbọ́, èyí sì fi hàn pé ó ti ní láti jókòó sítòsí níbi tó ti lè máa gbọ́ ohun tí wọ́n ń sọ kó tó di pé Jóòbù fọhùn lẹ́yìn ọjọ́ méje táwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ mẹ́ta ti dákẹ́ láìsọ nǹkan kan.—Jóòbù 3:1, 2.
34:7—Báwo ni Jóòbù ṣe dà bí ọkùnrin “tí ń mu ìfiniṣẹ̀sín bí ẹní mu omi”? Nínú ìbànújẹ́ ọkàn Jóòbù, ó ronú pé òun ni àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ mẹ́ta náà ń sọ àwọn ọ̀rọ̀ ìbàjẹ́ tí wọ́n ń sọ sí, bó tilẹ̀ jẹ́ pé Ọlọ́run gan-an ni wọ́n ń sọ ọ́ sí. (Jóòbù 42:7) Nípa bẹ́ẹ̀, ńṣe ló ń gba gbogbo ọ̀rọ̀ ìbàjẹ́ tí wọ́n ń sọ sára bí ẹni tó ń fi ìdùnnú mu omi.
Ẹ̀kọ́ Tá A Rí Kọ́:
32:8, 9. Ọgbọ́n ò kan tàgbà. Kéèyàn tó lè ní ọgbọ́n, onítọ̀hún ní láti lóye Ọ̀rọ̀ ọlọ́run kí ẹ̀mí mímọ́ sì máa tọ́ ọ sọ́nà.
34:36. Bí ohun kan bá ‘dán wa wò dé góńgó’ lọ́nà kan tàbí òmíràn àmọ́ tá ò yẹsẹ̀ lórí ìgbàgbọ́ wà, ìyẹn ló máa fi hàn pé adúróṣinṣin ni wá.
35:2. Élíhù tẹ́tí sílẹ̀ ó sì mọ ohun tó jẹ́ ìṣòro Jóòbù gan-an kó tó wá gbẹ́nu lé ọ̀rọ̀. (Jóòbù 10:7; 16:7; 34:5) Bákan náà, káwọn alàgbà ìjọ tó fún ẹnì kan nímọ̀ràn, wọ́n ní láti kọ́kọ́ fara balẹ̀ gbọ́ ìdí ọ̀rọ̀, kí wọ́n sì mọ gbogbo kúlẹ̀kúlẹ̀ rẹ̀.—Òwe 18:13.
37:14; 38:1-39:30. Tá a bá ń ṣàṣàrò lórí àwọn ohun ìyanu tí Jèhófà ṣe tó fi hàn pé ọlọ́gbọ́n àti alágbára ni, èyí á jẹ́ ká lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀, á sì jẹ́ ká rí i pé ìdáláre Jèhófà gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ ṣe pàtàkì ju ohun tí ì báà jẹ àwa ọmọ èèyàn lógún lọ.—Mátíù 6:9, 10.
40:1-4. Nígbà tó bá ń ṣe wá bíi pé ká ráhùn sí Olódùmarè, ńṣe ló yẹ ká ‘fi ọwọ́ wa lé ẹnu wa.’
40:15–41:34. Agbára Béhémótì (erinmi) àti ti Léfíátánì (ọ̀nì) mà pọ̀ o! Tá a bá fẹ́ máa ṣe iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run nìṣó, àwa náà gbọ́dọ̀ máa gba okun látọ̀dọ̀ Ẹni tó dá àwọn ẹranko alágbára wọ̀nyí, ìyẹn Jèhófà, ẹni tó ń fún wa lágbára.—Fílípì 4:13.
42:1-6. Bí Jóòbù ṣe gbọ́ ọ̀rọ̀ ẹnu Jèhófà àti bí Jèhófà ṣe rán an létí nípa bí òun ṣe ń fi agbára òun hàn ló mú kí Jóòbù “rí Ọlọ́run,” ìyẹn láti mọ òtítọ́ nípa rẹ̀. (Jóòbù 19:26) Èyí ló yí Jóòbù lérò padà. Bí wọ́n bá fi Bíbélì bá wa wí, ó yẹ ká tètè gba àṣìṣe wa ká sì ṣàtúnṣe.
Ẹ Jẹ́ Ká Ní Irú “Ìfaradà Jóòbù”
Ìwé Jóòbù jẹ́ kó ṣe kedere pé Ọlọ́run kọ́ ló fa ìjìyà àwa ẹ̀dá èèyàn. Sátánì ni. Bí Ọlọ́run ṣe fàyè gba ìwà ibi lórí ilẹ̀ ayé yìí fún kálukú wa láǹfààní láti fi hàn bóyá a gbà pé Jèhófà ni ọba aláṣẹ ayé òun ọ̀run, àti láti fi hàn bóyá adúróṣinṣin ni wá.
Gbogbo àwọn tó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà ni yóò rí ìdánwò bí Jóòbù ṣe rí ìdánwò. Ìtàn Jóòbù fi dá wa lójú pé a lè fara da ìdánwò èyíkéyìí. Ó rán wa létí pé ìṣòro wa á dópin lọ́jọ́ kan. Jákọ́bù 5:11 sọ pé: “Ẹ ti gbọ́ nípa ìfaradà Jóòbù, ẹ sì ti rí ìyọrísí tí Jèhófà mú wá.” Jèhófà san Jóòbù lẹ́san rere nítorí ìdúróṣinṣin rẹ̀. (Jóòbù 42:10-17) Ẹ ò rí i pé ohun àgbàyanu là ń retí, ìyẹn ni ìyè ayérayé nínú Párádísè orí ilẹ̀ ayé! Nítorí náà, ẹ́ jẹ́ ká pinnu pé a óò jẹ́ adúróṣinṣin bíi ti Jóòbù.—Hébérù 11:6.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ìtàn ohun tó ṣẹlẹ̀ ní ohun tó lé ní ogóje ọdún ló wà nínú ìwé Jóòbù, ìyẹn láti ọdún 1657 sí ọdún 1473 ṣáájú Sànmánì Kristẹni.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]
Ẹ̀kọ́ wo la lè rí kọ́ látinú “ìfaradà Jóòbù”?